Ǹjẹ́ O Lè ‘Ré Kọjá Lọ Sí Makedóníà’?
1. Kí ló mú kí Pọ́ọ̀lù àtàwọn tí wọ́n jọ rìnrìn àjò gbéra lọ sí Makedóníà?
1 Ní nǹkan bí ọdún 49 Sànmánì Kristẹni, Pọ́ọ̀lù gbéra láti Síríà Áńtíókù fún ìrìn-àjò míṣọ́nnárì rẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kejì. Ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ ni pé kó ṣèbẹ̀wò sí ìlú Éfésù àtàwọn ìlú míì ní Éṣíà Kékeré. Àmọ́, ńṣe ni ẹ̀mí mímọ́ darí rẹ̀ pé kí ó ‘ré kọjá lọ sí Makedóníà.’ Tayọ̀tayọ̀ ni Pọ́ọ̀lù àti àwọn tí wọ́n jọ rìnrìn àjò fi gba ìkésíni yìí, wọ́n sì láǹfààní láti dá ìjọ àkọ́kọ́ sílẹ̀ ní àgbègbè yẹn. (Ìṣe 16:9, 10; 17:1, 2, 4) Lóde òní, àwọn àgbègbè kan wà jákèjádò ayé tí wọ́n nílò àwọn olùkórè tó pọ̀ sí i. (Mát. 9:37, 38) Ǹjẹ́ ipò rẹ lè gbà ọ́ láyè láti ṣe ìrànlọ́wọ́?
2. Kí nìdí tí àwọn kan kò fi ronú nípa lílọ sí orílẹ̀-èdè míì?
2 Ó ṣeé ṣe kó wù ẹ́ láti di míṣọ́nnárì bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, àmọ́ kó jẹ́ pé o kò tíì ronú nípa lílọ sí orílẹ̀-èdè míì. Bí àpẹẹrẹ, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé o kò ní àǹfààní láti lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì torí ọjọ́ orí rẹ, ó ṣeé ṣe kó o jẹ́ arábìnrin tí kò lọ́kọ tàbí kó o ní àwọn ọmọ kéékèèké. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé kíkọ́ èdè míì ló ń bà ẹ́ lẹ́rù tí o kò fi ronú lílọ sìn nílẹ̀ òkèèrè. Tàbí kó jẹ́ pé ńṣe lo kó wá sí orílẹ̀-èdè tó o wà báyìí nítorí ọ̀rọ̀ ajé, tí o kò sì fẹ́ lọ sí ibòmíì. Lẹ́yìn tó o bá ti gbàdúrà nípa ọ̀ràn náà, tó o sì ti ronú nípa rẹ̀, o lè wá rí i pé àwọn nǹkan yẹn kò tó láti dí ẹ lọ́wọ́ lílọ sìn lórílẹ̀-èdè tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i.
3. Kí nìdí tí kò fi pọn dandan kéèyàn lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì kó tó lè ṣe àṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù nílẹ̀ òkèèrè?
3 Ǹjẹ́ Ó Pọn Dandan Kéèyàn Lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì? Kí ló mú kí Pọ́ọ̀lù àtàwọn tí wọ́n jọ rìnrìn-àjò ṣàṣeyọrí? Wọ́n gbára lé Jèhófà àti ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. (2 Kọ́r. 3:1-5) Torí náà, bí ipò rẹ kò bá jẹ́ kó o lè gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ àkànṣe, o ṣì lè ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù lórílẹ̀-èdè míì. Má sì gbàgbé pé, ò ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí kò dáwọ́ dúró ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run àti Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn. Tó o bá sì ní in lọ́kàn láti lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì tàbí ilé ẹ̀kọ́ míì tó jọ ọ́, tó o bá lọ sìn ní ilẹ̀ òkèèrè kí o bàa lè tọ́ iṣẹ́ míṣọ́nnárì wò, èyí á jẹ́ kó o ní ìrírí tó máa wúlò fún ẹ nígbà tí wọ́n bá pè ẹ́ fún ìdálẹ́kọ̀ọ́ síwájú sí i.
4. Kí nìdí tí kò fi yẹ kí àwọn àgbàlagbà ronú pé àwọn kò lè lọ wàásù nílẹ̀ òkèèrè?
4 Àwọn Àgbàlagbà: Àwọn àgbàlagbà tí wọ́n tún dàgbà nípa tẹ̀mí tí wọ́n sì ní ìlera tó dáa dé ìwọ̀n àyè kan máa wúlò gan-an láwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. Ṣé o ti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́? Ó ti ṣeé ṣe fún àwọn kan tó jẹ́ pé owó ìfẹ̀yìntì táṣẹ́rẹ́ ni wọ́n ń gbà pàápàá láti máa gbọ́ bùkátà ara wọn ní àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, tí àwọn nǹkan tí wọ́n ń náwó lé lórí, títí kan owó ìtọ́jú ìṣègùn, kò sì pọ̀ tó iye tí wọ́n máa ń ná ní orílẹ̀-èdè tíwọn.
5. Sọ ìrírí arákùnrin kan tó ti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ tó wá lọ sí orílẹ̀-èdè míì láti lọ ṣe iṣẹ́ ìsìn.
5 Arákùnrin kan tó ti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ ní orílẹ̀-èdè kan tí wọ́n ti ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì, tó jẹ́ alàgbà àti aṣáájú-ọ̀nà, lọ sí àgbègbè kan táwọn èèyàn ti sábà máa ń wá gbafẹ́ ní Gúúsù Ìlà Oòrùn ilẹ̀ Éṣíà, kó bàa lè ṣèrànwọ́ fún àwùjọ kan tí iye wọn jẹ́ mẹ́sàn-án, tí wọ́n ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì. Àwùjọ yìí máa ń wàásù fún àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè tí iye wọn tó ọ̀kẹ́ kan àtààbọ̀ [30,000] tó ń gbé àgbègbè náà. Láàárín ọdún méjì, iye àwọn tó ń wá sípàdé ti di àádọ́ta. Arákùnrin náà kọ̀wé pé: “Wíwá tí mo wá síbí ti jẹ́ kí n rí ìbùkún àgbàyanu tí mi ò rí irú rẹ̀ rí. Ẹnu mi kò lè sọ gbogbo ìbùkún àgbàyanu tí mo rí!”
6. Sọ ìrírí arábìnrin kan tí kò tíì lọ́kọ tó lọ sìn lórílẹ̀-èdè tá a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i.
6 Àwọn Arábìnrin Tí Kò Tíì Lọ́kọ: Jèhófà ti lo àwọn arábìnrin lọ́nà tó lágbára gan-an láti mú kí ìhìn rere délé dóko láwọn orílẹ̀-èdè tá a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. (Sm. 68:11) Arábìnrin ọ̀dọ́ kan ti fi ṣe àfojúsùn rẹ̀ láti mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ gbòòrò sí i nílẹ̀ òkèèrè, àmọ́ ààbò rẹ̀ jẹ àwọn òbí rẹ̀ lógún gan-an. Torí náà, ó yan orílẹ̀-èdè tí kò sí rògbòdìyàn ìṣèlú, tí ètò ọrọ̀ ajé sì fara rọ, ó kọ̀wé sí ẹ̀ka ọ́fíìsì, wọ́n sì fi ìsọfúnni tó ṣèrànwọ́ tó sì ṣe pàtó ránṣẹ́ sí i. Láàárín ọdún mẹ́fà tó lò lórílẹ̀-èdè náà, ó rí ọ̀pọ̀ ìbùkún gbà. Ó sọ pé: “Tó bá jẹ́ pé ilé ni mo wà, mi ò ní láǹfààní láti máa kọ́ àwọn èèyàn tó pọ̀ tó báyìí lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́ bí mo ṣe lọ sìn níbi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i ti jẹ́ kí n lè máa kọ́ àwọn èèyàn tó pọ̀ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì ti jẹ́ kí ọ̀nà tí mò ń gbà kọ́ni dára sí i.”
7. Sọ ìrírí ìdílé kan tí wọ́n kó lọ sí orílẹ̀-èdè mìíràn.
7 Àwọn Ìdílé: Tó o bá ní ọmọ, ǹjẹ́ ìyẹn dí ẹ lọ́wọ́ lílọ sí orílẹ̀-èdè mìíràn láti mú kí ìwàásù ìhìn rere gbòòrò sí i? Ìdílé kan tó ní ọmọ méjì, tí ọ̀kan jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́jọ, tí èkejì sì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́wàá, gbìyànjú èyí wò. Ìyá wọn sọ pé: “A dúpẹ́ gan-an pé ibi yìí la ti tọ́ àwọn ọmọ wa, torí pé àárín àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe àtàwọn míṣọ́nnárì ni wọ́n dàgbà sí. Ìgbésí ayé wa ti dára gan-an torí pé a lọ sìn níbi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i.”
8. Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe láti lọ sìn lórílẹ̀-èdè míì láìjẹ́ pé èèyàn kọ́ èdè tuntun? Ṣàlàyé.
8 Ọ̀rọ̀ Nípa Èdè: Ṣé ìṣòro àtikọ́ èdè ilẹ̀ òkèèrè ni kò jẹ́ kó o fẹ́ lọ sìn lórílẹ̀-èdè mìíràn? Ó ṣeé ṣe kí wọ́n máa sọ èdè tó o gbọ́ láwọn orílẹ̀-èdè tá a ti nílò àwọn oníwàásù Ìjọba Ọlọ́run púpọ̀ sí i. Tọkọtaya kan tí wọ́n ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì lọ sí orílẹ̀-èdè kan tí wọ́n ti ń sọ èdè Sípáníìṣì, àmọ́ tó ní àwọn èèyàn díẹ̀ tí wọ́n wá láti orílẹ̀-èdè míì, tí wọ́n gbọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì. Lẹ́yìn tí ẹ̀ka ọ́fíìsì ti sọ fún wọn nípa àwọn ìjọ mélòó kan tí wọ́n ti ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì, tí wọ́n sì nílò àwọn akéde ìjọba Ọlọ́run púpọ̀ sí i, àwọn tọkọtaya yìí mú ọ̀kan, wọ́n sì ṣèbẹ̀wò síbẹ̀ nígbà méjì. Wọ́n pa dà sílé, wọ́n dín owó tí wọ́n ń ná lóṣooṣù kù, wọ́n sì tọ́jú owó pa mọ́ fún ọdún kan. Nígbà tí wọ́n ṣe tán láti lọ, àwọn arákùnrin tó wà ní àgbègbè yẹn bá wọn wá ilé tí owó rẹ̀ kò pọ̀.
9, 10. Kí ni àwọn tó ṣí lọ sí orílẹ̀-èdè mìíràn lè ronú nípa rẹ̀, kí sì nìdí?
9 Àwọn Tó Ṣí Lọ́ sí Orílẹ̀-èdè Mìíràn: Ǹjẹ́ o tí ṣi kúrò ní orílẹ̀-èdè rẹ kó o tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́? Ó ṣeé ṣe kí wọ́n nílò àwọn olùkórè tó pọ̀ ní orílẹ̀-èdè tó o ti wá. Ǹjẹ́ o lè gbe é yẹ̀ wò bóyá o lè pa dà sílé, kó o lè ṣèrànwọ́? Ó lè rọrùn fún ẹ láti rí ilé àti iṣẹ́ ju fún ẹnì kan tó wá láti orílẹ̀-èdè mìíràn lọ. O tún ṣeé ṣe kó o gbọ́ èdè ìbílẹ̀ rẹ. Láfikún sí i, àwọn èèyàn lè fẹ́ láti gbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run látẹnu rẹ, ju ti ẹnì kan tí wọ́n kà sí àjèjì.
10 Ọkùnrin kan tó ń wá ibi ìsádi ṣí kúrò ní orílẹ̀-èdè Albania, ó sì lọ sí orílẹ̀-èdè Ítálì, ó rí iṣẹ́ tó ń mowó wọlé, ó sì ń fi owó ránṣẹ́ sí ìdílé rẹ̀ tó wà lórílẹ̀-èdè Albania. Lẹ́yìn tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe tí wọ́n jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Ítálì tí wọ́n fẹ́ lọ sìn níbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i ní èdè Albanian. Arákùnrin náà kọ̀wé pé: “Ìpínlẹ̀ ìwàásù tí mo ti kúrò ni wọ́n fẹ́ lọ. Wọn kò gbọ́ èdè tí wọ́n ń sọ níbẹ̀, àmọ́ inú wọn ń dùn láti lọ. Ọmọ Albania ni mí, mo gbédè, mo sì tún mọ àṣà ìbílẹ̀ wa. Kí ni mo wá ń ṣe lórílẹ̀-èdè Ítálì?” Arákùnrin náà pinnu láti pa dà sí orílẹ̀-èdè Albania láti mú kí ìhìn rere náà gbòòrò sí i. Ó sọ pé: “Ǹjẹ́ mo kábàámọ̀ bí mo ṣe fi iṣẹ́ àti owó tó ń wọlé fún mi sílẹ̀? Mi ò kábàámọ̀ rẹ̀ rárá! Mo rí iṣẹ́ tó dára jù lọ lórílẹ̀-èdè Albania. Ní tèmi o, iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ tó sì ń fúnni láyọ̀ tó wà pẹ́ títí ni sísin Jèhófà pẹ̀lú gbogbo ohun tí èèyàn ní!”
11, 12. Kí ló yẹ kí àwọn tó fẹ́ ṣí lọ sí orílẹ̀-èdè mìíràn ronú nípa rẹ̀?
11 Bẹ́ Ẹ Ṣe Máa Ṣe É: Kí Pọ́ọ̀lù àtàwọn tí wọ́n jọ rìnrìn àjò tó lọ sí Makedóníà, apá ìwọ̀ oòrùn ni wọ́n kọ́kọ́ fẹ́ lọ, àmọ́ “ẹ̀mí mímọ́ ka sísọ ọ̀rọ̀ náà . . . léèwọ̀ fún wọn,” ni wọ́n bá kọrí sí ìhà àríwá. (Ìṣe 16:6) Nígbà tí wọ́n sún mọ́ Bítíníà, Jésù kò gbà wọ́n láyè. (Ìṣe 16:7) Jèhófà ṣì ń darí iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run nípasẹ̀ Jésù. (Mát. 28:20) Torí náà, tó o bá ń ronú nípa lílọ sìn lórílẹ̀-èdè mìíran, gbàdúrà sí Jèhófà pé kó tọ́ ẹ sọ́nà.—Lúùkù 14:28-30; Ják. 1:5; wo àpótí náà, “Bó O Ṣe Lè Mọ̀ Bóyá Wọ́n Nílò Oníwàásù Ní Orílẹ̀-Èdè Tó O Fẹ́ Lọ,” lójú ìwé 6.
12 Ní kí àwọn alàgbà tàbí àwọn míì tí wọ́n dàgbà nípa tẹ̀mí gbà ẹ́ ní ìmọ̀ràn, kó o lè mọ̀ bóyá wàá kẹ́sẹ járí tó o ba lọ sìn nílẹ̀ òkèèrè. (Òwe 11:14; 15:22) Ka àwọn ìsọfúnni tá a ti tẹ̀ jáde nípa lílọ sìn lórílẹ̀-èdè míì, kó o sì ṣe ìwádìí nípa orílẹ̀-èdè tí ò ń ronú láti lọ. Ǹjẹ́ o lè kọ́kọ́ ṣèbẹ̀wò sí orílẹ̀-èdè tó wù ẹ́ láti lọ, bó tiẹ̀ jẹ́ fún bí ọjọ́ mélòó kan? Tó o bá fẹ́ lọ sí orílẹ̀-èdè míì lóòótọ́, o lè kọ lẹ́tà sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà lórílẹ̀-èdè yẹn fún ìsọfúnni síwájú sí i, kí o lo àdírẹ́sì tó wà nínú ìwé ọdọọdún wa, ìyẹn Yearbook, tó jáde kẹ́yìn. Àmọ́ ṣá o, dípò tí wàá fi fúnra rẹ fi lẹ́tà náà ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì náà, ńṣe ni kó o fún àwọn alàgbà ìjọ rẹ, wọ́n á kọ ohun tí wọ́n mọ̀ nípa rẹ sí i kí wọ́n tó fi ránṣẹ́.—Wo ìwé A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà, ojú ìwé 111 sí 112.
13. Ìrànlọ́wọ́ wo ni ẹ̀ka ọ́fíìsì máa fún ẹ, àmọ́ kí làwọn nǹkan tí ìwọ fúnra rẹ máa ṣe?
13 Ẹ̀ka ọ́fíìsì máa fún ẹ ní ìsọfúnni tó máa wúlò fún ẹ nípa orílẹ̀-èdè náà, èyí tó máa jẹ́ kó o lè ṣe àwọn ìpinnu tó yẹ, àmọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì kọ́ ló máa ṣe onídùúró rẹ lọ́dọ̀ ìjọba, àwọn kọ́ ló máa bá ẹ gba ìwé àṣẹ ìgbélùú tàbí àwọn fọ́ọ̀mù míì tí òfin bá béèrè, wọn ò sì ní gba ilé fún ẹ. Ọ̀ràn ara ẹni ni gbogbo ìyẹn jẹ́, èèyàn sì gbọ́dọ̀ fara balẹ̀ ṣèwádìí nípa rẹ̀ kó tó lọ síbẹ̀. Láfikún sí i, ìwọ fúnra rẹ lo máa bá àwọn aṣojú ìjọba sọ̀rọ̀ láti gba ìsọfúnni nípa ìwé àṣẹ ìgbélùú àti ìwé àṣẹ láti ṣiṣẹ́. Àwọn tó lọ sí orílẹ̀-èdè mìíràn gbọ́dọ̀ lè gbọ́ bùkátà ara wọn, kí wọ́n sì ṣe àwọn ohun tí òfin béèrè.—Gál. 6:5.
14. Nígbà tá a bá ṣèbẹ̀wò tàbí tá a kó lọ sí orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa, kí nìdí tó fi yẹ ká ṣọ́ra?
14 Àwọn Orílẹ̀-Èdè Tí Wọ́n Ti Fòfin De Iṣẹ́ Ìwàásù: Láwọn orílẹ̀-èdè kan, ọgbọ́n ni àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó wà níbẹ̀ fi ń ṣe ìjọsìn wọn. (Mát. 10:16) Àwọn ará tó ṣèbẹ̀wò síbẹ̀ tàbí tí wọ́n kó lọ síbẹ̀ sì lè pe àfiyèsí tí kò yẹ sí iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe níbẹ̀, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ fi àwọn arákùnrin wa tó wà níbẹ̀ sínú ewu. Tó o bá ń ronú àtilọ sí irú orílẹ̀-èdè bẹ́ẹ̀, jọ̀wọ́, kọ lẹ́tà sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà lórílẹ̀-èdè rẹ nípasẹ̀ àwọn alàgbà ìjọ rẹ, kó o tó lọ síbẹ̀.
15. Báwo ni àwọn tí ipò wọn kò gbà wọ́n láyè láti lọ sí orílẹ̀-èdè míì ṣe lè mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn gbòòrò sí i?
15 Bí O Kò Bá Lè Lọ sí Orílẹ̀-Èdè Mìíràn: Bí ipò rẹ kò bá gbà ẹ́ láyè láti lọ sí orílẹ̀-èdè mìíràn, má ṣe jẹ́ kí ìyẹn kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ẹ. “Ilẹ̀kùn ńlá tí ń ṣamọ̀nà sí ìgbòkègbodò” ṣì lè ṣí sílẹ̀ fún ìwọ náà. (1 Kọ́r. 16:8, 9) Alábòójútó àyíká yín lè mọ ibi tí wọ́n ti nílò ìrànlọ́wọ́ tí kò sì fi bẹ́ẹ̀ jìnnà sí ibi tí ò ń gbé. O sì lè lọ ṣèrànwọ́ ní ìjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè ilẹ̀ òkèèrè, tó bá wà nítòsí rẹ. Tàbí kó o mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ gbòòrò sí i ní ìjọ tó o wà báyìí. Láìka ipò tó o wà sí, ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé kó o máa sin Jèhófà tọkàntọkàn.—Kól. 3:23.
16. Báwo ló ṣe yẹ ká máa hùwà sí àwọn tó fẹ́ lọ sìn lórílẹ̀-èdè mìíràn?
16 Ǹjẹ́ o mọ Kristẹni kan tó dàgbà nípa tẹ̀mí tó fẹ́ lọ sìn nílẹ̀ òkèèrè? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kó o ti irú ẹni bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn, kó o sì fún un ní ìṣírí! Nígbà tí Pọ́ọ̀lù kúrò ní Síríà Áńtíókù tó jẹ́ ìlú kẹta tó tóbi jù lọ ní Ilẹ̀ Ọba Róòmù (lẹ́yìn Róòmù àti Alẹkisáńdíríà). Nítorí pé ìpínlẹ̀ yẹn tóbi, ó ṣeé ṣe kí àwọn ará ìjọ Áńtíókù nílò ìrànlọ́wọ́ Pọ́ọ̀lù, àárò rẹ̀ sí máa sọ wọ́n gan-an tó bá lọ. Síbẹ̀, Bíbélì kò sọ pé àwọn ará tó wà níbẹ̀ rọ Pọ́ọ̀lù pé kó má ṣe lọ. Ó jọ pé dípò tí wọn ò bá fi máa ronú nípa àgbègbè wọn nìkan, wọ́n rántí pé “pápá náà ni ayé.”—Mát. 13:38.
17. Kí làwọn ìdí tó fi yẹ ká ronú nípa ‘ríré kọjá lọ sí Makedóníà’?
17 Ọlọ́run bù kún Pọ́ọ̀lù àtàwọn tí wọ́n jọ rìnrìn àjò lọ́nà tó pọ̀ gan-an nítorí pé wọ́n tẹ́wọ́ gba ìkésíni náà láti ré kọjá lọ sí Makedóníà. Nígbà tí wọ́n wà ní ìlú Fílípì tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìlú tó wà ní Makedóníà, wọ́n pàdé Lìdíà, “Jèhófà sì ṣí ọkàn-àyà rẹ̀ sílẹ̀ láti fiyè sí àwọn ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ.” (Ìṣe 16:14) Ẹ wo bí ayọ̀ Pọ́ọ̀lù àtàwọn tí wọ́n jọ jẹ́ míṣọ́nnárì ṣe máa pọ̀ tó nígbà tí Lìdíà àti gbogbo agbo ilé rẹ̀ ṣe ìrìbọmi! Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, àwọn èèyàn wà tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ ọkàn bíi Lìdíà tí wọn kò tíì gbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Tó o bá ‘ré kọjá lọ sí Makedóníà,’ o lè rí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀, kó o sì ràn wọ́n lọ́wọ́, ìyẹn sì máa fún ẹ láyọ̀ gan-an.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]
Bó O Ṣe Lè Mọ̀ Bóyá Wọ́n Nílò Oníwàásù Ní Orílẹ̀-Èdè Tó O Fẹ́ Lọ
• Wo Ìròyìn Ọdún Iṣẹ́ Ìsìn Nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù February, ọdún 2011. Fún apá náà, “Ìṣirò Ìfiwéra, Akéde Kan sí,” ní àfiyèsí.
• Lo atọ́ka àwọn ìtẹ̀jáde ìyẹn Index, láti ṣe ìwádìí àwọn àpilẹ̀kọ àti àwọn ìrírí láti orílẹ̀-èdè náà.
• Bá àwọn akéde tó ti lọ sí orílẹ̀-èdè náà rí tàbí tí wọ́n ti gbé ibẹ̀ rí sọ̀rọ̀.
• Tó o bá ń ronú nípa orílẹ̀-èdè tó o máa ti lè fi èdè ìbílẹ̀ rẹ wàásù, wá ìsọfúnni síwájú sí i, irú bíi lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, kó o lè mọ iye àwọn èèyàn tó wà lórílẹ̀-èdè náà tí wọ́n ń sọ èdè rẹ.