ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w12 2/1 ojú ìwé 26-27
  • Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Ní Ètò Kan?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Ní Ètò Kan?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Ní Ètò Kan?
    Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run!
  • Ǹjẹ́ Ọlọ́run Ní Ètò Kan Tó Gbé Kalẹ̀?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Ǹjẹ́ Ó Pọn Dandan Kó O Dara Pọ̀ Mọ́ Ẹ̀sìn Kankan?
    Jí!—2012
  • Ọlọ́run Ètò Ni Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
w12 2/1 ojú ìwé 26-27

Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Ní Ètò Kan?

Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìbéèrè tó o ti lè máa béèrè, a sì tún sọ ibi tó o ti lè rí ìdáhùn wọn kà nínú Bíbélì rẹ. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti bá ẹ sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìdáhùn náà.

1. Kí nìdí tí Ọlọrun fi ṣètò àwọn ọmọ Ísírẹ́lì?

Ọlọ́run sọ àwọn àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù baba ńlá di orílẹ̀-èdè kan, ó sì fún wọn ní àwọn òfin. Ọlọ́run pe orílẹ̀-èdè yẹn ní Ísírẹ́lì, ó sì fi ìjọsìn tòótọ́ àti Ìwé Mímọ́ tó jẹ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ síkàáwọ́ wọn. (Sáàmù 147:19, 20) Èyí sì ti ṣe àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè láǹfààní.—Ka Jẹ́nẹ́sísì 22:18.

Ọlọ́run yan àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti jẹ́ ẹlẹ́rìí rẹ̀. Nígbà tí wọ́n bá ṣègbọràn, wọ́n máa ń jàǹfààní látinú àwọn òfin Ọlọ́run. (Diutarónómì 4:6) Tí a bá gbé ìtàn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yẹ̀ wò, a máa kọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa Ọlọ́run tòótọ́.—Ka Aísáyà 43:10, 12.

2. Kí nìdí tí àwọn Kristẹni tòótọ́ fi jẹ́ ètò kan?

Níkẹyìn, orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì pàdánù ojú rere Ọlọ́run, Jèhófà sì fi ìjọ Kristẹni rọ́pò rẹ̀. (Mátíù 21:43; 23:37, 38) Tẹ́lẹ̀, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni Ẹlẹ́rìí fún Ọlọ́run. Àmọ́, lónìí, àwọn Kristẹni tòótọ́ ni Ẹlẹ́rìí fún Jèhófà.—Ka Ìṣe 15:14, 17.

Jésù ṣètò àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti jẹ́rìí nípa Jèhófà kí wọ́n sì sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn. (Mátíù 10:7, 11; 24:14; 28:19, 20) Iṣẹ́ yìí ti fẹ́rẹ̀ẹ́ parí. Fún ìgbà àkọ́kọ́, Jèhófà ti mú kí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn èèyàn láti inú gbogbo orílẹ̀-èdè wà níṣọ̀kan nínú ìjọsìn tòótọ́. (Ìṣípayá 7:9, 10) Jésù tún ṣètò àwọn Kristẹni tòótọ́ kí wọ́n bàa lè máa fún ara wọn níṣìírí kí wọ́n sì ran ara wọn lọ́wọ́. Kárí ayé, ẹ̀kọ́ Bíbélì kan náà ni wọ́n máa ń kọ́ láwọn ìpàdé wọ́n.—Ka Hébérù 10:24, 25.

3. Báwo ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà òde òní ṣe bẹ̀rẹ̀?

Ètò àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà òde òní bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 1870 sí 1879. Àwùjọ kékeré kan tí wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàwárí àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tí kò yé àwọn èèyàn tẹ́lẹ̀. Wọ́n ṣàwárí pé Jésù ṣètò ìjọ Kristẹni láti máa wàásù. Nítorí náà, wọ́n dáwọ́ lé iṣẹ́ ìwàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run kárí ayé. Láti ọdún 1931 ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ́ orúkọ náà, Ẹlẹ́rìí Jèhófà.—Ka Ìṣe 1:8; 2:1, 4; 5:42.

4. Báwo ni a ṣe ṣètò àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lóde òní?

Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àwọn ìjọ Kristẹni ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀ jàǹfààní láti ọ̀dọ̀ ìgbìmọ̀ olùdarí tó gbà pé Jésù ni Orí ìjọ. (Ìṣe 16:4, 5) Bákan náà lónìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà pé Jésù ni Aṣáájú àwọn. (Mátíù 23:9, 10) Wọ́n tún ń jàǹfààní ìtọ́sọ́nà látọ̀dọ̀ àwọn alàgbà onírìírí tí wọ́n jẹ́ Ìgbìmọ̀ Olùdarí, tí wọ́n ń pèsè ìṣírí àti ìtọ́sọ́nà láti inú Bíbélì fún àwọn ìjọ tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún [100,000]. Ní ìjọ kọ̀ọ̀kan, àwọn ọkùnrin tó kúnjú ìwọ̀n jẹ́ alàgbà tàbí alábòójútó. Àwọn ọkùnrin yìí ń bójú tó agbo Ọlọ́run tìfẹ́tìfẹ́.—Ka 1 Pétérù 5:2, 3.

A ṣètò àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti wàásù ìhìn rere kí wọ́n sì sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. Kí wọ́n lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ níbi gbogbo, wọ́n ń túmọ̀ èdè, wọ́n ń tẹ ìwé, wọ́n sì ń pín àwọn ìwé tí a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fúnni ní èdè tí ó lé ní ọgọ́rùn-ún márùn-ún [500]. Wọ́n máa ń wàásù láti ilé dé ilé bíi ti àwọn àpọ́sítélì. (Ìṣe 20:20) Wọ́n ń fẹ́ kọ́ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ ní ẹ̀kọ́ Bíbélì. Nítorí pé àwọn èèyàn Jèhófà gbájú mọ́ ṣíṣe ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́, tí wọ́n sì ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, wọ́n jẹ́ ètò kan tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀, wọ́n sì láyọ̀.—Ka Sáàmù 33:12; Ìṣe 20:35.

Fún ìsọfúnni síwájú sí i, ka orí 19 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́