-
Ṣó Ti Yẹ Kí N Lẹ́ni Tí Mò Ń Fẹ́?Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
-
-
ORÍ 1
Ṣó Ti Yẹ Kí N Lẹ́ni Tí Mò Ń Fẹ́?
“Kò síbi tí mo yíjú sí tí mi ò ti ń rí àwọn nǹkan tó ń jẹ́ kó máa wù mí ṣáá láti lẹ́ni tí mò ń fẹ́. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, àwọn ọmọkùnrin tó dáa pọ̀ bí ilẹ̀ bí ẹní.”—Whitney.
“Àwọn ọmọbìnrin kì í fi mí lọ́rùn sílẹ̀, mi ò sì fẹ́ sọ pé mi ò ṣe. Àmọ́ tí mo bá bi àwọn òbí mi pé kí ni wọ́n rí sí i, mo mọ nǹkan tí wọ́n máa sọ.”—Phillip.
Ó SÁBÀ máa ń wùùyàn láti ní olólùfẹ́, kódà nígbà téèyàn wà ní kékeré. Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Jenifer sọ pé: “Mi ò tíì ju ọmọ ọdún mọ́kànlá lọ tó ti ń wù mí pé kí n lẹ́ni tí mò ń fẹ́.” Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Brittany náà sọ pé: “Bó o bá wà níléèwé, tí o ò sì lẹ́ni tó ò ń fẹ́, ńṣe ló máa dà bíi pé o ò dákan mọ̀!”
Ṣé bó ṣe ń ṣe ìwọ náà nìyẹn? Ṣó yẹ kó o ti lẹ́ni tí wàá máa fẹ́? Ká tó lè dáhùn ìbéèrè yìí, ó yẹ ká kọ́kọ́ dáhùn ìbéèrè kan tó ṣe pàtàkì jù:
Kí Ni “Ìfẹ́sọ́nà”?
Fàmì sí ohun tó o rò pé ó yẹ kó jẹ́ ìdáhùn sáwọn ìbéèrè wọ̀nyí:
Bí ìgbín bá fà ìkarahun a tẹ̀ lé e lọ̀rọ̀ ìwọ àti ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin kan. Ṣé ẹ ti ń fẹ́ra yín sọ́nà nìyẹn?
□ Bẹ́ẹ̀ ni
□ Rárá
Ìwọ àti ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin kan nífẹ̀ẹ́ ara yín gan-an, ọ̀pọ̀ ìgbà lójúmọ́ lo sì máa ń kọ̀wé ránṣẹ́ sórí fóònù ẹ̀ tàbí kó o fi fóònù pè é. Ṣẹ́ ẹ ti ń fẹ́ra yín sọ́nà nìyẹn?
□ Bẹ́ẹ̀ ni
□ Rárá
Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ìgbà tíwọ àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ bá ń ṣe fàájì, ó ní bọ̀bọ́ kan tàbí ọmọge kan tíwọ àti ẹ̀ sábà máa ń dá sọ̀rọ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ kan. Ṣẹ́ ẹ ti ń fẹ́ra yín sọ́nà nìyẹn?
□ Bẹ́ẹ̀ ni
□ Rárá
Ó lè má ṣòro fún ẹ láti dáhùn ìbéèrè àkọ́kọ́. Àmọ́ o ti ní láti ronú díẹ̀ lórí ìbéèrè kejì àti ìkẹta kó o tó lè dáhùn wọn. Kí ni ìfẹ́sọ́nà gan-an? Láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ́, bí ohunkóhun bá ti ń pa ìwọ àti ẹnì kan pọ̀, tọ́kàn rẹ ń fà sí onítọ̀hún, tónítọ̀hún náà sì nífẹ̀ẹ́ rẹ dọ́kàn, ẹ ti ń fẹ́ra yín sọ́nà nìyẹn. Èyí fi hàn pé bẹ́ẹ̀ ni ni ìdáhùn tó tọ̀nà sáwọn ìbéèrè mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Yálà lórí fóònù tàbí lójúkojú, lójú táyé tàbí ní bòókẹ́lẹ́, tíwọ àti ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin kan bá ṣáà ti lè ní ìfẹ́ tó ju ti ọ̀rẹ́ lásán lọ síra yín, tẹ́ ẹ sì ń bára yín sọ̀rọ̀ lọ́pọ̀ ìgbà, a jẹ́ pé ẹ ti ń fẹ́ra yín sọ́nà nìyẹn. Ṣó o wá rò pé o ti ṣe tán láti bẹ̀rẹ̀ sí fẹ́ ẹnì kan sọ́nà báyìí? Bó o bá gbé àwọn ìbéèrè mẹ́ta tá a máa jíròrò báyìí yẹ̀ wò, wàá lè dáhùn ìbéèrè yẹn.
Kí Nìdí Tó O Fi Fẹ́ Lẹ́ni Tí Wàá Fẹ́?
Ọ̀pọ̀ èèyàn làṣà ìlú wọn fàyè gba kí ọkùnrin àti obìnrin máa fẹ́ra wọn sọ́nà, torí pé ọ̀nà táwọn méjèèjì lè gbà mọwọ́ ara wọn nìyẹn. Àmọ́, ó yẹ kó nídìí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ tí ọkùnrin àti obìnrin á fi máa fẹ́ra wọn sọ́nà, ìyẹn sì ni láti mọ̀ bóyá àwọn méjèèjì á lè bára wọn kalẹ́ bí wọ́n bá gbéra wọn níyàwó.
Òótọ́ ni pé, àwọn ọ̀dọ́ kan ò ka fífẹ́ ara wọn sọ́nà sí nǹkan bàbàrà. Bóyá ńṣe ló kàn máa ń wù wọ́n láti máa wà lọ́dọ̀ ẹnì kan tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tiwọn, àmọ́ tí kò sí lọ́kàn wọn láti fẹ́ onítọ̀hún. Àwọn kan tiẹ̀ lè máa wo wíwà pẹ̀lú ọ̀rẹ́bìnrin tàbí ọ̀rẹ́kùnrin tí wọ́n fẹ́ láti máa wà lọ́dọ̀ ẹ̀ yẹn bí àpẹẹrẹ pé àwọn náà ti tẹ́gbẹ́, tàbí bí ohun tó ń mú káwọn máa gbayì láwùjọ. Àmọ́, lọ́pọ̀ ìgbà irú yíyan ara ẹni lọ́rẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀ kì í tọ́jọ́. Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Heather sọ pé: “Ọ̀pọ̀ lára àwọn ọ̀dọ́ tó ń fẹ́ra wọn sọ́nà ló ń fira wọn sílẹ̀ láàárín ọ̀sẹ̀ kan sí méjì tí wọ́n pàdé ara wọn. Wọ́n ti sọ àjọṣe tó wà láàárín wọn di ọsàn téèyàn lè mu kó sì sọ nù bí kò bá wù ú mu mọ́, ìyẹn sì ti jẹ́ kí wọ́n máa fi ìkọ̀sílẹ̀ kọ́ra dípò ìgbéyàwó.”
Kò sí àníàní pé bó o bá ti ń fẹ́ ẹnì kan sọ́nà, o ti ń nípa lórí bí nǹkan ṣe ń rí lára onítọ̀hún. Nítorí náà, rí i dájú pé o nídìí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ tó mú kó o máa fẹ́ ẹ sọ́nà. Rò ó wò ná: Ṣé wàá fẹ́ kẹ́nì kan sọ ìmọ̀lára ẹ di ìṣeré ọmọdé, téèyàn lè fi ṣeré fúngbà díẹ̀ kó sì wá gbé e sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan tó bá yá? Ọ̀dọ́mọbìnrin kan tó ń jẹ́ Chelsea sọ pé: “Lọ́pọ̀ ìgbà mo máa ń rò pé eré lásán ni kéèyàn máa lọ́kùnrin tàbí obìnrin tó ń fẹ́, àmọ́ kì í ṣe ọ̀rọ̀ eré mọ́ nígbà tẹ́nì kan bá ń ronú nípa ìgbéyàwó tí èkejì ò sì ríyẹn rò rárá.”
Ọmọ Ọdún Mélòó Ni Ẹ́?
Ọmọ ọdún mélòó lo rò pé ó yẹ kéèyàn jẹ́ kó tó lẹ́ni tó ń fẹ́ sọ́nà? ․․․․․
Ó yá, lọ bi Dádì tàbí Mọ́mì, kó o wá kọ ohun tí wọ́n bá sọ síbí yìí. ․․․․․
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọjọ́ orí tí ìwọ rò pé ó dáa kéèyàn ti máa fẹ́ ẹnì kan sọ́nà kéré sí èyí táwọn òbí ẹ sọ. Ó sì lè máà rí bẹ́ẹ̀! Bí kò bá rí bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé o wà lára àwọn ọ̀dọ́ tó gbọ́n débi pé wọ́n fẹ́ mọ ara wọn dunjú kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí fẹ́ ẹnì kan sọ́nà. Ohun tí ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17] kan tó ń jẹ́ Danielle pinnu láti ṣe náà nìyẹn, ó ní: “Nígbà tí mo wo bó ṣe ń ṣe mí lọ́dún méjì sẹ́yìn, mo rí i pé ohun tí mo máa rí lára ọkùnrin tí màá fi gbà fún un ti yàtọ̀ gan-an báyìí. Kódà, ní báyìí pàápàá, mi ò rò pé ó tíì yá mi láti ṣe irú ìpinnu bẹ́ẹ̀. Àmọ́, tí mo bá rí i pé fún nǹkan bí ọdún mélòó kan ohun tó ń wù mí lára ọkùnrin ò yí pa dà, mo lè wá bẹ̀rẹ̀ sí í ronú lórí wíwá ẹni tí màá fẹ́.”
Ìdí tó tún fi bọ́gbọ́n mu pé kó o dúró díẹ̀ rèé: Bíbélì lo ọ̀rọ̀ náà “ìgbà ìtànná òdòdó èwe” láti ṣàpèjúwe ìgbà téèyàn máa ń fẹ́ láti ní ìbálòpọ̀ ṣáá, tí ìfẹ́ ọkàn láti máa fara ro ẹni tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tèèyàn sì máa ń lágbára gan-an. (1 Kọ́ríńtì 7:36) Bó o bá ti wá lọ lẹ́ni tó ò ń fẹ́ nígbà tó o ṣì wà ní “ìgbà ìtànná òdòdó èwe,” ó lè mú kó o ṣìwà hù. Lóòótọ́, ìyẹn lè máà jẹ́ nǹkan bàbàrà lójú àwọn ojúgbà rẹ, torí púpọ̀ nínú wọn ló máa ń fẹ́ tètè mọ bí ìbálòpọ̀ ṣe ń rí lára. Àmọ́, o lè mú irú ìrònú yẹn kúrò lọ́kàn, kó o sì fìyẹn jù wọ́n lọ! (Róòmù 12:2) Bíbélì ṣáà gbà ẹ́ níyànjú pé kó o “sá fún àgbèrè.” (1 Kọ́ríńtì 6:18) Bó o bá dúró dìgbà tí ìfẹ́ láti ní ìbálòpọ̀ ò bá mu ẹ́ lómi tó bẹ́ẹ̀ mọ́, wàá lè “mú ibi kúrò [lórí] ara rẹ.”—Oníwàásù 11:10, Bibeli Ajuwe.
Ṣó O Ti Ṣe Tán Láti Ṣègbéyàwó?
Kó o tó dáhùn ìbéèrè yìí, kọ́kọ́ yẹ ara ẹ wò dáadáa. Àwọn ohun tó yẹ kó o gbé yẹ̀ wò rèé:
Bó o ṣe ń ṣe sáwọn èèyàn. Báwo lo ṣe ń ṣe sí Dádì àti Mọ́mì, àtàwọn ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò rẹ? Ṣó o mọ béèyàn ṣe ń ṣọ́ ọ̀rọ̀ sọ àbí ńṣe lo máa ń fagídí sọ̀rọ̀ tó o sì máa ń lo àwọn èdè rírùn láti sọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ? Kí lo rò pé wọ́n máa sọ nípa ẹ? Bó o bá ṣe ń ṣe sáwọn ará ilé ẹ náà lo ṣe máa ṣe sẹ́ni tó o bá fẹ́.—Ka Éfésù 4:31.
Ìwà ẹ. Ṣó o sábà máa ń lẹ́mìí pé nǹkan máa dáa àbí gbogbo nǹkan ni kì í dáa lójú ẹ? Ṣó o máa ń gba tẹlòmíì rò, àbí tìẹ lo máa ń fẹ́ ṣe ṣáá? Ṣó o máa ń fara balẹ̀ tí wàhálà bá ṣẹlẹ̀? Ṣó o máa ń ní sùúrù? Bó o bá fi èso ti ẹ̀mí Ọlọ́run ṣèwà hu nísinsìnyí, á ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti di aya tàbí ọkọ tó dáńgájíá.—Ka Gálátíà 5:22, 23.
Ṣíṣọ́ owó ná. Ṣó o mọ béèyàn ṣe ń ṣọ́ owó ná? Ṣó o sábà máa ń jẹ gbèsè? Ṣé tó o bá ríṣẹ́ kì í tètè bọ́ mọ́ ẹ lọ́wọ́? Tó bá máa ń tètè bọ́ mọ́ ẹ lọ́wọ́, kí ló máa ń fà á? Ṣé iṣẹ́ yẹn ò dáa tó ni àbí àwọn tó gbà ẹ́ síṣẹ́ ni ò ṣe ẹ́ dáadáa? Ṣé ìwà tàbí ohun kan tó yẹ kó o ṣiṣẹ́ lé lórí ló ń jẹ́ kí wọ́n máa dá ẹ dúró níbi iṣẹ́? Tó ò bá mọ béèyàn ṣe ń ṣọ́ owó ná, báwo ni wàá ṣe lè gbọ́ bùkátà ìdílé?—Ka 1 Tímótì 5:8.
Àjọṣe rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run. Tó bá jẹ́ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ẹ́, àwọn ànímọ́ wo lo ní nípa tẹ̀mí? Ṣó o máa ń wáyè ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ṣé wọn kì í rán ẹ létí kó o tó lọ sóde ẹ̀rí, ṣé wọn kì í sì í tì ẹ́ lọ sáwọn ìpàdé Kristẹni? Ẹni tó o máa fẹ́ nílò ẹni tó tóótun tó sì wà lójúfò nípa tẹ̀mí.—Ka Oníwàásù 4:9, 10.
Ohun Tó O Lè Ṣe
Bó bá ń wù ẹ́ láti lẹ́ni tí wàá máa fẹ́ sọ́nà nígbà tí kò tíì yá ẹ láti ṣègbéyàwó, ńṣe ló máa dà bí ìgbà tó o fẹ́ fi agídí ṣèdánwò àṣekágbá ilé ẹ̀kọ́ girama nígbà tó o ṣì wà níléèwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀. Ó dájú pé ìyẹn ò dáa tó! Ó di dandan kó o wáyè láti mọ àwọn ẹ̀kọ́ tí wọ́n ń kọ́ni nílé ẹ̀kọ́ girama, kó o lè mọ ohun tó o máa bá pàdé nínú ìdánwò ọ̀hún.
Bọ́ràn fífẹ́ra ẹni sọ́nà ṣe rí gan-an nìyẹn. Bá a ṣe sọ lókè, fífẹ́ra ẹni sọ́nà kì í ṣe ọ̀ràn eré. Torí náà kó o tó tọrùn bọ̀ ọ́, o ní láti mọ ẹ̀kọ́ pàtàkì kan dunjú, ìyẹn béèyàn ṣe ń báni dọ́rẹ̀ẹ́. Bó o bá sì wá rẹ́ni tó tẹ́ ẹ lọ́rùn, wàá lè mọ bó o ṣe lè máa ṣe sí i, kẹ́ ẹ lè dọ̀rẹ́ ara yín. Ó ṣe tán, bí tọkọtaya bá jẹ́ ọ̀rẹ́ ara wọn, ìgbéyàwó wọn á dùn bí oyin.
Má ṣe rò pé o máa léélẹ̀ tó ò bá tètè lẹ́ni tí wàá fẹ́. Ká sòótọ́, ìgbà tó ò bá tíì lẹ́ni tó ò ń fẹ́ gan-an lo máa lómìnira tó pọ̀ jù láti ‘yọ̀ ní ìgbà èwe rẹ.’ (Oníwàásù 11:9) Ìgbà yẹn gan-an lo sì máa ráyè tún ìwà ẹ ṣe, tí wàá sì lè mú kí àjọsẹ rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run dán mọ́rán sí i.—Ìdárò 3:27.
Ní báyìí, o lè gbádùn àjọṣe tó dáa pẹ̀lú ẹni tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tìẹ. Báwo lo ṣe lè ṣe é? Ọ̀nà tó dáa jù ni pé kẹ́ ẹ jọ wa pa pọ̀ láàárín àwọn ọ̀rẹ́ níbi táwọn àgbàlagbà wà. Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Tammy sọ pé: “Ìyẹn gan-an lodù ẹ̀, ó máa ń dáa kéèyàn lọ́rẹ̀ẹ́ tó pọ̀.” Monica náà ò jiyàn, ó ní: “Pé kéèyàn máa wà láàárín àwọn ọ̀rẹ́ tó pọ̀ dáa gan-an, torí wàá rí ọ̀pọ̀ èèyàn tí ànímọ́ wọn yàtọ̀ síra.”
Àmọ́, tó o bá lọ dójú sọ ẹnì kan nígbà tí kò tíì yá ẹ, ẹ̀dùn ọkàn lo máa kó bára ẹ. Torí náà, fara balẹ̀. Fi àsìkò tó o wà yìí kọ́ béèyàn ṣe ń yan ọ̀rẹ́ tí ò sì ní síjà. Bó bá sì yá ẹ láti ní àfẹ́sọ́nà, wàá ti mọ ara ẹ dunjú, wàá sì ti mọ irú ohun tó o máa fẹ́ lára ẹni tó o fẹ́ fi ṣe aya tàbí ọkọ.
KA PÚPỌ̀ SÍ I NÍPA ÀKÒRÍ YÌÍ NÍ ORÍ 29 ÀTI 30 NÍNÚ APÁ KÌÍNÍ ÌWÉ YÌÍ
Ṣó o ti ń ronú nípa fífẹ́ ẹnì kan sọ́nà láìjẹ́ káwọn òbí ẹ mọ̀? Ó léwu ju bó o ṣe rò lọ o.
ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́
“Afọgbọ́nhùwà máa ń ronú nípa àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.”—Òwe 14:15.
ÌMỌ̀RÀN
Tó o bá fẹ́ múra sílẹ̀ de ìgbà tó o máa bẹ̀rẹ̀ sí fẹ́ ẹnì kan sọ́nà tàbí tó o máa ṣègbéyàwó, ka 2 Pétérù 1:5-7, kó o sì fọkàn sí ànímọ́ kan tó yẹ kó o ṣiṣẹ́ lé lórí. Lẹ́yìn oṣù kan, ṣàyẹ̀wò bó o ṣe mọ ànímọ́ yẹn tó àti bó ṣe hàn nínú ìwà ẹ sí.
ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?
Ọ̀pọ̀ ìwádìí táwọn èèyàn ṣe ti fi hàn pé àwọn tó ṣègbéyàwó láì tíì pé ọmọ ogún [20] ọdún sábà máa ń kọ́ra wọn sílẹ̀ láàárín ọdún márùn-ún tí wọ́n fẹ́ra.
OHUN TÍ MÀÁ ṢE!
Àwọn ànímọ́ tó yẹ kí n ní rèé, tí mo bá fẹ́ múra sílẹ̀ fún ìgbéyàwó: ․․․․․
Àwọn ohun tó lè mú kí n láwọn ànímọ́ yẹn ni pé ․․․․․
Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․
KÍ LÈRÒ Ẹ?
● Àwọn ibo ló ti bójú mu láti wà pẹ̀lú àwọn tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tìẹ?
● Báwo lo ṣe lè bá àbúrò ẹ tó fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ ẹnì kan sọ́nà sọ̀rọ̀ nígbà tó ṣì kéré láti ṣe bẹ́ẹ̀?
● Bó o bá ń fẹ́ ẹnì kan àmọ́ tí kò sí lọ́kàn ẹ láti fẹ̀ ẹ́ tàbí láti jẹ́ kó gbé ẹ sílé, báwo ló ṣe máa rí lára onítọ̀hún?
[Ìsọfúnni tó wà ní ojú ìwé 18]
Èmi rò pé béèyàn bá mọyì ẹnì kan téèyàn sì rí i pé àjọgbé òun àti ẹ̀ máa wọ̀ ló yẹ kéèyàn tó bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ ẹ sọ́nà. Ẹni yẹn ló yẹ kó máa dá ẹ lọ́rùn kì í ṣe àjọṣe tó wà láàárín yín.’’—Amber
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
Bó o bá ń fẹ́ ẹnì kan síbẹ̀ tí kò sí lọ́kàn ẹ láti fi ṣe ọkọ tàbí aya, ńṣe lo dà bí ọmọdé tó ń fi bèbí ṣeré, àmọ́ tó wábi jù ú sí nígbà tó yá
-
-
Kí Ló Burú Nínú Fífẹ́ra Sọ́nà Ní Bòókẹ́lẹ́?Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
-
-
ORÍ 2
Kí Ló Burú Nínú Fífẹ́ra Sọ́nà Ní Bòókẹ́lẹ́?
Jessica ò tiẹ̀ wá mohun tí ì bá ṣe mọ́ báyìí. Jẹ́jẹ́ ẹ̀ ló jókòó tọ́mọ kíláàsì ẹ̀ kan tó ń jẹ́ Jeremy bẹ̀rẹ̀ sí í ta sí i. Jessica fúnra ẹ̀ sọ pé: “Ọmọkùnrin dáa síbẹ̀, àwọn ọ̀rẹ́ mi sì sọ pé èèyàn bíi tiẹ̀ ṣọ̀wọ́n. Ọ̀pọ̀ ọmọbìnrin ti wá bí wọ́n á ṣe bá a da nǹkan pọ̀, àmọ́ kò wojú wọn. Èmi nìkan ló ṣáà lóun fẹ́ràn.”
Kò pẹ́ sígbà tá à ń wí yìí tí Jeremy fi sọ fún Jessica pé kó jẹ́ káwọn máa fẹ́ra. Jessica ṣàlàyé fún un pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà lòun, òun ò sì ní lè fẹ́ ẹni tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Jessica sọ pé: “Jeremy lóun mọ ọgbọ́n tá a máa dá sí i. Ó wá bi mí pé, ‘Bá a bá ń fẹ́ra wa láìjẹ́ káwọn òbí ẹ mọ̀ ńkọ́?’”
BÍ ẸNÌ kan tó gba tìẹ bá dá irú àbá yìí, kí lo máa ṣe? Ó lè yà ẹ́ lẹ́nu láti gbọ́ pé Jessica gbà láti máa fẹ́ Jeremy. Ó ní: “Ó dá mi lójú pé bí èmi àti ẹ̀ bá ń fẹ́ra wa, mo lè sọ ọ́ dẹni tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà.” Ibo lọ̀rọ̀ náà wá já sí o? Ká ṣì máa bọ́rọ̀ bọ̀ ná. Àmọ́, jẹ́ ká kọ́kọ́ wo ohun tó fà á táwọn ọ̀dọ́ kan fi kó sínú pańpẹ́ fífẹ́ ara wọn sọ́nà ní bòókẹ́lẹ́.
Ìdí Táwọn Kan Fi Ń Ṣe É
Kí nìdí táwọn kan fi ń fẹ́ra wọn sọ́nà ní bòókẹ́lẹ́? Ọ̀dọ́mọkùnrin kan tó ń jẹ́ David dáhùn ìbéèrè yìí ní ṣókí pé, “Wọ́n mọ̀ pé àwọn òbí àwọn ò ní gbà, torí náà wọn kì í sọ fún wọn.” Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Jane tún sọ nǹkan míì tó lè fà á. Ó ní: “Fífẹ́ra sọ́nà ní bòókẹ́lẹ́ jẹ́ ọ̀nà táwọn ọ̀dọ́ kan gbà ń fi hàn pé àwọn fẹ́ dá dúró láyè ara àwọn. Béèyàn bá ti ń wo ara ẹ̀ bí àgbà, àmọ́ tí wọn ò yé fojú ọmọdé wò ó, ẹnu kó máa gbé ohun tó bá fẹ́ ṣe gbẹ̀yìn àwọn òbí ẹ̀ ni.”
Kí lo tún rò pé ó lè fà á táwọn ọ̀dọ́ kan fi máa ń fẹ́ra wọn ní bòókẹ́lẹ́? Kọ ọ́ síbí yìí.
․․․․․
Ìwọ náà kúkú mọ àṣẹ tí Bíbélì pa, pé kó o máa gbọ́ràn sáwọn òbí ẹ lẹ́nu. (Éfésù 6:1) Báwọn òbí ẹ bá wá sọ pé àwọn ò tíì fẹ́ kó o máa fẹ́ ẹnì kankan báyìí, ó dájú pé wọ́n mohun tí wọ́n ń sọ. Àmọ́, má ṣe jẹ́ kó yà ẹ́ lẹ́nu bó o bá bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé:
● Mi ò rẹ́ni bá rìn torí pé gbogbo èèyàn ló lẹ́ni tí wọ́n ń fẹ́ àfèmi nìkan.
● Ẹnì kan tí ẹ̀sìn ẹ̀ yàtọ̀ sí tèmi ni mo nífẹ̀ẹ́ sí.
● Ó wù mí kí n máa fẹ́ ẹnì kan tó jẹ́ Kristẹni bíi tèmi bí mi ò tiẹ̀ tíì tó ẹni tó yẹ kó ṣègbéyàwó.
Ó ṣeé ṣe kó o mọ ohun táwọn òbí ẹ máa sọ nípa àwọn nǹkan tó ò ń rò lọ́kàn yìí. Ìwọ náà sì mọ̀ nínú ọkàn ẹ lọ́hùn-ún pé òótọ́ ni wọ́n ń sọ. Síbẹ̀, ọ̀rọ̀ tìẹ náà lè rí bíi ti ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Manami, ó sọ pé: “Ńṣe lọ̀rọ̀ wíwá ẹnì kan fẹ́ máa ń gbà mí lọ́kàn débi tí mo fi máa ń rò pé bóyá kémi náà kúkú máa fẹ́ bọ̀bọ́ kan. Ó ṣòro kéèyàn rí ọ̀dọ́ kan láyé yìí tó máa sọ pé òun ò lẹ́ni tóun ń fẹ́. Kò sí ìgbádùn kankan nínú kémi nìkan máa dá wà!” Àwọn kan tọ́rọ̀ wọn rí bá a ṣe sọ yìí ti bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ ẹnì kan, wọn ò sì jẹ́ káwọn òbí wọn mọ̀ nípa ẹ̀. Báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀?
“Wọ́n Ní Ká Ṣe É Lọ́rọ̀ Àṣírí”
Gbólóhùn yẹn, “fífẹ́ra sọ́nà ní bòókẹ́lẹ́” fi hàn pé ìtànjẹ kan wà ńbẹ̀. Káwọn ẹlòmíì má bàa mọ̀ pé àwọn kan ń fẹ́ra wọn sọ́nà, orí fóònù tàbí Íńtánẹ́ẹ̀tì ni wọ́n ti sábà máa ń bára wọn sọ̀rọ̀. Wọ́n á kàn máa bára wọn ṣọ̀rẹ́ lásán lójú ayé, àmọ́ nǹkan míì pátápátá lọ̀rọ̀ tí wọ́n máa ń sọ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì àti lórí fóònù wọn.
Ọgbọ́n míì táwọn kan tún máa ń dá ni pé wọ́n á ṣètò pé káwọn bíi mélòó kan jọ pàdé fún nǹkan kan, ọkùnrin àtobìnrin á sì wá dọ́gbọ́n múra wọn ní méjì méjì kúrò níbẹ̀. James sọ pé: “Lọ́jọ́ kan báyìí, àwọn kan ní káwa mélòó kan jọ pàdé níbì kan, nígbà tá a débẹ̀, a wá rí i pé àjọmọ̀ àwọn tó pè wá ni pé káwa ọkùnrin tá a wà níbẹ̀ mú àwọn obìnrin tó wà níbẹ̀ níkọ̀ọ̀kan. Wọ́n ní ká ṣe é lọ́rọ̀ àṣírí.”
Bí James ṣe sọ, ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tó ń fẹ́ra wọn ní bòókẹ́lẹ́ máa ń ṣe ọ̀rọ̀ náà láṣìírí láàárín ara wọn àtàwọn ọ̀rẹ́ wọn. Carol sọ pé: “Ó kéré tán, ọ̀rẹ́ wa kan sábà máa ń mọ̀ nípa ẹ̀, àmọ́ ńṣe ló máa ṣẹnu fúrú, torí gbogbo wa ti gbà pé ‘bójú bá rí ẹnu a dákẹ́.’” Nígbà míì sì rèé, irọ́ pátápátá làwọn míì máa ń pa. Beth tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17] sọ pé: “Dípò káwọn ọ̀dọ́ kan sọ ibi tí wọ́n bá gbà lọ, irọ́ ni wọ́n máa ń pa fáwọn òbí wọn, kí wọ́n má bàa mọ̀ pé wọ́n ti ń fẹ́ ẹnì kan.” Ohun tí Misaki tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19] ṣe nìyẹn. Ó sọ pé: “Mo máa ń ronú odù tí màá gbé kalẹ̀ dáadáa. Mo sì máa ń ṣọ́ra kí n má parọ́ lórí àwọn ọ̀rọ̀ míì, àyàfi lórí ọ̀rọ̀ tó bá jẹ mọ́ ẹni tí mò ń fẹ́ kó má lọ di pé àwọn òbí mi á máa mú mi lónírọ́.”
Ohun Tó Burú Nínú Fífẹ́ra Sọ́nà ní Bòókẹ́lẹ́
Bó bá ń ṣe ẹ́ bíi kó o máa fẹ́ ẹnì kan sọ́nà ní bòókẹ́lẹ́, tàbí tó o bá ti ń ṣe bẹ́ẹ̀, ó yẹ kó o béèrè lọ́wọ́ ara ẹ pé:
Ibo lọ̀rọ̀ yìí máa já sí? Ṣó o ní in lọ́kàn láti fẹ́ onítọ̀hún láìpẹ́ láìjìnnà? Evan, tó jẹ́ ọmọ ogún [20] ọdún, sọ pé: “Bó o bá ń fẹ́ ẹnì kan láìjẹ́ pé o ti ṣe tán láti ṣègbéyàwó, ńṣe ló dà bí ìgbà tó ò ń polówó ọjà tó o kì í tà.” Ibo lọ̀rọ̀ náà lè já sí? Òwe 13:12 sọ pé: “Ìfojúsọ́nà tí a sún síwájú ń mú ọkàn-àyà ṣàìsàn.” Ṣé wàá fẹ́ kí ọkàn ẹni tó o fẹ́ràn ṣàìsàn? Nǹkan míì tó o ní láti ṣọ́ra fún rèé: Bó o bá ń fẹ́ ẹnì kan ní bòókẹ́lẹ́, ìyẹn ò ní jẹ́ kó o rí ìmọ̀ràn onífẹ̀ẹ́ táwọn òbí ẹ àtàwọn àgbàlagbà míì máa fẹ́ fún ẹ lórí ọ̀rọ̀ náà gbà. Bó ò bá sì gba irú àwọn ìmọ̀ràn wọ̀nyẹn, o lè lọ ṣèṣekúṣe.—Gálátíà 6:7.
Ojú wo ni Jèhófà Ọlọ́run fi ń wo ohun tí mò ń ṣe? Bíbélì sọ pé: “Ohun gbogbo wà ní ìhòòhò àti ní ṣíṣísílẹ̀ gbayawu fún ojú ẹni tí a óò jíhìn fún.” (Hébérù 4:13) Torí náà, bó o bá ń fẹ́ ẹnì kan ní bòókẹ́lẹ́ tàbí tó o bá ń bo ọ̀rẹ́ ẹ kan tó ń ṣe bẹ́ẹ̀ láṣìírí, jẹ́ kó yé ẹ pé ojú Jèhófà tó ohun tó ò ń ṣe o. Bó bá sì jẹ́ pé ńṣe lò ń tan àwọn òbí ẹ, a jẹ́ pé ó yẹ kó o túbọ̀ yẹra ẹ wò. Jèhófà Ọlọ́run kì í fojúure wo irọ́ pípa o. Kódà, gbangba gbàǹgbà ni Bíbélì mẹ́nu ba “ahọ́n èké” gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn nǹkan tí Ọlọ́run kórìíra!—Òwe 6:16-19.
Bó O Ṣe Lè Jẹ́ Kí Ẹlòmíì Mọ̀
O lè wá rí i báyìí pé, ó máa dáa kó o jẹ́ káwọn òbí ẹ tàbí Kristẹni kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀ mọ̀ nípa àjọṣe bòókẹ́lẹ́ èyíkéyìí tó o bá ní. Bó o bá sì lọ́rẹ̀ẹ́ tó ń fẹ́ ẹnì kan ní bòókẹ́lẹ́, má ṣe bá a bo ohun tí ò ṣeé bò. (1 Tímótì 5:22) Àbí, báwo ló ṣe máa rí lára ẹ bí irú àjọṣe bẹ́ẹ̀ bá lọ já síbi tí ò dáa? Ṣéwọ náà ò ní pín díẹ̀ nínú ẹ̀bi ẹ̀?
Jẹ́ ká ṣàpèjúwe ẹ̀ báyìí: Ká sọ pé ọ̀rẹ́ ẹ kan tó lárùn àtọ̀gbẹ ń jẹ mindin-mín-ìndìn ní kọ̀rọ̀. Ni àṣírí ẹ̀ bá tú sí ẹ lọ́wọ́, àmọ́ ó bẹ̀ ẹ́ pé kó o má sọ fẹ́ni kẹ́ni. Kí ló máa ká ẹ lára jù nínú ọ̀rọ̀ náà, ṣé bíbò tó o fẹ́ bá ọ̀rẹ́ ẹ bo ọ̀rọ̀ náà ni àbí kó o gba ẹ̀mí ẹ̀ là?
Bó ṣe yẹ kó rí náà nìyẹn bó o bá mọ̀ pé àwọn kan ń fẹ́ra wọn ní bòókẹ́lẹ́. Ìwọ gbàgbé ti pé ìyẹn lè bá àárín yín jẹ́. Bó pẹ́ bó yá, ọ̀rẹ́ tòótọ́ á mọ̀ pé tòun lò ń ṣe.—Sáàmù 141:5.
Ṣé Ọ̀rọ̀ Àṣírí Ni àbí Ẹ Ò Tíì Fẹ́ Káwọn Míì Mọ̀?
Òótọ́ kan ni pé, kì í ṣe gbogbo àwọn tó ń fẹ́ra wọn sọ́nà ní bòókẹ́lẹ́ ni wọn ò mọ ohun tí wọ́n ń ṣe o. Bí àpẹẹrẹ, ká ní ọ̀dọ́kùnrin àti ọ̀dọ́bìnrin kan tí wọ́n ti tó ṣègbéyàwó ń fẹ́ láti túbọ̀ mọ ara wọn, wọ́n lè pinnu pé títí dìgbà táwọn á fi mọra àwọn dáadáa, àwọn ò tíì fẹ́ káwọn míì mọ̀. Ó sì lè jẹ́ pé ohun tó fà á, gẹ́gẹ́ bí ọmọkùnrin kan tó ń jẹ́ Thomas ṣe sọ, ni pé, “wọn ò fẹ́ káwọn èèyàn máa yọ wọ́n lẹ́nu nípa bíbéèrè pé, ‘Ìgbà wo lẹ máa wá ṣègbéyàwó?’”
Káwọn ẹlòmíì máa kó gìrìgìrì báni ní ìpalára tó ń ṣe lóòótọ́. (Orin Sólómọ́nì 2:7) Torí náà, nígbà tí ọkùnrin kan àti obìnrin kan bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí fẹ́ra sọ́nà, wọ́n lè máà tíì fẹ́ kí gbogbo èèyàn mọ̀. (Òwe 10:19) Anna, ọmọ ogún [20] ọdún sọ pé: “Mímọ̀ tí wọn ò tíì fẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ báyìí máa jẹ́ kí wọ́n ní àkókò tó pọ̀ tó láti mọ̀ bóyá wọ́n á lè fẹ́ra. Bó bá ti wá dá wọn lójú, nígbà náà, wọ́n lè jẹ́ káyé gbọ́.”
Kò sì tún ní bójú mu pé kó o fi ọ̀rọ̀ ìwọ àtẹni tẹ́ ẹ jọ ń fẹ́ra pa mọ́ fáwọn tó yẹ kí wọ́n mọ̀ nípa ẹ̀, irú bí àwọn òbí ẹ àtàwọn òbí ẹni tó ò ń fẹ́ sọ́nà. Ká sòótọ́, bó bá ṣòro fún ẹ láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ ẹni tó ò ń fẹ́, a jẹ́ pé nǹkan míì wà ńbẹ̀ nìyẹn. Ṣéwọ náà mọ̀ lọ́kàn ara ẹ pé ìdí pàtàkì kan wà táwọn òbí ẹ ò fi ní fara mọ́ ọn?
“Mo Mọ Ohun Tó Yẹ Kí N Ṣe”
Jessica, tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí ò fẹ́ Jeremy mọ́ nígbà tó gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí arábìnrin kan tóun àtẹnì kan jọ ń fẹ́ra ní bòókẹ́lẹ́. Jessica sọ pé: “Lẹ́yìn tí mo gbọ́ ohun tí arábìnrin yẹn ṣe láti fòpin sí àjọṣe òun àti onítọ̀hùn, kíá ni mo mọ ohun tó yẹ kí n ṣe.” Ṣó rọrùn láti fòpin sírú àjọṣe bẹ́ẹ̀? Rárá o! Jessica sọ pé: “Ká sòótọ́, mo fẹ́ràn ọmọkùnrin yẹn gan-an. Ó tó ọ̀sẹ̀ bíi mélòó kan tí mo fi ń sunkún lójoojúmọ́.”
Ohun mìíràn tí Jessica tún mọ̀ ni pé òun nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, àti pé bó tiẹ̀ jẹ́ pé òun fìgbà díẹ̀ ṣe ohun tí kò tọ́, òun ṣì ń fẹ́ láti ṣe ohun tó tọ́. Bọ́jọ́ ti ń gorí ọjọ́, ìrònú nípa ọmọkùnrin yẹn kúrò lọ́kàn ẹ̀. Jessica wá sọ pé: “Àjọṣe àárín èmi àti Jèhófà ti wá dáa ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó ń fún wa ní ìtọ́sọ́nà tá a nílò ní àkókò tá a bá nílò rẹ̀ gẹ́lẹ́!”
Ká ló o ti tó ẹni tó ń ní àfẹ́sọ́nà, tó o sì ti rí ẹnì kan tó o fẹ́ràn. Báwo lo ṣe máa mọ̀ bóyá ẹni tó yẹ kó o fẹ́ nìyẹn?
ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́
‘À ń dàníyàn láti máa hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo.’—Hébérù 13:18.
ÌMỌ̀RÀN
Kì í ṣe pé wàá máa lọ sọ ẹni tó ò ń fẹ́ fún gbogbo ayé o. Àmọ́ ó yẹ kó o sọ fáwọn tó yẹ kó mọ̀ nípa ẹ̀. Ìyẹn sì kan àwọn òbí ẹ àti òbí ẹni tó ò ń fẹ́.
ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?
Òdodo ló lè mú kí àjọṣe àárín ìwọ àtàwọn òbí ẹ tọ́jọ́. Bó o bá ń fẹ́ ẹnì kan ní bòókẹ́lẹ́, àwọn òbí ẹ ò ní fọkàn tán ẹ, ìyẹn sì lè mú kẹ́ni tó ò ń fẹ́ náà máa ṣiyè méjì nípa ẹ.
OHUN TÍ MÀÁ ṢE!
Bí èmi àti Kristẹni bíi tèmi bá ń fẹ́ra wa ní bòókẹ́lẹ́, ohun tí màá ṣe ni pé ․․․․․
Bí ọ̀rẹ́ mi bá ń fẹ́ ẹnì kan ní bòókẹ́lẹ́, ohun tí màá ṣe ni pé ․․․․․
Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․
KÍ LÈRÒ Ẹ?
● Ronú lórí gbólóhùn mẹ́ta tá a fi lẹ́tà tó dúdú yàtọ̀ kọ lójú ìwé 22. Èwo nínú wọn ló bá bí nǹkan ṣe máa ń rí lára ẹ mu?
● Kí lo lè ṣe nípa àwọn ọ̀rọ̀ náà láìjẹ́ pé o lọ ń fẹ́ ẹnì kan ní bòókẹ́lẹ́?
● Bó o bá mọ̀ pé ọ̀rẹ́ ẹ kan ń fẹ́ ẹnì kan ní bòókẹ́lẹ́, kí lo máa ṣe, kí sì nìdí tó o fi máa ṣe bẹ́ẹ̀?
[Ìsọfúnni tó wà ní ojú ìwé 27]
Mi ò fẹ́ bọ̀bọ́ yẹn ní bòókẹ́lẹ́ mọ́. Àmọ́ kò rọrùn, bí mo bá ti ń rí i níléèwé lójoojúmọ́ báyìí ló máa ń ṣe mí bíi pé kí n tún lọ bá a. Jèhófà ló mọ ohun táwa ò mọ̀. Àfi ká gbẹ́kẹ̀ lé e.’’—Jessica
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Bó o bá ń bá ọ̀rẹ́ ẹ kan tó ń fẹ́ ẹnì kan ní bòókẹ́lẹ́ ṣe ọ̀rọ̀ ọ̀hún láṣìírí, ńṣe ló dà bí ìgbà tó ò ń bo ọ̀ràn ẹni tó lárùn àtọ̀gbẹ àmọ́ tó ń kó mindin-mín-ìndìn jẹ ní kọ̀rọ̀
-
-
Ṣé Ẹni Tó Yẹ Kí N Fẹ́ Nìyí?Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
-
-
ORÍ 3
Ṣé Ẹni Tó Yẹ Kí N Fẹ́ Nìyí?
Kọ́kọ́ wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí:
Àwọn ànímọ́ wo ló ṣe pàtàkì lójú ẹ báyìí pé kẹ́ni tó o máa fẹ́ ní? Nínú àwọn àlàfo tó wà nísàlẹ̀ yìí, fi àmì ✔ síwájú àwọn ànímọ́ mẹ́rin tó o gbà pé ó ṣe pàtàkì jù lọ.
□ Ó rẹwà □ Ó ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run
□ Ó kóni mọ́ra □ Ó ṣeé fọkàn tán
□ Ó gbajúmọ̀ □ Kì í hùwàkiwà
□ Ó máa ń ṣàwàdà □ Ó máa ń fètò sí ohun tó bá ń ṣe
Nígbà tó o ṣì kéré, ṣé ẹnì kan wà tọ́kàn ẹ máa ń fà sí ṣáá? Nínú àwọn àlàfo tó wà lókè yìí, fi àmì × síwájú ànímọ́ tó wù ẹ́ jù lọ lára onítọ̀hún nígbà yẹn.
KÒ SÓHUN tó burú nínú èyíkéyìí lára àwọn ànímọ́ tá a tò sókè yìí. Ó ní ibi tí gbogbo wọ́n dáa sí. Àmọ́, ǹjẹ́ o kíyè sí i pé nígbà tó o ṣì kéré, tọ́kàn ẹ ṣì máa ń fà sí ẹnì kan ṣáá, àwọn ànímọ́ tó jẹ mọ́ ẹwà ara lásán bí àwọn tá a tò sápá òsì yẹn ló sábà máa ń gbà ẹ́ lọ́kàn?
Àmọ́, bó o ṣe ń dàgbà, o bẹ̀rẹ̀ sí í lo agbára ìmòye rẹ láti ṣàyẹ̀wò àwọn ọ̀ràn tó túbọ̀ ṣe pàtàkì, bí àwọn tá a tò sápá ọ̀tún. Bí àpẹẹrẹ, o lè wá bẹ̀rẹ̀ sí í lóye pé ọmọbìnrin tó rẹwà jù lọ ládùúgbò yẹn lè má ṣeé gbára lé rárá tàbí kó jẹ́ pé oníwàkiwà lọmọkùnrin tó gbajúmọ̀ jù lọ ní kíláàsì yín. Bó o bá ti kọjá ìgbà ìbàlágà, ó ṣeé ṣe kó o wò ré kọjá àwọn ànímọ́ ti ara lásán kó o tó dáhùn ìbéèrè bíi, “Ṣé ẹni tó yẹ kí n fẹ́ nìyí?”
Kọ́kọ́ Mọra Ẹ Ná
Kó o tó lè mọ̀ bóyá ẹnì kan yẹ lẹ́ni tó o lè fẹ́, kọ́kọ́ mọra ẹ dáadáa. Kó o bàa lè mọ púpọ̀ sí i nípa ara ẹ, dáhùn àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí:
Ibo ni mo dáa sí? ․․․․․
Ibo ni mo kù sí? ․․․․․
Kí ni mò ń wá lára ẹni tí mo máa fẹ́, kí ló sì yẹ kí n ṣe nípa àjọṣe mi pẹ̀lú Ọlọ́run? ․․․․․
Wàá rí i pé iṣẹ́ kékeré kọ́ lèèyàn máa ṣe kó tó lè mọra ẹ̀ dáadáa, àmọ́ irú àwọn ìbéèrè tó wà lókè yìí náà ló lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti mọ̀. Bó o bá ṣe mọra ẹ dunjú tó, bẹ́ẹ̀ lá á ṣe rọrùn fún ẹ tó láti wá ẹni tó máa mọyì ibi tó o dáa sí tá á sì lè fara da ibi tó o kù sí.a Àmọ́, bó o bá wá rò pé o ti rẹ́ni tó wù ẹ̀ ńkọ́?
Ṣé Ẹnikẹ́ni Ni Mo Lè Fẹ́?
“Á wù mí kí n mọ̀ ẹ́ ju báyìí lọ!” Ó ṣeé ṣe kí gbólóhùn yẹn bá ẹ lójijì tàbí kó múnú ẹ dùn, ìyẹn sì sinmi lórí ẹni tó bá sọ bẹ́ẹ̀ sí ẹ. Ká wá sọ pé o gbà fónítọ̀hún ńkọ́? Bọ́jọ́ ti ń gorí ọjọ́, báwo lo ṣe máa mọ̀ bóyá ọkùnrin tàbí obìnrin tó yẹ kó o fẹ́ nìyẹn?
Ká sọ pé o fẹ́ ra bàtà tuntun kan. O lọ sí ṣọ́ọ̀bù tí wọ́n ti ń ta bàtà, o sì rí bàtà tó wù ẹ́ níbẹ̀. O wọ̀ ọ́ wò, àmọ́ ńṣe ló fún ẹ lẹ́sẹ̀ pinpin. Kí lo máa ṣe? Ṣé wàá ra bàtà náà bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀? Àbí wàá wá òmíràn tó bá ẹ lẹ́sẹ̀ mu. Ohun tó máa dáa jù lọ ni pé kó o dá bàtà náà pa dà, kó o sì wá òmíràn tó bá ẹ lẹ́sẹ̀ mu. Kò bọ́gbọ́n mu pé kó o máa wọ bàtà tó fún ẹ lẹ́sẹ̀ káàkiri!
Bọ́ràn ṣe máa ń rí nìyẹn béèyàn bá ń wá ẹni tó máa fẹ́. O lè rí i pé ọ̀pọ̀ lára àwọn ọkùnrin tàbí obìnrin tó ò ń bá pàdé ló wù ẹ́ láti fẹ́. Àmọ́, èyíkéyìí nínú wọn ò lè jẹ́ ọkọ tàbí aya rere fún ẹ. Ó ṣe tán, ẹni tó tẹ́ ẹ lọ́rùn tí ìwà ẹ̀ àtohun tó fẹ́ ò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ sí tìẹ, ló máa wù ẹ́ pé kó o fẹ́. (Jẹ́nẹ́sísì 2:18; Mátíù 19:4-6) Ṣó o ti wá rí irú ẹni bẹ́ẹ̀? Bó o bá ti rí i, báwo ni wàá ṣe mọ̀ bóyá òun ló yẹ kó o fẹ́?
Má Wo Ojú Lásán
Kó o bàa lè dáhùn ìbéèrè tó gbẹ̀yìn yẹn, fara balẹ̀ ronú nípa ẹni tó o ní lọ́kàn láti fẹ́. Àmọ́ kó o ṣọ́ra o! Kó má lọ jẹ́ pé ohun tó o fẹ́ rí nìkan ni wàá máa rí. Torí náà, fara ẹ balẹ̀. Gbìyànjú láti mọ̀wà ẹni náà dáadáa. Ìyẹn sì máa béèrè pé kó o sapá gidigidi. Kò yẹ kíyẹn yà ẹ́ lẹnu ṣá o. Àpẹẹrẹ kan rèé: Jẹ́ ká sọ pé o fẹ́ ra ọkọ ayọ́kẹ́lẹ́ kan. Ǹjẹ́ o ò ní yẹ ọkọ ayọ́kẹ́lẹ́ náà wò dáadáa? Àbí bó bá ṣáà ti dáa lójú, ó parí náà nìyẹn? Ǹjẹ́ kò ní bọ́gbọ́n mu pé kó o yẹ̀ ẹ́ wò tinú tẹ̀yìn, kó o sì tún wo bí ẹ́ńjìnnì ẹ̀ ṣe ń ṣiṣẹ́ sí pàápàá?
Wíwá ẹni téèyàn máa fẹ́ gbẹgẹ́ ju ríra ọkọ ayọ́kẹ́lẹ́ lọ. Síbẹ̀, ojú lásán lọ̀pọ̀ àwọn tó ń wá ẹni tí wọ́n máa fẹ́ ń wò. Ó máa ń yá wọn lára láti sọ ohun tí wọ́n jọ fẹ́ràn. Wọ́n lè sọ pé: ‘Irú orin kan náà ló máa ń wù wá gbọ́.’ ‘Irú eré kan náà ló máa ń wù wá ṣe.’ ‘A kì í jiyàn lórí ohunkóhun!’ Àmọ́, bá a ṣe sọ lẹ́ẹ̀kan, bó o bá ti kọjá ìgbà ìbàlágà, o ò ní máa wo ojú lásán mọ́. Wàá wá rí i pé o gbọ́dọ̀ fòye mọ “ẹni ìkọ̀kọ̀ ti ọkàn-àyà.”—1 Pétérù 3:4; Éfésù 3:16.
Bí àpẹẹrẹ, dípò tí wàá fi máa pọkàn pọ̀ sórí bẹ́ ẹ ṣe jọ ń fara mọ́ ohun kan náà tó, fífiyè sí ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ bí ẹ kò bá fara mọ́ ohun kan náà ló máa jẹ́ kó o mọ irú ẹni tó jẹ́ gan-an. Bí àpẹẹrẹ, báwo ló ṣe máa ń ṣe bí èdèkòyédè bá ṣẹlẹ̀? Ṣó máa ń rin kinkin pé òun lòun tọ̀nà, bóyá nípa ‘bíbínú fùfù’ tàbí kó máa ‘sọ̀rọ̀ èébú’? (Gálátíà 5:19, 20; Kólósè 3:8) Àbí olóye ẹ̀dá tí kì í rin kinkin mọ́ èrò rẹ̀ nítorí àtipa àlàáfíà mọ́ ni, bọ́ràn tó wà nílẹ̀ ò bá ṣáà ti ta ko ìlànà Bíbélì?—Jákọ́bù 3:17.
Ohun míì tó tún yẹ kó o gbé yẹ̀ wò nìyí: Ṣé ẹni tó máa ń dọ́gbọ́n darí ẹlòmíì ṣe nǹkan tó fẹ́ ni, ṣó máa ń fẹ́ ṣe bí ọ̀gá, àbí òjòwú ni? Ṣó máa ń fẹ́ mọ gbogbo ibi tó o bá ń rìn sí? Ọ̀dọ́mọkùnrin kan tó ń jẹ́ Nicole sọ pé: “Mo máa ń gbọ́ táwọn tó ń fẹ́ra wọn sọ́nà ń bára wọn jà nítorí pé ọ̀kan lára wọn ò máa pe èkejì lemọ́lemọ́ lórí fóònù láti máa sọ gbogbo bó ṣe ń rìn fún un. Àpẹẹrẹ burúkú nìyẹn lójú tèmi.”—1 Kọ́ríńtì 13:4.
Àwọn ọ̀ràn tó jẹ mọ́ ìwà ẹnì kan àti irú ẹni tónítọ̀hún jẹ́ lèyí tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ tán yìí. Àmọ́, ó tún ṣe pàtàkì pé kó o mọ ohun táwọn èèyàn ń sọ nípa ẹni tó o fẹ́ fẹ́. Ojú wo làwọn ẹlòmíì fi ń wò ó? Ó máa dáa kó o bá àwọn tó ṣe díẹ̀ tí wọ́n ti mọ ẹni yìí sọ̀rọ̀, irú bí àwọn tó dàgbà nípa tẹ̀mí nínú ìjọ. Ìyẹn lo máa fi mọ̀ bóyá wọ́n ń “ròyìn rẹ̀ dáadáa.”—Ìṣe 16:1, 2.
Ohun tó tún máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ ni pé kó o ṣe àkọsílẹ̀ bí ẹni tó o fẹ́ fẹ́ ṣe ń ṣe sí nínú àwọn ohun tá a ti jíròrò.
Irú ẹni tó jẹ́ ․․․․․
Ìwà rẹ̀ ․․․․․
Ohun tí wọ́n ń sọ nípa ẹ̀ ․․․․․
Wàá tún jàǹfààní púpọ̀ nípa wíwo Ṣé Mo Lè Fẹ́ Ẹ? lójú ìwé 39 tàbí Ṣé Mo Lè Gbé E Sílé? lójú ìwé 40. Àwọn ìbéèrè tó wà níbẹ̀ máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti pinnu bóyá ìwọ àti onítọ̀hún á lè fẹ́ra yín.
Lẹ́yìn tó o bá ti gbé ọ̀rọ̀ náà yẹ̀ wò, bó o bá wá pinnu pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ kọ́ lo máa fẹ́ ńkọ́? Bọ́ràn bá rí bẹ́ẹ̀, ìbéèrè ńlá tó o máa ní láti dáhùn ni pé:
Ṣé Ká Fira Wa Sílẹ̀?
Oore ńlá ló máa ń jẹ́ nígbà míì báwọn méjì bá fira wọn sílẹ̀. Gbé àpẹẹrẹ Jill yẹ̀ wò. Ó sọ pé: “Inú mi kọ́kọ́ máa ń dùn pé ẹni tí mò ń fẹ́ máa ń fẹ́ mọ ibi tí mo wà, ohun tí mò ń ṣe àti ọ̀dọ̀ ẹni tí mo wà. Àmọ́, ó bá a débi pé kò fẹ́ kí n da nǹkan pọ̀ pẹ̀lú ẹlòmíì, àfi òun nìkan ṣáá. Kódà, ó máa ń jowú bó bá rí èmi àtàwọn aráalé mi pa pọ̀, àgàgà dádì mi. Nígbà tá a fira wa sílẹ̀, ṣe ló dà bí ìgbà tí wọ́n gbé ẹrù ńlá kan kúrò léjìká mi!”
Irú nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí Sarah náà nìyẹn. Ó bẹ̀rẹ̀ sí kíyè sí i pé John, ọ̀dọ́mọkùnrin tí wọ́n jọ ń fẹ́ra máa ń fọ̀rọ̀ kanni lábùkù, ó ṣòroó tẹ́ lọ́rùn, ó sì máa ń ráwọn èèyàn fín. Sarah rántí ohun kan tó ṣẹlẹ̀, ó ní: “Ọjọ́ kan wà tó pẹ́ kó tó délé wa, ó ti tó wákàtí mẹ́ta tí mo ti ń dúró dè é! Nígbà tó kanlẹ̀kùn, mọ́mì mi ló lọ ṣílẹ̀kùn fún un. Àmọ́ kò kí wọn, ọ̀dọ̀ mi ló ń bọ̀ tààràtà bó ṣe gba ẹ̀gbẹ́ wọn kọjá, ó wá sọ fún mi pé: ‘Jẹ́ ká lọ, o ò mọ̀ pá a ti pẹ́ ni?’ Dípò kó sọ pé òun ti pẹ́,’ ó ní, ‘A ti pẹ́.’ Èmi tiẹ̀ retí pé kó ní kí wọ́n máà bínú, kó sì ṣàlàyé ohun tó mú kó pẹ́ dé. Àti pé èwo ni ti mọ́mì mi tó fojú pa rẹ́!” Ti pé ẹnì kan hùwà tá ò retí lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo ò fi dandan ní ká sọ pá ò ṣe mọ́. (Sáàmù 130:3) Àmọ́ nígbà tí Sarah wá rí i pé bí John ṣe máa ń ṣe nìyẹn, kì í wulẹ̀ ṣe pé ó ṣèèṣì, ó kúkú pinnu pé káwọn fira àwọn sílẹ̀.
Bíi ti Jill àti Sarah, bó bá wá ṣẹlẹ̀ pé ìwọ náà rí i pé ọ̀rọ̀ ìwọ àti ẹni tẹ́ ẹ jọ ń fẹ́ra yín ò wọ̀ mọ́ ńkọ́? Bọ́ràn bá rí bẹ́ẹ̀, má ṣe gbójú fo bó ṣe ń ṣe ẹ́! Ó lè má rọrùn lóòótọ́, àmọ́ ohun tó máa dáa jù ni pé kẹ́ ẹ fira yín sílẹ̀. Òwe 22:3 sọ pé: “Afọgbọ́nhùwà ni ẹni tí ó ti rí ìyọnu àjálù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ̀ pa mọ́.” Bí àpẹẹrẹ, bó o bá bá ọ̀kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lára àwọn ìwà tá a tò sábẹ́ ibi tí ìṣòro ti lè jẹ yọ lójú ìwé 39 àti 40 lọ́wọ́ ẹni tẹ́ ẹ jọ ń fẹ́ra yín, ohun tó máa dáa jù ni pé kẹ́ ẹ fòpin sí àjọṣe yẹn, àyàfi tí ẹni tọ́ràn kàn bá ṣàtúnṣe. Lóòótọ́ o, ó lè má rọrùn láti fòpin sí irú àjọṣe bẹ́ẹ̀, àmọ́ àjọṣe tó wà títí lọ ni ìgbéyàwó. Torí náà, bọ́rọ̀ ò bá wọ̀ mọ́, ó sàn kéèyàn jẹ̀rora ẹ̀ fúngbà díẹ̀, ju kó fagídí tọrùn bọ̀ ọ́, kó wá máa jẹ̀ka àbámọ̀ títí lọ lẹ́yìn náà!
Bó O Ṣe Máa Sọ fún Un
Báwo lo ṣe lè fòpin sí irú àjọṣe bẹ́ẹ̀? Kọ́kọ́ mọ bó ṣe yẹ kó o sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀, ibi tó yẹ kó o ti sọ ọ́, àti àkókò tó yẹ kó o sọ ọ́? Bíi báwo? Ó dára, ronú nípa bó o ṣe máa fẹ́ kéèyàn sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ fún ẹ. (Mátíù 7:12) Ṣó o máa fẹ́ kó sọ ọ́ fún ẹ níṣojú àwọn ẹlòmíì? Kò dájú pé wàá fẹ́ kó ṣe bẹ́ẹ̀. Kò dára kéèyàn fòpin sí irú àjọṣe bẹ́ẹ̀ lórí tẹlifóònù, lẹ́tà orí fóònù alágbèéká, tàbí lẹ́tà orí kọ̀ǹpútà, àyàfi bí kò bá sí ọgbọ́n míì téèyàn lè dá sí i. Kàkà bẹ́ẹ̀, wá àkókò, kó o sì tún wá ibi tó dáa tẹ́yin méjèèjì á ti lè jíròrò ọ̀ràn pàtàkì náà.
Bó bá wá tó àkókò àtisọ̀rọ̀, kí ló yẹ kó o sọ? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Kristẹni pé kí wọ́n máa “sọ òtítọ́” fúnra wọn. (Éfésù 4:25) Nítorí náà, ohun tó dáa jù lọ ni pé kó o fọgbọ́n sọ ọ́, àmọ́ jẹ́ kó ṣe kedere. Ṣàlàyé ìdí tó o fi rò pé kò ní ṣeé ṣe fún ẹ láti fẹ́ ẹ. Kò dìgbà tó o bá ṣẹ̀ṣẹ̀ ń to gbogbo àléébù rẹ̀ níkọ̀ọ̀kan tàbí tó o bá ń dá a lẹ́bi ṣáá. Àní sẹ́, dípò tí wàá fi sọ pé, “O ò” ṣe tibí, “o ò” ṣe tọ̀hún, ó máa sàn kó o lo èdè tó fi bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ hàn, bíi “Mò ń fẹ́ ẹni tó lè . . . ” tàbí “Mo lérò pé a gbọ́dọ̀ fòpin sí àjọṣe yìí torí pé . . . ”
Irú àkókò yìí kọ́ ni wàá máa ṣe mẹ-in mẹ-in tàbí tí wàá jẹ́ kó yí ẹ lérò pa dà. Rántí pé ohun pàtàkì kan ló mú kó o fẹ́ láti fòpin sí àjọṣe náà. Torí náà, jẹ́ ọlọgbọ́n bí ẹni tẹ́ ẹ jọ ń fẹ́ra yín bá ń gbìyànjú láti dọ́gbọ́n yí ẹ lérò pa dà. Ọ̀dọ́mọbìnrin kan tó ń jẹ́ Lori sọ pé: “Lẹ́yìn tí mo ti fòpin sí àjọṣe tó wà láàárín wa, ẹni tá a jọ ń fẹ́ra tẹ́lẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe bí ẹni tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀. Mo lérò pé torí kí n lè máa káàánú ẹ̀ ló fi ń ṣe bẹ́ẹ̀. Ó dùn mí gan-an. Àmọ́ mi ò tìtorí ìyẹn yí ìpinnu mi pa dà.” Bíi ti Lori, mọ ohun tó o fẹ́. Má sì ṣe yí ìpinnu rẹ pa dà. Jẹ́ kí bẹ́ẹ̀ kọ́ rẹ jẹ́ bẹ́ẹ̀ kọ́.—Jákọ́bù 5:12.
Ohun Tó Lè Ṣẹlẹ̀ Lẹ́yìn Tẹ́ Ẹ Bá Fira Yín Sílẹ̀
Má ṣe jẹ́ kó yà ẹ́ lẹ́nu bọ́rọ̀ náà bá ń dùn ẹ́ fún àkókò díẹ̀ lẹ́yìn tẹ́ ẹ ti fira yín sílẹ̀. Ó lè máa ṣe ẹ́ bíi ti onísáàmù tó sọ pé: “Mo ti di aláìbalẹ̀-ọkàn, mo ti tẹrí ba mọ́lẹ̀ ní ìwọ̀n tí ó dé góńgó; láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀ ni mo ń rìn káàkiri nínú ìbànújẹ́.” (Sáàmù 38:6) Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ kan tí wọ́n fẹ́ ẹ fún rere, tí wọ́n sì fẹ́ láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ lè gbà ẹ́ níyànjú pé kẹ́ ẹ máa bá eré ìfẹ́ yín lọ. Ṣọ́ra o! Ìwọ ni ìpinnu tó o bá ṣe máa já lé léjìká, kì í ṣe àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tí wọ́n ń fẹ́ ẹ fún rere. Nítorí náà má ṣe bẹ̀rù láti dúró lórí ìpinnu ẹ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tó ṣẹlẹ̀ náà lè bà ẹ́ nínú jẹ́.
Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé, bó pẹ́ bó yá, ọ̀rọ̀ náà á kúrò lọ́kàn ẹ. Ní báyìí ná, ṣé wàá kúkú ṣe àwọn ohun tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti kojú ẹ̀dùn ọkàn rẹ, bí irú èyí tó wà nísàlẹ̀ yìí?
Sọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára ẹ fún ẹnì kan tó o lè finú hàn.b (Òwe 15:22) Gbàdúrà sí Jèhófà nípa rẹ̀. (Sáàmù 55:22) Máa wá nǹkan ṣe. (1 Kọ́ríńtì 15:58) Má máa dá wà! (Òwe 18:1) Máa kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì tí wọ́n lè gbé ẹ ró. Máa pọkàn pọ̀ sórí àwọn nǹkan tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́.—Fílípì 4:8.
Bó bá tún yá, o lè rí ẹlòmíì tẹ́ ẹ lè jọ fẹ́ra yín. Bó bá rí bẹ́ẹ̀, wàá lo ọgbọ́n tó o ti kọ́ láti fi wo bí onítọ̀hún ṣe rí gan-an. Ó ṣeé ṣe nígbà yẹn kí ìdáhùn rẹ sí ìbéèrè náà, “Ṣé ẹni tó yẹ kí n fẹ́ nìyí?” jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni!
KA PÚPỌ̀ SÍ I NÍPA ÀKÒRÍ YÌÍ NÍ ORÍ 31, NÍNÚ APÁ KÌÍNÍ ÌWÉ YÌÍ
Bó o bá ti lẹ́ni tẹ́ ẹ jọ ń fẹ́ra yín, báwo lẹ ò ṣe ní ki àṣejù bọ bẹ́ ẹ ṣe ń fìfẹ́ hàn síra yín?
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a O lè túbọ̀ mọra ẹ dunjú nípa ṣíṣàyẹ̀wò àwọn ìbéèrè tó wà ní Orí 1, lábẹ́ ìsọ̀rí náà “Ṣó O Ti Ṣe Tán Láti Ṣègbéyàwó?”
b Àwọn òbí ẹ tàbí àwọn míì tó jẹ́ àgbàlagbà, bí àwọn alàgbà nínú ìjọ, lè ràn ẹ́ lọ́wọ́. O tiẹ̀ lè rí i pé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ẹ ti ṣẹlẹ̀ sáwọn náà rí nígbà tí wọ́n wà lọ́mọdé.
ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́
“Àní nípa àwọn ìṣe rẹ̀, ọmọdékùnrin kan ń mú kí a dá òun mọ̀, ní ti bóyá ìgbòkègbodò rẹ̀ mọ́ gaara tí ó sì dúró ṣánṣán.”—Òwe 20:11.
ÌMỌ̀RÀN
Ẹ jọ máa ṣàwọn nǹkan tá á firú ẹni tẹ́ ẹ jẹ́ hàn:
● Ẹ jọ máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
● Ẹ kíyè sí bẹ́ ẹ ṣe jọ ń ṣe sí láwọn ìpàdé ìjọ àti lóde ẹ̀rí.
● Ẹ jọ máa kópa nínú títún Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣe àti kíkọ́ àwọn ibi ìjọsìn.
ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?
Ìwádìí ti fi hàn léraléra pé ó ṣeé ṣe kí tọkọtaya tí ẹ̀sìn wọn yàtọ̀ síra kọra wọn sílẹ̀.
OHUN TÍ MÀÁ ṢE!
Bí ọkàn mi bá ń fà sí aláìgbàgbọ́, màá ․․․․․
Kí n bàa lè mọ ohun táwọn ẹlòmíì ń sọ nípa ẹni tí mò ń fẹ́, mo lè ․․․․․
Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․
KÍ LÈRÒ Ẹ?
● Àwọn ànímọ́ dáadáa wo ló máa mú kó o jẹ́ ọkọ tàbí aya rere?
● Àwọn ànímọ́ pàtàkì wo ló máa wù ẹ́ pé kẹ́ni tó o máa fẹ́ ní?
● Àwọn ọ̀ràn tó díjú wo ló lè wáyé tó o bá fẹ́ ẹnì kan tí ẹ̀sìn rẹ̀ yàtọ̀ sí tìẹ?
● Àwọn ọ̀nà wo lo lè gbà mọ púpọ̀ sí i nípa ìwà ẹni tẹ́ ẹ jọ ń fẹ́ra àti ohun táwọn èèyàn ń sọ nípa ẹ̀?
[Ìsọfúnni tó wà ní ojú ìwé 37]
“Bí ẹni tẹ́ ẹ jọ ń fẹ́ra bá ṣe ń ṣe sáwọn aráalé rẹ̀ ló ṣe máa ṣe síwọ náà.”—Tony
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 34]
“Má Ṣe Fi Àìdọ́gba So Pọ̀”
“Má ṣe fi àìdọ́gba so pọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́.” Ó ṣeé ṣe kí ìwọ náà gbà pé ìlànà Bíbélì tó wà nínú 2 Kọ́ríńtì 6:14 yìí, bọ́gbọ́n mu. Síbẹ̀, ó lè máa wù ẹ́ kó o fẹ́ aláìgbàgbọ́. Kí nìdí? Nígbà míì, ó kàn lè jẹ́ ẹwà ẹ̀ ló ń dá ẹ lọ́rùn. Ọmọkùnrin kan tó ń jẹ́ Mark sọ pé: “Ìgbà gbogbo ni mo máa ń bá ọmọbìnrin náà pàdé níbi tá a ti ń dára yá. Láìlọ bá a, á wá sọ́dọ̀ mi, á sì máa bá mi sọ̀rọ̀. Kò ṣòro rárá láti bá a ṣọ̀rẹ́.”
Bó o bá rántí irú ẹni tó o jẹ́, tó ò fẹ́ ṣe ohun tó lòdì sí ìlànà Bíbélì, tí òtítọ́ sì jinlẹ̀ nínú ẹ débi pé kì í ṣe tinú ẹ ṣáá lo máa ń ṣe, ó yẹ kó o mọ ohun tí wàá ṣe. Bó ti wù kí aláìgbàgbọ́ kan rẹwà tó, kó fani mọ́ra tó, tàbí kó jẹ́ olódodo tó, jẹ́ kó yé ẹ pé kò ní mú kí àjọṣe rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run sunwọ̀n sí i.—Jákọ́bù 4:4.
Àmọ́ ṣá o, ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Cindy ti wá rí i pé, bí ìfẹ́ ẹnì kan bá ti kó síni lórí, kì í rọrùn láti fòpin sí i. Ó sọ pé: “Ojoojúmọ́ ni mo máa ń sunkún. Ọkàn mi kì í kúrò lára ọmọkùnrin náà, àní nígbà tí mo bá wà nípàdé pàápàá. Mo fẹ́ràn rẹ̀ gan-an débi pé ikú yá mi lára ju kí n pàdánù ọmọkùnrin náà lọ.” Kò pẹ́ púpọ̀ ṣá tí Cindy fi rí ọgbọ́n tó wà nínú ohun tí mọ́mì ẹ̀ ń sọ fún un nípa fífẹ́ aláìgbàgbọ́. Ó sọ pé: “Bémi àti ẹ̀ ṣe fira wa sílẹ̀ yẹn ló dáa. Ó dá mi lójú gbangba pé Jèhófà á pèsè ọkọ tèmi fún mi.”
Ṣé bíi ti Cindy lọ̀rọ̀ tìẹ náà rí? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ àwọn ẹlòmíì! O lè fọ̀rọ̀ náà lọ àwọn òbí rẹ. Ohun tí Jim ṣe nìyẹn nígbà tí ìfẹ́ ọmọbìnrin kan níléèwé wọn kó sí i lórí. Ó sọ pé: “Ìgbà tó yá ni mo ní káwọn òbí mi ràn mí lọ́wọ́ lórí ọ̀ràn náà. Ohun tó ràn mí lọ́wọ́ gan-an nìyẹn tí mo fi yanjú ìṣòro náà.” Àwọn alàgbà ìjọ pẹ̀lú lè ràn ẹ́ lọ́wọ́. O ò ṣe sọ bó ṣe ń ṣe ẹ́ fún ọ̀kan nínú wọn?—Aísáyà 32:1, 2.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 39]
Tí mo kọ èrò mi sí
Ṣé Mo Lè Fẹ́ Ẹ?
Kòṣeémánìí
◻ Báwo ló ṣe máa ń lo àṣẹ tí wọ́n bá gbé lé e lọ́wọ́?—Mátíù 20:25, 26.
◻ Kí làwọn àfojúsùn rẹ̀?—1 Tímótì 4:15.
◻ Ṣó ti ń sapá báyìí kó bàa lè lé àwọn àfojúsùn yẹn bá?—1 Kọ́ríńtì 9:26, 27.
◻ Báwo ló ṣe ń ṣe sáwọn ará ilé ẹ̀?—Ẹ́kísódù 20:12.
◻ Àwọn wo ló ń bá rìn?—Òwe 13:20.
◻ Kí lọ̀rọ̀ ẹ̀ máa ń dá lé?—Lúùkù 6:45.
◻ Báwo lọ̀ràn owó ṣe máa ń rí lára ẹ̀?—Hébérù 13:5, 6.
◻ Irú eré ìnàjú wo ló fẹ́ràn láti máa ṣe?—Sáàmù 97:10.
◻ Báwo ló ṣe ń fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ Jèhófà?—1 Jòhánù 5:3.
Irú Ẹni Tó Yẹ Kó Jẹ́
◻ Ṣé òṣìṣẹ́ kára ni?—Òwe 6:9-11.
◻ Ṣé kì í náwó nínàákúnàá?—Lúùkù 14:28.
◻ Ṣé wọ́n máa ń sọ̀rọ̀ ẹ̀ ní rere?—Ìṣe 16:1, 2.
◻ Ṣó máa ń gba tàwọn ẹlòmíì rò?—Fílípì 2:4.
Ibi Tí Ìṣòro Ti Lè Jẹ Yọ
◻ Ṣé kì í pẹ́ bínú?—Òwe 22:24.
◻ Ṣó máa ń fẹ́ bá ẹ ṣèṣekúṣe?—Gálátíà 5:19.
◻ Ṣé oníjà ni àbí ó máa ń bú èèyàn?—Éfésù 4:31.
◻ Ṣé bí ò bá tíì rí ọtí líle kò lè gbádùn ara ẹ̀?—Òwe 20:1.
◻ Ṣé òjòwú àti onímọ̀-tara-ẹni nìkan ni?—1 Kọ́ríńtì 13:4, 5.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 40]
Tí mo kọ èrò mi sí
Ṣé Mo Lè Gbé E Sílé?
Kòṣeémánìí
◻ Báwo ló ṣe ń tẹrí ba sí nínú ilé àti nínú ìjọ? —Éfésù 5:21, 22.
◻ Báwo ló ṣe ń ṣe sáwọn ará ilé ẹ̀?—Ẹ́kísódù 20:12.
◻ Àwọn wo ló ń bá rìn?—Òwe 13:20.
◻ Kí lọ̀rọ̀ ẹ̀ máa ń dá lé?—Lúùkù 6:45.
◻ Báwo lọ̀ràn owó ṣe máa ń rí lára ẹ̀?—1 Jòhánù 2:15-17.
◻ Kí làwọn àfojúsùn rẹ̀?—1 Tímótì 4:15.
◻ Ṣó ti ń sapá báyìí láti lé àwọn àfojúsùn yẹn bá?—1 Kọ́ríńtì 9:26, 27.
◻ Irú eré ìnàjú wo ló fẹ́ràn láti máa ṣe?—Sáàmù 97:10.
◻ Báwo ló ṣe ń fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ Jèhófà?—1 Jòhánù 5:3.
Irú Ẹni Tó Yẹ Kó Jẹ́
◻ Ṣé òṣìṣẹ́ kára ni?—Òwe 31:17, 19, 21, 22, 27.
◻ Ṣé kì í náwó nínàákúnàá?—Òwe 31:16, 18.
◻ Ṣé wọ́n máa ń sọ̀rọ̀ ẹ̀ ní rere?—Rúùtù 3:11.
◻ Ṣó máa ń gba tàwọn ẹlòmíì rò?—Òwe 31:20.
Ibi Tí Ìṣòro Ti Lè Jẹ Yọ
◻ Ṣé alásọ̀ ni?—Òwe 21:19.
◻ Ṣó máa ń fẹ́ kó o bá òun ṣèṣekúṣe?—Gálátíà 5:19.
◻ Ṣó máa ń bú èèyàn àbí oníjà ni?—Éfésù 4:31.
◻ Ṣé bí ò bá tíì rọ́tí líle kò lè gbádùn ara ẹ̀?—Òwe 20:1.
◻ Ṣé òjòwú àti onímọ̀-tara-ẹni nìkan ni?—1 Kọ́ríńtì 13:4, 5.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]
Gbogbo bàtà kọ́ ló lè bá ẹ lẹ́sẹ̀ mu, bẹ́ẹ̀ náà sì ni gbogbo àwọn tó ò ń bá pàdé ò lè jẹ́ ọkọ tàbí aya rere fún ẹ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Ṣó o rò pé ó bọ́gbọ́n mu kó o wo ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tinú tòde kó o tó rà á? Ṣé kò wá yẹ kó o ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ bó o bá fẹ́ yan ẹni tó o máa fẹ́!
-
-
Ìgbà Wo Ló Dàṣejù?Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
-
-
ORÍ 4
Ìgbà Wo Ló Dàṣejù?
Òótọ́ àbí irọ́ . . .
Kò sígbà tó dáa káwọn tó ń fẹ́ra wọn sọ́nà fọwọ́ kanra wọn.
□ Òótọ́
□ Irọ́
Báwọn tó ń fẹ́ra wọn sọ́nà ò bá ní ìbálòpọ̀, wọ́n ṣì lè jẹ̀bi àgbèrè.
□ Òótọ́
□ Irọ́
Báwọn tó ń fẹ́ra wọn sọ́nà ò bá tíì máa fẹnu kora wọn lẹ́nu, kí wọ́n sì máa lọ́ mọ́ra, wọn ò lè nífẹ̀ẹ́ ara wọn dénú.
□ Òótọ́
□ Irọ́
KÒ SÍ àníàní pé o lè ti máa da ọ̀rọ̀ yìí rò. Ó ṣe tán, téèyàn bá ti yófẹ̀ẹ́, ó máa ṣòro láti mọ̀ bóyá ọ̀nà téèyàn gbà ń fìfẹ́ hàn sónítọ̀hún ti dàṣejù. Ní báyìí ná, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ lórí àwọn gbólóhùn mẹ́ta tó wà lókè yẹn, ká sì wo bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti dáhùn ìbéèrè náà “Ìgbà wo ló dàṣejù?”
● Kò sígbà tó dáa káwọn tó ń fẹ́ra wọn sọ́nà fọwọ́ kanra wọn.
Irọ́. Bíbélì ò sọ pé kéèyàn má fìfẹ́ hàn sẹ́ni téèyàn nífẹ̀ẹ́, bí ò bá ṣáà ti ní ìwàkiwà nínú. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ọmọbìnrin ará Ṣúnémù kan tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn mọ̀ sí Ṣúlámáítì àti ọ̀dọ́mọkùnrin olùṣọ́ àgùntàn kan tí wọ́n ń fẹ́ra sọ́nà. Wọn ò hùwà tí kò tọ́ nígbà tí wọ́n ń fẹ́ra wọn sọ́nà. Síbẹ̀, ó láwọn ọ̀nà kan tí wọ́n gbà fìfẹ́ hàn síra wọn kí wọ́n tó ṣègbéyàwó. (Orin Sólómọ́nì 1:2; 2:6; 8:5) Lónìí pẹ̀lú, àwọn tó ń fẹ́ra wọn sọ́nà tí wọ́n sì ní in lọ́kàn láti ṣègbéyàwó lè ronú pé ó yẹ káwọn máa fìfẹ́ hàn síra àwọn láwọn ọ̀nà kan tí ò la ìṣekúṣe lọ.a
Àmọ́ ṣá o, àwọn tó ń fẹ́ra wọn sọ́nà gbọ́dọ̀ ṣọ́ra gan-an. Fífẹnu konu, lílọ́ mọ́ra tàbí ṣíṣe ohunkóhun tó lè ru ìfẹ́ fún ìbálòpọ̀ sókè lè yọrí sí àgbèrè. Ó rọrùn fáwọn tó ní in lọ́kàn láti fẹ́ra wọn sílé pàápàá láti hùwà pálapàla torí pé ó máa ń ṣòro láti wà lójúfò.—Kólósè 3:5.
● Báwọn tó ń fẹ́ra wọn sọ́nà ò bá ní ìbálòpọ̀, wọ́n ṣì lè jẹ̀bi àgbèrè.
Òótọ́. Ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí “àgbèrè,” ìyẹn por·neiʹa, pín sí apá tó pọ̀. Ó kan onírúurú ìbálòpọ̀ téèyàn bá ṣe pẹ̀lú ẹni tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya rẹ̀, ó sì ní nǹkan ṣe pẹ̀lú lílo ẹ̀yà ìbímọ nílòkulò. Nítorí náà, kì í ṣe ìbálòpọ̀ nìkan ni àgbèrè. Béèyàn bá ń fọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ ẹlòmíì, téèyàn bá fẹnu lá ẹ̀yà ìbímọ ẹlòmíì, tàbí téèyàn ń gba ihò ìdí bá ẹlòmíì lò pọ̀, àgbèrè náà ni.
Yàtọ̀ síyẹn, àgbèrè nìkan kọ́ ni Bíbélì sọ pé kò dáa. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Àwọn iṣẹ́ ti ara fara hàn kedere, àwọn sì ni àgbèrè, ìwà àìmọ́, ìwà àìníjàánu.” Ó wá fi kún un pé: “Àwọn tí ń fi irúfẹ́ nǹkan báwọ̀nyí ṣe ìwà hù kì yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.”—Gálátíà 5:19-21.
Kí ni “ìwà àìmọ́”? Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí ìwà àìmọ́ túmọ̀ sí ohunkóhun tó lè sọ èèyàn di aláìmọ́, ì bá à jẹ́ ọ̀rọ̀ ẹnu tàbí ìwà. Ó dájú pé ìwà àìmọ́ ni tí ọwọ́ ẹnì kan bá ń rìn gbéregbère lábẹ́ aṣọ ẹlòmíì, tó bọ́ aṣọ onítọ̀hún, tàbí tó ń fọwọ́ pa àwọn ẹ̀yà ara tó wà lábẹ́ aṣọ, irú bí ọmú. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé, àwọn tó ti ṣègbéyàwó nìkan ló lè fọwọ́ pa ọmú ara wọn.—Òwe 5:18, 19.
Àwọn ọ̀dọ́ kan tiẹ̀ máa ń fi àìnítìjú hùwà tí ò bá ìlànà òdodo Ọlọ́run mu. Wọ́n máa ń mọ̀ọ́mọ̀ ti àṣejù bọ̀ ọ́, tàbí kí wọ́n máa kó àfẹ́sọ́nà jọ kí wọ́n lè máa hùwà àìmọ́ tó ní í ṣe pẹ̀lú ìbálòpọ̀ pẹ̀lú wọn. Àwọn tó ń ṣe bẹ́ẹ̀ lè jẹ̀bi ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pè ní “ìwà àìníjàánu.” Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí “ìwà àìníjàánu” tún túmọ̀ sí ‘àṣerégèé, àṣejù, àfojúdi, fífi ìfẹ́ hàn láìkó ara ẹni níjàánu.’ Láìsí àníàní, o ò ní fẹ́ “ré kọjá gbogbo agbára òye ìwà rere” nípa jíjẹ́ kí “ìwà àìníjàánu láti máa fi ìwà ìwọra hu onírúurú ìwà àìmọ́ gbogbo” wọ̀ ẹ́ lẹ́wù.—Éfésù 4:17-19.
● Báwọn tó ń fẹ́ra wọn sọ́nà ò bá tíì máa fẹnu kora wọn lẹ́nu, kí wọ́n sì máa lọ́ mọ́ra, wọn ò lè nífẹ̀ẹ́ ara wọn dénú.
Irọ́. Àwọn kan lè máa rò pé fífìfẹ́ hàn lọ́nà àìtọ́ ló máa ń jẹ́ káàárín àwọn tó ń fẹ́ra wọn sọ́nà gún, àmọ́ ńṣe ló máa jẹ́ kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í wọ́ra wọn nílẹ̀, wọn ò sì ní fọkàn tán ara wọn mọ́. Ronú lórí ìrírí ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Laura. Ó ní: “Lọ́jọ́ kan àfẹ́sọ́nà mi wá sílé wa nígbà tí mọ́mì mi ò sí nílé, mo rò pé kó kàn wo tẹlifíṣọ̀n tán kó dẹ̀ máa lọ ni. Nígbà tó yá ó dì mí lọ́wọ́ mú. Àmọ́, kí n tó mọ nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀, ó ti bẹ̀rẹ̀ sí í fọwọ́ pa mí lára. Ẹ̀rù ń bà mí láti sọ fún un pé kó fi mí sílẹ̀, torí ó lè bínú jáde.”
Kí lo rò? Ṣé àfẹ́sọ́nà Laura fẹ́ràn ẹ̀ ni, àbí ó kàn fẹ́ tẹ́ ara ẹ̀ lọ́rùn? Ṣé ẹni tó fẹ́ jẹ́ kó o hùwà àìmọ́ nífẹ̀ẹ́ ẹ lóòótọ́?
Bí ọmọkùnrin kan bá fòòró ọmọbìnrin kan débi tí ọmọbìnrin náà fi pa ẹ̀kọ́ Kristẹni tó ti kọ́ tì, tó sì ba ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ jẹ́, ọmọkùnrin yẹn ti tẹ òfin Ọlọ́run lójú, kò sì sí ẹ̀rí pé ó nífẹ̀ẹ́ ọmọbìnrin náà dénú. Bí ọmọbìnrin kan bá sì gbàgbàkugbà láyè, ńṣe ló tara ẹ̀ lọ́pọ̀. Èyí tó tún burú jù níbẹ̀ ni pé ó ti hùwà àìmọ́, ó tiẹ̀ lè ti jẹ̀bi àgbèrè pàápàá.b—1 Kọ́ríńtì 6:9, 10.
Ẹ Mọ̀gbà Tí Àṣejù Wọ̀ Ọ́
Bó o bá ti lẹ́ni tó ò ń fẹ́, báwo lo ṣe lè sá fún fífi ìfẹ́ hàn lọ́nà tí kò tọ́? Ohun tó bọ́gbọ́n mu jù lọ ni pé kẹ́ ẹ mọ̀gbà tí àṣejù wọ̀ ọ́. Òwe 13:10 sọ pé: “Ọgbọ́n wà pẹ̀lú àwọn tí ń fikùn lukùn.” Nítorí náà, bá àfẹ́sọ́nà rẹ jíròrò àwọn ọ̀nà tó tọ́ téèyàn lè gbà fìfẹ́ hàn. Bẹ́ ẹ bá lọ dúró dìgbà tára yín ti wà lọ́nà kẹ́ ẹ tó pinnu ìgbà táṣejù wọ̀ ọ́, ńṣe ló máa dà bí ìgbà tẹ́ ẹ dúró dìgbà tí iná di ńlá kẹ́ ẹ tó bẹ̀rẹ̀ sí í bomi pa á.
Ká sòótọ́, irú ìjíròrò bẹ́ẹ̀ kì í rọrùn, ó tiẹ̀ máa ń tini lójú, pàápàá tó bá jẹ́ pé ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ra yín ni. Àmọ́, bẹ́ ẹ bá tètè pinnu ìgbà táṣejù wọ̀ ọ́, kò ní jẹ́ káwọn ìṣòro tó máa ju agbára yín lọ yọjú tó bá yá. Bẹ́ ẹ bá pinnu ìgbà tó lè dàṣejù, ó máa jẹ́ kẹ́ ẹ mọ̀ bẹ́ ẹ bá ti fẹ́ kọjá àyè yín. Yàtọ̀ síyẹn, pé ẹ tiẹ̀ gbọ́n débi tẹ́ ẹ fi lè jíròrò irú ọ̀rọ̀ yẹn lè jẹ́ kẹ́ ẹ mọ̀ bóyá àjọṣe yín á yọrí sí rere. Kódà, ìkóra-ẹni-níjàánu, sùúrù àti àìmọ-tara-ẹni-nìkan máa ń jẹ́ kéèyàn gbádùn ìbálòpọ̀ nínú ìgbéyàwó.—1 Kọ́ríńtì 7:3, 4.
Ká sòótọ́, kò rọrùn láti máa fàwọn ìlànà Ọlọ́run ṣèwà hù. Ṣùgbọ́n o lè gbẹ́kẹ̀ lé ìmọ̀ràn Jèhófà. Ó ṣáà sọ nínú Aísáyà 48:17, pé òun ni “Ẹni tí ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní, Ẹni tí ń mú kí o tọ ọ̀nà tí ó yẹ kí o máa rìn.” Mọ̀ dájú pé Jèhófà ní ire ẹ lọ́kàn!
KA PÚPỌ̀ SÍ I NÍPA ÀKÒRÍ YÌÍ NÍ ORÍ 24 NÍNÚ APÁ KÌÍNÍ ÌWÉ YÌÍ
Pé o ò tíì ní ìbálòpọ̀ rí ò sọ pé o kì í ṣèèyàn gidi. Kódà ìwọ gan-an lo gbọ́n jù. Kà nípa rẹ̀ fúnra rẹ.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Láwọn ibì kan lágbàáyé, kì í ṣe ìwà ọmọlúwàbí táwọn méjì tí ò tíì ṣègbéyàwó bá ń fìfẹ́ hàn síra wọn ní gbangba, kódà ìwà ìdọ̀tí ni. Àwa Kristẹni sì gbọ́dọ̀ ṣọ́ra, ká má lọ máwọn ẹlòmíì kọsẹ̀.—2 Kọ́ríńtì 6:3.
b Tọkùnrin tobìnrin lọ̀rọ̀ tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ tán yìí bá wí.
ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́
“Ìfẹ́ . . . kì í hùwà lọ́nà tí kò bójú mu.”—1 Kọ́ríńtì 13:4, 5.
ÌMỌ̀RÀN
Bíwọ àti àfẹ́sọ́nà ẹ bá fẹ́ jáde, ẹ máa lọ síbi táwọn èèyàn wà, tàbí kẹ́ ẹ máa rí i dájú pé ẹnì kan sìn yín lọ. Ẹ má máa dá wà nínú mọ́tò, nínú yàrá, tàbí nínú ilé àdáni.
ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?
Tó o bá ti lẹ́ni tó ò ń fẹ́, ẹ gbọ́dọ̀ jọ jíròrò àwọn ọ̀rọ̀ tó kàn yín gbọ̀ngbọ̀n. Ṣùgbọ́n ẹ ní láti rántí pé ìwà àìmọ́ ni sísọ àwọn ọ̀rọ̀ àsọrégèé tó ń ru ìfẹ́ fún ìbálòpọ̀ sókè, kódà kó jẹ́ lórí fóònù tàbí fífi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sórí ẹ̀rọ alágbèéká.
OHUN TÍ MÀÁ ṢE!
Mo lè sá fún ìṣekúṣe nípa
Bẹ́ni tí mò ń fẹ́ bá fẹ́ mú mi hùwà àìmọ́, màá
Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni
KÍ LÈRÒ Ẹ?
● Ìgbà wo lo rò pé ìfararora pẹ̀lú ẹni tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tìẹ máa dàṣejù? ․․․․․
● Ṣàlàyé ìyàtọ̀ tó wà láàárín àgbèrè, ìwà àìmọ́ àti ìwà àìníjàánu. ․․․․․
[Ìsọfúnni tó wà ní ojú ìwé 46]
Èmi àti àfẹ́sọ́nà mi ti ka àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí Bíbélì, èyí tó sọ̀rọ̀ nípa béèyàn ṣe lè pa ìwà títọ́ mọ́. A sì mọrírì bí wọ́n ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́.’’—Leticia
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 44]
Bá A Bá Ti Ṣàṣejù Ńkọ́?
Bẹ́ ẹ bá ti ṣèṣekúṣe ńkọ́? Ẹ má ṣe rò pé ẹ lè dá yanjú ọ̀rọ̀ náà láàárín ara yín o! Ọ̀dọ́mọbìnrin kan sọ pé: “Mo máa ń gbàdúrà pé, ‘Ràn wá lọ́wọ́ ká má ṣe dán irú ẹ̀ wò mọ́.’” Ó fi kún un pé: “Ó máa ń ṣiṣẹ́ láwọn ìgbà kan, àmọ́ kì í ṣiṣẹ́ nígbà míì.” Torí náà, ẹ sọ fáwọn òbí yín. Bíbélì náà tún fún wa nímọ̀ràn àtàtà yìí: “Pe àwọn àgbà ọkùnrin ìjọ.” (Jákọ́bù 5:14) Àwọn Kristẹni olùṣọ́ àgùntàn wọ̀nyí lè gbà yín nímọ̀ràn, wọ́n sì lè fìbáwí tọ́ yín sọ́nà kẹ́ ẹ lè pa dà bá Ọlọ́run rẹ́.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 47]
Kò dájú pé wàá dúró dìgbà tí iná bá di ńlá kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí í bomi pa á. Kí nìdí tẹ́ ẹ fi ní láti dúró dìgbà tára yín bá wà lọ́nà kẹ́ ẹ tó ṣòfin ìwà híhù?
-
-
Kí Nìdí Tí Kò Fi Yẹ Kí N Ní Ìbálòpọ̀ Kí N Tó Ṣègbéyàwó?Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
-
-
ORÍ 5
Kí Nìdí Tí Kò Fi Yẹ Kí N Ní Ìbálòpọ̀ Kí N Tó Ṣègbéyàwó?
“Ó máa ń ṣe mí bíi kí ọkùnrin bá mi sùn.”—Kelly.
“Bí mi ò ṣe tíì bá obìnrin sùn rí máa ń ṣe mí bákan.”—Jordon.
“ṢÉ ÌWỌ náà ò tíì ní ìbálòpọ̀ rí?” Ìbéèrè yẹn lè ṣe ẹ́ bákan! Ká sòótọ́, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ibi téèyàn máa dé láyé yìí tí wọn ò ní fojú ọ̀dẹ̀ tí ò rọ́ọ̀ọ́kán wo ọ̀dọ́ tí ò bá tíì ní ìbálòpọ̀ rí. Abájọ tí ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ fi sábà máa ń ní ìbálòpọ̀ kí wọ́n tó pé ọmọ ogún ọdún!
Bó Ṣe Ń Wù Mí Ṣe Làwọn Ojúgbà Mi Náà Ń Tì Mí Sí I
Bó o bá jẹ́ Kristẹni, ìwọ náà mọ̀ pé Bíbélì ní kó o “ta kété sí àgbèrè.” (1 Tẹsalóníkà 4:3) Àmọ́ ó lè má rọrùn fún ẹ láti kápá wíwù tó ń wù ẹ́ láti ní ìbálòpọ̀. Paul sọ pé: “Nígbà míì, màá kàn rí i pé mò ń ronú nípa ìbálòpọ̀ ṣáá, láìnídìí.” Fọkàn ẹ balẹ̀, bó ṣe ń ṣe ọ̀pọ̀ èèyàn náà nìyẹn.
Àmọ́ ṣá o, ó máa ń káàyàn lára gan-an bí wọ́n bá ń fèèyàn ṣe yẹ̀yẹ́ léraléra, tí wọn ò sì yé sọ̀rọ̀ ẹ̀ torí pé kò tíì ní ìbálòpọ̀ rí! Bí àpẹẹrẹ, kí lo máa ṣe báwọn ẹgbẹ́ ẹ bá sọ fún ẹ pé, ó dìgbà tó o bá ní ìbálòpọ̀ kó o tó lè pera ẹ ní ọkùnrin tàbí obìnrin? Ellen sọ pé: “Àwọn ojúgbà ẹ á jẹ́ kó o máa wo ìbálòpọ̀ bí ohun tí kò burú, tó máa ń múnú èèyàn dùn. Bó ò bá tíì máa ṣèṣekúṣe, ńṣe ni wọ́n á máa fojú ẹni tí ò bẹ́gbẹ́ mu wò ẹ́.”
Àmọ́ àwọn nǹkan kan wà nípa níní ìbálòpọ̀ kéèyàn tó ṣègbéyàwó táwọn ojúgbà ẹ lè má sọ fún ẹ. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tí ọmọkùnrin tóun àti Maria jọ ń fẹ́ra bá a sùn tán, Maria sọ pé: “Ojú tì mí wẹ̀lẹ̀mù lẹ́yìn ìgbà yẹn. Mo sì kórìíra ara mí àti bọ̀bọ́ yẹn.” Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ni ò mọ̀ pé ibi tọ́rọ̀ sábà máa ń já sí nìyẹn. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé níní ìbálòpọ̀ kéèyàn tó ṣègbéyàwó sábà máa ń mú kéèyàn ki ìka àbámọ̀ bẹnu, ìbànújẹ́ kékeré sì kọ́ ló máa ń yọrí sí!
Síbẹ̀, ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Shanda béèrè pé, “Kí nìdí tí Ọlọ́run fi fi ìfẹ́ ìbálòpọ̀ sọ́kàn àwọn ọ̀dọ́ nígbà tó mọ̀ pé kò yẹ kí wọ́n ní ìbálòpọ̀ àyàfi bí wọ́n bá ti ṣègbéyàwó?” Ìbéèrè tó mọ́gbọ́n dání nìyẹn. Àmọ́, ronú lórí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ná:
Ṣé ìfẹ́ láti ní ìbálòpọ̀ nìkan lohun tó máa ń wù ẹ́ gan-an? Rárá o. Jèhófà Ọlọ́run ti dá agbára tó máa ń jẹ́ kí oríṣiríṣi nǹkan wu èèyàn mọ́ ẹ.
Ṣé gbogbo nǹkan tó bá ti ń wù ẹ́ náà lo gbọ́dọ̀ máa ṣe lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tó bá ti wá sí ẹ lọ́kàn? Rárá o, ìdí ni pé Ọlọ́run dá ẹ lọ́nà tí wàá fi lè máa darí ara ẹ.
Kí nìyẹn fi kọ́ ẹ? Ẹ̀kọ́ ibẹ̀ ni pé àwọn nǹkan kan wà tí ò lè ṣe kó má wù ẹ́, àmọ́ o lè darí ara rẹ láti mọ ohun tó yẹ kó o ṣe. Àti pé, tó bá jẹ́ pé gbogbo ìgbà tó bá ti ń wùùyàn láti ní ìbálòpọ̀ náà lèèyàn máa ń tẹra ẹ̀ lọ́rùn, ńṣe lèèyàn máa dà bí ẹni tó jẹ́ pé gbogbo ìgbà tínú bá ń bí i ló máa ń lu àwọn èèyàn, ìwà òpònú gbáà nìyẹn.
Òótọ́ kan tí kò ṣeé já ní koro ni pé, Ọlọ́run ò fún wa ní ẹ̀yà ìbímọ torí ká lè máa fi ṣèṣekúṣe. Bíbélì sọ pé: “Kí olúkúlùkù yín mọ bí yóò ti ṣèkáwọ́ ohun èlò tirẹ̀ nínú ìsọdimímọ́ àti ọlá.” (1 Tẹsalóníkà 4:4) Bí “ìgbà nínífẹ̀ẹ́ àti ìgbà kíkórìíra” ṣe wà, bẹ́ẹ̀ náà ni ìgbà tó yẹ kéèyàn ní ìbálòpọ̀ àti ìgbà tí kò yẹ kéèyàn ní in wà. (Oníwàásù 3:1-8) Ju gbogbo ẹ̀ lọ, ìwọ fúnra ẹ lo lè ṣèkáwọ́ ara ẹ!
Àmọ́, kí lo lè ṣe, bí ẹnì kan bá fẹ́ gbọ́ tẹnu ẹ, tó wá sọ bí ẹni tọ́rọ̀ yà lẹ́nu pé, “Ṣóòótọ́ ni pé o ò tíì ní ìbálòpọ̀ rí?” Máà jẹ́ kí wọ́n ko ẹ láyà jẹ. Bó bá jẹ́ pé ẹni yẹn kàn fẹ́ wọ́ ẹ nílẹ̀ lásán ni, o lè fèsì pé: “Hẹn, mi ò tíì ṣe é rí, ojú ò sì tì mí láti sọ ọ́!” O sì tún lè sọ pé, “Èmi ni mo mọ̀yẹn lọ́kàn ara mi, mi ò kì ń sọ ọ́ síta.”a (Òwe 26:4; Kólósè 4:6) Bó o bá sì wá rí i pé ó yẹ kẹ́ni yẹn mọ púpọ̀ sí i lóòótọ́, o lè ṣàlàyé àwọn ohun tó o mọ̀ látinú Bíbélì, tó mú kó o pinnu láti má ṣe ní ìbálòpọ̀, àyàfi bó o bá ṣègbéyàwó.
Kí lo tún lè sọ fẹ́ni tó bá bi ẹ́, torí àtigbọ́ tẹnu ẹ, pé: “Ṣó ò tíì ní ìbálòpọ̀ rí lóòótọ́ ni?” Kọ èsì tó o tún lè fún un sórí ìlà yìí.
․․․․․
Ẹ̀bùn Tó Ṣeyebíye
Irú ojú wo ni Ọlọ́run fi máa ń wo àwọn tó bá ń bára wọn sùn láì tíì ṣègbéyàwó? Ó dáa, jẹ́ ká sọ pe o ra ẹ̀bùn kan fún ọ̀rẹ́ rẹ kan. Àmọ́, ọ̀rẹ́ rẹ yẹn ò dúró kó o fún òun lẹ́bùn yẹn tó fi ṣí i wò! Ṣéyẹn ò ní bí ẹ nínú? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, wo bó ṣe máa rí lójú Ọlọrun, bó o bá ní ìbálòpọ̀ kó o tó ṣègbéyàwó. Ọlọ́run fẹ́ kó o dúró dìgbà tó o bá ṣègbéyàwó kó o tó gbádùn ẹ̀bùn ìbálòpọ̀ tó fún ẹ.—Jẹ́nẹ́sísì 1:28.
Kí ló wá yẹ kó o ṣe nípa ìfẹ́ láti ní ìbálòpọ̀ tó máa ń wá sí ẹ lọ́kàn? Ńṣe ni wàá kọ́ bó ò ṣe ní jẹ́ kírú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ mú ẹ ṣe ohun tí kò tọ́! Agbára ẹ sì gbé e láti ṣe bẹ́ẹ̀! Gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́. Ẹ̀mí rẹ̀ á fún ẹ lókun láti máa kóra ẹ níjàánu. (Gálátíà 5:22, 23) Má gbàgbé pé, Jèhófà “kì yóò fawọ́ ohunkóhun tí ó dára sẹ́yìn lọ́dọ̀ àwọn tí ń rìn ní àìlálèébù.” (Sáàmù 84:11) Ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Gordon sọ pé: “Nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí wá sí mi lọ́kàn pé kò sóhun tó burú nínú kéèyàn ní ìbálòpọ̀ láì tíì ṣègbéyàwó, mo ronú lórí bó ṣe máa mú kí n pàdánù ojúure Jèhófà, mo wá rí i pé kò sóhun tí mo lè fi wé àjọṣe tó wà láàárín èmi àti Jèhófà.”
Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, kò sóhun tó burú nínú ẹ̀ béèyàn ò bá ní ìbálòpọ̀ kó tó ṣègbéyàwó. Ìṣekúṣe ló burú jáì, kò yẹ ọmọlúwàbí rárá, àkóbá tó sì ń ṣe fáwọn èèyàn ò mọ níwọ̀n. Torí náà, má ṣe jẹ́ kí wọ́n firọ́ tàn ẹ́ jẹ, kó o wá lọ máa ronú pé ìlànà Bíbélì tó ò ń tẹ̀ lé ni ò jẹ́ kó o mọ ohun tó ò ń ṣe. Bó o bá kọ̀ láti ní ìbálòpọ̀ kó o tó ṣègbéyàwó, o ò ní í kó àrùn, ọkàn ẹ ò sì ní máa dá ẹ lẹ́bi. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, wàá ní àjọṣe tó dán mọ́ràn pẹ̀lú Ọlọ́run.
KA PÚPỌ̀ SÍ I NÍPA ÀKÒRÍ YÌÍ NÍ ORÍ 23, NÍNÚ APÁ KÌÍNÍ ÌWÉ YÌÍ
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a O ò rí i pé, Jésù pàápàá ò sọ̀rọ̀ nígbà tí Hẹ́rọ́dù béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀. (Lúùkù 23:8, 9) Ohun tó máa ń dáa jù ni pé kéèyàn má fèsì bí wọ́n bá bi í ní ìbéèrè tí kò mọ́gbọ́n dání.
ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́
“Bí ẹnikẹ́ni bá ti pinnu . . . nínú ọkàn-àyà ara rẹ̀, láti pa ipò wúńdíá tirẹ̀ mọ́, òun yóò ṣe dáadáa.”—1 Kọ́ríńtì 7:37.
ÌMỌ̀RÀN
Má ṣe bá àwọn tí kò níwà ọmọlúwàbí rìn, àní bó bá tiẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀sìn kan náà lẹ jọ ń ṣe.
ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?
Ìgbéyàwó ò ní kí ẹni tó bá ti sọ ìṣekúṣe dàṣà tẹ́lẹ̀ yí pa dà. Àmọ́ àwọn tó bá ti mọ́ lára láti máa tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run kí wọ́n tó ṣègbéyàwó, kì í sábà yẹ àdéhùn ìgbéyàwó wọn.
OHUN TÍ MÀÁ ṢE!
Kí n má bàa ní ìbálòpọ̀ kí n tó ṣègbéyàwó, ohun tí màá ṣe ni pé ․․․․․
Báwọn tí mò ń bá rìn ò bá fẹ́ jẹ́ kí n ṣe ohun tí mo ti pinnu yìí, ohun tí màá ṣe ni pé ․․․․․
Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․
KÍ LÈRÒ Ẹ?
● Kí lo rò pé ó fà á táwọn kan fi máa ń fàwọn tí kò bá tíì ní ìbálòpọ̀ rí ṣe yẹ̀yẹ́?
● Kí ló lè mú kó ṣòro láti wà láìní ìbálòpọ̀?
● Àwọn àǹfààní wo ló wà nínú kéèyàn má tíì ní ìbálòpọ̀ kó tó ṣègbéyàwó?
● Báwo lo ṣe máa ṣàlàyé fún àbúrò ẹ pé ọ̀pọ̀ àǹfààní ló wà nínú kéèyàn má tíì ní ìbálòpọ̀ kó tó ṣègbéyàwó?
[Ìsọfúnni tó wà ní ojú ìwé 51]
“Bí mo bá ti ń rántí pé ‘kò sí alágbèrè kankan tàbí aláìmọ́ tí ó ní ogún èyíkéyìí nínú ìjọba Ọlọ́run,’ ńṣe ni mo máa ń gbọ́kàn kúrò lórí ìbálòpọ̀.” (Éfésù 5:5)—Lydia
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 49]
Tí mo kọ èrò mi sí
Kí Ló Máa Ṣẹlẹ̀ Gan-an?
Àwọn ojúgbà ẹ, àwọn eléré àtàwọn olórin kì í sábà sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, tó bá kan àwọn àkóbá tí ìbálòpọ̀ láàárín àwọn tí kò tíì ṣègbéyàwó máa ń fà. Wo àwọn àpẹẹrẹ mẹ́ta yìí, kí lo rò pé ó máa ṣẹlẹ̀ sáwọn ọ̀dọ́ wọ̀nyí gan-an? ․․․․․
● Ọmọléèwé ẹ kan ń ṣakọ pé àìmọye ọmọbìnrin lòun ti bá sùn. Ó ní àwọn jọ gbádùn ara àwọn ni, nǹkan kan ò sì ṣe ẹnì kankan nínú àwọn. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sóun àtàwọn ọmọbìnrin yẹn gan-an? ․․․․․
● Nígbà tí wọ́n máa parí fíìmù kan, àwọn ọ̀dọ́ méjì tí kò tó ọmọ ogún ọdún bára wọn sùn láti fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn. Tó bá jẹ́ pé ojú ayé ni, kí ló lè tẹ̀yìn ẹ̀ yọ gan-an? ․․․․․
● O rí bọ̀bọ́ kan tó dáa lọ́mọkùnrin, ó sì ní kó o jẹ́ kóun bá ẹ sùn. Ó ní kò sẹ́ni táá mọ̀. Bó o bá gbà fún un, tíwọ náà sì ṣẹnu mẹ́rẹ́n, kí ló máa ṣẹlẹ̀ gan-an? ․․․․․
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 54]
Bó o bá ń ní ìbálòpọ̀ láì tíì ṣègbéyàwó, ńṣe ló dà bí ìgbà tó ò ń ṣí ẹ̀bùn tí wọn ò tíì fún ẹ wò
-