Ǹjẹ́ O Lè Sìn ní Ilẹ̀ Òkèèrè?
“ÌGBÀ gbogbo ni mo máa ń lálàá pé mò wà nínú iṣẹ́ míṣọ́nnárì. Nígbà tí mo wà lápọ̀n-ọ́n, mo sìn ní Texas, Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, níbi tí wọ́n ti nílò ọ̀pọ̀ àwọn tó máa wàásù. Lẹ́yìn táa ṣègbéyàwó, níyàwó mi wá bá mi níbẹ̀. Nígbà táa bí ọmọbìnrin wa, mo ronú pé, ‘O parí, gbogbo ìwéwèé mi ti dópin nìyẹn.’ Àmọ́ Jèhófà máa ń jẹ́ kí àlá ṣẹ, pàápàá jù lọ tí wọ́n bá ní í ṣe pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀.”—Jesse ló sọ ọ́, òun pẹ̀lú aya rẹ̀ àtàwọn ọmọ wọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ṣì ń sìn ní Ecuador títí di ìsinsìnyí.
“N kò fìgbà kan rò pé mo lè láǹfààní yẹn láìjẹ́ pé mo gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ míṣọ́nnárì ní ilé ẹ̀kọ́ Gilead. Bí mo bá rí ọ̀kan lára àwọn tí mò bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tó ń sọ àsọyé tàbí tó ń wàásù, ó máa ń mú inú mi dùn jọjọ, mo sì máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún fífún mi ní àǹfààní yìí.”—Karen, arábìnrin àpọ́n tó ti ṣe aṣáájú ọ̀nà fọ́dún mẹ́jọ ní Ilẹ̀ Gúúsù Amẹ́ríkà ló sọ bẹ́ẹ̀.
“Lẹ́yìn wíwàásù fún ọdún mẹ́tàlá gbáko ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, èmi àti aya mi gbà pé a nílò ìgbòkègbodò mìíràn. Inú wa ò dùn tó báyìí rí; ìgbésí ayé àgbàyanu lèyí jẹ́.”—Tom ló sọ ọ́, òun pẹ̀lú aya rẹ̀, Linda, ń ṣe aṣáájú ọ̀nà ní ẹkùn Amazon.
Àwọn tí ipò wọn ò jẹ́ kí wọ́n gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ míṣọ́nnárì ní Watchtower Bible School of Gilead ló sọ àwọn ọ̀rọ̀ ìmoore wọ̀nyí. Bó ti wù kó rí, wọ́n ti rí ayọ̀ tó wà nínú sísìn ní ilẹ̀ òkèèrè, wọ́n sì ti rí àwọn ìṣòro tó wà níbẹ̀ pẹ̀lú. Báwo lèyí ṣe ṣẹlẹ̀? Ǹjẹ́ o lè láǹfààní irú iṣẹ́ yìí?
A Nílò Ẹ̀mí Tó Tọ́
Kì í wulẹ̀ ṣe kìkì ẹ̀mí ká kàn máa rìnrìn àjò lásán la nílò ká tó lè kẹ́sẹ jári nínú pápá ilẹ̀ òkèèrè. Àwọn tí wọ́n forí tì í, ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí pé wọ́n ní ẹ̀mí tó tọ́. Gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, wọ́n ka ara wọn sí ajigbèsè, kì í ṣe sí Ọlọ́run nìkan, ṣùgbọ́n sí ènìyàn pẹ̀lú. (Róòmù 1:14) Wọ́n ṣáà lè pa àṣẹ àtọ̀runwá náà láti wàásù mọ́, nípa lílọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà ní ìpínlẹ̀ tí wọ́n ń gbé. (Mátíù 24:14) Àmọ́ wọ́n gbà pé àwọn jẹ gbèsè, èyí sì sún wọn láti làkàkà, láti ran àwọn tí kò láǹfààní náà lọ́wọ́, kí wọ́n lè gbọ́ ìhìn rere náà.
Ohun mìíràn tó tún ń sún àwọn èèyàn láti lọ ni fífẹ́ láti wàásù ní ìpínlẹ̀ tó lè túbọ̀ méso jáde. Ta ni nínú wa tí yóò rí apẹja mìíràn tó ń rí ẹja pa dáadáa níbì kan, tí kò ní fẹ́ sún mọ́ àgbègbè ibi tí ọwọ́ onítọ̀hún ti ń dẹ? Bákan náà, ìròyìn tí ń múni lọ́kàn yọ̀ nípa ìbísí gígadabú tó ń jáde ní àwọn ilẹ̀ mìíràn ti fún ọ̀pọ̀ níṣìírí láti lọ sí ibi tí “ògìdìgbó ńlá ẹja” wà.—Lúùkù 5:4-10.
Gbé Ìṣirò Lé E
Ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ni kì í gbà kí àwọn tó bá yọ̀ǹda ara wọn láti wá ṣiṣẹ́ ìsìn láti ilẹ̀ òkèèrè ṣiṣẹ́ mìíràn. Nítorí náà, lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn tó bá fẹ́ lọ sìn ní ilẹ̀ òkèèrè gbọ́dọ̀ jẹ́ àwọn tí kò ní bùkátà tó pọ̀. Báwo làwọn kan ti ṣe bójú tó ìṣòro ìṣúnná owó yìí? Àwọn kan ti ta ilé wọn láti lè rí owó tí wọn ó lò, àwọn mìíràn sì fi ilé wọn háyà. Àwọn mìíràn ta okòwò wọn. Àwọn mìíràn sì fowó pa mọ́ nítorí góńgó wọn. Bẹ́ẹ̀ kẹ̀, àwọn mìíràn sìn ní ilẹ̀ òkèèrè fún bí ọdún kan tàbí méjì, wọ́n á tún padà sí ìlú wọn láti lọ ṣiṣẹ́, kí wọ́n lè rí owó díẹ̀ kó jọ, lẹ́yìn èyí, wọ́n á tún padà lọ sìn.
Àǹfààní kan tí a kò lè jiyàn rẹ̀ pé ó wà nínú gbígbé ní orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà ni pé, owó ìgbọ́bùkátà kò pọ̀ tó ti àwọn ilẹ̀ tó ti gòkè àgbà. Èyí ti jẹ́ kí owó ìfẹ̀yìntì táwọn kan ń gbà tó wọn ná. Àmọ́ ṣá o, owó tí ẹnì kan ń ná yóò sinmi lé irú ìgbésí ayé tí ẹni náà ń gbé. Kódà ní àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà pàápàá, àwọn ilé tó dáa tó fọkàn ẹni balẹ̀ láti gbé lè wà, àmọ́, yóò náni lówó tó pọ̀.
Ó ṣe kedere pé, a gbọ́dọ̀ gbéṣirò lé ohun tí yóò náni, kó tó di pé a gbéra. Síbẹ̀, ohun tó ń béèrè tún kọjá ká wulẹ̀ ṣírò iye tí yóò náni. Ohun tí àwọn kan tí wọ́n ti sìn ní Gúúsù Amẹ́ríkà sọ lè túbọ̀ là wá lóye.
Ìṣòro Tó Tóbi Jù Lọ
Markku tó wá láti Finland rántí pé: “Kíkọ́ èdè Spanish jẹ́ ìṣòro ńlá fún mi. Mo rò pé nítorí tí n kò gbọ́ èdè yìí, yóò ṣe díẹ̀ kí n tó lè di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́. Ẹ wo bó ti jẹ́ ìyàlẹ́nu ńlá fún mi tó nígbà tí wọ́n ní kí n wá máa darí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ lóṣù kejì! Àmọ́ ṣá o, àwọn àkókò kan wà tí ìtìjú ò jẹ́ n gbádùn. Ìṣòro tí mo ní jù lọ ni pípe orúkọ àwọn èèyàn. Lọ́jọ́ kan, mo pe Arákùnrin Sancho ní ‘Arákùnrin Chancho (tó túmọ̀ sí ẹlẹ́dẹ̀),’ n kò sì lè gbàgbé ọjọ́ tí mo pe Arábìnrin Salamea ní ‘Malasea (èyí túmọ̀ sí èèyàn burúkú).’ Ọpẹ́lọpẹ́ pé àwọn arákùnrin àti arábìnrin náà jẹ́ onísùúrù.” Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ọdún mẹ́jọ ni Markku àti aya rẹ̀ fi sìn ní orílẹ̀-èdè yẹn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àyíká.
Chris, aya Jesse táa fa ọ̀rọ̀ ẹ̀ yọ lẹ́ẹ̀kan, sọ pé: “Mo rántí ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká táa kọ́kọ́ ní, lẹ́yìn oṣù mẹ́ta péré táa débi. Mo mọ̀ pé àkàwé ni arákùnrin náà ń ṣe o, àti pé ó ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ dídùndídùn, kó bàa lè dọ́kàn wa, ṣùgbọ́n ohun tó ń sọ gan-an ò yé mi. Nínú gbọ̀ngàn níbẹ̀ náà ni mo tí bú sẹ́kún gbẹ̀ẹ́. Nǹkan tí mò ń sọ yìí kì í ṣe ẹ̀kún díẹ̀ o; mò ń hu gan-an ni o. Nígbà típàdé parí, mo gbìyànjú láti ṣàlàyé ohun tó ń ṣe mi fún alábòójútó àyíká. Ọkùnrin náà mà ṣèèyàn o, ohun tí àwọn ará yòókù sọ lòun náà ń sọ fún mi, ó ń sọ pé, ‘Ten paciencia, hermana’ (‘Arábìnrin, ó ti tó, sùúrù lẹ máa ní’). Ọdún méjì tàbí mẹ́ta lẹ́yìn náà, a tún pàdé, odindi ìṣẹ́jú márùndínláàádọ́ta la sì fi sọ̀rọ̀, inú wa sì ń dùn pé ní báyìí, a ti gbọ́ èdè ara wa.”
Arákùnrin mìíràn wí pé: “Kíkọ́ ni mímọ̀. Báa bá ṣe ń sapá tó láti kọ́ èdè, bẹ́ẹ̀ náà la ó ṣe mọ̀ ọ́n sọ tó.”
Kò sẹ́ni tí kò ní gbà pé irú ìsapá bẹ́ẹ̀ ń mú ọ̀pọ̀ àǹfààní wá. Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, sùúrù, àti títẹra-mọ́-nǹkan ṣe pàtàkì tí ẹnì kan bá ń kọ́ èdè tuntun. Àǹfààní ńláǹlà yóò wá ṣí sílẹ̀ láti wàásù ìhìn rere fáwọn ẹlòmíràn. Fún àpẹẹrẹ, kíkọ́ èdè Spanish mú kó ṣeé ṣe láti sọ èdè tí àwọn tó lé ní irínwó mílíọ̀nù ń sọ yíká ayé. Ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn tó di dandan pé kí wọ́n padà sí ìlú wọn ló jẹ́ pé wọ́n ṣì lè fi èdè Spanish tí wọ́n gbọ́ bá àwọn tó ń sọ èdè náà sọ̀rọ̀.
Àárò Ilé Ńkọ́?
Deborah tí òun náà sìn pẹ̀lú ọkọ rẹ̀, Gary, ní ẹkùn Amazon sọ pé: “Nígbà táa kọ́kọ́ dé sí Ecuador ní 1989, àárò ilé kì í jẹ́ kí n gbádùn. Mo ti kọ́ fífaramọ́ àwọn arákùnrin àti arábìnrin tó wà nínú ìjọ mi. Wọ́n ti wá dà bí ìdílé mi gan-an.”
Karen, táa mẹ́nu kàn níbẹ̀rẹ̀, ṣàkíyèsí pé: “Ohun tí mo fi ṣẹ́gun àárò ilé ni lílọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ lójoojúmọ́. Lọ́nà yìí, ọkàn mi ò ní máa fà sílé ní gbogbo ìgbà. Mo sì máa ń fi sọ́kàn pé, inú àwọn òbí mi nílé lọ́hùn-ún ń dùn gan-an sí iṣẹ́ tí mò ń ṣe ní ilẹ̀ òkèèrè. Ìgbà gbogbo ni Màmá máa ń fi ọ̀rọ̀ yìí fún mi níṣìírí: ‘Jèhófà lè tọ́jú ẹ dáadáa ju bí mo ṣe lè tọ́jú ẹ lọ.’”
Makiko, tó wá láti Japan, sọ ọ́ lọ́nà ẹ̀fẹ̀ pé: “Èmi tí mo ti fodindi ọjọ́ kan ṣiṣẹ́ ìsìn pápá, tó ti rẹ̀ mí bí nǹkan mí-ìn. Bí mo bá délé, tí àárò sì fẹ́ máa sọ mí, tí ń ba ti bọ lulẹ̀ báyìí, oòrùn ti gbé mi lọ. Ìgbà tó tiẹ̀ yá, àárò ò sọ mí mọ́.”
Ọ̀ràn Ọmọ Ńkọ́?
Níbi tí ọ̀ràn ọmọ bá ti wọ̀ ọ́, a gbọ́dọ̀ ronú dáadáa nípa ohun tí wọ́n nílò, irú bí ètò ẹ̀kọ́ wọn. Ní ti èyí, ọ̀pọ̀ ló ti pinnu láti máa kọ́ àwọn ọmọ wọn níwèé nílé, nígbà tí àwọn mìíràn sì forúkọ ọmọ wọn sílẹ̀ nílé ẹ̀kọ́ tó wà ládùúgbò.
Al àti aya rẹ̀, pẹ̀lú ọmọ méjì, àti màmá rẹ̀ ni wọ́n jọ kó lọ sí Ilẹ̀ Gúúsù Amẹ́ríkà. Ó sọ pé: “A rí i pé fífi ọmọ sílé ẹ̀kọ́ ń jẹ́ kí wọ́n tètè gbọ́ èdè. Láàárín oṣù mẹ́ta èdè náà ti yọ̀ mọ́ wọn lẹ́nu.” Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, àwọn ọ̀dọ́langba ọmọkùnrin méjì, tí wọ́n jẹ́ ọmọ Mike àti Carrie, ń kàwé nípasẹ̀ ilé ẹ̀kọ́ àgbélékà tíjọba fọwọ́ sí. Àwọn òbí wọn sọ pé: “A rí i pé a kò lè dá àwọn ọmọ wa dá irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀. A ní láti kópa nínú ètò ẹ̀kọ́ náà, kí a sì rí i dájú pé àwọn ọmọ náà ń ṣe iṣẹ́ ilé tí wọ́n bá yàn fún wọn.”
David àti Janita, tí wọ́n wá láti Ọsirélíà, sọ èrò ọkàn wọn nípa ọmọkúnrin wọn méjèèjì. “A fẹ́ kí àwọn ọmọ wa rí bí àwọn èèyàn mìíràn ṣe ń gbé ìgbésí ayé. Ó rọrùn láti gbà pé irú ìgbésí ayé tí à ń gbé náà ni gbogbo èèyàn ń gbé, ṣùgbọ́n o, àwọn díẹ̀ ló ń gbé irú ìgbésí ayé tiwa. Wọ́n tún ti rí i bí ìlànà ìṣàkóso Ọlọ́run ṣe ń ṣiṣẹ́ káàkiri àgbáyé, láìka orílẹ̀-èdè tàbí ìṣẹ̀dálẹ̀ táa ti wá sí.”
Ken rántí pé: “Ọmọ ọdún mẹ́rin péré ni mí nígbà tí ìdílé mi ṣí kúrò ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lọ́dún 1969. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú mi ò dùn nítorí pé ohun tí mo rò kọ́ ni mo bá, a ò gbé inú ahéré táa fi amọ̀ kọ́, táa sì fi ewéko ṣe òrùlé rẹ̀, àmọ́, mo gbà pé ọ̀nà tí wọ́n gbà tọ́ mi dàgbà ni ọ̀nà tó dára jù lọ láti tọ́ ọ̀dọ́langba kan. Ìgbà gbogbo làánú àwọn ọmọ tí kò ní irú àǹfààní yìí máa ń ṣe mí! Nítorí fífararora pẹ̀lú àwọn míṣọ́nnárì àti àwọn aṣáájú ọ̀nà àkànṣe, ọmọ ọdún mẹ́sàn-án ni mí nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́.” Alábòójútó arìnrìn-àjò ni Ken báyìí.
Gabriella, ọmọbìnrin Jesse, sọ pé: “Ní báyìí o, Ecuador ti di ìlú wa. Inú mi dùn gan-an pé àwọn òbí mi pinnu láti wá síbí.”
Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, àwọn ọmọ kan wà tó jẹ́ pé wọn kò lé gbé ibi tí ìdílé wọn ṣí lọ, tí ìdílé náà sì ní láti padà sí orílẹ̀-èdè wọn. Ìdí nìyẹn tó fi dára pé ká kọ́kọ́ lọ sí ilẹ̀ òkèèrè náà, ká lọ yẹ ilẹ̀ wò, ká tó digbá dagbọ̀n lọ síbẹ̀. Èyí yóò lè ràn wá lọ́wọ́ láti gbé ìpinnu wa ka àwọn ìsọfúnni táa rí fúnra wa.
Àwọn Ìbùkún Tó Wà Nínú Ṣíṣílọ
Lóòótọ́, ṣíṣílọ sí ilẹ̀ òkèèrè kún fún ọ̀pọ̀ ìpèníjà, ó sì ń béèrè fífi ọ̀pọ̀ nǹkan rúbọ. Ǹjẹ́ nǹkan tiẹ̀ ṣẹnuure fún àwọn tó ti ṣí lọ? Ẹ jẹ́ kí wọ́n fẹnu ara wọn sọ ọ́ fún wa.
Jesse: “Ní ọdún mẹ́wàá táa ti wà nílùú Ambato, a ti rí bí ìjọ méjì ṣe di mọ́kànlá. A ti láǹfààní láti ṣèrànwọ́ láti bẹ̀rẹ̀ márùn-ún nínú ìjọ wọ̀nyẹn, a sì bá wọn kọ́ méjì lára Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn. Lọ́dọọdún, a làǹfààní láti ṣèrànwọ́ fún ìpíndọ́gba akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì méjì láti ṣèrìbọmi. Ohun kan ṣoṣo tí mo kábàámọ̀ ni pé—ó yẹ kí n ti wá síbi ní ọdún mẹ́wàá ṣáájú ìgbà tí mo wá.”
Linda: “Ìmọrírì táwọn èèyàn ní fún ìhìn rere náà àti fún ìsapá wa fún wa níṣìírí gan-an. Fún àpẹẹrẹ, ní ìletò kan tó wà nínú igbó, akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Alfonso wá mọ àǹfààní tí sísọ àsọyé ìta gbangba lágbègbè rẹ̀ yóò mú wá. Ó ṣẹ́ṣẹ́ kó sí ilé rẹ̀ túntun tó figi kọ́ ni, ó sì jẹ́ ọ̀kan lára ilé díẹ̀ tó wà lábúlé náà. Nígbà tó gbọ́ pé ilé òun nìkan ṣoṣo ló bójú mu fún jíjọ́sìn Jèhófà lábúlé náà, ló bá kó padà sínú ahéré ewéko rẹ̀, ó sì yọ̀ǹda pé kí àwọn ará máa lo ilé òun gẹ́gẹ́ bí Gbọ̀ngàn Ìjọba.”
Jim: “Àkókò tí a lò láti fi bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa fi ìlọ́po mẹ́wàá ju èyí tí a máa ń lò ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Ní àfikún sí i, ìgbésí ayé níbi kò gba gìrìgìrì. A ní àkókò tó pọ̀ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ àti iṣẹ́ ìsìn pápá.”
Sandra: “Rírí bí òtítọ́ Bíbélì ṣe lè yí àwọn ènìyàn padà, kó sọ wọn di ẹniire, fi mí lọ́kàn balẹ̀. Ìgbà kan wà tí mò ń bá Amada ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ẹni ọdún mọ́kàndínláàádọ́rin ni obìnrin yìí, ó sì ní ilé ìtajà kan. Ìgbà gbogbo ló máa ń bu omi la wàrà tó ń tà. Yàtọ̀ sí pé o ti bomi la wàrà náà, ó tún ń rẹ́ àwọn oníbàárà rẹ̀ jẹ nípa lílo òṣùwọ̀n tí kò tó táwọn yòókù. Àmọ́ lẹ́yìn kíkẹ́kọ̀ọ́ àpilẹ̀kọ tó wà lábẹ́ ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ náà, ‘Àìlábòsí Ń Yọrí Sí Ayọ̀’ ní orí kẹtàlá ìwé náà Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, Amada ki ọwọ́ ìwà wọ̀nyí bọlẹ̀. Ẹ wo bí inú mi ti dùn tó nígbà tó ṣèrìbọmi!”
Karen: “N kò tíì gbára lé Jèhófà tó báyìí rí, bẹ́ẹ̀ sì ni kò lò mí tó báyìí rí. Ìbátan mi pẹ̀lú Jèhófà ti jinlẹ̀ gan-an, ó sì ti lágbára sí i.”
Ìwọ Ńkọ́?
Jálẹ̀ gbogbo àwọn ọdún wọ̀nyí, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí ló ti lọ sìn nílẹ̀ òkèèrè. Àwọn kan sìn níbẹ̀ fún ọdún kan tàbí méjì, àwọn ẹlòmíràn wà níbẹ̀ jálẹ̀ ìgbésí ayé wọn. Wọ́n ti lo ìrírí wọn, ìdàgbàdénú wọn nípa tẹ̀mí, àti búrùjí wọn, pẹ̀lú góńgó náà láti mú ire Ìjọba náà tẹ̀ síwájú ní ilẹ̀ òkèèrè. Ó ti ṣeé ṣe fún wọn láti sìn ní àwọn àgbègbè tí àwọn akéde Ìjọba tó wà níbẹ̀ kò ti lè sìn nítorí iṣẹ́ tó wọ́n níbẹ̀. Àwọn mìíràn ti ra ọkọ̀ arinkòtò-ringegele láti lè dé àwọn àgbègbè tó ṣòro láti dé. Àwọn mìíràn tí wọ́n fẹ́ràn gbígbé ní ìlú ńlá ti jẹ́ ìrànlọ́wọ́ ńlá fún àwọn ìjọ tó tóbi, tó jẹ́ pé alàgbà díẹ̀ ló wà níbẹ̀. Síbẹ̀, láìyọ ẹnikẹ́ni sílẹ̀, gbogbo wọn ló gbà pé wọ́n ti rí ọ̀pọ̀ nǹkan jèrè pàápàá ní ti ìbùkún nípa tẹ̀mí táa ti fún wọn.
Ǹjẹ́ o lè nípìn-ín nínú àǹfààní sísìn ní ilẹ̀ òkèèrè? Bí ipò rẹ bá yọ̀ǹda, èé ṣe tí o kò fi ṣàyẹ̀wò bóyá ó ṣeé ṣe fún ọ láti gbé irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀? Ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ tó sì ṣe pàtàkì ni pé kóo kọ lẹ́tà sí ọ́fíìsì ẹ̀ka Society tó wà ní orílẹ̀-èdè tóo ti fẹ́ lọ sìn. Ìsọfúnni pàtó tí wọn yóò fún ọ yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti pinnu bó ṣe lè rọrùn fún ọ tó láti kẹ́sẹ járí. Ní àfikún sí i, ọ̀pọ̀ ìmọ̀ràn tó ṣeé mú lò ni a lè rí nínú àpilẹ̀kọ náà, “Jáde Kúrò Ní Ilé Rẹ ati Kúrò Lọ́dọ̀ Awọn Ẹbi Rẹ,” nínú Ilé Ìṣọ́nà ti August 15, 1988. Tóo bá ṣètò tó gún régé, tí Jèhófà sì fi ìbùkún sí i, ìwọ pẹ̀lú lè ní ayọ̀ sísìn ní ilẹ̀ òkèèrè.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
TOM ÀTI LINDA Ń GBA Ọ̀NÀ ẸLẸ́SẸ̀ YÌÍ LỌ, ÀGBÈGBÈ ÀWỌN SHUAR INDIAN NI WỌ́N FORÍ LÉ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Ọ̀PỌ̀ LÓ SÌN NÍ QUITO, OLÚ ÌLÚ ECUADOR
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
MAKIKO Ń WÀÁSÙ NÍ ÀWỌN ÒKÈ ANDES
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
ỌDÚN KARÙN-ÚN NÌYÍ TÍ ÌDÍLÉ HILBIG TI Ń SÌN NÍ ECUADOR