Orin 14
Jèhófà Sọ Ohun Gbogbo Di Tuntun
1. “Àmì” fi hàn pé ’jọba ọ̀run bẹ̀rẹ̀.
Ọmọ Jèhófà gorí ìtẹ́ rẹ̀.
Ó ti jagun tọ̀run ó sì ṣẹ́gun,
Ìfẹ́ Jèhófà máa tó ṣẹ láyé.
(ÈGBÈ)
Ẹ yọ̀! Àgọ́ Jáà dé sáyé,
Òun yóò máa bá wọn gbé pẹ̀lú.
Kò sẹ́kún mọ́, kò sí ìrora,
’Bànújẹ́ tán, kò sí ikú mọ́;
Jáà ti wí pé: ‘Mo so’un gbogbo dọ̀tun.’
Òdodo, òtítọ́ ni.
2. Káráyé wo Jerúsálẹ́mù Tuntun,
Aya Ọ̀dọ́ Àgùntàn ńtàn yanran.
A fòkúta ’yebíye ṣeé lọ́ṣọ̀ọ́,
Jèhófà nìkan ni ìmọ́lẹ̀ rẹ̀.
(ÈGBÈ)
Ẹ yọ̀! Àgọ́ Jáà dé sáyé,
Òun yóò máa bá wọn gbé pẹ̀lú.
Kò sẹ́kún mọ́, kò sí ìrora,
’Bànújẹ́ tán, kò sí ikú mọ́;
Jáà ti wí pé: ‘Mo so’un gbogbo dọ̀tun.’
Òdodo, òtítọ́ ni.
3. Ìlú rírẹwà dayọ̀ gbogbo ayé.
Ọ̀nà rẹ̀ ṣí sílẹ̀ tọ̀sán-tòru.
Gbogbo ayé yóò rìn ń’nú ògo rẹ̀;
Ìránṣẹ́ Jáà ńfi ìmọ́lẹ̀ náà hàn.
(ÈGBÈ)
Ẹ yọ̀! Àgọ́ Jáà dé sáyé,
Òun yóò máa bá wọn gbé pẹ̀lú.
Kò sẹ́kún mọ́, kò sí ìrora,
’Bànújẹ́ tán, kò sí ikú mọ́;
Jáà ti wí pé: ‘Mo so’un gbogbo dọ̀tun.’
Òdodo, òtítọ́ ni.
(Tún wo Mát. 16:3; Ìṣí. 12:7-9; 21:23-25.)