-
Ṣọ́ra Fún Àwọn Ìdẹkùn Èṣù!Ilé Ìṣọ́—2012 | August 15
-
-
Ṣọ́ra Fún Àwọn Ìdẹkùn Èṣù!
“Padà . . . kúrò nínú ìdẹkùn Èṣù.”—2 TÍM. 2:26.
BÁWO LO ṢE MÁA DÁHÙN?
Bó o bá sábà máa ń ní èrò tí kò tọ́ nípa àwọn míì, àyẹ̀wò wo ló yẹ kó o ṣe nípa ara rẹ?
Kí lo rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ Pílátù àti Pétérù nípa ìdí tí kò fi yẹ kó o kó sínú ìdẹkùn ìbẹ̀rù àti ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe?
Kí lo lè ṣe tó ò fi ní máa nímọ̀lára ẹ̀bi tó kọjá bó ṣe yẹ?
1, 2. Àwọn ìdẹkùn Èṣù wo la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
ÈṢÙ ń dọdẹ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà. Kì í ṣe pé ó ń wá bó ṣe máa pa wọ́n bí àwọn ọdẹ aperin ṣe máa ń pa ẹran ńlá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí Èṣù ń fẹ́ gan-an ni pé kó gbá ẹni tó bá ń dọdẹ mú láàyè, kó sì ṣe onítọ̀hún bó bá ṣe fẹ́.—Ka 2 Tímótì 2:24-26.
2 Bí ọdẹ kan bá fẹ́ mú ẹran láàyè, ó ní ohun tó máa ń lò. Ó lè fi ohun kan tan ẹran náà wá sí gbangba níbi táá ti kó sínú okùn tó dẹ. Tàbí kó dẹ páńpẹ́ kan síbi tó fara sin, kí páńpẹ́ náà lè ré lójijì nígbà tí ẹran ti wọ́n dẹ ẹ́ fún bá kó sínú rẹ̀. Irú àwọn ìdẹkùn bẹ́ẹ̀ ni Èṣù máa ń lò láti fi mú àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run láàyè. Bí a kò bá fẹ́ kó mú wa, a gbọ́dọ̀ wà lójúfò ká sì máa fiyè sí àwọn àmì tó ń jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀kan lára àwọn ìdẹkùn tàbí páńpẹ́ Sátánì wà nítòsí. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò ohun tá a lè ṣe tá ò fi ní kó sínú mẹ́ta lára àwọn páńpẹ́ tí Èṣù ń lò, tó ti fi mú àwọn èèyàn kan. Àwọn ni (1) sísọ̀rọ̀ gbàùgbàù, (2) ìbẹ̀rù àti ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe àti (3) ìmọ̀lára ẹ̀bi tó kọjá bó ṣe yẹ. Nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí, a máa jíròrò àwọn páńpẹ́, tàbí ìdẹkùn méjì míì tí Sátánì ń lò.
DẸ́KUN SÍSỌ̀RỌ̀ GBÀÙGBÀÙ
3, 4. Bí a kò bá kó ahọ́n wa níjàánu, kí ló lè yọrí sí? Sọ àpẹẹrẹ kan.
3 Bí ọdẹ kan bá fẹ́ kí àwọn ẹranko sá jáde kúrò níbi tí wọ́n fara pa mọ́ sí, ó lè sọ iná sí apá ibì kan nínú igbó, bí àwọn ẹranko náà bá sì ti ń sá jáde, á bẹ̀rẹ̀ sí í mú wọn. Bákan náà, Èṣù máa fẹ́ láti dáná ìjàngbọ̀n sínú ìjọ. Bí iná náà bá sì ti ràn, ó lè mú kí àwọn ará máa fi ìjọ tó jẹ́ ibi ààbò sílẹ̀ kí wọ́n sì máa lọ síbi tí ọwọ́ rẹ̀ ti lè tẹ̀ wọ́n. Báwo la ṣe lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ohun tó fẹ́ láìmọ̀, ká sì wá tipa bẹ́ẹ̀ kó sínú akóló rẹ̀.
4 Ọmọ ẹ̀yìn náà Jákọ́bù fi ahọ́n wé iná. (Ka Jákọ́bù 3:6-8.) Bí a kò bá kó ahọ́n wa níjàánu, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í dáná ìjàngbọ̀n sínú ìjọ. Báwo nìyẹn ṣe lè ṣẹlẹ̀? Ẹ ronú nípa ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ná: Wọ́n ṣèfilọ̀ ní ìpàdé ìjọ pé arábìnrin kan ti di aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Lẹ́yìn ìpàdé náà, àwọn akéde méjì ń sọ̀rọ̀ nípa ìfilọ̀ náà. Ọ̀kan nínú wọn sọ pé inú òun dùn pé ó di aṣáájú-ọ̀nà, àdúrà òun sì ni pé kí Jèhófà jẹ́ kó kẹ́sẹ járí. Èkejì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àríwísí aṣáájú-ọ̀nà náà, ó ní ńṣe ló máa ń fẹ́ láti fira rẹ̀ sípò ńlá nínú ìjọ. Èwo lo máa fẹ́ láti mú lọ́rẹ̀ẹ́ nínú àwọn akéde méjèèjì? Kò ṣòro láti mọ èyí tó ṣeé ṣe kó fi ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ dáná ìjàngbọ̀n sínú ìjọ láàárín àwọn méjèèjì.
5. Ká bàa lè dẹ́kun sísọ̀rọ̀ gbàùgbàù, àyẹ̀wò wo ló yẹ ká ṣe nípa ara wa?
5 Báwo la ṣe lè dẹ́kun sísọ̀rọ̀ gbàùgbàù? Jésù sọ pé: “Lára ọ̀pọ̀ yanturu tí ń bẹ nínú ọkàn-àyà ni ẹnu ń sọ.” (Mátíù 12:34) Torí náà, ohun tó yẹ ká kọ́kọ́ ṣe ni pé ká ṣe àyẹ̀wò ohun tó wà nínú ọkàn wa. Bí èrò búburú tó máa ń mú kéèyàn sọ̀rọ̀ ẹlòmíì láìdáa bá wá sí wa lọ́kàn, ǹjẹ́ a máa ń fàyè gbà á? Bí àpẹẹrẹ, bí a bá gbọ́ pé arákùnrin kan ń sapá láti kúnjú ìwọ̀n fún àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan, ṣé a tètè máa ń gbà pé èrò rere ló ní lọ́kàn, àbí ńṣe la máa ń fura sí i pé ire ti ara rẹ̀ nìkan ló ń wá? Bí a bá sábà máa ń ronú pé ìmọtara-ẹni-nìkan ló ń mú káwọn míì ṣe ohun tí wọ́n ń ṣe, ó máa dára ká rántí pé Èṣù jiyàn nípa ìdí tí Jóòbù, ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó jẹ́ olùṣòtítọ́ fi ń sìn Ín. (Jóòbù 1:9-11) Torí náà, dípò tí a ó fi máa fura sí arákùnrin wa, ó máa dára ká ronú nípa ohun tó fà á tá a fi ń ní èrò tí kò tọ́ nípa rẹ̀. Ǹjẹ́ ìdí rere kan tiẹ̀ wà tó fi yẹ ká máa ní irú èrò bẹ́ẹ̀? Àbí ẹ̀mí ìkórìíra tó gbilẹ̀ gan-an nínú ayé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí ti gbin ohun tí kò dára sí wa lọ́kàn?—2 Tím. 3:1-4.
6, 7. (a) Kí ni díẹ̀ lára ohun tó lè mú ká máa fẹ́ ṣàríwísí àwọn ẹlòmíì? (b) Kí ló yẹ ká ṣe bí ẹnì kan bá sọ̀rọ̀ tó dùn wá?
6 Ronú nípa àwọn ìdí míì tó lè mú ká máa ṣàríwísí àwọn ẹlòmíì. Ọ̀kan lára ohun tó lè mú ká ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé a fẹ́ kí àwọn èèyàn túbọ̀ máa kíyè sí àwọn àṣeyọrí wa. Lédè mìíràn, a lè fẹ́ láti máa fi hàn pé a sàn ju gbogbo èèyàn tó kù lọ. Ó sì lè jẹ́ pé ńṣe là ń gbìyànjú láti wá àwáwí torí ohun kan tó yẹ ká ti ṣe ṣùgbọ́n tí a kùnà láti ṣe. Yálà ìgbéraga ló sún wa ṣe ohun tá a ṣe ni o tàbí ìlara tàbí àìdára-ẹni-lójú, ó máa ṣèpalára tó pọ̀ gan-an.
7 A sì lè rò pé kò sí ohun tó burú nínú ṣíṣe àríwísí ẹnì kan. Bóyá òun náà ti sọ̀rọ̀ tí kò dára nípa wa rí. Bí ọ̀rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, gbígbẹ̀san ohun tó ṣe sí wa kọ́ ló máa yanjú ọ̀ràn náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe nìyẹn máa mú kí ọ̀ràn náà burú sí i. Èṣù ló sì máa ń fẹ́ kéèyàn gbẹ̀san, Ọlọ́run kò fẹ́ bẹ́ẹ̀. (2 Tím. 2:26) Torí náà, ó dára ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. Nígbà tí wọ́n ń kẹ́gàn rẹ̀, “kò bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́gàn padà.” Kàkà bẹ́ẹ̀, ó “ń bá a nìṣó ní fífi ara rẹ̀ lé ọwọ́ ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ lọ́nà òdodo.” (1 Pét. 2:21-23) Ó dá Jésù lójú pé Jèhófà máa bójú tó àwọn ọ̀ràn lọ́nà tí Ó fẹ́ àti nígbà tí ó bá tọ́ lójú Rẹ̀. Àwa pẹ̀lú gbọ́dọ̀ ní irú ìgbẹ́kẹ̀lé bẹ́ẹ̀ nínú Ọlọ́run. Tá a bá ń sọ àwọn ohun tó máa gbé àwọn mìíràn ró, a óò mú kí “ìdè asonipọ̀ṣọ̀kan ti àlàáfíà” máa wà nínú ìjọ wa.—Ka Éfésù 4: 1-3.
MÁ ṢE JẸ́ KÍ SÁTÁNÌ FI ÌBẸ̀RÙ ÀTI Ẹ̀MÍ ṢOHUN-TẸ́GBẸ́-Ń-ṢE DẸKÙN MÚ Ẹ
8, 9. Kí nìdí tí Pílátù fi dá Jésù lẹ́bi?
8 Bí ẹran kan bá kó sínú ìdẹkùn, ẹran náà kò ní lómìnira láti rìn fàlàlà bó ṣe wù ú mọ́. Bákan náà, bí ẹnì kan bá jẹ́ kí ìbẹ̀rù àti ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe máa darí òun, a jẹ́ pé ó gbà kí àwọn míì máa darí apá kan nínú ìgbésí ayé òun nìyẹn. (Ka Òwe 29:25.) Ẹ jẹ́ ká jíròrò àpẹẹrẹ àwọn ọkùnrin méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí wọ́n gbà kí ìbẹ̀rù àti ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe darí àwọn ká sì wo ohun tá a lè rí kọ́ nínú ìrírí wọn.
9 Pọ́ńtíù Pílátù tó jẹ́ gómìnà ìlú Róòmù mọ̀ pé Jésù kò jẹ̀bí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án, torí náà kò fẹ́ láti ṣe ohun tó máa pa á lára. Kódà, Pílátù sọ pé Jésù kò ṣe “nǹkan kan . . . tí ó yẹ fún ikú.” Síbẹ̀, Pílátù dájọ́ ikú fún un. Kí nìdí? Ìdí ni pé Pílátù fẹ́ láti ṣe ohun tí àwọn èèyàn fẹ́ kó ṣe. (Lúùkù 23:15, 21-25) Àwọn Júù tó ń ṣe àtakò sí Jésù wá ọ̀nà láti ṣe ohun tó wà lọ́kàn wọn, torí náà wọ́n kígbe pé: “Bí ìwọ bá tú ọkùnrin yìí sílẹ̀, ìwọ kì í ṣe ọ̀rẹ́ Késárì.” (Jòh. 19:12) Ẹ̀rù lè ti máa ba Pílátù pé bí òun bá gbè sẹ́yìn Kristi, ó ṣeé ṣe kí òun pàdánù ipò òun gẹ́gẹ́ bíi Gómìnà tàbí kí wọ́n tiẹ̀ pa òun. Torí náà, ó gbà kí àwọn èèyàn mú un ṣe ohun tí Èṣù fẹ́.
10. Kí ló mú kí Pétérù sẹ́ Kristi?
10 Àpọ́sítélì Pétérù jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ jù lọ fún Jésù. Ó polongo ní gbangba pé Jésù ni Mèsáyà náà. (Mát. 16:16) Pétérù ń bá a nìṣó láti máa tọ Jésù lẹ́yìn nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn yòókù kò lóye ohun tó sọ tí wọ́n sì fi Í sílẹ̀. (Jòh. 6:66-69) Nígbà tí àwọn ọ̀tá sì wá láti mú Jésù, Pétérù lo idà láti dáàbò bo Ọ̀gá rẹ̀. (Jòh. 18:10, 11) Àmọ́, nígbà tó yá, Pétérù jẹ́ kí ìbẹ̀rù borí òun, ó sẹ́ Jésù Kristi nípa sísọ pé òun kò mọ̀ ọ́n rí. Ó kó sínú ìdẹkùn fún ìgbà díẹ̀, ó gbà kí ìbẹ̀rù èèyàn fa òun sẹ́yìn láti lo ìgboyà.—Mát. 26:74, 75.
11. Àwọn ipò tí ń múni ṣe ohun tí kò tọ́ wó ló ṣeé ṣe ká dojú kọ?
11 Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, a gbọ́dọ̀ máa sá fún àwọn ohun tó lè mú ká ṣe ohun tí inú Ọlọ́run kò dùn sí. Àwọn agbanisíṣẹ́ tàbí àwọn míì lè gbìyànjú láti mú ká hùwà àìṣòótọ́ tàbí kí wọ́n wá bí wọ́n ṣe máa tàn wá ká lè lọ́wọ́ sí ìṣekúṣe. Ní ti àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ ọmọléèwé, àwọn ojúgbà wọn lè gbìyànjú láti mú kí wọ́n jí ìwé wò nígbà ìdánwò, kí wọ́n wo àwòrán oníhòòhò, kí wọ́n mu sìgá, kí wọ́n lo oògùn olóró, kí wọ́n mu ọtí líle ní àmuyó, tàbí kí wọ́n ṣe ìṣekúṣe. Ńṣe ni ìbẹ̀rù àti ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe dà bí ìdẹkùn. Torí náà, báwo la ò ṣe ní í jẹ́ kí wọ́n mú wa ṣe ohun tí inú Jèhófà kò dùn sí?
12. Kí la lè rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pílátù àti Pétérù?
12 Ẹ jẹ́ ká wo ohun tá a lè rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pílátù àti Pétérù. Òye díẹ̀ ni Pílátù ní nípa Kristi. Síbẹ̀, ó mọ̀ pé Jésù kò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án àti pé kì í ṣe èèyàn kan lásán. Àmọ́, agbéraga ni Pílátù kò sì nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tòótọ́. Torí náà, ó rọrùn fún Èṣù láti mú kó ṣe ohun tó fẹ́. Pétérù ní ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run, ó sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Àmọ́, láwọn ìgbà míì, kì í ṣe bó ti mọ, ẹ̀rù máa ń bà á, ó sì máa ń ṣe ohun tó wu àwọn míì. Kí wọ́n tó mú Jésù, Pétérù fọ́nnu pé: “Àní bí a bá mú gbogbo àwọn yòókù kọsẹ̀, síbẹ̀ a kì yóò mú èmi kọsẹ̀.” (Máàkù 14:29) Ì bá ti túbọ̀ rọrùn fún àpọ́sítélì yìí láti wà ní ìmúrasílẹ̀ de àwọn ìdánwò tó ń bọ̀ wá kojú rẹ̀ ká sọ pé ó ti ṣe bíi ti onísáàmù tó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run. Onísáàmù náà kọrin pé: “Jèhófà ń bẹ ní ìhà ọ̀dọ̀ mi; èmi kì yóò bẹ̀rù. Kí ni ará ayé lè fi mí ṣe?” (Sm. 118:6) Ní alẹ́ tí Jésù lò kẹ́yìn lórí ilẹ̀ ayé, ó mú Pétérù àti àwọn àpọ́sítélì méjì mìíràn lọ sí àárín gbùngbùn inú ọgbà Gẹtisémánì. Àmọ́, dípò kí Pétérù àti àwọn àpọ́sítélì méjì náà wà lójúfò, ńṣe ni wọ́n sùn lọ. Jésù jí wọn, ó sì wí pé: “Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, kí ẹ sì máa gbàdúrà, kí ẹ má bàa wá sínú ìdẹwò.” (Máàkù 14:38) Àmọ́, Pétérù tún sùn lẹ́yìn ìgbà yẹn, ó sì wá kó sínú ìdẹkùn ìbẹ̀rù àti ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe.
13. Báwo la ṣe lè sá fún ṣíṣe ohun tí kò tọ́?
13 A tún lè rí ẹ̀kọ́ pàtàkì mìíràn kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pílátù àti Pétérù. Ẹ̀kọ́ náà sì ni pé, ká lè sá fún ṣíṣe ohun tí kò tọ́, a gbọ́dọ̀ ní ìmọ̀ pípéye, ká ní ìwà ìrẹ̀lẹ̀, ká mọ̀wọ̀n ara wa, ká nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, ká sì bẹ̀rù Jèhófà dípò àwọn èèyàn. Tá a bá gbé ìgbàgbọ́ wa ka orí ìmọ̀ pípéye, a ó máa fi ìgboyà sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tá a gbà gbọ́ lọ́nà tó fi hàn pé ó dá wa lójú. Èyí máa ràn wá lọ́wọ́ láti sá fún ṣíṣe ohun tí kò tọ́ ká sì borí ìbẹ̀rù èèyàn. Àmọ́ ṣá o, a kò gbọ́dọ̀ dá ara wa lójú ju bó ṣe yẹ lọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ mọ̀ pé a nílò agbára Ọlọ́run ká tó lè sá fún ṣíṣe ohun tí kò tọ́. A gbọ́dọ̀ máa gbàdúrà sí Jèhófà pé kó fi ẹ̀mí rẹ̀ ràn wá lọ́wọ́, ká jẹ́ kí ìfẹ́ tá a ní fún un mú ká sá fún ṣíṣe ohun tó máa tàbùkù sí orúkọ rẹ̀, ká sì máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ̀. Ó sì tún yẹ ká ti máa wà ní ìmúrasílẹ̀ de ohun tó lè mú ká ṣe ohun tí kò tọ́. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá ń jẹ́ kí àwọn ọmọ wa wà ní ìmúrasílẹ̀ tá a sì jọ ń gbàdúrà, wọ́n máa mọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe bí àwọn ojúgbà wọn bá fẹ́ mú kí wọ́n ṣe ohun tí kò tọ́.—2 Kọ́r. 13:7.a
SÁ FÚN Ẹ̀BÌTÌ SÁTÁNÌ, ÌYẸN ÌMỌ̀LÁRA Ẹ̀BI TÓ KỌJÁ BÓ ṢE YẸ
14. Kí ni Èṣù máa fẹ́ ká ní lọ́kàn nípa àwọn àṣìṣe tá a ti ṣe kọjá?
14 Ìgbà míì wà táwọn èèyàn máa ń dẹ ẹ̀bìtì láti fi mú ẹran. Ẹ̀bìtì yìí jẹ́ igi rìbìtì kan tàbí òkúta tí wọ́n so rọ̀ sára igi tẹ́ẹ́rẹ́ ní ojú ọ̀nà tí ẹran sábà máa ń gbà kọjá. Bí ẹranko kan tí kò fura bá fara kọ́ ohun tó gbé igi tẹ́ẹ́rẹ́ náà ró, ńṣe ni igi rìbìtì tàbí òkúta náà á wó lù ú mọ́lẹ̀ tá á sì tẹ̀ ẹ́ rẹ́. Ìmọ̀lára ẹ̀bi tó kọjá bó ṣe yẹ la lè fi wé igi rìbìtì tàbí òkúta yẹn. Tá a bá ń ronú nípa ẹ̀ṣẹ̀ kan tá a ti ṣẹ̀ kọjá, ìyẹn lè mú ká máa rí ara wa bí “ẹni ìtẹ̀mọ́lẹ̀ ní ìwọ̀n tí ó dé góńgó.” (Ka Sáàmù 38:3-5, 8.) Sátánì á fẹ́ ká máa ronú pé ẹ̀ṣẹ̀ tá a ṣẹ̀ ti mú ká kọjá ẹni tí Jèhófà lè fi àánú hàn sí àti pé kò lè ṣeé ṣe fún wa láti ṣe àwọn nǹkan tí Ọlọ́run fẹ́.
15, 16. Báwo lo ṣe lè sá fún ìmọ̀lára ẹ̀bi tó kọjá bó ṣe yẹ?
15 Báwo lo ṣe lè sá fún ìmọ̀lára ẹ̀bi tó kọjá bó ṣe yẹ? Tó o bá ti dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì, tètè wá nǹkan ṣe nípa rẹ̀ kó o lè pa dà ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Jèhófà. Tọ àwọn alàgbà lọ kó o sì ní kí wọ́n ràn ẹ́ lọ́wọ́. (Ják. 5:14-16) Ṣe ohun tó o bá lè ṣe láti wá ojútùú sí àṣìṣe náà. (2 Kọ́r. 7:11) Tí wọ́n bá sì bá ẹ wí, má ṣe rẹ̀wẹ̀sì. Ìbáwí jẹ́ ẹ̀rí tó dájú pé Jèhófà fẹ́ràn rẹ. (Héb. 12:6) Pinnu pé o kò ní ṣe ohun tó mú kó o dẹ́ṣẹ̀ yẹn mọ́, kó o sì ṣiṣẹ́ lórí ìpinnu rẹ. Lẹ́yìn tó o bá ti ronú pìwà dà tó o sì ti yí pa dà, ní ìgbàgbọ́ pé ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi lè mú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kúrò ní ti gidi.—1 Jòh. 4:9, 14.
16 Ọkàn àwọn míì kì í yé dá wọn lẹ́bi ẹ̀ṣẹ̀ tí Jèhófà ti dárí rẹ̀ jì wọ́n. Bó bá jẹ́ pé bí ọ̀ràn tìrẹ náà ṣe rí nìyẹn, rántí pé Jèhófà dárí ji Pétérù àti àwọn àpọ́sítélì yòókù bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n fi Jésù tó jẹ́ ààyò olùfẹ́ Ọmọ Ọlọ́run sílẹ̀, nígbà tó nílò wọn jù lọ. Jèhófà dárí ji ọkùnrin tí wọ́n yọ kúrò nínú ìjọ Kọ́ríńtì torí ìwà ìṣekúṣe bíburú jáì tó hù àmọ́ tó ronú pìwà dà lẹ́yìn náà. (1 Kọ́r. 5:1-5; 2 Kọ́r. 2:6-8) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ fún wa nípa àwọn tó dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì tí Ọlọ́run sì dárí jì wọ́n.—2 Kíró. 33:2, 10-13; 1 Kọ́r. 6:9-11.
17. Kí ni ìràpadà lè ṣe fún wa?
17 Jèhófà máa dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó o ti ṣẹ̀ tẹ́lẹ̀ jì ẹ́, ó sì máa gbàgbé wọn tó o bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn tó o sì gbà pé ó máa fi àánú hàn sí ẹ. Má ṣe ronú láé pé ẹbọ ìràpadà Jésù kò lè mú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ kúrò. Tó o bá ronú bẹ́ẹ̀, ìyẹn lè mú kó o kó sínú ọ̀kan lára àwọn ìdẹkùn Sátánì. Láìka ohun yòówù tí Èṣù lè fẹ́ kó o gbà gbọ́ sí, ẹbọ ìràpadà náà lè mú ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo àwọn tó bá ti dẹ́ṣẹ̀ tí wọ́n sì ti ronú pìwà dà kúrò. (Òwe 24:16) Bó o bá ń ní ìmọ̀lára ẹ̀bi tó kọjá bó ṣe yẹ, ìgbàgbọ́ nínú ìràpadà lé mú un kúrò, ó sì lè fún ẹ lókun kó o lè máa fi gbogbo ọkàn-àyà, èrò inú àti ọkàn rẹ sin Ọlọ́run.—Mát. 22:37.
A KÒ ṢE ALÁÌMỌ ÀWỌN ÈTE-ỌKÀN SÁTÁNÌ
18. Kí la lè ṣe ká máa bàa kó sínú ìdẹkùn Èṣù?
18 Sátánì ò fẹ́ mọ èyí tá a kó sí nínú àwọn ìdẹkùn rẹ̀, tiẹ̀ ṣáà ni pé kó rí wa mú. Níwọ̀n bí a kò ti ṣe aláìmọ àwọn ète-ọkàn Sátánì, ohun tá a lè ṣe wà kí Èṣù má bàa fi ọgbọ́n àyínìke rẹ̀ borí wa. (2 Kọ́r. 2:10, 11) Tá a bá ń gbàdúrà sí Jèhófà pé kó fún wa ní ọgbọ́n tá a máa fi kojú àwọn àdánwò wa, a kò ní kó sínú àwọn ìdẹkùn rẹ̀, ẹ̀bìtì rẹ̀ kò sì ní ré lù wá. Jákọ́bù sọ pé: “Bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá ṣaláìní ọgbọ́n, kí ó máa bá a nìṣó ní bíbéèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, nítorí òun a máa fi fún gbogbo ènìyàn pẹ̀lú ìwà ọ̀làwọ́ àti láìsí gíganni; a ó sì fi í fún un.” (Ják. 1:5) Ó pọn dandan pé ká máa ṣiṣẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú àdúrà wa nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ déédéé àti nípa fífi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò. Àwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì tí ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye ń mú jáde ń jẹ́ ká dá àwọn ohun tí Èṣù fi ń múni mọ̀, wọ́n sì ń jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè sá fún wọn.
19, 20. Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ kórìíra ohun tó burú?
19 Àdúrà àti ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì máa ń jẹ́ ká túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ ohun tó dára. Àmọ́, ó tún ṣe pàtàkì pé ká kórìíra ohun tó burú. (Sm. 97:10) Ṣíṣe àṣàrò lórí wàhálà tó lè jẹ yọ tó bá jẹ́ pé ohun tó bá ṣáà ti wù wá là ń ṣe, máa jẹ́ ká yẹra fún lílépa ìfẹ́ ọkàn wa. (Ják. 1:14, 15) Tá a bá kórìíra ohun tó burú tó sì jẹ́ pé lóòótọ́ la nífẹ̀ẹ́ ohun tó dára, ohun tí Sátánì fi ń tan àwọn èèyàn kó ní fà wá mọ́ra, ńṣe ló máa kó wa nírìíra.
20 Ẹ wo bó ti yẹ ká kún fún ọpẹ́ tó pé Ọlọ́run ń ràn wá lọ́wọ́ kí Sátánì má bàa fi ọgbọ́n àyínìke rẹ̀ borí wa! Nípasẹ̀ ẹ̀mí Rẹ̀, Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ètò rẹ̀, Jèhófà ń dá wa nídè “kúrò lọ́wọ́ ẹni burúkú náà.” (Mát. 6:13) Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa bá a ṣe lè sá fún ohun méjì míì tí Èṣù fi ń mú àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run láàyè.
-
-
Ẹ Dúró Gbọn-in Kẹ́ Ẹ Sì Sá Fún Àwọn Ohun Tí Sátánì Fi Ń Múni!Ilé Ìṣọ́—2012 | August 15
-
-
Ẹ Dúró Gbọn-in Kẹ́ Ẹ Sì Sá Fún Àwọn Ohun Tí Sátánì Fi Ń Múni!
“Ẹ . . . dúró gbọn-in gbọn-in lòdì sí àwọn ètekéte Èṣù.”—ÉFÉ. 6:11.
BÁWO LO ṢE MÁA DÁHÙN?
Kí ni ẹnì kan tó jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà lè ṣe kó má bàa kó sínú ìdẹkùn ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì?
Kí ló lè ran Kristẹni kan tó ti ṣègbéyàwó lọ́wọ́ kó má bàa kó sínú ọ̀fìn panṣágà?
Kí nìdí tó o fi gbà pé ó ṣàǹfààní kéèyàn má ṣe fàyè gba ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì àti ìṣekúṣe?
1, 2. (a) Kí nìdí tí Sátánì kò fi láàánú àwọn ẹni àmì òróró àti “àwọn àgùntàn mìíràn” lójú? (b) Àwọn ohun tí Sátánì fi ń múni wo la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
SÁTÁNÌ ÈṢÙ kò láàánú àwọn èèyàn lójú, pàápàá jù lọ àwọn tó ń sin Jèhófà. Ká sòótọ́, ńṣe ni Sátánì ń bá àwọn àṣẹ́kù ẹni àmì òróró jagun. (Ìṣí. 12:17) Àwọn Kristẹni adúróṣinṣin yìí ló ń mú ipò iwájú nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run lóde òní, wọ́n sì ń tú àṣírí Sátánì pé òun ni olùṣàkóso ayé yìí. Bákan náà, Èṣù kò nífẹ̀ẹ́ “àwọn àgùntàn mìíràn” tí wọ́n ń ṣètìlẹ́yìn fún àwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n sì nírètí láti jogún ìyè àìnípẹ̀kun, èyí tó ti bọ́ mọ́ Sátánì lọ́wọ́. (Jòh. 10:16) Abájọ tó fi ń bínú kíkan-kíkan! Yálà a ní ìrètí láti lọ sí ọ̀run tàbí láti wà lórí ilẹ̀ ayé, ire wa kò jẹ Sátánì lógún, bó ṣe máa sọ wá di ẹran ọdẹ rẹ̀ ló ń wá.—1 Pét. 5:8.
2 Kí ọwọ́ Sátánì lè tẹ̀ wá, ó ti dẹ onírúurú páńpẹ́ tàbí ìdẹkùn. Níwọ̀n bó sì ti “fọ́ èrò inú” àwọn aláìgbàgbọ́, wọn kì í fẹ́ gba ìhìn rere, wọn ò sì lè rí àwọn ìdẹkùn yìí. Àmọ́ ṣá o, Èṣù tún ń dẹkùn mú àwọn kan tí wọ́n ti tẹ́wọ́ gba ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. (2 Kọ́r. 4:3, 4) Àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí sọ bá a ṣe lè sá fún mẹ́ta lára àwọn ohun tí Sátánì fi ń múni, ìyẹn (1) sísọ̀rọ̀ gbàùgbàù, (2) ìbẹ̀rù àti ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe àti (3) ìmọ̀lára ẹ̀bi tó kọjá bó ṣe yẹ. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wá sọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe lè dúró gbọin-in lòdì sí méjì míì lára àwọn ohun tí Sátánì fi ń múni, ìyẹn ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì àti ìdánwò láti ṣe panṣágà.
ÌFẸ́ ỌRỌ̀ ÀLÙMỌ́Ọ́NÌ, OKÙN TÍ Ń FÚNNI PA
3, 4. Báwo ni àníyàn ètò àwọn nǹkan yìí ṣe lè mú ká máa nífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì?
3 Nínú ọ̀kan lára àwọn àkàwé Jésù, ó sọ̀rọ̀ nípa irúgbìn tí wọ́n gbìn sáàárín ẹ̀gún. Ó ṣàlàyé pé ẹnì kan lè gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, ‘ṣùgbọ́n kí àníyàn ètò àwọn nǹkan yìí àti agbára ìtannijẹ ọrọ̀ fún ọ̀rọ̀ náà pa, kó sì di aláìléso.’ (Mát. 13:22) Ó dájú pé ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì jẹ́ ọ̀kan lára ìdẹkùn tí Sátánì tó jẹ́ ọ̀tá wa ń lò.
4 Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fi hàn pé ohun méjì ló fún ọ̀rọ̀ náà pa. Èyí àkọ́kọ́ ni “àníyàn ètò àwọn nǹkan yìí.” Ní “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” yìí, ọ̀pọ̀ nǹkan ló lè mú kó o máa ṣàníyàn. (2 Tím. 3:1) Nítorí bí àwọn nǹkan ṣe túbọ̀ ń gbówó lórí, tí ọ̀pọ̀ èèyàn ò sì níṣẹ́ lọ́wọ́, ó lè ṣòro fún ẹ láti máa wá jíjẹ mímu. O tún lè máa ṣàníyàn nípa ọjọ́ ọ̀la, kó o sì máa ṣe kàyéfì pé, ‘Ǹjẹ́ màá máa rí owó tó pọ̀ tó ná lẹ́yìn tí mo bá fẹ̀yìn tì?’ Bí àwọn kan ṣe ń ṣàníyàn ti mú kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í lépa ọrọ̀, wọ́n ronú pé bí àwọn bá lówó lọ́wọ́ ọkàn àwọn á balẹ̀.
5. Báwo ni ‘agbára ọrọ̀’ ṣe lè tanni jẹ?
5 Jésù tún sọ̀rọ̀ nípa ohun kejì, ìyẹn ni “agbára ìtannijẹ ọrọ̀.” Èyí, pa pọ̀ pẹ̀lú àníyàn, lè fún ọ̀rọ̀ náà pa. Òótọ́ ni Bíbélì sọ pé ‘owó jẹ́ fún ìdáàbòbò.’ (Oníw. 7:12) Àmọ́, kò bọ́gbọ́n mu kéèyàn máa lépa ọrọ̀. Ọ̀pọ̀ ti rí i pé bí àwọn ṣe ń sapá tó láti kó ọrọ̀ jọ, bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì túbọ̀ ń dẹkùn mú àwọn. Àwọn kan tiẹ̀ ti di ẹrú fún ọrọ̀.—Mát. 6:24.
6, 7. (a) Kí ló lè mú kéèyàn di ẹni tó ní ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì níbi tó ti ń ṣiṣẹ́? (b) Bí wọ́n bá ní kí Kristẹni kan wá máa ṣe àfikún iṣẹ́, kí làwọn ohun tó yẹ kó gbé yẹ̀ wò?
6 Ìfẹ́ láti di ọlọ́rọ̀ lè bẹ̀rẹ̀ bí ohun kan tí kò fi bẹ́ẹ̀ burú. Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa ìṣẹ̀lẹ̀ yìí. Ẹni tó gbà ẹ́ síṣẹ́ wá bá ẹ ó sì sọ fún ẹ pé: “Mo ní ìròyìn ayọ̀ kan fún ẹ! Wọ́n ti gbé iṣẹ́ ńlá kan fún ilé iṣẹ́ wa. Èyí túmọ̀ sí pé ní báyìí títí di oṣù mélòó kan, wàá máa ṣe àfikún iṣẹ́ lemọ́lemọ́. Àmọ́, mo fẹ́ kó dá ẹ lójú pé tó o bá ṣe iṣẹ́ náà owó tó jọjú ló máa wọlé fún ẹ.” Bó bá jẹ́ ìwọ ni wọ́n fi irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ lọ̀, kí lo máa ṣe? Òótọ́ ni pé ó ṣe pàtàkì kó o gbọ́ bùkátà ìdílé rẹ, àmọ́ ìyẹn nìkan kọ́ ni ojúṣe tó o ní. (1 Tím. 5:8) Àwọn ohun mélòó kan tún wà tó o gbọ́dọ̀ gbé yẹ̀ wò. Báwo ni àfikún iṣẹ́ tí wàá máa ṣe á ṣe pọ̀ tó? Ǹjẹ́ iṣẹ́ rẹ á jẹ́ kó o lè máa lọ́wọ́ sí àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí, tó fi mọ́ àwọn ìpàdé ìjọ àti Ìjọsìn Ìdílé?
7 Tó o bá ń ronú nípa ohun tó o máa ṣe, kí lo máa kà sí ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ, ṣé bí owó táá máa wọlé fún ẹ á ṣe pọ̀ tó ni àbí ipa tó máa ní lórí àjọṣe rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run? Ṣé bó o ṣe ń fẹ́ láti ní owó púpọ̀ sí i á mú kó o jáwọ́ nínú fífi ire Ìjọba Ọlọ́run sí ipò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé rẹ? Ǹjẹ́ o rí bí ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì ṣe máa nípa lórí rẹ bí o kò bá fọwọ́ pàtàkì mú ipò tẹ̀mí rẹ àti ti ìdílé rẹ? Bí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ń ṣẹlẹ̀ sí ẹ ní báyìí, báwo lo ṣe lè dúró gbọn-in, kó o má sì ṣe jẹ́ kí ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì fún ẹ pa?—Ka 1 Tímótì 6:9, 10.
8. Àwọn àpẹẹrẹ inú Ìwé Mímọ́ wo ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣàyẹ̀wò bá a ṣe ń gbé ìgbésí ayé wa?
8 Bí o kò bá fẹ́ kí ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì fún ẹ pa, ó yẹ kó o máa ṣàyẹ̀wò bó o ṣe ń gbé ìgbésí ayé rẹ déédéé. Ó dájú pé o kò ní fẹ́ dà bí Ísọ̀, tí ìwà rẹ̀ fi hàn pé kò ka àwọn nǹkan tẹ̀mí sí pàtàkì! (Jẹ́n. 25:34; Héb. 12:16) Ó sì dájú pé o kò ní fẹ́ dà bí ọkùnrin ọlọ́rọ̀ tí wọ́n sọ fún pé kó ta gbogbo ohun ìní rẹ̀, kó fi owó tó rí tọrẹ fáwọn òtòṣì, kó sì máa tọ Jésù lẹ́yìn. Àmọ́, dípò tí ọkùnrin náà ì bá fi ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe lo “lọ kúrò pẹ̀lú ẹ̀dùn-ọkàn, nítorí ó ní ohun ìní púpọ̀.” (Mát. 19:21, 22) Torí pé ọrọ̀ ti dẹkùn mú ọkùnrin ọlọ́rọ̀ náà, kò ṣeé ṣe fún un láti máa tọ Jésù tó jẹ́ ọkùnrin títóbi lọ́lá jù lọ tó tíì gbé ayé rí lẹ́yìn, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ pàdánù àǹfààní ńlá! Ṣọ́ra kó o má bàa pàdánù àǹfààní jíjẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi.
9, 10. Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ, ojú wo ló yẹ ká máa fi wo àwọn nǹkan tara?
9 Kó o má bàa máa ṣe àníyàn jù nípa àwọn nǹkan tara, ó dára kó o fi ìmọ̀ràn Jésù sílò. Ó sọ pé: “Ẹ má ṣàníyàn láé, kí ẹ sì wí pé, ‘Kí ni a ó jẹ?’ tàbí, ‘Kí ni a ó mu?’ tàbí, ‘Kí ni a ó wọ̀?’ Nítorí gbogbo ìwọ̀nyí ni nǹkan tí àwọn orílẹ̀-èdè ń fi ìháragàgà lépa. Nítorí Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run mọ̀ pé ẹ nílò gbogbo nǹkan wọ̀nyí.”—Mát. 6:31, 32; Lúùkù 21:34, 35.
10 Dípò tí wàá fi kó sínú ìdẹkùn agbára ìtannijẹ ọrọ̀, ńṣe ni kó o wo ọ̀rọ̀ náà bíi ti Ágúrì tó jẹ́ òǹkọ̀wé Bíbélì. Ó sọ pé: “Má ṣe fún mi ní ipò òṣì tàbí ti ọrọ̀. Jẹ́ kí n jẹ ìwọ̀n oúnjẹ tí ó jẹ́ ìpín tèmi.” (Òwe 30:8) Ó ṣe kedere pé Ágúrì mọ̀ pé owó lè dáàbò boni àti pé ọrọ̀ lágbára láti tanni jẹ. Ó yẹ kó o mọ̀ pé àníyàn ètò àwọn nǹkan yìí àti agbára ìtannijẹ ọrọ̀ lè ba àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. Tó o bá ń ṣàníyàn láìnídìí nípa àwọn nǹkan tara, ó lè gba àkókò rẹ, ó lè tán ẹ lókun, o lè má fi bẹ́ẹ̀ wá Ìjọba Ọlọ́run mọ́ tàbí kó o ṣíwọ́ láti máa wá a. Torí náà, pinnu pé o kò ní jẹ́ kí Sátánì fi ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì dẹkùn mú ẹ!—Ka Hébérù 13:5.
PANṢÁGÀ, Ọ̀FÌN TÓ FARA SIN
11, 12. Báwo ni Kristẹni kan ṣe lè kó sínú ọ̀fìn ṣíṣe panṣágà níbi iṣẹ́ rẹ̀?
11 Bí àwọn ọdẹ bá fẹ́ mú ẹranko kan tó lágbára, wọ́n lè gbẹ́ kòtò sí ojú ọ̀nà tó sábà máa ń gbà, wọ́n á wá to àwọn igi tẹ́ẹ́rẹ́ sórí kòtò náà, wọ́n á sì da iyẹ̀pẹ̀ bò ó. Ọ̀fìn yìí la lè fi wé irú ìdẹwò kan tí Sátánì máa ń lò jù lọ láti mú ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe ohun tí kò tọ́, ìyẹn ni ìṣekúṣe. (Òwe 22:14; 23:27) Àwọn Kristẹni kan ti jìn sínú ọ̀fìn yìí torí pé wọ́n fira wọn sípò tó ti rọrùn láti ṣèṣekúṣe. Àwọn Kristẹni kan tí wọ́n ti ṣègbéyàwó máa ń fa ojú ẹni tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya wọn mọ́ra, èyí sì ti mú kí wọ́n ṣe panṣágà.
12 O lè bẹ̀rẹ̀ sí í fa ojú ẹni tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya rẹ̀ mọ́ra níbi tó o ti ń ṣiṣẹ́. Kódà, ìwádìí kan fi hàn pé iye tó ju ìdajì lọ nínú àwọn obìnrin àti nǹkan bíi mẹ́ta nínú àwọn ọkùnrin mẹ́rin tó ń ṣe panṣágà ló jẹ́ pé ẹni tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ ni wọ́n bá ṣèṣekúṣe. Ṣé iwọ àtàwọn tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya rẹ lẹ jọ ń ṣiṣẹ́? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, irú àjọṣe wo ló wà láàárín yín? Ǹjẹ́ o ti ṣe àwọn nǹkan tí kò ní jẹ́ kí ohun tó máa dà yín pọ̀ kọjá iṣẹ́? Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tí arábìnrin kan bá ti ń bá òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tó jẹ́ ọkùnrin sọ ọ̀rọ̀ tí kò jẹ mọ́ iṣẹ́ léraléra, ó lè sọ ọkùnrin náà di alábàárò rẹ̀ kó sì tún wá máa sọ àwọn ìṣòro tó ń dojú kọ nínú ìgbéyàwó rẹ̀ fún un. Ní ọwọ́ mìíràn ẹ̀wẹ̀, bí arákùnrin kan bá ń yan obìnrin tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ lọ́rẹ̀ẹ́, ó lè máa ronú pé: “Ó máa ń ka ọ̀rọ̀ mi sí, ó sì máa ń fetí sílẹ̀ dáadáa tí mo bá ń bá a sọ̀rọ̀. Ó sì tún mọyì mi. Ì bá wù mí ká sọ pé bí ìyàwó mi ṣe ń ṣe sí mi nílé rèé!” Ǹjẹ́ o ti wá rí bó ṣe rọrùn tó fún irú Kristẹni bẹ́ẹ̀ láti ṣe panṣágà?
13. Báwo lèèyàn ṣe lè bẹ̀rẹ̀ sí í fa ojú ẹlòmíì mọ́ra nínú ìjọ?
13 Ó lè ṣẹlẹ̀ pé kí àwọn tó wà nínú ìjọ máa fa ojú ara wọn mọ́ra. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí tọkọtaya kan rèé. Aṣáájú-ọ̀nà déédéé ni Daniel àti Saraha ìyàwó rẹ̀. Alàgbà ni Daniel, ṣùgbọ́n ó sọ pé òun ò mọ béèyàn ṣe ń kọ nǹkan. Ó máa ń yá a lára láti tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ èyíkéyìí tí wọ́n bá fún un nínú ìjọ. Gẹ́gẹ́ bí ara iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, Daniel darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àwọn ọ̀dọ́kùnrin márùn-ún, mẹ́ta lára wọn sì ti ṣe ìrìbọmi. Àwọn arákùnrin tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe ìrìbọmi yìí nílò ẹni tí wọ́n á máa fi ọ̀ràn lọ̀. Àmọ́, torí pé onírúurú iṣẹ́ tí Daniel ń bójú tó nínú ìjọ máa ń jẹ́ kí ọwọ́ rẹ̀ dí, Sarah ló máa ń pèsè ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n bá nílò fún wọn. Bó ṣe di pé Sarah di alábàárò àwọn tí ọkọ rẹ̀ kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yìí nìyẹn, bẹ́ẹ̀ náà làwọn pẹ̀lú sì di alábàárò Sarah. Ó wá dà bí ìgbà tí Sarah ń rìn ní bèbè ọ̀fìn ńlá kan. Daniel sọ pé: “Ọ̀pọ̀ oṣù ni ìyàwó mi fi gbọ́ tàwọn arákùnrin yìí. Ìyẹn ò jẹ́ kó fi bẹ́ẹ̀ ráyè kẹ́kọ̀ọ́ mọ́, kò sì rẹ́ni sọ tinú rẹ̀ fún. Èyí, pa pọ̀ pẹ̀lú bí mi ò ṣe ráyè gbọ́ tiẹ̀, wá mú kí wàhálà ṣẹlẹ̀. Ìyàwó mi ṣe panṣágà pẹ̀lú ọ̀kan lára àwọn tí mo kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú ilé kan náà la jọ ń gbé, àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà ti jó rẹ̀yìn pátápátá. Àwọn iṣẹ́ tí mò ń bójú tó nínú ìjọ sì ti gbà mí lọ́kàn débi pé mi ò kíyè sí i.” Kí lo lè ṣe tí irú èyí ò fi ní ṣẹlẹ̀ sí ẹ?
14, 15. Àwọn nǹkan wo ló lè ran àwọn Kristẹni tó ti ṣègbéyàwó lọ́wọ́ tí wọn kò fi ní kó sínú ọ̀fìn panṣágà?
14 Kó o má bàa kó sínú ọ̀fìn panṣágà, ronú nípa àdéhùn tó o ṣe pẹ̀lú ọkọ tàbí aya rẹ. Jésù sọ pé: “Ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀.” (Mát. 19:6) Má ṣe ronú pé àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tó o ní ṣe pàtàkì ju ọkọ tàbí aya rẹ lọ. Kó o sì tún rántí pé tó o bá sábà máa ń fi ọkọ tàbí aya rẹ sílẹ̀ láti lọ jókòó sídìí àwọn nǹkan tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì, ìyẹn lè fi hàn pé ìdè ìgbéyàwó yín kò lágbára mọ́, èyí lè fa ìdẹwò, ó sì lè yọrí sí dídá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì.
15 Tó o bá jẹ́ alàgbà, kí lo máa ṣe nípa agbo? Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé: “Ẹ máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run tí ń bẹ lábẹ́ àbójútó yín, kì í ṣe lábẹ́ àfipáṣe, bí kò ṣe tinútinú; bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe nítorí ìfẹ́ fún èrè àbòsí, bí kò ṣe pẹ̀lú ìháragàgà.” (1 Pét. 5:2) Ó dájú pé kò yẹ kó o pa àwọn ará ìjọ tó wà lábẹ́ àbójútó rẹ tì. Àmọ́, o kò gbọ́dọ̀ pa ojúṣe rẹ gẹ́gẹ́ bí ọkọ tì torí kó o lè bójú tó ojúṣe rẹ gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn. Kò sídìí tó o fi ní láti gbájú mọ́ fífi oúnjẹ tẹ̀mí bọ́ ìjọ nígbà tí “ebi” tẹ̀mí ń pa ìyàwó rẹ nílé, kódà ó léwu láti ṣe bẹ́ẹ̀. Daniel sọ pé, “Gbígbé ìgbé ayé tó dára ò túmọ̀ sí pé kéèyàn pa ìdílé rẹ̀ tì torí kó lè máa bójú tó àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn.”
16, 17. (a) Àwọn nǹkan wo làwọn Kristẹni tó ti ṣègbéyàwó lè ṣe níbi iṣẹ́ tó máa fi hàn kedere pé wọn ò gbà kéèyàn fa ojú àwọn mọ́ra? (b) Ìtẹ̀jáde wo ló lè ran àwọn Kristẹni lọ́wọ́ kí wọ́n má bàa ṣe panṣágà?
16 Ọ̀pọ̀ ìmọ̀ràn tó lè ran àwọn Kristẹni tó ti ṣègbéyàwó lọ́wọ́ kí wọ́n má bàa kó sínú ìdẹkùn panṣágà la ti tẹ̀ jáde nínú àwọn ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Bí àpẹẹrẹ, Ilé Ìṣọ́ September 15, 2006, fúnni ní ìmọ̀ràn yìí: “Tó o bá wà níbi iṣẹ́ tàbí láwọn ibòmíì, yẹra fún àwọn ipò tó lè mú kí ọkàn rẹ máa fà sí obìnrin tàbí ọkùnrin míì. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá dúró lẹ́yìn iṣẹ́ láti ṣe àfikún iṣẹ́ tó sì jẹ́ pé obìnrin tàbí ọkùnrin mìíràn lẹ jọ fẹ́ ṣiṣẹ́ ọ̀hún, èyí lè jẹ́ ìdẹwò fún ọ. Gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ti lọ́kọ tàbí tó ti níyàwó, tó o bá wà níbi iṣẹ́, ó yẹ kó hàn nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe rẹ pé o ò gbàgbàkugbà. Ó dájú pé ìwọ tó ò ń fi tọkàntọkàn sin Ọlọ́run ò ní fẹ́ fa ojú ẹlòmíràn mọ́ra nípa bíbá a tage tàbí nípa wíwọṣọ tàbí mímúra lọ́nà tí kò bójú mu. . . . Tó o bá fi fọ́tò ọkọ tàbí aya rẹ àti tàwọn ọmọ rẹ sí ibi iṣẹ́ rẹ, èyí á jẹ́ kí ìwọ àtàwọn ẹlòmíì máa rántí pé ìdílé rẹ ló ṣe pàtàkì sí ọ jù. Pinnu pé o ò ní ṣe ohun táá jẹ́ kí ẹlòmíì fẹ́ láti fa ojú rẹ mọ́ra, tẹ́nì kan bá sì wá fẹ́ fa ojú ẹ mọ́ra, má ṣe gbà fún un.”
17 Àpilẹ̀kọ inú ìwé ìròyìn Jí! April–June 2009 tó ní àkòrí náà, “Kí Ló Túmọ̀ sí Pé Kí Ọkọ Tàbí Aya Má Dalẹ̀ Ara Wọn?” sọ pé kò dára kéèyàn máa ronú pé òun ń bá ọkùnrin tàbí obìnrin tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya rẹ̀ lò pọ̀. Àpilẹ̀kọ náà fi hàn pé bí ẹnì kan bá ń ronú pé òun ń bá ẹlòmíì lò pọ̀, ó ṣeé ṣe kó túbọ̀ rọrùn fún un láti ṣe panṣágà. (Ják. 1:14, 15) Tó o bá ti ṣe ìgbéyàwó, ohun tó máa mọ́gbọ́n dání ni pé kí ìwọ àti ẹnì kejì rẹ jọ máa jíròrò irú àwọn àpilẹ̀kọ bẹ́ẹ̀ látìgbàdégbà. Jèhófà fúnra rẹ̀ ló dá ètò ìgbéyàwó sílẹ̀, ohun mímọ́ ló sì jẹ́. Tó o bá ń ya àkókò sọ́tọ̀ láti bá ọkọ tàbí aya rẹ sọ̀rọ̀ nípa ìgbéyàwó yín, ńṣe lò ń fi hàn pé o mọyì àwọn nǹkan mímọ́.—Jẹ́n. 2:21-24.
18, 19. (a) Àwọn nǹkan wo ni panṣágà máa ń yọrí sí? (b) Kí ni jíjẹ́ olóòótọ́ nínú ìgbéyàwó máa ń yọrí sí?
18 Tó o bá rí i pé ọkàn rẹ ti ń fẹ́ máa fà sí ẹnì kan tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya rẹ, ronú nípa bí ṣíṣe àgbèrè àti panṣágà ṣe máa ń yọrí sí ibi tí kò dáa. (Òwe 7:22, 23; Gál. 6:7) Téèyàn bá ṣèṣekúṣe, ó máa ń dun Jèhófà, yóò sì ṣèpalára fún ọkọ tàbí aya onítọ̀hún àtẹni tó ṣèṣekúṣe náà. (Ka Málákì 2:13, 14.) Nípa bẹ́ẹ̀, ṣe ni kó o máa ronú lórí àwọn àǹfààní tí àwọn tó jẹ́ oníwà mímọ́ máa ní. Kì í ṣe pé wọ́n máa ní ìrètí láti wà láàyè títí láé nìkan ni, àmọ́ wọ́n tún máa gbádùn ìgbésí ayé tó dára jù lọ báyìí, wọ́n á sì ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́.—Ka Òwe 3:1, 2.
19 Onísáàmù náà kọrin pé: “Ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà jẹ́ ti àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ [Ọlọ́run], kò sì sí ohun ìkọ̀sẹ̀ fún wọn.” (Sm. 119:165) Torí náà, nífẹ̀ẹ́ òtítọ́, kó o sì “máa ṣọ́ra lójú méjèèjì pé bí [o] ṣe ń rìn” ní àwọn àkókò búburú tá à ń gbé yìí “kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí aláìlọ́gbọ́n ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n.” (Éfé. 5:15, 16) Ojú ọ̀nà tá à ń tọ̀ kún fún àwọn ìdẹkùn tí Sátánì fẹ́ láti fi mú àwọn olùjọsìn tòótọ́. Àmọ́, a ti ní ọ̀pọ̀ nǹkan tá a lè fi dáàbò bo ara wa. Jèhófà ti fún wa ní ohun tá a nílò láti “dúró gbọn-in gbọn-in” ká lè “paná gbogbo ohun ọṣẹ́ oníná ti ẹni burúkú náà”!—Éfé. 6:11, 16.
-