-
Ṣé Jíjẹ́ Olóòótọ́ Ṣì Bóde Mu?Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016 | No. 1
-
-
KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | KÍ NÌDÍ TÓ FI YẸ KÁ JẸ́ OLÓÒÓTỌ́?
Ṣé Jíjẹ́ Olóòótọ́ Ṣì Bóde Mu?
Ọ́fíìsì àkáǹtì ni Hitoshi ti ń ṣiṣẹ́ ní iléeṣẹ́ kan tó máa bá àwọn èèyàn wáṣẹ́ ní Japan. Lọ́jọ́ kan, òun àti ọ̀gá rẹ̀ jọ ń ṣàyẹ̀wò àkáǹtì, ni ọ̀gá rẹ̀ bá sọ fún un pé ó yẹ kó máa yí ìwé nídìí iṣẹ́ náà. Hitoshi ṣàlàyé fún ọ̀gá rẹ̀ pé ẹ̀rí ọkàn òun kò lè jẹ́ kí òun ṣe màdàrú. Ni ọ̀gá rẹ̀ bá halẹ̀ mọ́ ọn pé òun máa lé e lẹ́nu iṣẹ́, kò sì pẹ́ tí iṣẹ́ náà fi bọ́ lọ́wọ́ Hitoshi.
Láwọn oṣù tó tẹ̀ lé e, ẹ̀dùn ọkàn bá Hitoshi pé bóyá lòun máa rí iṣẹ́ míì. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó lọ ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò fún iṣẹ́ kan, Hitoshi sọ pé òun kò lè ṣe iṣé tó bá gba pé kí òun ṣe àìṣòótọ́. Ẹni tó ń fọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò sọ pé, “Ìrònú tìẹ yìí kò bá tayé mu!” Àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ Hitoshi sọ fún un pé bó ṣe jẹ́ olóòótọ́ nídìí iṣẹ́ rẹ̀ ló dáa jù, síbẹ̀ ọkàn Hitoshi bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe kámi-kàmì-kámi. Bi àpẹẹrẹ, ó ní: “Mi ò rò pé bí mo ṣe ń ṣòótọ́ yìí máa gbè mí.”
Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Hitoshi jẹ́ ká rí i pé kì í ṣe gbogbo èèyàn ló mọyì jíjẹ́ olóòótọ́. Kódà, àwọn kan gbà pé wàhálà lèèyàn ń wá tó bá jẹ́ olóòótọ́, pàápàá nídìí iṣẹ́ ajé. Obìnrin kan ní orílẹ̀-èdè South Africa sọ pé: “Àwọn aláìṣòótọ́ ló yí mi ká níbi iṣé, nígbà míì ó máa ń ṣe mí bíi pé kí èmi náà hùwà àìṣòótọ́.”
Irọ́ pípa jẹ́ ọkàn lára ìwà àìṣòótọ́ tó gbòde kan lóde òní. Láwọn ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, ọ̀jọ̀gbọ́n kan tó ń jẹ́ Robert S. Feldman láti yunifásítì Massachusetts Amherst ṣe ìwádìí kan. Ìwádìí náà fi hàn pé èèyàn mẹ́fà nínú mẹ́wàá ló jẹ́ pé tí wọ́n bá bá èèyàn sọ̀rọ̀ fún ìṣẹ́jú mẹ́wàá, ó kéré tán irọ́ kan á wà níbẹ̀. Feldman sọ pé: “Èyí yani lẹ́nu púpọ̀, a ò mọ̀ pé irọ́ pípa ti máa jingíri sáwọn èèyàn lára tó bẹ́ẹ̀.” Ó jọni lójú pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn kì í fẹ́ kí wọ́n parọ́ fáwọn, síbẹ̀ ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máa sì ìwà àìṣòótọ́ míì tó gbòde kan tó irọ́ pípa.
Kí nìdí tí irọ́ pípa, olè jíjà àtàwọn ìwà àìṣòótọ́ míì fi gbòde kan lóde òní? Báwo ni ìwà àìṣòótọ́ ṣe ń ṣàkóbá fún gbogbo èèyàn? Èyí tó wá ṣe pàtàkì jù ni pé kí la lè ṣe tí a kò fi ní máa lọ́wọ́ sí ìwà àìṣòótọ́ yìí?
-
-
Àkóbá Tí Ìwà Àìṣòótọ́ Lè Ṣe fún ẸIlé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016 | No. 1
-
-
KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | KÍ NÌDÍ TÓ FI YẸ KÁ JẸ́ OLÓÒÓTỌ́?
Àkóbá Tí Ìwà Àìṣòótọ́ Lè Ṣe fún Ẹ
“Èèyàn máa ń kó sí àwọn wàhálà kan tó jẹ́ pé àfi kéèyàn hùwà àìṣòótọ́ díẹ̀ kó tó bọ́ nínú wàhálà náà.”—Samantha, South Africa.
Ṣé o fara mọ́ ohun tí ẹni yìí sọ? Bíi ti Samantha, gbogbo wa la máa ń dojú kọ ìṣòro lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Àwọn ìṣòro yìí lè fẹ́ mú ká hùwà àìṣòótọ́. Ohun tá a bá ṣe láti yanjú ìṣòro náà máa fi hàn bóyá olóòótọ́ èèyàn ni wá tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Bí àpẹẹrẹ, tó bá jẹ́ pé ńṣe la ò fẹ́ kí ojú tì wá, a lè wò ó pé ó máa dáa ká kúkú parọ́ ká lè fi yọ ara wa. Tí òótọ́ bá wá jáde lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ohun tó máa ń tìdí ẹ̀ yọ kì í bára dé. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó sábà máa ń jẹ́ àbájáde ìwà àìṣòótọ́.
ÀÌṢÒÓTỌ́ KÌ Í JẸ́ KÍ WỌ́N FỌKÀN TÁNNI
Kí àárín ọ̀rẹ́ méjì tó lè wọ̀, wọ́n gbọ́dọ̀ fọkàn tán ara wọn. Tí àwọn méjì bá fọkàn tán ara wọn, wọn ò ní máa fura òdì sí ara wọn. Àmọ́, àwọn èèyàn ò kàn lè ṣàdédé bẹ̀rẹ̀ sí í fọkàn tán wa. Ohun tó lè mú káwọn èèyàn fọkàn tán wa ni pé ká máa sọ òótọ́, ká má sì figbá kan bọ̀kan nínú. Àmọ́ téèyàn bá hùwà àìṣòótọ́ lẹ́ẹ̀kan péré, àwọn èèyàn lè má fọkàn tán wa mọ́ rárá. Tọ́rọ̀ bá sì rí bẹ́ẹ̀, ó máa ṣòro gan-an ká tó lè mú káwọn èèyàn pa dà máa fọkàn tán wa.
Ṣé ẹnì kan tó o kà sí ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ti parọ́ fún ẹ rí? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, báwo ló ṣe rí lára rẹ? Ó ṣeé ṣe kó dùn ẹ́ wọra, wàá sì ka ẹni náà sí ọ̀rẹ́ ọ̀dàlẹ̀. Bó ṣe máa ń rí fún ọ̀pọ̀ èèyàn nìyẹn. Kò sí àní-àní pé ńṣe ni ìwà àìṣòótọ́ máa ń ba àjọṣe tó wà láàárín àwọn èèyàn jẹ́.
ÌWÀ ÀÌṢÒÓTỌ́ MÁA Ń RANNI
Ọ̀jọ̀gbọ́n Robert Innes, tó jẹ́ onímọ̀ nípa ètò ọrọ̀ ajé ní yunifásítì California ṣe ìwádìí kan. Ìwádìí náà fi hàn pé “ìwà àìṣòótọ́ máa ń ran àwọn ẹlòmíì.” Torí náà, a lè fi ìwà àìṣòótọ́ wé àrùn tó máa ń ranni. Èyí fi hàn pé tó o bá ń bá ẹlẹ́tàn èèyàn rìn, kò ní pẹ́ tí ìwọ náà á fi máa hùwà ẹ̀tàn. Ó ṣe tán, àgùntàn tó bá ń bá ajá rìn máa jẹ ìgbẹ́.
Kí lo lè ṣe tí o kò fi ní di aláìṣòótọ́? Bíbélì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́. Jẹ́ ká wo díẹ̀ nínú àwọn ìlànà Bíbélì yìí.
-
-
Àǹfààní Tó Wà Nínú Jíjẹ́ Olóòótọ́Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016 | No. 1
-
-
KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | KÍ NÌDÍ TÓ FI YẸ KÁ JẸ́ OLÓÒÓTỌ́?
Àǹfààní Tó Wà Nínú Jíjẹ́ Olóòótọ́
“Àwa ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé a ní ẹ̀rí-ọkàn aláìlábòsí, gẹ́gẹ́ bí a ti dàníyàn láti máa hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo.”—Hébérù 13:18.
Nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ Gíríìkì ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n tú sí “aláìlábòsí” túmọ̀ sí “ohun kan tó dára lọ́nà àrà ọ̀tọ̀.” Ó tún túmọ̀ sí ìwà rere tàbí ìṣòtítọ́ tí kò lẹ́gbẹ́.
Ọwọ́ pàtàkì làwọn Kristẹni fi mú ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti sọ yìí, ó ní: “A ti dàníyàn láti máa hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo.” Báwo la ṣe lè jẹ́ aláìlábòsí?
MÁ ṢE FÀYÈ GBA ÈRÒKÉRÒ
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń wo gíláàsì lárààárọ̀ kí wọ́n tó jáde kúrò nílé. Kí nìdí? Torí pé wọ́n fẹ́ kí ìrísí wọn dáa lójú àwọn èèyàn. Àmọ́, ohun kan wà tó ṣe pàtàkì ju pé kéèyàn ṣe irun tó dáa tàbí kó wọ aṣọ tó gbayì. Nǹkan náà ni, irú ẹni tá a jẹ́ ní inú lọ́hùn-ún tàbí ìwà wa. Ìwà tí à ń hù lè buyì kún wa tàbí kó kàn wá lábùkù láìka bá a ṣe rẹwà sí.
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dìídì sọ pé ó máa ń wu àwa èèyàn láti ṣe ohun tó burú. Jẹ́nẹ́sísì 8:21 sọ pé: “Ìtẹ̀sí èrò ọkàn-àyà ènìyàn jẹ́ búburú láti ìgbà èwe rẹ̀ wá.” Tórí náà, ká tó lè jẹ́ olóòótọ́ èèyàn, a gbọ́dọ̀ máa sapá láti má ṣe jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ darí wa. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ bó ṣe sapá tó láti má ṣe jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ darí òun, ó ní: “Ní ti gidi, mo ní inú dídùn sí òfin Ọlọ́run ní ìbámu pẹ̀lú ẹni tí mo jẹ́ ní inú, ṣùgbọ́n mo rí òfin mìíràn nínú àwọn ẹ̀yà ara mi tí ń bá òfin èrò inú mi jagun, tí ó sì ń mú mi lọ ní òǹdè fún òfin ẹ̀ṣẹ̀ tí ó wà nínú àwọn ẹ̀yà ara mi.”—Róòmù 7:22, 23.
Bí àpẹẹrẹ, tí ọkàn wa bá ń sún wa ṣáá pé ká hùwà àìṣòótọ́, kò yẹ ká gbà láti ṣe ohun tí ọkàn wa ń fẹ́ sún wa ṣe. Àwa fúnra wa la máa yan ohun tá a máa ṣe. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àárín àwọn aláìṣòótọ́ èèyàn là ń gbé, tí a kò bá gba èròkérò láyè lọ́kàn wa, a ò ní bá wọn lọ́wọ́ sí híhùwà àìṣòótọ́.
BÁ A ṢE LÈ JẸ́ OLÓÒÓTỌ́
Ká tó lè jẹ́ olóòótọ́, a gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé ìlànà ìwà rere tí Ọlọ́run fún wa. Àmọ́, ó ṣeni láàánú pé, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń lo àkókò tó pọ̀ láti ronú lórí bí ‘ìmúra tàbí ìrísí’ wọn ṣe máa dáa sí i, àmọ́ wọn kì í fi bẹ́ẹ̀ ronú lórí bí ìwà wọn ṣe máa dáa sí i. Torí náà, wọ́n máa ń ṣe àwáwí pé ipò tí àwọn wà ló mú káwọn hùwà àìṣòótọ́. Ìwé The (Honest) Truth About Dishonesty sọ pé: “À máa ń ronú pé tá a bá rẹ́ àwọn èèyàn jẹ níwọ̀nba, a ò tíì ṣe ohun tó burú jù.” Ǹjẹ́ ìlànà kankan wa tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun gbogbo? Bẹ́ẹ̀ ni, ó wà.
Bíbélì ti ran ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn kárí ayé lọ́wọ́ láti jẹ́ olóòótọ́. Bíbélì ní ọ̀pọ̀ ìlànà ìwà rere tí a kò lè rí níbòmíì. (Sáàmù 19:7) Bíbélì tún pèsè ìtọ́sọ́nà tó wúlò lórí àwọn nǹkan bí ìdílé, iṣẹ́, ìwà mímọ́ àti àjọṣe pẹ̀lú Ọlọ́run. Ó sì ti pẹ́ gan-an tí àwọn ìlànà inú rẹ̀ ti ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Àwọn òfin àti ìlànà inú Bíbélì wúlò fún onírúurú èèyàn, láìka orílẹ̀-èdè, ẹ̀yà àti ìran tí wọ́n ti wá sí. Tá a bá ń ka Bíbélì, tá a ronú lórí ohun tá a kà, tá a sì fi àwọn ìmọ̀ràn rẹ̀ sílò, ó máa jẹ́ ká lè kọ́ ara wa láti jẹ́ olóòótọ́.
Àmọ́ yàtọ̀ sí pé ká ní ìmọ̀ Bíbélì, àwọn nǹkan míì wà tá a tún ní láti ṣe ká tó lè jẹ́ olóòótọ́. Ó ṣe tán, inú ayé tí onírúurú ìwà ìbàjẹ́ ti kún ọwọ́ àwọn èèyàn là ń gbé, wọ́n sì fẹ́ sọ wá di bí wọ́n ṣe dà. Ìdí nìyẹn tá a fi ní láti gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ràn wá lọ́wọ́ kó sì tì wá lẹ́yìn. (Fílípì 4:6, 7, 13) Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a máa ní ìgboyà láti ṣe ohun tó tọ́, a ò sì lè jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun gbogbo.
ÈRÈ TÓ WÀ NÍNÚ JÍJẸ́ OLÓÒÓTỌ́
Hitoshi, tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́ jàǹfààní torí pé ó jẹ́ òṣìṣẹ́ tí kì í ṣe màdàrú. Ẹni tó mọyì kéèyàn jẹ́ olóòótọ́ ló ń bá ṣiṣẹ́ báyìí. Hitoshi sọ pé: “Mo dúpẹ́ pé mo rí iṣẹ́ tó máa jẹ́ kí n ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́.”
Àwọn míì náà ti rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí. Wo àpẹẹrẹ àwọn tó ti jàǹfààní nínú títẹ̀lé ìlànà Bíbélì tó sọ pé ká máa “hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo.”
Ẹ̀rí Ọkàn Tó Mọ́
“Ọmọ ọdún mẹ́tàlá [13] ni mí nígbà tí mo fi iléèwé sílẹ̀, tí mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn olè ṣiṣẹ́. Torí náà, ọ̀nà èrú ni mò ń gbà rí èyí tó pọ̀ jù lọ lára owó tí mò ń ná. Lẹ́yìn tí mo lọ sílé ọkọ, èmi àti ọkọ mi bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. A kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófàa Ọlọ́run kórìíra ìwà àìṣòótọ́, torí náà a pinnu láti yíwà pa dà. Lọ́dún 1990, a ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà, a sì ṣe ìrìbọmi, a sì tipa bẹ́ẹ̀ di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.”—Òwe 6:16-19.
“Nígbà kan, ẹrù olè ló kún ilé mi, àmọ́ ní báyìí kò sí ẹrù olè mọ́ nílé wa, èyí sì jẹ́ kí n ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́. Tí mo bá ronú pa dà sẹ́yìn sí àwọn ọdún tí mo fi hùwà àìṣòótọ́, ńṣe ni mo máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún àánú rẹ̀ lórí mi. Ọkàn mi sì máa ń balẹ̀ tí mo bá fẹ́ lọ sùn lálẹ́ pé Jèhófà ti yọ́nú sí mi báyìí.”—Cheryl, Ireland.
“Nígbà tí ọ̀gá mi gbọ́ pé mi ò gba rìbá lọ́wọ́ ẹnì kan tó fẹ́ di oníbàárà wa, ó sọ fún mi pé: ‘Ọlọ́run rẹ ti sọ ẹ́ di ẹni téèyàn lè fọkàn tán! Ìbùkún gidi lo jẹ́ fún iléeṣẹ́ yìí.’ Bí mo ṣe jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun gbogbo ti jẹ́ kí n ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́ níwájú Jèhófà Ọlọ́run. Ó tún ti jẹ́ kí n lè ran ìdílé mi àtàwọn míì lọ́wọ́ láti jẹ́ olóòótọ́.”—Sonny, Hong Kong.
Ìbàlẹ̀ Ọkàn
“Báǹkì ńlá kan ni mo ti ń ṣiṣẹ́. Ọ̀kan lára àwọn ọ̀gá pátápátá ni mo sì ń bá ṣiṣẹ́. Nínú irú iṣẹ́ báyìí, àwọn èèyàn kì í ṣe òótọ́, torí kí wọ́n lè di ọlọ́rọ̀. Ohun tí wọ́n sábà máa ń sọ ni pé, ‘kò sí ohun tó burú nínú ṣíṣe èrú tí owó bá ṣáà ti máa yọ nídìí ẹ̀, tó sì máa jẹ́ kí ọrọ̀ ajé túbọ̀ gbèrú.’ Àmọ́ torí pé mo jẹ́ olóòótọ́, ọkàn mi balẹ̀. Mo ti pinnu pé mi ò ní jáwọ́ nínú jíjẹ́ olóòótọ́ láìka ohun yòówù kó tìdí ẹ̀ yọ. Àwọn tó gbà mí síṣẹ́ mọ̀ pé mi ò ní parọ́ fún wọn, mi ò sì ní báwọn parọ́.”—Tom, Amẹ́ríkà.
Iyì Ara Ẹni
“Ọ̀gá mi sọ fún mi pé kí n parọ́ nípa àwọn ohun èlò ibi iṣẹ́ wa tó sọnù, àmọ́ mo kọ̀ jálẹ̀. Nígbà tí àṣírí àwọn olè náà tú, àwọn tó gbà mí síṣẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ mi torí pé mo jẹ́ olóòótọ́. Ó gba pé kéèyàn ní ìgboyà kó tó lè jẹ́ olóòótọ́ nínú ayé tí ìwà àìṣòótọ́ kúnnú rẹ̀ yìí. Àmọ́ ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, àwọn èèyàn máa fọkàn tán wa.”—Kaori, Japan.
Ó ṣàǹfààní gan-an pé kéèyàn jẹ́ olóòótọ́, torí pé ó máa jẹ́ kéèyàn ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́, ìbàlẹ̀ ọkàn àti iyì ara ẹni. Ṣé o gbà bẹ́ẹ̀?
a Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.
-