Orin 29
Rírìn Nínú Ìwà Títọ́
Bíi Ti Orí Ìwé
(Sáàmù 26)
1. Ṣèdájọ́ mi, Jèhófà yẹ̀ mí wò;
Wo ìwà títọ́ mi, mo gbẹ́kẹ̀ mi lé ọ.
Wádìí mi wò, kí o sì dán mi wò;
Tún yọ́ ọkàn mi mọ́, kín lè ní ìbùkún.
(ÈGBÈ)
Ṣùgbọ́n ńtèmi, Mo ti pinnu wí pé
Nó máa rìn títí láé Ń’nú ìwà títọ́ mi.
2. Èmi kò bá ẹni ibi jókòó.
Mo kórìíra àwọn tí kò fẹ́ràn òótọ́.
Má ṣe gbẹ̀mí mi mọ́ tẹni ibi;
Ọwọ́ ẹni tí ó kún fún àbẹ̀tẹ́lẹ̀.
(ÈGBÈ)
Ṣùgbọ́n ńtèmi, Mo ti pinnu wí pé
Nó máa rìn títí láé Ń’nú ìwà títọ́ mi.
3. Mo ní ìfẹ́ ibùgbé ilé rẹ.
Ìjọsìn rẹ mímọ́ lèmi yóò máa lépa.
Èmi yóò máa rìn yí pẹpẹ rẹ ká,
Ká lè gbóhùn ọpẹ́ jákèjádò ayé.
(ÈGBÈ)
Ṣùgbọ́n ńtèmi, Mo ti pinnu wí pé
Nó máa rìn títí láé Ń’nú ìwà títọ́ mi.
(Tún wo Sm. 25:2.)