Ayẹyẹ Ìkẹ́kọ̀ọ́yege Kíláàsì Kọkànléláàádóje Ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì
“Mú Inú Jèhófà Dùn”
ÀWỌN ẹbí, ọ̀rẹ́ àtàwọn míì pé jọ síbi ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege kíláàsì kọkànléláàádóje ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì ní September 10, ọdún 2011. Ní àárọ̀ ọjọ́ yẹn, ara àwọn olùbánisọ̀rọ̀ àti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà wà lọ́nà. Àmọ́, nígbà tí ayẹyẹ náà parí, ńṣe ni ará tu gbogbo àwọn ẹgbẹ̀rún mẹ́sàn-án àti mẹ́tàlélọ́gọ́ta [9,063] èèyàn tó wà níbẹ̀, tí inú wọ́n sì ń dùn nítorí pé wọ́n ti gbádùn àwọn àsọyé, àṣefihàn àti ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò tó wáyé níbẹ̀.
Arákùnrin Stephen Lett tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tó sì jẹ́ alága ayẹyẹ náà ló sọ ọ̀rọ̀ àkọ́kọ́. Ó ṣàyẹ̀wò àwọn ẹsẹ Bíbélì tó sọ pé Jèhófà Ọlọ́run ní ara ìṣàpẹẹrẹ, ó sì ṣàlàyé àwọn ẹsẹ Bíbélì tó sọ bí Jèhófà ṣe ń lo ojú, etí, ọwọ́ àti apá ìṣàpẹẹrẹ rẹ̀.
Olùbánisọ̀rọ̀ náà kọ́kọ́ ṣàgbéyẹ̀wò 2 Kíróníkà 16:9, tó sọ pé “ojú [Jèhófà] ń lọ káàkiri ní gbogbo ilẹ̀ ayé láti fi okun rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí ọkàn-àyà wọn pé pérépéré síhà ọ̀dọ̀ rẹ̀.” Ó gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà níyànjú pé kí wọ́n máa fi ọkàn tó pé pérépéré sin Jèhófà nígbà gbogbo. Ó sọ fún wọn pé bí wọ́n ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Ọlọ́run ni pé kí wọ́n máa wo ibi tí àwọn èèyàn dára sí. Lẹ́yìn náà Arákùnrin Lett sọ̀rọ̀ lórí 1 Pétérù 3:12, tó sọ pé etí Jèhófà ṣí sí ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ àwọn olódodo. Ó rọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà pé kí wọ́n máa gbàdúrà sí Jèhófà, kí wọ́n rántí pé Jèhófà múra tán láti fetí sí àdúrà wọn.
Olùbánisọ̀rọ̀ náà tún ṣàyẹ̀wò Aísáyà 41:13, níbi tí Jèhófà ti ṣèlérí pé: “Èmi, Jèhófà Ọlọ́run rẹ, yóò di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú, Ẹni tí ń wí fún ọ pé, ‘Má fòyà. Èmi fúnra mi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́.’” Arákùnrin Lett wá sọ látọkàn wá pé: “Ẹ kíyè sí ọ̀rọ̀ tó wọni lọ́kàn tí Jèhófà sọ yìí. Ó na ọwọ́ rẹ̀ kí ó bàa lè di ọwọ́ wa mú.” Ó wá sọ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà pé kí wọ́n jẹ́ kí Jèhófà máa ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbà gbogbo, kí wọ́n má sì kọ ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ láé. Ó tún sọ pé bí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà ni pé kí wọ́n máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́.
Nígbà tí Arákùnrin Lett fẹ́ parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ó ka Aísáyà 40:11. Ó ní kí àwùjọ fojú inú wo ọwọ́ jẹ̀lẹ́ńkẹ́ tí Jèhófà fi ń mú wa gẹ́gẹ́ bí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn ṣe sọ. Arákùnrin Lett sọ pé: “Jèhófà ń fi apá rẹ̀ kó wa jọ. Ó ń gbé wa sí oókan àyà rẹ̀.” Kí ló yẹ ká ṣe? Ó gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà nímọ̀ràn pé kí wọ́n fara balẹ̀ kí wọ́n sì ṣe jẹ́jẹ́ bí ọ̀dọ́ àgùntàn ti máa ń ṣe, kó bàa lè wu Jèhófà láti gbé wọn sí oókan àyà rẹ̀.
“Àwa Ní Ìṣúra Yìí Nínú Àwọn Ohun Èlò Tí A Fi Amọ̀ Ṣe”
Arákùnrin David Splane tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣàlàyé àkòrí yìí tó wá látinú Ìwé Mímọ́. (2 Kọ́ríńtì 4:7) Kí ni ìṣúra yìí? Ṣé ìmọ̀ ni tàbí ọgbọ́n? Olùbánisọ̀rọ̀ náà dáhùn pé: “Rárá o. Ìṣúra tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ rẹ̀ ni ‘iṣẹ́ òjíṣẹ́ yìí,’ ìyẹn ni, ‘fífi òtítọ́ hàn kedere.’” (2 Kọ́ríńtì 4:1, 2, 5) Arákùnrin Splane rán àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà létí pé oṣù márùn-ún tí wọ́n fi kẹ́kọ̀ọ́ ti múra wọn sílẹ̀ fún àkànṣe iṣẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Ojú pàtàkì ni wọ́n gbọ́dọ̀ fi wo iṣẹ́ náà.
Olùbánisọ̀rọ̀ náà ṣàlàyé pé “àwọn ohun èlò tí a fi amọ̀ ṣe” dúró fún ara èèyàn. Ó sọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín ohun èlò tí a fi amọ̀ ṣe àti èyí tí a fi wúrà ṣe. Àwọn ohun èlò tí a fi wúrà ṣe kì í sábà wà fún iṣẹ́. Àmọ́, iṣẹ́ ni àwọn ohun èlò tí a fi amọ̀ ṣe wà fún. Bí a bá fi ìṣúra kan sínú ohun èlò tí a fi wúrà ṣe, ojú iyebíye tí a fi ń wo ìṣura náà la máa fi wo ohun èlò tí a fi wúrà ṣe náà. Arákùnrin Splane wá sọ pé: “Kí ẹ̀yin akẹ́kọ̀ọ́ má ṣe pe àfiyèsí sí ara yín. Bí ẹ ṣe ń ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì, ọ̀dọ̀ Jèhófà ni kí ẹ dárí àwọn èèyàn sí. Ohun èlò tí a fi amọ̀ ṣe ni yín, ẹ mọ̀wọ̀n ara yín.”
Nígbà tí olùbánisọ̀rọ̀ náà ń bá àfiwé rẹ̀ lọ, ó sọ pé lákòókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì, àwọn ohun èlò kan wà tí a fi amọ̀ ṣe tí kì í jóná, àwọn kan sì ní ohun tó ń dán tí kì í jẹ́ kí wọ́n fọ́. Kí nìyẹn wá kọ́ wa? Ní àwọn oṣù tí wọ́n máa kọ́kọ́ lò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wọn, kò sí àní-àní pé àwọn míṣọ́nnárì yẹn máa dojú kọ àwọn ìṣòro tó máa kọ́ wọn ní ìfaradà. Àríwísí táwọn èèyàn bá ń ṣe sí wọn kò ní dùn wọ́n, wọn kò sì ní máa tètè bínú. Arákùnrin Splane sọ pé: “Ẹ máa wá rí i pé ìfaradà yín á pọ̀ ju bí ẹ ṣe rò lọ.” Jèhófà kò fi iṣẹ́ ìwàásù tó ṣeyebíye yìí lé àwọn áńgẹ́lì lọ́wọ́, àmọ́ àwa èèyàn tá a jẹ́ ohun èlò tí a fi amọ̀ ṣe ló gbé e lé lọ́wọ́. Olùbánisọ̀rọ̀ náà wá parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Èyí fi hàn pé Jèhófà fọkàn tán yín.”
‘Ìwọ Ti Bá Àwọn Ẹlẹ́sẹ̀ Sáré, Ṣé O Lè Bá Àwọn Ẹṣin Sá Eré Ìje?’
Arákùnrin Samuel Herd tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà béèrè pé, “Báwo lo ṣe lè sáré tó? Ibo lo sì lè sáré dé?” Kí nìdí tó fi bi àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ní ìbéèrè yìí? Olùbánisọ̀rọ̀ náà fi ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà wé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wòlíì Jeremáyà. Ó ṣòro fún ọkùnrin olóòótọ́ yẹn láti fara da àwọn ìṣòro tó dé bá a. Àmọ́ àwọn ìṣòro tó ṣì máa dé bá a máa le ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Torí náà, Jèhófà bi í pé: “Nítorí pé ìwọ ti bá àwọn ẹlẹ́sẹ̀ sáré, wọ́n sì kó àárẹ̀ bá ọ, báwo wá ni ìwọ ṣe lè bá àwọn ẹṣin sá eré ìje?”—Jeremáyà 12:5.
Nígbà tí Arákùnrin Herd ń sọ bí ẹsẹ Bíbélì yìí ṣe kan àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà, ó sọ pé: “Gbogbo ìdánwò tí ẹ ti ṣe lè mú kí ẹ rò pé ẹ ti ń bá àwọn ẹṣin sáré. Àmọ́, òótọ́ ibẹ̀ ni pé àwọn ẹlẹ́sẹ̀, ni ẹ ti ń bá sáré, kì í ṣe ẹṣin. Ní ibi tí a yàn yín sí láti máa wàásù, ẹṣin ni ẹ ó máa bá sáré, tàbí ẹ ó dojú kọ àwọn ìṣòro tó ju èyí tí ẹ lè ronú kàn ní báyìí. Ṣé ẹ máa lè ṣe àṣeyọrí? Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì ti dá yín lẹ́kọ̀ọ́ láti máa bá ẹṣin sáré láìṣàárẹ̀.” Ó gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà níyànjú pé kí wọ́n máa fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dá ara wọn lẹ́kọ̀ọ́ nìṣó, kí wọ́n ṣètò àkókò láti máa fi kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti láti máa gbàdúrà.
Arákùnrin Herd sọ pé lọ́jọ́ iwájú àwọn kan lára àwọn tí wọ́n rán lọ ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì máa rẹ̀wẹ̀sì tàbí kí àwọn tí wọ́n fẹ́ wàásù fún dágunlá sí iṣẹ́ wọn. Àìsàn máa kó ìdààmú bá àwọn míì tàbí kí wọ́n máa rò pé agbára àwọn kò gbé e mọ́. Àmọ́, ó fi dá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà lójú pé wọ́n á rí okun gbà láti borí ipò búburú yòówù kí wọ́n bá ara wọn, wọn kò sì ní ṣàárẹ̀. Olùbánisọ̀rọ̀ náà sọ pé: “Ì báà jẹ́ àwọn ẹlẹ́sẹ̀ tàbí ẹṣin lẹ̀ ń bá sáré, jẹ́ kó dá yín lójú pé ọwọ́ Ọlọ́run tó lágbára á ràn yín lọ́wọ́ láti ṣàṣeyọrí. Ẹ ó sì di míṣọ́nnárì tó ṣe àṣeyọrí tó sì mú ìyìn àti ògo bá Jèhófà.”
Àwọn Kókó Míì Nínú Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Náà
“Má Fi Mọ sí Díẹ̀.” Arákùnrin John Ekrann tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka Ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, jíròrò àkọsílẹ̀ tó sọ nípa wòlíì Èlíṣà àti opó kan tí wọ́n fẹ́ gba àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀, tí wọ́n sì fẹ́ ta àwọn ọmọ náà ṣe ẹrú. (2 Àwọn Ọba 4:1-7) Ìṣà kékeré kan ni opó náà ní tó lè da òróró sí. Èlíṣà sọ fún obìnrin náà pé kó lọ gba àwọn ìṣà sí i lọ́wọ́ àwọn aládùúgbò rẹ̀, ó ní: “Má fi mọ sí díẹ̀.” Nípasẹ̀ Èlíṣà, lọ́nà ìyanu Jèhófà fi òróró kún gbogbo ìṣà tí opó náà lọ gbà. Opó náà wá ta òróró náà, owó tó sì rí gbà tó láti san gbèsè tó jẹ, kí ó sì fi bójú tó ìdílé rẹ̀ fún ìgbà díẹ̀.
Ẹ̀kọ́ wo ni àwọn tó máa tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ míṣọ́nnárì lè rí kọ́ látinú ìtàn yìí? Nígbà tí opó yẹn lọ gba àwọn ìṣà sí i kò dájú pé èyí tó wù ú nìkan ló gbà. Olùbánisọ̀rọ̀ náà sọ pé: “Gbogbo ìṣà tó lè gba òróró ló máa kó wá, èyí tó bá tóbi gan-an ló jọ pé ó dáa jù.” Arákùnrin Ekrann wá gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà níyànjú pé kí wọ́n gba iṣẹ́ èyíkéyìí tí wọ́n bá fún wọn, yálà ó kéré tàbí ó tóbi. Ó ní, “Má ṣe máa mú èyí tó bá wù ẹ́ nìkan.” Ó tún rán àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà létí pé bí opó náà ṣe tẹ̀ lé ìtọ́ni tí Èlíṣà fún un tó, bẹ́ẹ̀ náà ni ìbùkún tó rí gbà ṣe pọ̀ tó. Ẹ̀kọ́ wo ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà rí kọ́ nínú èyí? Bí ìtara àti ìgbàgbọ́ tí a ní bá ṣe pọ̀ tó, bẹ́ẹ̀ náà ni ìbùkún tá a máa rí gbà ṣe máa pọ̀ tó. Olùbánisọ̀rọ̀ náà sọ pé: “Ẹ má fàyè gba ìmẹ́lẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ yín.”
“Oúnjẹ Ni Wọ́n Jẹ́ fún Wa.” Arákùnrin William Samuelson tó jẹ́ alábòójútó Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Ẹ̀kọ́ Ètò Ọlọ́run, ló sọ̀rọ̀ lórí kókó yìí tá a mú látinú ìwé Númérì 14:9. Ó sọ̀rọ̀ nípa àpẹẹrẹ tó dára tí Jóṣúà àti Kálébù fi lélẹ̀. Ọ̀rọ̀ náà “oúnjẹ” bí wọ́n ṣe lò ó nínú ẹsẹ Bíbélì yẹn fi hàn pé ó máa rọrùn láti ṣẹ́gun àwọn olùgbé Kénáánì àti pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà máa gbé orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ró, ó sì máa fún wọn lókun. Ẹ̀kọ́ wo làwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà rí kọ́? Olùbánisọ̀rọ̀ náà sọ pé: “Ẹ máa wo àwọn ìṣòro tẹ́ ẹ máa bá pà dé lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run lọ́jọ́ iwájú bí ohun tó máa fún yín lókun tó sì máa gbé yín ró.”
“Ǹjẹ́ Wọ́n Lè Fi Ìdákọ̀ró So Ọkọ̀ Ìgbàgbọ́ Wọn Mọ́lẹ̀ Nígbà Tí Ìjì Bá Dé?” Arákùnrin Sam Roberson tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ wọn sọ̀rọ̀ nípa ìkìlọ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe pé àwọn kan ti “ní ìrírí rírì ọkọ̀ ìgbàgbọ́ wọn.” (1 Tímótì 1:19) Ó rọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà pé kí wọ́n kọ́ àwọn ẹlòmíì láti ní ìgbàgbọ́ tó dúró ṣinṣin nínú Jèhófà Ọlọ́run, bí ìgbà tí ìdákọ̀ró bá so ọkọ̀ òkun kan mọ́lẹ̀ ṣinṣin. Ó sọ pé: “A lè fi iṣẹ́ yín wé ti alágbẹ̀dẹ.” Lọ́nà wo? Alágbẹ̀dẹ máa ń jó irin roboto mọ́ra láti fi ṣe ẹ̀wọ̀n tí ó jẹ́ ìdákọ̀ró tí kì í jẹ́ kí omi gbé ọkọ̀ òkun lọ. Lọ́nà kan náà, àwọn míṣọ́nnárì máa ń ran àwọn tí wọ́n ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ láti ní àwọn ìwà tí inú Jèhófà dùn sí tó máa mú kí wọ́n ní ìgbàlà.
Olùbánisọ̀rọ̀ náà fi ìsokọ́ra àwọn irin roboto tí wọ̀n fi ṣe ẹ̀wọ̀n wé àwọn ohun mẹ́jọ tó wà nínú 2 Pétérù 1:5-8. Arákùnrin Roberson sọ pé bí àwọn míṣọ́nnárì bá jẹ́ kí àwọn tí wọ́n ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ àwọn ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà lo àwọn nǹkan yìí, àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà á lè wà pẹ́ títí. Wọ́n á kojú ìpọ́njú èyíkéyìí tó dà bí ìjì tó lè dán ìgbàgbọ́ wọn wò.
Àwọn Ìrírí àti Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò
Arákùnrin Michael Burnett, olùkọ́ míì ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì ní kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà sọ díẹ̀ lára àwọn ìrírí tí wọ́n ní lẹ́nu àìpẹ́ yìí nínú iṣẹ́ ìwàásù, kí wọ́n sì ṣe àṣefihàn àwọn ìrírí náà. Inú àwọn tó pé jọ síbi ayẹyẹ náà dùn láti gbọ́ bí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ṣe wàásù ní ilé ìtajà ńlá kan, ní pápá ọkọ̀ òfuurufú, láti ilé dé ilé àti pàápàá bí wọ́n ṣe wàásù lórí fóònù fún ẹnì kan tó ṣi nọ́ńbà pè.
Arákùnrin Michael Hansen tó jẹ́ ara Ìdílé Bẹ́tẹ́lì orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà wá fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu arákùnrin mẹ́ta tí wọ́n ti ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì fún ọ̀pọ̀ ọdún. Àwọn ni Stephen McDowell tó ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì ní orílẹ̀-èdè Panama, Mark Noumair ní orílẹ̀-èdè Kẹ́ńyà àti William Yasovsky ní orílẹ̀-èdè Paraguay. Ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ ṣàlàyé àkòrí tí wọ́n pe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò náà, ìyẹn “Bí O Ṣe Lè Rí Ìdùnnú Nínú Ṣíṣe Ìfẹ́ Jèhófà.” (Sáàmù 40:8) Bí àpẹẹrẹ, Arákùnrin Mark Noumair sọ àwọn ohun pàtó tó múnú òun àti ìyàwó rẹ̀ dùn níbi tí wọ́n yàn wọ́n sí láti máa wàásù. Ohun tó ń fún wọn láyọ̀ ni bí wọ́n ṣe di ọ̀rẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà níbi tí wọ́n yàn wọ́n sí. Ohun mìíràn tó tún fún tọkọtaya yìí láyọ̀ ni bí wọ́n ṣe rí i tí àwọn arákùnrin àti arábìnrin wọn ń tẹ̀ lé ìtọ́ni, tí wọ́n ń ṣe àwọn ìyípadà pàtàkì ní ìgbésí ayé wọn, wọ́n sì tún kíyè sí bí Jèhófà ṣe mú kí ìsapá wọn yọrí sí rere. Ó fi dá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà lójú pé àwọn ohun tó máa fún wọn láyọ̀ jù lọ ṣì wà lọ́jọ́ iwájú.
Lẹ́yìn tí ọ̀kan lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kíláàsì kọkànléláàádóje náà ka lẹ́tà ìmọrírì tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà kọ lọ́nà tó wúni lórí, Arákùnrin Lett parí ayẹyẹ náà nípa fífún àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege náà ní ìṣírí pé kí wọ́n máa fọgbọ́n hùwà. Ó ní tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n máa “mú inú Jèhófà dùn.” Ó dájú pé àwọn míṣọ́nnárì náà máa mú inú Jèhófà dùn bí wọ́n ṣe ń fi ìṣòtítọ́ sin Ọlọ́run níbi tí wọ́n yàn wọ́n sí láti máa wàásù.—Aísáyà 65:19.
[Àtẹ Ìsọfúnnni/Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 31]
ÌSỌFÚNNI NÍPA KÍLÁÀSÌ
10 iye orílẹ̀-èdè táwọn akẹ́kọ̀ọ́ ti wá
34.7 ìpíndọ́gba ọjọ́ orí wọn
19.0 ìpíndọ́gba ọdún tí wọ́n ti ṣèrìbọmi
13.5 ìpíndọ́gba ọdún tí wọ́n ti lò nínú ìṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún
[Àwòrán ilẹ̀]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
A rán kíláàsì tó kẹ́kọ̀ọ́ yege yìí lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè tó wà nísàlẹ̀ yìí
IBI TÍ A RÁN ÀWỌN MÍṢỌ́NNÁRÌ LỌ
BENIN
BRAZIL
BULGARIA
BÙRÚŃDÌ
KAMẸRÚÙNÙ
KÁNÁDÀ
CENTRAL AFRICAN REPUBLIC
JÁMÁNÌ
GÁNÀ
HONG KONG
INDONESIA
KẸ́ŃYÀ
LÀÌBÉRÍÀ
LITHUANIA
MALAYSIA
MÒSÁŃBÍÌKÌ
NEPAL
PANAMA
PARAGUAY
SIERRA LEONE
SLOVAKIA
SOUTH AFRICA
ORILẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ
FẸNẸSÚÉLÀ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì ṣe àṣefihàn ọ̀kan lára ìrírí tí wọ́n ní nígbà tí wọ́n ń wàásù
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Kíláàsì Kọkàndínláàádóje Tó Kẹ́kọ̀ọ́ Yege ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì
A to nọ́ńbà ìlà kọ̀ọ̀kan láti iwájú lọ sẹ́yìn, a sì to orúkọ láti ọwọ́ òsì lọ sí ọwọ́ ọ̀tún lórí ìlà kọ̀ọ̀kan.
(1) Lesch, C.; Lesch, N.; Shakarjian, P.; Shakarjian, T.; Budden, R.; Budden, K.; Nash, T.; Nash, L.
(2) Tremblay, E.; Tremblay, C.; Garvey, D.; Garvey, G.; Gaunt, R.; Gaunt, P.; Lau, J.; Lau, J.
(3) Davis, S.; Davis, S.; Sargeant, J.; Sargeant, J.; Fonseca, C.; Fonseca, S.; Thenard, E.; Thenard, A.
(4) Petratyotin, A.; Petratyotin, R.; Reyes, N.; Reyes, N.; Eisiminger, B.; Eisiminger, S.; Hacker, J.; Hacker, C.
(5) Hartman, E.; Hartman, T.; Goolia, W.; Goolia, K.; Thomas, J.; Thomas, E.; Okazaki, N.; Okazaki, M.
(6) Mills, C.; Mills, A.; Benning, L.; Benning, T.; Sobiecki, S.; Sobiecki, T.; Gagnon, L.; Gagnon, E.
(7) Hansen, B.; Hansen, M.; Fahie, A.; Fahie, M.; Dalgaard, J.; Dalgaard, J.; Andersson, M.; Andersson, R.