-
“Nǹkan Wọ̀nyí Gbọ́dọ̀ Ṣẹlẹ̀”Ilé Ìṣọ́—1999 | May 1
-
-
“Nǹkan Wọ̀nyí Gbọ́dọ̀ Ṣẹlẹ̀”
“Jésù wí fún wọn pé: ‘. . . Nǹkan wọ̀nyí gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n òpin kì í ṣe ìsinsìnyí.’”—MÁTÍÙ 24:4-6.
1. Kókó ẹ̀kọ́ wo ló yẹ kó gba àfiyèsí wa?
ÓDÁJÚ pé ọ̀ràn ìgbésí ayé rẹ àti ọjọ́ ọ̀la rẹ jẹ ẹ́ lọ́kàn. Nígbà náà, ó yẹ kóo nífẹ̀ẹ́ nínú kókó ẹ̀kọ́ kan tó gba àfiyèsí C. T. Russell nígbà yẹn lọ́hùn-ún, lọ́dún 1877. Russell, tó wá dá ẹgbẹ́ Watch Tower Society sílẹ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ló kọ ìwé náà, The Object and Manner of Our Lord’s Return. Ìwé pẹlẹbẹ olójú ìwé mẹ́rìnlélọ́gọ́ta yìí dá lórí ìpadàbọ̀ Jésù, tàbí bíbọ̀ Jésù ní ọjọ́ iwájú. (Jòhánù 14:3) Nígbà kan tí Jésù wà lórí Òkè Ólífì, àwọn àpọ́sítélì lọ béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ nípa ìpadàbọ̀ náà, wọ́n bi í pé: “Nígbà wo ni nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹlẹ̀, kí ni yóò sì jẹ́ àmì wíwàníhìn-ín rẹ [tàbí, “wíwá,” King James Version] àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan?”—Mátíù 24:3.
2. Èé ṣe tí ọ̀pọ̀ èrò tó ta kora fi wà nípa ohun tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀?
2 Ǹjẹ́ o mọ ìdáhùn Jésù, ǹjẹ́ ìdáhùn náà yé ọ? A lè rí i nínú mẹ́ta lára àwọn ìwé Ìhìn Rere. Ọ̀jọ̀gbọ́n D. A. Carson sọ pé: “Gbogbo àwọn orí Bíbélì tó fa awuyewuye láàárín àwọn alálàyé Bíbélì kò tó nǹkan kan rárá táa bá fi wọ́n wé awuyewuye tí Mátíù orí kẹrìnlélógún, Máàkù orí kẹtàlá àti Lúùkù orí kọkànlélógún fà.” Lẹ́yìn náà, ọ̀jọ̀gbọ́n yìí wá sọ èrò tirẹ̀—tó tún jẹ́ òmíràn nínú àwọn èrò èèyàn tó máa ń takora. Ní ọ̀rúndún tó kọjá yìí, ọ̀pọ̀ irú àwọn èrò bẹ́ẹ̀ ló ti fi àìnígbàgbọ́ hàn. Ọ̀pọ̀ àwọn tó ní irú èrò bẹ́ẹ̀ ló gbà pé Jésù kò fìgbà kankan sọ ohun táa kà nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere, wọ́n ní lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn la yí ohun tó sọ padà, wọ́n ní tàbí kó jẹ́ pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ kò ṣẹ—àwọn aṣelámèyítọ́ ìtàn àti ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́ ló gbé àwọn èrò wọ̀nyí kalẹ̀. Alálàyé kan tilẹ̀ wo ìwé Ìhìn Rere Máàkù ‘lọ́nà tí ìmọ̀ ọgbọ́n orí àwọn ẹlẹ́sìn Mahayanaa, tó jẹ́ ẹ̀ya ẹ̀sìn Búdà gbà wò ó’!
3. Ojú wo ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń wo àsọtẹ́lẹ̀ Jésù?
3 Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ka Bíbélì sí ìwé tó kún fún òótọ́, tó sì ṣeé gbára lé, títí kan ohun tí Jésù sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀ ní Òkè Ólífì nígbà tó ku ọjọ́ mẹ́ta tí yóò kú. Láti ìgbà ayé C. T. Russell, òye àwọn ènìyàn Ọlọ́run nípa àsọtẹ́lẹ̀ tí Jésù sọ níbẹ̀ túbọ̀ ń pọ̀ sí i ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé. Láwọn ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ ti mú kí òye wọn nípa àsọtẹ́lẹ̀ yìí túbọ̀ ṣe kedere sí i. Ǹjẹ́ ìsọfúnni wọ̀nyẹn ti wọnú ọpọlọ rẹ dáadáa, tóo sì ti rí ipa rẹ̀ nínú ìgbésí ayé rẹ?a Ẹ jẹ́ a gbé e yẹ̀ wò nígbà náà.
Ìmúṣẹ Kíkàmàmà Kan Tí Yóò Ṣẹlẹ̀ Láìpẹ́
4. Èé ṣe tí àwọn àpọ́sítélì fi lè béèrè ìbéèrè nípa ọjọ́ ọ̀la lọ́wọ́ Jésù?
4 Àwọn àpọ́sítélì mọ̀ pé Jésù ni Mèsáyà náà. Nítorí náà, nígbà tí wọ́n gbọ́ tó ń sọ nípa ikú rẹ̀, àjíǹde rẹ̀, àti ìpadàbọ̀ rẹ̀, wọ́n ti lè máa kọminú pé, ‘Bí Jésù bá ní láti kú, kó tún padà lọ, báwo ni yóò ṣe wá ṣe àwọn nǹkan àgbàyanu táa ń retí pé kí Mèsáyà ṣe?’ Ní àfikún sí i, Jésù sọ nípa òpin Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀. Àwọn àpọ́sítélì náà ti lè máa ṣe kàyéfì pé, ‘Ìgbà wo nìyẹn máa ṣẹlẹ̀, báwo ló sì ṣe máa ṣẹlẹ̀?’ Níbi tí àwọn àpọ́sítélì ti ń gbìyànjú àtilóye èyí ni wọ́n ti béèrè pé: “Nígbà wo ni nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹlẹ̀, kí ni yóò sì jẹ́ àmì ìgbà tí a ti yàn tẹ́lẹ̀ pé kí gbogbo nǹkan wọ̀nyí wá sí ìparí?”—Máàkù 13:4; Mátíù 16:21, 27, 28; 23:37–24:2.
5. Báwo ni ohun tí Jésù sọ ṣe nímùúṣẹ ní ọ̀rúndún kìíní?
5 Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé ogun yóò jà, ìyàn yóò mú, àjàkálẹ̀ àrùn, ìsẹ̀lẹ̀, ìkórìíra yóò wà, àwọn èèyàn yóò máa ṣenúnibíni sáwọn Kristẹni, àwọn mèsáyà èké yóò lọ bí rẹ́rẹ, iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba náà yóò sì tàn kálẹ̀. Nígbà náà ni òpin yóò sì dé. (Mátíù 24:4-14; Máàkù 13:5-13; Lúùkù 21:8-19) Níbẹ̀rẹ̀ ọdún 33 Sànmánì Tiwa ni Jésù sọ nǹkan wọ̀nyí. Ní ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún tó tẹ̀ lé e, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tí wọ́n wà lójúfò lè rí i pé àwọn ohun tó sọ ti ń ṣẹlẹ̀ lọ́nà tó pàfiyèsí gan-an. Àní, ìtàn jẹ́rìí sí i pé àmì náà nímùúṣẹ lákòókò yẹn, èyí tó sì yọrí sí òpin ètò àwọn nǹkan àwọn Júù látọwọ́ àwọn ará Róòmù lọ́dún 66 sí 70 Sànmánì Tiwa. Báwo ló ṣe ṣẹlẹ̀?
6. Kí ló ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn ará Róòmù àti àwọn Júù lọ́dún 66 Sànmánì Tiwa?
6 Lákòókò tí ọ̀gbẹlẹ̀ ń jà gan-an lágbègbè Jùdíà lọ́dún 66 Sànmánì Tiwa, Àwọn Júù Onítara Ẹ̀sìn kọ lu àwọn ọmọ ogun ẹ̀ṣọ́ Róòmù tí wọ́n wà lágọ̀ọ́ wọn tó wà nítòsí tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù, ni rògbòdìyàn bá bẹ́ sílẹ̀ láwọn àgbègbè kan nílẹ̀ náà. Nínú ìwé náà, History of the Jews, tí Ọ̀jọ̀gbọ́n Heinrich Graetz ṣe, ó ròyìn pé: “Cestius Gallus tó jẹ́ pé òun ni Gómìnà Síríà, tó sì ní láti gbé agbára Róòmù lárugẹ, . . . kò lè fọwọ́ lẹ́rán mọ́ kò máa wo bí ọ̀tẹ̀ ṣe ń tàn kálẹ̀ lágbègbè rẹ̀ láìwá nǹkan ṣe sí i. Ó pe àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ jọ, àwọn alákòóso àgbègbè tó wà nítòsí sì fi àwọn ọmọ ogun wọn ránṣẹ́ sí i.” Ni ọ̀kẹ́ kan ààbọ̀ ẹgbẹ́ ọmọ ogun [30,000] bá yí Jerúsálẹ́mù ká. Lẹ́yìn ìjà díẹ̀, làwọn Júù bá sá padà sẹ́yìn ògiri tó wà nítòsí tẹ́ńpìlì. “Láàárín ọjọ́ márùn-ún tó tẹ̀ lé e, àwọn ọmọ ogun Róòmù gbẹ́ ògiri náà, ṣùgbọ́n ohun ìjà tí àwọn ará Jùdíà ń jù sí wọn mú kí wọ́n máa sá sẹ́yìn. Ọjọ́ kẹfà nìkan ṣoṣo ni wọ́n tó kẹ́sẹ járí láti dá àlàfo lu sára ògiri ìhà àríwá tó wà níwájú Tẹ́ńpìlì.”
7. Èé ṣe tí èrò àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù fi yàtọ̀ pátápátá sí ti ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn Júù?
7 Tiẹ̀ ronú nípa bí ọkàn àwọn Júù yóò ti dàrú tó, àwọn tó jẹ́ pé wọ́n ti ń rò ó lọ́kàn tipẹ́tipẹ́ pé Ọlọ́run yóò dáàbò bò wọ́n, tí yóò tún dáàbò bo ìlú mímọ́ wọn! Ṣùgbọ́n, a ti kìlọ̀ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù pé àjálù ńlá yóò já lu Jerúsálẹ́mù. Jésù ti sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Àwọn ọjọ́ yóò dé bá ọ, nígbà tí àwọn ọ̀tá rẹ yóò fi àwọn òpó igi olórí ṣóńṣó ṣe odi yí ọ ká, wọn yóò sì ká ọ mọ́, wọn yóò sì wàhálà rẹ láti ìhà gbogbo, wọn yóò sì fọ́ ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ tí ń bẹ nínú rẹ mọ́lẹ̀, wọn kì yóò sì fi òkúta kan sílẹ̀ lórí òkúta kan nínú rẹ.” (Lúùkù 19:43, 44.) Ṣùgbọ́n, ṣé ìyẹn yóò mú ikú wá sórí àwọn Kristẹni tó wà ní Jerúsálẹ́mù lọ́dún 66 Sànmánì Tiwa ni?
8. Ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá wo ni Jésù sọ tẹ́lẹ̀, àwọn wo sì ni “àwọn àyànfẹ́” táa tìtorí wọn ké àwọn ọjọ́ wọnnì kúrú?
8 Nígbà tí Jésù ń fèsì ìbéèrè àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ lórí Òkè Ólífì, ó sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Ọjọ́ wọnnì yóò jẹ́ àwọn ọjọ́ ìpọ́njú irúfẹ́ èyí ti kò tíì ṣẹlẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìṣẹ̀dá tí Ọlọ́run dá títí di àkókò yẹn, kì yóò sì tún ṣẹlẹ̀ mọ́. Ní ti tòótọ́, láìjẹ́ pé Jèhófà ké àwọn ọjọ́ náà kúrú, kò sí ẹran ara kankan tí à bá gbà là. Ṣùgbọ́n ní tìtorí àwọn àyànfẹ́ tí ó ti yàn, ó ti ké àwọn ọjọ́ náà kúrú.” (Máàkù 13:19, 20; Mátíù 24:21, 22) Nítorí náà, a óò ké àwọn ọjọ́ náà kúrú, a óò sì gba “àwọn àyànfẹ́” là. Àwọn wo làyànfẹ́? Dájúdájú, kì í ṣe àwọn Júù ọlọ̀tẹ̀ tí wọ́n sọ páwọn ń jọ́sìn Jèhófà ṣùgbọ́n tí wọ́n kọ Ọmọ rẹ̀ sílẹ̀. (Jòhánù 19:1-7; Ìṣe 2:22, 23, 36) Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, àwọn àyànfẹ́ ni àwọn Júù àti àwọn tí kì í ṣe Júù tí wọ́n lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù gẹ́gẹ́ bí Mèsáyà àti Olùgbàlà. Ọlọ́run yan irú àwọn bẹ́ẹ̀, nígbà tó sì di ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì 33 Sànmánì Tiwa, ó sọ wọ́n di orílẹ̀-èdè tuntun nípa tẹ̀mí, ìyẹn ni “Ísírẹ́lì Ọlọ́run.”—Gálátíà 6:16; Lúùkù 18:7; Ìṣe 10:34-45; 1 Pétérù 2:9.
9, 10. Báwo la ṣe “ké” àwọn ọjọ́ tí àwọn ará Róòmù fi kọ lu Jerúsálẹ́mù “kúrú,” kí ló sì yọrí sí?
9 Ǹjẹ́ a “ké àwọn ọjọ́ náà kúrú,” tí a sì gba àwọn àyànfẹ́ tó wà ní Jerúsálẹ́mù là? Ọ̀jọ̀gbọ́n Graetz sọ pé: “[Cestius Gallus] rí i pé pẹ̀lú bójú ọjọ́ ti rí nígbà yẹn kò bọ́gbọ́n mu láti máa bá ìjà táwọn ń bá àwọn tó ti gbékútà jà nìṣó, torí pé ìgbà òjò ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé . . . tí kò sì ní ṣáǹfààní láti máa kó ohun táwọn ọmọ ogun nílò fún wọn. Ó ní láti jẹ́ pé tìtorí ìyẹn ló fi ronú pé ó kúkú sàn jù káwọn padà sílé.” Ohun yòówù tó lè wà lọ́kàn Cestius Gallus, ẹgbẹ́ ọmọ ogun Róòmù kógun wọn kúrò nílùú náà, àwọn Júù tí ń lépa wọn sì ṣe wọ́n bọ́ṣẹ́ ṣe ń ṣojú.
10 Kíkógun tí àwọn ará Róòmù kógun wọn lọ lọ́nà yíyani lẹ́nu fàyè gba “ẹran ara”—ìyẹn ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tí wọ́n ti há sí Jerúsálẹ́mù—láti rí ìgbàlà. Ìtàn fi yéni pé bí ilẹ̀kùn àǹfààní yìí ti ṣí sílẹ̀, làwọn Kristẹni ti sá kúrò lágbègbè náà. Ẹ wo bí agbára Ọlọ́run láti mọ ọjọ́ ọ̀la ti pọ̀ tó, ẹ sì wo bó ti lágbára tó láti rí i pé àwọn tí ń jọ́sìn òun rí ìgbàlà! Síbẹ̀, kí ni nípa àwọn Júù aláìgbàgbọ́ tí wọ́n ṣì wà ní Jerúsálẹ́mù àti Jùdíà?
Àwọn Alájọgbáyé Yóò Rí I
11. Kí ni Jésù sọ nípa “ìran yìí”?
11 Ọ̀pọ̀ Júù ló gbà gbọ́ pé ọ̀nà ìgbàjọ́sìn wọn, èyí tí wọ́n gbé ka lílọ sí tẹ́ńpìlì, yóò máa bá a lọ títí ayé. Ṣùgbọ́n Jésù wí pé: “Ẹ kẹ́kọ̀ọ́ . . . yìí lára igi ọ̀pọ̀tọ́ . . . pé: Gbàrà tí ẹ̀ka rẹ̀ tuntun bá yọ ọ̀jẹ̀lẹ́, tí ó sì mú ewé jáde, ẹ mọ̀ pé ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn sún mọ́lé. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ẹ̀yin pẹ̀lú, nígbà tí ẹ bá rí gbogbo nǹkan wọ̀nyí, kí ẹ mọ̀ pé ó ti sún mọ́ tòsí lẹ́nu ilẹ̀kùn. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé ìran yìí kì yóò kọjá lọ lọ́nàkọnà títí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹlẹ̀. Ọ̀run àti ilẹ̀ ayé yóò kọjá lọ, ṣùgbọ́n àwọn ọ̀rọ̀ mi kì yóò kọjá lọ lọ́nàkọnà.”—Mátíù 24:32-35.
12, 13. Kí ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn lóye pé ó jẹ́ “ìran yìí” tí Jésù sọ nípa rẹ̀?
12 Ní àwọn ọdún tó ṣáájú ọdún 66 Sànmánì Tiwa, ó dájú pé àwọn Kristẹni yóò ti rí ìmúṣẹ ọ̀pọ̀ ẹ̀ka àmì alápá púpọ̀ náà—ogun, ìyàn, àní wíwàásù ìhìn rere Ìjọba náà lọ́nà gbígbòòrò pàápàá. (Ìṣe 11:28; Kólósè 1:23) Ṣùgbọ́n, nígbà wo ni òpin náà yóò dé? Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé: ‘Ìran yìí [ge·ne·aʹ lédè Gíríìkì] kì yóò kọjá lọ’? Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jésù ti pe àwọn Júù alátakò tí wọ́n jẹ́ alájọgbáyé rẹ̀, títí kan àwọn aṣáájú ìsìn, ní ‘ìran burúkú onípanṣágà.’ (Mátíù 11:16; 12:39, 45; 16:4; 17:17; 23:36) Nítorí náà, nígbà tó wà lórí Òkè Ólífì, tó tún sọ nípa “ìran yìí,” ó dájú pé kì í ṣe gbogbo ìran àwọn Júù jálẹ̀ ìtàn ló ní lọ́kàn; kì í sì í ṣe àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pẹ̀lú, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n jẹ́ “ẹ̀yà àyànfẹ́.” (1 Pétérù 2:9) Jésù kò sì tún sọ pé “ìran yìí” jẹ́ àkókò kan pàtó.
13 Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn Júù alátakò ni Jésù ní lọ́kàn, àwọn tó jẹ́ pé nígbà náà lọ́hùn-ún wọ́n rí ìmúṣẹ àmì tó fún wọn. Nígbà tí Ọ̀jọ̀gbọ́n Joel B. Green ń sọ̀rọ̀ nípa ìtọ́kasí tó wà lórí “ìran yìí” nínú Lúùkù 21:32, ó sọ pé: “Nínú ìwé Ìhìn Rere Kẹta, ‘ìran yìí’ (àti àwọn ọ̀rọ̀ tó tan mọ́ ọn) sábà máa ń dúró fún àwùjọ èèyàn kan tí wọ́n lòdì sí ète Ọlọ́run. . . . [Ó ń tọ́ka] sáwọn èèyàn tí oríkunkun mú kí wọ́n kẹ̀yìn sí ète Ọlọ́run.”b
14. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí “ìran” yẹn, ṣùgbọ́n kí ni ìyàtọ̀ tó wà láàárín ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn àti ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn Kristẹni?
14 Ìran búburú, ìran àwọn Júù alátakò tí wọ́n rí àmì náà tó nímùúṣẹ ni yóò tún rí òpin náà. (Mátíù 24:6, 13, 14) Wọ́n sì rí i lóòótọ́! Lọ́dún 70 Sànmánì Tiwa, àwọn ọmọ ogun Róòmù padà wá, Titus, ọmọ Olu Ọba Vespasian, ló kó wọn wá. Ìyà tó jẹ àwọn Júù tí wọ́n ká mọ́nú ìlú náà kò ṣeé fẹnu sọ.c Flavius Josephus tó fojú ara rẹ̀ rí ohun tó ṣẹlẹ̀ ròyìn pé nígbà tí àwọn ará Róòmù fi máa pa ìlú náà run, nǹkan bí ọ̀kẹ́ márùndínlọ́gọ́ta Júù [1,100,000] ló ti kú, wọ́n sì ti kó nǹkan bí ọ̀kẹ́ márùn-ún [100,000] nígbèkùn, àwọn tó jẹ́ pé ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn lebi máa tó pa kú tàbí kí wọ́n kú sínú gbọ̀ngàn ìwòran àwọn ará Róòmù. Lóòótọ́, ìpọ́njú tó ṣẹlẹ̀ lọ́dún 66 sí 70 Sànmánì Tiwa ni èyí tó burú jù lọ nínú ìtàn Jerúsálẹ́mù àti ètò àwọn Júù, kò sì tún sírú ẹ̀ mọ́ nínú ìtàn wọn. Ẹ wá wo bí ìyọrísí rẹ̀ ti yàtọ̀ tó fáwọn Kristẹni tí wọ́n ti kọbi ara sí ìkìlọ̀ alásọtẹ́lẹ̀ Jésù, tí wọ́n sì sá kúrò ní Jerúsálẹ́mù lẹ́yìn tí àwọn ọmọ ogun Róòmù kógun wọn lọ lọ́dún 66 Sànmánì Tiwa! Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró “àwọn àyànfẹ́” ni a “gbà là,” tàbí ni a pa mọ́, lọ́dún 70 Sànmánì Tiwa.—Mátíù 24:16, 22.
Ìmúṣẹ Mìíràn Tí Ń Bọ̀ Lọ́nà
15. Báwo la ṣe lè ní ìdánilójú pé àsọtẹ́lẹ̀ Jésù yóò nímùúṣẹ tó tóbi ju ti ọdún 70 Sànmánì Tiwa?
15 Ṣùgbọ́n, kò pin síbẹ̀ yẹn. Ṣáájú, Jésù ti fi hàn pé lẹ́yìn tí a bá ti pa ìlú náà run, òun yóò wá lórúkọ Jèhófà. (Mátíù 23:38, 39; 24:2) Ó túbọ̀ mú èyí ṣe kedere nínú àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ tó sọ lórí Òkè Ólífì. Lẹ́yìn tó ti mẹ́nu kan “ìpọ́njú ńlá,” ó wí pé lẹ́yìn náà àwọn èké Kristi yóò fara hàn, àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì tẹ Jerúsálẹ́mù mọ́lẹ̀ fún àkókò gígùn. (Mátíù 24:21, 23-28; Lúùkù 21:24) Ó ha lè jẹ́ pé, ìmúṣẹ mìíràn, tó tún tóbi ju ti ìṣáájú lọ ṣì ń bọ̀? Àwọn kókó táa rí fi hàn pé bẹ́ẹ̀ ni. Báa bá fi Ìṣípayá 6:2-8 (tí a kọ lẹ́yìn ìpọ́njú tó dé bá Jerúsálẹ́mù lọ́dún 70 Sànmánì Tiwa) wé Mátíù 24:6-8 àti Lúùkù 21:10, 11, a óò rí i pé ogun, ọ̀wọ́n oúnjẹ, àti àjàkálẹ̀ àrùn yóò ṣì ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú lọ́nà tó pọ̀ ju ti ìṣáájú. Ìmúṣẹ títóbi jù yìí tó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ Jésù ti ń ṣẹlẹ̀ láti ìgbà Ogun Àgbáyé Kìíní tó jà lọ́dún 1914.
16-18. Kí là ń retí pé kó ṣẹlẹ̀ láìpẹ́?
16 Fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún báyìí, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti kọ́ni pé ìmúṣẹ àmì náà ní lọ́ọ́lọ́ọ́ ń fi hàn pé “ìpọ́njú ńlá” kò tí ì dé. “Ìran” búburú ti ìsinsìnyí yóò rí ìpọ́njú yẹn. Ó jọ pé ìpọ́njú náà yóò ní bí yóò ṣe bẹ̀rẹ̀ (kíkọlu gbogbo ìsìn èké), gẹ́gẹ́ bí Gallus ṣe kọ lu Jerúsálẹ́mù lọ́dún 66 Sànmánì Tiwa, tí ìyẹn sì jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ìpọ́njú lórí ìlú ńlá náà.d Lẹ́yìn náà, nígbà tí àkókò kan tí a kò sọ bí yóò ti gùn tó bá parí, òpin náà yóò dé—ìparun jákèjádò ayé, tí yóò jọ ti ọdún 70 Sànmánì Tiwa.
17 Nígbà tí Jésù ń tọ́ka sí ìpọ́njú tó wà gẹ́rẹ́ níwájú wa, ó wí pé: “Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, lẹ́yìn ìpọ́njú ọjọ́ wọnnì [ìparun ìsìn èké], oòrùn yóò ṣókùnkùn, òṣùpá kì yóò sì fi ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ hàn, àwọn ìràwọ̀ yóò sì jábọ́ láti ọ̀run, àwọn agbára ọ̀run ni a ó sì mì. Nígbà náà sì ni àmì Ọmọ ènìyàn yóò fara hàn ní ọ̀run, nígbà náà sì ni gbogbo àwọn ẹ̀yà ilẹ̀ ayé yóò lu ara wọn nínú ìdárò, wọn yóò sì rí Ọmọ ènìyàn tí ń bọ̀ lórí àwọsánmà ọ̀run pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá.”—Mátíù 24:29, 30.
18 Abájọ́ tí Jésù fúnra rẹ̀ fi sọ pé “lẹ́yìn ìpọ́njú ọjọ́ wọnnì,” onírúurú ohun mérìíyìírí ti ojú ọ̀run yóò máa ṣẹlẹ̀. (Fi wé Jóẹ́lì 2:28-32; 3:15.) Èyí yóò mú àwọn aláìgbọràn ta gìrì, yóò sì kó jìnnìjìnnì bá wọn tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí wọn yóò fi “lu ara wọn nínú ìdárò.” Ọ̀pọ̀ yóò sì “kú sára nítorí ìbẹ̀rù àti ìfojúsọ́nà fún àwọn ohun tí ń bọ̀ wá sórí ilẹ̀ ayé tí a ń gbé.” Ṣùgbọ́n kò ní rí bẹ́ẹ̀ fún àwọn Kristẹni tòótọ́! Àwọn wọ̀nyí ‘yóò gbé orí wọn sókè, nítorí pé ìdáǹdè wọn ń sún mọ́lé.’—Lúùkù 21:25, 26, 28.
Ìdájọ́ Wà Níwájú!
19. Báwo la ṣe lè fìdí ìgbà tí àkàwé àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́ yóò nímùúṣẹ múlẹ̀?
19 Ṣàkíyèsí pé Mátíù 24:29-31 sọ tẹ́lẹ̀ pé (1) Ọmọ ènìyàn yóò wá, (2) wíwá yìí yóò jẹ́ pẹ̀lú ògo ńlá, (3) àwọn áńgẹ́lì yóò bá a wá, àti pé (4) gbogbo ẹ̀yà ilẹ̀ ayé ni yóò rí i. Jésù tún àwọn nǹkan wọ̀nyí sọ nínú àkàwé tó ṣe nípa àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́. (Mátíù 25:31-46) Nítorí náà, a lè parí èrò sí pé àkàwé yìí ní í ṣe pẹ̀lú àkókò náà, ìyẹn ni lẹ́yìn tí ìpọ́njú ńlá bá ti bẹ́ sílẹ̀, nígbà tí Jésù yóò wá pẹ̀lú àwọn áńgẹ́lì rẹ̀, tí yóò sì jókòó lórí ìtẹ́ láti ṣèdájọ́. (Jòhánù 5:22; Ìṣe 17:31; fi wé 1 Àwọn Ọba 7:7; Dáníẹ́lì 7:10, 13, 14, 22, 26; Mátíù 19:28.) Àwọn wo la ó dá lẹ́jọ́, kí ni yóò sì yọrí sí? Àkàwé náà fi hàn pé Jésù yóò darí àfiyèsí sí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè, bí ẹni pé wọ́n pé jọ síwájú ìtẹ́ rẹ̀ lókè ọ̀run.
20, 21. (a) Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn àgùntàn inú àkàwé Jésù? (b) Kí ni ojú àwọn ewúrẹ́ yóò rí lọ́jọ́ iwájú?
20 Jésù yóò ya àwọn ẹni bí àgùntàn lọ́kùnrin àti lóbìnrin sọ́tọ̀ sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, yóò fojú rere hàn sí wọn. Èé ṣe? Nítorí tí wọ́n ti lo àwọn àǹfààní tí wọ́n ní láti ṣoore fún àwọn arákùnrin rẹ̀—àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, tí wọn yóò nípìn-ín nínú Ìjọba Kristi lókè ọ̀run. (Dáníẹ́lì 7:27; Hébérù 2:9–3:1) Ní ìbámu pẹ̀lú àkàwé náà, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn Kristẹni ẹni bí àgùntàn ti mọ ipò tí àwọn arákùnrin Jésù nípa tẹ̀mí wà, wọ́n sì ń tì wọ́n lẹ́yìn. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, ogunlọ́gọ̀ ńlá yìí ní ìrètí tí a gbé ka Bíbélì, ìyẹn ni ti líla “ìpọ́njú ńlá náà” já, àti ìrètí wíwà láàyè títí láé nínú Párádísè, àgbègbè àkóso Ìjọba Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé.—Ìṣípayá 7:9, 14; 21:3, 4; Jòhánù 10:16.
21 Ohun tó máa yọrí sí fáwọn ewúrẹ́ yóò mà yàtọ̀ pátápátá o! A ṣàpèjúwe wọn nínú Mátíù 24:30 pé nígbà tí Jésù dé, ṣe ni ‘wọ́n ń lu ara wọn nínú ìdárò.’ Bó ṣe yẹ kó rí fún wọn nìyẹn, nítorí yóò ti wà lákọọ́lẹ̀ pé wọ́n kọ etí ikún sí ìhìn rere Ìjọba náà, pé wọ́n ṣàtakò sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù, àti pé wọ́n fẹ́ràn ayé tó ń kọjá lọ ju Kristi. (Mátíù 10:16-18; 1 Jòhánù 2:15-17) Jésù ló mọ ẹni tó jẹ́ ewúrẹ́ o, kò sí ìkankan nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tó wà lórí ilẹ̀ ayé tó mọ̀ wọ́n. Nípa àwọn ewúrẹ́, ó sọ pé: “Àwọn wọ̀nyí yóò sì lọ sínú ìkékúrò àìnípẹ̀kun.”—Mátíù 25:46.
22. Apá wo nínú àsọtẹ́lẹ̀ Jésù ló yẹ ká túbọ̀ gbé yẹ̀ wò?
22 Ìtẹ̀síwájú wa nínú lílóye àsọtẹ́lẹ̀ inú Mátíù orí kẹrìnlélógún àti ìkarùndínlọ́gbọ̀n ti mú inú wa dùn jọjọ. Ṣùgbọ́n, apá kan tún wà nínú àsọtẹ́lẹ̀ Jésù tó yẹ ká fiyè sí gidigidi—“ohun ìríra tí ń ṣokùnfà ìsọdahoro, tí ó dúró ní ibi mímọ́.” Jésù rọ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti fòye mọ èyí, kí wọ́n sì múra tán láti gbégbèésẹ̀. (Mátíù 24:15, 16) Kí ni “ohun ìríra” yìí? Ìgbà wo ló dúró ní ibi mímọ́? Báwo ló sì ṣe kan ìgbésí ayé wa nísinsìnyí àti ìrètí wa ọjọ́ ọ̀la? Àpilẹ̀kọ tó tẹ lé e yóò la ọ̀rọ̀ yìí lẹ́sẹẹsẹ.
-
-
“Kí Òǹkàwé Lo Ìfòyemọ̀”Ilé Ìṣọ́—1999 | May 1
-
-
“Kí Òǹkàwé Lo Ìfòyemọ̀”
“Nígbà tí ẹ bá tajú kán rí ohun ìríra tí ń ṣokùnfà ìsọdahoro, tí ó dúró ní ibi mímọ́, . . . nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ní Jùdíà bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ sí àwọn òkè ńlá.”—MÁTÍÙ 24:15, 16.
1. Kí ni àbájáde tí ìkìlọ̀ Jésù tí a rí nínú Lúùkù 19:43, 44 ní?
JÍJẸ́ ẹni tó tètè fura pé àjálù ń bọ̀ lè ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún un. (Òwe 22:3) Nítorí náà, ronú nípa ipò tí àwọn Kristẹni tó wà ní Jerúsálẹ́mù wà lẹ́yìn tí àwọn ará Róòmù kọ lu ìlú náà lọ́dún 66 Sànmánì Tiwa. Jésù ti kìlọ̀ pé a óò yí ìlú náà ká, a óò sì pa á run. (Lúùkù 19:43, 44) Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn Júù ló yínmú sí Jésù. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kọbi ara sí ìkìlọ̀ rẹ̀. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, a gbà wọ́n là kúrò lọ́wọ́ àjálù tó wáyé lọ́dún 70 Sànmánì Tiwa.
2, 3. Èé ṣe tó fi yẹ ká nífẹ̀ẹ́ sí àsọtẹ́lẹ̀ Jésù tó wà nínú Mátíù 24:15-21?
2 Nínú àsọtẹ́lẹ̀ tó kàn wá lónìí, Jésù mẹ́nu kan àmì alápá púpọ̀ tó ní nínú, ogun, àìtó oúnjẹ, ìsẹ̀lẹ̀, àjàkálẹ̀ àrùn, àti inúnibíni tí a óò ṣe sí àwọn Kristẹni tí ń wàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run. (Mátíù 24:4-14; Lúùkù 21:10-19) Jésù tún sọ ohun tó lè jẹ́ kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun tètè fura pé òpin ti sún mọ́lé—ìyẹn ni, “ohun ìríra tí ń ṣokùnfà ìsọdahoro, tí ó dúró ní ibi mímọ́.” (Mátíù 24:15) Ẹ jẹ́ ká ṣàtúnyẹ̀wò àwọn ọ̀rọ̀ pàtàkì wọ̀nyẹn, láti lè mọ bí wọ́n ṣe kan ìgbésí ayé wa nísinsìnyí àti ní ọjọ́ ọ̀la.
3 Lẹ́yìn tó ti to àmì náà lẹ́sẹẹsẹ, Jésù wí pé: “Nígbà tí ẹ bá tajú kán rí ohun ìríra tí ń ṣokùnfà ìsọdahoro, tí ó dúró ní ibi mímọ́, gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ọ́ nípasẹ̀ Dáníẹ́lì wòlíì, (kí òǹkàwé lo ìfòyemọ̀,) nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ní Jùdíà bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ sí àwọn òkè ńlá. Kí ẹni tí ó wà ní orí ilé má ṣe sọ̀ kalẹ̀ láti kó àwọn ẹrù kúrò nínú ilé rẹ̀; kí ẹni tí ó wà ní pápá má sì padà sí ilé láti mú ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀. Ègbé ni fún àwọn obìnrin tí ó lóyún àti àwọn tí ń fi ọmú fún ọmọ ọwọ́ ní ọjọ́ wọnnì! Ẹ máa gbàdúrà kí sísá yín má ṣẹlẹ̀ ní ìgbà òtútù, tàbí ní ọjọ́ sábáàtì; nítorí nígbà náà ni ìpọ́njú ńlá yóò wà, irúfẹ́ èyí tí kò tíì ṣẹlẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé títí di ìsinsìnyí.”—Mátíù 24:15-21.
4. Kí ló fi hàn pé Mátíù 24:15 nímùúṣẹ ní ọ̀rúndún kìíní?
4 Àkọsílẹ̀ ti Máàkù àti Lúùkù tún jẹ́ ká mọ àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ mìíràn. Ibi tí Mátíù ti lo gbólóhùn náà, “tí ó dúró ní ibi mímọ́,” Máàkù 13:14 sọ pé “tí ó dúró níbi tí kò yẹ.” Lúùkù 21:20 fi àwọn ọ̀rọ̀ Jésù náà kún un pé: “Nígbà tí ẹ bá rí tí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun adótini bá yí Jerúsálẹ́mù ká, nígbà náà ni kí ẹ mọ̀ pé ìsọdahoro rẹ̀ ti sún mọ́lé.” Èyí ràn wá lọ́wọ́ láti mọ̀ pé ìmúṣẹ àkọ́kọ́ náà ní í ṣe pẹ̀lú bí àwọn ará Róòmù ṣe kọ lu Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀—ibi tí àwọn Júù kà sí ibi mímọ́ ṣùgbọ́n tí Jèhófà kò kà sí ibi mímọ́ mọ́—ìkọlù tó bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 66 Sànmánì Tiwa. Sísọ ọ́ dahoro pátápátá wáyé nígbà tí àwọn ará Róòmù pa ìlú náà àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ run lọ́dún 70 Sànmánì Tiwa. Kí ni “ohun ìríra náà” nígbà náà lọ́hùn-ún? Báwo ló sì ṣe “dúró ní ibi mímọ́”? Ìdáhùn táa bá rí sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti lóye bó ṣe nímùúṣẹ lóde òní.
5, 6. (a) Èé ṣe tí àwọn tó bá ka Dáníẹ́lì orí kẹsàn-án fi ní láti lo òye? (b) Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ Jésù nípa “ohun ìríra” ṣe nímùúṣẹ?
5 Jésù rọ àwọn òǹkàwé láti lo òye. Ìwe wo ni wọ́n ń kà? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìwé Dáníẹ́lì orí kẹsàn-án. Níbẹ̀ ni a ti rí àsọtẹ́lẹ̀ kan tó ń sọ ìgbà tí Mèsáyà náà yóò fara hàn, tó tún ń sọ tẹ́lẹ̀ pé a óò ‘ké e kúrò’ lẹ́yìn ọdún mẹ́ta àti ààbọ̀. Àsọtẹ́lẹ̀ náà sọ pé: “Àti lórí ìyẹ́ apá ohun ìríra ni ẹni tí ń ṣokùnfà ìsọdahoro yóò wà; títí di ìparun pátápátá, ohun tí a ti ṣe ìpinnu lé lórí yóò máa dà jáde sórí ẹni tí ó wà ní ahoro pẹ̀lú.”—Dáníẹ́lì 9:26, 27; tún wo Dáníẹ́lì 11:31; 12:11.
6 Àwọn Júù rò pé bíbà tí Áńtíókọ́sì Kẹrin ba tẹ́ńpìlì jẹ́ ní nǹkan bí igba ọdún ṣáájú àkókò tí Jésù ń sọ̀rọ̀ ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí ń sọ. Àmọ́ ṣá o, Jésù fi hàn pé ohun tí òun ń sọ yàtọ̀ pátápátá sí èrò ọkàn wọn, ó rọ̀ wọ́n láti lo òye nítorí pé “ohun ìríra náà” kò tí ì fara hàn, kò sì tí ì dúró ní “ibi mímọ́.” Ó ṣe kedere pé Jésù ń tọ́ka sí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Róòmù tí yóò wá lọ́dún 66 Sànmánì Tiwa pẹ̀lú àwọn àsíá táa fi lè dá a mọ̀ yàtọ̀. Àwọn Júù, ka irú àsíá bẹ́ẹ̀ táwọn èèyàn ti ń lò tipẹ́tipẹ́ sí ère, wọ́n jẹ́ ohun ìríra sí wọn.a Ṣùgbọ́n, nígbà wo ni wọn yóò “dúró ní ibi mímọ́”? Ìyẹn ṣẹlẹ̀ nígbà tí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Róòmù, pẹ̀lú àsíá wọn, kọ lu Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀, tí àwọn Júù kà sí ibi mímọ́. Àwọn ará Róòmù tilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí dá ihò lu sára ògiri tó yí àgbègbè tẹ́ńpìlì náà ká. Lóòótọ́, ohun tó ti jẹ́ ohun ìríra fún ìgbà pípẹ́ mà ti wá dúró sí ibi mímọ́ báyìí o!—Aísáyà 52:1; Mátíù 4:5; 27:53; Ìṣe 6:13.
“Ohun Ìríra” Lóde Òní
7. Àsọtẹ́lẹ̀ Jésù wo ló ń nímùúṣẹ lọ́jọ́ tiwa?
7 Láti ìgbà Ogun Àgbáyé Kìíní, a ti rí ìmúṣẹ àmì tí Jésù sọ, tí a kọ sílẹ̀ nínú Mátíù orí kẹrìnlélógún, lọ́nà gbígbòòrò. Síbẹ̀, rántí àwọn ọ̀rọ̀ tó sọ pé: “Nígbà tí ẹ bá tajú kán rí ohun ìríra tí ń ṣokùnfà ìsọdahoro, tí ó dúró ní ibi mímọ́, . . . nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ní Jùdíà bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ sí àwọn òkè ńlá.” (Mátíù 24:15, 16) Apá yìí nínú àsọtẹ́lẹ̀ náà tún gbọ́dọ̀ nímùúṣẹ tirẹ̀ ní àkókò tiwa yìí.
8. Fún ọ̀pọ̀ ọdún, kí ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń sọ nípa “ohun ìríra” ti òde òní?
8 Nígbà tó ń fi ìgbọ́kànlé tí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ní nínú àsọtẹ́lẹ̀ yìí hàn pé bó ti wù kó rí yóò nímùúṣẹ, ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ ti January 1, 1921, (Gẹ̀ẹ́sì) darí àfiyèsí sí i ní ìsopọ̀ pẹ̀lú àwọn nǹkan tí ń ṣẹlẹ̀ ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn Ayé nígbà náà. Nígbà tó ṣe, nínú ìtẹ̀jáde rẹ̀ ti December 15, 1929, ojú ìwé 374, ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ (Gẹ̀ẹ́sì) sọ ní pàtó pé: “Gbogbo ète Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ni láti yí àwọn èèyàn padà kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run àti lọ́dọ̀ Kristi, nítorí náà ohun ìsọdahoro ló jẹ́, ọ̀dọ̀ Sátánì ló ti wá, ohun ẹlẹ́gbin gbáà ló sì jẹ́ lójú Ọlọ́run.” Nítorí náà lọ́dún 1919 “ohun ìríra” náà yọ kúlẹ́. Nígbà tó ṣe, Ìmùlẹ̀ náà ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè. Ó ti pẹ́ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti tú ètò àjọ tí àwọn èèyàn gbé kalẹ̀ láti lè mú àlàáfíà wá yìí fó pé ó jẹ́ ohun ìríra lójú Ọlọ́run.
9, 10. Báwo ni òye táa kọ́kọ́ ní nípa ìpọ́njú ńlá ṣe nípa lórí ojú ìwòye wa nípa àkókò náà tí “ohun ìríra” yóò dúró ní ibi mímọ́?
9 Àpilẹ̀kọ tó ṣáájú ṣàkópọ̀ èrò tó ṣe kedere nípa ọ̀pọ̀ ohun tí ń bẹ nínú Mátíù orí kẹrìnlélógún àti ìkarùndínlọ́gbọ̀n. Ǹjẹ́ ó bójú mu láti ṣe àwọn àlàyé tó ṣe kedere nípa “ohun ìríra tó dúró ní ibi mímọ́”? Bẹ́ẹ̀ ni. Àsọtẹ́lẹ̀ Jésù sọ pé ‘dídúró ní ibi mímọ́’ ní í ṣe pẹ̀lú ìbẹ́sílẹ̀ “ìpọ́njú” náà tí a ti sọ tẹ́lẹ̀ lọ́nà tó fi hàn pé ohun kan so àwọn méjèèjì pọ̀. Nítorí náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé “ohun ìríra” náà ti wà tipẹ́, ìsopọ̀ tó wà láàárín ‘dídúró tó dúró sí ibi mímọ́’ àti ìpọ́njú ńlá yẹ kó nípa lórí ìrònú wa. Lọ́nà wo?
10 Nígbà kan rí àwọn èèyàn Ọlọ́run lóye pé apá àkọ́kọ́ ìpọ́njú ńlá náà bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1914 àti pé apá tó kẹ́yìn yóò dé nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì. (Ìṣípayá 16:14, 16; fi wé Ilé Ìṣọ́, April 1, 1939, (Gẹ̀ẹ́sì) ojú ìwé 110.) Nítorí náà, a lè lóye ìdí tí a fi ronú nígbà kan pé “ohun ìríra” ti òde òní ti dúró ní ibi mímọ́ ní kété tí Ogun Àgbáyé Kìíní parí.
11, 12. Lọ́dún 1969, ojú ìwòye tuntun wo nípa ìpọ́njú ńlá la gbé kalẹ̀?
11 Ṣùgbọ́n, ní àwọn ọdún tó tẹ̀ lé e a ti wá rí i pé ọ̀ràn kò rí bẹ́ẹ̀. Lọ́jọ́ Thursday, July 10, 1969, níbi Àpéjọ Àgbáyé “Àlàáfíà Lórí Ilẹ̀ Ayé” táa ṣe ní New York City, ni F. W. Franz, tó jẹ́ igbá kejì ààrẹ Watch Tower Bible and Tract Society nígbà náà, sọ àwíyé kan tó tani jí gidigidi. Nígbà tó ń ṣàgbéyẹ̀wó òye táa ti ní tẹ́lẹ̀ nípa àsọtẹ́lẹ̀ Jésù, Arákùnrin Franz wí pé: “A ti ṣàlàyé rẹ̀ nígbà kan pé ‘ìpọ́njú ńlá’ náà ti bẹ̀rẹ̀ látọdún 1914 ti Sànmánì Tiwa àti pé a kò yọ̀ǹda fún un láti máa bá a nìṣó, ṣùgbọ́n pé Ọlọ́run mú Ogun Àgbáyé Kìíní wá sópin ní November ọdún 1918. Láti ìgbà náà wá, Ọlọ́run ń yọ̀ǹda àkókò kan fún ìgbòkègbodò àṣẹ́kù àwọn ẹni àmì òróró tí í ṣe àwọn Kristẹni àyànfẹ́ kó tó di pé yóò jẹ́ kí apá tó kẹ́yìn nínú ‘ìpọ́njú ńlá’ náà bẹ̀rẹ̀ nínú ogun Amágẹ́dọ́nì.”
12 Lẹ́yìn náà ló wá ṣàlàyé kan tí a fi ṣàtúnṣe ojú ìwòye náà lọ́nà tó gba àfiyèsí gidigidi, àlàyé ọ̀hún lọ báyìí: “Láti lè bá àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ọ̀rúndún kìíní mu, . . . ‘ìpọ́njú ńlá’ amápẹẹrẹṣẹ kò bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1914 Sànmánì Tiwa. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jerúsálẹ́mù amápẹẹrẹṣẹ, ìyẹn ni ohun tó dúró fún un lóde òní, lọ́dún 1914 sí 1918 wulẹ̀ jẹ ‘ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìroragógó wàhálà’ . . . ‘Ìpọ́njú ńlá’ náà tí irú rẹ̀ kò tún ní ṣẹlẹ̀ mọ́ ṣì wà níwájú, nítorí yóò jẹ́ ìparun ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé (títí kan Kirisẹ́ńdọ̀mù), èyí tí ‘ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè’ ní Amágẹ́dọ́nì yóò tẹ̀ lé.” Èyí túmọ̀ sí pé ìpọ́njú ńlá náà látòkèdélẹ̀ ṣì wà níwájú.
13. Èé ṣe tó fi bọ́gbọ́n mu láti sọ pé ó ṣì di ọjọ́ iwájú kí “ohun ìríra” náà tó “dúró ní ibi mímọ́”?
13 Èyí ní nǹkan ṣe ní tààràtà pẹ̀lú ìgbà tí “ohun ìríra” náà dúró ní ibi mímọ́. Rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ọ̀rúndún kìíní. Àwọn ará Róòmù kọ lu Jerúsálẹ́mù lọ́dún 66 Sànmánì Tiwa, àmọ́ wọ́n kógun wọn lọ láìròtẹ́lẹ̀, èyí tó fún “ẹran ara,” tí í ṣe àwọn Kristẹni, láǹfààní láti rí ìgbàlà. (Mátíù 24:22) Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, a retí pé kí ìpọ́njú ńlá bẹ̀rẹ̀ láìpẹ́, ṣùgbọ́n a óò ké e kúrú nítorí àwọn àyànfẹ́ Ọlọ́run. Ṣàkíyèsí kókó pàtàkì yìí: Nínú ìmúṣẹ ti ìgbàanì, a pe ‘ohun ìríra tó dúró ní ibi mímọ́’ náà ní kíkọlù tí àwọn ará Róòmù kọ lu Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ lábẹ́ Ọ̀gágun Gallus lọ́dún 66 Sànmánì Tiwa. Ìkọlù tòde òní tó jẹ́ aláfijọ tọjọ́sí—ìyẹn ni ìbẹ́sílẹ̀ ìpọ́njú ńlá—ṣì wà ní iwájú. Nítorí náà, “ohun ìríra tí ń ṣokùnfà ìsọdahoro,” tó ti wà láti ọdún 1919, ti fi hàn gbangba pé òun kò tí ì dúró ní ibi mímọ́.b Báwo lèyí yóò ṣe ṣẹlẹ̀? Báwo ni yóò sì ṣe kàn wá?
Ìkọlù Ní Ọjọ́ Iwájú
14, 15. Báwo ni Ìṣípayá orí kẹtàdínlógún ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti lóye àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí yóò yọrí sí Amágẹ́dọ́nì?
14 Ìwé Ìṣípayá ṣàpèjúwe ìkọlù apanirun kan tí yóò dé sórí ìsìn èké lọ́jọ́ ọ̀la. Orí kẹtàdínlógún ṣàlàyé ìdájọ́ Ọlọ́run tí yóò dé sórí “Bábílónì Ńlá, ìyá àwọn aṣẹ́wó”—ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé. Kirisẹ́ńdọ̀mù jẹ́ apá pàtàkì nínú rẹ̀, ó sì ń sọ pé òun ti bá Ọlọ́run dá májẹ̀mú. (Fi wé Jeremáyà 7:4.) Ó ti pẹ́ ti àwọn ìsìn èké, títí kan Kirisẹ́ńdọ̀mù, ti ń bá “àwọn ọba ilẹ̀ ayé” da nǹkan pọ̀, ṣùgbọ́n èyí yóò dópin nígbà ìsọdahoro àwọn ìsìn wọ̀nyẹn. (Ìṣípayá 17:2, 5) Ọwọ́ ta ni ìsọdahoro náà yóò ti wá?
15 Ìwé Ìṣípayá ṣàpèjúwe “ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò kan” tó ti wà fún sáà kan, tí a kò tún gbúròó rẹ̀ mọ́, tó tún padà yọ kúlẹ́. (Ìṣípayá 17:3, 8) Àwọn alákòóso ayé ni wọ́n jẹ́ igi lẹ́yìn ọgbà fún ẹranko ẹhànnà yìí. Àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ táa pèsè nínú àsọtẹ́lẹ̀ náà ràn wá lọ́wọ́ láti mọ ẹranko ẹhànnà ìṣàpẹẹrẹ yìí gẹ́gẹ́ bí ètò àjọ tí a pète láti mú àlàáfíà wá, èyí tó wá sójútáyé lọ́dún 1919 gẹ́gẹ́ bí Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè (“ohun ìríra”) tí a sì wá mọ̀ nísinsìnyí sí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè. Ìṣípayá 17:16, 17 fi hàn pé láìpẹ́, Ọlọ́run yóò fi í sí ọkàn-àyà àwọn alákòóso ẹ̀dá ènìyàn kan tí wọn kò ṣeé fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn nínú àjọ tó dúró fún “ẹranko ẹhànnà” yìí láti sọ ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé dahoro. Kíkọlù tí yóò kọ lù ú yẹn ni yóò sàmì sí ìbẹ́sílẹ̀ ìpọ́njú ńlá.
16. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó gba àfiyèsí wo ló ń wáyé nípa ẹ̀sìn báyìí?
16 Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ìbẹ̀rẹ̀ ìpọ́njú ńlá náà ṣì wà níwájú, ṣé ‘dídúró ní ibi mímọ́’ náà ṣì wà lọ́jọ́ iwájú ni? Ó dájú pé bẹ́ẹ̀ ni. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé “ohun ìríra” náà ti fara hàn ní apá ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún yìí, tí ó sì tipa bẹ́ẹ̀ wà fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún, yóò dúró “ní ibi mímọ́” lọ́nà tí yóò pabanbarì, ní ọjọ́ ọ̀la tí kò jìnnà mọ́. Bó ṣe jẹ́ pé ṣe ni àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi ọ̀rúndún kìíní ní láti fara balẹ̀ kí wọ́n sì ṣàkíyèsí bí ‘dídúró ní ibi mímọ́’ náà ṣe wáyé, bẹ́ẹ̀ náà làwọn Kristẹni tí ń bẹ lóde òní gbọ́dọ̀ fara balẹ̀ láti rí ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀. Kò sí tàbí-ṣùgbọ́n, sùúrù la óò ní láti lè rí ìmúṣẹ náà gan-an, ká sì mọ gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ rẹ̀. Síbẹ̀, ó yẹ fún àfiyèsí pé ní àwọn ilẹ̀ kan ṣá o, ẹ̀tanú ẹ̀sìn kàn ń pọ̀ sí i ṣáá ni. Àwọn olóṣèlú kan, tí wọ́n ti lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú àwọn kan tí wọ́n jẹ́ Kristẹni tẹ́lẹ̀ rí, ṣùgbọ́n tí wọ́n ti kúrò nínú ẹ̀sìn tòótọ́, làwọn tí ń gbé ẹ̀tanú dìde sí ẹ̀sìn ní gbogbo gbòò, pàápàá jù lọ àwọn ló ń gbé ẹ̀tanú dìde sí àwọn Kristẹni tòótọ́. (Sáàmù 94:20, 21; 1 Tímótì 6:20, 21) Àbárèbábọ̀ rẹ̀ ni pé, àwọn agbára ìṣèlú pàápàá nísinsìnyí ‘ń bá Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà jagun,’ gẹ́gẹ́ bí Ìṣípayá 17:14 sì ti fi hàn, ìjà yìí ṣì máa gbóná sí i o. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọwọ́ wọn kò lè tẹ Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run—Jésù Kristi táa ti gbé ga sí ipò ológo—wọn yóò túbọ̀ gbé àtakò wọn dìde sí àwọn olùjọsìn tòótọ́ ti Ọlọ́run, pàápàá “àwọn ẹni mímọ́” rẹ̀. (Dáníẹ́lì 7:25; fi wé Róòmù 8:27; Kólósè 1:2; Ìṣípayá 12:17.) Ọlọ́run ti mú un dá wa lójú pé Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà àti àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ ni yóò borí nínú ìjà náà.—Ìṣípayá 19:11-21.
17. Láìlẹ́mìí pé ohun táa ti mọ̀ náà la ó rinkinkin mọ́, kí la lè sọ nípa bí “ohun ìríra” náà yóò ṣe dúró ní ibi mímọ́?
17 A mọ̀ dájú pé ìsọdahoro ń dúró de ìsìn èké. Bábílónì Ńlá ti “mu ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹni mímọ́” ó sì ti ṣe gẹ́gẹ́ bí ọbabìnrin, ṣùgbọ́n kò sóhun tó lè yẹ ìparun rẹ̀. Agbára àìmọ́ tó ti lò lórí àwọn ọba ilẹ̀ ayé yóò yí padà lójijì bí àjọṣe wọn ti máa yí padà bírí, nígbà tí ‘ìwo mẹ́wàá àti ẹranko ẹhànnà náà’ bá kórìíra rẹ̀ pátápátá. (Ìṣípayá 17:6, 16; 18:7, 8) Nígbà tí “ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò” bá kọ lu ẹ̀sìn tó ti ya aṣẹ́wó kalẹ̀ yìí, “ohun ìríra” náà yóò dúró ní ibi tí Kirisẹ́ńdọ̀mù ń pè ní ibi mímọ́, lọ́nà tí yóò fi hàn pé ewu ń bọ̀.c Nítorí náà, ìsọdahoro náà yóò bẹ̀rẹ̀ lórí Kirisẹ́ńdọ̀mù aláìgbàgbọ́, tí ń fi ara rẹ̀ hàn bí ẹni mímọ́.
“Sá”—Sá Lọ Síbo?
18, 19. Kí ni àwọn ìdí táa fún wa tó fi hàn pé ‘sísa lọ sórí òkè ńlá’ kò ní túmọ̀ sí títi inú ẹ̀sìn kan bọ́ sí òmíràn?
18 Lẹ́yìn tó ti sọ tẹ́lẹ̀ nípa ‘dídúró tí ohun ìríra náà yóò dúró ní ibi mímọ́,’ Jésù kìlọ̀ fún àwọn olóye láti máà jáfara. Ṣé ohun tí ó ń sọ ni pé nígbà tí àkókò ti lọ tán yẹn—nígbà tí “ohun ìríra” ti “dúró ní ibi mímọ́”—ọ̀pọ̀ èèyàn yóò sá kúrò nínú ìsìn èké lọ sínú ìsìn tòótọ́? Kò dájú. Ṣàgbéyẹ̀wò ìmúṣẹ àkọ́kọ́. Jésù wí pé: “Kí àwọn tí ń bẹ ní Jùdíà bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ sí àwọn òkè ńlá. Kí ẹni tí ó wà ní orí ilé má ṣe sọ̀ kalẹ̀, tàbí kí ó wọlé lọ mú ohunkóhun jáde kúrò nínú ilé rẹ̀; kí ẹni tí ó wà ní pápá má sì padà sí àwọn ohun tí ń bẹ lẹ́yìn láti mú ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀. Ègbé ni fún àwọn obìnrin tí ó lóyún àti àwọn tí ń fi ọmú fún ọmọ ọwọ́ ni ọjọ́ wọnnì! Ẹ máa gbàdúrà kí ó má ṣẹlẹ̀ ní ìgbà òtútù.”—Máàkù 13:14-18.
19 Jésù kò sọ pé kìkì àwọn tó wà ní Jerúsálẹ́mù nìkan ló ní láti sá, kó wá dà bí ẹni pé kókó ohun tó ń sọ ni pé wọ́n ní láti kúrò ní ibi tí ó jẹ́ ojúkò fún ìjọsìn àwọn Júù; bẹ́ẹ̀ sì ni ìkìlọ̀ rẹ̀ kò mẹ́nu kan títi inú ẹ̀sìn kan bọ́ sí òmíràn—ìyẹn ni sísa kúrò nínú ẹ̀sìn èké, kí a sì gba ẹ̀sìn tòótọ́. Lóòótọ́, àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù kò nílò ìkìlọ̀ kankan nípa sísá láti inú ẹ̀sìn kan sínú òmíràn; wọ́n kúkú ti di Kristẹni tòótọ́ ná. Kíkọlù tí a sì kọ lu Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ lọ́dún 66 Sànmánì Tiwa kò sún àwọn ẹlẹ́sìn Júù tí wọ́n wà ní Jerúsálẹ́mù àtàwọn tó wà jákèjádò Jùdíà láti pa ẹ̀sìn wọn tì, kí wọ́n sì wá tẹ́wọ́ gba ẹ̀sìn Kristẹni. Ọ̀jọ̀gbọ́n Heinrich Graetz sọ pé àwọn tó gbá tẹ̀ lé àwọn ará Róòmù tí wọ́n fẹsẹ̀ fẹ tún padà wá sínú ìlú náà, ó sọ pé: “Àwọn Onítara Ìsìn, tí wọ́n ń fi ohùn rara kọrin ogun kiri ìgboro, gbogbo wọn ló padà wá sí Jerúsálẹ́mù (lọ́jọ́ kẹjọ oṣù October), tí wọ́n ń yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ pé ìdáǹdè àti òmìnira wọn ti dé. . . . Ǹjẹ́ Ọlọ́run kò ti ràn wọ́n lọ́wọ́ báyìí bí Ó ti ran àwọn baba ńlá wọn lọ́wọ́? Digbídigbí lọkàn Àwọn Onítara Ìsìn náà balẹ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la.”
20. Báwo ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ìjímìjí ṣe dáhùn padà sí ìkìlọ̀ tó fún wọn nípa sísá lọ sí àwọn òkè ńlá?
20 Bó bá wá rí bẹ́ẹ̀, báwo làwọn àyànfẹ́ tí wọ́n kéré níye gan-an nígbà náà lọ́hùn-ún ṣe wá ṣiṣẹ́ lórí ìmọ̀ràn Jésù? Nípa fífi Jùdíà sílẹ̀ àti sísá tí wọn sá lọ sórí àwọn òkè níkọjá Jọ́dánì, wọ́n fi hàn pé àwọn kì í ṣe apá kan ètò àwọn nǹkan ti àwọn Júù, ì báà jẹ́ ní ti ìṣèlú o, tàbí ní ti ẹ̀sìn. Wọ́n filé fọ̀nà wọn sílẹ̀, wọn ò tiẹ̀ kó dúkìá tí wọ́n ní sílé pàápàá. Nítorí pé wọ́n nígbọ̀ọ́kànlé pé Jèhófà yóò dáàbò bo àwọn, àti pé yóò pèsè fáwọn, wọ́n fi ìjọsìn rẹ̀ ṣáájú ohunkóhun tó lè jọ pé ó ṣe pàtàkì.—Máàkù 10:29, 30; Lúùkù 9:57-62.
21. Kí ni kò yẹ ká máa retí nígbà tí “ohun ìríra” náà bá ṣe ìkọlù rẹ̀?
21 Wàyí o, wá gbé ìmúṣẹ rẹ̀ títóbi jù yẹ̀ wò. Ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún la ti ń rọ àwọn èèyàn láti jáde kúrò nínú ìsìn èké, kí wọ́n sì tẹ́wọ́ gba ìsìn tòótọ́. (Ìṣípayá 18:4, 5) Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ló ti ṣe bẹ́ẹ̀. Àsọtẹ́lẹ̀ Jésù kò fi hàn pé gbàrà tí ìpọ́njú ńlá bá ti bẹ́ sílẹ̀, àwọn èèyàn yóò wá yíjú sí ìjọsìn mímọ́ gaara; ó dájú pé ìyípadà irú-wá-ògìrì-wá bẹ́ẹ̀ kò ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn Júù lọ́dún 66 Sànmánì Tiwa. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ nǹkan ni yóò mú àwọn Kristẹni tòótọ́ lórí yá láti fi ìkìlọ̀ Jésù sílò, kí wọ́n sì sá.
22. Kí ni fífi táa bá fi ìmọ̀ràn Jésù nípa sísálọ sórí òkè sílò lè ní nínú?
22 Ní báyìí, a kò lè mọ gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ìpọ́njú ńlá, ṣùgbọ́n ó bọ́gbọ́n mu fún wa láti dé ìparí èrò pé ní tiwa, sísá tí Jésù sọ kò ní jẹ́ sísá láti àgbègbè kan lọ sí àgbègbè mìíràn. Ní lọ́ọ́lọ́ọ́, àwọn èèyàn Ọlọ́run ti wà káàkiri àgbáyé, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ibi tí wọn ò sí. Ṣùgbọ́n o, ká jẹ́ kó dá wa lójú pé, nígbà tó bá pọndandan pé kí àwọn Kristẹni sá, sísá wọn yóò jẹ́ bíbá a nìṣó láti di ìdúró wọn gédégbé mú ní ti pé wọ́n yàtọ̀ pátápátá sí àwọn ètò ìsìn èké. Ó tún ṣe pàtàkì pé Jésù kìlọ̀ pé kéèyàn má padà lọ sílé rẹ̀ torí pé ó fẹ́ lọ mú ẹ̀wù àwọ̀lékè tàbí torí àwọn ẹrù mìíràn tó fẹ́ gbé. (Mátíù 24:17, 18) Nítorí náà, àdánwò lè wà níwájú nípa ojú táa fi ń wo ọrọ̀ àlùmọ́nì; ṣé àwọn nǹkan yẹn la kà sí ohun to ṣe pàtàkì jù lọ, àbí ìgbàlà tí yóò ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá? Bẹ́ẹ̀ ni, sísá wa lè ní àwọn ìnira àti ìṣòro kan nínú. A ní láti múra tán láti ṣe gbogbo ohun tó bá yẹ, gẹ́gẹ́ bí àwọn akẹgbẹ́ wa ní ọ̀rúndún kìíní ti ṣe, àwọn tí wọ́n sá kúrò ní Jùdíà lọ sí Pèríà, níkọjá Jọ́dánì.
23, 24. (a) Ibo ni ibì kan ṣoṣo táa ti lè rí ààbò? (b) Ipa wo ló yẹ kí ìkìlọ̀ Jésù nípa “ohun ìríra, tí ó dúró ní ibi mímọ́” ní lórí wa?
23 A gbọ́dọ̀ nígbàgbọ́ pé Jèhófà àti ètò àjọ rẹ̀ tó dà bí òkè ńlá ni yóò máa jẹ́ ibi ìsádi wa. (2 Sámúẹ́lì 22:2, 3; Sáàmù 18:2; Dáníẹ́lì 2:35, 44) Ibẹ̀ yẹn la ti lè rí ààbò! Ẹ má ṣe jẹ́ ká fara wé àwọn èèyàn ayé tí wọn yóò sá lọ sínú “àwọn hòrò” tí wọn yóò lọ fara pamọ́ “sínú àwọn àpáta ràbàtà àwọn òkè ńlá”—àwọn ètò àjọ tí ẹ̀dá ènìyàn gbé kalẹ̀ tó ṣeé ṣe kó wà fúngbà díẹ̀ lẹ́yìn tí a bá ti sọ Bábílónì Ńlá dahoro. (Ìṣípayá 6:15; 18:9-11) Lóòótọ́, nǹkan lè máà rọrùn—bó ti ṣeé ṣe kó rí fún àwọn aboyún tí wọ́n sá kúrò ní Jùdíà tàbí àwọn kan tí wọ́n ní láti rìnrìn àjò nígbà òtútù tàbí ní àkókò àrọ̀ọ̀rọ̀dá òjò lọ́dún 66 Sànmánì Tiwa. Ṣùgbọ́n a lè nígbàgbọ́ pé lágbára Ọlọ́run a óo là á já. Àní láti ìsinsìnyí lọ, ẹ jẹ́ kí a máa fún ìgbàgbọ́ táa ní nínú Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ lókun, Ọmọ rẹ̀ tí ń ṣàkóso nísinsìnyí gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba náà.
24 Kò sídìí kankan fún wa láti máa gbọ̀n jìnnìjìnnì nípa ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀. Jésù kò fẹ́ kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun nígbà yẹn bẹ̀rù, bẹ́ẹ̀ sì ni kò fẹ́ kí àwa pẹ̀lú máa fòyà báyìí tàbí ní àwọn ọjọ́ tí ń bọ̀. Ó ta wá lólobó torí kí a bàa lè múra ọkàn-àyà àti ìrònú wa sílẹ̀. Ó ṣe tán, a kò ní fìyà jẹ àwọn Kristẹni onígbọràn nígbà tí ìparun bá dé sórí ìsìn èké àti ìyókù ètò búburú yìí. Wọn yóò lo òye, wọn yóò sì kọbi ara sí ìkìlọ̀ nípa “ohun ìríra tí ó dúró ni ibi mímọ́.” Ìgbàgbọ́ wọn tí kò lè yẹ̀ yóò sì jẹ́ kí wọ́n gbégbèésẹ̀ láìjáfara. Ǹjẹ́ kí a má gbàgbé ìlérí Jésù yìí láé pé: “Ẹni tí ó bá fara dà á dé òpin ni ẹni tí a ó gbà là.”—Máàkù 13:13.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a “Nínú tẹ́ńpìlì Róòmù, ọ̀wọ̀ ńlá tó wà fún nǹkan ẹ̀sìn ni wọ́n fún àsíá àwọn ará Róòmù; bí àwọn èèyàn wọ̀nyí sì ṣe gbà pé wọ́n lọ́lá ju àwọn orílẹ̀-èdè yòókù lọ tó, bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ṣe gbé àsíá ilẹ̀ wọn gẹ̀gẹ̀ tó . . . [Lójú àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ náà], kò sóhùn tó tún ṣe pàtàkì tó o lágbàáyé. Àsíá náà wà lára àwọn ohun tí ọmọ ogun Róòmù fi máa ń búra.”—The Encyclopædia Britannica, Ìtẹ̀jáde kọkànlá.
b Ó yẹ ká kíyè sí i pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìmúṣẹ àwọn ọ̀rọ̀ Jésù lọ́dún 66 sí 70 Sànmánì Tiwa lè ràn wá lọ́wọ́ láti lóye bí wọn yóò ṣe nímùúṣẹ nígbà ìpọ́njú ńlá, ìmúṣẹ méjèèjì kò lè rí bákan náà nítorí pé àwọn ìmúṣẹ náà ṣẹlẹ̀ nínú ipò tó yàtọ̀ síra.
c Jọ̀wọ́ wo Ile Iṣọ Na, October 15, 1976, ojú ìwé 617 sí 623.
Ǹjẹ́ O Rántí?
◻ Báwo ni “ohun ìríra tí ń ṣokùnfà ìsọdahoro” ṣe fi ara rẹ̀ hàn ní ọ̀rúndún kìíní?
◻ Èé ṣe tó fi bọ́gbọ́n mu láti ronú pé ó ṣì di ọjọ́ ọ̀la kí “ohun ìríra” ti òde òní tó dúró ní ibi mímọ́?
◻ Ìkọlù wo táa ti sọ tẹ́lẹ̀ nínú ìwé Ìṣípayá ni “ohun ìríra” náà yóò ṣe?
◻ Irú ‘sísá’ wo ni a ṣì lè sọ pé kí a sá?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
A pe Bábílónì Ńlá ni “ìyá àwọn aṣẹ́wó”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò inú ìwé Ìṣípayá orí kẹtàdínlógún ni “ohun ìríra” tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò yóò kọ lu ẹ̀sìn lọ́nà tí yóò fi sọ ọ́ dahoro
-
-
Ẹ Wà Lójúfò, Kí Ẹ Sì Jẹ́ Aláápọn!Ilé Ìṣọ́—1999 | May 1
-
-
Ẹ Wà Lójúfò, Kí Ẹ Sì Jẹ́ Aláápọn!
“Nítorí náà, ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, nítorí pé ẹ kò mọ ọjọ́ tàbí wákàtí náà.”—MÁTÍÙ 25:13.
1. Kí ni àpọ́sítélì Jòhánù ń wọ̀nà fún?
NÍNÚ ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tó wáyé kẹ́yìn nínú Bíbélì, Jésù ṣèlérí pé: “Mo ń bọ̀ kíákíá.” Jòhánù àpọ́sítélì rẹ̀ fèsì pé: “Àmín! Máa bọ̀, Jésù Olúwa.” Àpọ́sítélì náà kò ṣiyè méjì nípa bíbọ̀ Jésù. Jòhánù wà lára àwọn àpọ́sítélì tó béèrè lọ́wọ́ Jésù pé: “Nígbà wo ni nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹlẹ̀, kí ni yóò sì jẹ́ àmì wíwàníhìn-ín rẹ [lédè Gíríìkì, pa·rou·siʹa] àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan?” Bẹ́ẹ̀ ni, Jòhánù ń fojú sọ́nà fún wíwàníhìn-ín Jésù ní ọjọ́ ọ̀la pẹ̀lú ìgbọ́kànlé.—Ìṣípayá 22:20; Mátíù 24:3.
2. Ní ti wíwàníhìn-ín Jésù, ọwọ́ wo làwọn oníṣọ́ọ̀ṣì fi mú un?
2 Irú ìgbọ́kànlé bẹ́ẹ̀ ṣọ̀wọ́n lóde òní. Ọ̀pọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì ní àwọn ẹ̀kọ́ tí wọ́n fi ń kọ́ni nípa “wíwá” Jésù, ṣùgbọ́n díẹ̀ nínú àwọn mẹ́ńbà wọn ló ń retí wíwá náà. Wọ́n sì ń lo ìgbésí ayé wọn bí ẹni pé Jésù kò ní wá. Ìwé náà, The Parousia in the New Testament, sọ pé: “Ipa díẹ̀ ni ìrètí Ìpadàbọ̀ Kristi ní nínú ìgbésí ayé, ìrònú àti iṣẹ́ ṣọ́ọ̀ṣì. . . . Ẹ̀mí ìjẹ́kánjúkánjú tó yẹ kí ṣọ́ọ̀ṣì ní sí ìpolongo ìrònúpìwàdà àti iṣẹ́ ìkéde ìhìn rere náà ti ń kú lọ, tàbí ká kúkú sọ pé ó tilẹ̀ ti kú pátápátá.” Àmọ́ ṣá o, kò rí bẹ́ẹ̀ lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn!
3. (a) Kí ni ìmọ̀lára àwọn Kristẹni tòótọ́ nípa pa·rou·siʹa? (b) Ní pàtàki, kí la fẹ́ gbé yẹ̀ wò báyìí?
3 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tòótọ́ ń fi ìháragàgà dúró de òpin ètò àwọn nǹkan búburú ti ìsinsìnyí. Bí a ti ń fi ìdúróṣinṣin ṣe bẹ́ẹ̀, a ní láti ní ojú ìwòye tòótọ́ nípa gbogbo àwọn ohun tó wé mọ́ wíwà níhìn-ín Jésù, kí a sì hùwà lọ́nà tó bá a mu. Ìyẹn yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ‘fara dà á dé òpin kí a bàa lè rí ìgbàlà.’ (Mátíù 24:13) Nígbà tó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ táa rí nínú Mátíù orí kẹrìnlélógún àti ìkẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n, Jésù pèsè ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tí a lè fi sílò, fún àǹfààní wa ayérayé. Orí kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ní àwọn àkàwé tó ṣeé ṣe kóo ti mọ̀, títí kan ọ̀kan tó sọ nípa wúńdíá mẹ́wàá (olóye àti òmùgọ̀
-