Orin 51
A Rọ̀ Mọ́ Jèhófà
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Jèhófà Ọba fi hàn pé òun nìjọsìn yẹ.
Ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀, ìdájọ́ òdodo ńhàn.
Kò sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ kan tó máa já sí asán.
A rọ̀ mọ́ Jèhófà, láìkúrò lọ́dọ̀ rẹ̀;
Títẹ̀ lé àṣẹ rẹ̀, èrè láéláé ló jẹ́.
2. Òótọ́ àtìdájọ́
òdodo ni ìtẹ́ rẹ̀.
Inú ògo dídán ló fi ṣe ibùgbé rẹ̀.
Ọlọ́kàn tútù tó pè ńrọ́ wá sọ́dọ̀ rẹ̀.
A rọ̀ mọ́ Jèhófà, Ọlọ́run gíga jù;
Òun ló yẹ ká máa sìn ká sì tún máa gbé ga.
3. Ọ̀run àwọn ọ̀run kò lè gba Ọlọ́run wa.
Kò sọ́tàá tó lè ta kòó, wọn kò lè dènà rẹ̀.
Ó dájú pé yóò mú gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ.
A rọ̀ mọ́ Jèhófà; Ìfẹ́ rẹ̀ la ńfẹ́ ṣe,
Kí ìfọkànsìn wa fúnun sì máa jinlẹ̀ síi.
(Tún wo Diu. 4:4; 30:20; 2 Ọba 18:6; Sm. 89:14.)