ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 4/1 ojú ìwé 32
  • “Ẹ Nílò Ìfaradà”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Ẹ Nílò Ìfaradà”
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 4/1 ojú ìwé 32

“Ẹ Nílò Ìfaradà”

ANÍLÒ “ìfaradà,” láti lè rí “ìmúṣẹ ìlérí naa” gbà. (Heberu 10:36) Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan nínú Bibeli, ṣàlàyé pé ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà fún “ìfaradà” tí aposteli Paulu lo nínú ẹsẹ ìwé yìí, nígbà míràn máa ń ṣiṣẹ́ láti ṣàlàyé “agbára tí irúgbìn ní láti wà láàyè lábẹ́ ipò tí ó le koko tí kò sì fara rọ.”

Irú irúgbìn kan bẹ́ẹ̀ máa ń hù ní orí àwọn òkè ní Europe. Bí ó ti yani lẹ́nu tó, a ń pè é ní agbáyépẹ́. Dájúdájú, irúgbìn orí òkè yìí kì í wà láàyè títí láé, ṣùgbọ́n ó máa ń fara dà bí ọdún ti ń gorí ọdún, ní mímú àwọn òdòdó rírẹwà jáde ní gbogbo ìgbà ẹ̀rùn. Ìwé agbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica ṣàlàyé pé, orúkọ náà, agbáyépẹ́, ni a fún irúgbìn náà nítorí pé ara rẹ̀ gbàyà, kì í sì í kú bọ̀rọ̀.” (Sempervivum tí ó jẹ́ orúkọ ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ fún irú àwọn irúgbìn yìí tún túmọ̀ sí “agbáyépẹ́.”

Ohun kíkàmàmà lára irúgbìn tí kì í kú bọ̀rọ̀ yìí ni pé, ó ń hù ní bi tí kò fara rọ rárá. A lè rí i ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè gíga fíofío tí ìjì ń gbá mọ́ féfé, níbi tí ìwọ̀n ìtutù ti lè lọ sílẹ̀ sí ìwọ̀n 35 lórí ìdiwọ̀n Celsius ní wákàtí 24 péré. Ó lè ta gbòǹgbò nínú àpáta tí ó lanu tí ó ní erùpẹ̀ díẹ̀. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ohun tí ó fà á tí ó fi lè fara dà lábẹ́ irú ipò tí ó ṣòro bẹ́ẹ̀?

Ewé agbáyépẹ́ lẹ̀ lọ́wọ́, ó sì máa ń tọ́jú omi pa mọ́ dáradára. Èyí ń mú kí ó lo omi tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó láti ara òjò àti yìnyín yíyọ́ ní kíkún. Ní àfikún sí i, ó máa ń hù ní ìṣùjọ tí ń mú okun wọn pa pọ̀ láti lè lẹ̀ típẹ́típẹ́ mọ́ ara àpáta tí wọ́n fara tì. Nípa títa gbòǹgbò nínú àpáta tí ó là, ó ní ìwọ̀n ìdáàbòbò díẹ̀ lòdì sí àwọn ipò inú erùpẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé erùpẹ̀ díẹ̀ ni ó ṣeé ṣe kí ó wà níbẹ̀. Ní èdè míràn, ó ń wà láàyè nípa lílo àǹfààní àyíká ipò líle koko náà ní kíkún.

Nípa tẹ̀mí, a lè bá ara wa ni àwọn ipò tí ń dán bí ìfaradà wa ti jẹ́ ojúlówó tó wò. Kí ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti fara dà lábẹ́ ìdánwò? Gẹ́gẹ́ bí irúgbìn agbáyépẹ́, a lè tọ́jú omi afúnniníyè ti Ọ̀rọ̀ Ọlọrun pa mọ́, kí a sì máa kẹ́gbẹ́ pọ̀ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn Kristian tòótọ́ fún ìtìlẹyìn àti ààbò. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, bí irúgbìn orí òkè náà, a gbọ́dọ̀ dìrọ̀ pinpin mọ́ “àpáta” wa, Jehofa, àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ètò àjọ rẹ̀ pẹ̀lú.—2 Samueli 22:3.

Lóòótọ́, irúgbìn agbáyépẹ́ jẹ́ ìránnilétí tí ó fani mọ́ra pé, àní ní àwọn ipò tí ó ṣòro pàápàá, a lè fara dà bí a bá lo àǹfààní ìpèsè tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó ní kíkún. Jehofa fi dá wa lójú pé irú ìfaradà bẹ́ẹ̀ yóò yọrí sí ‘jíjogún àwọn ìlérí náà,’ tí yóò túmọ̀ sí wíwà láàyè títí láé ní ti gidi fún wa.—Heberu 6:12; Matteu 25:46.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́