ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w12 2/1 ojú ìwé 25
  • Ṣé Aayé Yìí Máa Pa Run?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Aayé Yìí Máa Pa Run?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Ilẹ̀ Ayé Máa Pa Run?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ilẹ̀ Ayé Yóò Ha Jóná Lúúlúú Bí?
    Jí!—1997
  • Ohun Tí Ọjọ́ Jèhófà Máa Ṣí Payá
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Ìdáhùn sí Ìbéèrè Mẹ́rin Nípa Òpin Ayé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
w12 2/1 ojú ìwé 25

Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé . . .

Ṣé Aayé Yìí Máa Pa Run?

▪ Àwọn èèyàn kan rò pé ayé yìí máa pa run ní October 21, ọdún 2011. Àmọ́, ayé kò pa run. Torí náà àsọtẹ́lẹ̀ Harold Camping tó jẹ́ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ orí rédíò ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà kò ṣẹ. Ó sọ tẹ́lẹ̀ pé Ọjọ́ Ìdájọ́ máa wáyé ní May 21, ọdún 2011, pé ìmìtìtì ilẹ̀ tó fakíki kan máa ṣẹlẹ̀ kárí ayé àti pé oṣù márùn-ún lẹ́yìn náà, ìyẹn ní October 21, ayé máa pa run.

Àmọ́, ayé yìí kò ní pa run láé. Ẹlẹ́dàá ayé kò ní jẹ́ kó pa run. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ pé: “Ìwọ ti fi ilẹ̀ ayé sọlẹ̀ gbọn-in gbọn-in, kí ó lè máa bá a nìṣó ní dídúró.”—Sáàmù 119:90.

Àmọ́, àwọn kan tó ń ka Bíbélì lè sọ pé iná ló máa pa ayé wa yìí run. Wọ́n tọ́ka sí 2 Pétérù 3:7, 10 láti fi ti ọrọ̀ wọn lẹ́yìn. Ó sọ pé: “Nípa ọ̀rọ̀ kan náà, àwọn ọ̀run àti ilẹ̀ ayé tí ó wà nísinsìnyí ni a tò jọ pa mọ́ fún iná, a sì ń fi wọ́n pa mọ́ de ọjọ́ ìdájọ́ àti ti ìparun àwọn ènìyàn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run. . . . Síbẹ̀ ọjọ́ Jèhófà yóò dé gẹ́gẹ́ bí olè, nínú èyí tí àwọn ọ̀run yóò kọjá lọ pẹ̀lú ariwo tí ó dún ṣì-ì-ì, ṣùgbọ́n àwọn ohun ìpìlẹ̀ tí ó ti gbóná janjan yóò di yíyọ́, ilẹ̀ ayé àti àwọn iṣẹ́ tí ń bẹ nínú rẹ̀ ni a ó sì wá rí.” Ṣé ohun tí ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pétérù túmọ̀ sí gan-gan nìyẹn?

Rárá o, ohun tó túmọ̀ sí kọ́ nìyẹn. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé ìtúmọ̀ àwọn ẹsẹ yìí gbọ́dọ̀ bá ohun tí ọ̀rọ̀ Pétérù dá lé nínú lẹ́tà yẹn mu, ó sì gbọ́dọ̀ bá ohun tí àwọn ìwé Bíbélì yòókù sọ mu. Bí a bá wo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn lóréfèé, ó máa túmọ̀ sí pé iná máa jó ayé àtọ̀run pátápátá, ìyẹn ọ̀kẹ́ àìmọye ìràwọ̀ àtàwọn nǹkan míì torí pé àwọn èèyàn búburú ń gbé nínú ayé. Ṣé wàá kó yẹ̀pẹ̀ etíkun tó lọ salalu dà nù torí hóró yẹ̀pẹ̀ kan ṣoṣo tí o kò fẹ́? Ìyẹn kò ní bọ́gbọ́n mu! Lọ́nà kan náà, Jèhófà kò ní pa ayé àtọ̀run tó dá run torí pé àwọn kàn ṣọ̀tẹ̀ lára àwọn tó wà nínú ayé.

Yàtọ̀ síyẹn, èrò yìí ta ko ohun tí Jésù Kristi sọ, ó ní: “Aláyọ̀ ni àwọn onínú tútù, níwọ̀n bí wọn yóò ti jogún ilẹ̀ ayé.” (Mátíù 5:5; Sáàmù 37:29) Ǹjẹ́ bàbá onífẹ̀ẹ́ kan lè fi ọwọ́ ara rẹ̀ kọ́ ilé kan tó tura fún ìdílé rẹ̀ lẹ́yìn náà kó wá fi iná sun ilé ọ̀hún? (Sáàmù 115:16) Ìyẹn ò bọ́gbọ́n mu rárá! Kì í ṣe pé Jèhófà jẹ́ Ẹlẹ́dàá nìkan, àmọ́ ó tún jẹ́ Bàbá onífẹ̀ẹ́.—Sáàmù 103:13; 1 Jòhánù 4:8.

Pétérù lo ọ̀rọ̀ náà “ilẹ̀ ayé” lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, láti tọ́ka sí àwùjọ èèyàn, ìyẹn àwọn èèyàn búburú. Kíyè sí i pé Pétérù fi ohun tó máa ṣẹlẹ̀ yẹn wé ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ìgbà Ìkún-omi ọjọ́ Nóà. (2 Pétérù 3:5, 6) Nígbà yẹn, àwọn èèyàn búburú nìkan ló pa run, ayé fúnra rẹ̀ àti Nóà tó jẹ́ olóòótọ́ àti ìdílé rẹ̀ yè bọ́. Lọ́nà kan náà, a jẹ́ pé “àwọn ọ̀run” ìṣàpẹẹrẹ ni Pétérù ń sọ. Ní ti “àwọn ọ̀run,” ó dúró fún ìjọba èèyàn. Torí náà, àwọn èèyàn búburú tí wọ́n kọ̀ láti yí pa dà kò ní sí mọ́, bákan náà gbogbo ìjọba búburú kò ní sí mọ́, ìṣàkóso tàbí Ìjọba Ọlọ́run láti ọ̀run sì máa rọ́pò rẹ̀.—Dáníẹ́lì 2:44

Nítorí náà, ṣé ayé yìí máa pa run? Rárá o. Ohun tó máa pa run ni ayé ìṣàpẹẹrẹ, ìyẹn àwọn èèyàn búburú. Ayé yìí àtàwọn èèyàn tí á máa ṣègbọràn sí Ọlọ́run lọ́jọ́ iwájú máa wà títí láé.—Òwe 2:21, 22.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́