ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 5/1 ojú ìwé 30-31
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • A Máa Bá Yín Lọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020
  • “Àwa Yóò Bá Yín Lọ”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
  • “Ẹ̀mí Fúnra Rẹ̀ Ń Jẹ́rìí”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020
  • Ọlọ́run Kà Wá Yẹ Láti Gba Ìjọba Kan
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 5/1 ojú ìwé 30-31

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìgbà wo ni pípè tí Ọlọ́run ń pe àwọn Kristẹni sí ọ̀run yóò dópin?

Bíbélì kò fún wa ní ìdáhùn kan pàtó sí ìbéèrè yẹn. Ohun tá a mọ̀ ni pé fífi ẹ̀mí mímọ́ yan àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù kí wọ́n lè ní ìrètí àtilọ sí ọ̀run bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 33 Sànmánì Kristẹni. (Ìṣe 2:1-4) A tún mọ̀ pé lẹ́yìn táwọn àpọ́sítélì kú tán, àwọn ojúlówó Kristẹni tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró, ìyẹn “àlìkámà,” bẹ̀rẹ̀ sí í “dàgbà pa pọ̀” pẹ̀lú àwọn Kristẹni aláfẹnujẹ́, ìyẹn “èpò.” (Mátíù 13:24-30) Lẹ́yìn ìyẹn, bẹ̀rẹ̀ láti òpin ọ̀rúndún kọkàndínlógún, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tún bẹ̀rẹ̀ sí í fara hàn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní pẹrẹu. Ní ọdún 1919, “ìkórè ilẹ̀ ayé,” títí kan kíkó àwọn tó kù lára àwọn ẹni àmì òróró jọ, bẹ̀rẹ̀.—Ìṣípayá 14:15, 16.

Olórí ohun tí iṣẹ́ ìwàásù wà fún láti òpin ọ̀rúndún kọkàndínlógún títí di ọdún 1931 ni láti lè ko àwọn tó kù lára àwọn tó jẹ́ ara Kristi jọ. Lọ́dún 1931, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ́ orúkọ tó wá látinú Bíbélì, ìyẹn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àlàyé tó sì wà nínú Ilé Ìṣọ́ November 15, 1933 lédè Gẹ̀ẹ́sì ni pé, orúkọ àrà ọ̀tọ̀ yìí ni “dínárì” tí Jésù tọ́ka sí nínú àkàwé rẹ̀ tó wà nínú ìwé Mátíù 20:1-16. Wákàtí méjìlá tó mẹ́nu kàn nínú àkàwé yẹn ni wọ́n rò pé ó dúró fún ọdún méjìlá tó bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1919 títí di ọdún 1931. Ohun tí wọ́n gbà gbọ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn ìyẹn ni pé, pípe àwọn èèyàn sí Ìjọba ọ̀run ti dópin lọ́dún 1931, àti pé àwọn tá a pè láti jẹ́ ajogún pẹ̀lú Kristi lọ́dún 1930 àti ọdún 1931 làwọn “ẹni ìkẹyìn” tá a pè. (Mátíù 20:6-8) Àmọ́, lọ́dún 1966, a wá ní òye mìíràn nípa àkàwé yìí, ìgbà yẹn ló wá hàn kedere pé àkàwé náà kò ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú ìgbà tí pípe àwọn ẹni àmì òróró sí ọ̀run dópin.

Òye tá a ní lọ́dún 1935 ni pé, “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tá a mẹ́nu kàn nínú Ìṣípayá 7:9-15 ni àwọn “àgùntàn mìíràn,” tí wọ́n jẹ́ Kristẹni tó ní ìrètí àtigbé lórí ilẹ̀ ayé, tó sì jẹ́ pé àwọn la bẹ̀rẹ̀ sí í kó jọ “ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” àti pé àwọn, gẹ́gẹ́ bí àwùjọ kan, ló máa la Amágẹ́dọ́nì já. (Jòhánù 10:16; 2 Tímótì 3:1; Ìṣípayá 21:3, 4) Ìdí pàtàkì tá a wá fi ń ṣe iṣẹ́ sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn lẹ́yìn ọdún yẹn ni láti kó àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá jọ. Èyí ló mú ká wá gbà gbọ́, pàápàá lẹ́yìn ọdún 1966 pé, ìpè ti ọ̀run ti dópin lọ́dún 1935. Ó jọ pé ohun tá a gbà gbọ́ yìí túbọ̀ fìdí múlẹ̀ nígbà tó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo àwọn tó ṣèrìbọmi lẹ́yìn ọdún 1935 ló gbà pé orí ilẹ̀ ayé làwọn máa gbé. Ìdí nìyẹn tá a fi gbà pé ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá tún pè sí ọ̀run lẹ́yìn ìyẹn ní láti jẹ́ ẹni tá a fi rọ́pò àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó di aláìṣòótọ́.

Láìsí àní-àní, tí ọ̀kan lára àwọn ẹni àmì òróró bá ṣẹ̀ tí kò ronú pìwà dà, tó sì wá kúrò nínú òtítọ́, Jèhófà yóò pe ẹlòmíràn láti gba ipò rẹ̀. (Róòmù 11:17-22) Àmọ́, ó ṣeé ṣe kí iye àwọn ojúlówó ẹni àmì òróró tó fi ìjọsìn tòótọ́ sílẹ̀ má fi bẹ́ẹ̀ pọ̀. Yàtọ̀ síyẹn, bí àkókò ti ń lọ, àwọn Kristẹni kan tó ṣèrìbọmi lẹ́yìn ọdún 1935 tún rí i pé ẹ̀mí mímọ́ bá àwọn jẹ́rìí pé ọ̀run làwọn ń lọ. (Róòmù 8:16, 17) Nípa bẹ́ẹ̀, ó dà bíi pé a ò lè sọ pé àkókò kan báyìí pàtó ni pípè tí Ọlọ́run ń pe àwọn Kristẹni sí ọ̀run dópin.

Ojú wo ló wá yẹ ká fi wo ẹnì kan tó mọ̀ nínú ọkàn rẹ̀ pé òun ti di ẹni àmì òróró tó sì bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ tó sì ń mu ohun ìṣàpẹẹrẹ tá a máa ń lò fún ìrántí ikú Kristi? A ò gbọ́dọ̀ dá a lẹ́jọ́. Àárín òun àti Jèhófà ni ọ̀rọ̀ náà wà. (Róòmù 14:12) Àmọ́ o, àwọn ojúlówó Kristẹni ẹni àmì òróró kì í retí pé káwọn èèyàn máa yẹ́ wọn sí lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ kan. Wọ́n ò gbà gbọ́ pé jíjẹ́ táwọn jẹ́ ẹni àmì òróró mú káwọn ní “òye” ara ọ̀tọ̀ kan tó ju èyí táwọn kan tó lóye gan-an lára ogunlọ́gọ̀ ńlá ní. Wọn ò gbà pé àwọn ní ẹ̀mí mímọ́ ju àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn tó jẹ́ àgùntàn mìíràn, bẹ́ẹ̀ náà ni wọn kì í retí pé káwọn èèyàn inú ìjọ máa gbé wọn gẹ̀gẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í sọ pé jíjẹ táwọn ń jẹ lára ohun ìṣàpẹẹrẹ mú káwọn lọ́lá ju àwọn alàgbà inú ìjọ. Tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ ni wọ́n ń rántí pé àwọn ọkùnrin kan tó jẹ́ ẹni àmì òróró ní ọ̀rúndún kìíní kò kúnjú ìwọ̀n láti sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà tàbí ìránṣẹ́ ìṣẹ́ òjíṣẹ́. (1 Tímótì 3:1-10, 12, 13; Títù 1:5-9; Jákọ́bù 3:1) Kódà àwọn ẹni àmì òróró kan tiẹ̀ jẹ́ aláìlera nípa tẹ̀mí nígbà yẹn lọ́hùn-ún. (1 Tẹsalóníkà 5:14) Àti pé àwọn arábìnrin tó jẹ́ ẹni àmì òróró kò kọ́ni nínú ìjọ.—1 Tímótì 2:11, 12.

Nítorí náà, ńṣe làwọn Kristẹni ẹni àmì òróró àtàwọn ẹlẹgbẹ́ wọn tó jẹ́ àgùntàn mìíràn ń sa gbogbo ipá wọn kí àjọṣe àárín wọn pẹ̀lú Ọlọ́run lè gún régé. Wọ́n ń wá báwọn á ṣe máa ní èso tẹ̀mí nìṣó, wọ́n sì ń sapá láti mú kí àlàáfíà gbilẹ̀ nínú ìjọ. Gbogbo Kristẹni, yálà àwọn ẹni àmì òróró tàbí àwọn àgùntàn mìíràn, ló ń sa gbogbo ipá wọn nínú iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere àti iṣẹ́ sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn, èyí tí Ìgbìmọ̀ Olùdarí ń bójú tó. Ó sì tẹ́ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró lọ́rùn láti máa bá iṣẹ́ yìí lọ níwọ̀n ìgbà tó bá ṣì wu Ọlọ́run pé kí wọ́n wà lórí ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́