Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ǹjẹ́ a lè yọ ẹnì kan kúrò nínú ìjọ Ọlọ́run nítorí ìwà àìmọ́ bá a ṣe lè yọ ẹnì kan nítorí àgbèrè àti ìwà àìníjàánu?
Bẹ́ẹ̀ ni, tẹ́nì kan bá ń ṣe àgbèrè, tàbí tó ń hu irú àwọn ìwà àìmọ́ tàbí ìwà àìníjàánu kan, tí kò sì ronú pìwà dà, yíyọ la máa yọ ọ́ kúrò nínú ìjọ Ọlọ́run. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ka àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí mọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó lè mú kí wọ́n yọ ẹnì kan lẹ́gbẹ́, ó kọ̀wé pé: “Àwọn iṣẹ́ ti ara fara hàn kedere, àwọn sì ni àgbèrè, ìwà àìmọ́, ìwà àìníjàánu, . . . Èmi ń kìlọ̀ ṣáájú fún yín . . . pé àwọn tí ń fi irúfẹ́ nǹkan báwọ̀nyí ṣe ìwà hù kì yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.”—Gálátíà 5:19-21.
Àgbèrè (tí wọ́n ń pè ní por·neiʹa lédè Gíríìkì) jẹ́ ìbálòpọ̀ láàárín àwọn tí kì í ṣe tọkọtaya tó ti ṣègbéyàwó lọ́nà tó bá Ìwé Mímọ́ mu. Lára àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó jẹ́ àgbèrè ni panṣágà, ṣíṣe aṣẹ́wó, àti ìbálòpọ̀ láàárín ẹni méjì tí kò bára wọn ṣègbéyàwó, títí kan kéèyàn máa fi ẹnu kan ẹ̀yà ìbímọ ẹlòmíràn, kéèyàn máa ti ihò ìdí báni lòpọ̀, àti fífi ọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ ẹlòmíràn tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya ẹni. Yíyọ la máa yọ ẹni tó bá ń ṣe àgbèrè tí kò sì ronú pìwà dà kúrò nínú ìjọ Ọlọ́run.
Ìwà àìníjàánu (tí wọ́n ń pè ní a·selʹgei·a lédè Gíríìkì) jẹ́ “ìṣekúṣe; ìṣekúṣe tí kò níjàánu; ìwà àìnítìjú; ìwà ìbàjẹ́.” Ìwé atúmọ̀ èdè The New Thayer’s Greek-English Lexicon sọ pé ọ̀rọ̀ Gíríìkì yìí túmọ̀ sí “ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ tí kò níjàánu, . . . ìwà tí kò bójú mu, ìwà àìnítìjú, ìwà àfojúdi.” Ìwé atúmọ̀ èdè míì sọ pé ìwà àìníjàánu jẹ́ ara àwọn ìwà tó “burú kọjá gbogbo ohun tó yẹ ká bá lọ́wọ́ ọmọlúwàbí.”
Gẹ́gẹ́ bí àwọn ìtumọ̀ tó wà lókè yìí ṣe fi hàn, ohun méjì ló ṣe kedere nípa “ìwà àìníjàánu.” Ìkíní, ìwà yẹn fúnra rẹ̀ ta ko àwọn òfin Ọlọ́run ní gbogbo ọ̀nà. Ìkejì, ìwà àrífín àti àfojúdi lonítọ̀hún hù.
Nítorí náà, “ìwà àìníjàánu” kì í wulẹ̀ ṣe ẹ̀ṣẹ̀ kékeré kan tẹ́nì kan ṣẹ̀. Ó jẹ́ gbogbo ìwà tó rú òfin Ọlọ́run lọ́nà tó burú jáì, ó sì jẹ mọ́ ohun tá a lè pè ní ìwà ọ̀dájú tàbí ìwà ta-ní-máa-mú-mi, ìyẹn ìwà tí kò fọ̀wọ̀ hàn fún àṣẹ, òfin àti ìlànà, tó sì tún ń tẹ́ńbẹ́lú wọn. Pọ́ọ̀lù fi hàn pé ìwà àìníjàánu kan ìbádàpọ̀ tó tàpá sófin. (Róòmù 13:13, 14) Níwọ̀n bí Gálátíà 5:19-21 ti ka ìwà àìníjàánu mọ́ ara àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí kò ní jẹ́ kéèyàn wọ Ìjọba Ọlọ́run, nígbà náà ìwà àìníjàánu jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí ìgbìmọ̀ onídàájọ́ lè tìtorí ẹ̀ fún ẹnì kan ní ìbáwí tàbí kí wọ́n tiẹ̀ yọ ọ́ kúrò nínú ìjọ Ọlọ́run pàápàá.
Ìwà àìmọ́ (tí wọ́n ń pè ní a·ka·thar·siʹa lédè Gíríìkì) ló ní ìtumọ̀ tó gbòòrò jù lọ nínú ọ̀rọ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tá a túmọ̀ sí “àgbèrè,” “ìwà àìmọ́,” àti “ìwà àìníjàánu.” Ìwà àìmọ́ jẹ mọ́ ìwà èérí èyíkéyìí, ì báà jẹ́ nípa ìbálòpọ̀, nínú ọ̀rọ̀, nínú ìṣe, àti nínú ìjọsìn. Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ńlá tá a lè kà sí “ìwà àìmọ́” pọ̀ gan-an ni.
Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú 2 Kọ́ríńtì 12:21, Pọ́ọ̀lù tọ́ka sí àwọn tí wọ́n “ti dẹ́ṣẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí ṣùgbọ́n tí wọn kò tíì ronú pìwà dà ìwà àìmọ́ àti àgbèrè àti ìwà àìníjàánu wọn tí wọ́n ti fi ṣe ìwà hù.” Níwọ̀n bí Bíbélì ti mẹ́nu kan “ìwà àìmọ́” pa pọ̀ pẹ̀lú “àgbèrè àti ìwà àìníjàánu,” àwọn ìwà àìmọ́ kan wà tó la ọ̀ràn ìgbẹ́jọ́ lọ. Àmọ́ ṣá o, ìwà àìmọ́ jẹ́ ọ̀rọ̀ tí ìtumọ̀ rẹ̀ gbòòrò, ó tún lè tọ́ka sí àwọn nǹkan míì tí kò la ọ̀ràn ìgbẹ́jọ́ lọ. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá sọ pé ilé kan dọ̀tí díẹ̀, ó yàtọ̀ sí ìgbà tá a bá sọ pé ó kún fún ẹ̀gbin. Nítorí náà, ìwà àìmọ́ ju ìwà àìmọ́ lọ.
Nínú Éfésù 4:19, Pọ́ọ̀lù sọ pé àwọn kan “ti wá ré kọjá gbogbo agbára òye ìwà rere,” àti pé “wọ́n fi ara wọn fún ìwà àìníjàánu láti máa fi ìwà ìwọra hu onírúurú ìwà àìmọ́ gbogbo.” Ohun tí Pọ́ọ̀lù ń fi yéni pẹ̀lú ọ̀rọ̀ yẹn ni pé ohun kan náà ni ‘ìwà àìmọ́ téèyàn fi ìwà ìwọra hù’ àti ìwà àìníjàánu. Tí ẹnì kan tó ti ṣèrìbọmi bá ń fi “ìwà ìwọra . . . hu ìwà àìmọ́” tí kò sì ronú pìwà dà, a lè tìtorí ìyẹn yọ onítọ̀hún kúrò nínú ìjọ Ọlọ́run nítorí pé ìwà àìmọ́ tó burú jáì ló hù yẹn.
Ká ló ṣẹlẹ̀ pé, àwọn méjì kan tó ń fẹ́ra wọn sọ́nà ń fẹnu ko ara wọn lẹ́nu, wọ́n sì ń fọwọ́ pa ara wọn lára lọ́nà tó ń ru ìfẹ́ ìbálòpọ̀ sókè, tí èyí sì ṣẹlẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà. Àwọn alàgbà lè wò ó pé ìwà tí wọ́n hù yẹn kì í ṣe ti ọ̀dájú, èyí tí í ṣe ìwà àìníjàánu, síbẹ̀ ohun tí wọ́n ṣe fi ìwà ìwọra hàn dé ìwọ̀n àyè kan. Nítorí náà, àwọn alàgbà lè yan ìgbìmọ̀ onídàájọ́ láti rí sí ọ̀ràn náà nítorí pé ìwà àìmọ́ tó burú jáì ni wọ́n hù yẹn. Tẹ́nì kan bá ń bá ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ lórí tẹlifóònù látìgbàdégbà, tó sì jẹ́ pé ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ ni wọ́n máa ń sọ ṣáá, a lè ka irú ìyẹn náà sí ìwà àìmọ́ tó burú jáì tí ìgbìmọ̀ onídàájọ́ yóò bójú tó àgàgà táwọn alàgbà bá ti bá onítọ̀hún sọ̀rọ̀ tẹ́lẹ̀ nípa ẹ̀.
Ó gba ìfòyemọ̀ káwọn alàgbà tó lè dá irú ẹjọ́ báwọ̀nyí. Káwọn alàgbà sì tó pinnu pé àwọn máa yan ìgbìmọ̀ onídàájọ́ nítorí ọ̀rọ̀ kan, wọ́n gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ fara balẹ̀ gbé ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹ̀ wò, kí wọ́n sì tún wo bí ọ̀ràn náà ṣe rinlẹ̀ tó. Kì í ṣe pé kí wọ́n kàn fẹ̀sùn kan ẹni tí kò bá ti gba ìmọ̀ràn tí wọ́n fún un látinú Ìwé Mímọ́ pé ó ti jẹ̀bi ìwà àìníjàánu. Bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ọ̀rọ̀ kí wọ́n máa ka iye ìgbà tẹ́nì kan máa dẹ́ṣẹ̀ kan kí wọ́n tó yan ìgbìmọ̀ onídàájọ́ láti bójú tó ọ̀ràn náà. Àwọn alàgbà ní láti fara balẹ̀ gbé ọ̀kọ̀ọ̀kan ọ̀ràn tó bá jẹ yọ yẹ̀ wò, kí wọ́n fi í sínú àdúrà, kí wọ́n wádìí láti mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an àti iye ìgbà tó ṣẹlẹ̀, kí wọ́n mọ irú ẹ̀ṣẹ̀ tó jẹ́ gan-an àti bó ṣe rinlẹ̀ tó, kí wọ́n sì mọ ohun tẹ́ni tó dẹ́ṣẹ̀ náà ní lọ́kàn àtohun tó sún un ṣe nǹkan tó ṣe.
Kì í ṣe nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó jẹ mọ́ ìbálòpọ̀ nìkan lèèyàn ti lè hu ìwà àìmọ́ tó burú jáì o. Bí àpẹẹrẹ, ká ní ọ̀dọ́kùnrin kan tó ti ṣèrìbọmi mu sìgá mélòó kan láàárín àkókò tí kò fi bẹ́ẹ̀ pẹ́ síra, ó sì jẹ́wọ́ fáwọn òbí rẹ̀. Ó wá pinnu pé òun ò ní dán irú rẹ̀ wò mọ́. Ìwà àìmọ́ lohun tó ṣe yẹn jẹ́, àmọ́ kò tíì burú débi tá a fi lè sọ pé ó hu ìwà àìmọ́ tó burú jáì tàbí pé ó “fi ìwà ìwọra hu . . . ìwà àìmọ́.” Ìmọ̀ràn tí alàgbà kan tàbí méjì bá fún un látinú Ìwé Mímọ́ àti ìrànlọ́wọ́ àwọn òbí rẹ̀ ti tó láti yanjú ọ̀ràn náà. Àmọ́ tí ọ̀dọ́kùnrin yìí bá ń mu sìgá látìgbàdégbà, á jẹ́ pé ńṣe ló ń mọ̀ọ́mọ̀ ṣe ohun tó máa sọ ọ́ di ẹlẹ́gbin nípa tara, nítorí náà ìgbìmọ̀ onídàájọ́ ní láti bójú tó ọ̀ràn náà nítorí pé ìwà àìmọ́ tó burú jáì ni. (2 Kọ́ríńtì 7:1) Tí ọ̀dọ́kùnrin yìí ò bá ronú pìwà dà, ńṣe la ó yọ ọ́ lẹ́gbẹ́.
Àwọn Kristẹni kan máa ń wo àwòrán oníhòòhò. Inú Ọlọ́run ò dùn sí irú nǹkan báyìí rárá àti rárá, ó sì máa ń ba àwọn alàgbà nínú jẹ́ bí wọ́n bá gbọ́ pé onígbàgbọ́ ẹlẹ́gbẹ́ wọn wo irú àwòrán bẹ́ẹ̀. Àmọ́ kì í ṣe gbogbo ọ̀ràn tó bá jẹ mọ́ wíwo irú àwòrán oníhòòhò bẹ́ẹ̀ la máa tìtorí ẹ̀ yan ìgbìmọ̀ onídàájọ́. Bí àpẹẹrẹ, ká ní arákùnrin kan wo irú àwòrán oníhòòhò táwọn èèyàn sọ pé kò tíì burú jù nígbà mélòó kan. Ojú ara rẹ̀ wá gbà á tì fún ohun tó ṣe yẹn, ó jẹ́wọ́ fún alàgbà kan, ó sì pinnu pé òun ò jẹ́ dẹ́ṣẹ̀ yẹn mọ́ láyé. Alàgbà náà lè pinnu pé ìwà tí arákùnrin náà hù ò tíì burú débi tá a fi lè sọ pé ó ti ‘fi ìwà ìwọra hu ìwà àìmọ́.’ Bẹ́ẹ̀ la ò sì lè sọ pé ó ti hùwà ọ̀dájú tí í ṣe ìwà àìníjàánu. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ ẹ̀ ò la ìgbẹ́jọ́ lọ, síbẹ̀ alàgbà náà yóò fi Ìwé Mímọ́ bá a wí gidigidi nítorí irú ìwà àìmọ́ tó hù yìí, àwọn alàgbà sì tún lè máa ràn án lọ́wọ́ nìṣó.
Àmọ́, ká ní fún ọ̀pọ̀ ọdún ni Kristẹni kan ti ń yọ́ wo àwòrán oníhòòhò tó burú jáì, èyí tó ń fi ìbálòpọ̀ hàn lọ́nà òdì, tí ẹni náà sì ti wá gbogbo ọ̀nà láti bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ yìí mọ́lẹ̀. Ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kí ibi tí àwọn ọmọọ̀ta ti ń fipá bá ẹnì kan ṣoṣo lòpọ̀ wà nínú àwòrán náà, àti ibi tí wọ́n ti dèèyàn mọ́lẹ̀ láti bá a lòpọ̀, ibi tí wọ́n ti ń fi ọ̀dájú dáni lóró, ibi tí wọ́n ti ń han àwọn obìnrin léèmọ̀ tàbí ibi tí wọ́n tiẹ̀ ti ń fi ìhòòhò àwọn ọmọdé hàn. Nígbà táwọn èèyàn wá ká a mọ́, ojú tì í gan-an. Ìwà tó hù kò tíì di ti ọ̀dájú, àmọ́ àwọn alàgbà lè pinnu pé ó ti ‘fi ara rẹ̀ fún’ ìwà èérí yìí, ó sì ti fi ‘ìwà ìwọra hu ìwà àìmọ́,’ tó jẹ́ ìwà àìmọ́ tó burú jáì. A óò yan ìgbìmọ̀ onídàájọ́ nítorí pé ọ̀rọ̀ náà ti la ìwà àìmọ́ tó burú jáì lọ. Yíyọ la ó sì yọ oníwà àìtọ́ yìí kúrò nínú ìjọ Ọlọ́run bí kò bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn kó sì pinnu pé òun ò ní wo àwòrán oníhòòhò mọ́ láyé òun. Tó bá sì jẹ́ pé ńṣe ni ẹni náà máa ń pe àwọn mìíràn wá sílé rẹ̀ láti wá wo àwòrán oníhòòhò, tó túmọ̀ sí pé ó ń gbé wíwo irú àwòrán bẹ́ẹ̀ lárugẹ, ìwà ọ̀dájú gbáà nìyẹn, tó fi hàn pé ó ti hu ìwà àìníjàánu.
Gbogbo ìwà tó wà lábẹ́ ohun tí Ìwé Mímọ́ pè ní “ìwà àìníjàánu” ló jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ ńlá, ó sì sábà máa ń jẹ mọ́ ìbálòpọ̀. Nígbà táwọn alàgbà bá ń yiiri ẹ̀ṣẹ̀ kan wò láti mọ̀ bóyá ìwà àìníjàánu ni àbí òun kọ́, kí wọ́n kọ́kọ́ wò ó bóyá ó ní í ṣe pẹ̀lú ìwà ọ̀dájú, ìṣekúṣe tí kò níjàánu, ìwà èérí, ìwà àìnítìjú àti ìwà táráyé ò gbọ́dọ̀ báni gbọ́ sétí. Àmọ́, ẹnì kan lè rú òfin Jèhófà láìsí pé ó hùwà ọ̀dájú, síbẹ̀ ohun tó ṣe lè jẹ́ ìwà “ìwọra.” Ìgbìmọ̀ onídàájọ́ ní láti bójú tó irú àwọn ọ̀ràn báwọ̀nyí nítorí pé ìwà àìmọ́ tó burú jáì ni wọ́n.
Láti pinnu bóyá ẹ̀ṣẹ̀ ẹnì kan rinlẹ̀ débi tá a fi lè sọ pé ó jẹ̀bi ìwà àìmọ́ tó burú jáì tàbí ìwà àìníjàánu kì í ṣe nǹkan kékeré, nítorí pé ọ̀ràn tó la ìwàláàyè lọ ni. Nítorí náà, àwọn tó ń gbọ́ irú ẹjọ́ bẹ́ẹ̀ ní láti kún fún àdúrà, kí wọ́n bẹ Ọlọ́run pé kó fún àwọn ní ìfòyemọ̀, òye àti ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. Bákan náà, àwọn alàgbà ní láti rí i pé àwọn ń mú kí ìjọ wà ní mímọ́, àwọn sì ń gbé ìdájọ́ wọn karí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ìtọ́ni tó bá wá látọ̀dọ̀ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye.” (Mátíù 18:18; 24:45) Ní ayé èṣù tá a wà yìí, ju ti ìgbàkígbà rí lọ, àwọn alàgbà ní láti fiyè sí ọ̀rọ̀ yìí: “Ẹ kíyè sí ohun tí ẹ ń ṣe, nítorí pé kì í ṣe ènìyàn ni ẹ ń ṣe ìdájọ́ fún bí kò ṣe Jèhófà.”—2 Kíróníkà 19:6.