Kíkojú Àárò Ilé Lẹ́nu Iṣẹ́-Ìsìn Ọlọrun
JESU KRISTI pàṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ lọ kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ-ẹ̀yìn.” (Matteu 28:19, NW) Fún ọ̀pọ̀ àwọn Kristian, mímú àṣẹ yẹn ṣẹ ti túmọ̀sí títẹ́wọ́gba àwọn àyíká-ipò tí ó ṣòro ní ibi tí ó jìnnà sí ilé. Àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò, àwọn aya wọn, àti àwọn ẹlòmíràn fi ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan sílẹ̀ sẹ́yìn nítorí ti iṣẹ́-ìsìn Ọlọrun. Ṣíṣàárò ilé lè jẹ́ ìpèníjà gidi kan fún gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa wọ̀nyí.
Ṣíṣàárò ilé máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí agbára ìrántí bá gbé ìrònú rẹ padà lọ sára àìléwu àti ìfẹ́ fún ìgbà gbígbádùnmọ́ni kan tí ó ti kọjá. Èyí lè fa èrò-ìmọ̀lára mímúná tóbẹ́ẹ̀ tí ìwọ yóò fi nímọ̀lára ìsoríkọ́ tí kò sì ní ṣeéṣe fún ọ mọ́ láti máa báa lọ. Nítòótọ́, lẹ́yìn títa àwọn ohun-ìní wọn àti rírin ìrìn-àjò tí ń náni ní ohun púpọ̀ lọ sí ilẹ̀ àjèjì, àwọn kan ti pa ìwéwèé wọn tì wọ́n sì ti padà sílé. Ṣíṣàárò ilé borí wọn.
Irú àwọn ìgbéjàkò bẹ́ẹ̀ lórí èrò-ìmọ̀lára sábà máa ń ṣe lemọ́lemọ́ lẹ́yìn tí ẹnìkan bá kọ́kọ́ ṣílọ, ṣùgbọ́n fún àwọn kan wọ́n máa ń bá a nìṣó jálẹ̀ àkókò ìgbésí-ayé wọn. Lẹ́yìn tí ó ti ṣílọ fún ohun tí ó ju 20 ọdún, “ọkàn” Jakọbu “fa gidigidi sí ilé baba rẹ̀.” (Genesisi 31:30) Ta ni lè retí pé òun yóò jìyà lọ́wọ́ ṣíṣàárò ilé? Kí ní ń ṣokùnfà rẹ̀? Báwo ni ẹnìkan ṣe lè kojú irú àwọn ìmọ̀lára bẹ́ẹ̀?
Kí Ní Ń Ṣokùnfà Ìbànújẹ́ Náà?
Ṣíṣàárò ilé lè nípalórí ẹnikẹ́ni. Ó ṣe kedere pé ìdí gbogbo wà fún Amytis, ọmọbìnrin ọba Media náà Astyages, láti láyọ̀: ọrọ̀, ipò-iyì, ilé rírẹwà kan. Síbẹ̀, àárò àwọn òkè ńlá Media sọ ọ́ débi pé ọkọ rẹ̀, Ọba Nebukadnessari, gbin àwọn ọgbà orí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ ti Babiloni nínú ìsapá kan láti tù ú nínú.
Ṣíṣàárò ilé lè jẹ́ èyí tí ń dánniwò ní pàtàkì nígbà tí ìgbésí-ayé bá dàbí èyí tí ó túbọ̀ ṣòro ju bí ó ti rí tẹ́lẹ̀ ṣáájú kí ẹnìkan tó ṣí kúrò. Nígbà tí àwọn ènìyàn ilẹ̀ Juda di ìgbèkùn, wọ́n kédàárò pé: “Ní ẹ̀bá odò Babeli, níbẹ̀ ni àwa gbé jókòó, àwa sì sọkún nígbà tí àwa rántí Sioni. Àwa ó ti ṣe kọ orin Oluwa ní ilẹ̀ àjèjì?”—Orin Dafidi 137:1, 4.
Ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan ni ó lè fa ìbànújẹ́ ti kí àárò ilé máa sọni. Terri, tí ó ti fi Canada sílẹ̀ sọ pé: “Ní ọjọ́ kan fọ́tò tí gbogbo ìdílé jọ yà jábọ́ láti inú ìwé kan. Nígbà tí mo mú un nílẹ̀, ń ṣe ni àárò ilé bẹ̀rẹ̀ síí sọ mi gan-an lójijì, mo sì sọkún.” Chris, ẹni tí ó ṣílọ láti England sí orílẹ̀-èdè kan tí ó tòṣì lọ́pọ̀lọpọ̀, gbà pé: “Wíwulẹ̀ rántí dídún ohùn orin kan tí mo ti gbọ́ rí tàbí ìtasánsán oúnjẹ kan tí mo mọ̀ dáradára lè mú kí n yánhànhàn fún àwọn nǹkan tí mo fi sílẹ̀ sẹ́yìn.”—Fiwé Numeri 11:5.
Ìwàpapọ̀ ìdílé tí ó ṣe tímọ́tímọ́ ni ó sábà máa ń jẹ́ ìdí abájọ. Roseli, ọmọ ilẹ̀ Brazil kan tí ń gbé nísinsìnyí ní orílẹ̀-èdè kan tí ó múlégbe ìlú rẹ̀, ṣàlàyé pé: “Mo máa ń rẹ̀wẹ̀sì nígbà tí mo bá gbọ́ ìròyìn búburú láti ilé tí ń kò sì lè wà níbẹ̀ láti ṣèrànwọ́. Nígbà mìíràn ó máa ń burú jù nígbà tí n kò bá gbúròó rárá tí mo sì bẹ̀rẹ̀ síí finúro àwọn nǹkan.” Janice ṣílọ láti North America sí ìlú kékeré kan ní àwọn ilẹ̀ olóoru tí Amazon. Ó sọ pé: “Àárò ilé máa ń sọ mí nígbà tí mo bá gbọ́ ìròyìn rere láti ilé. Mo ń gbọ́ nípa bí wọ́n ṣe ń gbádùn araawọn, ó sì wù mí láti wà níbẹ̀ pẹ̀lú wọn.”
Fífi àwọn ènìyàn sílẹ̀ nìkan kọ́ ni kìkì ohun tí ń fa ṣíṣàárò ilé. Linda ṣàlàyé pé: “Ìjákulẹ̀ ni ó máa ń jẹ́ fún mi nígbà tí n kò bá mọ ibi tí èmi yóò ti ra àwọn nǹkan tí mo nílò. Èmi kò mọ iye tí àwọn nǹkan jẹ́ tàbí bí a ti ń dúnàádúrà. Ó ti gbówólórí jù láti ní ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan, a sì máa ń tì mí síhìn-ín sọ́hùn-ún lọ́pọ̀ ìgbà bí mo ti ń jìjàkadì láti wọ àwọn ọkọ̀ èrò tí ó kúnfọ́fọ́. Èyí wulẹ̀ mú kí n máa yánhànhàn láti padà sílé ni.” Ní ṣíṣàlàyé lórí àlàfo àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àti ti ìṣúnná-owó, Janet sọ pé: “Ipò òṣì náà ni ohun tí ó mú ọkàn mi gbọgbẹ́. Èmi kò tíì rí àwọn ènìyàn tí ń ṣagbe búrẹ́dì rí, tàbí àwọn ìdílé ńlá tí gbogbo wọn ń gbé papọ̀ nínú iyàrá kanṣoṣo láìsí omi ẹ̀rọ. . . . Irúfẹ́ àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ mú ọkàn mi gbọgbẹ́ tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ ti mo fi ronú pé èmi kò lè dúró síbẹ̀ mọ́.”
Kíkojú Àwọn Ìmọ̀lára Rẹ
A kò níláti jẹ́ kí ara ni wá nípa níní àwọn ìmọ̀lára ìmí-ẹ̀dùn lílágbára fún àwọn ènìyàn tí a fẹ́ràn tàbí fún àyíká kan tí a mọ̀ dunjú ti àwọn ọdún ìgòkè àgbà wa. Jehofa Ọlọrun fún wa ní èrò-ìmọ̀lára kí á baà lè gbádùn ipò-ìbátan ọlọ́yàyà. Àwọn Kristian alábòójútó ìjọ tí ó wà ní Efesu jẹ́ àwọn ọkùnrin tí wọ́n dàgbàdénú níti èrò-ìmọ̀lára. Ṣùgbọ́n kí ni ó ṣẹlẹ̀ nígbà tí ìbẹ̀wò aposteli Paulu sọ́dọ̀ wọ́n wá sí ìparí? Họ́wù, “gbogbo wọn sì sọkún gidigidi, wọ́n sì rọ̀ mọ́ Paulu ní ọrùn, wọ́n sì fi ẹnu kò ó ní ẹnu”! (Iṣe 20:37) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn kò nííṣe pẹ̀lú ṣíṣàárò ilé. Síbẹ̀, ó fún wa ní ohun kan láti ronú lé lórí. Ó jẹ́ ohun tí ó wàdéédéé láti ní ìmọ̀lára, ṣùgbọ́n a kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí wọ́n darí wa. Báwo nígbà náà, ni ìwọ ṣe lè kojú ṣíṣàárò ilé lọ́nà yíyọrísírere?
Kíkẹ́kọ̀ọ́ láti sọ èdè àdúgbò jẹ́ kọ́kọ́rọ́ kan sí dídi ẹni tí araarẹ̀ mọlé. Ìmọ̀lára ṣíṣàárò ilé lè ga síi nígbà tí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ kò bá ṣeéṣe nítorí pé o níláti lo èdè àjèjì. Bí ó bá ṣeéṣe, nígbà náà, kọ́ láti kà kí o sì sọ èdè ẹkùn náà ṣáájú kí o tó ṣílọ síbẹ̀. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, pọkànpọ̀ sórí kíkọ́ èdè ni ìwọ̀nba ọ̀sẹ̀ díẹ̀ àkọ́kọ́ lẹ́yìn tí o bá dé ibẹ̀. Nígbà yẹn ni o ní ìṣúnniṣe lílágbára jùlọ àti nípa bẹ́ẹ̀ ìfojúsọ́nà dídára jùlọ láti kọ́ ọ. Bí o bá yọ̀ǹda àwọn ọ̀sẹ̀ wọ̀nyí ní pàtàkì fún kíkẹ́kọ̀ọ́ èdè, kò ní pẹ́ tí ìwọ yóò fi bẹ̀rẹ̀ síí gbádùn ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀, ìyẹn sì lè ṣèrànwọ́ láti mú ìmọ̀lára ṣíṣàárò ilé fúyẹ́.
Wá àwọn ọ̀rẹ́ titun bí ó bá ti lè ṣeéṣe kí ó yá tó, nítorí pé èyí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mú kí ara rẹ mọlé. Ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni ibi dídára jùlọ tí o ti lè rí àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́. Lo ìdánúṣe kí o sì lọ́kàn-ìfẹ́ nínú àwọn ẹlòmíràn. Sapá láti mọ ipò àtilẹ̀wá wọn, ìdílé wọn, àwọn ìṣòro wọn, àti àwọn ohun tí wọ́n lọ́kàn-ìfẹ́ sí. Késí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ wá sí ilé rẹ. Ní ìdáhùnpadà, ìwọ yóò ríi pé àwọn ẹlòmíràn yóò lọ́kàn-ìfẹ́ nínú rẹ.
Láàárín àwọn ènìyàn Ọlọrun, ipò ìbánidọ́rẹ̀ẹ́ lè súnmọ́ra pẹ́kípẹ́kí bí ìdè ìdílé. Jesu wí pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe ìfẹ́ Ọlọrun, òun náà ni arákùnrin mi, àti arábìnrin mi, àti ìyá mi.” (Marku 3:35) Kristi tún mú kí ó dá àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lójú pé: “Kò sí ẹni tí ó fi ilé sílẹ̀, tàbí arákùnrin, tàbí arábìnrin, tàbí baba, tàbí ìyá, tàbí aya, tàbí ọmọ, tàbí ilẹ̀, nítorí mi, àti nítorí ìhìnrere, ṣùgbọ́n nísinsìnyí ní ayé yìí òun ó sì gba ọgọ́rọ̀ọ̀rún, ilé, àti arákùnrin, àti arábìnrin, àti ìyá, àti ọmọ, àti ilẹ̀, pẹ̀lú inúnibíni, àti ní ayé tí ń bọ̀ ìyè àìnípẹ̀kun.” (Marku 10:29, 30) Pẹ̀lú irú ipò jíjẹ́ arákùnrin nípa tẹ̀mí bẹ́ẹ̀, a kò dá wà ní àwa nìkanṣoṣo, àní ní ilẹ̀ titun pàápàá.
Dídi ipò ìbádọ́rẹ̀ẹ́ mú pẹ̀lú àwọn tí o fisílẹ̀ nílé tún lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti kojú ṣíṣàárò ilé. Ó lè yà ọ́ lẹ́nu láti rí i pé nísinsìnyí tí o ti ṣílọ, ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ nípasẹ̀ lẹ́tà kíkọ kún fún ìtumọ̀ níti gidi, níwọ̀n bí ìwọ ti lè ronú gidigidi lórí àwọn ọ̀rọ̀ tí ìwọ yóò sọ. Àwọn nǹkan tí ń runisókè yóò wà láti sọ. Janet, tí a mẹ́nukàn ní ìṣáájú, dámọ̀ràn pé: “Ìkésíni lórí tẹlifóònù láti ọ̀nà jíjìn ti gbówólórí jù, ṣùgbọ́n fífi kásẹ́ẹ̀tì tí a gba ọ̀rọ̀ sí ṣọwọ́ nípasẹ̀ ìfìwéránṣẹ́ kò wọ́n ní ìfiwéra. Sísọ̀rọ̀ sínú ẹ̀rọ lè kọ́kọ́ dàbí ohun tí ó ṣàjèjì. Síbẹ̀, bí ìwọ bá ń bá ẹnìkan jùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ pẹ̀lú maikrofon láàárín yín, ó máa ń rọrùn ó sì ń gbádùnmọ́ni.” Ìwọ tún lè béèrè pé kí a fi kásẹ́ẹ̀tì tí a gba ọ̀rọ̀ sí nínú ránṣẹ́ sí ọ pẹ̀lú.
Shirley, tí ó ṣílọ sí Latin America láti United States ní ọdún 25 sẹ́yìn, sọ pé: “Mo sábà máa ń kọ̀wé nípa àwọn ìrírí tí ń gbéniró dípò kí ó jẹ́ àwọn ìṣòro. Èyí ń fún àwọn ẹlòmíràn níṣìírí láti máa kọ̀wé sí mi ṣáá.” Bí ó ti wù kí ó rí, ṣọ́ra. Àkọjù lẹ́tà lè fà ọ́ sẹ́yìn láti wá àwọn ọ̀rẹ́ titun. Del, tí ó ṣílọ sí orílẹ̀-èdè mìíràn láti Canada, sọ pé: “Yẹra fún dídúró sílé láti máa banújẹ́ nípa àwọn nǹkan tí o kò ní àǹfààní rẹ̀ mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, jáde lọ kí o sì gbádùn ibùgbé rẹ titun.”
Wá ọ̀nà láti mọ àwọn àṣà, ìtàn, ohun apanilẹ́rìn-ín, àti àwọn ibi fífanimọ́ra àti ibi rírẹwà tí ó wà ní ilẹ̀ titun náà. Èyí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti máṣe darí àfiyèsí rẹ sí àwọn apá tí kò gbádùnmọ́ni. Bí o bá sì ní in lọ́kàn láti dúró sí ibi tí o ṣílọ, ó dára jù kí o máṣe bẹ ìlú ìbílẹ̀ rẹ wò ní kíákíá tàbí ní lemọ́lemọ́ jù. Ó ń gba àkókò láti ní àwọn ọ̀rẹ́ titun àti kí àyíká titun tó mọ́nilára. Ìṣèbẹ̀wò sílé fún àkókò gígùn ń bẹ́gidínà irú nǹkan bẹ́ẹ̀. Ní gbàrà tí araàrẹ bá ti mọlé níbẹ̀, o lè gbádùn lílọ sí ibùgbé rẹ àtijọ́ fún ìbẹ̀wò—àti pípadà lẹ́yìn náà. Ní báyìí ná, jẹ́ kí ọwọ́ rẹ dí ní mímú araàrẹ fàmọ́ ilé rẹ titun.
Máa Fojúsọ́nà Nìṣó
Jehofa fún wa ní gbogbo ilẹ̀-ayé gẹ́gẹ́ bí ilé wa. (Orin Dafidi 115:16) Pẹ̀lú ẹ̀mí Kristian tí ó jẹ́ aláyọ̀, ìgbésí-ayé lè gbádùnmọ́ni ní ilẹ̀ èyíkéyìí. Bí o bá ṣílọ nítorí àtimú ire Ìjọba náà gasíwájú kí o sì wàásù ìhìnrere náà ní orílẹ̀-èdè mìíràn tàbí ní ibòmíràn ní ìlú ìbílẹ̀ rẹ, ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ìfojúsọ́nà aláyọ̀. Máa fojúsọ́nà fún níní àwọn ọ̀rẹ́ titun, kíkọ́ nípa àwọn àṣà yíyàtọ̀síra, sísọni di ọmọ-ẹ̀yìn, tàbí ṣíṣe àwọn nǹkan tí ń mú èrè wá nínú iṣẹ́-ìsìn Ọlọrun.
Jehofa Ọlọrun jẹ́ Ọ̀rẹ́ kan tí yóò máa wà pẹ̀lú rẹ nígbà gbogbo, láìka ibi yòówù kí o wà sí. (Orin Dafidi 94:14; 145:14, 18) Nítorí náà wà tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀ nínú àdúrà. (Romu 12:12) Èyí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ní ète rẹ nínú ìgbésí-ayé gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Ọlọrun lọ́kàn. Abrahamu àti Sara fi ète wọn sọ́kàn nígbà tí wọ́n fi ilé wọn tí ó tunilára ní ìlú-ńlá Uri sílẹ̀. Ní ìgbọràn sí àṣẹ Jehofa, wọ́n fi àwọn ọ̀rẹ́ àti ìbátan sílẹ̀ lẹ́yìn. (Iṣe 7:2-4) Bí wọ́n bá ti ń báa lọ ní rírántí àti yíyánhànhàn fún ibi tí wọ́n ti kúrò ni, wọn ìbá ti ní àǹfààní láti padà. Ṣùgbọ́n wọ́n ń lépa láti dé ibí dídára jù kan—èyí tí, ní opin gbogbo rẹ̀ pátápátá, yóò jẹ́ ìgbésí-ayé nínú paradise lórí ilẹ̀-ayé lábẹ́ Ìjọba ọ̀run ti Ọlọrun.—Heberu 11:15, 16.
Wíwàásù ní àwọn pápá ilẹ̀ àjèjì tàbí níbi tí àìní gbé pọ̀jù fún àwọn olùpòkìkí Ìjọba ní ìlú ìbílẹ̀ rẹ lè kún fún ìpèníjà gidigidi. Ṣùgbọ́n ó tún jẹ́ iṣẹ́ tí ń sèso tí ó sì ń mú èrè wá jùlọ. (Johannu 15:8) Bí àwọn èrò tí kò wọ̀ bá ṣì ń bò ọ́ mọ́lẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, o lè borí wọn nípa fífi góńgó rẹ sọ́kàn àti títẹjúmọ́ ọ̀kánkán. Míṣọ́nnárì arábìnrin kan tí kò ṣègbéyàwó wí pé: “Nígbà tí mo bá nímọ̀lára pé ìbànújẹ́ ń dàbò mí, mo ń gbìyànjú láti ronú nípa ayé titun àti bí gbogbo aráyé yóò ṣe jẹ́ ìdílé kan.” Àwọn ìrònú dídùnmọ́ni bí ìwọ̀nyí lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti pa ayọ̀ rẹ mọ́ kí o má sì ṣe jọ̀gọ̀nù fún ṣíṣàárò ilé.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Kò yẹ kí ṣíṣàárò ilé ṣèdíwọ́ fún iṣẹ́-òjíṣẹ́ Kristian