ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Énọ́kù Bá Ọlọ́run Rìn Nínú Ayé Aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́—2001 | September 15
    • Ó Sọ Àsọtẹ́lẹ̀ Lòdì sí Àwọn Aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run

      Kì í rọrùn rárá láti tẹ̀ lé ìlànà ìwà rere nígbà táwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run bá yí wa ká. Àmọ́ Énọ́kù tún jẹ́ iṣẹ́ ìdájọ́ mímúná lòdì sí àwọn olubi. Ẹ̀mí Ọlọ́run darí Énọ́kù láti sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Wò ó! Jèhófà wá pẹ̀lú ẹgbẹẹgbàárùn-ún rẹ̀ mímọ́, láti mú ìdájọ́ ṣẹ ní kíkún sí gbogbo ènìyàn, àti láti dá gbogbo aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run lẹ́bi nípa gbogbo ìṣe àìṣèfẹ́ Ọlọ́run wọn, èyí tí wọ́n ṣe lọ́nà àìṣèfẹ́ Ọlọ́run, àti nípa gbogbo ohun amúnigbọ̀nrìrì tí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run ti sọ lòdì sí i.”—Júúdà 14, 15.

      Ipa wo ni iṣẹ́ yẹn máa ní lórí àwọn aláìgbàgbọ́ tí ń hu ìwàkiwà? Láìṣẹ̀ṣẹ̀ máa sọ, irú ọ̀rọ̀ títanilára bẹ́ẹ̀ á mú kí wọ́n máa fojú burúkú wo Énọ́kù, wọ́n á tilẹ̀ máa fi í ṣẹ̀sín, wọ́n á máa pẹ̀gàn rẹ̀, wọ́n á sì máa halẹ̀ mọ́ ọn. Àwọn kan á tiẹ̀ fẹ́ rẹ́yìn rẹ̀ pátápátá. Àmọ́ ṣá o, ẹ̀rù ò ba Énọ́kù. Ó mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ébẹ́lì olódodo, Énọ́kù sì ti pinnu pé àforí-àfọrùn, òun ti ṣe tán láti sin Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí Ébẹ́lì ti ṣe.

  • Énọ́kù Bá Ọlọ́run Rìn Nínú Ayé Aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́—2001 | September 15
    • [Àpótí tó wà ní ojú ìwé 30]

      Ǹjẹ́ Bíbélì Fa Ọ̀rọ̀ Yọ Látinú Ìwé Énọ́kù?

      Ìwé tí wọ́n ń pè ní Ìwé Énọ́kù kì í ṣe ara Ìwé Mímọ́, kì í sì í ṣe Énọ́kù ló kọ ọ́ ní ti gidi. Wọ́n kàn parọ́ mọ́ Énọ́kù pé òun lọ́ kọ ọ́ ni. Ó ní láti jẹ́ ọ̀rúndún kejì tàbí èkíní ṣááju Sànmánì Tiwa ni wọ́n kọ ọ́. Inú ìtàn àròsọ àwọn Júù tó kún fún àbùmọ́ ló ti wá. Ó sì hàn gbangba pé ọ̀rọ̀ ṣókí tí ìwé Jẹ́nẹ́sísì sọ nípa Énọ́kù ni wọ́n fẹ̀ lójú fẹ̀ nímú. Òkodoro òtítọ́ yìí ti tó láti mú kí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí yàgò pátápátá fún ìwé yìí.

      Nínú Bíbélì, ìwé Júúdà nìkan ló sọ̀rọ̀ nípa àsọtẹ́lẹ̀ Énọ́kù, pé: “Wò ó! Jèhófà wá pẹ̀lú ẹgbẹẹgbàárùn-ún rẹ̀ mímọ́, láti mú ìdájọ́ ṣẹ ní kíkún sí gbogbo ènìyàn, àti láti dá gbogbo aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run lẹ́bi nípa gbogbo ìṣe àìṣèfẹ́ Ọlọ́run wọn, èyí tí wọ́n ṣe lọ́nà àìṣèfẹ́ Ọlọ́run, àti nípa gbogbo ohun amúnigbọ̀nrìrì tí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run ti sọ lòdì sí i.” (Júúdà 14, 15) Ọ̀pọ̀ ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ló ń jiyàn pé inú Ìwé Énọ́kù la ti ṣàyọlò àsọtẹ́lẹ̀ tí Énọ́kù sọ lòdì sí àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run ìgbà ayé rẹ̀. Ó ha ṣeé ṣe kí Júúdà fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ látinú ìwé tí kò ṣeé gbára lé, tí kì í ṣe ara Bíbélì?

      Ìwé Mímọ́ kò ṣàlàyé bí Júúdà ṣe mọ̀ nípa àsọtẹ́lẹ̀ Énọ́kù. Ó kúkú lè jẹ́ pé orísun kan tí gbogbo èèyàn mọ̀ nígbà yẹn ló lò, bóyá ìtàn kan tó ṣeé gbára lé láti ìgbà ìṣẹ̀ǹbáyé. Ó jọ pé Pọ́ọ̀lù ṣe ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ nígbà tó dárúkọ Jánésì àti Jámíbírésì, ìyẹn àwọn pidánpidán tí a kò dárúkọ wọn, tí wọ́n tako Mósè ní ààfin Fáráò. Bí ẹni tó kọ Ìwé Énọ́kù bá mọ̀ nípa irú ìtàn àtayébáyé bẹ́ẹ̀, kí nìdí fún sísẹ́ pé Júúdà pẹ̀lú kò lè mọ̀ nípa irú ìtàn yẹn?a—Ẹ́kísódù 7:11, 22; 2 Tímótì 3:8.

      Bí Júúdà ṣe mọ̀ nípa àsọtẹ́lẹ̀ tí Énọ́kù sọ lòdì sí àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run kì í ṣe nǹkan bàbàrà. Ó ṣeé gbára lé nítorí pé abẹ́ ìmísí ni Júúdà wà nígbà tó ń kọ̀wé. (2 Tímótì 3:16) Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run rí sí i pé kò kọ ọ̀rọ̀ tí kì í ṣòótọ́.

      [Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

      a Sítéfánù ọmọ ẹ̀yìn pẹ̀lú lo ìsọfúnni tí a kò rí níbòmíì nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Ó lò ó nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tí Mósè gbà ní Íjíbítì, jíjẹ́ tó jẹ́ ẹni ogójì ọdún nígbà tó sá fi Íjíbítì sílẹ̀, ogójì ọdún tó fi wà ní ilẹ̀ Mídíánì, àti ipa tí áńgẹ́lì kó nínú títa àtaré Òfin Mósè.—Ìṣe 7:22, 23, 30, 38.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́