ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • wp16 No. 1 ojú ìwé 4-5
  • Àkóbá Tí Ìwà Àìṣòótọ́ Lè Ṣe fún Ẹ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àkóbá Tí Ìwà Àìṣòótọ́ Lè Ṣe fún Ẹ
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ÀÌṢÒÓTỌ́ KÌ Í JẸ́ KÍ WỌ́N FỌKÀN TÁNNI
  • ÌWÀ ÀÌṢÒÓTỌ́ MÁA Ń RANNI
  • Àwọn Ohun Tó Mú Kó Ṣòro Láti Jẹ́ Olóòótọ́
    Jí!—2012
  • Àǹfààní Tó Wà Nínú Jíjẹ́ Olóòótọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016
  • Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
  • Àìṣòótọ́ Gbòde Kan!
    Jí!—2012
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016
wp16 No. 1 ojú ìwé 4-5
Àwọn obìnrin méjì ń bá ara wọn sọ̀rọ̀

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | KÍ NÌDÍ TÓ FI YẸ KÁ JẸ́ OLÓÒÓTỌ́?

Àkóbá Tí Ìwà Àìṣòótọ́ Lè Ṣe fún Ẹ

“Èèyàn máa ń kó sí àwọn wàhálà kan tó jẹ́ pé àfi kéèyàn hùwà àìṣòótọ́ díẹ̀ kó tó bọ́ nínú wàhálà náà.”—Samantha, South Africa.

Ṣé o fara mọ́ ohun tí ẹni yìí sọ? Bíi ti Samantha, gbogbo wa la máa ń dojú kọ ìṣòro lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Àwọn ìṣòro yìí lè fẹ́ mú ká hùwà àìṣòótọ́. Ohun tá a bá ṣe láti yanjú ìṣòro náà máa fi hàn bóyá olóòótọ́ èèyàn ni wá tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Bí àpẹẹrẹ, tó bá jẹ́ pé ńṣe la ò fẹ́ kí ojú tì wá, a lè wò ó pé ó máa dáa ká kúkú parọ́ ká lè fi yọ ara wa. Tí òótọ́ bá wá jáde lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ohun tó máa ń tìdí ẹ̀ yọ kì í bára dé. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó sábà máa ń jẹ́ àbájáde ìwà àìṣòótọ́.

ÀÌṢÒÓTỌ́ KÌ Í JẸ́ KÍ WỌ́N FỌKÀN TÁNNI

Kí àárín ọ̀rẹ́ méjì tó lè wọ̀, wọ́n gbọ́dọ̀ fọkàn tán ara wọn. Tí àwọn méjì bá fọkàn tán ara wọn, wọn ò ní máa fura òdì sí ara wọn. Àmọ́, àwọn èèyàn ò kàn lè ṣàdédé bẹ̀rẹ̀ sí í fọkàn tán wa. Ohun tó lè mú káwọn èèyàn fọkàn tán wa ni pé ká máa sọ òótọ́, ká má sì figbá kan bọ̀kan nínú. Àmọ́ téèyàn bá hùwà àìṣòótọ́ lẹ́ẹ̀kan péré, àwọn èèyàn lè má fọkàn tán wa mọ́ rárá. Tọ́rọ̀ bá sì rí bẹ́ẹ̀, ó máa ṣòro gan-an ká tó lè mú káwọn èèyàn pa dà máa fọkàn tán wa.

Ṣé ẹnì kan tó o kà sí ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ti parọ́ fún ẹ rí? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, báwo ló ṣe rí lára rẹ? Ó ṣeé ṣe kó dùn ẹ́ wọra, wàá sì ka ẹni náà sí ọ̀rẹ́ ọ̀dàlẹ̀. Bó ṣe máa ń rí fún ọ̀pọ̀ èèyàn nìyẹn. Kò sí àní-àní pé ńṣe ni ìwà àìṣòótọ́ máa ń ba àjọṣe tó wà láàárín àwọn èèyàn jẹ́.

ÌWÀ ÀÌṢÒÓTỌ́ MÁA Ń RANNI

Ọ̀jọ̀gbọ́n Robert Innes, tó jẹ́ onímọ̀ nípa ètò ọrọ̀ ajé ní yunifásítì California ṣe ìwádìí kan. Ìwádìí náà fi hàn pé “ìwà àìṣòótọ́ máa ń ran àwọn ẹlòmíì.” Torí náà, a lè fi ìwà àìṣòótọ́ wé àrùn tó máa ń ranni. Èyí fi hàn pé tó o bá ń bá ẹlẹ́tàn èèyàn rìn, kò ní pẹ́ tí ìwọ náà á fi máa hùwà ẹ̀tàn. Ó ṣe tán, àgùntàn tó bá ń bá ajá rìn máa jẹ ìgbẹ́.

Kí lo lè ṣe tí o kò fi ní di aláìṣòótọ́? Bíbélì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́. Jẹ́ ká wo díẹ̀ nínú àwọn ìlànà Bíbélì yìí.

Onírúurú Ìwà Àìṣòótọ́

Irọ́

Ọkùnrin kan ń yọ òrùka ìgbéyàwó rẹ̀

KÍ LÓ TÚMỌ̀ SÍ? Kéèyàn sọ ohun tí kì í ṣe òótọ́ fún ẹni tó yẹ kó mọ òótọ́. Irọ́ pípa kan kéèyàn má sọ bọ́rọ̀ ṣe jẹ́ gan-an tàbí kéèyàn dojú ọ̀rọ̀ rú kó lè ṣini lọ́nà. Ó tún kan yíyọ ìsọfúnni pàtàkì kúrò láti tanni jẹ àti kéèyàn ṣe àbùmọ́ kó lè gbayì lójú àwọn èèyàn.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: “Oníbékebèke jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà, ṣùgbọ́n ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ Rẹ̀ wà pẹ̀lú àwọn adúróṣánṣán.” (Òwe 3:32) “Nísinsìnyí tí ẹ ti fi èké ṣíṣe sílẹ̀, kí olúkúlùkù yín máa bá aládùúgbò rẹ̀ sọ òtítọ́.”—Éfésù 4:25.

Òfófó

Ọkùnrin méjì sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ sí ara wọn bí ọkùnrin mí ì ṣe wọlé

KÍ LÓ TÚMỌ̀ SÍ? Píparọ́ tàbí sísọ̀rọ̀ burúkú láti fi bani lórúkọ jẹ́.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: “Ènìyàn tí ń so ìpàǹpá ń rán asọ̀ jáde ṣáá, afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́ sì ń ya àwọn tí ó mọ ara wọn dunjú nípa.” (Òwe 16:28) “Níbi tí igi kò bá sí, iná a kú, níbi tí afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́ kò bá sì sí, asọ̀ a dá.”—Òwe 26:20.

Jìbìtì

Ọkùnrin kan nawọ́ sí àwọn aago tó kó pamọ́ sínú ẹ̀wù rẹ̀

KÍ LÓ TÚMỌ̀ SÍ? Títan ẹnì kan jẹ láti gba owó tàbí dúkìá lọ́wọ́ rẹ̀.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ lu lébìrà tí a gbà sí iṣẹ́, tí ó wà nínú ìdààmú, tí ó sì jẹ́ òtòṣì, ní jìbìtì.” (Diutarónómì 24:14, 15) “Ẹni tí ń lu ẹni rírẹlẹ̀ ní jìbìtì ti gan Olùṣẹ̀dá rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ń fi ojú rere hàn sí àwọn òtòṣì ń yìn Ín.”—Òwe 14:31.

Olè

Ẹnì kan ń jí pọ́ọ̀sì nínu báàgì kan

KÍ LÓ TÚMỌ̀ SÍ? Mímú nǹkan ẹlòmíì láìgba àṣẹ.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: “Kí ẹni tí ń jalè má jalè mọ́, ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, kí ó máa ṣe iṣẹ́ àṣekára, kí ó máa fi ọwọ́ rẹ̀ ṣe ohun tí ó jẹ́ iṣẹ́ rere, kí ó lè ní nǹkan láti pín fún ẹni tí ó wà nínú àìní.” (Éfésù 4:28) ‘Kí a má ṣì yín lọ́nà, àwọn olè, tàbí àwọn oníwọra, tàbí àwọn ọ̀mùtípara, tàbí àwọn olùkẹ́gàn, tàbí àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà kì yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.’—1 Kọ́ríńtì 6:9, 10.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́