Orin 112
Jèhófà, Ọlọ́run Gíga
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Jèhófà Ọlọ́run Ńlá, ìwọ ni
Ìyìn tó ga jù lọ yẹ.
Gbogbo ọ̀nà rẹ ló tọ́.
Ìdájọ́ òdodo ni ìtẹ́ rẹ;
Ọlọ́run ayérayé.
2. O ńdarí ìṣìnà òun ẹ̀ṣẹ̀ jì,
O ń ṣàánú fún àwọn
Tó ńṣe àánú bíi tìrẹ.
Ìdájọ́ òdodo òun inúure,
Lo fi ńṣe ohun gbogbo.
3. Kí èèyàn òun áńgẹ́lì jọ yìn ọ́;
Ya oókọ rẹ sí mímọ́,
Kẹ́gàn kúrò lórí rẹ̀.
Kí Ìjọba rẹ ọ̀run mú kífẹ̀ẹ́
Rẹ ṣẹ ní ayé láìpẹ́.
(Tún wo Diu. 32:4; Òwe 16:12; Mát. 6:10; Ìṣí. 4:11.)