ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 3/15 ojú ìwé 28-30
  • Ta ni Teofilu Ará Antioku?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ta ni Teofilu Ará Antioku?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìtàn Rẹ̀
  • Yíyẹ Àwọn Àkọsílẹ̀ Rẹ̀ Wò
  • Ẹ̀rí Tí Ó Ṣeyebíye
  • Lúùkù—Alábàáṣiṣẹ́pọ̀ Tó Jẹ́ Ẹni Ọ̀wọ́n
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • “Ẹ Ó sì Jẹ́ Ẹlẹ́rìí Mi”
    “Jẹ́rìí Kúnnákúnná Nípa Ìjọba Ọlọ́run”
  • Inúnibíni Mú Kí Ìbísí Ya Wọlé ní Áńtíókù
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Ǹjẹ́ O Rántí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 3/15 ojú ìwé 28-30

Ta ni Teofilu Ará Antioku?

“ẸPÈ mí ní Kristian, bí ẹni pé orúkọ búburú ni, ní tèmi, mo gbà láìtijú, pé Kristian ni mí, mo sì ń jẹ́ orúkọ yìí láti lè di àyànfẹ́ Ọlọrun, ní ríretí láti wúlò fún Ọlọrun.”

Báyìí ni Teofilu ṣe bẹ̀rẹ̀ iwé alápá mẹ́ta rẹ̀ tí ó pè ní Theophilus to Autolycus. Ó jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ìgbèjà rẹ̀ lòdì sí ìpẹ̀yìndà ọ̀rúndún kejì. Teofilu fi tìgboyàtigboyà fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí ọmọlẹ́yìn Kristi. Ó dà bíi pé, ó pinnu láti darí àwọn àlámọ̀rí rẹ̀ kí ó baà lè di “àyànfẹ́ Ọlọrun,” ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí orúkọ rẹ̀ ní èdè Gíríìkì túmọ̀ sí. Ṣùgbọ́n ta ni Teofilu? Níbo ni ó gbé? Kí sì ni ó ṣe yọrí?

Ìtàn Rẹ̀

A kò mọ púpọ̀ nípa ìtàn Teofilu. Àwọn òbí tí kì í ṣe Kristian ni ó tọ́ ọ dàgbà. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, Teofilu di Kristian, ṣùgbọ́n ó jẹ́ kìkì lẹ́yìn tí ó ti fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́. Ó di bíṣọ́ọ̀bù ìjọ Antioku ti Syria, tí a mọ̀ sí Antakya lónìí, ní Turkey.

Ní ìbámu pẹ̀lú àṣẹ Jesu, àwọn Kristian ọ̀rúndún kìíní wàásù láàárín àwọn ará Antioku. Luku ṣàkọsílẹ̀ àṣeyọrí wọn, ní sísọ pé: “Ọwọ́ Jehofa wà pẹlu wọn, ọ̀pọ̀lọpọ̀ iye awọn tí ó di onígbàgbọ́ sì yípadà sọ́dọ̀ Oluwa.” (Ìṣe 11:20, 21) Gẹ́gẹ́ bí a ti darí rẹ̀ látọ̀runwá, àwọn ọmọlẹ́yìn Jesu Kristi ni a wá mọ̀ sí Kristian. Antioku ti Siria ni a ti kọ́kọ́ lo orúkọ yìí. (Ìṣe 11:26) Ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa, aposteli Paulu rin ìrìn àjò lọ sí Antioku ti Siria, ó sì fi ibẹ̀ ṣe ilé. Barnaba àti Paulu, tí Johannu Marku tẹ̀ lé, bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò míṣọ́nnárì wọn àkọ́kọ́ ní Antioku.

Ìbẹ̀wò tí àwọn aposteli ṣe sí ìlú wọn ti gbọ́dọ̀ fún àwọn Kristian ìjímìjí ní Antioku níṣìírí lọ́pọ̀lọpọ̀. Kò sí iyè méjì pé, lápá kan, ìdáhùnpadà onítara ọkàn wọn sí òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun jẹ́ nítorí àwọn ìbẹ̀wò afúngbàgbọ́lókun tí àwọn aṣojú ẹgbẹ́ olùṣàkóso ní ọ̀rúndún kìíní ṣe. (Ìṣe 11:22, 23) Ẹ wo bí yóò ti fún wọn níṣìírí tó láti rí ọ̀pọ̀ àwọn olùgbé Antioku tí wọ́n ya ìgbésí ayé wọn sí mímọ́ fún Jehofa Ọlọrun! Ṣùgbọ́n, ó lé ní 100 ọdún lẹ́yìn náà kí Teofilu tó gbé ní Antioku.

Òpìtàn náà, Eusebius, sọ pé Teofilu ni bíṣọ́ọ̀bù kẹfà ní Antioku, tí a bá bẹ̀rẹ̀ sí í kà á láti ìgbà àwọn aposteli Kristi. Teofilu ṣàkọsílẹ̀ ọ̀pọ̀ ìjíròrò àtẹnudẹ́nu àti àtakò lòdì sí àdámọ̀. Ó wà lára àwọn méjìlá tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tí wọ́n jẹ́ agbèjà ìgbàgbọ́ Kristian ní ọjọ́ rẹ̀.

Yíyẹ Àwọn Àkọsílẹ̀ Rẹ̀ Wò

Ní dídáhùn padà sí ìjíròrò ìṣáájú, Teofilu kọ̀wé sí kèfèrí Autolycus pẹ̀lú àwọn ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: “Ẹnu dídùn àti ọ̀rọ̀ dídùn ń gbádùn mọ́ni, irú ọ̀rọ̀ ìyìn bẹ́ẹ̀ bí ògo asán ń dùn mọ́ àwọn ẹni òṣì tí a ti ba ìrònú wọn jẹ́.” Teofilu ṣàlàyé, ní sísọ pé: “Olùfẹ́ òtítọ́ kì í kọbi ara sí àwọn ọ̀rọ̀ dídùn, ṣùgbọ́n, ó máa ń yẹ kókó ọ̀rọ̀ náà wò . . . ó ti fi ọ̀rọ̀ asán gbéjà kò mí, ní fífi àwọn ọlọrun igi àti òkúta rẹ gbéra ga, ọlọrun tí a kàn, tí a gbẹ́, tí a sì fín, tí kò lè ríran tàbí gbọ́ràn, nítorí ère ni wọ́n, àti iṣẹ́ ọwọ́ ènìyàn.”—Fi wé Orin Dafidi 115:4-8.

Teofilu tú àṣírí ẹ̀tàn ìbọ̀rìṣà. Nínú ọ̀nà ìkọ̀wé rẹ̀ tí ó sọ di àṣà, lọ́nà dídán mọ́rán, bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tilẹ̀ pọ̀ jù, ó sakun láti sọ bí Ọlọrun ṣe rí gan-an. Ó ṣàlàyé pé: “Ìrísí Ọlọrun kò ṣeé fẹnu sọ, kò sì ṣeé ṣàpèjúwe, ojú ìyójú kò sì lè rí i. Nítorí nínú ògo Òun kò ṣeé lóye, nínú ìtóbilọ́lá kò ṣeé finú mòye, ní ti ipò kò ṣeé finú rò, ní ti agbára kò láfiwé, ní ti ọgbọ́n kò lójúgbà, ní ti ìwà rere kò sí ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, ní ti inú rere kò ṣeé fẹnu sọ.”

Ní àfikún sí àpèjúwe yìí nípa Ọlọrun, Teofilu ń bá a nìṣó pé: “Ṣùgbọ́n òun ni Oluwa, nítorí pé Ó ń ṣàkóso lórí àgbáyé; Bàbá, nítorí pé ó wà ṣáájú ohun gbogbo; Olùpète àti Olùṣẹ̀dá, nítorí pé Òun ni ẹlẹ́dàá àti olùṣẹ̀dá àgbáyé; Ẹni Gíga Jù Lọ, nítorí pé Ó ga ju ẹni gbogbo lọ; àti Olodumare, nítorí pé Òun Fúnra Rẹ̀ ń ṣàkóso gbogbo ẹ̀dá, ó sì kó wọn mọ́ra.”

Lẹ́yìn èyí, ní dídarí àfiyèsí sí àwọn àṣeparí kan pàtó tí Ọlọrun ṣe, Teofilu ń bá a lọ ní ọ̀nà sísọ̀rọ̀ kúná àti ti ṣíṣe àtúnwí, ní sísọ pé: “Nítorí àwọn ọ̀run jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ Rẹ̀, ilẹ̀ ayé jẹ́ ìṣẹ̀dá Rẹ̀, òkun jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ Rẹ̀; ènìyàn jẹ́ iṣẹ́ Rẹ̀ àti àwòrán Rẹ̀; oòrùn, òṣùpá, àti ìràwọ̀ jẹ́ ìṣẹ̀dá Rẹ̀, tí ó ṣe fún àmì, àti ìgbà, àti ọjọ́, àti ọdún, kí wọ́n baà lè ṣiṣẹ́ sin ènìyàn, kí wọ́n sì jẹ́ ẹrú fún un; Ọlọrun sì dá ohun gbogbo láti inú àwọn ohun tí kò sí, sí àwọn ohun tí ó wà, kí a baà lè tipasẹ̀ iṣẹ́ ọwọ́ Rẹ̀ mọ ìtóbilọ́lá Rẹ̀, kí a sì lóye wọn.”

Àpẹẹrẹ àtakò míràn tí Teofilu gbé dìde sí àwọn ọlọrun èké ọjọ́ rẹ̀ ni a rí nínú àwọn ọ̀rọ̀ tí ó tẹ̀ lé e wọ̀nyí sí Autolycus pé: “Orúkọ àwọn tí o sọ pé ò ń jọ́sìn, jẹ́ orúkọ àwọn òkú ènìyàn. . . . Irú ènìyàn wo sì ni wọ́n jẹ́? A kò ha rí i pé Saturn jẹ́ ajẹ̀nìyàn, tí ń pa àwọn ọmọ ara rẹ̀, tí ó sì ń jẹ wọ́n bí? Bí o bá sì sọ ọmọ rẹ̀ ní Jupiter, . . . bí ó ṣe mu ọmú ewúrẹ́ . . . Àti àwọn ìṣe rẹ̀ míràn,—bíbá ìbátan ẹni lòpọ̀, àti ìwà panṣágà, àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀.”

Nígbà tí ó ń tẹ̀ síwájú nínú ìjiyàn rẹ̀, Teofilu túbọ̀ fìdí àtakò rẹ̀ lòdì sí ìbọ̀rìṣà kèfèrí múlẹ̀. Ó kọ̀wé pé: “O ha yẹ kí n tún máa rán ọ létí ògìdìgbó ẹranko tí àwọn ará Egipti ń jọ́sìn bí, àwọn ẹran afàyàfà, àti màlúù, àti ẹranko ẹhànnà, àti ẹyẹ, àti ẹja odò . . . Àwọn Gíríìkì àti àwọn orílẹ̀-èdè míràn, wọ́n ń jọ́sìn òkúta àti igi, àti irú àwọn nǹkan mìíràn tí ó ṣeé fojú rí.” Teofilu polongo pé: “Ṣùgbọ́n Ọlọrun, Ọlọrun tòótọ́ tí ń bẹ láàyè, ni èmí ń jọ́sìn.”—Fi wé 2 Samueli 22:47; Ìṣe 14:15; Romu 1:22, 23.

Ẹ̀rí Tí Ó Ṣeyebíye

Àwọn ọ̀rọ̀ ìṣílétí àti ọ̀rọ̀ ìyànjú tí ń bẹ nínú ìwé alápá mẹ́ta tí Teofilu kọ, tí ó fi mú Autolycus ní elékèé jẹ́ alápá púpọ̀, ó sì kún fún ìsọfúnni. Àwọn ìwé mìíràn tí Teofilu kọ ni a darí rẹ̀ lòdì sí Hermogenes àti Marcion. Ó tún kọ àwọn ìwé onítọ̀ọ́ni àti agbéniró, ní kíkọ àwọn àlàyé kún àwọn ìwé Ìròyìn Rere. Ṣùgbọ́n, kìkì àwọn ìwé mẹ́ta sí Autolycus, ìwé àfọwọ́kọ kan ṣoṣo, ní a tọ́jú.

Ìwé àkọ́kọ́ ni lẹ́tà ẹ̀bẹ̀ tí ó kọ sí Autolycus ní ìgbèjà ìsìn Kristian. Ìwé kejì sí Autolycus jiyàn lòdì sí ìsìn, ìméfò, àwọn ọlọ́gbọ́n èrò orí, àti àwọn akéwì abọgibọ̀pẹ̀, tí wọ́n gbajúmọ̀. Nínú ìwé kẹta tí Teofilu kọ, a fi ìwé àwọn abọgibọ̀pẹ̀ wéra pẹ̀lú Ìwé Mímọ́.

Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìwé Teofilu kẹta, ó dájú pé Autolycus ṣì ní èrò náà pé, Ọ̀rọ̀ òtítọ́ jẹ́ ìtàn àròsọ. Teofilu ṣe lámèyítọ́ Autolycus, ní sísọ pé: “O fi tayọ̀tayọ̀ fara mọ́ àwọn òmùgọ̀. Bí kì í bá ṣe bẹ́ẹ̀, a kì bá ti sún ọ láti gba òfìfo ọ̀rọ̀ àwọn aláìnírònú ènìyàn gbọ́, kí o sì gbóṣùbà fún ọ̀rọ̀ àhesọ tí ó gbòde kan.”

Kí ni “ọ̀rọ̀ àhesọ tí ó gbòde kan”? Teofilu ṣí orísun rẹ̀ payá. Àwọn abanijẹ́ “tí wọ́n ní ètè èké, ń fẹ̀sùn kan [àwa] tí a jẹ́ olùjọsìn Ọlọrun, tí a sì ń pè ní Kristian, pé a ń fi aya ara wa ṣe pàṣípààrọ̀ fún ète ìbálòpọ̀; àti pé a tún ń ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú àbúrò tàbí ẹ̀gbọ́n wa obìnrin, èyí tí ó tilẹ̀ tàbùkù, tí ó sì burú jù lọ ni pé, a ń jẹ ẹran ara ènìyàn.” Teofilu tiraka láti gbéjà ko ojú ìwòye àwọn kèfèrí tí kò péye rárá yìí nípa àwọn tí wọ́n sọ pé àwọn jẹ́ Kristian ní ọ̀rúndún kejì. Ó lo ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ tí ń bẹ nínú Ọ̀rọ̀ tí Ọlọrun mí sí.—Matteu 5:11, 12.

Ẹ̀rí pé Teofilu mọ tinútòde Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ni a rí nínú bí ó ṣe ń lo àwọn ẹsẹ Bibeli tí a kọ lédè Heberu àti Gíríìkì nígbà gbogbo àti bí ó ṣe ń tọ́ka sí wọn. Ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn tí wọ́n ṣáájú lára àwọn alálàyé lórí àwọn ìwé Ìròyìn Rere. Àwọn ọ̀pọ̀ ìtọ́kasí tí Teofilu ṣe sí Ìwé Mímọ́ pèsè òye inú yanturu sínú ìrònú tí ó gbòde kan nígbà ayé rẹ̀. Ó lo bí ó ṣe mọ tinútẹ̀yìn àwọn àkọsílẹ̀ onímìísí tó láti gbé bí wọ́n ṣe ga lọ́nà gíga lọ́lá ju ọgbọ́n èrò orí kèfèrí lọ jáde.

Ìṣètò àwọn ìwé Teofilu, ọ̀nà ìkọ̀wé rẹ̀ tí a pète láti kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ àti ọ̀nà ìgbàsọ̀rọ̀ ní àsọtúnsọ rẹ̀ lè fi ohun kan tí a lè nífẹ̀ẹ́ ọkàn sí sọ́kàn àwọn kan. A kò lè sọ ní báyìí, bí ìpẹ̀yìndá tí a ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ṣe nípa lórí ìpéye ojú ìwòye rẹ̀ tó. (2 Tessalonika 2:3-12) Síbẹ̀síbẹ̀, nígbà tí yóò fi kú, ní nǹkan bí ọdún 182 Sànmánì Tiwa, ó hàn kedere pé, Teofilu ti di aláìṣàárẹ̀ agbèjà ìgbàgbọ́, ẹni tí àwọn ojúlówó Kristian sànmánì òde òní nífẹ̀ẹ́ ọkàn sí àwọn ìwé rẹ̀.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]

Teofilu fi tìgboyàtìgboyà fihàn pé irọ́ ni ìjiyàn Autolycus

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 28]

A mú àwọn àwòrán tí ó wà ní ojú ewé 28 àti 30 jáde láti inú Illustrirte Pracht - Bibel/Heilige Schrift des Alten und Neuen Testaments, nach der deutschen Uebersetzung D. Martin Luther’s

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́