Orin 41
Sin Jèhófà Nígbà Èwe
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Ọlọ́run fẹ́ràn ẹ̀yin ọmọ wa;
Iyebíye ni ẹ jẹ́ lójú rẹ̀.
Ìfẹ́ ló ní ká fi máa tọ́jú yín,
Àwa òbí, ọ̀rẹ́ àtẹbí yín.
2. Ẹ bọlá fáwọn òbí tó ńtọ́ yín,
Ẹ má ṣe di àrísunkún ọmọ.
Bẹ́ẹ rójúure Ọlọ́run àtèèyàn,
Ìgbà èwe yín yóò dùn bí oyin.
3. Jọ̀wọ́ rántí Ọlọ́run rẹ léwe;
Jẹ́ kífẹ̀ẹ́ òótọ́ gbilẹ̀ lọ́kàn rẹ.
Ìfọkànsìn rẹ sí Ọlọ́run wa,
Yóò sì múnú Jèhófà Ọba dùn.
(Tún wo Sm. 71:17; Ìdárò 3:27; Éfé. 6:1-3.)