ORIN 54
“Èyí Ni Ọ̀nà”
1. Ọ̀nà kan wà tó ti
Wà lọ́jọ́ tó ti pẹ́.
Jésù sọ nípa rẹ̀
Nígbà tó wá sáyé.
Mo kẹ́kọ̀ọ́, mo sì ti
Wá mọ ọ̀nà yìí gan-an.
Ọ̀nà àlàáfíà yìí
Wà nínú Bíbélì.
(ÈGBÈ)
Ọ̀nà ìyè àìnípẹ̀kun nìyí.
Tẹsẹ̀ mọ́rìn, má ṣe wọ̀tún-wòsì!
Jèhófà ń sọ pé: ‘Má yà kúrò;
Má ṣe wẹ̀yìn, ojú ọ̀nà lo wà.’
2. Ọ̀nà ìfẹ́ lo wà,
Má ṣe wọ̀tún-wòsì.
Bíbélì fi hàn pé
Jèhófà jẹ́ ìfẹ́.
Ìfẹ́ tó dára, tó
Jinlẹ̀ ló ní sí wa.
Ọ̀nà tí à ń sọ yìí
Kan ìgbé ayé wa.
(Ègbè)
Ọ̀nà ìyè àìnípẹ̀kun nìyí.
Tẹsẹ̀ mọ́rìn, má ṣe wọ̀tún-wòsì!
Jèhófà ń sọ pé: ‘Má yà kúrò;
Má ṣe wẹ̀yìn, ojú ọ̀nà lo wà.’
3. Ọ̀nà ìyè la wà,
Má ṣe bojú wẹ̀yìn.
Kò sí ibòmíràn
Tá a lè lọ, tá a lè rí
Àlàáfíà àtìfẹ́
Tí Jáà ṣèlérí rẹ̀.
Ọ̀nà ìyè nìyí,
Ọpẹ́ yẹ Jèhófà.
(Ègbè)
Ọ̀nà ìyè àìnípẹ̀kun nìyí.
Tẹsẹ̀ mọ́rìn, má ṣe wọ̀tún-wòsì!
Jèhófà ń sọ pé: ‘Má yà kúrò;
Má ṣe wẹ̀yìn, ojú ọ̀nà lo wà.’