ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • yp1 orí 25 ojú ìwé 178-182
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Jáwọ́ Nínú Fífọwọ́ Pa Ẹ̀yà Ìbímọ Mi?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Jáwọ́ Nínú Fífọwọ́ Pa Ẹ̀yà Ìbímọ Mi?
  • Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tó O Lè Ṣe Bí Ọkàn Rẹ Bá Ń Dá Ẹ Lẹ́bi
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Jáwọ́ Nínú Àṣà Búburú Yìí?
    Jí!—2007
  • Jáwọ́ Nínú Fífọwọ́ Pa Ẹ̀yà Ìbímọ Rẹ
    ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Gbọ́kàn Mi Kúrò Lórí Ìbálòpọ̀?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
  • Bá A Ṣe Lè Jẹ́ Mímọ́ Lójú Ọlọ́run
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
Àwọn Míì
Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní
yp1 orí 25 ojú ìwé 178-182

ORÍ 25

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Jáwọ́ Nínú Fífọwọ́ Pa Ẹ̀yà Ìbímọ Mi?

“Ọmọ ọdún mẹ́jọ ni mí tí mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í fi ọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ mi. Ìgbà tí mo wá mọ ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ọ̀ràn náà, inú mi kì í dùn ní gbogbo ìgbà tí mo bá tún ṣe bẹ́ẹ̀. Mo máa ń bi ara mi pé, ‘Ṣé inú Ọlọ́run á sì máa dùn sírú èmi yìí?’”​—Luiz.

TÉÈYÀN bá ti ń bàlágà, ọkàn rẹ̀ á túbọ̀ máa fà sí ìbálòpọ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, ó lè wá dẹni tó ń fọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ rẹ̀.a Ọ̀pọ̀ èèyàn lè sọ fún ẹ pé ìyẹn kì í ṣe ìṣòro. Wọ́n lè sọ pé, “kò ṣáà pa ẹnikẹ́ni lára.” Àmọ́, ìdí púpọ̀ ló wà tó fi yẹ kó o yẹra fún irú àṣà bẹ́ẹ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Nítorí náà, ẹ sọ àwọn ẹ̀yà ara yín . . . di òkú ní ti . . . ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ takọtabo.” (Kólósè 3:5) Fífi ọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ ẹni kì í mú kéèyàn sọ ẹ̀yà ara ẹni di òkú, ṣe ló máa ń mára dìde. Láfikún sí i, ronú lórí àwọn ohun tá a sọ sísàlẹ̀ yìí:

● Fífi ọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ ẹni máa ń mú kéèyàn di onímọtara-ẹni-nìkan. Bí àpẹẹrẹ, bí ẹnì kan bá ń fọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ ara ẹ̀, bó ṣe máa tẹ́ ara rẹ̀ nìkan lọ́rùn ló máa gbà á lọ́kàn.

● Fífi ọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ ẹni máa ń mú kẹ́ni tó ń ṣe bẹ́ẹ̀ máa wo ọkùnrin (tàbí obìnrin) bí ohun tí òun kàn lè lò láti tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara òun lọ́rùn.

● Ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan tí àṣà yìí máa ń mú kẹ́ni tó ń ṣe bẹ́ẹ̀ ní kì í jẹ́ kó lè gbádùn ìbálòpọ̀ tó máa ń wáyé láàárín lọ́kọláya.

Dípò tí wàá fi máa fọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ rẹ torí àtimú kí ara rẹ tó wà lọ́nà wálẹ̀, ṣe ni kó o máa kó ara rẹ níjàánu. (1 Tẹsalóníkà 4:4, 5) Bíbélì sọ bó o ṣe lè máa kó ara rẹ níjàánu, ó ní ohun tó ti dára jù ni pé kó o máa yẹra fún àwọn ipò tó lè jẹ́ kí ara rẹ dìde. (Òwe 5:8, 9) Síbẹ̀, kí lo lè ṣe tó bá jẹ́ pé fífọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ ẹ ti wọ̀ ẹ́ lẹ́wù? Bóyá o ti gbìyànjú pé kó o ṣíwọ́ àmọ́ pàbó ló ń já sí. Ó rọrùn láti rò pé kò sí bó o ṣe lè jáwọ́, pé kò lè ṣeé ṣe fún ẹ láti pa gbogbo ìlànà Ọlọ́run mọ́. Ohun tí ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Pedro rò gẹ́lẹ́ nìyẹn. Ó ní: “Ṣe ni ìbànújẹ́ máa ń bá mi ní gbogbo ìgbà tí mo bá tún ti fọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ mi. Mo máa ń rò pé kò sí ohun tí mo lè ṣe tí Ọlọ́run á fi dárí jì mí. Àtigbàdúrà gan-an wá dogun fún mi.”

Tó bá jẹ́ pé bó ṣe ń ṣe ẹ́ nìyẹn, fọkàn balẹ̀. Ohun tó o ń ṣe ẹ́ kò tíì kọjá àtúnṣe! Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́, tó fi mọ́ àwọn àgbàlagbà pàápàá, ni wọ́n ti jáwọ́ nínú àṣà fífi ọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ wọn. Ó dájú pé ìwọ náà lè jáwọ́!

Ohun Tó O Lè Ṣe Bí Ọkàn Rẹ Bá Ń Dá Ẹ Lẹ́bi

Bá a ṣe sọ ṣáájú, ọkàn àwọn tó máa ń fi ọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ wọn sábà máa ń dá wọn lẹ́bi. Ó dájú pé, bí àṣà yìí bá ń mú ẹ ‘banú jẹ́ lọ́nà ti Ọlọ́run,’ wàá lè sa gbogbo ipá rẹ láti borí rẹ̀. (2 Kọ́ríńtì 7:11) Ṣùgbọ́n ìbànújẹ́ náà kò gbọ́dọ̀ pọ̀ ju bó ṣe yẹ lọ kó má bàa ṣàkóbá fún ẹ. Àkóbá tó lè ṣe ni pé ó lè kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ẹ débi tó o fi ní fẹ́ gbìyànjú láti borí ẹ̀ mọ́.​—Òwe 24:10.

Nítorí náà, ṣe ni kó o gbìyànjú láti mọ bí ohun tó ń ṣe ẹ́ yìí ṣe jẹ́ gan-an. Ìwà àìmọ́ ni fífọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ ẹni jẹ́. Ó lè sọ ẹ́ ‘dẹrú fún oríṣiríṣi ìfẹ́ ọkàn àti adùn,’ ó sì lè mú kéèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í lọ́wọ́ sí àwọn ìwà tó lè sọ ìrònú ẹni dìdàkudà. (Títù 3:3) Àmọ́, fífọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ kì í ṣe ọ̀kan lára ẹ̀ṣẹ̀ ìbálòpọ̀ tó burú jáì bí àgbèrè. (Júúdà 7) Ìdí nìyí tó fi jẹ́ pé bí fífọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ bá ti di ìṣòro fún ẹ, kò sídìí fún ẹ láti máa rò pé o ti dẹ́ṣẹ̀ tí kò ní ìdáríjì. Àṣírí ibẹ̀ ni pé kó o má gbà fún un tó bá ti ń wù ẹ́ ṣe, kó o má sì ṣe juwọ́ sílẹ̀!

Láwọn ìgbà míì, ó rọrùn láti kárí sọ lẹ́yìn téèyàn bá tún ṣe é. Nígbà tíyẹn bá wáyé, má ṣe gbàgbé ọ̀rọ̀ tó wà nínú Òwe 24:16, tó sọ pé: “Olódodo lè ṣubú ní ìgbà méje pàápàá, yóò sì dìde dájúdájú; ṣùgbọ́n àwọn ẹni burúkú ni a óò mú kọsẹ̀ nípasẹ̀ ìyọnu àjálù.” Torí pé o pa dà tún ṣe é kò túmọ̀ sí pé o ti dèèyàn burúkú. Má ṣe jẹ́ kó sú ẹ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni kó o fẹ̀sọ̀ ronú lé ohun tó mú kó o tún pa dà sídìí ẹ̀, kó o sì gbìyànjú láti rí i pé o ò tún ṣe nǹkan yẹn mọ́.

Máa wáyè láti ṣàṣàrò nípa ìfẹ́ àti àánú Ọlọ́run. Dáfídì tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ ìwé Sáàmù, tóun náà ti ṣàṣìṣe rí, sọ pé: “Bí baba ti ń fi àánú hàn sí àwọn ọmọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà ń fi àánú hàn sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀. Nítorí tí òun fúnra rẹ̀ mọ ẹ̀dá wa, Ó rántí pé ekuru ni wá.” (Sáàmù 103:13, 14) Ó dájú pé Jèhófà máa ń ro ti àìpé wa mọ́ wa lára, ó sì “ṣe tán láti dárí jini” nígbà tá a bá ṣẹ̀. (Sáàmù 86:5) Síbẹ̀, ó fẹ́ ká sapá láti ṣàtúnṣe. Torí náà, àwọn nǹkan wo ló yẹ kó o ṣe kó o lè gba ara rẹ lọ́wọ́ àṣà yìí, kó o má sì tún ṣe é mọ́?

Ronú lórí àwọn ohun tó o fi ń najú. Ṣé o máa ń wo àwọn ohun tó ń mú ọkàn èèyàn fà sí ìṣekúṣe nínú fíìmù tàbí lórí tẹlifíṣọ̀n tàbí nínú Íńtánẹ́ẹ̀tì? Ọ̀kan lára àwọn tó kọ ìwé Sáàmù gbàdúrà sí Ọlọ́run pé: “Mú kí ojú mi kọjá lọ láìrí ohun tí kò ní láárí.”b​—Sáàmù 119:37.

Darí ọkàn rẹ síbòmíràn. Ìmọ̀ràn Kristẹni kan tó ń jẹ́ William ni pé: “Kó o tó lọ sùn, ka àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run. Ó ṣe pàtàkì pé kí ohun tí wàá máa rò lọ́kàn kó tó di pé o lọ sùn jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run.”​—Fílípì 4:8.

Sọ ìṣòrò tó o ní yìí fún ẹnì kan. Ìtìjú lè mú kó nira fún ẹ láti sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ fún ẹni tó yẹ kó o finú hàn. Síbẹ̀, sísọ tó o bá sọ ọ́ lè jẹ́ kó o borí àṣà burúkú náà! Ohun tó ran Kristẹni kan tó ń jẹ́ David lọ́wọ́ gan-an nìyẹn. Ó sọ pé: “Mo sọ fún dádì mi ní ìdákọ́ńkọ́. Mi ò jẹ́ gbàgbé ohun tí wọ́n sọ láé. Pẹ̀lú ẹ̀rín músẹ́ lẹ́nu wọn, tó mú kí ọkàn mi balẹ̀, wọ́n wí pé, ‘Bó o ṣe wá sọ fún mi yìí mú inú mi dùn sí ẹ gan-an.’ Wọ́n mọ̀ pé kò rọrùn fún mi rárá kí n tó lè sọ ohun tí mo sọ fún wọn. Ohun tí dádì mi sọ yẹn mú kí orí mi yá gágá, ó sì jẹ́ kí n túbọ̀ fẹ́ láti borí àṣà burúkú náà.

“Dádì mi wá fi àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ mélòó kan hàn mí láti jẹ́ kí n mọ̀ pé ‘ọ̀rọ̀ mi ò tíì kọjá àtúnṣe,’ wọ́n sì tún lo àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ míì láti jẹ́ kí n túbọ̀ mọ bí ohun tí mò ń ṣe yẹn ṣe burú tó. Wọ́n wá sọ fún mi pé kí n ṣì túbọ̀ gbìyànjú láti rí i pé mo ṣe àtúnṣe ná, tó bá wá yá àwọn máa fẹ́ ká tún sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. Wọ́n sọ pé kí n má ṣe jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì bá mi tó bá di pé mo tún pa dà fọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ mi, kí n ṣáà rí i pé mò ń borí ẹ̀ díẹ̀díẹ̀ títí màá fi jáwọ́ nínú rẹ̀.” Kí ni David wá sọ? Ó sọ pé: “Kì í ṣe àǹfààní kékeré ni mo ní pé mo lẹ́nì kan tó mọ ìṣòrò mi tó sì ń ràn mí lọ́wọ́.”c

NÍNÚ ORÍ TÓ KÀN

Káwọn èèyàn máa gbé ara wọn sùn kì í ṣe ọ̀ràn kékeré rára. Kà nípa rẹ̀ fúnra rẹ.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fífi ọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ ẹni yàtọ̀ sí ìgbà tí ara ẹni bá dìde, bí ẹni tí ara ẹ̀ wà lọ́nà láti ní ìbálòpọ̀. Bí àpẹẹrẹ, ọmọkùnrin kan lè jí lójú oorun kó wá rí i pé ẹ̀yà ìbímọ òun dìde tàbí pé àtọ̀ ti jáde lára òun nígbà tóun ṣì ń sùn. Bákan náà, àwọn ọmọbìnrin míì kàn lè rí i pé ara àwọn wà lọ́nà láti ní ìbálòpọ̀ láìjẹ́ pé àwọn ni wọ́n fà á, pàápàá tó bá kù díẹ̀ kí wọ́n ṣe nǹkan oṣù tàbí gbàrà tí wọ́n ṣe é tán. Fífi ọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ ẹni yàtọ̀ pátápátá sí èyí, ṣe ni ẹni tó ń fọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ rẹ̀ ń mọ̀ọ́mọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ kí ara rẹ̀ lè dìde bí ẹni tó fẹ́ ní ìbálòpọ̀.

b Wo Orí 33 nínú ìwé Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé, Apá Kejì, fún àlàyé síwájú sí i.

c Wo ojú ìwé 239 sí 241 nínú ìwé Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé, Apá Kejì, fún àlàyé síwájú sí i.

ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́

“Sá fún àwọn ìfẹ́-ọkàn tí ó máa ń bá ìgbà èwe rìn, ṣùgbọ́n máa lépa òdodo, ìgbàgbọ́, ìfẹ́, àlàáfíà, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn tí ń ké pe Olúwa láti inú ọkàn-àyà tí ó mọ́.”​—2 Tímótì 2:22.

ÌMỌ̀RÀN

Bí ọkàn rẹ bá fà sí ìṣekúṣe, gbàdúrà kó tó di pé ó ń le sí i. Bẹ Jèhófà Ọlọ́run pé kó fún ẹ ní “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá” tí wàá fi lè borí ìdẹwò.​—2 Kọ́ríńtì 4:7.

ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?

Ẹni tí kò lè ṣèkáwọ́ ara rẹ̀ máa ń tètè juwọ́ sílẹ̀ bí ọkàn rẹ̀ bá ti ń fà sí ìṣekúṣe. Àmọ́, ọkùnrin tàbí obìnrin tó bá ń kó ara ẹ̀ níjàánu kódà nígbà tó wà níkọ̀kọ̀, la lè pè ní ọkùnrin tàbí obìnrin tó jẹ́ alágbára.

OHUN TÍ MÀÁ ṢE!

Màá máa fọkàn mi ro ohun tó mọ́ bí mo bá ․․․․․

Dípò tí màá fi jẹ́ kí ọkàn mi máa fà sí ìṣekúṣe, màá ․․․․․

Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․

KÍ LÈRÒ Ẹ?

● Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kó o máa rántí pé Jèhófà “ṣe tán láti dárí jini”?​—Sáàmù 86:5.

● Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Ọlọ́run tó dá ìfẹ́ láti máa ní ìbálòpọ̀ mọ́ àwa èèyàn náà ló sọ pé kó o máa kó ara rẹ níjàánu, kí ni Ọlọ́run mọ̀ dájú pé wàá lè ṣe?

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 182]

“Látìgbà tí mo ti borí ìṣòro yìí ni mo ti dẹni tó ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́ níwájú Jèhófà, ìyẹn sì jẹ́ ohun kan tí mi ò lè fi bá èèyàn ṣeré!”​—Sarah

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 180]

Pé o ṣubú nígbà tó ò ń sáré kò túmọ̀ sí pé wàá tún lọ bẹ̀rẹ̀ eré sísá látìbẹ̀rẹ̀, bákan náà tó o bá tún bẹ̀rẹ̀ sí í fọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ rẹ, kò túmọ̀ sí pé ìtẹ̀síwájú tó o ti ní já sásán

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́