Orin 32
Ẹ Fẹsẹ̀ Múlẹ̀ Ṣinṣin!
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Hílàhílo ti dé bá aráyé.
Wọ́n ńbẹ̀rù ohun táá ṣẹlẹ̀ láyé.
Ó yẹ káwa fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin,
Ká fòótọ́ sin Ọlọ́run.
(ÈGBÈ)
Ó yẹ ká dúró ṣinṣin;
Ká ta kété sáyé yìí,
Báa ti ńkẹ́kọ̀ọ́ òótọ́;
pa ìwà títọ́ mọ́.
2. Ìdẹkùn òun ìdẹwò pọ̀ láyé.
A lè borí táa bá ńlo làákàyè.
Táa bá di òtítọ́ Ọlọ́run mú,
Yóò yọ wá nínú ewu.
(ÈGBÈ)
Ó yẹ ká dúró ṣinṣin;
Ká ta kété sáyé yìí,
Báa ti ńkẹ́kọ̀ọ́ òótọ́;
pa ìwà títọ́ mọ́.
3. Máa jọ́sìn Ọlọ́run látọkàn wá.
Ká lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ Olúwa.
Wàásù ìhìn rere, dìí mú ṣinṣin.
Ayé yìí máa tó dópin.
(ÈGBÈ)
Ó yẹ ká dúró ṣinṣin;
Ká ta kété sáyé yìí,
Báa ti ńkẹ́kọ̀ọ́ òótọ́;
pa ìwà títọ́ mọ́.
(Tún wo Lúùkù 21:9; 1 Pét. 4:7.)