ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ǹjẹ́ Ọlọ́run Máa Ń Ronú Nípa Rẹ?
    Ilé Ìṣọ́—2014 | August 1
    • KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ǸJẸ́ ỌLỌ́RUN BÌKÍTÀ NÍPA RẸ?

      Ǹjẹ́ Ọlọ́run Máa Ń Ronú Nípa Rẹ?

      “Ẹni tí a ń ṣẹ́ níṣẹ̀ẹ́ àti òtòṣì ni mí. Jèhófà tìkára rẹ̀ ń gba tèmi rò.”a​—DÁFÍDÌ, ỌBA ÍSÍRẸ́LÌ NÍ ỌGỌ́RÙN-ÚN ỌDÚN KỌKÀNLÁ.

      [Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

      “Àwọn orílẹ̀-èdè dà bí ẹ̀kán omi kan láti inú korobá.”—AÍSÁYÀ 40:15

      Ṣé ó burú tí Dáfídì bá sọ pé kí Ọlọ́run gba tòun rò? Ǹjẹ́ Ọlọ́run máa ń ronú nípa rẹ? Ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò gbà pé Ọlọ́run Olódùmarè rí tàwọn rò rárá. Kí nìdí tí wọ́n fi rò bẹ́ẹ̀?

      Ìdí ni pé wọ́n mọ̀ pé Ọlọ́rùn wà ní ipò tí ó ga fíofío ju tàwa èèyàn lọ. Tá a bá ní ká wo ipò tí Ọlọ́run wà sí tèèyàn lóòótọ́, Bíbélì sọ pé ńṣe ni gbogbo orílẹ̀-èdè “dà bí ẹ̀kán omi kan láti inú korobá; bí ekuru fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ lórí òṣùwọ̀n sì ni a kà wọ́n sí.” (Aísáyà 40:15) Òǹkọ̀wé kan ṣàríwísí pé: “A kàn ń tanra wa lásán ni tá a bá rò pé Ọlọ́run wà níbi kan tó rí tiwa rò.”

      Ohun táwọn míì tún rò ni pé ibi tí ìwà àwọn burú dé, àwọn ò yẹ lẹ́ni tí Ọlọ́run lè ronú kàn. Bí àpẹẹrẹ, ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Jim sọ pé: “Mo máa ń gbàdúrà pé kí Ọlọ́run jẹ́ kí n ní àmúmọ́ra, kí n sì jẹ́ èèyàn àlàáfíà, àmọ́ kì í pẹ́ tí nǹkan kékeré á tún fi múnú bí mi. Ni mo bá kúkú gba kámú pé bóyá ìwà mi ti burú débi pé mi ò lè rí ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run gbà.”

      Ṣé Ọlọ́run wá jìnnà sí wa débi pé kò tiẹ̀ ń kíyè sí wa rárá? Ǹjẹ́ àwa èèyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ já mọ́ nǹkan kan lójú rẹ̀? Láì jẹ́ pé Ọlọ́run fúnra rẹ̀ jẹ́ ká mọ ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí, kò sí ẹ̀dá kankan tó lè sọ pé bọ́rọ̀ ṣe rí rèé. Inú wá sì dùn pé nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Ó jẹ́ ká lóye pé òun kò jìnnà sí wa àti pé òun máa ń ronú nípa wa. Kódà, Bíbélì sọ pé “ní ti tòótọ́, kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.” (Ìṣe 17:27) Nínú àwọn àkòrí mẹ́rin tó tẹ̀ lé e, a máa gbé ohun tí Ọlọ́run sọ nípa wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan yẹ̀ wò àti bó ṣe fi hàn pé òun bìkítà fún àwọn èèyàn bíi tìrẹ.

      a Sáàmù 40:17; Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.

  • Ọlọ́run Máa Ń bójú Tó Ẹ
    Ilé Ìṣọ́—2014 | August 1
    • KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ǸJẸ́ ỌLỌ́RUN BÌKÍTÀ NÍPA RẸ?

      Ọlọ́run Máa Ń bójú Tó Ẹ

      “Ojú [Ọlọ́run] ń bẹ ní àwọn ọ̀nà ènìyàn, ó sì ń rí ìṣísẹ̀ rẹ̀ gbogbo.”—JÓÒBÙ 34:21.

      [Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

      Bí ọjọ́ orí ọmọ bá ṣe kéré sí náà ló ṣe máa nílò àbójútó sí

      ÌDÍ TÁWỌN KAN FI Ń ṢIYÈMÉJÌ: Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí fi hàn pé ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ Onírìísí Wàrà, ìyẹn Milky Way galaxy tí ayé yìí wà nínú rẹ̀ ní ohun tó ju ọgọ́rùn-ún bílíọ̀nù pílánẹ́ẹ̀tì lọ. Nígbà táwọn èèyàn wo bí ọ̀run ṣe lọ salalu, wọ́n ronú pé, ‘Kí ni Ọlọ́run Olódùmarè fẹ́ rí lára àwa èèyàn tá a rí tíntìntín lórí ilẹ̀ ayé tó kéré yìí?’

      OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: Ọlọ́run ò kàn fún wa ní Bíbélì kó sì pa wá tì. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jèhófà fi dá wa lójú pé: “Èmi yóò fún ọ ní ìmọ̀ràn pẹ̀lú ojú mi lára rẹ.”—Sáàmù 32:8.

      Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí obìnrin ará Íjíbítì kan tó ń jẹ́ Hágárì, ní ọgọ́rùn-ún ọdún lọ́nà ogún ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Nígbà tí ó hùwà àrífín sí Sáráì ọ̀gá rẹ̀, Sáráì náà sì kàn án lábùkù, ni Hágárì bá sá lọ sínú aginjù. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Hágárì ṣàṣìṣe, Ọlọ́run ò pa á tì. Bíbélì sọ pé: “Áńgẹ́lì Jèhófà rí i.” Áńgẹ́lì náà sọ fún Hágárì pé: “Jèhófà ti gbọ́ nípa ṣíṣẹ́ tí a ń ṣẹ́ ọ níṣẹ̀ẹ́.” Lẹ́yìn náà, Hágárì sọ fún Jèhófà pé: ‘Ìwọ ni Ọlọ́run tó ń rí ohun gbogbo.’—Jẹ́nẹ́sísì 16:4-13.

      ‘Ọlọ́run tó ń rí ohun gbogbo’ ń fi ìṣọ́ rẹ̀ ṣọ́ ìwọ náà. Bí àpẹẹrẹ: Ìyá onífẹ̀ẹ́ máa ń ṣọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ kéékèèké, pàápàá bọ́jọ́ orí wọn bá ṣì kéré. Torí pé bí ọjọ́ orí ọmọ bá ṣe kéré sí náà ló ṣe máa nílò àbójútó sí. Lọ́nà kan náà, Ọlọ́run máa ń bójú tó wa àgàgà nígbà tó bá dà bíi pé a ò já mọ́ nǹkan kan tá ò sí rẹ́ni fẹ̀yìn tì. Jèhófà sọ pé: “Ibi gíga àti ibi mímọ́ ni ibi tí mo ń gbé, àti pẹ̀lú ẹni tí a tẹ̀ rẹ́, tí ó sì rẹ̀wẹ̀sì ní ẹ̀mí, láti mú ẹ̀mí àwọn ẹni rírẹlẹ̀ sọ jí àti láti mú ọkàn-àyà àwọn tí a tẹ̀ rẹ́ sọ jí.”—Aísáyà 57:15.

      Síbẹ̀, o lè máa ṣe kàyéfì pé: ‘Báwo ni Ọlọ́run ṣe ń bójú tó mi? Ṣé Ọlọ́run mọ irú ẹni tí mo jẹ́ nínú lọ́hùn-ún, àbí ìrísí mi nìkan ló máa ń wò?’

  • Ọ̀rọ̀ Rẹ Yé Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́—2014 | August 1
    • KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ǸJẸ́ ỌLỌ́RUN BÌKÍTÀ NÍPA RẸ?

      Ọ̀rọ̀ Rẹ Yé Ọlọ́run

      “Jèhófà, ìwọ ti yẹ̀ mí wò látòkè délẹ̀, ìwọ sì mọ̀ mí.”—SÁÀMÙ 139:1.

      [Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

      “Àní ojú rẹ rí ọlẹ̀ mi.”—SÁÀMÙ 139:16

      ÌDÍ TÁWỌN KAN FI Ń ṢIYÈMÉJÌ: Ọ̀pọ̀ èèyàn rò pé Ọlọ́run ò rí nǹkan míì lára wa ju ẹ̀ṣẹ̀ wa lọ, a ò sì yẹ lẹ́ni tó ń bójú tó. Bí àpẹẹrẹ, obìnrin kan tó ń jẹ́ Kendra sọ pé bí òun ṣe ń sapá tó láti ṣèfẹ́ Ọlọ́run, òun máa ń ṣàṣìṣe lọ́pọ̀ ìgbà. Èyí mú kí òun ka ara òun sí ẹlẹ́ṣẹ̀ paraku, ìbànújẹ́ sì máa ń dorí òun kodò. Nítorí ẹ̀dùn ọkàn yìí, Kendra sọ pé: “Òun kì í gbàdúrà mọ́.”

      OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: Kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ wa ni Jèhófà ń wò, ńṣe ló máa ń wo irú ẹni tí a jẹ́ ní inú lọ́hùn-ún. Bíbélì sọ pé: ‘Òun fúnra rẹ̀ mọ ẹ̀dá wa, ó rántí pé erùpẹ̀ ni wa.’ Síwájú sí i, Bíbélì tún jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run kì í ṣe sí wa “gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ wa,” àmọ́ nínú àánú rẹ̀, ó máa ń dárí jì wá nígbà tá a bá ronú pìwà dà.—Sáàmù 103:10, 14.

      Nígbà tí Dáfídì ọba Ísírẹ́lì tá a mẹ́nu kàn ní ìbẹ̀rẹ̀ àkòrí àkọ́kọ́ ń gbàdúrà sí Ọlọ́run, ó sọ pé: “Àní ojú rẹ rí ọlẹ̀ mi, inú ìwé rẹ sì ni gbogbo àwọn ẹ̀yà rẹ̀ wà ní àkọsílẹ̀ . . . Yẹ̀ mí wò látòkè délẹ̀, Ọlọ́run, kí o sì mọ ọkàn-àyà mi.” (Sáàmù 139:16, 23) Dáfídì mọ̀ pé òun máa ń ṣẹ̀, àmọ́ tí òun bá tiẹ̀ dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì pàápàá, Jèhófà máa ń rí inú òun lọ́hùn-ún, ó sì máa ń mọ̀ pé òun kábàámọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ náà.

      Jèhófà mọ̀ ẹ́ ju bí ẹnikẹ́ni ṣe lè mọ̀ ẹ́ lọ. Bíbélì sọ pé: “Ènìyàn lásán-làsàn ń wo ohun tí ó fara hàn sí ojú; ṣùgbọ́n ní ti Jèhófà, ó ń wo ohun tí ọkàn-àyà jẹ́.” (1 Sámúẹ́lì 16:7) Bó bá ṣẹlẹ̀ pé a ṣe àṣìṣe, Ọlọ́run mọ ohun tó fà á. Ó mọ̀ pé àyíká tí à ń gbé, àwọn tó tọ́ wa dàgbà àti ìwà tá a jogún láti ara àwọn òbí wa máa ń nípa lórí wa. Síbẹ̀, ó mọyì bá a ṣe ń sapá láti ṣèfẹ́ rẹ̀, kódà tá a bá tiẹ̀ ń ṣàṣìṣe léraléra.

      Báwo ni Ọlọ́run ṣe máa ń lo òye tó ní nípa rẹ láti tù ẹ́ nínú?

  • Ọlọ́run Lè Tù Ẹ́ Nínú
    Ilé Ìṣọ́—2014 | August 1
    • KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ǸJẸ́ ỌLỌ́RUN BÌKÍTÀ NÍPA RẸ?

      Ọlọ́run Lè Tù Ẹ́ Nínú

      “Ọlọ́run, ẹni tí ń tu àwọn tí a rẹ̀ sílẹ̀ nínú, tù wá nínú.”—2 KỌ́RÍŃTÌ 7:6.

      [Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

      “Ọmọ Ọlọ́run . . . nífẹ̀ẹ́ mi, ó sì fi ara rẹ̀ lélẹ̀ fún mi.”—GÁLÁTÍÀ 2:20

      ÌDÍ TÁWỌN KAN FI Ń ṢIYÈMÉJÌ: Nígbà míì tí àwọn èèyàn bá nílò ìtùnú lójú méjèèjì nítorí ìṣòro tó bò wọ́n mọ́lẹ̀, wọ́n lè máa rò pé àṣejù ni tí àwọn bá ń yọ Ọlọ́run lẹ́nu pé kó dá sí ìṣòro àwọn. Bọ́rọ̀ ṣe rí lára obìnrin kan tó ń jẹ Raquel náà nìyẹn. Ó sọ pé: “Tí mo bá wo bí ìṣòro ṣe kún inú ayé, tí mo sì rí nǹkan tí ẹlòmíì ń bá yí, ńṣe ló máa ń ṣe mí bíi pé ohun tó ń bá mi fínra kò tó nǹkan tó yẹ kí n máa da Ọlọ́run láàmù sí.”

      OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: Ọlọ́run ti ṣe ètò kan láti ràn wá lọ́wọ́ kó sì tù wá nínú. Gbogbo èèyàn pátápátá ló ti jogún ẹ̀ṣẹ̀, torí náà kò sí bá a ṣe lè sapá tó, a kò lè ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ délẹ̀délẹ̀. Síbẹ̀, Bíbélì sọ pé Ọlọ́run “nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì rán Ọmọ rẹ̀ [Jésù Kristi] jáde gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìpẹ̀tù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.” (1 Jòhánù 4:10) Ipasẹ̀ ikú ìrúbọ Jésù yìí ni a fi máa ń rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run, ó tún ń jẹ́ ká ní ẹ̀rí ọkàn rere, a sì máa ní ìrètí láti gbé títí láé nínú ayé tuntun tí àlàáfíà ti máa jọba.a Àmọ́, ṣé Ọlọ́run kàn ṣe ètò yìí fún gbogbo ìran èèyàn lápapọ̀ ni àbí ó ṣeé torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan?

      Wo àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Ikú ìrúbọ Jésù wú Pọ́ọ̀lù lórí débi tó fi sọ pé: “Mo ń gbé nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Ọmọ Ọlọ́run, ẹni tí ó nífẹ̀ẹ́ mi, tí ó sì fi ara rẹ̀ lélẹ̀ fún mi.” (Gálátíà 2:20) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù ti kú ṣáájú kí Pọ́ọ̀lù tó di Kristẹni, síbẹ̀, ó rí ohun tí Jésù ṣe gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn tí Ọlọ́run dìídì fún òun.

      Ikú ìrúbọ Jésù jẹ́ ẹ̀bùn tí Ọlọ́run dìídì fún ìwọ náà. Ẹ̀bùn yìí fi hàn pé Ọlọ́run kà ẹ́ sí pàtàkì. Ẹ̀bùn yìí sì lè fún ẹ ní “ìtùnú àìnípẹ̀kun àti ìrètí,” èyí á sì mú kí o ‘fìdí múlẹ̀ gbọn-in nínú gbogbo iṣẹ́ rere àti ọ̀rọ̀.’—2 Tẹsalóníkà 2:16, 17.

      Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù ti fi ẹ̀mí rẹ̀ rúbọ láti nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì [2,000] ọdún sẹ́yìn, ẹ̀rí wo la ní lónìí pé Ọlọ́run fẹ́ kí o sún mọ́ òun?

      a Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ikú ìrúbọ Jésù, ka orí 5 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

  • Ọlọ́run Fẹ́ Kí O Sún Mọ́ Òun
    Ilé Ìṣọ́—2014 | August 1
    • KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ǸJẸ́ ỌLỌ́RUN BÌKÍTÀ NÍPA RẸ?

      Ọlọ́run Fẹ́ Kí O Sún Mọ́ Òun

      “Kò sí ènìyàn kankan tí ó lè wá sọ́dọ̀ mi láìjẹ́ pé Baba, tí ó rán mi, fà á.”—JÒHÁNÙ 6:44.

      ÌDÍ TÁWỌN KAN FI Ń ṢIYÈMÉJÌ: Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ló gba Ọlọ́run gbọ́, síbẹ̀ ó máa ń ṣe wọ́n bíi pé wọn ò sún mọ́ ọn rárá. Irú èrò yìí ni obìnrin kan tó ń jẹ́ Christina tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Ireland ní. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í pa ṣọ́ọ̀ṣì jẹ, ó sọ pé: “Mo kàn mọ̀ pé Ọlọ́run ló dá ohun gbogbo àmọ́ èmi fúnra mi kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ ọ́n. Kò tiẹ̀ ṣe mí rí bíi pé mo sún mọ́ Ọlọ́run.”

      OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: Tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé o jìnnà sí Ọlọ́run, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Ọlọ́run ò ní fi ẹ sílẹ̀. Jésù ṣe àkàwé kan tó jẹ́ ká rí bí Ọlọ́run ṣe ń fìfẹ́ bójú tó wa, ó ní: “Bí ọkùnrin kan bá wá ní ọgọ́rùn-ún àgùntàn, tí ọ̀kan nínú wọn sì ṣáko lọ, kì yóò ha fi mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún náà sílẹ̀ lórí àwọn òkè ńlá, kí ó sì mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n láti wá ọ̀kan tí ó ṣáko lọ?” Kí ni Jésù fẹ́ fàyọ? Ó sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, kì í ṣe ohun tí Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run ní ìfẹ́-ọkàn sí, pé kí ọ̀kan nínú àwọn ẹni kékeré wọ̀nyí ṣègbé.”—Mátíù 18:12-14.

      Gbogbo ọ̀kọ̀ọ̀kan “àwọn ẹni kékeré wọ̀nyí” ló ṣeyebíye lójú Ọlọ́run. Báwo wá ni Ọlọ́run ṣe ń ‘wá ọ̀kan tí ó bá ṣáko lọ’? Ẹsẹ Bíbélì tó wà níbẹ̀rẹ̀ àkòrí yìí sọ pé, Jèhófà ń fa àwọn èèyàn sọ́dọ̀ ara rẹ̀.

      [Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

      Lónìí, àwọn wo ló máa ń lọ bá àwọn èèyàn nílé wọn àti níbikíbi tí wọ́n bá ti rí wọn kí wọ́n lè sọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún wọn?

      Wo díẹ̀ lára ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà fa àwọn èèyàn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ sọ́dọ̀ ara rẹ̀. Ní ọdún díẹ̀ lẹ́yìn tí Jésù kú, Ọlọ́run ní kí ọmọ ẹ̀yìn Jésù tó ń jẹ́ Fílípì lọ pàdé ìwẹ̀fà ará Etiópíà kan nínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀, kí ó sì ṣàlàyé ìtumọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tí ìwẹ̀fà náà ń kà fún un. (Ìṣe 8:26-39) Lẹ́yìn ìgbà yẹn ni Ọlọ́run rán àpọ́sítélì Pétérù lọ sí ilé ọ̀gágun ará Róòmù kan tó ń jẹ́ Kọ̀nílíù tó ti ń gbàdúrà, tó sì ń sapá láti jọ́sìn Ọlọ́run. (Ìṣe 10:1-48) Ọlọ́run tún darí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ lọ sí odò kan nítòsí ìlú Fílípì. Ibẹ̀ ni wọ́n ti pàdé obìnrin kan tó ń jẹ́ Lìdíà “ẹni tí ó jẹ́ olùjọsìn Ọlọ́run,” Bíbélì sọ pé: “Jèhófà sì ṣí ọkàn-àyà rẹ̀ sílẹ̀ láti fiyè sí” àwọn ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù ń sọ.—Ìṣe 16:9-15.

      Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn àpẹẹrẹ yìí fi hàn pé, Jèhófà máa ń fún gbogbo àwọn tó bá ń wá a ní àǹfààní láti mọ òun. Lónìí, àwọn wo ló máa ń lọ bá àwọn èèyàn nílé wọn àti níbikíbi tí wọ́n bá ti rí wọn kí wọ́n lè sọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún wọn? Ọ̀pọ̀ ló gbà pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni. Wá bi ara rẹ pé, ‘Ṣé kì í ṣe pé Ọlọ́run ló ń lò wọ́n láti ràn mí lọ́wọ́ kí n lè sún mọ́ ọn?’ Jọ̀wọ́ gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ràn ẹ́ lọ́wọ́ kí o lè gba ìrànlọ́wọ́ tó ń pèsè yìí, kó bàa lè fà ẹ́ mọ́ra.a

      a Fún ìsọfúnni síwájú sí i, wo fídíò náà Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? lórí ìkànnì wa ìyẹn, www.jw.org/yo.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́