Orin 22
“Jèhófà Ni Olùṣọ́ Àgùntàn Mi”
(Sáàmù 23)
1. Jèhófà ni Olùṣọ́ mi;
Kí ni yóò dẹrù bà mí?
Ẹni tó ńtọ́jú àgùntàn rẹ̀
Kò jẹ́ gbàgbé ìkankan.
Ó ńdarí mi létí omi,
Ó ńtu ọkàn mi lára.
Ó ńtọ́ mi ní ọ̀nà òdodo
Nítorí orúkọ rẹ̀.
Ó ńtọ́ mi ní ọ̀nà òdodo
Nítorí orúkọ rẹ̀.
2. Bí mo ńrìn láfonífojì,
N kò bẹ̀rù aburú.
Olùṣọ́ mi ń bẹ pẹ̀lú mi;
Ọ̀pá rẹ̀ ló ńkó mi yọ.
Ó fòróró pa orí mi;
Ife mi sì kún dáadáa.
Inúure rẹ̀ yóò máa bá mi lọ,
Nó máa gbénú ilé rẹ̀.
Inúure rẹ̀ yóò máa bá mi lọ,
Nó máa gbénú ilé rẹ̀.
3. Olùṣọ́ mi lọ́gbọ́n, nífẹ̀ẹ́!
N ó fayọ̀ kọrin yìnín.
Nó ròyìn bó ṣe ń tọ́jú mi
Fún ẹni bí àgùntàn.
Nó pa gbogbo Ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́,
Nó rọra rìn lọ́nà rẹ̀.
Àǹfààní ló jẹ́ láti máa sìnín,
Nó sì máa sìnín títí láé.
Àǹfààní ló jẹ́ láti máa sìnín,
Nó sì máa sìnín títí láé.