Orin 95
“Ẹ Tọ́ Ọ Wò, Kí Ẹ sì Rí I Pé Jèhófà Jẹ́ Ẹni Rere”
Bíi Ti Orí Ìwé
1. A nífẹ̀ẹ́ iṣẹ́ Ọlọ́run;
A mọyì iṣẹ́ ìwàásù.
A ńràkòókò pa dà fún ’ṣẹ́ ìsìn,
Torí ọ̀pọ̀ kòì gbọ́wàásù.
(ÈGBÈ)
Bíbélì sọ pé: ‘Tọ́ọ wò, kóo ríi,
Ẹniire ni Jèhófà.’
Ìfọkànsìn Ọlọ́run lérè,
Gbogbo ipá wa la ńsà.
2. Ìbùkún jìngbìnnì ló wà
Fáwọn alákòókò-kíkún.
Wọ́n gbà pé Ọlọ́run ńtọ́jú àwọn,
Wọ́n ńnítẹ̀ẹ́lọ́run láyé wọn.
(ÈGBÈ)
Bíbélì sọ pé: ‘Tọ́ọ wò, kóo ríi,
Ẹniire ni Jèhófà.’
Ìfọkànsìn Ọlọ́run lérè,
Gbogbo ipá wa la ńsà.
(Tún wo Máàkù 14:8; Lúùkù 21:2; 1 Tím. 1:12; 6:6.)