ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Títẹ Orí Ejò Náà Fọ́
    Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
    • 3. Kí ni Jòhánù sọ fún wa pé yóò ṣẹlẹ̀ sí Sátánì?

      3 Kí ló máa wá ṣẹlẹ̀ sí Sátánì fúnra rẹ̀ àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀? Jòhánù sọ fún wa pé: “Mo sì rí áńgẹ́lì kan tí ń sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run wá pẹ̀lú kọ́kọ́rọ́ ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ àti ẹ̀wọ̀n ńlá ní ọwọ́ rẹ̀. Ó sì gbá dírágónì náà mú, ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà, ẹni tí í ṣe Èṣù àti Sátánì, ó sì dè é fún ẹgbẹ̀rún ọdún. Ó fi í sọ̀kò sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ náà, ó tì í, ó sì fi èdìdì dí i lórí rẹ̀, kí ó má bàa ṣi àwọn orílẹ̀-èdè lọ́nà mọ́ títí ẹgbẹ̀rún ọdún náà yóò fi dópin. Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, a gbọ́dọ̀ tú u fún ìgbà díẹ̀.”—Ìṣípayá 20:1-3.

  • Títẹ Orí Ejò Náà Fọ́
    Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
    • 5. Kí ni áńgẹ́lì ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ náà ṣe sí Sátánì Èṣù, kí sì nìdí?

      5 Nígbà tá a fi dírágónì ńlá aláwọ̀ iná náà sọ̀kò sísàlẹ̀ láti ọ̀run, ìwé Ìṣípayá sọ pé òun ni “ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà, ẹni tí a ń pè ní Èṣù àti Sátánì, ẹni tí ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà.” (Ìṣípayá 12:3, 9) Nígbà tí wọ́n sì gbá a mú láti gbé e sọ sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀, wọ́n tún sọ lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ pé òun ni ‘dírágónì náà, ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀, ẹni tí í ṣe Èṣù àti Sátánì.’ Ẹni ibi tó jẹ́ ajẹnirun, atannijẹ, afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, àti alátakò yìí ni wọ́n fi ẹ̀wọ̀n dè tí wọ́n sì fi sọ̀kò “sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀,” lẹ́yìn náà wọ́n pa á dé wọ́n sì fi èdìdì dì í pinpin, “kí ó má bàa ṣi àwọn orílẹ̀-èdè lọ́nà mọ́.” Ẹgbẹ̀rún ọdún ni Sátánì yóò fi wà nínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ yìí. Láàárín àkókò náà, agbára rẹ̀ lórí aráyé kó ní ju ti ẹlẹ́wọ̀n kan tó wà nínú àjà ilẹ̀ jíjìn. Áńgẹ́lì ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ náà mú Sátánì kúrò lórí ilẹ̀ ayé pátápátá kó má bàa ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú Ìjọba òdodo náà. Ẹ ò rí i pé ìtura ńlá lèyí máa jẹ́ fún aráyé!

  • Títẹ Orí Ejò Náà Fọ́
    Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
    • 7. (a) Ipò wo ni Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ yóò wà nínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ náà, báwo la sì ṣe mọ̀? (b) Ṣé ọ̀kan náà ni Hédíìsì àti ọ̀gbun àìnísàlẹ̀? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)

      7 Ṣé Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ yóò máa báṣẹ́ lọ nígbà tí wọ́n bá wà nínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ náà? Ó dáa, ṣó o rántí ẹranko ẹhànnà olórí méje, aláwọ̀ rírẹ̀dòdò náà tó ‘ti wà tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n tí kò sí, síbẹ̀ tó máa tó gòkè wá láti inú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀’? (Ìṣípayá 17:8) Nígbà tí ẹranko náà wà nínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀, “kò sí.” Ó jẹ́ aláìlè-ṣiṣẹ́, aláìlè-ta-pútú, ká kúkú sọ pé ó ti kú. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa Jésù, ó ní: “‘Ta ni yóò sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀?’ èyíinì ni, láti mú Kristi gòkè wá láti inú òkú.” (Róòmù 10:7) Nígbà tí Jésù wà nínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ yẹn, òkú ni.a Nítorí náà, ó bọ́gbọ́n mu láti sọ pé Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ kò ní lè ṣe ohunkóhun, wọ́n á dà bí òkú fún ẹgbẹ̀rún ọdún tí wọ́n máa lò nínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ náà. Ẹ ò rí i pé ìròyìn ayọ̀ lèyí jẹ́ fáwọn olùfẹ́ òdodo!

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́