ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g00 8/8 ojú ìwé 24-26
  • Báwo Ni Gbígbé Lókè Òkun Ṣe Lè Gbè Mí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Ni Gbígbé Lókè Òkun Ṣe Lè Gbè Mí?
  • Jí!—2000
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Pinnu Láti Mú Ara Rẹ Bá Ipò Nǹkan Mu
  • ‘Àárò Ilé Ń Sọ Mi!’
  • Bíbá Ìdílé Tó Gbani Lálejò Gbé
  • Yíyanjú Àwọn Ìṣòro
  • Pípadà Sílé
  • Ṣé Kí N Lọ Gbé Lókè Òkun?
    Jí!—2000
  • Ṣiṣiro Ohun Ti Ṣiṣilọ Sí Ilẹ Ọlọrọ Yoo Náni
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
  • Báwọn Òbí Mi Ò Bá Lówó Ńkọ́?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
Àwọn Míì
Jí!—2000
g00 8/8 ojú ìwé 24-26

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Báwo Ni Gbígbé Lókè Òkun Ṣe Lè Gbè Mí?

“Nígbà tí mo dé pápákọ̀ òfuurufú, ṣe ló dà bíi pé kí ń padà sílé! . . . Gbogbo ìyánhànhàn mi láti dé ibi tí mi ò dé rí àti gbogbo ayọ̀ àwárí tí mo ṣe ti pòórá. Lọ́rọ̀ kan ṣáá, àárò ilé sọ mi ju ti ìgbàkígbà rí lọ.”—Uta.

Ó MÁA ń bani lẹ́rù pé kí ó kù ọ́ ku ìwọ nìkan ní ilẹ̀ àjèjì. Ṣùgbọ́n bí àpilẹ̀kọ tó ṣáájú lára ọ̀wọ́ yìí ti fi hàn, ọ̀pọ̀ èwe ló ń yàn láti lọ gbé lókè òkun fún ìgbà díẹ̀. Àwọn kan máa ń lọ láti kọ́ ẹ̀kọ́ ìwé tàbí láti gba àkànṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́. Àwọn kan máa ń lọ kọ́ èdè. Àwọn kan sì rèé, owó ni wọ́n ń wá lọ. Ṣùgbọ́n o, àwọn mìíràn lọ láti sìn ní ilẹ̀ òkèèrè níbi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù Ìjọba náà.

Ká ní tìtorí ìdí tó bọ́gbọ́n mu lo ṣe ń gbé lókè òkun—àwọn ìdí tó fún àwọn àìní àti góńgó rẹ nípa tẹ̀mí ní àfiyèsía—kí lo lè ṣe láti rí i dájú pé gbígbé níbẹ̀ á gbè ọ́?

Pinnu Láti Mú Ara Rẹ Bá Ipò Nǹkan Mu

Lákọ̀ọ́kọ́ ná, o gbọ́dọ̀ múra tán láti mú ara rẹ bá ipò nǹkan mu. Ìyẹn kò túmọ̀ sí pé kí o pa àwọn ìlànà Kristẹni tàbí àwọn nǹkan tẹ̀mí tí o máa ń ṣe tì. Ṣùgbọ́n ó lè túmọ̀ sí pé o gbọ́dọ̀ kọ́ jíjẹ àwọn oúnjẹ tuntun, kí o kọ́ àwọn ìlànà ìwà rere tuntun kan, tàbí kí o gbìyànjú àwọn ọ̀nà tuntun tí a ń gbà ṣe àwọn nǹkan. Àwọn àṣà tuntun wọ̀nyí lè yàtọ̀ pátápátá sí bí o ṣe ń ṣe àwọn nǹkan nílé. Ṣùgbọ́n àṣẹ Jésù pé “ẹ dẹ́kun dídánilẹ́jọ́” ṣeé fi sílò gidigidi níhìn-ín. (Mátíù 7:1) Lóòótọ́, kò sí ẹ̀yà ìran tàbí àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ táa lè sọ pé ó sàn ju àwọn yòókù lọ. (Ìṣe 17:26) Gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn àgbàlagbà ṣe gbọ́dọ̀ yẹra fún ṣíṣe àfiwé lọ́nà àríwísí láàárín àwọn èwe àtijọ́ àti àwọn tòde òní, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ọ̀dọ́ tó wà lókè òkun gbọ́dọ̀ yẹra fún ṣíṣe àfiwé lọ́nà àríwísí láàárín ilẹ̀ òkèèrè àti ilẹ̀ tiwọn. (Oníwàásù 7:10) Pọkàn pọ̀ sórí àwọn nǹkan rere tí ilẹ̀ tuntun àti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ tuntun yẹn lè fi fún ọ. Pẹ̀lúpẹ̀lù, bí o bá ṣe tètè kọ́ èdè ilẹ̀ náà sí, bẹ́ẹ̀ náà ni ibẹ̀ yóò ṣe tètè mọ́ ọ lára tó.

Pọ́ọ̀lù ṣàṣeyọrí nínú mímú kí onírúurú àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ mọ́ òun lára nígbà tó ń ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì nítorí pé ó múra tán láti di “ohun gbogbo fún ènìyàn gbogbo.” (1 Kọ́ríńtì 9:22) Irú ìṣarasíhùwà kan náà lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mú ara rẹ bá ipò nǹkan mu. Adrianne jẹ́ ọmọ ọ̀dọ̀ tó ń gbé ní Jámánì, ó máa ń bá ìdílé kan ṣe iṣẹ́ ilé kí ó lè rí ilé gbé, kí ó sì máa rí oúnjẹ jẹ. Ó ṣàlàyé pé: “Mo gbọ́dọ̀ ṣe ìyípadà ní wàràǹṣeṣà nítorí pé mi ò lè retí pé kí àwọn ẹlòmíràn mú ara wọn bá ipò mi mu.”

‘Àárò Ilé Ń Sọ Mi!’

Fún ọ̀sẹ̀ mélòó kan àkọ́kọ́, ó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ pé kí inú èèyàn bàjẹ́, kí àárò ilé sì máa sọni. Bíbélì fi hàn pé Jékọ́bù ‘ṣàfẹ́rí ilé baba rẹ̀ gidigidi,’ bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lé lógún ọdún tí Jékọ́bù ti wà ní ilẹ̀ òkèèrè! (Jẹ́nẹ́sísì 31:30) Nítorí náà, má ṣe jẹ́ kó yà ọ́ lẹ́nu bí ìrẹ̀wẹ̀sì bá mú ọ nígbà mìíràn. Àmọ́ ṣá o, bí o bá ń fìgbà gbogbo ronú nípa àwọn nǹkan tí o fi sílẹ̀ nílé, ṣe ni wàá túbọ̀ máa ba inú ara rẹ jẹ́. (Númérì 11:4, 5) Ọ̀nà tó dáa jù lọ, tí o lè gbà borí ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn ni pé kí o sapá láti mú kí àwọn ọ̀nà tuntun tí wàá máa gbà ṣe nǹkan àti àyíká ipò rẹ tuntun mọ́ ọ lára. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó dáa kí o máa gbúròó ìdílé rẹ nípa kíkọ lẹ́tà sí wọn tàbí kí o máa fi tẹlifóònù bá wọn sọ̀rọ̀, kíkàn sí wọn nílé lórí tẹlifóònù ní gbogbo ìgbà lè máà jẹ́ kí ibùgbé rẹ tuntun bá ọ lára mu.

Ọ̀pọ̀ Kristẹni ọ̀dọ́ rí i pé pípadà sẹ́nu ìtòlẹ́sẹẹsẹ wọn tẹ̀mí ti ṣèrànwọ́ dídára jù lọ láti dènà ìṣòro ìnìkanwà. (Fílípì 3:16) Amber rántí àwọn ọ̀sẹ̀ díẹ̀ àkọ́kọ́ tó lò lókè òkun, ó ní: “Kò rọrùn fún mi rárá ní àwọn ọwọ́ ìrọ̀lẹ́ nígbà tí kò bá sí ohunkóhun láti ṣe, nítorí náà, mó máa ń gbìyànjú láti kẹ́kọ̀ọ́ sí i tàbí kí n máa kàwé.” Rachel tó jẹ́ ọ̀dọ́ sọ̀rọ̀ látinú ìrírí ara rẹ̀ nígbà tó gbani nímọ̀ràn pé: “Dara pọ̀ ní lílọ́wọ́ nínú ìgbòkègbodò ìjọ lójú ẹsẹ̀. Bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí ìpàdé lọ́gán.” Lákọ̀ọ́kọ́, o lè nílò ìrànwọ́ díẹ̀ láti lè máa lọ sí ìpàdé. Ṣùgbọ́n láàárín ìjọ Kristẹni, o lè rí àwọn ọ̀rẹ́ tó gbámúṣé tó lè dà bí “àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin àti àwọn ìyá.”—Máàkù 10:29, 30.

Kíkópa nínú iṣẹ́ ìjíhìnrere Kristẹni tún jẹ́ apá pàtàkì nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ tẹ̀mí tó dáa. Iṣẹ́ ìwàásù yóò ṣe ọ́ láǹfààní nípa tẹ̀mí, ṣùgbọ́n ìyẹn nìkan kọ́ o, yóò tún ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mú kí àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ tuntun yẹn mọ́ ọ lára, kí o sì gbọ́ èdè tuntun.

Paríparí rẹ̀, máa gbàdúrà, kí o sì máa dá kẹ́kọ̀ọ́ déédéé. Wọ́n ṣe kókó bí ìwọ yóò bá máa jẹ́ onílera nípa tẹ̀mí. (Róòmù 12:12; 1 Tímótì 4:15) Nítorí èyí, Adrianne, tí a mẹ́nu kàn ní ìṣáájú, rí i dájú pé òun kó àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì dání lédè ìbílẹ̀ òun.

Bíbá Ìdílé Tó Gbani Lálejò Gbé

Nígbà tí wọ́n bá wà lókè òkun, àwọn Kristẹni ọ̀dọ́ kan ti ṣètò láti máa gbé lọ́dọ̀ àwọn ìdílé wọn tó jẹ́ onígbàgbọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò lè retí pé kí ìdílé tó gbani lálejò gba iṣẹ́ òbí ṣe, wọ́n lè jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ rere àti orísun ìṣírí nípa tẹ̀mí.—Òwe 27:17.

Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ ní fàlàlà pẹ̀lú ìdílé náà ṣe kókó fún níní àjọṣe tó gún régé. (Òwe 15:22; 20:5; 25:11) Amber sọ pé: “Ó yẹ kí o wéwèé ohun tí o fẹ́ ṣe. O gbọ́dọ̀ mọ ohun tí àwọn tó gbà ọ́ lálejò ń retí látọ̀dọ̀ rẹ. Ó sì yẹ kí àwọn pẹ̀lú mọ ohun tí ìwọ náà ń retí látọ̀dọ̀ wọn.” Wádìí àwọn ìlànà tí ìdílé náà ń tẹ̀ lé nínú ilé àti ìwọ̀n tí wọ́n retí pé kí o máa ṣe nínú iṣẹ́ ilé. Kí ẹ jíròrò irú àwọn ọ̀ràn bẹ́ẹ̀ dáadáa.

Ipò náà yóò túbọ̀ jẹ́ ìpèníjà gidigidi bó bá ṣẹlẹ̀ pé fún àpẹẹrẹ, ìdílé tí kò gba àwọn ohun tí ìwọ gbà gbọ́ lo gbà ọ́ lálejò, tí o sì ń ṣiṣẹ́ fún. Níwọ̀n bí ìdílé náà ti lè má mọ ìdúró rẹ nípa àwọn ìlànà Bíbélì, o lè bá ara rẹ ní àwọn ipò tí ń dẹni wò. (Òwe 13:20) Wọ́n lè sọ pé kí o máa ṣiṣẹ́ ilé lákòókò tó máa tako àwọn ojúṣe rẹ nípa tẹ̀mí, irú bíi lílọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni. Nítorí náà, bí àyíká ipò tí kò ṣeé yẹ sílẹ̀ bá mú kí o máa gbé pẹ̀lú ìdílé tí kì í ṣe ẹ̀sìn tí ò ń ṣe, nígbà náà, o gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ ṣe àwọn nǹkan tí kò ní jẹ́ kí ọ̀ràn dàrú.

Rachel, tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, tó ń ṣe ọmọ ọ̀dọ̀ ní Jámánì, dámọ̀ràn pé: “Rí i dájú pé wọ́n mọ̀ pé Kristẹni ni ọ́. Ó dára jù lọ pé kí o yáa sọ òótọ́ ọ̀rọ̀ fún wọn lójú ẹsẹ̀.” Ṣíṣàlàyé ìlànà ẹ̀sìn rẹ àti ti ìwà rere fún wọn lè jẹ́ ààbò kan. Pẹ̀lúpẹ̀lù, o gbọ́dọ̀ ṣàlàyé yékéyéké fún ẹni tó gbà ọ́ síṣẹ́ pé àwọn ìpàdé Kristẹni àti iṣẹ́ ìwàásù ṣe pàtàkì fún ọ gidigidi. Paríparí rẹ̀, ó bọ́gbọ́n mu pé kí o rí i dájú pé àwọn ọ̀ràn pàtàkì, irú bíi wákàtí iṣẹ́, àkókò ìsinmi, àti owó iṣẹ́ ti wà lákọọ́lẹ̀ kí o tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́. Èyí kò ní jẹ́ kí wọ́n já ọ kulẹ̀ nígbà tó bá yá.

Yíyanjú Àwọn Ìṣòro

Láìka gbogbo ìsapá dídára jù lọ tí o lè ṣe sí, ìṣòro ṣì lè ṣẹlẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, bí àwọn tó gbà ọ́ lálejò bá sọ pé kí o kúrò nílé àwọn ńkọ́? Èyí lè kó ìdààmú bá ọ gidigidi. Bí èdè àìyédè bá ṣẹlẹ̀, o lè gbìyànjú láti yanjú ọ̀ràn ọ̀hún pẹ̀lú àwọn tó gbà ọ́ lálejò, kí o fi pẹ̀lẹ́tù ṣe èyí, kí o sì ṣe é lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu. (Òwe 15:1) Múra tán láti gba àṣìṣe èyíkéyìí tí o bá ṣe. Bóyá wọ́n lè yí ọkàn wọn padà. Bí wọn ò bá gbà, a jẹ́ pé o máa wá ibùgbé mìíràn nìyẹn.

Àwọn ìṣòro mìíràn lè gba pé kí o bẹ ẹnì kan pé kí ó ràn ọ́ lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, o lè ní ìṣòro ìṣúnná owó, tàbí kí o ṣàìsàn. Nítorí pé o ń bẹ̀rù pé àwọn òbí rẹ lè fẹ́ wá mú ọ padà sílé, o lè máa lọ́ tìkọ̀ láti jẹ́ kí wọ́n mọ nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀. Yàtọ̀ sí ìyẹn, ọ̀nà wọn jìn sí ọ, wọ́n sì lè máà mọ bó ṣe yẹ láti bójú tó irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ní ilẹ̀ òkèèrè. Ṣùgbọ́n àwọn alàgbà ìjọ rẹ lè ní ìrírí nípa bí o ṣe lè yanjú irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀, ó sì ṣeé ṣe kí wọ́n fún ọ ní ìmọ̀ràn tó gbéṣẹ́. Wọ́n tún lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti pinnu bóyá ó yẹ kí àwọn òbí rẹ mọ̀ nípa ọ̀ràn yẹn.

Pípadà Sílé

Láìka àwọn ìṣòro àti ìpèníjà sí, gbígbé lókè òkun lè jẹ́ ìrírí tí ń mérè wá, pàápàá tó bá jẹ́ pé tìtorí nǹkan tẹ̀mí lo fi lọ. Ó dájú pé, àkókò lè tó fún ọ láti padà sílé. Andreas wí pé: “Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí rántí ọ̀pọ̀ nǹkan tó gbádùn mọ́ mi, kò pẹ́ tí mo fi gbàgbé àwọn tí kò gbádùn mọ́ mi, ó sì wá ṣòro fún mi nígbà tí mo fẹ́ kúrò níbẹ̀.” Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, má ṣe retí pé kí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tàbí ìdílé tóo fi sílé ṣàdédé yí ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣe àwọn nǹkan padà nísinsìnyí tí o ti dé pẹ̀lú àṣà tuntun tí o kọ́ lókè òkun. Síwájú sí i, má ṣe mú wọn bínú nípa rírán wọn létí ní gbogbo ìgbà nípa bí wọ́n ṣe máa ń ṣe àwọn nǹkan ní ilẹ̀ mìíràn. Bí ó ṣe máa ń rí, wàá fẹ́ sọ ìrírí rẹ fún gbogbo èèyàn, ṣùgbọ́n má ṣe rẹ̀wẹ̀sì bí kì í bá ṣe gbogbo èèyàn ni ohun tí o ń sọ dùn mọ́.

Ní kedere, a gbọ́dọ̀ fi ọwọ́ pàtàkì mú ṣíṣe ìpinnu láti lọ gbé fún ìgbà díẹ̀ ní ilẹ̀ òkèèrè. Bó bá ṣẹlẹ̀ pé lẹ́yìn tí o jíròrò ọ̀ràn náà pẹ̀lú àwọn òbí rẹ, ẹ pinnu pé ó bọ́gbọ́n mu pé kí o lọ, múra sílẹ̀ láti kojú àwọn ìṣòro tí wàá dojú kọ. Bó ṣe máa ń rí nígbà tí o bá dojú kọ ìpinnu wíwúwo nínú ìgbésí ayé, ó bọ́gbọ́n mu pé kí o kọ́kọ́ ṣírò ohun tí yóò ná ọ.—Lúùkù 14:28-30.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Ṣé Kí N Lọ Gbé Lókè Òkun?” tó wà nínú ìtẹ̀jáde ti July 8, 2000.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Àwọn Ìsọfúnni Tí Ń Dáàbò Boni

● Fi ìwé àṣẹ ìrìnnà, owó, àti tíkẹ́ẹ̀tì tí wàá fi wọkọ̀ padà, síbi tí nǹkan kò ní ṣe é.

● Ṣe àwọn ẹ̀dà ìwé àṣẹ ìrìnnà rẹ títí kan ìwé àṣẹ láti wọlé sí orílẹ̀-èdè mìíràn àti òǹtẹ̀ àṣẹ ìwọ̀lú, tíkẹ́ẹ̀tì tí wàá fi wọkọ̀ padà, àti àwọn ìwé mìíràn tó ṣe pàtàkì. Fi ọ̀wọ́ kan lára àwọn ẹ̀dà yẹn pa mọ́ sọ́wọ́, kí o sì fi ọ̀wọ́ kejì ránṣẹ́ sí àwọn òbí tàbí ọ̀rẹ́ rẹ nílé.

● Gbogbo ìgbà ni kí o ní nọ́ńbà fóònù àwọn òbí tàbí ọ̀rẹ́ rẹ̀ nílé lọ́wọ́, kí o sì ní ti ìdílé tó gbà ọ́ lálejò lọ́wọ́ pẹ̀lú.

● Rí i pé ìwà mímọ́ lo ń hù sí àwọn tó jẹ́ ẹ̀yà òdì kejì, ì báà jẹ́ nínú ìdílé tó gbà ọ́ lálejò, ní ilé ẹ̀kọ́, níbi iṣẹ́, tàbí ní àwọn ibòmíràn.

● Ó kéré tán, kọ́ àwọn ọ̀rọ̀ àti gbólóhùn pàtàkì díẹ̀ ní èdè orílẹ̀-èdè tí o ń lọ.

● Lọ ṣe àyẹ̀wò ara rẹ lọ́dọ̀ oníṣègùn kí o tó gbéra. Rí i dájú pé bí o bá nílò oògùn èyíkéyìí, o ní èyí tó pọ̀ tó lọ́wọ́.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Bí èdè àìyédè bá ṣẹlẹ̀ láàárín ìwọ àti ìdílé tó gbà ọ́ lálejò, fi pẹ̀lẹ́tù yanjú rẹ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́