ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 6/15 ojú ìwé 18-20
  • Ṣé bíi Ti Jèhófà Lo Ṣe Ń Bìkítà Nípa Àwọn Ẹlòmíì?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé bíi Ti Jèhófà Lo Ṣe Ń Bìkítà Nípa Àwọn Ẹlòmíì?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ọlọ́run Nínú Bó O Ṣe Ń Bójú Tó Àwọn Ọmọ Rẹ
  • Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jèhófà Nínú Bó O Ṣe Ń Bójú Tó Agbo Rẹ̀
  • “Ẹ Máa Ṣe Olùṣọ́ Àgùntàn Agbo Ọlọ́run Tí Ń bẹ Lábẹ́ Àbójútó Yín”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Ẹ̀yin Olùṣọ́ Àgùntàn, Ẹ Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Àwọn Olùṣọ́ Àgùntàn Ńlá Náà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Ṣègbọràn sí Àwọn Olùṣọ́ Àgùntàn tí Jèhófà Yàn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Fifi Jẹlẹnkẹ Bojuto Awọn Agutan Ṣiṣeyebiye Ti Jehofa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 6/15 ojú ìwé 18-20

Ṣé bíi Ti Jèhófà Lo Ṣe Ń Bìkítà Nípa Àwọn Ẹlòmíì?

‘Ẹ KÓ gbogbo àníyàn yín lé Ọlọ́run, nítorí ó bìkítà fún yín.’ (1 Pétérù 5:7) Ohun tí Bíbélì rọ̀ wá pé ká ṣe yìí mà ń tuni lára o! Jèhófà Ọlọ́run bìkítà nípa àwọn èèyàn rẹ̀ gan-an ni. Ọkàn wa balẹ̀ bó ṣe ń bójú tó wa.

Ó yẹ káwa náà jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àwọn ẹlòmíì máa jẹ wá lógún ká sì máa ṣe ohun tó máa fi hàn bẹ́ẹ̀. Àmọ́, níwọ̀n bá a ti jẹ́ aláìpé, àwọn nǹkan kan wà tó yẹ ká ṣọ́ra fún tá a bá ń ṣaájò àwọn ẹlòmíì. Ká tó gbé díẹ̀ lára àwọn nǹkan náà yẹ̀ wò, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ wo àwọn ọ̀nà kan tí Jèhófà gbà ń bójú tó àwọn èèyàn rẹ̀.

Nígbà tí onísáàmù náà Dáfídì ń sọ̀rọ̀ nípa bí Ọlọ́run ṣe ń bójú tóni, ó lo àpẹẹrẹ olùṣọ́ àgùntàn, ó ní: “Jèhófà ni Olùṣọ́ Àgùntàn mi. Èmi kì yóò ṣaláìní nǹkan kan. Ó ń mú mi dùbúlẹ̀ ní pápá ìjẹko tí ó kún fún koríko; ó ń darí mi lẹ́bàá àwọn ibi ìsinmi tí ó lómi dáadáa. Ó ń tu ọkàn mi lára. . . . Bí mo tilẹ̀ ń rìn ní àfonífojì ibú òjìji, èmi kò bẹ̀rù ohun búburú kankan, nítorí tí ìwọ wà pẹ̀lú mi.”—Sáàmù 23:1-4.

Níwọ̀n bí Dáfídì alára ti jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn, ó mọ ohun tó gbà láti bójú tó agbo àgùntàn. Olùṣọ́ àgùntàn máa ń dáàbò bo àwọn àgùntàn kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹranko tó lè pa wọ́n jẹ, irú bíi kìnnìún, ìkookò àti béárì. Kì í jẹ́ kí àwọn àgùntàn rẹ̀ tú ká, ó máa ń wá àgùntàn tó bá sọ nù, ó máa ń gbé èyí tó bá rẹ̀ sí oókan àyà rẹ̀, ó sì máa ń tọ́jú èyí tí ara rẹ̀ ò bá yá tàbí èyí tó fara pa. Ó máa ń rí i pé wọ́n ń rí omi mu lójoojúmọ́. Èyí kò túmọ̀ sí pé gbogbo ìgbésẹ̀ àgùntàn ni olùṣọ́ àgùntàn máa ń darí. Àwọn àgùntàn lè rìn fàlàlà, síbẹ̀, olùṣọ́ àgùntàn máa ń rí i pé ewu ò wu wọ́n.

Bí Jèhófà ṣe ń bójú tó àwọn èèyàn rẹ̀ nìyẹn. Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé: ‘Agbára Ọlọ́run ń fi ìṣọ́ ṣọ́ yín.’ Ní olówuuru, “fífi ìṣọ́ ṣọ́” tó wà nínú ẹsẹ Bíbélì yìí túmọ̀ sí ṣíṣọ́ ohun kan lójú méjèèjì. (1 Pétérù 1:5) Nítorí ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa, ìgbà gbogbo ló máa ń fi ìṣọ́ ṣọ́ wa, ó sì ṣe tán láti ràn wá lọ́wọ́ nígbàkigbà tá a bá ké pè é. Àmọ́ Jèhófà dá wa lọ́nà tá a fi lè yan ohun tó bá wù wá, nítorí náà, kì í ṣe gbogbo ohun tá a bá ń ṣe ló ń pinnu fún wa. Báwo la ṣe lè fara wé Jèhófà lọ́nà yìí?

Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ọlọ́run Nínú Bó O Ṣe Ń Bójú Tó Àwọn Ọmọ Rẹ

“Àwọn ọmọ jẹ́ ogún láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.” Nítorí náà, ó yẹ káwọn òbí máa dáàbò bo àwọn ọmọ wọn kí wọ́n sì máa bójú tó wọn. (Sáàmù 127:3) Ìyẹn lè gba pé kí wọ́n máa gbà wọ́n níyànjú kí wọ́n sọ èrò wọn àti bí nǹkan ṣe rí lára wọn, kí wọ́n wá máa fi ìyẹn sọ́kàn nígbà tí wọ́n bá ń tọ́ wọn. Bí òbí bá fẹ́ máa pinnu gbogbo nǹkan fún ọmọ rẹ̀, tí ò gba ìfẹ́ ọkàn ọmọ rẹ̀ rò rárá, ńṣe ló máa dà bí ìgbà tí olùṣọ́ àgùntàn fi okùn sọ́rùn àgùntàn rẹ̀ tó wá fi ń fà á káàkiri. A mọ̀ pé kò sí olùṣọ́ àgùntàn táá fẹ́ máa darí agbo àgùntàn rẹ̀ bẹ́ẹ̀; Jèhófà kì í sì í darí wa lọ́nà yẹn.

Òbí kan tó ń jẹ́ Marikoa sọ pé: “Fún ọ̀pọ̀ ọdún, ńṣe ni mo kàn máa ń sọ fáwọn ọmọ mi pé, ‘Ṣe tibí, ṣe tọ̀hún, eléyìí ni kó o ṣe, má ṣèyẹn.’ Èrò mi ni pé ojúṣe mi gẹ́gẹ́ bí òbí ni mò ń ṣe. N kì í yìn wọ́n, bẹ́ẹ̀ ni n kì í bá wọn ní ìjíròrò gidi.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọbìnrin Mariko máa ń bá àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀ fún ọ̀pọ̀ wákàtí lórí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀, òun àti ìyá rẹ̀ kì í lè bára wọn sọ̀rọ̀ pẹ́ lọ títí. Mariko ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “Nígbà tó yá, mo wá rí ohun tó fa ìyàtọ̀ yìí. Àwọn nǹkan kan wà tí ọmọ mi yìí ń ṣe tí èmi kì í ṣe. Tó bá ń bá àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀, mo rí i pé ó máa ń lo àwọn ọ̀rọ̀ tó fi hàn pé ó lẹ́mìí ìfọ̀rọ̀-rora-ẹni-wò, ìyẹn àwọn ọ̀rọ̀ bíi, ‘Òótọ́ ni, mo gbà’ tàbí ‘Bó ṣe rí lójú tèmi náà nìyẹn.’ Èmi náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í lo irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ láti fi mú kí ọmọ mi yìí lè máa sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀. Kò pẹ́ kò jìnnà, a bẹ̀rẹ̀ sí í bára wa sọ̀rọ̀ pẹ́ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, a sì túbọ̀ ń gbádùn ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ wa.” Èyí fi hàn pé ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ tó mọ́yán lórí ṣe pàtàkì. Sọ-kí-n-sọ ló sì yẹ kí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ jẹ́, kì í ṣe pé kẹ́nì kan máa dá gbogbo ọ̀rọ̀ sọ.

Ó ṣe pàtàkì pé káwọn òbí fọgbọ́n mú kí àwọn ọmọ wọn sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn, ó sì yẹ káwọn ọmọ mọ ìdí tí àníyàn táwọn òbí wọn ń ṣe lórí wọn fi jẹ́ ààbò fún wọn. Bíbélì sọ fáwọn ọmọ pé kí wọ́n máa gbọ́ràn sáwọn òbí wọn lẹ́nu, ó sì wá sọ ìdí rẹ̀, ó ní: “Kí nǹkan lè máa lọ dáadáa fún ọ, kí ìwọ sì lè wà fún àkókò gígùn lórí ilẹ̀ ayé.” (Éfésù 6:1, 3) Tó bá dá àwọn ọmọ lójú hán-únhán-ún pé àǹfààní wà nínú káwọn fi ara àwọn sábẹ́ àwọn òbí àwọn, ó máa ń túbọ̀ rọrùn fún wọn láti máa gbọ́ràn sí wọn lẹ́nu.

Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jèhófà Nínú Bó O Ṣe Ń Bójú Tó Agbo Rẹ̀

Tá a bá wo ètò ìjọ Kristẹni, àá rí i pé Jèhófà bìkítà nípa àwọn tó wà nínú ìjọ. Jésù Kristi tí í ṣe Orí ìjọ ní káwọn alàgbà máa bójú tó agbo. (Jòhánù 21:15-17) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tó túmọ̀ sí alábòójútó tan mọ́ ọ̀rọ̀ ìṣe kan tó túmọ̀ sí láti “ṣọ́ lójú méjèèjì.” Pétérù tẹnu mọ́ ọ̀nà tó yẹ káwọn alàgbà gbà ṣe é, ó ní: “Ẹ máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run tí ń bẹ lábẹ́ àbójútó yín, kì í ṣe lábẹ́ àfipáṣe, bí kò ṣe tinútinú; bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe nítorí ìfẹ́ fún èrè àbòsí, bí kò ṣe pẹ̀lú ìháragàgà; bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe bí ẹní ń jẹ olúwa lé àwọn tí í ṣe ogún Ọlọ́run lórí, ṣùgbọ́n kí ẹ di àpẹẹrẹ fún agbo.”—1 Pétérù 5:2, 3.

Dájúdájú, iṣẹ́ àwọn alàgbà jọ tàwọn olùṣọ́ àgùntàn. Àwọn Kristẹni alàgbà ní láti máa bójú tó àwọn tó ń ṣàìsàn nípa tẹ̀mí kí wọ́n sì tọ́ wọn sọ́nà kí wọ́n lè padà máa tẹ̀ lé ìlànà òdodo. Àwọn alàgbà ló máa ń ṣètò ìgbòkègbodò ìjọ, àwọn ló ń ṣètò ìpàdé, wọ́n sì máa ń rí i pé gbogbo nǹkan ń lọ létòlétò nínú ìjọ.—1 Kọ́ríńtì 14:33.

Àmọ́ ọ̀rọ̀ Pétérù tá a ṣàyọlò yìí jẹ́ ká mọ̀ nípa ewu kan, ìyẹn ni pé káwọn alàgbà má lọ máa “jẹ olúwa lé” ìjọ lórí. Ọ̀nà kan tí alàgbà kan lè gbà jẹ olúwa lé ìjọ lórí ni tó bá ń ṣe òfin tí kò pọn dandan. Níbi tí alàgbà kan ti ń gbìyànjú láti ṣe ojúṣe rẹ̀ láti bójú tó agbo, ó lè ṣàṣejù. Àwọn alàgbà ìjọ kan lápá Ìlà Oòrùn Ayé ṣòfin nípa bó ṣe yẹ́ káwọn ará máa kíra nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n sọ ẹni tó yẹ kó kọ́kọ́ kí ẹnì kejì táwọn méjì bá pàdé. Èrò wọn ni pé irú òfin bẹ́ẹ̀ á jẹ́ kí àlàáfíà túbọ̀ wà nínú ìjọ. Lóòótọ́, nǹkan dáadáa ló wà lọ́kàn wọn tí wọ́n fi ṣe irú òfin bẹ́ẹ̀, àmọ́ ṣé bí Jèhófà ṣe ń bójú tó àwọn èèyàn rẹ̀ ni wọ́n ṣe ń bójú tó wọn yẹn? Ní ti Pọ́ọ̀lù, irú ẹ̀mí tó ní hàn nínú ọ̀rọ̀ kan tó sọ, ó ní: “Kì í ṣe pé a jẹ́ ọ̀gá lórí ìgbàgbọ́ yín, ṣùgbọ́n a jẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ fún ìdùnnú yín, nítorí nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ yín ni ẹ dúró.” (2 Kọ́ríńtì 1:24) Ẹ ẹ̀ rí i pé Jèhófà fọkàn tán àwọn èèyàn rẹ̀.

Yàtọ̀ sí pé àwọn alàgbà tó ń fìfẹ́ bójú tó agbo kì í ṣòfin tí ò bá ìlànà Ìwé Mímọ́ mu, ẹ̀mí ìgbatẹnirò tún máa ń mú kí wọ́n yẹra fún sísọ ọ̀rọ̀ àṣírí ẹlòmíì fáyé gbọ́. Wọ́n máa ń fi ìkìlọ̀ tí Ọlọ́run ṣe sọ́kàn, pé: “Má [ṣe] ṣí ọ̀rọ̀ àṣírí ẹlòmíràn payá.”—Òwe 25:9.

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi ìjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró wé ara ènìyàn, ó ní: “Ọlọ́run pa ara pọ̀ ṣọ̀kan . . . kí ó má bàa sí ìpínyà kankan nínú ara, ṣùgbọ́n kí àwọn ẹ̀yà ara rẹ̀ lè ní aájò kan náà fún ara wọn.” (1 Kọ́ríńtì 12:12, 24-26) Ní olówuuru, gbólóhùn náà “ní aájò kan náà fún ara wọn” ní èdè Gíríìkì túmọ̀ sí ‘máa ṣàníyàn nípa ara wọn.’ Ó yẹ káwọn tó wà nínú ìjọ Kristẹni máa wa ire ara wọn lójú méjèèjì.—Fílípì 2:4.

Báwo làwọn Kristẹni tòótọ́ ṣe lè fi hàn pé wọ́n ń ‘ṣàníyàn nípa ara wọn lẹ́nì-kìíní-kejì’? Wọ́n lè fi hàn pé wọ́n ń ṣàníyàn nípa àwọn tí wọ́n jọ wà nínú ìjọ nípa fífi wọ́n sádùúrà àti nípa ríran àwọn tó jẹ́ aláìní lọ́wọ́. Èyí máa ń jẹ́ kí wọ́n lè dẹni tó wúlò. Wo bí fífi tí ìdílé kan fi irú àníyàn bẹ́ẹ̀ hàn sí ọmọkùnrin kan tó ń jẹ́ Tadataka ṣe ràn án lọ́wọ́. Nígbà tó ṣèrìbọmi lọ́mọ ọdún mẹ́tàdínlógún, òun nìkan ni olùjọsìn Jèhófà nínú ìdílé rẹ̀. Ó sọ pé: “Ìdílé kan nínú ìjọ wa sábà máa ń pè mí pé kí n wá báwọn jẹun tàbí kí n wá gbádùn ìfararora pẹ̀lú àwọn ará. Ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ lè jẹ́ àràárọ̀ ni mo máa ń ya ilé wọn tí mo bá ń lọ sí iléèwé kí n lè bá wọn ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ojoojúmọ́. Wọ́n máa ń fún mi nímọ̀ràn nípa ohun tí mo lè ṣe tí mo bá níṣòro níléèwé, a sì jọ máa ń gbàdúrà nípa àwọn ìṣòro náà. Ara ìdílé yìí ni mo ti kọ́ ìwà ọ̀làwọ́.” Ní báyìí, Tadataka ń fi ohun tó kọ́ sílò, ó ń ṣiṣẹ́ Ọlọ́run ní ọ̀kan lára ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣèkìlọ̀ nípa ọ̀fìn tó yẹ kéèyàn kíyè sí tó bá ń ṣàníyàn nípa àwọn ẹlòmíràn. Ó mẹ́nu kan àwọn obìnrin kan tí wọ́n di ‘olófòófó àti alátojúbọ àlámọ̀rí àwọn ẹlòmíràn, tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí kò yẹ kí wọ́n sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.’ (1 Tímótì 5:13) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó dára ká máa ṣàníyàn nípa àwọn ẹlòmíràn, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra ká má lọ ṣe é débi tá a ó fi máa tojú bọ ọ̀rọ̀ tí kò kàn wá. Tá a bá ‘ń sọ ohun tí kò yẹ ká máa sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀,’ bí àpẹẹrẹ, tá à ń ṣàríwísí wọn, ìyẹn á fi hàn pé a ti ń ṣàníyàn nípa àwọn ẹlòmíràn lọ́nà tí kò yẹ.

Ó yẹ ká rántí pé bí Kristẹni kan ṣe máa ṣe nǹkan tiẹ̀ kọ́ ni Kristẹni míì máa ṣe é, bákan náà, oúnjẹ àti eré ìtura bíbójú mu tí kálukú wọn nífẹ̀ẹ́ sí lè má dọ́gba. Olúkúlùkù ló lómìnira láti yan ohun tó fẹ́ ṣe, tí kò bá ti ta ko ìlànà tó wà nínú Bíbélì. Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn Kristẹni tó wà ní Róòmù pé: “Kí a má ṣe máa dá ara wa lẹ́jọ́ mọ́ lẹ́nì kìíní-kejì. . . . Ẹ jẹ́ kí a máa lépa àwọn ohun tí ń yọrí sí àlàáfíà àti àwọn ohun tí ń gbéni ró fún ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.” (Róòmù 14:13, 19) Bá a ṣe ń fi tọkàntọkàn ṣàníyàn nípa àwọn tá a jọ wà nínú ìjọ, ńṣe ni ká múra tán láti ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n bá nílò rẹ̀, kì í ṣe pé ká máa tojú bọ ọ̀ràn wọn. Tá a bá ń bìkítà nípa ara wa lọ́nà yìí, ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan á gbilẹ̀ nínú ìdílé àti nínú ìjọ.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Mú káwọn ọmọ rẹ sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn nípa yíyìn wọ́n àti fifi ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀-rora-ẹni wò hàn

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́