ÀWỌN OHUN PÀTÀKÌ TÓ ṢẸLẸ̀ LỌ́DÚN TÓ KỌJÁ
Ètò Ọlọ́run Ń Tẹ̀ Síwájú
Ní ọjọ́ Friday, July 5, 2013, ìdùnnú ṣubú lu ayọ̀ ní Bẹ́tẹ́lì tó wà nílẹ̀ Amẹ́ríkà nígbà táwọn tó wà níbẹ̀ gbọ́ ìfilọ̀ kan tí Arákùnrin Anthony Morris tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí ṣe, pé: “Lọ́jọ́ Thursday, July 4, 2013, a buwọ́ lu ìwé àdéhùn láti ta àwọn ilé mẹ́fà tó wà ní ojúlé 117 Adams Street àti ojúlé 90 Sands Street ní ìlú Brooklyn. Ní báyìí tá a ti ta àwọn ilé yìí, àdéhùn tó wà nílẹ̀ ni pé a gbọ́dọ̀ kó jáde nínú ilé márùn-ún àkọ́kọ́ títí ìdajì oṣù August ọdún yìí.”
Arákùnrin Morris ṣàlàyé pé Ẹ̀ka Ìfọṣọ ṣì máa wà ní àjà kẹfà àti ìkeje ní ilé kẹta títí di ìdajì ọdún 2014. Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Ó ṣeé ṣe kó di ọdún 2017 ká tó kó kúrò ní Ilé tó wà ní ojúlé 90 Sands Street.”
Ìdí tá a fi ta ilé ńlá mẹ́fẹ̀ẹ̀fà yẹn ni pé a fẹ́ kó oríléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kúrò ní ìlú New York City lọ sí ìlú Warwick níbi tá a ti ra ilẹ̀ igba àti mẹ́tàléláàádọ́ta [253] éékà. Àmọ́ a ò tíì lè bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ kankan lorí ilẹ̀ yẹn láìrí gbogbo ìwé àṣẹ ìkọ́lé gbà.
Torí náà gbogbo ìdílé Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Amẹ́ríkà tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ nígbà tí Arákùnrin Mark Sanderson tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí ka ìfilọ̀ kan lọ́jọ́ Thursday, July 18, pé: “Inú wa dùn láti sọ fún yín pé nírọ̀lẹ́ àná, ìyẹn Wednesday July 17, àjọ tó ń bójú tó ilé kíkọ́ nílùú Warwick fọwọ́ sí ìwé àwòrán ilé tá a fẹ́ fi kọ́ oríléeṣẹ́ tuntun ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ìwé tí wọ́n fọwọ́ sí yìí ló máa jẹ́ ká lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ lórí bá a ṣe máa rí ìwé àṣẹ gbà lọ́wọ́ ìjọba pé ká lọ bẹ̀rẹ̀ ilé kíkọ́. Ohun tó tún yani lẹ́nu ni pé ìrọ̀lẹ́ àná tá a rí ìwé àwòrán ilé tí wọ́n fọwọ́ sí yẹn gbà gan-an ló pé ọdún mẹ́rin géérégé tá a parí gbogbo ètò lórí ilẹ̀ tá a rà sí ìlú Warwick. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ohun tó ti ń ṣẹlẹ̀ láti ọjọ́ bíi mélòó kan sẹ́yìn fi hàn pé ó lọ́wọ́ Jèhófà nínú.” Arákùnrin Sanderson dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo wọn fún iṣẹ́ takuntakun àti àdúrà wọn lorí iṣẹ́ ìkọ́lé tó ṣe pàtàkì yìí. Ó wá sọ pé: “Ní pàtàkì jù lọ, a dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà, a sì ń yìn ín fún àṣeyọrí pàtàkì tá a ṣe lórí bá a ṣe fẹ́ kó oríléeṣẹ́ wa lọ sí ìlú Warwick ní ìpínlẹ̀ New York.”
Nígbà tó di ọjọ́ Friday, July 26, Arákùnrin Morris ṣèpàdé pẹ̀lú nǹkan bí ẹgbẹ̀rún kan [1,000] èèyàn tó jẹ́ ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì àtàwọn òṣìṣẹ́ Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn tí wọ́n pé jọ sí yàrá ìjẹun tó wà níbi tí wọ́n ti ń ṣètò iṣẹ́ ìkọ́lé náà ní ìlú Tuxedo, ìpínlẹ̀ New York. Lẹ́yìn tó ti sọ àsọyé kan láti fún wọn níṣìírí, ó ní kí wọ́n fetí sí ìfilọ̀ pàtàkì kan. Arákùnrin Morris sọ pé, “Ìwé kan ṣẹ̀ṣẹ̀ tẹ̀ mí lọ́wọ́, mo sì fẹ́ ka ohun tó wà níbẹ̀ fún yín. Àkọlé tó wà lórí rẹ̀ ni: ‘Ìwé Àṣẹ Ìkọ́lé.’” Bó ṣe ka àkọlé yìí, àtẹ́wọ́ sọ! Ńṣe ni inú wọn ń dùn bí Arákùnrin Morris ṣe ka ọ̀rọ̀ díẹ̀ jáde nínú ìwé àṣẹ ìkọ́lé tó ṣe pàtàkì tí wọ́n kọ́kọ́ gbà yìí, èyí táwọn aláṣẹ ìlú Warwick ṣẹ̀ṣẹ̀ fọwọ́ sí ní nǹkan bíi wákàtí mẹ́ta sẹ́yìn.
Kí Ló Ń Ṣẹlẹ̀ ní Wallkill, Warwick àti Tuxedo?
Látìgbà tá a ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn àfikún ilé sí ọ́fíìsì wa tó wà ní ìlú Wallkill ní August 2009, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ [2,800] àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin ló ti yọ̀ǹda ara wọn láti wá ṣiṣẹ́ níbẹ̀ fúngbà díẹ̀. Díẹ̀ lára àwọn àfikún ilé tá à ń kọ́ yẹn ni ilé gbígbé, ibi ìgbọ́kọ̀sí àti ọ́fíìsì. À ń ṣe àtúnṣe sí ọ̀kan lára àwọn ilé gbígbé tó ti wà níbẹ̀, a sì ń ṣe àwọn àyípadà díẹ̀ sí ilé ìtẹ̀wé, ilé ìfọṣọ, gbọ̀ngàn ńlá, ilé tó wà fún onírúurú iṣẹ́ àti gbọ̀ngàn ìgbàlejò. Tó bá fi máa di ìparí ọdún 2015, a retí pé kí iṣẹ́ ti parí lórí àwọn àfikún ilé tá à ń kọ́ sí ìlú Wallkill.
Ní báyìí ná, iṣẹ́ ìkọ́lé ti bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹu ní ìlú Warwick níbi tá a fẹ́ fi ṣe oríléeṣẹ́ wa tó bá yá. Láti bí oṣù mélòó kan tí iṣẹ́ náà ti bẹ̀rẹ̀, wọ́n ti ń gbẹ́lẹ̀ láwọn ibì kan, wọ́n ti ń kó iyẹ̀pẹ̀ sí àwọn ibòmíì, wọ́n sì ti ń ri àwọn wáyà àtàwọn páìpù tó yẹ mọ́lẹ̀. Apá ìparí ọdún 2013 la bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ilé mẹ́ta àkọ́kọ́, ìyẹn ilé ìtọ́kọ̀ṣe, ibi ìgbọ́kọ̀sí fáwọn àlejò àti ilé ẹ̀ka tó ń tún nǹkan ṣe. Àwọn ilé yìí ṣe pàtàkì torí àtimáa tọ́jú àwọn ohun èlò ìkọ́lé àtàwọn tó ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀, yálà nígbà tí iṣẹ́ ìkọ́lé ń lọ lọ́wọ́ tàbí nígbà tá a bá kọ́lé tán. Lẹ́yìn ìyẹn la máa wá kọ́ àwọn ilé gbígbé àtàwọn ilé tá a máa lò fún ọ́fíìsì àti onírúurú iṣẹ́, ìyẹn sì máa bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 2014.
Arákùnrin Kenneth Chernish tó wà lára ìgbìmọ̀ ìkọ́lé náà sọ pé a ní ilẹ̀ kan tó jẹ́ àádọ́ta [50] éékà sí ìlú Tuxedo, kò ju nǹkan bíi kìlómítà mẹ́wàá sí ìlú Warwick lápá àríwá, ibẹ̀ la “ti ń ṣètò iṣẹ́ kíkọ́ oríléeṣẹ́ wa tó máa wà ní ìlú Warwick.” Ó fi kún un pé: “Ibẹ̀ ni díẹ̀ lára àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn á máa gbé, àtibẹ̀ la ó sì ti máa ṣètò oúnjẹ àtàwọn ohun èlò ìkọ́lé tó fi mọ́ irin iṣẹ́ tí wọ́n á máa lò.” Láti mú kí iṣẹ́ ìkọ́lé tó ń lọ lọ́wọ́ nílùú Tuxedo yá, àwọn kan lára Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn tó wà lápá ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ti ń bá wa ṣe díẹ̀ lára àwọn iṣẹ́ ọ̀hún.
Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn tó ń bá àwọn Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn jákèjádò orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ṣiṣẹ́ ló ń wọ̀nà fún àǹfààní láti kópa nínú kíkọ́ oríléeṣẹ́ wa tá à ń kọ́ lọ́wọ́. Àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n jẹ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ti ń yọ̀ǹda ara wọn láti ṣiṣẹ́ fúngbà díẹ̀ láwọn ibi tá a ti ń kọ́lé lọ́wọ́. Arábìnrin Leslie Blondeau tí òun àti Peter ọkọ rẹ̀ jọ ń ṣiṣẹ́ púlọ́ńbà sọ pé, “Bá a ṣe jọ ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ ti jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ ara wa, ọ̀pọ̀ nǹkan tó sì ń ṣẹlẹ̀ báyìí la ò jẹ́ gbàgbé láé.”
Arábìnrin Mallory Rushmore sọ pé: “Ẹ̀ka tó ń ṣètò iná mànàmáná ni mò ń bá ṣiṣẹ́ báyìí. Ojoojúmọ́ ni inú mi máa ń dùn bí mo ṣe ń rí gbogbo àwa tá a yọ̀ǹda ara wa tá a sì jọ ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ níbí.”
Arákùnrin Quincy Dotson sọ pé: “Àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ ni iṣẹ́ yìí jẹ́ fún mi. Ṣe ni mo rò pé ọ̀pọ̀ ohun tí mo mọ̀ nípa iṣẹ́ mi ni màá ṣe níbẹ̀, àmọ́ ohun tí mo ti kọ́ níbẹ̀ pọ̀ ju ohun tí mo ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ lọ.”
Arákùnrin Chernish sọ pé: “Ìdùnnú ńlá ló jẹ́ láti lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ yìí. Àwọn arákùnrin àti arábìnrin tá a jọ ń ṣiṣẹ́ yára bí àṣá, wọn ò sì fiṣẹ́ ṣeré, síbẹ̀ wọ́n ń gbádùn iṣẹ́ wọn dọ́ba.”