-
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn ÒǹkàwéIlé Ìṣọ́—2003 | December 15
-
-
Ó yẹ kí ohun kan ṣe kedere, ìyẹn ni pé, ká tiẹ̀ tó lé Èṣù àtàwọn áńgẹ́lì burúkú yìí jáde pàápàá, nígbà tí wọ́n ṣì lè wọ ọ̀run, ẹni ìtanù ni wọ́n jẹ́ nínú ìdílé Ọlọ́run, wọ́n sì wà lábẹ́ àwọn ìkálọ́wọ́kò kan. Bí àpẹẹrẹ, Júúdà ẹsẹ kẹfà fi hàn pé ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa pàápàá, a ti “fi [wọ́n] pa mọ́ de ìdájọ́ ọjọ́ ńlá náà pẹ̀lú àwọn ìdè ayérayé lábẹ́ òkùnkùn biribiri.” Bákan náà, 2 Pétérù 2:4 sọ pé: “Ọlọ́run kò . . . fawọ́ sẹ́yìn ní fífìyàjẹ àwọn áńgẹ́lì tí ó ṣẹ̀, ṣùgbọ́n, nípa sísọ wọ́n sínú Tátárọ́sì [ipò ẹ̀tẹ́ gbáà], ó jù wọ́n sínú àwọn kòtò òkùnkùn biribiri [nípa tẹ̀mí] láti fi wọ́n pa mọ́ de ìdájọ́.”b
-
-
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn ÒǹkàwéIlé Ìṣọ́—2003 | December 15
-
-
b Àpọ́sítélì Pétérù fi ipò ìtanù nípa tẹ̀mí yìí wé bí ìgbà téèyàn wà nínú “ẹ̀wọ̀n.” Àmọ́ ṣá, kì í ṣe “ọ̀gbun àìnísàlẹ̀” tí a ó sọ àwọn ẹ̀mí èṣù sí fún ẹgbẹ̀rún ọdún ni Pétérù ń sọ o.—1 Pétérù 3:19, 20; Lúùkù 8:30, 31; Ìṣípayá 20:1-3.
-