Ǹjẹ́ O Rántí?
Ǹjẹ́ o gbádùn kíka àwọn Ilé Ìṣọ́ tó jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, wò ó bóyá wàá lè dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí:
• Kí nìdí tí ọ̀rọ̀ inú “Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù” fi jẹ́ èyí tó wúlò títí ayérayé?
Jèhófà Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ ni Ẹni tó ni Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, kì í ṣe ọlọ́run àìmọ̀ tó jẹ́ òǹrorò. Jésù àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ máa ń fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Àwọn ìmọ̀ràn tó ń ṣeni láǹfààní nígbèésí ayé, tó sì jẹ́ ká ní ìrètí pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa ló wà nínú rẹ̀.—9/1, ojú ìwé 4 sí 7.
• Kí lákòókò tó ti kọjá lẹ́yìn tí Ádámù àti Éfà dẹ́ṣẹ̀ ti fi hàn?
Àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ láti ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́fà [6,000] ọdún sẹ́yìn ti fi hàn pé òpùrọ́ ni Sátánì. Ìdí ni pé Ádámù, Éfà àti àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn àtọmọdọ́mọ wọn ti kú. Àkókò tó kọjá yìí ti fi hàn pé nǹkan ò lè dáa fáwọn èèyàn tí wọn ò bá fi ti Ọlọ́run ṣe, àti pé wọn ò ní ẹ̀tọ́ tàbí agbára láti darí ìṣísẹ̀ ara wọn.—9/15, ojú ìwé 6 àti 7.
• Kí nìdí tí wọn ò fi dá Jékọ́bù lẹ́bi nígbà tó pe ara rẹ̀ ní Ísọ̀?
Jékọ́bù lẹ́tọ̀ọ́ láti gba ìre lẹ́nu bàbá rẹ̀, nítorí ó ti fi ẹ̀tọ́ ra ipò àkọ́bí lọ́wọ́ Ísọ̀. Nígbà tí Ísákì mọ̀ pé Jékọ́bù lòun súre fún, kò wá ọ̀nà láti yí ìre náà padà. Ọlọ́run tí ì bá sì tún dá sí ọ̀rọ̀ náà fẹ́ kí ìre náà jẹ́ ti Jékọ́bù.—10/1, ojú ìwé 31.
• Ọ̀nà wo ni ẹ̀rí ọkàn táwa èèyàn ní gbà fi hàn pé kì í ṣe nípa ẹfolúṣọ̀n lèèyàn fi wà?
Káàkiri gbogbo ìran àti onírúurú ẹ̀yà la ti ráwọn èèyàn tó máa ń fẹ́ ṣèrànlọ́wọ́ fáwọn ẹlòmíì láìwo ti pé irú ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀ lè kó wàhálà bá àwọn. A ò ní retí irú ìwà àìmọtara-ẹni-nìkan bẹ́ẹ̀ látọ̀dọ̀ èèyàn ká sọ pé ẹranko lásán tó ń wá ohun tó máa jẹ kiri lèèyàn.—10/15, ojú ìwé 20.
• Kí nìdí tá a fi lè sọ pé Ọlọ́run ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, ọ̀nà wo ló sì gbà fi ànímọ́ yìí hàn?
Níwọ̀n bí Ọlọ́run ti jẹ́ Ọba Aláṣẹ àti Ẹlẹ́dàá wa, a ò lè fi agbára rẹ̀ wé tàwa èèyàn. Síbẹ̀ níbàámu pẹ̀lú 2 Sámúẹ́lì 22:36, Ọlọ́run ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ní ti pé ó bìkítà gan-an nípa àwọn ẹni rírẹlẹ̀ tí wọ́n ń sapá láti ṣe ohun tó wù ú, ó sì máa ń fi àánú hàn sí wọn. Ọlọ́run rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, kó bàa lè fìfẹ́ bá àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀ lò.—11/1, ojú ìwé 4 àti 5.
• Báwo làwọn àpáàdì ayé ìgbàanì ṣe kín ọ̀rọ̀ inú Bíbélì lẹ́yìn?
Àwọn awalẹ̀pìtàn ti rí àwọn àpáàdì kan ní Samáríà tí méje nínú orúkọ àwọn agbo ìdílé tó wà nínú Jóṣúà 17: 1-6 wà lára wọn. Àwọn àpáàdì tí wọ́n rí ní Árádì kín ohun tí Bíbélì sọ nípa ìdílé àwọn àlùfáà lẹ́yìn, orúkọ Ọlọ́run sì tún wà lára àwọn àpáàdì náà. Àwọn àpáàdì tí wọ́n wú ní Lákíṣì fi ipò tí àkóso ilẹ̀ Júdà wà hàn àti pákáǹleke tó bá àwọn ará ibẹ̀ ṣáájú kí Bábílónì tó wá kógun ja ilẹ̀ Júdà.—11/15, ojú ìwé 12 sí 14.
• Kí lò jẹ́ ká gbà pé Lúùkù ló kọ ìwé Ìṣe?
Tìófílọ́sì tí Lúùkù kọ ìwé Ìhìn Rere Lúùkù sí náà ni wọ́n kọ ìwé Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì sí, nítorí náà, ó ní láti jẹ́ pé Lúùkù ló kọ ìwé méjèèjì tí Ọlọ́run mí sí wọ̀nyẹn. Ọ̀rọ̀ arọ́pò orúkọ bí “a,” “àwa” àti “wa” tí wọ́n lò láwọn ibì kan, fi hàn pé Lúùkù kópa nínú àwọn kan lára ohun tí ìwé Ìṣe sọ pé ó ṣẹlẹ̀. (Ìṣe 16:8-15 )—11/15, ojú ìwé 18.
• Ojú wo ló yẹ káwọn Kristẹni fi wo iṣẹ́ ọdẹ àti iṣẹ́ ẹja pípa?
Láti ìgbà ayé Nóà ni Ọlọ́run ti fàyè gba àwọn èèyàn láti máa pa ẹran jẹ. Síbẹ̀, àṣẹ náà pé kí wọ́n máa ro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ dà nù jẹ́ ká túbọ̀ rí i pé ó yẹ ká ka ìwàláàyè ẹran sí ohun pàtàkì tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ìdí nìyẹn táwọn Kristẹni kò fi gbọ́dọ̀ pa ẹran fún eré ìdárayá, kí wọ́n máa dọdẹ wọn kiri tàbí kí wọ́n máa pa wọ́n fún ìgbádùn lásán. Ó ṣe pàtàkì pé ká máa pa òfin Késárì mọ́, ká má sì ṣe ohun táá pa ẹ̀rí ọkàn àwọn ẹlòmíì lára. (Róòmù 14:13)—12/1, ojú ìwé 31.