Orin 129
Dídi Ìrètí Wa Mú Ṣinṣin
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ̀dá ti fi wà lókùnkùn.
Wọ́n ńsapá lásán, ẹ̀fúùfù ni wọ́n ńlé.
Ẹ̀ṣẹ̀ kò jẹ́ kí wọ́n lè gbara wọn là,
Àléébù wọn yìí hàn kedere.
(ÈGBÈ)
Fayọ̀ kọrin, Ìjọba Jáà dé tán!
Ń’nú àkóso Ọmọ rẹ̀,
ẹ̀rù yóò tán.
Nípasẹ̀ rẹ̀, ibi yóò tán láìpẹ́;
Ìrètí yìí ló fi wá lọ́kàn balẹ̀.
2. A ńkéde pé, “Ọjọ́ Ọlọ́run sún mọ́lé!”
Ẹ̀dá kò ní ké mọ́ pé: “Yóò ti pẹ́ tó?”
Láìpẹ́, ìtura yóò bá gbogbo ẹ̀dá.
Ẹ forin yin Olódùmarè.
(ÈGBÈ)
Fayọ̀ kọrin, Ìjọba Jáà dé tán!
Ń’nú àkóso Ọmọ rẹ̀,
ẹ̀rù yóò tán.
Nípasẹ̀ rẹ̀, ibi yóò tán láìpẹ́;
Ìrètí yìí ló fi wá lọ́kàn balẹ̀.
(Tún wo Háb. 1:2, 3; Sm. 27:14; Jóẹ́lì 2:1; Róòmù 8:22.)