-
Ṣé bíi Ti Jèhófà Lo Ṣe Ń Bìkítà Nípa Àwọn Ẹlòmíì?Ilé Ìṣọ́—2007 | June 15
-
-
Tá a bá wo ètò ìjọ Kristẹni, àá rí i pé Jèhófà bìkítà nípa àwọn tó wà nínú ìjọ. Jésù Kristi tí í ṣe Orí ìjọ ní káwọn alàgbà máa bójú tó agbo. (Jòhánù 21:15-17) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tó túmọ̀ sí alábòójútó tan mọ́ ọ̀rọ̀ ìṣe kan tó túmọ̀ sí láti “ṣọ́ lójú méjèèjì.” Pétérù tẹnu mọ́ ọ̀nà tó yẹ káwọn alàgbà gbà ṣe é, ó ní: “Ẹ máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run tí ń bẹ lábẹ́ àbójútó yín, kì í ṣe lábẹ́ àfipáṣe, bí kò ṣe tinútinú; bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe nítorí ìfẹ́ fún èrè àbòsí, bí kò ṣe pẹ̀lú ìháragàgà; bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe bí ẹní ń jẹ olúwa lé àwọn tí í ṣe ogún Ọlọ́run lórí, ṣùgbọ́n kí ẹ di àpẹẹrẹ fún agbo.”—1 Pétérù 5:2, 3.
-
-
Ṣé bíi Ti Jèhófà Lo Ṣe Ń Bìkítà Nípa Àwọn Ẹlòmíì?Ilé Ìṣọ́—2007 | June 15
-
-
Àmọ́ ọ̀rọ̀ Pétérù tá a ṣàyọlò yìí jẹ́ ká mọ̀ nípa ewu kan, ìyẹn ni pé káwọn alàgbà má lọ máa “jẹ olúwa lé” ìjọ lórí. Ọ̀nà kan tí alàgbà kan lè gbà jẹ olúwa lé ìjọ lórí ni tó bá ń ṣe òfin tí kò pọn dandan. Níbi tí alàgbà kan ti ń gbìyànjú láti ṣe ojúṣe rẹ̀ láti bójú tó agbo, ó lè ṣàṣejù. Àwọn alàgbà ìjọ kan lápá Ìlà Oòrùn Ayé ṣòfin nípa bó ṣe yẹ́ káwọn ará máa kíra nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n sọ ẹni tó yẹ kó kọ́kọ́ kí ẹnì kejì táwọn méjì bá pàdé. Èrò wọn ni pé irú òfin bẹ́ẹ̀ á jẹ́ kí àlàáfíà túbọ̀ wà nínú ìjọ. Lóòótọ́, nǹkan dáadáa ló wà lọ́kàn wọn tí wọ́n fi ṣe irú òfin bẹ́ẹ̀, àmọ́ ṣé bí Jèhófà ṣe ń bójú tó àwọn èèyàn rẹ̀ ni wọ́n ṣe ń bójú tó wọn yẹn? Ní ti Pọ́ọ̀lù, irú ẹ̀mí tó ní hàn nínú ọ̀rọ̀ kan tó sọ, ó ní: “Kì í ṣe pé a jẹ́ ọ̀gá lórí ìgbàgbọ́ yín, ṣùgbọ́n a jẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ fún ìdùnnú yín, nítorí nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ yín ni ẹ dúró.” (2 Kọ́ríńtì 1:24) Ẹ ẹ̀ rí i pé Jèhófà fọkàn tán àwọn èèyàn rẹ̀.
-