Orin 70
“Máa Wádìí Dájú Àwọn Ohun Tí Ó Ṣe Pàtàkì Jù”
1. A nílò ìfòyemọ̀ gan-an lónìí,
Ká lè mohun tó jóòótọ́,
Ká lè mohun tó ṣe pàtàkì jù,
Ká mohun táa gbọ́dọ̀ ṣe!
Nífẹ̀ẹ́ ire; Sá fún ibi.
Mọ́kàn Jáà yọ̀;
Yóò fún ọ láyọ̀. Máa gba àdúrà;
Kóo máa kẹ́kọ̀ọ́.
Ohun pàtàkì yìí laó máa ṣe.
2. Kí ló tún lè ṣe pàtàkì ju pé
Ká wàásù ìhìn rere,
Ká wá àgùntàn Baba wa tó nù
Ká sì fọ̀nà rẹ̀ hàn wọ́n?
Wọ́n gbọ́dọ̀ gbọ́; Wọ́n gbọ́dọ̀ mọ̀.
Ẹ jẹ́ ká máa
Fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn, kí wọ́n lè
Dòmìnira!
Iṣẹ́ ìwàásù ṣe pàtàkì.
3. Táa bá lè ńṣohun tó ṣe pàtàkì,
Ìgbàgbọ́ wa kò ní mì.
Aó lálàáfíà tẹ́dàá kò lè mú wá,
Ìrètí wa yóò dájú.
Aó ní ọ̀rẹ́; Aó rí ìfẹ́.
Yóò sì jinlẹ̀.
Ká kọ́ ohun pàtàkì, ká mọ̀ wọ́n,
Ká máa ṣe wọ́n,
Ìbùkún ńlá ló máa jẹ́ fún wa!
(Tún wo Sm. 97:10; Mát. 22:37; Jòh. 21:15-17; Ìṣe 10:42.)