ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • “Ìdáǹdè Yín Ń Sún Mọ́lé”!
    Ilé Ìṣọ́—2015 | July 15
    • 16, 17. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ kí ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà tó wáyé ní ọ̀run?

      16 Lẹ́yìn tí gbogbo àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] bá ti wà ní ọ̀run, ìmúrasílẹ̀ tó kẹ́yìn fún ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn lè wá bẹ̀rẹ̀. (Ìṣí. 19:9) Ṣùgbọ́n ohun mìíràn máa ṣẹlẹ̀ kí ìṣẹ̀lẹ̀ aláyọ̀ yẹn tó wáyé. Rántí pé, kí àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì tó lọ sí ọ̀run, Gọ́ọ̀gù máa gbéjà ko àwọn èèyàn Ọlọ́run. (Ìsík. 38:16) Kí ló máa wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà? Ó máa dà bíi pé àwọn èèyàn Ọlọ́run tó wà lórí ilẹ̀ ayé kò ní olùgbèjà. Wọ́n máa ṣègbọràn sí ìtọ́ni tí Ọlọ́run fún àwọn èèyàn nígbà ayé Ọba Jèhóṣáfátì, pé: “Kì yóò sí ìdí kankan fún yín láti jà nínú ọ̀ràn yìí. Ẹ mú ìdúró yín, ẹ dúró jẹ́ẹ́ kí ẹ sì rí ìgbàlà Jèhófà fún yín. Ìwọ Júdà àti Jerúsálẹ́mù, ẹ má fòyà tàbí kí ẹ jáyà.” (2 Kíró. 20:17) Àmọ́, kí ló máa ṣẹlẹ̀ lọ́run? Nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa ìgbà tí gbogbo àwọn ẹni àmì òróró á ti wà ní ọ̀run, Ìṣípayá 17:14 sọ nípa ọ̀tá àwọn èèyàn Ọlọ́run pé: “Àwọn wọ̀nyí yóò bá Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà jagun, ṣùgbọ́n, nítorí pé òun ni Olúwa àwọn olúwa àti Ọba àwọn ọba, Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà yóò ṣẹ́gun wọn. Pẹ̀lúpẹ̀lù, àwọn tí a pè, tí a yàn, tí wọ́n sì jẹ́ olùṣòtítọ́ pẹ̀lú rẹ̀ yóò ṣe bẹ́ẹ̀.” Jésù àti àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì tí wọ́n máa bá a ṣàkóso ní ọ̀run máa wá láti gbèjà àwọn èèyàn Ọlọ́run tó wà lórí ilẹ̀ ayé.

      17 Èyí máa yọrí sí ogun Amágẹ́dọ́nì. Ogun yìí á sì gbé orúkọ mímọ́ Jèhófà ga. (Ìṣí. 16:16) Nígbà yẹn, gbogbo àwọn tó bá jẹ́ ewúrẹ́ máa “lọ sínú ìkékúrò àìnípẹ̀kun.” Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, gbogbo ìwà ibi á ti di àwátì, àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá á sì la apá tó kẹ́yìn lára ìpọ́njú ńlá náà já. Lẹ́yìn tí gbogbo ìmúrasílẹ̀ bá ti parí, ìwé Ìṣípayá á wá dé ìparí rẹ̀, ìyẹn ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà. (Ìṣí. 21:1-4)d Gbogbo àwọn tó la ìpọ́njú ńlá náà já lórí ilẹ̀ ayé á máa yọ̀ torí pé wọ́n rí ojúure Ọlọ́run, wọ́n sì ń gbádùn ọ̀pọ̀ yanturu ìfẹ́ tó fi hàn sí wọn. Àsè ìgbéyàwó yẹn á mà kàmàmà o! Ǹjẹ́ kò máa ṣe wá bíi pé kí ọjọ́ náà ti dé?—Ka 2 Pétérù 3:13.

  • “Ìdáǹdè Yín Ń Sún Mọ́lé”!
    Ilé Ìṣọ́—2015 | July 15
    • d Sáàmù 45 pẹ̀lú sọ̀rọ̀ nípa bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe máa wáyé ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé. Ọba máa kọ́kọ́ jagun, lẹ́yìn yẹn ni ìgbéyàwó náà á wáyé.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́