ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ṣé Dandan Ni Kéèyàn Di Àtúnbí Kó Tó Lè Nígbàlà?
    Ilé Ìṣọ́—2009 | April 1
    • Ṣé Dandan Ni Kéèyàn Di Àtúnbí Kó Tó Lè Nígbàlà?

      TẸ́NÌ kan bá bi ẹ́ pé, “Ṣó o ti di àtúnbí”? Kí lo máa sọ? Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn tó máa ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì ló máa dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni!” Wọ́n gbà gbọ́ pé téèyàn ò bá tíì di àtúnbí, kò tíì di Kristẹni gidi àti pé àfi kéèyàn di àtúnbí kó tó lè nígbàlà. Èrò wọn bá tàwọn aṣáájú ìsìn mu, irú bí Ọ̀gbẹ́ni Robert C. Sproul tó kọ̀wé pé: “Bẹ́nì kan kì í bá ṣe àtúnbí, . . . á jẹ́ pé onítọ̀hún kì í ṣe Kristẹni nìyẹn.”

      Ṣéwọ náà gbà gbọ́ pé tó o bá ti dàtúnbí, o ti wà lójú ọ̀nà tó máa jẹ́ kó o nígbàlà nìyẹn? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ó dájú pé wàá fẹ́ káwọn mọ̀lẹ́bí àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ náà mọ ojú ọ̀nà yẹn, kí wọ́n sì máa rìn níbẹ̀. Àmọ́, kí wọ́n tó lè ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n ní láti mọ ìyàtọ̀ láàárín ẹnì kan tó ti di àtúnbí àtẹni tí kì í ṣe àtúnbí. Torí náà, báwo lo ṣe máa ṣàlàyé ohun tó túmọ̀ sí láti di àtúnbí fún wọn?

      Ọ̀pọ̀ ló gbà gbọ́ pé ẹni tó ti di “àtúnbí” lẹni tó ti jẹ́jẹ̀ẹ́ láti máa fi tọkàntọkàn sin Ọlọ́run àti Kristi, tíyẹn sì ti wá jẹ́ kó ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Ọlọ́run. Kódà, ìwé atúmọ̀ èdè kan tó dé kẹ́yìn sọ pé ẹni tó ti di àtúnbí “sábà máa ń jẹ́ Kristẹni tí ìgbàgbọ́ ẹ̀ ti túbọ̀ lágbára sí i tàbí kónítọ̀hún ti rí ẹ̀rí pé Ọlọ́run ti pe òun lẹ́yìn tóun bá Ọlọ́run pàdé.”—Merriam-Webster’s Collegiate Dictionary—Eleventh Edition.

      Ṣé kò ní yà ẹ́ lẹ́nu láti mọ̀ pé àlàyé tí Bíbélì ṣe nípa àtúnbí yàtọ̀ sóhun tí ìwé atúmọ̀ èdè yẹn sọ? Ṣé wàá fẹ́ mohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ni nípa dídi àtúnbí? Ó dájú pé wàá jàǹfààní gan-an tó o bá fara balẹ̀ gbé ọ̀rọ̀ yìí yẹ̀ wò. Ìdí sì ni pé mímọ ohun tí Bíbélì sọ nípa àtúnbí máa nípa lórí ìgbésí ayé ẹ àti ohun tó ò ń retí lọ́jọ́ ọ̀la.

      Kí Ni Bíbélì Kọ́ni?

      Ọ̀kan lára ibi tí Bíbélì ti sọ̀rọ̀ nípa àtúnbí lèyí tó wà nínú Jòhánù 3:1-12, ẹsẹ Bíbélì yẹn ṣàlàyé ìjíròrò tó lárinrin kan tó wáyé láàárín Jésù àti aṣáájú ẹ̀sìn kan nílùú Jerúsálẹ́mù. Àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí wà nínú àpótí tó wà lójú ìwé tó tẹ̀ lé e. A fẹ́ kó o fara balẹ̀ kà á.

      Nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì yẹn, Jésù sọ̀rọ̀ lórí oníruúrú ọ̀nà tí àtúnbí pín sí.a Kódà, ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ jẹ́ ká mọ ìdáhùn tó tọ̀nà sáwọn ìbéèrè pàtàkì márùn-ún yìí:

      ◼ Báwo ló ṣe ṣe pàtàkì tó láti di àtúnbí?

      ◼ Ṣéèyàn fúnra ẹ̀ ló máa ń pinnu póun fẹ́ di àtúnbí?

      ◼ Kí nìdí táwọn kan fi ní láti di àtúnbí?

      ◼ Báwo lèèyàn ṣe lè di àtúnbí?

      ◼ Àjọṣe tuntun wo lèèyàn máa ní pẹ̀lú Ọlọ́run téèyàn bá di àtúnbí?

      Ẹ jẹ́ ká wá jíròró àwọn ìbéèrè yìí lọ́kọ̀ọ̀kan.

      [Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

      a Bíbélì tún sọ̀rọ̀ nípa àtúnbí nínú 1 Pétérù 1:3, 23, ó pè é ní “ìbí tuntun.” Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n ń pè ní gen·naʹo la tú sí ìbí tuntun, òun náà làwọn èèyàn sì mọ̀ sí àtúnbí.

      [Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

      “A Gbọ́dọ̀ Tún Yín Bí”

      “Wàyí o, ọkùnrin kan wà nínú àwọn Farisí, Nikodémù ni orúkọ rẹ̀, olùṣàkóso kan fún àwọn Júù. Ẹni yìí wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní òru, ó sì wí fún un pé: ‘Rábì, àwa mọ̀ pé ìwọ gẹ́gẹ́ bí olùkọ́, wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run; nítorí kò sí ẹni tí ó lè ṣe iṣẹ́ àmì wọ̀nyí tí ìwọ ń ṣe láìjẹ́ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀.’ Ní ìdáhùn, Jésù wí fún un pé: ‘Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, Láìjẹ́ pé a tún ẹnikẹ́ni bí, kò lè rí ìjọba Ọlọ́run.’ Nikodémù wí fún un pé: ‘Báwo ni a ṣe lè bí ènìyàn nígbà tí ó ti dàgbà? Kò lè wọ inú ilé ọlẹ̀ ìyá rẹ̀ ní ìgbà kejì kí a sì bí i, àbí ó lè ṣe bẹ́ẹ̀?’ Jésù dáhùn pé: ‘Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, Láìjẹ́ pé a bí ẹnikẹ́ni láti inú omi àti ẹ̀mí kò lè wọ ìjọba Ọlọ́run. Ohun tí a ti bí láti inú ẹran ara jẹ́ ẹran ara, ohun tí a sì ti bí láti inú ẹ̀mí jẹ́ ẹ̀mí. Kí ẹnu má ṣe yà ọ́ nítorí mo sọ fún ọ pé, A gbọ́dọ̀ tún yín bí. Ẹ̀fúùfù ń fẹ́ síbi tí ó wù ú, ìwọ sì ń gbọ́ ìró rẹ̀, ṣùgbọ́n ìwọ kò mọ ibi tí ó ti wá àti ibi tí ó ń lọ. Bẹ́ẹ̀ ni olúkúlùkù ẹni tí a ti bí láti inú ẹ̀mí.’ Ní ìdáhùn, Nikodémù wí fún un pé: ‘Báwo ní nǹkan wọ̀nyí ṣe lè ṣẹlẹ̀?’ Ní ìdáhùn, Jésù wí fún un pé: ‘Ìwọ ha jẹ́ olùkọ́ Ísírẹ́lì, síbẹ̀ tí o kò sì mọ nǹkan wọ̀nyí? Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, Ohun tí àwa mọ̀ ni a ń sọ, ohun tí a sì ti rí ni a ń jẹ́rìí rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ kò gba ẹ̀rí tí àwa jẹ́. Bí mo bá ti sọ àwọn ohun ti ilẹ̀ ayé fún yín, síbẹ̀ tí ẹ kò sì gbà gbọ́, báwo ni ẹ ó ṣe gbà gbọ́ bí mo bá sọ àwọn ohun ti ọ̀run fún yín?’”—Jòhánù 3:1-12.

  • Báwo Ló Ṣe Ṣe Pàtàkì Tó Láti Di Àtúnbí?
    Ilé Ìṣọ́—2009 | April 1
    • Báwo Ló Ṣe Ṣe Pàtàkì Tó Láti Di Àtúnbí?

      NÍNÚ ọ̀rọ̀ tí Jésù bá Nikodémù sọ látòkè délẹ̀, ó jẹ́ kó ṣe kedere pé ó ṣe pàtàkì gan-an káwọn kan di àtúnbí. Báwo ló ṣe sọ ọ́?

      Jésù sọ pé: “Láìjẹ́ pé a tún ẹnikẹ́ni bí, kò lè rí ìjọba Ọlọ́run.” (Jòhánù 3:3) Àwọn ọ̀rọ̀ yìí “láìjẹ́” àti “kò lè” jẹ́ ká mọ bó ti ṣe pàtàkì tó fáwọn kan láti di àtúnbí. Wo àpèjúwe yìí ná: Bẹ́nì kan bá sọ pé, “Láìjẹ́ pé oòrùn ràn, ojú ọjọ́ kò lè mọ́lẹ̀,” ohun tó ń sọ ni pé ìmọ́lẹ̀ ṣe pàtàkì kójú ọjọ́ tó lè mọ́lẹ̀. Ohun tí Jésù náà ń sọ ni pé kéèyàn di àtúnbí ṣe pàtàkì kéèyàn tó lè rí Ìjọba Ọlọ́run.

      Níkẹyìn, ńṣe ni ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ tẹ̀ lé e mú iyèméjì kúrò lórí kókó yìí, ó sọ pé: “A gbọ́dọ̀ tún yín bí.” (Jòhánù 3:7) Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Jésù sọ, ẹni tó bá fẹ́ “wọ ìjọba Ọlọ́run” gbọ́dọ̀ di àtúnbí.—Jòhánù 3:5.

      Ní báyìí tá a ti rí i pé Jésù ka dídi àtúnbí sóhun tó ṣe pàtàkì gan-an, ó yẹ káwa Kristẹni rí i dájú pé ọ̀rọ̀ dídi àtúnbí yé wa dáadáa. Bí àpẹẹrẹ, ṣó o rò pé Kristẹni kan lè pinnu láti di àtúnbí?

      [Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 5]

      “Láìjẹ́ pé oòrùn ràn, ojú ọjọ́ kò lè mọ́lẹ̀”

  • Ṣéèyàn Fúnra Ẹ̀ Ló Máa Pinnu Póun Fẹ́ Di Àtúnbí?
    Ilé Ìṣọ́—2009 | April 1
    • Ṣéèyàn Fúnra Ẹ̀ Ló Máa Pinnu Póun Fẹ́ Di Àtúnbí?

      TA LÓ ń sọ èèyàn di àtúnbí? Táwọn aṣáájú ẹ̀sìn kan bá ń rọ àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn láti di àtúnbí, wọ́n máa ń tún ọ̀rọ̀ Jésù sọ pé: “A gbọ́dọ̀ tún yín bí.” (Jòhánù 3:7) Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn wọ̀nyí máa ń lo ọ̀rọ̀ yìí láti fi pàṣẹ fáwọn ọmọ ìjọ wọn, ńṣe ló dà bí ìgbà tí wọ́n bá ń sọ pé, “O gbọ́dọ̀ di àtúnbí!” Ohun tí wọ́n wá ń wàásù rẹ̀ fáwọn ọmọ ìjọ wọn ni pé ọwọ́ olúkúlùkù wọn ló wà láti pinnu póun máa ṣe ohun tí Jésù sọ, kóun ṣe gbogbo ohun tó bá yẹ kóun ṣe kóun lè di àtúnbí. Ohun tí wọ́n ń dọ́gbọ́n sọ ni pé àwọn èèyàn fúnra wọn ló máa pinnu pé àwọn fẹ́ di àtúnbí. Àmọ́, ṣé ohun tí Jésù sọ fún Nikodémù nìyẹn?

      Tá a bá fara balẹ̀ ka ọ̀rọ̀ Jésù dáadáa, a máa rí i pé Jésù ò kọ́ni pé ọwọ́ èèyàn ló kù sí láti pinnu bóyá òun máa di àtúnbí tàbí òun ò ní dì í. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Lédè Gíríìkì, gbólóhùn tá a tú sí “tún ẹnikẹ́ni bí” tún lè túmọ̀ sí “ó yẹ kí Ọlọ́run tún ẹ bí.”a Torí náà, a lè sọ pé “láti òkè,” ìyẹn “láti ọ̀run” tàbí “láti ọ̀dọ̀ Baba” lẹnì kan ti lè dí àtúnbí. (Jòhánù 19:11; àlàyé ìsàlẹ̀ NW; Jákọ́bù 1:17) Èyí fi hàn pé Ọlọ́run ló ń pinnu ẹni tó máa di àtúnbí.—1 Jòhánù 3:9.

      Tá ò bá gbàgbé pé ọ̀rọ̀ Gíríìkì táwọn èèyàn wá mọ̀ sí àtúnbí tún lè túmọ̀ sí “láti òkè,” ó máa rọrùn láti rí ìdí tẹ́nì kan ò fi lè pinnu fúnra ẹ̀ póun fẹ́ di àtúnbí. Ronú lórí bí wọ́n ṣe bí ẹ ná. Ṣéwọ lo pinnu pé kí wọ́n bí ẹ ni? Ó dájú pé kì í ṣèwọ! Ọwọ́ bàbá ẹ nìyẹn wá. Bákan náà, ọwọ́ Ọlọ́run, ìyẹn Bàbá wa ọ̀run, ló wà bóyá ẹnì kan máa di àtúnbí tàbí kò ní dì í. (Jòhánù 1:13) Abájọ tí àpọ́sítélì Pétérù fi sọ pé: “Ìbùkún ni fún Ọlọ́run àti Baba Olúwa wa Jésù Kristi, nítorí ní ìbámu pẹ̀lú àánú ńlá rẹ̀, ó fún wa ní ìbí tuntun.”—1 Pétérù 1:3.

      Ṣé Àṣẹ ni?

      Àwọn kan lè ronú pé, ‘Tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ lẹnì kan ò lè pinnu fúnra ẹ̀ póun fẹ́ di àtúnbí, kí nìdí tí Jésù fi pàṣẹ pé: “A gbọ́dọ̀ tún yín bí”?’ Ìbéèrè ọlọ́gbọ́n nìyẹn. Ó ṣe tán, tó bá jẹ́ àṣẹ ni Jésù pa, á jẹ́ pé ohun tó kọjá agbára wa ló fẹ́ ká ṣe. Ìyẹn ò sì bọ́gbọ́n mu. Ó dáa, kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé ẹ gbọ́dọ̀ di “àtúnbí”?

      Nígbà tá a túṣu ọ̀rọ̀ yìí désàlẹ̀ ìkòkò lédè tí wọ́n fi kọ Bíbélì, a rí i pé àṣẹ kọ́ ni Jésù pa. Kàkà bẹ́ẹ̀, gbólóhùn yẹn dà bí ìgbà téèyàn kàn ń sọ̀rọ̀. Lọ́rọ̀ kan, nígbà tí Jésù sọ pé ẹ gbọ́dọ̀ di “àtúnbí,” ńṣe ló kàn ń sọ òótọ́ ọ̀rọ̀, kì í ṣe pé ó ń pàṣẹ. Ó ní: “Ó ṣe pàtàkì pé ká tún yín bí látòkè.”—Jòhánù 3:7, ìtumọ̀ Modern Young’s Literal Translation.

      Ẹ jẹ́ ká fi àpèjúwe yìí ṣàlàyé ìyàtọ̀ tó wà láàárín kéèyàn pàṣẹ àti kéèyàn kàn wulẹ̀ sọ òótọ́ ọ̀rọ̀. Ká sọ pé ìlú kan wà tó níléèwé tó pọ̀, tí ọ̀kan lára àwọn iléèwé náà sì jẹ́ èyí tí wọ́n dìídì dá sílẹ̀ torí àwọn ọmọ ìlú náà tó ń gbé lọ́nà jíjìn. Lọ́jọ́ kan, ọmọkùnrin kan tí kì í ṣe ọmọ ìlú yẹn sọ fún ọ̀gá iléèwé náà pé òun fẹ́ láti máa wá síléèwé wọn. Ọ̀gá iléèwé náà wá sọ fún un pé, “Kó o tó lè dọmọ iléèwé wa, o gbọ́dọ̀ jẹ́ ọmọ ìlú wa.” Ó dájú pé àṣẹ kọ́ ni ọ̀gá iléèwé yẹn pa. Kò sọ fún un pé, “O gbọ́dọ̀ di ọmọ ìlú wa!” Àmọ́, ọ̀gá iléèwé náà wulẹ̀ sọ òótọ́ tó wà nídìí ọ̀rọ̀ náà, ìyẹn sì ni ohun tọ́mọ náà gbọ́dọ̀ ṣe kó tó lè dọmọ iléèwé wọn. Bó ṣe rí náà nìyẹn nígbà tí Jésù sọ pé: “Ẹ gbọ́dọ̀ di àtúnbí.” Òótọ́ tó wà nídìí ọ̀rọ̀ náà ló sọ, ìyẹn sì ni ohun tẹ́nì kan gbọ́dọ̀ ṣe tó bá fẹ́ “wọ ìjọba Ọlọ́run.”

      Ọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run tí Jésù sọ lókè yìí tún ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú apá mìíràn lórí ọ̀rọ̀ dídi àtúnbí. Ìyẹn ni pé, Kí nìdí táwọn kan fi ní láti di àtúnbí? Mímọ ìdáhùn sí ìbéèrè yìí máa jẹ́ ká lóye ohun tí dídi àtúnbí túmọ̀ sí gan-an.

      [Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

      a Bí èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn ìtumọ̀ Bíbélì ṣe tú Jòhánù 3:3 nìyẹn. Bí àpẹẹrẹ, bí Bíbélì A Literal Translation of the Bible ṣe túmọ̀ ẹsẹ Bíbélì yìí rèé: “Bí Ọlọ́run ò bá tún ẹnì kan bí, kò lè wọ Ìjọba Ọlọ́run.”

      [Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

      Ọ̀nà wo ni dídi àtúnbí àti bíbímọ gbà jọra?

  • Kí Nìdí Táwọn Kan Fi Ní Láti Di Àtúnbí?
    Ilé Ìṣọ́—2009 | April 1
    • Kí Nìdí Táwọn Kan Fi Ní Láti Di Àtúnbí?

      Ọ̀PỌ̀ ló gbà gbọ́ pé téèyàn ò bá di àtúnbí kò lè nígbàlà. Àmọ́, jẹ́ ká wo ohun tí Jésù fúnra ẹ̀ sọ nípa ìdí téèyàn fi ní láti di àtúnbí. Ó sọ pé: “Láìjẹ́ pé a tún ẹnikẹ́ni bí, kò lè rí ìjọba Ọlọ́run.” (Jòhánù 3:3) Torí náà, èèyàn ní láti di àtúnbí kó tó lè wọ Ìjọba Ọlọ́run, kì í ṣe kónítọ̀hún tó lè ní ìgbàlà. Àwọn míì lè sọ pé, ‘Ṣebí ohun kan náà ló túmọ̀ sí láti wọ Ìjọba Ọlọ́run àti láti nígbàlà?’ Rárá o, wọ́n yàtọ̀ síra. Ká lè mọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín méjèèjì, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ wo ohun tí “ìjọba Ọlọ́run” túmọ̀ sí.

      Oríṣiríṣi ọ̀nà làwọn ìjọba gbà ń ṣàkóso, torí náà, “ìjọba Ọlọ́run” túmọ̀ sí “ìṣàkóso Ọlọ́run.” Bíbélì kọ́ni pé Jésù Kristi tó jẹ́ “ọmọ ènìyàn” ni Ọba Ìjọba Ọlọ́run àti pé Kristi láwọn tí wọ́n jọ máa ṣàkóso. (Dáníẹ́lì 7:1, 13, 14; Mátíù 26:63, 64) Yàtọ̀ síyẹn, ìràn kan tí àpọ́sítélì Jòhánù rí jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn tó máa ṣàkóso pẹ̀lú Kristi jẹ́ onírúurú èèyàn tí Ọlọ́run yàn láti “inú gbogbo ẹ̀yà àti ahọ́n àti àwọn ènìyàn àti orílẹ̀-èdè,” wọ́n sì máa “ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lé ilẹ̀ ayé lórí.” (Ìṣípayá 5:9, 10; 20:6) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tún jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn tó máa jọba ló máa para pọ̀ di “agbo kékeré” tí iye wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000], àwọn yìí ni Ọlọ́run “ti rà láti ilẹ̀ ayé wá.”—Lúùkù 12:32; Ìṣípayá 14:1, 3.

      Ibo ni Ìjọba Ọlọ́run á ti máa ṣàkóso wá? Bíbélì pe “ìjọba Ọlọ́run” ní “ìjọba ọ̀run,” ìyẹn sì jẹ́ ká mọ̀ pé látọ̀run wá ni Jésù àtàwọn tó máa jọba pẹ̀lú rẹ̀ ti máa ṣàkóso. (Lúùkù 8:10; Mátíù 13:11) Torí náà, tí Bíbélì bá ń sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run, ìṣàkóso àtọ̀runwá látọwọ́ Jésù Kristi àtàwọn èèyàn tí Ọlọ́run yàn láti ṣàkóso pẹ̀lú rẹ̀ ló ń sọ.

      Kí wá ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé èèyàn gbọ́dọ̀ di àtúnbí kó tó lè “wọ ìjọba Ọlọ́run”? Ohun tó ní lọ́kàn ni pé ẹnì kan ní láti di àtúnbí kó tó lè ṣàkóso pẹ̀lú òun lọ́run. Lọ́rọ̀ kan, ìdí tí Ọlọ́run fi ń sọ ìwọ̀nba àwọn èèyàn kan di àtúnbí ni pé kí wọ́n lè ṣàkóso lọ́run.

      Látinú ìjíròrò wa, a ti rí i pé ó ṣe pàtàkì pé káwọn kan di àtúnbí, pé Ọlọ́run ló máa ń pinnu ẹni tó máa di àtúnbí àti pé dídi àtúnbí ń jẹ́ kó ṣeé ṣe fáwọn kan láti ṣàkóso lọ́run. Àmọ́, báwo lèèyàn ṣe lè di àtúnbí gan-an?

      [Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 7]

      Ìdí tí Ọlọ́run fi ń sọ ìwọ̀nba àwọn èèyàn kan di àtúnbí ni pé kí wọ́n lè ṣàkóso lọ́run

      [Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

      Jésù Kristi àtàwọn èèyàn tí Ọlọ́run yàn láti ṣàkóso pẹ̀lú rẹ̀ ló para pọ̀ di Ìjọba Ọlọ́run

  • Báwo Lèèyàn Ṣe Lè Di Àtúnbí?
    Ilé Ìṣọ́—2009 | April 1
    • Báwo Lèèyàn Ṣe Lè Di Àtúnbí?

      YÀTỌ̀ sí pé Jésù jẹ́ kí Nikodémù mọ bí dídi àtúnbí ṣe ṣe pàtàkì tó, tó jẹ́ kó mọ ohun tó máa jẹ́ kéèyàn di àtúnbí, tó sì jẹ́ kó mọ ìdí tó fi yẹ káwọn kan di àtúnbí, ó tún jẹ́ kó mọ béèyàn ṣe lè di àtúnbí. Jésù sọ pé: “Láìjẹ́ pé a bí ẹnikẹ́ni láti inú omi àti ẹ̀mí kò lè wọ ìjọba Ọlọ́run.” (Jòhánù 3:5) Torí náà, omi àti ẹ̀mí ló ń sọ ẹnì kan di àtúnbí. Àmọ́, kí ni “omi àti ẹ̀mí” túmọ̀ sí gan-an?

      Ohun Tí “Omi àti Ẹ̀mí” Túmọ̀ Sí Gan-an

      Torí pé ọ̀mọ̀wé ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn Júù ni Nikodémù, ó dájú pé ó ti ní láti mọ bí Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù ṣe máa ń sọ̀rọ̀ nípa “ẹ̀mí Ọlọ́run,” ìyẹn agbára ìṣiṣẹ́ tí Ọlọ́run lè fi mú káwọn èèyàn ṣe ohun kan tí kò ṣeé ṣe lójú lásán. (Jẹ́nẹ́sísì 41:38; Ẹ́kísódù 31:3; 1 Sámúẹ́lì 10:6) Torí náà, nígbà tí Jésù mẹ́nu ba “ẹ̀mí,” ó ti máa yé Nikodémù pé ọ̀rọ̀ nípa ẹ̀mí mímọ́, ìyẹn agbára ìṣiṣẹ́ Ọlọ́run, ni Jésù ń sọ.

      Omi tí Jésù wá sọ ńkọ́? Kíyè sáwọn ohun tí Bíbélì sọ pó ṣẹlẹ̀ ṣáájú kí Nikodémù tó wá bá Jésù àti lẹ́yìn tí wọ́n jọ sọ̀rọ̀ tán. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jòhánù Olùbatisí àtàwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ń batisí àwọn èèyàn nínú omi. (Jòhánù 1:19, 31; 3:22; 4:1-3) Nílùú Jerúsálẹ́mù, ọ̀pọ̀ ló mọ̀ pé ó yẹ́ kéèyàn ṣe batisí nínú omi. Torí náà, nígbà tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa omi, Nikodémù á ti fòye gbé e pé omi tí wọ́n fi ń ṣe batisí ni Jésù ń sọ, kì í kàn ṣe omi lásán.a

      Ṣe Batisí Nípasẹ̀ “Ẹ̀mí Mímọ́”

      Tí bíbí ẹnì kan “láti inú omi” bá túmọ̀ sí kéèyàn ṣe batisí nínú omi, kí ló wá túmọ̀ sí láti bí ẹnì kan ‘látinú ẹ̀mí’? Kó tó di pé Nikodémù lọ bá Jésù nílé, Jòhánù Olùbatisí ti sọ fáwọn èèyàn pé yàtọ̀ sí omi, ẹ̀mí tún máa nípa tó ń kó nínú batisí. Ó sọ pé: “Èmi fi omi batisí yín, ṣùgbọ́n [Jésù] yóò fi ẹ̀mí mímọ́ batisí yín.” (Máàkù 1:7, 8) Máàkù tóun náà kọ lára ìwé Ìhìn Rere sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà àkọ́kọ́ tírú batisí bẹ́ẹ̀ wáyé. Ó sọ pé: “Ó sì ṣe ní ọjọ́ wọnnì, Jésù wá láti Násárétì ti Gálílì, Jòhánù sì batisí rẹ̀ nínú Jọ́dánì. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, bí ó ti ń jáde sókè kúrò nínú omi, ó rí tí ọ̀run ń pínyà, àti pé, bí àdàbà, ẹ̀mí bà lé e.” (Máàkù 1:9, 10) Nígbà tí Jésù ṣèrìbọmi lódò Jọ́dánì, ó ṣe batisí nínú omi. Àmọ́, ó ṣe batisí nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ nígbà tí ẹ̀mí láti ọ̀run bà lé e.

      Ní nǹkan bí ọdún mẹ́ta lẹ́yìn tí Jésù ṣe batisí, ó jẹ́ kó dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lójú pé: “A ó batisí [wọn] nínú ẹ̀mí mímọ́ ní ọjọ́ tí kò ní pẹ́ púpọ̀ lẹ́yìn èyí.” (Ìṣe 1:5) Ìgbà wo nìyẹn ṣẹlẹ̀?

      Ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, nǹkan bí ọgọ́fà [120] ọmọ ẹ̀yìn Jésù kora jọ sílé kan ní Jerúsálẹ́mù. Bíbélì ròyìn pé: “Lójijì, ariwo kan dún láti ọ̀run gan-an gẹ́gẹ́ bí ti atẹ́gùn líle tí ń rọ́ yìì, ó sì kún inú gbogbo ilé tí wọ́n jókòó sí. Àwọn ahọ́n bí ti iná sì di rírí fún wọn . . . , gbogbo wọ́n sì wá kún fún ẹ̀mí mímọ́.” (Ìṣe 2:1-4) Lọ́jọ́ yẹn kan náà ni àpọ́sítélì Pétérù rọ àwọn èèyàn tó wà ní Jerúsálẹ́mù láti ṣe batisí nínú omi. Àpọ́sítélì Pétérù sọ fáwọn tó ń bá sọ̀rọ̀ pé: “Ẹ ronú pìwà dà, kí a sì batisí olúkúlùkù yín ní orúkọ Jésù Kristi fún ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín, ẹ ó sì gba ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ ẹ̀mí mímọ́.” Kí làwọn èèyàn náà ṣe? Bíbélì sọ pé: “Àwọn tí wọ́n fi tọkàntọkàn gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni a batisí, ní ọjọ́ yẹn nǹkan bí ẹgbẹ̀ẹ́dógún [3,000] ọkàn ni a sì fi kún wọn.”—Ìṣe 2:38, 41.

      Batisí Méjì Ló Ń Sọ Èèyàn Di Àtúnbí

      Kí làwọn batisí méjèèjì yìí jẹ́ ká mọ̀ nípa dídi àtúnbí? Wọ́n jẹ́ ká mọ̀ pé èèyàn ní láti ṣe batisí méjì kó tó lè di àtúnbí. Kíyè sí i pé Jésù kọ́kọ́ ṣe batisí nínú omi. Lẹ́yìn náà ló tó wa gba ẹ̀mí mímọ́. Bákan náà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ti kọ́kọ́ ṣe batisí nínú omi (Jòhánù Olùbatisí ló batisí àwọn kan), lẹ́yìn ìgbà yẹn ni wọ́n tó wá gba ẹ̀mí mímọ́. (Jòhánù 1:26-36) Àwọn ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000] èèyàn tí wọ́n wá di ọmọ ẹ̀yìn nígbà tó yá náà kọ́kọ́ ṣe batisí nínú omi, lẹ́yìn náà wọ́n gba ẹ̀mí mímọ́.

      Tá a bá ronú lórí batisí tó wáyé nígbà Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, a lè béèrè pé, báwo lèèyàn ṣe lè di àtúnbí lóde òní? Bó ṣe ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọlẹ́yìn Jésù àtàwọn míì tó dọmọ ẹ̀yìn nígbà yẹn náà ló ṣe máa rí. Onítọ̀hún máa kọ́kọ́ ronú pìwà dà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ó máa jáwọ nínú ìwà búburú, ó máa ya ìgbésí ayé ara ẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà láti máa jọ́sìn rẹ̀ àti láti máa ṣiṣẹ́ sìn ín, ó sì máa wá jẹ́ kí gbogbo èèyàn mọ̀ pé òun ti ya ara òun sí mímọ́ nípa ṣíṣe batisí nínú omi. Lẹ́yìn náà, tí Ọlọ́run bá yan onítọ̀hún láti jọba nínú Ìjọba ọ̀run, Ọlọ́run á fi ẹ̀mí mímọ́ yàn án. Kálukú ló máa pinnu láti ṣe apá àkọ́kọ́ (ìyẹn batisí nínú omi), àmọ́ Ọlọ́run ló máa pinnu apá kéji (ìyẹn batisí nínú ẹ̀mí). Tẹ́nì kan bá ṣe batisí méjèèjì, onítọ̀hún ti di àtúnbí nìyẹn.

      Kí wá nìdí tí Jésù fi sọ fún Nikodémù pé “láìjẹ́ pé a bí ẹnikẹ́ni láti inú omi àti ẹ̀mí kò lè wọ ìjọba Ọlọ́run”? Ó fẹ́ ko ṣe kedere pé ìyípadà pàtàkì ló máa wáyé nígbésí ayé àwọn tó bá ṣe batisí nínú omi àti nípasẹ̀ ẹ̀mí. Àpilẹ̀kọ tó kàn báyìí máa sọ̀rọ̀ nípa ìyípadà pàtàkì yìí.

      [Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

      a Nígbà kan, àpọ́sítélì Pétérù náà sọ ohun kan tó jọ èyí níbi batisí kan, ó ní: “Ẹnikẹ́ni ha lè ka omi léèwọ̀?”—Ìṣe 10:47.

      [Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

      Jòhánù fi omi batisí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ti ronú pìwà dà

  • Kí Ni Dídi Àtúnbí Máa Jẹ́ Kó Ṣeé Ṣe?
    Ilé Ìṣọ́—2009 | April 1
    • Kí Ni Dídi Àtúnbí Máa Jẹ́ Kó Ṣeé Ṣe?

      KÍ NÌDÍ tí Jésù fi lo gbólóhùn náà ‘bí látinú ẹ̀mí’ nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa batisí nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́? (Jòhánù 3:5) Lédè Yorùbá, tí wọ́n bá lo “bí” gẹ́gẹ́ bí àkànlò èdè, “ìbẹ̀rẹ̀” nǹkan ló sábà máa ń túmọ̀ sí. Bí àpẹẹrẹ téèyàn bá sọ pé “ìbí orílẹ̀-èdè,” ìgbà tí wọ́n dá orílẹ̀-èdè kan sílẹ̀ ló túmọ̀ sí. Torí náà, ọ̀rọ̀ náà “àtúnbí” túmọ̀ sí “ìbẹ̀rẹ̀ tuntun.” Bí Bíbélì ṣe lo “bí” àti “àtúnbí” gẹ́gẹ́ bí àkànlò èdè jẹ́ ká mọ̀ pé àjọṣe tuntun kan máa bẹ̀rẹ̀ láàárín Ọlọ́run àtàwọn tí Ọlọ́run bá fi ẹ̀mí mímọ́ batisí. Báwo ni àjọṣe tó kàmàmà yìí ṣe wáyé?

      Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń ṣàlàyé bí Ọlọ́run ṣe jẹ́ kó ṣeé ṣe fún ẹ̀dá èèyàn láti jọba lọ́run, ó fi ohun tó lè ṣẹlẹ̀ nínú ìgbésí ayé èèyàn ṣe àpèjúwe kan. Ó kọ̀wé sáwọn Kristẹni tí wọ́n jọ wà láyé nígbà yẹn pé Ọlọ́run máa ‘sọ wọ́n dọmọ,’ Ọlọ́run á sì wá máa bá wọn lò “bí ẹní ń bá àwọn ọmọ lò.” (Gálátíà 4:5; Hébérù 12:7) Tá a bá fẹ́ mọ bí àpẹẹrẹ ẹnì kan tí wọ́n sọ dọmọ ṣe lè jẹ́ ká lóye irú ìyípadà tó máa bá àwọn tí Ọlọ́run bá fi ẹ̀mí mímọ́ batisí, ẹ jẹ́ ká tún ronú lórí àpèjúwe ọmọkùnrin tó fẹ́ lọ síléèwé tó wà fáwọn ọmọ ìlú nìkan.

      Ìyípadà Tó Máa Ń Bá Ẹni Tí Wọ́n Bá Sọ Dọmọ

      Nínú àpèjúwe yẹn, ọmọkùnrin yẹn ò lè lọ kàwé níléèwé tí wọ́n dìídì dá sílẹ̀ fáwọn ọmọ ìlú yẹn. Àmọ́, ká sọ pé lọ́jọ́ kan, nǹkan yí pa dà. Bàbá kan tó jẹ́ ọmọ ìlú sọ ọmọkùnrin yìí dọmọ lábẹ́ òfin. Báwo lèyí ṣe máa nípa lórí ọmọkùnrin yìí? Torí pé wọ́n ti sọ òun náà dọmọ ìlú báyìí, gbogbo ohun tó tọ́ sáwọn ọmọ ìlú ti wá tọ́ sóun náà, ìyẹn sì kan ẹ̀tọ́ láti kàwé níléèwé tí wọ́n dá sílẹ̀ fáwọn ọmọ ìlú. Torí pé wọ́n ti sọ ọ́ dọmọ, àwọn ohun tí kò lè tẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ tẹ́lẹ̀ ti wá wà ní àtẹ́lẹwọ́ ẹ̀ báyìí.

      Bọ́rọ̀ àwọn tó ti di àtúnbí náà ṣe rí nìyẹn, bó tiẹ̀ jẹ́ pé tiwọn túbọ̀ lágbára gan-an ju tẹni tí wọ́n sọ dọmọ ìlú lọ. Jẹ́ ká wo àwọn ohun tó jọra nínú àpèjúwe ọmọkùnrin yẹn àtàwọn tó di àtúnbí. Ó dìgbà tí ọmọkùnrin inú àpèjúwé yẹn bá ṣe ohun táwọn aláṣẹ ìléèwé yẹn ní kó ṣe kó tó lè kàwé níléèwé yẹn, ìyẹn sì ni pé kó di ọmọ ìlú. Àmọ́, tá a bá fi dídàá ẹ̀, kò lè kúnjú ìwọ̀n láti kàwé níbẹ̀. Bákàn náà, àwọn ẹ̀dá èèyàn kan máa jọba nínú Ìjọba Ọlọ́run tàbí ìṣàkóso tó wà lọ́run, àmọ́ kìkì tí wọ́n bá kúnjú ìwọ̀n ohun tí Ọlọ́run ń béèrè lọ́wọ́ àwọn tó máa jọba lọ́run, ìyẹn sì ni pé kí wọ́n di “àtúnbí.” Àmọ́, tá a bá fi dídàá wọn, wọn ò lè jọba lọ́run torí Ọlọ́run ló ń pinnu ẹni tó máa di àtúnbí.

      Kí ló jẹ́ kọ́mọ náà láǹfààní láti kàwé níléèwé tí wọ́n dá sílẹ̀ fáwọn ọmọ ìlú? Torí pé bàbá kan sọ ọ́ dọmọ lábẹ́ òfin. Àmọ́, kì í ṣe pé ọmọkùnrin yí pa dà di ẹlòmíì. Lẹ́yìn tó ti ṣe gbogbo nǹkan tí òfin ní kó ṣe, ọmọ náà kúrò lálejò, ó dọmọ ìlú nìyẹn. Láìsí àní-àní, ọmọ náà bẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé tuntun tàbí ká kúkú sọ pé ó di àtúnbí. Ó dọmọ ìlú yẹn, ìyẹn sì jẹ́ kó lẹ́tọ̀ọ́ láti lọ síléèwé tó fẹ́ lọ, kó sì wá di ọ̀kan lára àwọn ọmọ bàbá tó sọ ọ́ dọmọ.

      Bákan náà, Jèhófà jẹ́ kí nǹkan yí pa dà fáwọn èèyàn díẹ̀ kan tí wọ́n jẹ́ aláìpé nípa ṣíṣe ohun tó bá òfin mu kó lè sọ wọ́n dọmọ. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tóun náà wà lára àwọn èèyàn kéréje yẹn kọ̀wé sáwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ pé: “Ẹ̀yin gba ẹ̀mí ìsọdọmọ, ẹ̀mí tí ń mú kí a ké jáde pé: ‘Ábà, Baba!’ Ẹ̀mí tìkára rẹ̀ ń jẹ́rìí pẹ̀lú ẹ̀mí wa pé àwa jẹ́ ọmọ Ọlọ́run.” (Róòmù 8:15, 16) Torí pé Ọlọ́run sọ àwọn Kristẹni yẹn dọmọ, wọ́n di ara ìdílé Ọlọ́run tàbí “ọmọ Ọlọ́run.”—1 Jòhánù 3:1; 2 Kọ́ríńtì 6:18.

      Àmọ́ o, bí Ọlọ́run ṣe sọ àwọn kan dọmọ ò wá sọ wọ́n di ẹni pípé, torí pé aláìpé náà ṣì ni wọ́n. (1 Jòhánù 1:8) Síbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ṣe jẹ́ ká mọ̀, lẹ́yìn tí Ọlọ́run ti sọ wọ́n dọmọ lábẹ́ òfin, wọ́n bọ́ sí ipò tuntun. Yàtọ̀ síyẹn, ẹ̀mí Ọlọ́run ló ń jẹ́ kó dá àwọn tí Ọlọ́run sọ dọmọ lójú pé wọ́n máa jọba pẹ̀lú Kristi lọ́run. (1 Jòhánù 3:2) Bí ẹ̀mí mímọ́ ṣe jẹ́ kó dá wọn lójú pé wọ́n máa jọba lọ́run ti jẹ́ kí ìrònú wọn nípa ìgbésí ayé yàtọ̀. (2 Kọ́ríńtì 1:21, 22) Wọ́n tipa bẹ́ẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé tuntun tàbí ká kúkú sọ pé wọ́n di àtúnbí.

      Bíbélì sọ nípa àwọn tí Ọlọ́run sọ dọmọ pé: “Wọn yóò jẹ́ àlùfáà Ọlọ́run àti ti Kristi, wọn yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba pẹ̀lú rẹ̀ fún ẹgbẹ̀rún ọdún náà.” (Ìṣípayá 20:6) Àwọn tí Ọlọ́run sọ dọmọ yìí máa jọba pẹ̀lú Kristi nínú Ìjọba Ọlọ́run tàbí ìṣàkóso ọ̀run. Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé sáwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni pé ìṣàkóso yẹn jẹ́ “aláìlè-díbàjẹ́ àti aláìlẹ́gbin àti aláìlèṣá” tí Ọlọ́run fi “pa mọ́ ní ọ̀run [dè wọ́n].” (1 Pétérù 1:3, 4) Ogún tó ṣeyebíye lèyí lóòótọ́!

      Àmọ́ ṣá o, ọ̀rọ̀ nípa ìṣàkóso yìí jẹ́ kí ìbéèrè kan wá síni lọ́kàn. Táwọn tí wọ́n ti di àtúnbí bá máa jọba lọ́run, àwọn wo ni wọ́n máa jọba lé lórí? Ìdáhùn sí ìbéèrè yìí wà nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e.

      [Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

      Kí ni Pọ́ọ̀lù sọ nípa àwọn tí Ọlọ́run sọ dọmọ?

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́