ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • yp2 orí 2 ojú ìwé 21-27
  • Kí Ló Burú Nínú Fífẹ́ra Sọ́nà Ní Bòókẹ́lẹ́?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ló Burú Nínú Fífẹ́ra Sọ́nà Ní Bòókẹ́lẹ́?
  • Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìdí Táwọn Kan Fi Ń Ṣe É
  • “Wọ́n Ní Ká Ṣe É Lọ́rọ̀ Àṣírí”
  • Ohun Tó Burú Nínú Fífẹ́ra Sọ́nà ní Bòókẹ́lẹ́
  • Bó O Ṣe Lè Jẹ́ Kí Ẹlòmíì Mọ̀
  • Ṣé Ọ̀rọ̀ Àṣírí Ni àbí Ẹ Ò Tíì Fẹ́ Káwọn Míì Mọ̀?
  • “Mo Mọ Ohun Tó Yẹ Kí N Ṣe”
  • Kí Ló Burú Nínú Bíbára Ẹni Jáde Ní Bòókẹ́lẹ́?
    Jí!—2007
  • Ìgbà Wo Ló Yẹ Kí N Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Bá Ẹni Tí Kì Í Ṣe Ọkùnrin Tàbí Obìnrin Bíi Tèmi Jáde?
    Jí!—2007
  • Ṣó Ti Yẹ Kí N Lẹ́ni Tí Mò Ń Fẹ́?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
  • Ṣé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ní Òfin tí Wọ́n Máa Ń Tẹ̀ Lé tí Wọ́n Bá Ń Fẹ́ra Sọ́nà?
    Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Sábà Máa Ń Béèrè Nípa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
Àwọn Míì
Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
yp2 orí 2 ojú ìwé 21-27

ORÍ 2

Kí Ló Burú Nínú Fífẹ́ra Sọ́nà Ní Bòókẹ́lẹ́?

Jessica ò tiẹ̀ wá mohun tí ì bá ṣe mọ́ báyìí. Jẹ́jẹ́ ẹ̀ ló jókòó tọ́mọ kíláàsì ẹ̀ kan tó ń jẹ́ Jeremy bẹ̀rẹ̀ sí í ta sí i. Jessica fúnra ẹ̀ sọ pé: “Ọmọkùnrin dáa síbẹ̀, àwọn ọ̀rẹ́ mi sì sọ pé èèyàn bíi tiẹ̀ ṣọ̀wọ́n. Ọ̀pọ̀ ọmọbìnrin ti wá bí wọ́n á ṣe bá a da nǹkan pọ̀, àmọ́ kò wojú wọn. Èmi nìkan ló ṣáà lóun fẹ́ràn.”

Kò pẹ́ sígbà tá à ń wí yìí tí Jeremy fi sọ fún Jessica pé kó jẹ́ káwọn máa fẹ́ra. Jessica ṣàlàyé fún un pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà lòun, òun ò sì ní lè fẹ́ ẹni tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Jessica sọ pé: “Jeremy lóun mọ ọgbọ́n tá a máa dá sí i. Ó wá bi mí pé, ‘Bá a bá ń fẹ́ra wa láìjẹ́ káwọn òbí ẹ mọ̀ ńkọ́?’”

BÍ ẸNÌ kan tó gba tìẹ bá dá irú àbá yìí, kí lo máa ṣe? Ó lè yà ẹ́ lẹ́nu láti gbọ́ pé Jessica gbà láti máa fẹ́ Jeremy. Ó ní: “Ó dá mi lójú pé bí èmi àti ẹ̀ bá ń fẹ́ra wa, mo lè sọ ọ́ dẹni tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà.” Ibo lọ̀rọ̀ náà wá já sí o? Ká ṣì máa bọ́rọ̀ bọ̀ ná. Àmọ́, jẹ́ ká kọ́kọ́ wo ohun tó fà á táwọn ọ̀dọ́ kan fi kó sínú pańpẹ́ fífẹ́ ara wọn sọ́nà ní bòókẹ́lẹ́.

Ìdí Táwọn Kan Fi Ń Ṣe É

Kí nìdí táwọn kan fi ń fẹ́ra wọn sọ́nà ní bòókẹ́lẹ́? Ọ̀dọ́mọkùnrin kan tó ń jẹ́ David dáhùn ìbéèrè yìí ní ṣókí pé, “Wọ́n mọ̀ pé àwọn òbí àwọn ò ní gbà, torí náà wọn kì í sọ fún wọn.” Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Jane tún sọ nǹkan míì tó lè fà á. Ó ní: “Fífẹ́ra sọ́nà ní bòókẹ́lẹ́ jẹ́ ọ̀nà táwọn ọ̀dọ́ kan gbà ń fi hàn pé àwọn fẹ́ dá dúró láyè ara àwọn. Béèyàn bá ti ń wo ara ẹ̀ bí àgbà, àmọ́ tí wọn ò yé fojú ọmọdé wò ó, ẹnu kó máa gbé ohun tó bá fẹ́ ṣe gbẹ̀yìn àwọn òbí ẹ̀ ni.”

Kí lo tún rò pé ó lè fà á táwọn ọ̀dọ́ kan fi máa ń fẹ́ra wọn ní bòókẹ́lẹ́? Kọ ọ́ síbí yìí.

․․․․․

Ìwọ náà kúkú mọ àṣẹ tí Bíbélì pa, pé kó o máa gbọ́ràn sáwọn òbí ẹ lẹ́nu. (Éfésù 6:1) Báwọn òbí ẹ bá wá sọ pé àwọn ò tíì fẹ́ kó o máa fẹ́ ẹnì kankan báyìí, ó dájú pé wọ́n mohun tí wọ́n ń sọ. Àmọ́, má ṣe jẹ́ kó yà ẹ́ lẹ́nu bó o bá bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé:

● Mi ò rẹ́ni bá rìn torí pé gbogbo èèyàn ló lẹ́ni tí wọ́n ń fẹ́ àfèmi nìkan.

● Ẹnì kan tí ẹ̀sìn ẹ̀ yàtọ̀ sí tèmi ni mo nífẹ̀ẹ́ sí.

● Ó wù mí kí n máa fẹ́ ẹnì kan tó jẹ́ Kristẹni bíi tèmi bí mi ò tiẹ̀ tíì tó ẹni tó yẹ kó ṣègbéyàwó.

Ó ṣeé ṣe kó o mọ ohun táwọn òbí ẹ máa sọ nípa àwọn nǹkan tó ò ń rò lọ́kàn yìí. Ìwọ náà sì mọ̀ nínú ọkàn ẹ lọ́hùn-ún pé òótọ́ ni wọ́n ń sọ. Síbẹ̀, ọ̀rọ̀ tìẹ náà lè rí bíi ti ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Manami, ó sọ pé: “Ńṣe lọ̀rọ̀ wíwá ẹnì kan fẹ́ máa ń gbà mí lọ́kàn débi tí mo fi máa ń rò pé bóyá kémi náà kúkú máa fẹ́ bọ̀bọ́ kan. Ó ṣòro kéèyàn rí ọ̀dọ́ kan láyé yìí tó máa sọ pé òun ò lẹ́ni tóun ń fẹ́. Kò sí ìgbádùn kankan nínú kémi nìkan máa dá wà!” Àwọn kan tọ́rọ̀ wọn rí bá a ṣe sọ yìí ti bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ ẹnì kan, wọn ò sì jẹ́ káwọn òbí wọn mọ̀ nípa ẹ̀. Báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀?

“Wọ́n Ní Ká Ṣe É Lọ́rọ̀ Àṣírí”

Gbólóhùn yẹn, “fífẹ́ra sọ́nà ní bòókẹ́lẹ́” fi hàn pé ìtànjẹ kan wà ńbẹ̀. Káwọn ẹlòmíì má bàa mọ̀ pé àwọn kan ń fẹ́ra wọn sọ́nà, orí fóònù tàbí Íńtánẹ́ẹ̀tì ni wọ́n ti sábà máa ń bára wọn sọ̀rọ̀. Wọ́n á kàn máa bára wọn ṣọ̀rẹ́ lásán lójú ayé, àmọ́ nǹkan míì pátápátá lọ̀rọ̀ tí wọ́n máa ń sọ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì àti lórí fóònù wọn.

Ọgbọ́n míì táwọn kan tún máa ń dá ni pé wọ́n á ṣètò pé káwọn bíi mélòó kan jọ pàdé fún nǹkan kan, ọkùnrin àtobìnrin á sì wá dọ́gbọ́n múra wọn ní méjì méjì kúrò níbẹ̀. James sọ pé: “Lọ́jọ́ kan báyìí, àwọn kan ní káwa mélòó kan jọ pàdé níbì kan, nígbà tá a débẹ̀, a wá rí i pé àjọmọ̀ àwọn tó pè wá ni pé káwa ọkùnrin tá a wà níbẹ̀ mú àwọn obìnrin tó wà níbẹ̀ níkọ̀ọ̀kan. Wọ́n ní ká ṣe é lọ́rọ̀ àṣírí.”

Bí James ṣe sọ, ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tó ń fẹ́ra wọn ní bòókẹ́lẹ́ máa ń ṣe ọ̀rọ̀ náà láṣìírí láàárín ara wọn àtàwọn ọ̀rẹ́ wọn. Carol sọ pé: “Ó kéré tán, ọ̀rẹ́ wa kan sábà máa ń mọ̀ nípa ẹ̀, àmọ́ ńṣe ló máa ṣẹnu fúrú, torí gbogbo wa ti gbà pé ‘bójú bá rí ẹnu a dákẹ́.’” Nígbà míì sì rèé, irọ́ pátápátá làwọn míì máa ń pa. Beth tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17] sọ pé: “Dípò káwọn ọ̀dọ́ kan sọ ibi tí wọ́n bá gbà lọ, irọ́ ni wọ́n máa ń pa fáwọn òbí wọn, kí wọ́n má bàa mọ̀ pé wọ́n ti ń fẹ́ ẹnì kan.” Ohun tí Misaki tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19] ṣe nìyẹn. Ó sọ pé: “Mo máa ń ronú odù tí màá gbé kalẹ̀ dáadáa. Mo sì máa ń ṣọ́ra kí n má parọ́ lórí àwọn ọ̀rọ̀ míì, àyàfi lórí ọ̀rọ̀ tó bá jẹ mọ́ ẹni tí mò ń fẹ́ kó má lọ di pé àwọn òbí mi á máa mú mi lónírọ́.”

Ohun Tó Burú Nínú Fífẹ́ra Sọ́nà ní Bòókẹ́lẹ́

Bó bá ń ṣe ẹ́ bíi kó o máa fẹ́ ẹnì kan sọ́nà ní bòókẹ́lẹ́, tàbí tó o bá ti ń ṣe bẹ́ẹ̀, ó yẹ kó o béèrè lọ́wọ́ ara ẹ pé:

Ibo lọ̀rọ̀ yìí máa já sí? Ṣó o ní in lọ́kàn láti fẹ́ onítọ̀hún láìpẹ́ láìjìnnà? Evan, tó jẹ́ ọmọ ogún [20] ọdún, sọ pé: “Bó o bá ń fẹ́ ẹnì kan láìjẹ́ pé o ti ṣe tán láti ṣègbéyàwó, ńṣe ló dà bí ìgbà tó ò ń polówó ọjà tó o kì í tà.” Ibo lọ̀rọ̀ náà lè já sí? Òwe 13:12 sọ pé: “Ìfojúsọ́nà tí a sún síwájú ń mú ọkàn-àyà ṣàìsàn.” Ṣé wàá fẹ́ kí ọkàn ẹni tó o fẹ́ràn ṣàìsàn? Nǹkan míì tó o ní láti ṣọ́ra fún rèé: Bó o bá ń fẹ́ ẹnì kan ní bòókẹ́lẹ́, ìyẹn ò ní jẹ́ kó o rí ìmọ̀ràn onífẹ̀ẹ́ táwọn òbí ẹ àtàwọn àgbàlagbà míì máa fẹ́ fún ẹ lórí ọ̀rọ̀ náà gbà. Bó ò bá sì gba irú àwọn ìmọ̀ràn wọ̀nyẹn, o lè lọ ṣèṣekúṣe.—Gálátíà 6:7.

Ojú wo ni Jèhófà Ọlọ́run fi ń wo ohun tí mò ń ṣe? Bíbélì sọ pé: “Ohun gbogbo wà ní ìhòòhò àti ní ṣíṣísílẹ̀ gbayawu fún ojú ẹni tí a óò jíhìn fún.” (Hébérù 4:13) Torí náà, bó o bá ń fẹ́ ẹnì kan ní bòókẹ́lẹ́ tàbí tó o bá ń bo ọ̀rẹ́ ẹ kan tó ń ṣe bẹ́ẹ̀ láṣìírí, jẹ́ kó yé ẹ pé ojú Jèhófà tó ohun tó ò ń ṣe o. Bó bá sì jẹ́ pé ńṣe lò ń tan àwọn òbí ẹ, a jẹ́ pé ó yẹ kó o túbọ̀ yẹra ẹ wò. Jèhófà Ọlọ́run kì í fojúure wo irọ́ pípa o. Kódà, gbangba gbàǹgbà ni Bíbélì mẹ́nu ba “ahọ́n èké” gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn nǹkan tí Ọlọ́run kórìíra!—Òwe 6:16-19.

Bó O Ṣe Lè Jẹ́ Kí Ẹlòmíì Mọ̀

O lè wá rí i báyìí pé, ó máa dáa kó o jẹ́ káwọn òbí ẹ tàbí Kristẹni kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀ mọ̀ nípa àjọṣe bòókẹ́lẹ́ èyíkéyìí tó o bá ní. Bó o bá sì lọ́rẹ̀ẹ́ tó ń fẹ́ ẹnì kan ní bòókẹ́lẹ́, má ṣe bá a bo ohun tí ò ṣeé bò. (1 Tímótì 5:22) Àbí, báwo ló ṣe máa rí lára ẹ bí irú àjọṣe bẹ́ẹ̀ bá lọ já síbi tí ò dáa? Ṣéwọ náà ò ní pín díẹ̀ nínú ẹ̀bi ẹ̀?

Jẹ́ ká ṣàpèjúwe ẹ̀ báyìí: Ká sọ pé ọ̀rẹ́ ẹ kan tó lárùn àtọ̀gbẹ ń jẹ mindin-mín-ìndìn ní kọ̀rọ̀. Ni àṣírí ẹ̀ bá tú sí ẹ lọ́wọ́, àmọ́ ó bẹ̀ ẹ́ pé kó o má sọ fẹ́ni kẹ́ni. Kí ló máa ká ẹ lára jù nínú ọ̀rọ̀ náà, ṣé bíbò tó o fẹ́ bá ọ̀rẹ́ ẹ bo ọ̀rọ̀ náà ni àbí kó o gba ẹ̀mí ẹ̀ là?

Bó ṣe yẹ kó rí náà nìyẹn bó o bá mọ̀ pé àwọn kan ń fẹ́ra wọn ní bòókẹ́lẹ́. Ìwọ gbàgbé ti pé ìyẹn lè bá àárín yín jẹ́. Bó pẹ́ bó yá, ọ̀rẹ́ tòótọ́ á mọ̀ pé tòun lò ń ṣe.—Sáàmù 141:5.

Ṣé Ọ̀rọ̀ Àṣírí Ni àbí Ẹ Ò Tíì Fẹ́ Káwọn Míì Mọ̀?

Òótọ́ kan ni pé, kì í ṣe gbogbo àwọn tó ń fẹ́ra wọn sọ́nà ní bòókẹ́lẹ́ ni wọn ò mọ ohun tí wọ́n ń ṣe o. Bí àpẹẹrẹ, ká ní ọ̀dọ́kùnrin àti ọ̀dọ́bìnrin kan tí wọ́n ti tó ṣègbéyàwó ń fẹ́ láti túbọ̀ mọ ara wọn, wọ́n lè pinnu pé títí dìgbà táwọn á fi mọra àwọn dáadáa, àwọn ò tíì fẹ́ káwọn míì mọ̀. Ó sì lè jẹ́ pé ohun tó fà á, gẹ́gẹ́ bí ọmọkùnrin kan tó ń jẹ́ Thomas ṣe sọ, ni pé, “wọn ò fẹ́ káwọn èèyàn máa yọ wọ́n lẹ́nu nípa bíbéèrè pé, ‘Ìgbà wo lẹ máa wá ṣègbéyàwó?’”

Káwọn ẹlòmíì máa kó gìrìgìrì báni ní ìpalára tó ń ṣe lóòótọ́. (Orin Sólómọ́nì 2:7) Torí náà, nígbà tí ọkùnrin kan àti obìnrin kan bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí fẹ́ra sọ́nà, wọ́n lè máà tíì fẹ́ kí gbogbo èèyàn mọ̀. (Òwe 10:19) Anna, ọmọ ogún [20] ọdún sọ pé: “Mímọ̀ tí wọn ò tíì fẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ báyìí máa jẹ́ kí wọ́n ní àkókò tó pọ̀ tó láti mọ̀ bóyá wọ́n á lè fẹ́ra. Bó bá ti wá dá wọn lójú, nígbà náà, wọ́n lè jẹ́ káyé gbọ́.”

Kò sì tún ní bójú mu pé kó o fi ọ̀rọ̀ ìwọ àtẹni tẹ́ ẹ jọ ń fẹ́ra pa mọ́ fáwọn tó yẹ kí wọ́n mọ̀ nípa ẹ̀, irú bí àwọn òbí ẹ àtàwọn òbí ẹni tó ò ń fẹ́ sọ́nà. Ká sòótọ́, bó bá ṣòro fún ẹ láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ ẹni tó ò ń fẹ́, a jẹ́ pé nǹkan míì wà ńbẹ̀ nìyẹn. Ṣéwọ náà mọ̀ lọ́kàn ara ẹ pé ìdí pàtàkì kan wà táwọn òbí ẹ ò fi ní fara mọ́ ọn?

“Mo Mọ Ohun Tó Yẹ Kí N Ṣe”

Jessica, tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí ò fẹ́ Jeremy mọ́ nígbà tó gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí arábìnrin kan tóun àtẹnì kan jọ ń fẹ́ra ní bòókẹ́lẹ́. Jessica sọ pé: “Lẹ́yìn tí mo gbọ́ ohun tí arábìnrin yẹn ṣe láti fòpin sí àjọṣe òun àti onítọ̀hùn, kíá ni mo mọ ohun tó yẹ kí n ṣe.” Ṣó rọrùn láti fòpin sírú àjọṣe bẹ́ẹ̀? Rárá o! Jessica sọ pé: “Ká sòótọ́, mo fẹ́ràn ọmọkùnrin yẹn gan-an. Ó tó ọ̀sẹ̀ bíi mélòó kan tí mo fi ń sunkún lójoojúmọ́.”

Ohun mìíràn tí Jessica tún mọ̀ ni pé òun nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, àti pé bó tiẹ̀ jẹ́ pé òun fìgbà díẹ̀ ṣe ohun tí kò tọ́, òun ṣì ń fẹ́ láti ṣe ohun tó tọ́. Bọ́jọ́ ti ń gorí ọjọ́, ìrònú nípa ọmọkùnrin yẹn kúrò lọ́kàn ẹ̀. Jessica wá sọ pé: “Àjọṣe àárín èmi àti Jèhófà ti wá dáa ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó ń fún wa ní ìtọ́sọ́nà tá a nílò ní àkókò tá a bá nílò rẹ̀ gẹ́lẹ́!”

NÍNÚ ORÍ TÓ KÀN

Ká ló o ti tó ẹni tó ń ní àfẹ́sọ́nà, tó o sì ti rí ẹnì kan tó o fẹ́ràn. Báwo lo ṣe máa mọ̀ bóyá ẹni tó yẹ kó o fẹ́ nìyẹn?

ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́

‘À ń dàníyàn láti máa hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo.’—Hébérù 13:18.

ÌMỌ̀RÀN

Kì í ṣe pé wàá máa lọ sọ ẹni tó ò ń fẹ́ fún gbogbo ayé o. Àmọ́ ó yẹ kó o sọ fáwọn tó yẹ kó mọ̀ nípa ẹ̀. Ìyẹn sì kan àwọn òbí ẹ àti òbí ẹni tó ò ń fẹ́.

ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?

Òdodo ló lè mú kí àjọṣe àárín ìwọ àtàwọn òbí ẹ tọ́jọ́. Bó o bá ń fẹ́ ẹnì kan ní bòókẹ́lẹ́, àwọn òbí ẹ ò ní fọkàn tán ẹ, ìyẹn sì lè mú kẹ́ni tó ò ń fẹ́ náà máa ṣiyè méjì nípa ẹ.

OHUN TÍ MÀÁ ṢE!

Bí èmi àti Kristẹni bíi tèmi bá ń fẹ́ra wa ní bòókẹ́lẹ́, ohun tí màá ṣe ni pé ․․․․․

Bí ọ̀rẹ́ mi bá ń fẹ́ ẹnì kan ní bòókẹ́lẹ́, ohun tí màá ṣe ni pé ․․․․․

Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․

KÍ LÈRÒ Ẹ?

● Ronú lórí gbólóhùn mẹ́ta tá a fi lẹ́tà tó dúdú yàtọ̀ kọ lójú ìwé 22. Èwo nínú wọn ló bá bí nǹkan ṣe máa ń rí lára ẹ mu?

● Kí lo lè ṣe nípa àwọn ọ̀rọ̀ náà láìjẹ́ pé o lọ ń fẹ́ ẹnì kan ní bòókẹ́lẹ́?

● Bó o bá mọ̀ pé ọ̀rẹ́ ẹ kan ń fẹ́ ẹnì kan ní bòókẹ́lẹ́, kí lo máa ṣe, kí sì nìdí tó o fi máa ṣe bẹ́ẹ̀?

[Ìsọfúnni tó wà ní ojú ìwé 27]

Mi ò fẹ́ bọ̀bọ́ yẹn ní bòókẹ́lẹ́ mọ́. Àmọ́ kò rọrùn, bí mo bá ti ń rí i níléèwé lójoojúmọ́ báyìí ló máa ń ṣe mí bíi pé kí n tún lọ bá a. Jèhófà ló mọ ohun táwa ò mọ̀. Àfi ká gbẹ́kẹ̀ lé e.’’—Jessica

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Bó o bá ń bá ọ̀rẹ́ ẹ kan tó ń fẹ́ ẹnì kan ní bòókẹ́lẹ́ ṣe ọ̀rọ̀ ọ̀hún láṣìírí, ńṣe ló dà bí ìgbà tó ò ń bo ọ̀ràn ẹni tó lárùn àtọ̀gbẹ àmọ́ tó ń kó mindin-mín-ìndìn jẹ ní kọ̀rọ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́