ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 4/1 ojú ìwé 26-29
  • Ṣiṣiro Ohun Ti Ṣiṣilọ Sí Ilẹ Ọlọrọ Yoo Náni

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣiṣiro Ohun Ti Ṣiṣilọ Sí Ilẹ Ọlọrọ Yoo Náni
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Awọn Otitọ Gidi Nipa Igbesi-Aye Oke Okun
  • Awọn Ikimọlẹ Iwarere
  • Awọn Obi Ti Wọn Ko Sí Nile
  • Ni Igbẹkẹle Ninu Awọn Ipese Ọlọrun
  • Ṣé Kí N Lọ Gbé Lókè Òkun?
    Jí!—2000
  • ‘Pípèsè fún Agbo Ilé Ẹni’—Kíkojú Ìpènijà Náà ní Àwọn Ilẹ̀ Tí Ń Gòkè Àgbà
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Báwo Ni Gbígbé Lókè Òkun Ṣe Lè Gbè Mí?
    Jí!—2000
  • Báwọn Òbí Mi Ò Bá Lówó Ńkọ́?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 4/1 ojú ìwé 26-29

Ṣiṣiro Ohun Ti Ṣiṣilọ Sí Ilẹ Ọlọrọ Yoo Náni

ÓJẸ́ iran ti kò ṣajeji ni ọfiisi aṣoju orilẹ-ede jakejado apa ilẹ-aye ti o ṣẹṣẹ ngoke àgbà: yara iduro kan ti o kun fọ́fọ́ fun awọn eniyan tí wọn nfojusọna pẹlu aniyan fun ifọrọwanilẹnuwo wọn. Lori ipilẹ ijiroro ṣoki ṣugbọn ti o ṣe pataki yẹn, a o pinnu rẹ̀ boya wọn le ri òǹtẹ̀ gbà sori iwe irinna wọn lati lọ si awọn ilẹ ti wọ ni ile iṣẹ ẹrọ nlanla ni Iwọ-oorun. Ọpọlọpọ gbagbọ pe eyi ni yoo jẹ́ tíkẹ́ẹ̀tì wọn sí aasiki. Ọ̀dọ́ kan lati Iwọ-oorun Africa ráhùn pe, “Mo ti nṣiṣẹ kara fun ọdun mẹrin, sibẹ ipa mi ko tii ká a lati ní redio kan. Bi mo ba wà ni England tabi United States ni, nisinsinyi nba ti ni ọkọ ayọkẹlẹ ati ibugbe temi lati gbé.”

Kò ṣoro lati loye ìdí ti ọpọlọpọ ní awọn orilẹ-ede ti ko lọrọ, ti o ṣẹṣẹ ngoke àgbà fi ni iru awọn ero bẹẹ. Fun wọn, iṣẹ ṣoro lati rí, owo ti a nsan sì kere. Ifosoke owo ọja ńyìnrìn owo ti a fi pamọ. Ile gbigbe ṣoro lati rí o sì há gádígádí. Awọn eniyan nwọ aṣọ ti awọn ilẹ wọnni ti wọn lọrọ ju ti rù danu. Ọpọlọpọ nimọlara kiko sinu hílàhílo ọ̀ràn ìṣúnná owó.

Bawo si ni Iwọ-oorun ọlọrọ ti nfanimọra tó! Ọ̀dọ́ ọkunrin kan ni Sierra Leone wipe: “Awọn kan tí wọn ti lọ si oke okun pada wa wọn si pìtàn ti o fun wa niṣiiri lati lọ ki a si ri awọn ilẹ ti wọn ni ile iṣẹ́ ẹ̀rọ nlanla naa funraawa. Wọn sọ pe iwọ nilati ṣiṣẹ kara, ṣugbọn iwọ yoo ri owo ti o pọ̀ to debi pé iwọ yoo le ran araarẹ lọwọ ki o si ni awọn ohun idẹra diẹ paapaa, iru bii ọkọ ayọkẹlẹ. Bí iwọ ba si pada wa sihin-in pẹlu nǹkan bii ẹgbẹrun dollar meji, iwọ le dá ile iṣẹ silẹ kí o sì gbeyawo.”

Ko yanilẹnu pe, awọn iranṣẹ Ọlọrun diẹ ti ronu lọna ti o farajọra. Arabinrin ara Africa kan wipe: “Awa ọ̀dọ́ ninu eto-ajọ Ọlọrun maa nfetisilẹ sí awọn ijumọsọrọpọ nipa bi awọn miiran ti wọn ti lọ sí oke okun ti nṣe daradara tó. Nitori naa nigba miiran emi yoo beere lọwọ araami pe, ‘Emi nkọ? Eeṣe ti mo fi njiya nihin-in? Ṣe ki nlọ tabi ki nduro?’”

Bi iwọ ba ngbe ni orilẹ ede tí kò lọrọ, iwọ pẹlu lè ṣe kayeefi boya iṣilọ kan yoo mu ijojulowo igbesi-aye rẹ sunwọn sii. Bi o ti wu ki o ri, ṣiṣilọ si ilẹ ajeji kan jẹ́ idawọle titobi kan, igbesẹ anánilówó kan ti o gba ironu jinlẹ. O le wemọ kíkọ́ ede titun kan, níní awọn òye iṣẹ titun, mimu ara ba aṣa ibilẹ titun kan mu, fifarada ẹtanu ti ọpọlọpọ lè fihan sí awọn ajeji, ati kikẹkọọ odidi ọna igbesi-aye titun kan. Sibẹ, ọpọlọpọ awọn Kristian ti ṣe bẹẹ pẹlu aṣeyọrisirere wọn sì ti jasi anfaani tootọ fun awọn ijọ ninu ilẹ ibugbe wọn titun, ti wọn nṣiṣẹsin gẹgẹ bi akede awofiṣapẹẹrẹ, aṣaaju-ọna, alagba, ati iranṣẹ iṣẹ-ojiṣẹ.

Bi o ti wu ki o ri, kii ṣe gbogbo wọn ni wọn ṣe daadaa bẹẹ. Awọn masunmawo ati igalara ti iṣilọ sí orilẹ-ede miiran ti yọrisi iparun tẹmi fun awọn kan. Lọna ti o han gbangba, nigba naa, iru iṣikuro bẹẹ ni a ko nilati ṣe laisi ironu jinlẹ, ti o kun fun adura. Bibeli gbaninimọran ni Owe 3:5, 6 pe: “Fi gbogbo aya rẹ gbẹkẹle Oluwa [“Jehofa,” NW]; ma si ṣe tẹ̀ sí imọ ara rẹ. Mọ ọn ni gbogbo ọna rẹ: oun o si maa tọ ipa ọna rẹ.” Bẹẹni, iwọ fẹ ri i daju pe o nhuwa ni ibamu pẹlu ifẹ inu Jehofa. (Jakọbu 4:13-15) Jesu si funni ni awọn imọran diẹ ti wọn ṣee fisilo lati ran ọ lọwọ lati ṣe eyi nigba ti oun rọ awọn olufetisilẹ rẹ̀ lati ‘ṣiro iye ti yoo ná wọn.’ (Luuku 14:28) Eyi ni ninu ju awọn igbeyẹwo ọran inawo. O tumọsi ṣiṣiro iye ti o ṣeeṣe kí ṣiṣilọ sí orilẹ-ede miiran náni nipa tẹmi.

Awọn Otitọ Gidi Nipa Igbesi-Aye Oke Okun

Ṣaaju ṣiṣilọ sí ibikibi, iwọ nilati ni oye oun ti iwọ yoo reti nigba ti o ba de ibẹ. Bi o ba ṣeeṣe, ṣe ibẹwo iṣaaju ki o sì rí bi awọn nǹkan ti ri funraarẹ. Bí bẹẹ kọ́, iwọ yoo nilati gbarale isọfunni tí o gbọ́ lati ẹnu ẹlomiran. Bibeli kilọ pe: “Òpè eniyan gba ọrọ gbogbo gbọ: ṣugbọn amoye eniyan wo ọna ara rẹ̀ rere.”—Owe 14:15.

Awọn kan ti gba gbogbo isọfunni wọn nipa igbesi-aye ni awọn ilẹ Iwọ-oorun lati inu awọn aworan ere sinima ati tẹlifiṣọn. Wọn tipa bayii gbagbọ pe olukuluku eniyan ti wọn wà nibẹ jẹ́ ọlọ́rọ̀, ngun ọkọ ayọkẹlẹ titun, wọn sì ngbe ile ti o kun fun faaji. Bi o ti wu ki o ri, bi ọran ṣe ri niti gidi yatọ gan-an. Ọpọlọpọ ilẹ ọlọrọ ni iwọn ipo oṣi, àìrílégbé ati airiṣẹṣe ti njanilaya. Ọpọlọpọ awọn olugbe tí wọn sì jẹ́ otoṣi julọ jẹ awọn ti wọn ṣẹṣẹ ṣí wọnú orilẹ-ede. Oṣiṣẹ aṣoju kan ni ọfiisi aṣoju U.S. ni orilẹ-ede kan ti ko lọrọ ṣalaye pe: “Awọn eniyan kò wulẹ mọ bí ó ti ṣòro tó lati fidimulẹ ni America. Awọn kan yoo kọwe si ile ni sisọ bi wọn ti nṣe daradara tó—bí wọn ti ra ọkọ ayọkẹlẹ meji ati ile kan—ṣugbọn niti tootọ wọn nja fitafita gidigidi ni.”

Ipo naa farajọra nibomiran. Ọgbẹni Sahr Sorie jẹ́ olukọni ara Iwọ-oorun Africa kan ti o ti gbe ti o sì kẹkọọ ni London. Oun sọ pe: “Ko rọrun lati ṣi kuro ni Africa lati maa gbe ni England. Ọpọ julọ awọn ti nṣi lọ si orilẹ-ede miiran maa ngbe igbesi-aye otoṣi gan-an. Iwọ ri ipa ìyà ni oju wọn. Kò rọrun fun awọn kan lati kó 20 eépìnnì jọ (20 pence) lati ṣe ikesini ori tẹlifoonu. Niye igba wọn nṣajọpin iyara kanṣoṣo pẹlu ọpọlọpọ awọn miiran, eyi ti o ni kiki amulegbona kekere kan lati mú ara wọn mooru. O ṣeeṣe fun wọn lati rí kiki iṣẹ ọmọ ọdọ, ani pẹlu iyẹn paapaa kò tó fun wọn lati san awọn gbèsè tí wọn jẹ. Awọn wọnni ti wọn fi Africa silẹ lati bọ lọwọ ipo oṣi maa nri i lemọlemọ pe o buru ju fun wọn ninu ile awọn akuṣẹẹ ti Europe.”

Awọn ikimọlẹ ọran inawo ti o wepọ mọ́ fifidimulẹ ni ilẹ titun lè fi tirọruntirọrun fun ipo tẹmi ẹnikan pa. (Matiu 13:22) Loootọ, iṣẹ aṣekara ni a gboriyin fun ninu Bibeli. (Owe 10:4; 13:4) Ṣugbọn ọpọlọpọ tí wọn lọ sí oke okun ni a fipa mú lati ṣe iṣẹ meji tabi mẹta kí ọwọ wọn baa le tẹ gongo ọran inawo wọn—tabi lati wulẹ mu ki awọ kájú ìlù. Akoko kekere ni o ṣẹku lati lepa ijọsin Ọlọrun tabi ki o ma tilẹ sí rara. Awọn ipade Kristian, ikẹkọọ Bibeli, ati ṣiṣajọpin otitọ Bibeli pẹlu awọn ẹlomiran ni a pati. Awọn ọ̀rọ̀ Jesu Kristi jásí otitọ lọna ti o banininujẹ: “Ẹyin ko le sìnrú fun Ọlọrun ati fun Ọrọ̀.”—Matiu 6:24, NW.

Awọn Ikimọlẹ Iwarere

Iwọ nilati gbe ayika ọna iwahihu ilẹ titun ti o nnaga fun yẹwo pẹlu. Bibeli sọ fun wa pe Lọti yan lati gbe ní Agbegbe Jọdani. Lati inú oju iwoye ohun ti ara, ipinnu rẹ̀ dabi ti ọlọgbọn kan, nitori ‘o jẹ́ agbegbe ti o ni omi nibi gbogbo, . . . bi ọgba Oluwa [“Jehofa,” NW].” (Jẹnẹsisi 13:10) Bi o ti wu ki o ri, awọn alabaagbe titun Lọti jẹ́ “ẹlẹṣẹ gidigidi niwaju Oluwa [“Jehofa,” NW]”—onibalopọ takọtabo ti a gbégbòdì! (Jẹnẹsisi 13:13) Gẹgẹ bi iyọrisi rẹ̀, “ọkunrin oloootọ nì bi o ti ngbe laaarin wọn, ti o nri ti o si ngbọ, lojoojumọ ni iwa buburu wọn nba ọkan otitọ rẹ̀ jẹ́.”—2 Peteru 2:8.

Lọna ti o farajọra, lonii iṣilọ sí Iwọ-oorun le ṣi iwọ ati idile rẹ silẹ sí awọn ikimọlẹ iwahihu ati awọn idanwo tí wọn gbónájanjan ju ti ilẹ ibilẹ rẹ. Ni afikun, awọn eniyan tí wọn jẹ́ agbalagba ni a lè má bọla fun gẹgẹ bi a ti nṣe fun wọn ni ile. Ọ̀wọ̀ fun awọn obi ni a le ma fun niṣiiri. Awọn alabaagbe lè má nifẹẹ-ọkan pupọ ninu araawọn. Bawo ni iru awọn ikimọlẹ bẹẹ ṣe lè nipa lori rẹ ati idile rẹ? Eyi jẹ́ ohun kan ti a nilati fun ni ironu ti o kun fun adura.

Awọn Obi Ti Wọn Ko Sí Nile

Awọn obi kan ti yan lati fi idile wọn silẹ kí wọn si dánìkan rinrin ajo lọ si oke okun. Iṣeto wọn ni lati ranṣẹ pe idile wọn ní gbàrà tí wọn bá ti ribi dé sí tabi boya lati pada si ile pẹlu ọpọ yanturu owo. Njẹ iru iṣeto bẹẹ bọgbọnmu bi?

Iwe Mimọ rọ awọn obi lati pese awọn ohun ini ti ara fun awọn idile wọn, ati ninu awọn ọran kan ti ko ṣee yẹ silẹ rárá, obi kan le ma ni yiyan miiran ju lati ṣiṣẹ loke okun ki o baa le ṣe iru ipese bẹẹ. (1 Timoti 5:8) Sibẹ, awọn òbí ni a tun rọ lati bojuto aini tẹmi awọn idile wọn. Ọrọ Ọlọrun wipe: “Ẹyin baba, ẹ maṣe mú awọn ọmọ yin binu: ṣugbọn ẹ maa tọ́ wọn ninu ẹkọ ati ikilọ Oluwa [“Jehofa,” NW].”—Efesu 6:4.

Njẹ baba kan ha le ṣe eyi lọna gbigbeṣẹ bí oun ba fi idile rẹ̀ silẹ fun ọpọ oṣu tabi ọdun lẹẹkan naa? Ko daju. Nitori naa iwọ gbọdọ gbe iyẹn wo bi anfaani ohun ti ara eyikeyii ti o jere ba to ipa ti aisinile rẹ lé ni lori awọn ọmọ rẹ. Yatọ sí iyẹn, awọn ti nṣi lọ si orilẹ-ede miiran saba maa nri i pe kò rọrun lati ko “nǹkan ìní” wọn jọ gẹgẹ bi wọn ti ronu. Bi ẹni ti o ṣi lọ si orilẹ-ede miiran naa kò bá le sanwo irin ajo ọkọ ofuurufu idile, ipinya naa le maa baa lọ fun ọpọ ọdun. Eyi, ẹ̀wẹ̀ lè dá awọn ewu ọna iwahihu ti o lewu silẹ. (Fiwe 1 Kọrinti 7:1-5.) O banininujẹ lati sọ pe, awọn kan tí wọn wà ninu irú awọn ipo ti ndanniwo bẹẹ ti juwọsilẹ fun iwa palapala takọtabo.

Ni Igbẹkẹle Ninu Awọn Ipese Ọlọrun

Gẹgẹ bi awọn ipo ìṣúnná owo aye ti njorẹhin, o dara lati ranti pe awọn iranṣẹ Ọlọrun kò nilati bẹru pe a o kọ awọn silẹ. Jesu wipe: “Ẹ maṣe ṣe aniyan, wipe, ki ni a o jẹ? Tabi, ki ni a o mu? Tabi, aṣọ wo ni a o fi wọ wa? Nitori gbogbo nǹkan wọnyi ni awọn Keferi nwa kiri. Nitori baba yin ti nbẹ ni ọrun mọ pe, ẹyin ko le ṣe alaini gbogbo nǹkan wọnyi. Ṣugbọn ẹ tete maa wa ijọba Ọlọrun ná, ati ododo rẹ̀; gbogbo nǹkan wọnyi ni a o si fi kun un fun yin.”—Matiu 6:31-33.

Awọn Ẹlẹrii Jehofa lonii nṣiṣẹsin fun ire Ijọba Ọlọrun nipa pipokiki ihinrere naa pẹlu itara. (Matiu 24:14; 28:19, 20) Ni ọpọlọpọ awọn orilẹ-ede ti ko lọrọ, aini titobi wa fun awọn oniwaasu Ijọba. Ni pataki ni aini wa fun awọn alagba ati iranṣẹ iṣẹ-ojiṣẹ ti wọn dagbadenu. Dipo lilọ si ilẹ alaasiki niti ìṣúnná owo nibi ti aini kò ti pọ pupọ, ọpọlọpọ ti yan lati wà ni orilẹ-ede ibilẹ wọn. Bawo ni o ti ri fun diẹ lara irú awọn eniyan bẹẹ?

Alethia, ara Iwọ-oorun Africa kan ti o ti ṣe aṣaaju-ọna fun 30 ọdun ti o wa ni orilẹ-ede ibilẹ rẹ̀, wipe: “Mo ni anfaani lati gbe ni oke okun. Ìdí ti emi ko fi ṣe bẹẹ ni pe mo nifẹẹ lati wa pẹlu awọn eniyan ati ibatan mi funraami. Mo gbadun riran wọn lọwọ lati kẹkọọ otitọ ki a baa le ṣiṣẹsin Jehofa papọ. Emi ko tii padanu ohunkohun kankan nipa diduro nihin-in, emi ko si kabaamọ ohunkohun.”

Winifred bakan naa gbe ni orilẹ-ede Africa kan. Ojulowo igbesi-aye ti ara nibẹ ni a ka si eyi ti o rẹlẹ julọ ni agbaye. Ṣugbọn lẹhin 42 ọdun ninu iṣẹ-isin aṣaaju ọna alakooko kikun, oun wipe: “Ko maa nfigba gbogbo rọrun lati ṣaṣeyọri niti ìṣúnná owo. Satani ngbiyanju lati mú awọn nǹkan lekoko, ṣugbọn ìgbà gbogbo ni Jehofa maa npese fun mi o si nbojuto awọn aini mi.”

Ni akoko igbaani Abrahamu “gbagbọ pẹlu idaniloju kikun pe ohun ti [Ọlọrun] ti ṣeleri ó le ṣee pẹlu.” (Roomu 4:21, NW) Bakan naa iwọ ha gbagbọ pẹlu idaniloju pe Jehofa le mu ileri rẹ̀ ṣẹ ki o si bikita fun ọ bi iwọ ba fi ire Ijọba si iwaju ninu igbesi-aye rẹ? Iwọ ha gba pẹlu onisaamu naa ti o kọwe pe: “Ofin ẹnu [Ọlọrun] dara fun mi ju ẹgbẹẹgbẹrun wura ati fadaka lọ”? (Saamu 119:72) Tabi aini lati fi imọran Apọsteli Pọọlu silo ni kikun ha wa fun ọ? Ni 1 Timoti 6:8, oun kọwe pe: “Bi a ba si ni ounjẹ ati aṣọ iwọnyi yoo tẹ́ wa lọrun.” O ha le jẹ pe ohun ti o bọgbọnmu lati ṣe yoo jẹ́, lati maṣe wa ayika titun, ṣugbọn lati lo ti isinsinyi lọna ti o dara julọ?

Awọn ipo ìṣúnná owo ni ọpọlọpọ ilẹ le fa awọn ipo inira mímúná fun awọn Kristian. Nipa bayii, lẹhin gbigbe gbogbo awọn koko ti o wemọ ọn yẹwo, bi idile kan ba pinnu lati ṣi lọ si orilẹ-ede miiran, ko si ìdí eyikeyii fun awọn ẹlomiran lati ṣe ariwisi. (Galatia 6:5) Awọn wọnni ti wọn kù lẹhin lè maa beere fun iranlọwọ Jehofa lati maa farada awọn ipo inira ti eto igbekalẹ yii muwa, nigba ti wọn ńyọ̀ ninu awọn ibukun tẹmi ti Ọlọrun fun wọn. Ranti, laipẹ awọn aiṣedajọ ododo ati aidọgba aye yii ni a o ṣatunṣe labẹ Ijọba Ọlọrun. Nigba naa yoo ri bi onisaamu naa ti kọwe pe: “Iwọ [Jehofa] ṣí ọwọ rẹ, iwọ si tẹ ifẹ gbogbo ohun alaye lọrun.”—Saamu 145:16.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́