Orin 109
Yin Àkọ́bí Jèhófà!
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Ẹ yin Àkọ́bí Jáà,
Ọba tí Ọlọ́run yàn.
Olóòótọ́ àtòdodo,
Àìlópin nìbùkún rẹ̀.
Yóò dá Jèhófà láre
Póun lọ́ba gíga jù,
Pẹ̀lú iyì, ọlá ńlá,
Àtìfẹ́ foókọ rẹ̀.
(ÈGBÈ)
Ẹ yin Àkọ́bí Jáà!
Ọmọ tó fòróró yàn.
Ó jọba lókè Síónì,
Ìjọba rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀!
2. Ẹ yin Àkọ́bí Jáà,
Tó kú kí a lè níyè.
Ó san ìràpadà wa;
Ọlọ́run ńdárí jì wá.
Aya Kristi ńdúró dèé,
Aṣọ funfun ló wọ̀.
Ìgbéyàwó ọ̀run yìí
Ńfẹ̀tọ́ ’jọba Jáà hàn.
(ÈGBÈ)
Ẹ yin Àkọ́bí Jáà!
Ọmọ tó fòróró yàn.
Ó jọba lókè Síónì,
Ìjọba rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀!