Orin 50
Àpẹẹrẹ Ìfẹ́ Ọlọ́run
1. Jèhófà Ọlọ́run ti fọgbọ́n pèsè
Fún àwa,
Gbogbo wa,
Àpẹẹrẹ ìfẹ́, kí ó lè máa tọ́ wa,
Ká má ṣubú,
Ká má ṣubú.
Wá sí ọ̀nà Jáà, ó dùn, ó lárinrin;
Ọ̀nà tó tọ́ ni, ó ńjẹ́ ká ṣe rere;
Ọ̀nà àlàáfíà, tó ńso wá pọ̀ ṣọ̀kan.
Ọ̀nà ìfẹ́,
Lọ̀nà Ọlọ́run.
2. Rírìn lọ́nà Jáà, ńmú ká nífẹ̀ẹ́ ará
Láìṣẹ̀tàn,
Lódodo;
Yóò mú ká tètè ran ara wa lọ́wọ́
Lọ́nà gbogbo,
Lọ́nà gbogbo;
Aó sì máa gbàgbé àṣìṣe pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́,
Ká lè fìyọ́nú máa bá ara wa lò,
Ká lè fi ìwà jọ Baba wa ọ̀run,
Ká lè nífẹ̀ẹ́,
Àwọn ará wa.
3. Ìfẹ́ Ọlọ́run táa ní ló ńjẹ́ ká sìnín
Lójúmọ́,
Lójúmọ́.
Gbogbo ọkàn wa la fi ńṣe ìgbọràn,
A ńkọrin yìnín,
A ńkọrin yìnín.
Ká kéde oókọ rẹ̀ fún gbogbo èèyàn;
Kí wọ́n lè wá rí òtítọ́ kedere.
Kí iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ tún máa wu wá síi,
Èyí nìfẹ́,
Ìfẹ́ òtítọ́.
(Tún wo Róòmù 12:10; Éfé. 4:3; 2 Pét. 1:7.)