ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Kò Sí Ẹni Tó Lè Sin Ọ̀gá Méjì
    Ilé Ìṣọ́—2014 | April 15
    • Kò Sí Ẹni Tó Lè Sin Ọ̀gá Méjì

      “Kò sí ẹnì kan tí ó lè sìnrú fún ọ̀gá méjì. . . . Ẹ kò lè sìnrú fún Ọlọ́run àti fún Ọrọ̀.”—MÁT. 6:24.

      KÍ LÈRÒ RẸ?

      • Báwo ni àwọn ìlànà Bíbélì ṣe lè mú ká máa fi ojú tó tọ́ wo ojúṣe wa nínú ìdílé?

      • Báwo làwọn ìpinnu wa ṣe lè fi hàn pé Jèhófà nìkan là ń sìn?

      • Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà ń bù kún àwọn ìpinnu wa tá a bá fi Í sípò àkọ́kọ́?

      1-3. (a) Báwo lọ̀rọ̀ ìṣúnná owó ṣe rí fún ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí? Kí làwọn kan ń ṣe láti yanjú ìṣòro náà? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.) (b) Ìṣòro wo làwọn kan máa ń ní nípa bí wọ́n á ṣe tọ́jú àwọn ọmọ wọn?

      OBÌNRIN kan tó ń jẹ́ Marilyna sọ nípa ọkọ rẹ̀ tó ń jẹ́ James pé: “Ojoojúmọ́ ló máa ń rẹ ọkọ mi tẹnutẹnu nígbà tó bá fi máa dé láti ibiṣẹ́, gbogbo owó tó sì ń mú wálé kò kọjá ohun tá a lè ná tán lóòjọ́. Mò ń wá bí màá ṣe mú kí ẹrù rẹ̀ fúyẹ́, kí n sì tún lè máa ra àwọn nǹkan ìṣeré ọmọdé fún Jimmy ọmọ wa, irú èyí tó máa ń rí lọ́wọ́ àwọn ọmọ iléèwé rẹ̀.” Ó tún wu Marilyn pé kó ran àwọn ìbátan wọn lọ́wọ́ kó sì fi owó díẹ̀ pa mọ́ torí ọjọ́ ìdágìrì. Ọ̀pọ̀ lára àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ló ti gba àwọn orílẹ̀-èdè míì lọ kí wọ́n lè rí towó ṣe. Àmọ́ nígbà tó ń ronú bóyá kóun lọ tàbí kóun má lọ, kò mọ èyí tí ì bá ṣe. Kí nìdí?

      2 Ìdí ni pé Marilyn kò fẹ́ fi ìdílé rẹ̀ ọ̀wọ́n sílẹ̀ kò sì fẹ́ kí àwọn nǹkan tẹ̀mí tí wọ́n jọ máa ń ṣe dúró. Síbẹ̀, ó ronú pé àwọn kan ti lọ sókè òkun rí tó sì dà bíi pé ìyẹn ò pa àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run lára. Àmọ́, ó wá ń ronú nípa bó ṣe máa tọ́ Jimmy dàgbà látòkè òkun. Ó ronú pé, ṣé òun á sì lè tọ́ ọmọ náà dàgbà “nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà” látorí Íńtánẹ́ẹ̀tì?—Éfé. 6:4.

      3 Marilyn fi ọ̀rọ̀ náà lọ àwọn èèyàn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò wu ọkọ rẹ̀ pé kó lọ, síbẹ̀ ó sọ pé òun ò ní dá a dúró. Àwọn alàgbà àtàwọn míì nínú ìjọ gbà á níyànjú pé kó má lọ, àmọ́ àwọn arábìnrin mélòó kan rọ̀ ọ́ pé kó lọ sókè òkun. Wọ́n sọ fún un pé: “Tó o bá nífẹ̀ẹ́ ìdílé rẹ, wàá lọ. Ìyẹn ò sì ní kó o má sin Jèhófà.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọkàn Marilyn kò balẹ̀, ó fẹnu ko ọkọ rẹ̀ àti ọmọ rẹ̀ lẹ́nu, ó dágbére fún wọn, ó sì gba òkè òkun lọ. Ó wá ṣèlérí fún wọn pé: “Mi ò ní pẹ́ rárá tí màá fi pa dà.”

      OJÚṢE ÌDÍLÉ ÀTI ÀWỌN ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ

      4. Kí nìdí tí àwọn kan fi ń kó lọ sí ilẹ̀ òkèèrè? Àwọn wo ni wọ́n sábà máa ń fi àwọn ọmọ wọn tì?

      4 Kò wu Jèhófà pé kí òṣì máa ta àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ọjọ́ sì ti pẹ́ táwọn èèyàn ti máa ń lọ sílẹ̀ òkèèrè kí wọ́n lè gbọn ìṣẹ́ dà nù. (Sm. 37:25; Òwe 30:8) Kí ebi má bàa pa ìdílé Jékọ́bù tó jẹ́ baba ńlá ìgbàanì kú, ó rán àwọn ọmọ rẹ̀ lọ sílẹ̀ Íjíbítì pé kí wọ́n lọ ra oúnjẹ.b (Jẹ́n. 42:1, 2) Kì í sábà jẹ́ torí ebi ni ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe ń gba ilẹ̀ òkèèrè lọ lóde òní. Àmọ́ ó lè jẹ́ torí pé wọ́n ti tọrùn bọ gbèsè ńlá. Ohun táwọn míì sì ń wá ò ju bí wọ́n ṣe lè mú kí nǹkan gbé pẹ́ẹ́lí sí i nínú ìdílé wọn. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló sì jẹ́ pé wọn ò fẹ́ kí ọrọ̀ ajé tó ń dẹnu kọlẹ̀ febi pa ìdílé wọn, torí náà wọ́n pinnu pé ó máa dára káwọn wá àtijẹ àtimu lọ sí apá ibòmíì ní orílẹ̀-èdè wọn tàbí ní ilẹ̀ òkèèrè. Irú àwọn bẹ́ẹ̀ sábà máa ń fi àwọn ọmọ wọn tí kò tíì tójú bọ́ sílẹ̀ fún ọkọ tàbí aya wọn. Ó sì lè jẹ́ èyí tó dàgbà jù nínú àwọn ọmọ náà ní wọ́n á ní kó máa tọ́jú àwọn yòókù, tàbí kí wọ́n kó wọn ti òbí wọn àgbà, ìbátan wọn míì, tàbí àwọn ọ̀rẹ́ wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ojú bọ̀rọ̀ kọ́ ni àwọn tó ń kó lọ sílẹ̀ míì fi ń fi aya tàbí ọkọ àtàwọn ọmọ wọn sílẹ̀, síbẹ̀ wọ́n gbà pé kò sí ọgbọ́n míì táwọn lè dá sí i.

      5, 6. (a) Kí ni Jésù sọ nípa béèyàn ṣe lè rí ayọ̀ àti ìfọ̀kànbalẹ̀? (b) Àwọn nǹkan tara wo ni Jésù ní kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun máa gbàdúrà fún? (d) Báwo ni Jèhófà ṣe ń bù kún wa?

      5 Nígbà tí Jésù wà láyé, ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò fi bẹ́ẹ̀ rí já jẹ, tí nǹkan ò sì ṣẹnuure fún, wọ́n sì lè máa ronú pé ó dìgbà táwọn bá lówó lọ́wọ́ kí àwọn tó láyọ̀ kí ọkàn àwọn sì balẹ̀. (Máàkù 14:7) Àmọ́, ibòmíì ni Jésù fẹ́ kí àwọn èèyàn fojú sí. Ó fẹ́ kí wọ́n gbára lé Jèhófà, tó jẹ́ Orísun ọrọ̀ tí kì í tán. Nínú ìwàásù tí Jésù ṣe lórí Òkè, ó ṣàlàyé pé èèyàn ò lè rí ojúlówó ayọ̀ àti ìfọ̀kànbalẹ̀ látinú àwọn nǹkan tara tàbí ìsapá ara ẹni, bí kò ṣe látinú àjọṣe tó dára pẹ̀lú Baba wa ọ̀run.

      6 Nínú àdúrà àwòṣe tí Jésù kọ́ wa, kò sọ pé ká máa gbàdúrà fún owó. Ohun tá a nílò lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan ló ní ká béèrè, ìyẹn “oúnjẹ wa fún ọjọ́ òní.” Ó sọ ní ṣàkó fún àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Ẹ dẹ́kun títo àwọn ìṣúra jọ pa mọ́ fún ara yín lórí ilẹ̀ ayé . . . Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ to ìṣúra jọ pa mọ́ fún ara yín ní ọ̀run.” (Mát. 6:9, 11, 19, 20) Kò sídìí fún wa láti ṣiyè méjì pé Jèhófà máa bù kún wa bó ti ṣèlérí. Ìbùkún tí Ọlọ́run máa fún wa kọjá o káre láé, ńṣe ló máa dìídì fún wa ní ohun tá a nílò ní ti gidi. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, ọ̀nà kan ṣoṣo tá a fi lè ní ayọ̀ àti ìfọ̀kànbalẹ̀ ni pé ká gbẹ́kẹ̀ lé Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́ dípò tá ó fi máa gbẹ́kẹ̀ lé owó.—Ka Mátíù 6:24, 25, 31-34.

      7. (a) Ta ni Jèhófà fa iṣẹ́ títọ́ àwọn ọmọ lé lọ́wọ́? (b) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí àwọn òbí méjèèjì pawọ́ pọ̀ láti tọ́ àwọn ọmọ wọn?

      7 Lára ọ̀nà téèyàn lè gbà máa ‘wá òdodo Ọlọ́run lákọ̀ọ́kọ́’ ni pé kéèyàn máa ṣe ojúṣe rẹ̀ nínú ìdílé bí Jèhófà ṣe fẹ́. Ìlànà tó kan àwa Kristẹni yìí náà wà nínú Òfin Mósè. Ó yẹ kí àwọn òbí máa kọ́ àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Ka Diutarónómì 6:6, 7.) Àwọn òbí ni Ọlọ́run fa iṣẹ́ yìí lé lọ́wọ́, kì í ṣe àwọn òbí wọn àgbà tàbí àwọn míì. Sólómọ́nì Ọba sọ pé: “Fetí sílẹ̀, ọmọ mi, sí ìbáwí baba rẹ, má sì ṣá òfin ìyá rẹ tì.” (Òwe 1:8) Ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn ni pé kí òbí méjèèjì pawọ́ pọ̀ tọ́ àwọn ọmọ wọn dàgbà kí wọ́n sì jọ kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. (Òwe 31:10, 27, 28) Ọ̀dọ̀ òbí làwọn ọmọ ti máa ń kọ́ ọ̀pọ̀ ohun tí wọ́n mọ̀. Ní pàtàkì, wọ́n máa ń kọ́ àwọn ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run látinú ohun táwọn òbí ń sọ nípa Jèhófà lójoojúmọ́ àti bí wọ́n ṣe ń kíyè sí àpẹẹrẹ tí wọ́n ń fi lélẹ̀.

      ÀWỌN ÀBÁJÁDE ÀÌRÒTẸ́LẸ̀

      8, 9. (a) Kí ló sábà máa ń ṣẹlẹ̀ tí òbí kan ò bá gbé pẹ̀lú àwọn yòókù nínú ìdílé? (b) Báwo ni jíjìnnà sí ìdílé ẹni ṣe lè fa ẹ̀dùn ọkàn kó sì mú kéèyàn hùwà tí kò tọ́?

      8 Àwọn tó máa ń lọ sílẹ̀ òkèèrè máa ń ro ohun tó máa ná wọn àti ewu tó wà nínú ṣíṣe bẹ́ẹ̀ kó tó di pé wọ́n lọ. Àmọ́, kì í ṣe gbogbo wọn ló máa ń ro ibi tó máa já sí tí wọ́n bá fi ìdílé wọn sílẹ̀. (Òwe 22:3)c Kò pẹ́ tí Marilyn fi ilé sílẹ̀ tó fi bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàárò ọkọ àti ọmọ rẹ̀, tí ọkàn rẹ̀ sì ń gbọgbẹ́. Ọkọ rẹ̀ àti ọmọ rẹ̀ náà sì ń ṣàárò rẹ̀. Ńṣe ni Jimmy ọmọ rẹ̀ kékeré yìí máa ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ló dé tẹ́ ẹ fi mi sílẹ̀?” Ìwọ̀nba oṣù díẹ̀ ni Marilyn dágbére pé òun máa lò lẹ́yìn odi, ló bá di pé ọdún ń gorí ọdún. Ó wá kíyè sí i pé nǹkan ti ń yí pa dà nínú ìdílé òun. Ó kíyè sí i pé Jimmy kì í fi bẹ́ẹ̀ kọbi ara sí òun mọ́, ọkàn rẹ̀ kò sì fà sí òun mọ́ bíi ti tẹ́lẹ̀. Pẹ̀lú ìbànújẹ́ ni obìnrin yìí fi sọ pé, “Mo wa di àjèjì sí ọmọ mi gbáà.”

      9 Tí àwọn òbí àtàwọn ọmọ kò bá gbé pọ̀, ó lè fa ẹ̀dùn ọkàn, ó sì lè mú kí wọ́n hùwà tí kò tọ́.d Bí àwọn ọmọ bá ṣe kéré tó lọ́jọ́ orí nígbà táwọn òbí já wọn jù sílẹ̀, bí wọ́n bá sì ṣe pẹ́ tó tí wọ́n fi wà lọ́tọ̀ọ̀tọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìpalára tó máa ṣé á ṣe pọ̀ tó. Marilyn ṣàlàyé fún Jimmy pé torí rẹ̀ lòun ṣe ń forí ṣe fọrùn ṣe. Àmọ́ lójú Jimmy, ńṣe ló dà bíi pé màmá rẹ̀ pa á tì. Inú Jimmy kì í dùn nígbà tí màmá rẹ̀ kọ́kọ́ fi ilé sílẹ̀. Àmọ́ lẹ́yìn yẹn, tí màmá rẹ̀ bá wá bẹ ilé wò, kì í wù ú láti rí i sójú. Bó ṣe sábà máa ń rí lára irú àwọn ọmọ tí wọ́n pa tì bẹ́ẹ̀, Jimmy gbà pé màmá òun ò yẹ lẹ́ni tóun ń ṣègbọràn sí, ọkàn òun ò sì fà sí i mọ́.—Ka Òwe 29:15.

      [Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

      O kò lè gbá ọmọ rẹ mọ́ra lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì (Wo ìpínrọ̀ 10)

      10. (a) Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tí òbí bá ń fi ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí àwọn ọmọ dípò kó wà pẹ̀lú wọn? (b) Àwọn nǹkan wo ni kò ṣeé ṣe tí òbí kan bá ń tọ ọmọ rẹ̀ láti ọ̀nà jíjìn?

      10 Marilyn máa ń fi owó àtàwọn ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí ọmọ rẹ̀ láti fi rọ́pò bí kó ṣe sí pẹ̀lú rẹ̀. Àmọ́, ó wá rí i pé ńṣe lòun túbọ̀ ń sọ ara òun di àjèjì sí ọmọ òun, àti pé láìfura òun tún ń kọ́ ọ pé àwọn nǹkan tara ló ṣe pàtàkì ju àjọṣe téèyàn ní pẹ̀lú Ọlọ́run àti ìdílé. (Òwe 22:6) Jimmy tiẹ̀ máa ń sọ fún ìyá rẹ̀ pé: “Ẹ dúró sí ọ̀hún, ẹ ṣá ti máa fi ẹ̀bùn ránṣẹ́.” Marilyn wá bẹ̀rẹ̀ sí í rí i pé òun ò lè máa tọ́ ọmọ òun láti ọ̀nà jíjìn nípasẹ̀ lẹ́tà, bíbá a sọ̀rọ̀ lórí fóònù tàbí nípasẹ̀ fídíò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Ó sọ pé: “O kò lè gbá ọmọ rẹ mọ́ra tàbí kó o fi ẹnu kò ó lẹ́nu pé ó dàárọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì.”

      [Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

      Tó o bá ń gbé níbi tí ọkọ tàbí aya rẹ kò sí, ewu wo lo lè tibẹ̀ wá? (Wo ìpínrọ̀ 11)

      11. (a) Bí tọkọtaya bá ń gbé lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ torí iṣẹ́, kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí ìgbéyàwó wọn? (b) Báwo ni arábìnrin kan ṣe wá rí i pé ó máa dára kí òun pa dà sọ́dọ̀ ìdílé òun?

      11 Nígbà tó yá, àárín Marilyn àti Jèhófà kò gún mọ́, bọ́rọ̀ sì ṣe rí nípa òun àti ọkọ rẹ̀ James náà nìyẹn. Ẹ̀ẹ̀kan lọ́sẹ̀ ló kù tó ń lọ sípàdé àti òde ẹ̀rí tàbí kó má tiẹ̀ lọ nígbà míì. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló sì ní láti já ara rẹ̀ gbà lọ́wọ́ ọ̀gá rẹ̀ tó fẹ́ bá a ṣèṣekúṣe. Torí pé Marilyn àti James ò ní ẹni tí wọ́n lè fi ṣe agbọ̀ràndùn, ó di pé kí wọ́n máa fi ọ̀rọ̀ wọn lọ ẹlòmíì, wọ́n sì fẹ́rẹ̀ẹ́ bá àwọn yẹn ṣe ìṣekúṣe. Marilyn wá rí i pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé òun àti ọkọ òun ò bá àwọn míì ṣe panṣágà, bí àwọn ṣe ń gbé lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ mú kó nira fáwọn láti fi ìtọ́ni Bíbélì sílò pé káwọn máa gba ti ara àwọn rò, káwọn má sì máa fi ìbálòpọ̀ du ara àwọn. Bí wọ́n ṣe jìnnà síra wọn kì í jẹ́ kí wọ́n lè ṣe àwọn nǹkan téèyàn máa ń dédé ṣe, bíi kí wọ́n jọ ronú, kí wọ́n jọ dínjú síra wọn, kí wọ́n jọ rẹ́rìn-ín músẹ́, kí wọ́n fọwọ́ kanra, kí wọ́n dì mọ́ra, kí wọ́n ‘fìfẹ́ hàn’ síra wọn, tàbí kí wọ́n jọ gbádùn “ẹ̀tọ́” ìgbéyàwó. (Orin Sól. 1:2; 1 Kọ́r. 7:3, 5) Bẹ́ẹ̀ ni kò sí bí wọ́n ṣe lè jọ́sìn Jèhófà pa pọ̀ pẹ̀lú ọmọ wọn. Marilyn wá sọ pé: “Nígbà tí mo gbọ́ ní àpéjọ àgbègbè pé ká tó lè la ọjọ́ ńlá Jèhófà já, a gbọ́dọ̀ máa ṣe ìjọsìn ìdílé déédéé, ó yé mi pé ilé tóó lọ. Mo rí i pé ó pọn dandan kí n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàtúnṣe sí àjọṣe àárín èmi àti ìdílé mi àti àjọṣe tí mo ní pẹ̀lú Jèhófà.”

      ÌMỌ̀RÀN RERE NI WÀÁ TẸ̀ LÉ NI ÀBÍ BÚBURÚ?

      12. Ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ wo la lè fún àwọn tó ń gbé níbi tó jìn sí ìdílé wọn?

      12 Ojú ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ làwọn èèyàn fi wo ìpinnu tí Marilyn ṣe pé òun máa pa dà sílé. Àwọn alàgbà ìjọ tó ń dara pọ̀ mọ́ lókè òkun yìn ín torí ìgbàgbọ́ àti ìgboyà tó fi hàn. Àmọ́, ńṣe làwọn míì tó fi ilẹ̀ òkèèrè ṣe ilé tí wọ́n sì fi àwọn ìdílé wọn sẹ́yìn bẹnu àtẹ́ lù ú. Dípò tí wọ́n á fi tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rere rẹ̀, ṣe ni wọ́n ń rọ̀ ọ́ pé kó ṣì dúró. Wọ́n sọ fún un pé: “O máa tó pa dà wá. Báwo ni wàá ṣe máa gbọ́ bùkátà ìdílé rẹ tó o bá pa dà sílé?” Dípò tí Kristẹni kan á fi máa sọ irú ọ̀rọ̀ yìí sí Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, ńṣe ló yẹ kó “pe orí àwọn ọ̀dọ́bìnrin wálé láti nífẹ̀ẹ́ àwọn ọkọ wọn, láti nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn, láti jẹ́ . . . òṣìṣẹ́ ní ilé,” ìyẹn ní ilé tiwọn, “kí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run má bàa di èyí tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ tèébútèébú.”—Ka Títù 2:3-5.

      13, 14. Kí nìdí tó fi gba ìgbàgbọ́ kéèyàn tó fi ìfẹ́ Jèhófà ṣáájú ti ìdílé? Sọ àpẹẹrẹ kan.

      13 Ọ̀pọ̀ ló jẹ́ pé àṣà ìbílẹ̀ wọn ló mú kí wọ́n lọ máa gbé nílẹ̀ òkèèrè. Ìdí sì ni pé, àṣà ilẹ̀ wọn, ojúṣe wọn nínú ìdílé, ní pàtàkì ojúṣe wọn sí àwọn òbí ni wọ́n kà sí pàtàkì jù. Dájúdájú, ó gba ìgbàgbọ́ fún Kristẹni kan láti sọ pé ìfẹ́ Jèhófà lòun máa ṣe dípò kóun máa tẹ̀ lé àṣà tó gbòde tàbí ohun tí ìdílé òun fẹ́.

      14 Ẹ gbọ́ ohun tí Carin sọ: “Òkè òkun lèmi àti ọkọ mi ń gbé nígbà tí mo bí ọmọ wa ọkùnrin tó ń jẹ́ Don, kò sì tíì pẹ́ tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Gbogbo àwọn ará ilé wa retí pé kí n fi ọmọ mi ránṣẹ́ kí àwọn òbí mi lè bá mi tọ́jú rẹ̀ títí tí nǹkan á fi ṣẹnuure fún wa.” Nígbà tí Carin kọ̀ jálẹ̀ pé òun lòun máa tọ́jú ọmọ òun, ńṣe làwọn ẹbí rẹ̀, títí kan ọkọ rẹ̀ ń fi í ṣẹlẹ́yà, wọ́n sọ pé alápá-má-ṣiṣẹ́ ni. Òun alára sọ pé: “Ká sòótọ́, nígbà yẹn, mi ò fi bẹ́ẹ̀ rí ohun tó burú nínú kí n gbé Don ti àwọn òbí mi fún ìwọ̀nba ọdún díẹ̀. Àmọ́, mo mọ̀ pé àwa tá a jẹ́ òbí Don ni Jèhófà gbé iṣẹ́ títọ́ ọmọ wa lé lọ́wọ́.” Nígbà tí Carin lóyún ẹlẹ́ẹ̀kejì, ọkọ rẹ̀ tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ sọ pé kó ṣẹ́ oyún náà. Ìpinnu rere tí Carin ṣe nígbà tó bí àkọ́bí rẹ̀ mú kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ túbọ̀ lágbára, ó tún wá pinnu pé ìfẹ́ Jèhófà lòun máa ṣe. Ní báyìí, inú gbogbo wọn dùn pé àwọn jọ ń gbé pa pọ̀. Nǹkan míì là bá máa sọ báyìí ká ní Carin ti fi àwọn ọmọ rẹ̀ ránṣẹ́ sílé fún àwọn míì láti bá a tọ́ wọn dàgbà.

      15, 16. (a) Sọ ìrírí arábìnrin kan tí àwọn òbí rẹ̀ já sílẹ̀ ní kékeré. (b) Kí nìdí tó fi pinnu pé òun ò ní já ọmọ òun sílẹ̀ fún ẹlòmíì?

      15 Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Vicky sọ pé: “Mo gbé lọ́dọ̀ ìyá mi àgbà fún ọdún mélòó kan, ṣùgbọ́n àbúrò mi obìnrin wà lọ́dọ̀ àwọn òbí wa. Nígbà tí mo fi máa pa dà sọ́dọ̀ àwọn òbí mi, wọ́n ti dà bí àjèjì sí mi. Ará máa ń yá àbúrò mi láti sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ fún wọn, ó máa ń dì mọ́ wọn, wọ́n sì sún mọ́ra gan-an. Ara tèmi ò fi bẹ́ẹ̀ yá mọ́ wọn títí tí mo fi dàgbà, mi kì í sì í finú hàn wọ́n. Èmi àti àbúrò mi fi dá àwọn òbí wa lójú pé a máa tọ́jú wọn lọ́jọ́ ogbó wọn. Torí pé ó jẹ́ ojúṣe mi ni mo ṣe máa ṣe é, àmọ́ àbúrò mi á ṣe é torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wọn.

      16 Vicky sọ pé: “Ní báyìí, màámi sọ pé kí n mú ọmọbìnrin mi wá káwọn tọ́jú rẹ̀, bí wọ́n ṣe fi èmi náà sọ́dọ̀ màmá wọn. Mo yáa dọ́gbọ́n sọ fún wọn pé rárá. Èmi àti ọkọ mi fẹ́ láti tọ́ ọmọ tá a bí dàgbà ní ọ̀nà Jèhófà. Mi ò sì fẹ́ kí ohunkóhun ba àjọṣe èmi àti ọmọ mi jẹ́ lọ́jọ́ iwájú.” Vicky wá rí i pé ọ̀nà kan ṣoṣo téèyàn lè gbà ṣàṣeyọrí ni pé kéèyàn fi ìfẹ́ Jèhófà àtàwọn ìlànà rẹ̀ ṣáájú lílépa owó àtàwọn ohun tí ìdílé fẹ́. Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ ṣe kedere pé: “Kò sí ẹnì kan tí ó lè sìnrú fún ọ̀gá méjì,” fún Ọlọ́run àti fún Ọrọ̀.—Mát. 6:24; Ẹ́kís. 23:2.

      JÈHÓFÀ Ń MÚ KÍ ÌSAPÁ WA “YỌRÍ SÍ RERE”

      17, 18. (a) Kí ló fi hàn pé ìgbà gbogbo làwa Kristẹni lè ṣe yíyàn tó tọ́? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?

      17 Jèhófà, Baba wa ti gbà pé òun á rí i dájú pé ọwọ́ wa tẹ àwọn ohun tá a nílò lóòótọ́ tí a bá fi Ìjọba náà àti òdodo Ọlọ́run sí ipò kìíní nínú ìgbésí ayé wa. (Mát. 6:33) Látàrí èyí, ìgbà gbogbo làwa Kristẹni tòótọ́ lè yan ohun tó tọ́. Jèhófà ṣèlérí pé, ìṣòro yòówù kó lè dé, òun máa ṣe “ọ̀nà àbájáde” tí kò ní mu wa tẹ àwọn ìlànà Bíbélì lójú. (Ka 1 Kọ́ríńtì 10:13.) Tá a bá ‘fi ìyánhànhàn dúró de’ Jèhófà, tá a “gbójú lé e” nípa gbígbàdúrà pé kó fún wa ní ọgbọ́n àti ìtọ́sọ́nà, tá a sì ń pa àwọn àṣẹ àti ìlànà rẹ̀ mọ́, ó dájú pé ‘yóò gbé ìgbésẹ̀’ nítorí wa. (Sm. 37:5, 7) Ó máa dìídì bù kún wa bá a ṣe ń sapá tọkàntọkàn láti máa sìn ín, tá a sì gbà pé òun nìkan ṣoṣo ni Ọ̀gá wa tòótọ́. Tá a bá fi Jèhófà sípò àkọ́kọ́, ó máa mú kí ayé wa “yọrí sí rere.”—Fi wé Jẹ́nẹ́sísì 39:3.

      18 Bí ọkọ àti ìyàwó bá ń gbé lọ́tọ̀ọ̀tọ̀, tí ìyẹn sì ti fa ìpalára èyíkéyìí, kí ni wọ́n lè ṣe sí irú ìpalára bẹ́ẹ̀? Àwọn nǹkan pàtó wo la lè ṣe ká lè máa bójú tó ìdílé wa láìsí pé à ń gbé lọ́tọ̀ọ̀tọ̀? Báwo la sì ṣe lè rọ àwọn míì láti ṣe ìpinnu tó tọ́ lórí kókó yìí? A máa jíròrò àwọn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.

  • Jẹ́ Onígboyà—Jèhófà Ni Olùrànlọ́wọ́ Rẹ!
    Ilé Ìṣọ́—2014 | April 15
    • Jẹ́ Onígboyà—Jèhófà Ni Olùrànlọ́wọ́ Rẹ!

      ‘Jẹ́ onígboyà gidi gan-an, kí o sì sọ pé: “Jèhófà ni olùrànlọ́wọ́ mi.”’—HÉB. 13:6.

      KÍ LÈRÒ RẸ?

      • Kí làwọn òbí gbọ́dọ̀ ṣe kí ìdílé wọn bàa lè ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run?

      • Báwo làwọn olórí ìdílé ṣe lè pèsè ohun tí ìdílé wọn nílò láìjẹ́ pé wọ́n lọ sílùú míì?

      • Kí làwọn Kristẹni lè ṣe táwọn èèyàn bá ń rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n wá owó lọ sókè òkun?

      1, 2. Ìṣòro wo ni ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ṣí lọ sí ilẹ̀ òkèèrè máa ń ní nígbà tí wọ́n bá pa dà sílé? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

      ỌKÙNRIN kan tó ń jẹ́ Eduardoa sọ pé: “Nígbà tí mo wà lókè òkun, mo níṣẹ́ gidi lọ́wọ́, owó tabua sì ń wọlé fún mi. Ṣùgbọ́n, nígbà tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mo wá rí i pé mo ní ojúṣe míì tó ṣe pàtàkì ju kí n máa fowó ránṣẹ́ sílé, ìyẹn ni pé kí n wà pẹ̀lú ìdílé mi kí n sì rí i pé wọ́n ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run. Torí bẹ́ẹ̀, mo pa dà sílé.”—Éfé. 6:4.

      2 Eduardo mọ̀ pé òun mú inú Jèhófà dùn bí òun ṣe pa dà sọ́dọ̀ ìdílé òun. Àmọ́ bíi ti Marilyn tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, ó gba Eduardo náà lákòókò kó tó di pé àárín òun àti ìdílé rẹ̀ pa dà gún régé. Òun náà rí i pé kò fi bẹ́ẹ̀ rọrùn láti pèsè fún taya-tọmọ ní orílẹ̀-èdè tí nǹkan ò ti fi bẹ́ẹ̀ rọ̀ṣọ̀mù. Báwo ló ṣe máa wá gbọ́ bùkátà wọn? Ìrànlọ́wọ́ wo ló lè retí pé àwọn míì nínú ìjọ máa ṣe fún òun?

      Ó TÚN ÀJỌṢE RẸ̀ PẸ̀LÚ ỌLỌ́RUN ÀTI ÌDÍLÉ RẸ̀ ṢE

      3. Báwo ló ṣe máa ń rí lára àwọn ọmọ bí bàbá tàbí màmá wọn kò bá sí pẹ̀lú wọn?

      3 Eduardo sọ pé: “Mo gbà pé mi ò sí pẹ̀lú àwọn ọmọ mi nígbà tí wọ́n nílò mi láti máa tọ́ wọn sọ́nà kí n sì máa fìfẹ́ hàn sí wọn. Àjò ni mo wà ní gbogbo ìgbà tó yẹ kí n máa ka ìtàn Bíbélì sí wọn létí, ká jọ máa gbàdúrà, kí n máa gbá wọn mọ́ra, kí n sì máa bá wọn ṣeré.” (Diu. 6:7) Anna tó jẹ́ ọmọbìnrin rẹ̀ àgbà sọ pé: “Ńṣe ni mo dà bí ẹni tí kò ní alábàárò ní gbogbo ìgbà tí dádì wa ò fi sí nílé. Nígbà tí wọ́n pa dà dé, ńṣe ni wọ́n dà bí àjèjì sí wa. Ó sì máa ń ṣe wá bákan tí wọ́n bá gbá wa mọ́ra.”

      4. Bí ọkọ ò bá sí nílé, báwo ló ṣe lè ṣòro fún un láti ṣe ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olórí ìdílé?

      4 Àìsínílé bàbá lè mú kó ṣòro fún un láti ṣe ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olórí ìdílé. Ruby tó jẹ́ ìyàwó Eduardo sọ pé: “Ó wá di dandan pé kí n máa ṣe ojúṣe tèmi àti tọkọ mi, ó sì ti mọ́ mi lára pé kí n máa pinnu ọ̀pọ̀ nǹkan nínú ìdílé. Nígbà tí ọkọ mi pa dà dé ni mo ṣẹ̀ṣẹ̀ wá kọ́ bó ṣe yẹ kí Kristẹni aya máa fi ara rẹ̀ sábẹ́ ọkọ rẹ̀ ní ti gidi. Kódà lẹ́yìn tó ti dé, ìgbà míì wà tí mo ní láti máa rán ara mi létí pé ọkọ ní olórí aya.” (Éfé. 5:22, 23) Eduardo fi kún un pé: “Ó ti mọ́ àwọn ọmọ wa lára pé kí wọ́n máa gba àyè lọ́wọ́ ìyá wọn tí wọ́n bá fẹ́ ṣe nǹkan. A wá rí i pé gẹ́gẹ́ bí òbí, a gbọ́dọ̀ pawọ́ pọ̀ láti tọ́ àwọn ọmọ wa, èmi náà sì rí i pé ó yẹ kí n tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Kristi bí mo ṣe ń darí ìdílé mi.”

      5. Báwo ni bàbá kan ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í yanjú ìṣòro tí àìsínílé rẹ̀ dá sílẹ̀? Kí ni àbájáde ohun tó ṣe?

      5 Eduardo pinnu pé òun máa sa gbogbo ipá òun kí àjọṣe ìdílé òun lè pa dà gún régé, kí àwọn sì túbọ̀ ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Ọlọ́run. Ó sọ pé: “Ohun tó wà lọ́kàn mi ni pé kí n gbin òtítọ́ sọ́kàn àwọn ọmọ mi, lọ́rọ̀ àti níṣe. Kì í ṣe kí n wulẹ̀ sọ pé mo nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, mo fẹ́ fi hàn pé òótọ́ ni mo nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.” (1 Jòh. 3:18) Ǹjẹ́ Jèhófà bù kún ohun tó fi ìgbàgbọ́ hàn tí Eduardo ṣe yìí? Ọmọ rẹ̀ tó ń jẹ́ Anna sọ pé: “Bá a ṣe rí i tí dádì ń sapá láti jẹ́ bàbá rere tí wọ́n sì tún ń sún mọ́ wa jẹ́ ká rí i pé ìyàtọ̀ ńláǹlà ti wà. Ìwúrí ló sì jẹ́ fún wa bí wọ́n ṣe ń ṣe ohun táá jẹ́ kí wọ́n lè máa sìn nínú ìjọ. Ayé yìí fẹ́ mú ká jìnnà sí Jèhófà. Àmọ́, a rí i pé àwọn òbí wa pọkàn pọ̀ sórí òtítọ́, àwa náà sì ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn. Dádì ṣèlérí fún wa pé àwọn ò ní já wa jù sílẹ̀ mọ́, wọ́n sì mú ìlérí wọn ṣẹ. Bóyá ni màá wà nínú ètò Jèhófà lónìí ká sọ pé wọ́n tún pa dà lọ ni.”

      Ẹ MÁA ṢE OJÚṢE YÍN

      6. Ẹ̀kọ́ wo làwọn òbí kan kọ́ lásìkò tí ogun jà nílẹ̀ wọn?

      6 Àwọn ìrírí kan tá a gbọ́ fi hàn pé nígbà tí ogun jà láwọn àgbègbè Balkan, inú àwọn ọmọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà níbẹ̀ máa ń dùn bó tilẹ̀ jẹ́ pé ipò àwọn nǹkan nira fún wọn. Kí nìdí? Ìdí ni pé, ogun náà kò jẹ́ kí àwọn òbí wọn lè lọ síbi iṣẹ́. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n ń ráyè kọ́ àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́, wọ́n ń bá wọn ṣeré, wọ́n sì ń bá wọn sọ̀rọ̀. Kí nìyẹn kọ́ wa? Ó kọ́ wa pé yàtọ̀ sí owó tàbí ẹ̀bùn, ohun táwọn ọmọ nílò jù lọ ni pé kí ẹ̀yin òbí máa wà pẹ̀lú wọn. Ká sòótọ́, bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe sọ ọ́ náà ló rí, ó máa ṣe àwọn ọmọ yín láǹfààní gan-an tí ẹ̀yin òbí bá ń wáyè gbọ́ tiwọn, tẹ́ ẹ sì ń kọ́ wọn.—Òwe 22:6.

      7, 8. (a) Àṣìṣe wo làwọn òbí kan tó pa dà sílé máa ń ṣe? (b) Báwo làwọn òbí ṣe lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti borí èrò òdì?

      7 Nígbà tí àwọn òbí kan pa dà délé, ohun tí wọ́n retí kọ́ ni wọ́n bá. Ńṣe làwọn ọmọ kójú kúrò nílẹ̀, wọn ò sì náání ohun tí òbí yẹn ń ṣe. Irú àwọn òbí bẹ́ẹ̀ á fa ìbínú yọ, wọ́n á sì sọ pé, “Ẹyin ọmọ yìí ṣe ya aláìmoore báyìí, tẹ́ ẹ sì mọ̀ pé torí yín ni mo ṣe forí jágbó lọ?” Àmọ́, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé torí bí àwọn òbí wọn ṣe fi wọ́n sílẹ̀ ló fà á tí àwọn ọmọ náà fi hùwà bẹ́ẹ̀. Torí náà, kí ni òbí kan lè ṣe láti fa ojú àwọn ọmọ rẹ̀ mọ́ra?

      8 Bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa fi sùúrù bá ìdílé rẹ lò. Tó o bá sì ń bá ìdílé rẹ sọ̀rọ̀, jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ìwọ náà jẹ nínú ẹ̀bi ọ̀rọ̀ tó wà nílẹ̀ yìí, kó o sì gba ẹ̀bi rẹ lẹ́bi. Ọkàn wọn lè rọ̀ tó o bá tọrọ àforíjì látọkànwá lọ́wọ́ wọn. Bí ìyàwó àtàwọn ọmọ rẹ bá ṣe ń kíyè sí i pé gbogbo ìgbà lò ń wá bí nǹkan ṣe máa pa dà gún régé, wọ́n máa gbà pé kì í ṣe ojú ayé lò ń ṣe. Tó o bá sa gbogbo ipá rẹ tó o sì mú sùúrù, aya rẹ àtàwọn ọmọ rẹ lè wá bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ rẹ kí wọ́n sì máa bọ̀wọ̀ fún ọ.

      ‘MÁA PÈSÈ FÚN ÀWỌN TÌRẸ’

      9. Kí nìdí tí pípèsè fún ìdílé ẹni ò fi dandan túmọ̀ sí pé kéèyàn máa forí ṣe fọrùn ṣe kó lè ní àníkún nǹkan tara?

      9 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé tó bá di pé àwọn Kristẹni tó ti dàgbà kò lè bójú tó ara wọn mọ́, kí àwọn ọmọ àtàwọn ọmọ ọmọ “san àsanfidípò yíyẹ fún àwọn òbí wọn àti àwọn òbí wọn àgbà.” Àmọ́ Pọ́ọ̀lù tún rọ gbogbo Kristẹni pé kí wọ́n jẹ́ kí àwọn nǹkan kòṣeémánìí ojoojúmọ́, bí oúnjẹ, aṣọ àti ilé, tẹ́ wọn lọ́rùn. Kò sídìí láti máa forí ṣe fọrùn ṣe torí ká lè máa gbé ìgbé ayé yọ̀tọ̀mì tàbí ká lè kó ọrọ̀ jọ torí ọjọ́ iwájú. (Ka 1 Tímótì 5:4, 8; 6:6-10.) Kò pọn dandan pé kí Kristẹni kan máa lépa ọrọ̀ nínú ayé tó máa tó kọjá lọ yìí torí kó lè “pèsè fún àwọn tí í ṣe tirẹ̀.” (1 Jòh. 2:15-17) A kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí “agbára ìtannijẹ ọrọ̀” tàbí “àníyàn ìgbésí ayé” mú kí ìdílé wa dẹwọ́ nínú dídi “ìyè tòótọ́” nínú ayé tuntun òdodo Ọlọ́run “mú gírígírí”!—Máàkù 4:19; Lúùkù 21:34-36; 1 Tím. 6:19.

      10. Báwo ni ọgbọ́n Ọlọ́run ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ ká má bàa tọrùn bọ gbèsè?

      10 Jèhófà mọ̀ pé a nílò owó díẹ̀. Àmọ́, ọgbọ́n Ọlọ́run ló lè dáàbò bò wá kó sì dá ẹ̀mí wa sí, kì í ṣe owó. (Oníw. 7:12; Lúùkù 12:15) Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn tó ń lọ sókè òkun máa ń fojú kéré owó tó ń ná wọn, kò sì dájú pé wọ́n máa rí towó ṣe níbẹ̀. Kódà, ńṣe ló dà bí ìgbà téèyàn rí oko ní oko ikún, tó wá lọ gbin ẹ̀pà sí i. Gbèsè tó wà nílẹ̀ fún ọ̀pọ̀ lára wọn kí wọ́n tó lọ sókè òkun kò tó èyí tó bá wọn wálé. Kàkà kí wọ́n túbọ̀ ní òmìnira láti máa sin Ọlọ́run, ńṣe ni wọ́n di ẹrú fún àwọn tó yá wọn lówó. (Ka Òwe 22:7.) Ohun tó ti bọ́gbọ́n mu ni pé kéèyàn má tiẹ̀ tọrùn bọ gbèsè rárá.

      11. Bí ìdílé bá ń tẹ̀ lé ètò tí wọ́n ṣe láti máa náwó, báwo ni kò ṣe ní jẹ́ kí wọ́n wọko gbèsè?

      11 Eduardo mọ̀ pé tóun bá máa dúró lórí ìpinnu tóun ṣe pé òun ò ní fi ìdílé òun sílẹ̀ mọ́, òun gbọ́dọ̀ mọ béèyàn ṣe ń ṣọ́wó ná. Òun àti ìyàwó rẹ̀ gbé ìṣirò lé àwọn nǹkan tí wọ́n nílò, ìyẹn ni wọ́n sì lò láti ṣètò bí wọ́n á ṣe máa náwó. Ohun kan ni pé ètò ìṣúnná owó tí wọ́n ṣe kò fún wọn láyè láti máa náwó bí wọ́n ti máa ń ṣe tẹ́lẹ̀. Àmọ́ gbogbo wọn fọwọ́ sowọ́ pọ̀, wọn ò sì ra àwọn ohun tí kò pọn dandan.b Eduardo sọ pé: “Bí àpẹẹrẹ, mo mú àwọn ọmọ wa kúrò nílé ẹ̀kọ́ àdáni, mo sì fi wọ́n sílé ẹ̀kọ́ ìjọba tí wọ́n ti ń kọ́mọ níwèé dáadáa.” Òun àti ìdílé rẹ̀ gbàdúrà pé kí Ọlọ́run jẹ́ kí òun rí iṣẹ́ tí kò ní dí òun lọ́wọ́ àwọn ìgbòkègbodò tó jẹ mọ́ ìjọsìn Jèhófà. Báwo ni Jèhófà ṣe dáhùn àdúrà wọn?

      12, 13. Àwọn ohun tó bọ́gbọ́n mu wo ni bàbá kan ṣe kó lè máa pèsè fún ìdílé rẹ̀? Báwo ni Jèhófà ṣe bù kún ìpinnu tí bàbá náà ṣe pé òun á máa jẹ́ kí ìwọ̀nba ohun ìní tara tẹ́ òun lọ́rùn?

      12 Eduardo rántí pé: “Láàárín ọdún méjì ti mo pa dà dé, nǹkan kò fi bẹ́ẹ̀ rọgbọ. Owó tí mo ní lọ́wọ́ ti ń tán lọ, owó oṣù mi kò tó gbọ́ bùkátà, ó sì máa ń rẹ̀ mí gan-an. Àmọ́, a máa ń lọ sí gbogbo ìpàdé, a sì máa ń jáde òde ẹ̀rí.” Eduardo tún pinnu pé òun ò ní ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí tó bá máa mú kóun fi ìdílé òun sílẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù tàbí ọdún. Ó wá sọ pé: “Kàkà bẹ́ẹ̀, mo kọ́ onírúurú iṣẹ́ tó fi jẹ́ pé bí ìkan kò bá ṣe, òmíì á ṣe.”

      [Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

      Ṣé o lè kọ́ onírúurú iṣẹ́ tí wàá lè máa fi gbọ́ bùkátà ìdílé rẹ? (Wo ìpínrọ̀ 12)

      13 Torí pé díẹ̀díẹ̀ ni Eduardo ní láti máa san àwọn gbèsè tó jẹ, èlé tó ní láti san lórí owó tó yá náà pọ̀ ju ojú owó lọ. Àmọ́, ó gbà pé ìyẹn ò tó nǹkan bí òun bá ṣáà ti wà pẹ̀lú ìdílé òun tí àwọn sì jọ ń lọ́wọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò wọn, ó ṣe tán, ohun tí Jèhófà fẹ́ káwọn òbí máa ṣe nìyẹn. Eduardo sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé owó tí mò ń rí báyìí kò ju ìdá kan nínú mẹ́wàá èyí tí mò ń rí ní òkè òkun, síbẹ̀ ebi ò pa wá. ‘Ọwọ́ Jèhófà kò kúrú.’ Kódà, a tún gba iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ pé nígbà tó yá, ọ̀rọ̀ ìṣúnná owó rọjú, ó sì wá túbọ̀ rọrùn fún wa láti máa gbọ́ bùkátà wa.”—Aísá. 59:1.

      BÁ Ò ṢE NÍ JẸ́ KÍ ÌDÍLÉ MÚ WA ṢE OHUN TÍ KÒ TỌ́

      14, 15. Báwo làwọn ìdílé ò ṣe ní jẹ́ káwọn míì mú kí wọ́n pa àwọn nǹkan tẹ̀mí tì torí àtimáa lépa àwọn nǹkan tara? Kí ló lè ṣẹlẹ̀ táwọn ìdílé bá fi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀?

      14 Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, àwọn èèyàn gbà pé ojúṣe àwọn ni pé káwọn máa fún àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ ní owó àti ẹ̀bùn. Eduardo sọ pé: “Bó ṣe rí nínú àṣà wa nìyẹn, ó sì máa ń dùn mọ́ wa láti fáwọn èèyàn ní nǹkan.” Ó wá fi kún un pé: “Àmọ́, ó níbi tó mọ o. Mo fọgbọ́n sọ fún àwọn ẹbí mi pé màá máa fún wọn ní nǹkan tí agbára mi bá gbé láìjẹ́ kó dí ìjọsìn àtàwọn ìgbòkègbodò ìdílé mi lọ́wọ́.”

      15 Ohun tí ojú àwọn tó pa dà sílé láti ilẹ̀ òkèèrè àtàwọn tí kò gbà láti lọ rárá ń rí kì í ṣe kékeré. Ìjákulẹ̀ ló máa ń jẹ́ fún àwọn ẹbí tó ń retí pé wọ́n á máa ti òkè òkun gbọ́ bùkátà ìdílé, torí bẹ́ẹ̀, wọ́n máa ń bínú sí wọn, wọ́n sì máa ń fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́. Àwọn kan tiẹ̀ kà wọ́n sí ọ̀dájú. (Òwe 19:6, 7) Àmọ́, Anna, ìyẹn ọmọ Arákùnrin Eduardo sọ pé: “Tá ò bá pa àwọn nǹkan tẹ̀mí tì torí àtimáa lépa àwọn nǹkan tara, bópẹ́ bóyá, a lè rí lára àwọn ẹbí wa tí wọ́n á rí i pé ọwọ́ pàtàkì la fi mú ojúṣe wa gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni. Ṣùgbọ́n báwo ni wọ́n ṣe máa mọ̀ tá a bá ṣe ohun tí wọ́n fẹ́?”—Fi wé 1 Pétérù 3:1, 2.

      BÓ O ṢE LÈ LO ÌGBÀGBỌ́ NÍNÚ ỌLỌ́RUN

      16. (a) Báwo ni ẹnì kan ṣe lè fi ‘èrò èké tan ara rẹ̀ jẹ’? (Ják. 1:22) (b) Irú ìpinnu wo ni Jèhófà máa ń bù kún?

      16 Arábìnrin kan fi ọkọ àtàwọn ọmọ rẹ̀ sílé ó sì dá lọ sí orílẹ̀-èdè kan tí nǹkan ti rọ̀ṣọ̀mù. Nígbà tó débẹ̀, ó sọ fún àwọn alàgbà pé: “Ọ̀pọ̀ nǹkan la yááfì kí n lè wá síbí. Kódà ọkọ mi fi ipò alàgbà sílẹ̀. Torí náà, ó dá mi lójú pé Jèhófà máa bù kún wíwá tí mo wá síbí.” Òótọ́ ni pé Jèhófà máa ń bù kún àwọn ìpinnu tó bá fi hàn pé a nígbàgbọ́ nínú rẹ̀, àmọ́ báwo ló ṣe lè bù kún ìpinnu tó ta ko ìfẹ́ rẹ̀, pàápàá tírú ìpinnu bẹ́ẹ̀ bá mú kéèyàn pa àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tì láìnídìí kan tó ṣe gúnmọ́?—Ka Hébérù 11:6; 1 Jòhánù 5:13-15.

      17. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa wá ìtọ́sọ́nà Jèhófà ká tó ṣe ìpinnu? Báwo la ṣe lè wá ìtọ́sọ́nà rẹ̀?

      17 Máa wá ìtọ́sọ́nà Jèhófà kó o tó ṣe ìpinnu tàbí àdéhùn èyíkéyìí, kì í ṣe lẹ́yìn tó o bá ti ṣe é tán. Gbàdúrà pé kó tọ́ ẹ sọ́nà, pé kó fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ àti ọgbọ́n. (2 Tím. 1:7) Bi ara rẹ pé: ‘Lábẹ́ àwọn ipò wo ló ti máa ń wù mí pé kí n ṣègbọràn sí Jèhófà? Tí mo bá kojú inúnibíni ńkọ́?’ Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ṣé wàá ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́ tó bá tiẹ̀ gba pé kó o jẹ́ kí ìwọ̀nba ohun ìní tara tẹ́ ọ lọ́rùn? (Lúùkù 14:33) Ní kí àwọn alàgbà gbà ọ́ nímọ̀ràn látinú Ìwé Mímọ́, kó o sì fi hàn pé o nígbàgbọ́ nínú ìlérí Jèhófà àti pé o fọkàn tán an nípa fífi ìmọ̀ràn rẹ̀ sílò. Àwọn alàgbà ò ní bá ẹ ṣèpinnu, àmọ́ wọ́n lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè ṣe yíyàn táá mú kó o láyọ̀ nígbẹ̀yìngbẹ́yín.—2 Kọ́r. 1:24.

      18. Ta ló yẹ kó máa bójú tó ìdílé? Àwọn nǹkan wo ló lè mú kí àwọn míì ṣèrànwọ́?

      18 Ìkáwọ́ olórí ìdílé ni Jèhófà fi gbígbé “ẹrù” ìdílé rẹ̀ láti ọjọ́ dé ọjọ́ sí. Ó yẹ ká máa yin àwọn tó dúró ti ìdílé wọn tí wọ́n sì bójú tó wọn ká sì tún máa fi wọ́n sádùúrà. Ìdí ni pé wọ́n kọ̀ láti fi aya tàbí àwọn ọmọ wọn sílẹ̀ bó tilẹ̀ jẹ́ pé ipò nǹkan le àti pé àwọn èèyàn ń rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn ìṣòro téèyàn ò rò tẹ́lẹ̀ bí ìjábá tàbí ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì, lè mú ká rí ìdí tó fi yẹ ká fi ojúlówó ìfẹ́ ará àti ìgbatẹnirò hàn fún àwọn ará wa. (Gál. 6:2, 5; 1 Pét. 3:8) Ǹjẹ́ o lè fún wọn lówó nírú àsìkò pàjáwìrì bẹ́ẹ̀, tàbí kẹ̀ bóyá o lè wá iṣẹ́ fún arákùnrin rẹ ní àgbègbè ibi tẹ́ ẹ̀ ń gbé? Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, kò ní sídìí fún arákùnrin náà láti fi ìdílé rẹ̀ sílẹ̀ torí pé ó ń wáṣẹ́ lọ sílẹ̀ míì.—Òwe 3:27, 28; 1 Jòh. 3:17.

      RÁNTÍ PÉ JÈHÓFÀ NI OLÙRÀNLỌ́WỌ́ RẸ!

      19, 20. Kí nìdí tó fi yẹ kí ọkàn àwọn Kristẹni balẹ̀ pé Jèhófà máa ran àwọn lọ́wọ́?

      19 Ìwé Mímọ́ rọ̀ wá pé: “Kí ọ̀nà ìgbésí ayé yín wà láìsí ìfẹ́ owó, bí ẹ ti ń ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú àwọn nǹkan ìsinsìnyí. Nítorí [Ọlọ́run] ti wí pé: ‘Dájúdájú, èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà.’ Kí a lè jẹ́ onígboyà gidi gan-an, kí a sì sọ pé: ‘Jèhófà ni olùrànlọ́wọ́ mi; èmi kì yóò fòyà. Kí ni ènìyàn lè fi mí ṣe?’” (Héb. 13:5, 6) Báwo lọ̀rọ̀ yìí ṣe jóòótọ́ sí?

      20 Alàgbà kan tó ti ń sìn tipẹ́ ní orílẹ̀-èdè kan tí nǹkan kò ti fi bẹ́ẹ̀ rọ̀ṣọ̀mù sọ pé: “Àwọn èèyàn sábà máa ń sọ pé ńṣe ni inú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń dùn ṣáá. Wọ́n tún máa ń kíyè sí i pé ìgbà gbogbo ni àwọn ará wa tí kò rí já jẹ pàápàá máa ń múra dáadáa, ó sì dà bíi pé nǹkan ṣẹnuure fún wọn ju àwọn míì lọ.” Èyí bá ìlérí tí Jésù ṣe fún àwọn tó bá fi ire Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́ mu. (Mát. 6:28-30, 33) Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé, Jèhófà Baba rẹ ọ̀run nífẹ̀ẹ́ rẹ kò sì fẹ́ kí láburú kankan ṣẹlẹ̀ sí ìwọ àtàwọn ọmọ rẹ. Bíbélì sọ pé: “Ojú [Jèhófà] ń lọ káàkiri ní gbogbo ilẹ̀ ayé láti fi okun rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí ọkàn-àyà wọn pé pérépéré síhà ọ̀dọ̀ rẹ̀.” (2 Kíró. 16:9) Ó ti fún wa ní àwọn òfin rẹ̀, títí kan àwọn tó dá lórí ọ̀rọ̀ ìdílé àtàwọn ohun tá a nílò nípa tara. Àwọn òfin rẹ̀ sì ń ṣe wá láǹfààní. Tá a bá pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́, à ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ a sì fọkàn tán an. Ó ṣe tán, Bíbélì sọ pé: “Èyí ni ohun tí ìfẹ́ fún Ọlọ́run túmọ̀ sí, pé kí a pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́; síbẹ̀ àwọn àṣẹ rẹ̀ kì í ṣe ẹrù ìnira.”—1 Jòh. 5:3.

      21, 22. Kí nìdí tó o fi pinnu pé wàá máa fọkàn tán Jèhófà?

      21 Eduardo sọ pé: “Mo mọ̀ pé mi ò lè san àkókò tí mi ò fi wà pẹ̀lú ìyàwó àtàwọn ọmọ mi pa dà, àmọ́ mi ò kábàámọ̀ pé mo pa dà wálé. Ọ̀pọ̀ àwọn tá a jọ lọ ti dolówó rẹpẹtẹ, àmọ́ wọn ò láyọ̀. Ńṣe ni ìṣòro ń ṣubú lu ìṣòro nínú ìdílé wọn. Àmọ́ ní tiwa, ìdílé wa ń láyọ̀ ṣáá ni! Orí mi sì máa ń wú tí mo bá ń rí bí àwọn ará wa tó wà lórílẹ̀-èdè yìí ṣe ń fi nǹkan tẹ̀mí sípò àkọ́kọ́, bí wọn ò tiẹ̀ rí já jẹ. Gbogbo wa pátá là ń jadùn ohun tí Jésù ṣèlérí.”—Ka Mátíù 6:33.

      22 Jẹ́ onígboyà! Pinnu pé wàá ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́, kó o sì fọkàn tán an. Jẹ́ kí ìfẹ́ tó o ní fún Ọlọ́run, ìyàwó tàbí ọkọ rẹ àtàwọn ọmọ rẹ mú kó o ṣe ojúṣe rẹ, ìyẹn láti mú kí ìdílé rẹ ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá rí i pé ‘Jèhófà ni olùrànlọ́wọ́ rẹ’ ní tòótọ́.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́