Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
Ṣé Kí N Lọ Gbé Lókè Òkun?
“Mo fẹ́ lọ wá ibòmíì gbé.”—Sam.
“Mo kàn ṣáà fẹ́ tọpinpin ni. Mo fẹ́ láti rí nǹkan tó tún yàtọ̀.”—Maren.
“Ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́ kan sọ fún mi pé ó máa dáa fún mi tí n bá lè kúrò nílé fúngbà díẹ̀.”—Andreas.
“Mo ń yánhànhàn láti rìnrìn àjò ìgbádùn lọ.”—Hagen.
ṢÉ ÌWỌ náà ti fi lálàá rí pé kóo lọ gbé nílẹ̀ òkèèrè—bó bá tiẹ̀ jẹ́ pé oò ní pẹ́ púpọ̀ níbẹ̀? Lọ́dọọdún, ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọ̀dọ́ ló ń ní àǹfààní láti ṣe bẹ́ẹ̀. Andreas sọ nípa ìrírí ẹ̀ nílẹ̀ òkèèrè pé: “Á wù mí kí n tún padà lọ.”
Àwọn ọ̀dọ́ kan máa ń ṣípò padà fúngbà díẹ̀ nítorí kí wọ́n lè ṣiṣẹ́ owó tàbí kí wọ́n lè kọ́ èdè kan tó jẹ́ ti ilẹ̀ òkèèrè. Fún àpẹẹrẹ, ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, ètò fún gbígbé lọ́dọ̀ àwọn ìdílé kan nítorí àti kọ́ èdè wọn wọ́pọ̀. Ìwọ̀nyí ń fún àwọn àjèjì tó jẹ́ ọ̀dọ́ láǹfààní láti máa ṣiṣẹ́ ilé fún ìdílé kan, ìdílé náà yóò sì fún wọn ní iyàrá tí wọn óò máa gbé àti oúnjẹ, wọ́n sì máa ń lo àkókò tó bá ṣí sílẹ̀ fún wọn láti fi kọ́ èdè tí wọ́n ń sọ níbẹ̀. Àwọn ọ̀dọ́ kan tún wà tí wọ́n lọ sókè òkun láti lọ kàwé. Àwọn mìíràn lọ síbẹ̀ láti lọ ṣiṣẹ́, kí wọ́n lè rówó ran ìdílé wọn lọ́wọ́. Síbẹ̀ àwọn mìíràn ń lọ nítorí pé wọn ò mọ nǹkan tí wọ́n máa ṣe tí wọ́n bá jáde ilé ìwé, wọ́n á sì fẹ́ láti lọ sinmi díẹ̀ lókè òkun.
Ó dùn mọ́ni pé, àwọn Kristẹni ọ̀dọ́ kan ti ṣí lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè kan níbi tí àwọn oníwàásù kò ti tó, kí wọ́n lè mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn gbòòrò sí i. Ohun yòówù tó lè jẹ́ ìdí fún kíkó lọ síbòmíràn, gbígbé ní ilẹ̀ òkèèrè lè pèsè ẹ̀kọ́ gidi kan tó máa wúlò nígbà téèyàn bá dàgbà, tó dẹni tó dá dúró. O lè túbọ̀ nírìírí sí i nípa oríṣiríṣi àṣà. O tiẹ̀ lè mọ èdè òkèèrè kan dunjú, ìyẹn sì lè fún ẹ láǹfààní tó pọ̀ sí i nígbà tóo bá ń wáṣẹ́.
Síbẹ̀síbẹ̀, kì í ṣe gbogbo ìgbà ni lílọ gbé lókè òkun máa ń jẹ́ ìrírí tó gbádùn mọ́ni. Fún àpẹẹrẹ, Susanne lọ lo ọdún kan gẹ́gẹ́ bí akẹ́kọ̀ọ́ tó lọ rọ́pò akẹ́kọ̀ọ́ mìíràn tó wá sí orílẹ̀-èdè tirẹ̀ láti ilẹ̀ òkèèrè. Ó sọ pé: “Mo ní ìdánilójú pé gbogbo ẹ̀ á máa dùn yùngbà fún mi ni látìbẹ̀rẹ̀ dópin. Àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ mọ́.” Wọ́n ti lo àwọn ọ̀dọ́ kan nílòkulò tàbí kí wọ́n tiẹ̀ ti níṣòro tó burú jáì. Nítorí náà, á bọ́gbọ́n mu pé kóo kọ́kọ́ jókòó, kóo ro àwọn ewu àti àǹfààní tó lè wà nínú rẹ̀ dáadáa wò kóo tó palẹ̀ ẹrù ẹ mọ́.
Gbé Èrò Inú Ẹ Yẹ̀ Wò Dáadáa
Ó dájú pé ohun tó wé mọ́ gbígbé àwọn ewu àti àǹfààní tó wà nídìí rẹ̀ yẹ̀ wò kan yíyẹ èrò inú ẹ wò dáadáa láti mọ ìdí tóo fi fẹ́ lọ sókè òkun. Ohun kan ni láti rìnrìn àjò nítorí àtilè túbọ̀ lépa ire tẹ̀mí tàbí láti bójú tó ẹrù iṣẹ́ ìdílé. Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀dọ́ táa fa ọ̀rọ̀ wọn yọ níbẹ̀rẹ̀ ti sọ, ọ̀pọ̀ nífẹ̀ẹ́ láti ṣí lọ síbòmíràn kìkì nítorí kí wọ́n lè lọ gbádùn ara wọn, kí wọ́n lè túbọ̀ rí òmìnira fàlàlà, tàbí láti lọ ṣe fàájì. Kì í ṣe pé èyí kúkú burú. Ṣebí Oníwàásù 11:9 rọ àwọn ọ̀dọ́ láti ‘yọ̀ nígbà èwe wọn.’ Ṣùgbọ́n, ẹsẹ kẹwàá kìlọ̀ pé: “Mú pákáǹleke kúrò ní ọkàn-àyà rẹ, kí o sì taari ìyọnu àjálù kúrò ní ẹran ara rẹ.”
Bó bá jẹ́ nítorí kóo lè yẹra fún ìkálọ́wọ́kò tó ń wá látọ̀dọ̀ àwọn òbí lo ṣe fẹ́ lọ sí ilẹ̀ òkèèrè, àfàìmọ̀ kó máà jẹ́ pé “ìyọnu àjálù” lò ń fà lẹ́sẹ̀ o. Ṣóo rántí àkàwé Jésù nípa ọmọ onínàákúnàá? Ìtàn ọ̀dọ́kùnrin kan tó fi ìmọtara ẹni nìkan rìnrìn àjò lọ sílẹ̀ òkèèrè, ó sì hàn gbangba pé nítorí àti túbọ̀ rí òmìnira fàlàlà ni. Kò pẹ́ kò jìnnà, ìyọnu bẹ̀rẹ̀ sí í já lù ú, ebi bẹ̀rẹ̀ sí pa á, ó di aláìní, àìsàn tẹ̀mí sì tún kọ lù ú.—Lúùkù 15:11-16.
Àwọn kan tún wà tí wọ́n fẹ́ ṣí lọ nítorí kí wọ́n lè bọ́ lọ́wọ́ ìṣòro tí wọ́n ń ní nílé. Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí Heike Berg tí sọ nínú ìwé rẹ̀ What’s Up, “tó bá jẹ́ pé kìkì nítorí pé o ò láyọ̀ lo ṣe fẹ́ wábi gbà lọ . . . tóo sì wá rò pé gbogbo nǹkan á gún régé sí i níbòmíràn, irọ́ lo pa!” Láìsí tàbí-tàbí, ó sàn kéèyàn kúkú tẹ́wọ́ gba ìṣòro bó ti rí gan-an. Kò sí àǹfààní kankan nínú sísá lọ fún àwọn ipò tólúwa ẹ̀ ò fẹ́.
Àwọn èrò mìíràn tó tún léwu ni ti ojúkòkòrò àti ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́nì. Bí ìfẹ́ ọkàn wọn fún ọrọ̀ àlùmọ́nì ti ń ti ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́, ńṣe ni wọ́n ń ro bí ìgbésí ayé ti rí ní àwọn orílẹ̀-èdè tó ti rọ́wọ́ mú, àwọn nǹkan ńláńlá, tọ́wọ́ wọn ò lè tẹ̀ ni wọ́n sì ń rò. Àwọn kan ń finú wòye pé gbogbo àwọn ará Ìwọ̀ Oòrùn ayé pátá ló jẹ́ ọlọ́rọ̀. Àmọ́ èyí kì í ṣòótọ́ rárá. Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti kó lọ tán, ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ wọ̀nyí á wá ríra wọn nílẹ̀ àjèjì, tí wọ́n ń jìjàkadì láti máà kú sínú ìṣẹ́.a Bíbélì kìlọ̀ pé: “Ìfẹ́ owó ni gbòǹgbò onírúurú ohun aṣeniléṣe gbogbo, àti nípa nínàgà fún ìfẹ́ yìí, a ti mú àwọn kan ṣáko lọ kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọ́n sì ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrora gún ara wọn káàkiri.”—1 Tímótì 6:10.
Ṣé O Ti Múra Tán?
Kókó mìíràn wà tó tún yẹ kóo gbé yẹ̀ wò: Ṣé lóòótọ́ lo ti dàgbà dénú tó láti kojú àwọn ìnira, ìṣòro, àti àwọn ìforígbárí tó ṣeé ṣe kó ṣẹlẹ̀ lókè òkun? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìwọ àti ẹnì kan lẹ máa jọ gbé tàbí kó jẹ́ pé ọ̀dọ̀ ìdílé kan ni wàá lọ gbé, tí wàá sì ní láti mú ara rẹ bá ìgbòkègbodò wọn mu. Nítorí náà, báwo lo ṣe ń ṣe nílé nísinsìnyí? Ṣé àwọn òbí ẹ ń ṣàròyé pé o kì í gba tẹlòmíràn rò, pé anìkànjọpọ́n ni ẹ́? Ṣóo nítẹ̀sí láti máa yanbọ oúnjẹ? Báwo lo ṣe ń fi tinútinú ṣé èyí tó kàn ẹ́ nínú iṣẹ́ ilé tó? Bí àwọn ohun wọ̀nyí bá jẹ́ ìṣòro lílekoko fún ẹ nísinsìnyí, finú ro bí wọ́n ṣe máa túbọ̀ ṣòro fún ẹ tó nílùú onílùú o!
Bóo bá wá jẹ́ Kristẹni kan, ṣé wàá lè dá mójú tó ipò tẹ̀mí ẹ? Àbí gbogbo ìgbà ló jẹ́ pé ńṣe làwọn òbí ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ ń rán ẹ létí pé kóo má gbàgbé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àwọn ìpàdé Kristẹni àti iṣẹ́ ìwàásù? Ṣé wàá lókun tó nípa tẹ̀mí láti dènà àwọn pákáǹleke àti ìdẹwò tó wà lókè okun, èyí tí kò sí nílùú ẹ? Ọjọ́ tí ọ̀dọ́ Kristẹni kan, tó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ kan tó lọ rọ́pò akẹ́kọ̀ọ́ mìíràn tó wá sí ìlú rẹ̀ kọ́kọ́ lọ sílé ẹ̀kọ́ ní ilẹ̀ òkèèrè, ni wọ́n ti júwe ibi tó ti lè rí oògùn olóró rà fún un. Lẹ́yìn ìgbà yẹn ni ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ẹlẹgbẹ́ ẹ̀ tó jẹ́ obìnrin tún sọ fún un pé káwọn jọ ròde. Àmọ́ nílùú ẹ̀ níbi tó ti wá, ọmọbìnrin kan kò lè sọ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ jáde. Ọ̀dọ́kùnrin kan, ọmọ ilẹ̀ Áfíríkà, tó ṣí lọ sí Yúróòpù náà tún sọ pé: “Lórílẹ̀-èdè tí mo ti wá, ẹ ò jẹ́ rí àwòrán ìṣekúṣe níta gbangba. Àmọ́ níbí, kò síbi tẹ́ ò ti ní rí i.” Lílọ gbé lókè òkun lè yọrí sí rírì ọkọ̀ ìgbàgbọ́ bí ẹnì kan kò bá “dúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́.”—1 Pétérù 5:9.
Ṣèwádìí Dáadáa!
Kó tó di pé o ṣí lọ, ó yẹ kóo kọ́kọ́ wádìí dáadáa. Máà gbára lé ọ̀rọ̀ wọ́n-ní wọ́n-pé. Fún àpẹẹrẹ, ká ní o ń ronú láti lọ rọ́pò akẹ́kọ̀ọ́ mìíràn tó wá sílùú rẹ, èló ló máa ná ẹ? Ó lè yà ẹ́ lẹ́nu láti mọ̀ pé ẹgbẹẹgbẹ̀rún náírà ló sábà máa ń náni. Ó tún yẹ kóo wádìí bóyá ẹ̀kọ́ tóo bá gbà lókè òkun á wúlò nílé. Bákan náà, wá gbogbo ìsọfúnni tóo bá lè rí nípa orílẹ̀-èdè náà—òfin wọn, àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ wọn, àṣà ìbílẹ̀ wọn. Kí làwọn nǹkan tí gbígbé níbẹ̀ máa ná ẹ? Irú owó orí wo ní wàá ní láti san? Ṣé àwọn ewu ìlera wà tó yẹ kí o gbé yẹ̀ wò? Ó lè ṣèrànwọ́ bí o bá bá àwọn tó ti gbé níbẹ̀ rí sọ̀rọ̀.
Lẹ́yìn náà, ọ̀ràn nípa ibi tí wàá gbé tún wà níbẹ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn òbí tó ń gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó wá rọ́pò òmíràn sílé kì í retí pé kí wọ́n san nǹkankan padà fáwọn. Bó tiẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, lílọ gbé pẹ̀lú àwọn ẹni tí kò bọ̀wọ̀ fún àwọn ìlànà Bíbélì lè fa àìfararọ àti pákáǹleke tó pọ̀. O sì tún lè yàn láti gbé lọ́dọ̀ àwọn ẹbí tàbí àwọn ọ̀rẹ́. Àmọ́ ṣọ́ra o, kóo máà tún wá dẹ́rù pa wọ́n—kódà tí wọ́n bá tiẹ̀ ń rọ̀ ẹ́ pé kóo dúró. Eléyìí lè mú ìfàsẹ́yìn bá àjọṣe rẹ pẹ̀lú wọn, kódà, ó lè bà á jẹ́.—Òwe 25:17.
Tóo bá wéwèé láti ṣiṣẹ́ ní gbogbo ìgbà tóo fi máa wà lókè okun, má gbàgbé ojúṣe ẹ gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni láti ṣègbọràn sáwọn aláṣẹ ayé. (Róòmù 13:1-7) Ṣé òfin gbà ẹ́ láyè láti ṣiṣẹ́ lórílẹ̀-èdè yẹn? Bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, lábẹ́ irú àwọn àyíká ipò wo ni? Tóo bá lọ ṣiṣẹ́ láìbófinmu, o lè fi ipò ẹ gẹ́gẹ́ bi Kristẹni aláìlábòsí kan sínú ewu, kóo sì fi ara ẹ sípò kan tí o ò ti ní lẹ́tọ̀ọ́ sí ààbò tó ṣe pàtàkì, irú bí ẹ̀tọ́ ìbánigbófò nígbà jàǹbá. Kódà tó bá tiẹ̀ bófin mu pé o lè ṣiṣẹ́, wàá fẹ̀sọ̀ ṣe, kí o sì fọgbọ́n hùwà. (Òwe 14:15) Àwọn agbanisíṣẹ́ tí kò lóòótọ́ sábà máa ń ṣe àwọn àjèjì bó ṣe wù wọ́n ni.
Ṣíṣe Ìpinnu Kan
Ó ti wá ṣe kedere pé, ìpinnu láti lọ gbé nílẹ̀ òkèèrè jẹ́ ọ̀kan tó ṣe pàtàkì, kò sì yẹ kóo fọwọ́ dẹngbẹrẹ mú un. Kí ìwọ àti àwọn òbí rẹ jọ jókòó, kẹ́ẹ sì jọ gbé àwọn àǹfààní tí ẹ lè retí àti àwọn ewu tó ṣeé ṣe kó wà nínú ẹ̀ wò dáadáa. Má torí pé inú ẹ ń dùn láti lọ, kóo wá gbé agbára ìfòyemọ̀ ẹ tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan. Má ṣe tan ara ẹ jẹ nígbà tóo bá ń ṣàyẹ̀wò kínníkínní nípa ìdí tóo fi fẹ́ lọ. Fetí sílẹ̀ dáadáa sí àwọn òbí ẹ. Ó ṣe tán, wọ́n mọ̀ pé àwọn làwọn ṣì máa dáhùn fún bóo ṣe rìn ín, bí o tiẹ̀ fi ọgọ́rọ̀ọ̀rún kìlómítà jìnnà sí wọn. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé wàá nílò ìtìlẹ́yìn wọn ní ti ọ̀ràn ìnáwó láti lè ṣàṣeyọrí.
Lẹ́yìn táa ti gbé gbogbo àwọn kókó yìí yẹ̀ wò, ó lè máà bọ́gbọ́n mu pé kóo ṣí lọ—ó kéré tan ní lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí. Èyí lè jẹ́ ìjákulẹ̀ fún ẹ, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan tó gbádùn mọ́ni mìíràn wà tóo lè ṣe. Fún àpẹẹrẹ, ṣóo ti ṣèwádìí bóyá yóò ṣeé ṣe fún ẹ láti bẹ àwọn ibi tó gbádùn mọ́ni wò ní orílẹ̀-èdè tìẹ gangan? Tàbí kẹ̀, o ò ṣe kúkú bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ èdè ilẹ̀ òkèèrè kan? Bí àkókò ti ń lọ, bóyá àǹfààní láti lọ sókè òkun lè ṣí sílẹ̀.
Tó bá wá jẹ́ pé o ṣì pinnu síbẹ̀síbẹ̀ láti ṣí lọ ńkọ́? Àpilẹ̀kọ kan tí yóò tún jáde nígbà míì yóò jíròrò bí o ṣe lè gbé lókè òkun tí wàá sì ṣàṣeyọrí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo àpilẹ̀kọ náà “Ṣiṣiro Ohun Ti Ṣiṣilọ Sí Ilẹ Ọlọrọ Yoo Náni” nínú ìtẹ̀jáde Ilé-Ìṣọ́nà, April 1, 1991, tí Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania, tẹ̀ jáde.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Àwọn ọ̀dọ́ kan ṣí lọ síbòmíì láti lè mú kí iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run tẹ̀ síwájú
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Kí ìwọ àtàwọn òbí ẹ jọ sọ̀rọ̀ nípa àwọn àǹfààní àti ewu tó wà nínú ṣíṣílọ