Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka Sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
JULY 2-8
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | LÚÙKÙ 6-7
“Ẹ Máa Díwọ̀n Fúnni Fàlàlà”
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Lk 6:37
Ẹ máa bá a nìṣó ní títúnisílẹ̀, a ó sì tú yín sílẹ̀: Tàbí “Ẹ máa bá a nìṣó ní dídárí jini, a ó sì dárí jì yín.” Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a túmọ̀ sí “dárí jini” túmọ̀ sí kéèyàn “fi nǹkan sílẹ̀; kó máa lọ; kó dáni sílẹ̀ (bí àpẹẹrẹ, ẹlẹ́wọ̀n).” Ní ibi yìí, ìdásílẹ̀ àti ìdáríjì jẹ́ òdìkejì dídáni lẹ́jọ́ àti dídáni lẹ́bi, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó yẹ kí ẹni náà jìyà ohun tó ṣe tàbí kó jèrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.
Ẹ Máa Ṣe Rere
13 Gẹ́gẹ́ bí Ìhìn Rere Mátíù ṣe sọ, Jésù sọ pé: “Ẹ dẹ́kun dídánilẹ́jọ́ kí a má bàa dá yín lẹ́jọ́.” (Mát. 7:1) Ohun tí Ìhìn Rere Lúùkù sọ pé Jésù sọ rèé: “Ẹ dẹ́kun dídánilẹ́jọ́, a kì yóò sì dá yín lẹ́jọ́ lọ́nàkọnà; ẹ sì dẹ́kun dídánilẹ́bi, a kì yóò sì dá yín lẹ́bi lọ́nàkọnà. Ẹ máa bá a nìṣó ní títúnisílẹ̀, a ó sì tú yín sílẹ̀.” (Lúùkù 6:37) Ní ọ̀rúndún kìíní, àwọn Farisí máa ń dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́ lọ́nà líle koko, àwọn òfin àtọwọ́dọ́wọ́ tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu ni wọ́n sì máa ń lò. Bí ẹnikẹ́ni lára àwọn tó ń gbọ́rọ̀ Jésù bá ti ń ṣerú nǹkan bẹ́ẹ̀, ó ní láti “dẹ́kun dídánilẹ́jọ́” lọ́nà bẹ́ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kí wọ́n máa “bá a nìṣó ní títúnisílẹ̀,” ìyẹn ni pé kí wọ́n máa dárí jini. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pẹ̀lú fún wa ní ìmọ̀ràn tó jọ èyí lórí ọ̀ràn ìdáríjì.
14 Báwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù bá ń dárí jini, èyí á mú káwọn ẹlòmíì pẹ̀lú máa dárí jì wọ́n. Jésù sọ pé: “Irú ìdájọ́ tí ẹ fi ń dáni lẹ́jọ́, ni a ó fi dá yín lẹ́jọ́; àti òṣùwọ̀n tí ẹ fi ń díwọ̀n fúnni, ni wọn yóò fi díwọ̀n fún yín.” (Mát. 7:2) Tó bá dọ̀rọ̀ bá a ṣe ń ṣe sáwọn èèyàn, ohun tá a bá fúnrúgbìn la máa ká.—Gál. 6:7.
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Lk 6:38
Ẹ sọ fífúnni dàṣà: Tàbí “Ẹ máa fúnni.” Irú ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n lò níbí yìí lè tọ́ka sí kéèyàn “fúnni” ní nǹkan, ìyẹn ni pé kéèyàn máa ṣe é láìdáwọ́dúró.
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Lk 6:38
itan yín: Ọ̀rọ̀ Gíríìkì yìí túmọ̀ sí “ọkàn àyà,” àmọ́ nínú ẹsẹ Bíbélì yìí, ó ṣeé ṣe kó máa tọ́ka sí ìgbà tí ẹnì kan bá ṣẹ́ ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀ po níbi tó ti fẹ̀ lọ́wọ́ ìsàlẹ̀. ‘Wọn yóò da òṣùwọ̀n àtàtà sórí itan yín,’ ọ̀rọ̀ yìí lè máa tọ́ka sí bí àwọn tó ń tajà ṣe máa ń wọn ọjà wọn kún dáadáa, tí wọ́n á sì dà á sínú ìṣẹ́po ẹ̀wù àwọ̀lékè ẹni tó wá rajà.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Báwo Lo Ṣe Lè Dẹni Tó Sún Mọ́ Ọlọ́run?
Jésù sábà máa ń lo àkókò gígùn tó bá ń gbàdúrà. (Jòhánù 17:1-26) Bí àpẹẹrẹ, kí Jésù tó yan àwọn ọkùnrin méjìlá tó wá di àpọ́sítélì rẹ̀, ó “lọ sórí òkè ńlá láti gbàdúrà, ó sì ń bá a lọ nínú àdúrà gbígbà sí Ọlọ́run ní gbogbo òru náà.” (Lúùkù 6:12) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tó sún mọ́ Ọlọ́run lè má fi gbogbo òru gbàdúrà, síbẹ̀ wọ́n máa ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. Kí wọ́n tó ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì nígbèésí ayé wọn, wọ́n á wá àkókò tó pọ̀ tó láti gbàdúrà sí Ọlọ́run, wọ́n á bẹ̀ ẹ́ pé kó fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ tọ́ àwọn sọ́nà káwọn lè ṣe ìpinnu tó máa jẹ́ káwọn lè túbọ̀ sún mọ́ ọn.
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Lk 7:35
àwọn ọmọ rẹ̀: Tàbí “àbájáde rẹ̀.” Níbí yìí, wọ́n sọ̀rọ̀ ọgbọ́n bíi pé ó jẹ́ èèyàn, tó sì ní àwọn ọmọ. Nínú ìtàn kan náà tó wà ní Mt 11:19, wọ́n ṣàpèjúwe ọgbọ́n pé ó ní “àwọn iṣẹ́.” Àwọn ọmọ tí ọgbọ́n bí tàbí àwọn iṣẹ́ rẹ̀, ni àwọn ẹ̀rí tí Jòhánù Oníbatisí àti Jésù fi hàn, pé ẹ̀sùn èké làwọn èèyàn fi ń kàn wọ́n. Jésù sì ń tipa bẹ́ẹ̀ sọ pé: ‘Ẹ wo àwọn iṣẹ́ rere mi àti ìwà mi, ẹ óò sì rí i pé irọ́ làwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn mí.’
Bíbélì Kíkà
JULY 9-15
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | LÚÙKÙ 8-9
“Kí Ló Túmọ̀ Sí Láti Di Ọmọlẹ́yìn?”
it-2 494
Ibi wíwọ̀sí
Nígbà tí ọ̀kan lára àwọn akọ̀wé òfin sọ fún Jésù pé: “Olùkọ́, dájúdájú, èmi yóò tẹ̀ lé ọ lọ sí ibi yòówù tí ìwọ bá fẹ́ lọ,” Jésù dáhùn pé: “Àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ní ihò, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ní ibi wíwọ̀sí, ṣùgbọ́n Ọmọ ènìyàn kò ní ibi kankan láti gbé orí rẹ̀ lé.” (Mt 8:19, 20; Lk 9:57, 58) Jésù tipa báyìí jẹ́ kí ọkùnrin náà mọ̀ pé, kó tó lè di ọmọlẹ́yìn òun, ó gbọ́dọ̀ mọ́kàn kúrò lórí ìtura àti ìgbé ayé ìdẹ̀rùn tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń gbádùn, kó sì gbọ́kàn lé Jèhófà pátápátá. Ìlànà yìí hàn nínú àdúrà àwòṣe tí Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Fún wa lónìí oúnjẹ wa fún ọjọ́ òní” àti ọ̀rọ̀ míì tó sọ pé: “Nípa báyìí, ìwọ lè mọ̀ dájú pé, kò sí ẹnì kankan nínú yín tí kò sọ pé ó dìgbòóṣe fún gbogbo àwọn nǹkan ìní rẹ̀ tí ó lè jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn mi.”—Mt 6:11; Lk 14:33.
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Lk 9:59, 60
sìnkú baba mi: Ọ̀rọ̀ yìí kò túmọ̀ sí pé bàbá ọkùnrin náà ṣẹ̀ṣẹ̀ kú, tó wá ń tọrọ àyè láti lọ ṣètò ìsìnkú rẹ̀. Tó bá jẹ́ pé bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn, kò lè ṣeé ṣe kí ọkùnrin náà wà níbi tó ti ń bá Jésù sọ̀rọ̀ yẹn. Nílẹ̀ Ísírẹ́lì àtijọ́, tẹ́nì kan bá kú nínú ìdílé, wọ́n máa ń tètè sìnkú rẹ̀, ọ̀pọ̀ ló sì jẹ́ pé ọjọ́ yẹn gan-an ni wọ́n máa sin ín. Torí náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ni bàbá ọkùnrin náà ń ṣàìsàn tàbí kó ti darúgbó, kì í ṣe pé ó ti kú. Bákan náà, Jésù ò lè sọ fún ọkùnrin náà pé kó pa òbí tó ń ṣàìsàn tàbí tó nílò ìrànlọ́wọ́ tì, torí náà ó ní láti jẹ́ pé àwọn kan ṣì wà nínú ìdílé náà tó lè bójú tó àwọn ojúṣe pàtàkì yẹn. (Mk 7:9-13) Ohun tí ọkùnrin náà ń dọ́gbọ́n sọ ni pé, ‘Màá tẹ̀ lé ẹ, àmọ́ kì í ṣe nígbà tí bàbá mi bá ṣì wà láàyè. Dúró dìgbà tí bàbá mi bá kú, tí mo sì sìnkú rẹ̀.’ Àmọ́ lójú Jésù, ńṣe ló dà bíi pé ọkùnrin náà fẹ́ pàdánù àǹfààní tó ní láti fi ohun tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́ láyé rẹ̀.—Lk 9:60, 62.
Jẹ́ kí àwọn òkú máa sin òkú wọn: Bá a ṣe rí i nínú àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Lk 9:59, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ni bàbá ọkùnrin náà ń ṣàìsàn tàbí kó ti darúgbó, kì í ṣe pé ó ti kú. Torí náà, ó hàn gbangba pé ohun tí Jésù ń sọ ni pé: ‘Jẹ́ kí àwọn tó ti kú nípa tẹ̀mí máa sìnkú ara wọn,’ ìyẹn ni pé, kí ọkùnrin náà jẹ́ kí àwọn míì nínú ìdílé wọn tọ́jú bàbá rẹ̀ títí táá fi kú, tí wọ́n á sì sin ín. Bí ọkùnrin náà bá tẹ̀ lé Jésù, ó máa wà lára àwọn tó nírètí ìyè àìnípẹ̀kun, kò ní sí lára àwọn tó ti kú nípa tẹ̀mí lójú Ọlọ́run. Nínú ìdáhùn Jésù, ó fi hàn pé tá a bá fi Ìjọba Ọlọ́run sí ipò àkọ́kọ́ láyé wa tá a sì ń kéde rẹ̀ kárí ayé, ó máa jẹ́ ká máa wà láàyè nípa tẹ̀mí.
nwtsty àwòrán àti fídíò
Títúlẹ̀
Àsìkò òjò tí ilẹ̀ sábà máa ń rọ̀ ni wọ́n máa ń túlẹ̀. (Wo Àfikún Ìsọfúnni Apá 19.) Igi ni wọ́n fi máa ń ṣe àwọn ohun ìtúlẹ̀ kan, ó sì máa ń ní irin ẹlẹ́nu ṣóńṣó, wọ́n á wá kàn án mọ́ ọ̀pá kan tí wọ́n gbé dábùú, ẹran kan tàbí méjì á sì máa fà á. Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti túlẹ̀ tán, wọ́n máa gbin èso tí wọ́n fẹ́. Nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, wọ́n fi iṣẹ́ ìtúlẹ̀ ṣe àpèjúwe torí iṣẹ́ tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń ṣe ni. (Ond 14:18; Ais 2:4; Jer 4:3; Mik 4:3) Jésù sábà máa ń lo iṣẹ́ àgbẹ̀ láti fi ṣàpèjúwe àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì. Bí àpẹẹrẹ, ó tọ́ka sí iṣẹ́ títúlẹ̀ láti fi tẹnu mọ́ ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kéèyàn fi tọkàntọkàn jẹ́ ọmọlẹ́yìn rẹ̀. (Lk 9:62) Tí ẹni tó ń túlẹ̀ bá lọ jẹ́ kí ohunkóhun pín ọkàn rẹ̀ níyà nínú iṣẹ́ tó ń ṣe, ńṣe ni ebè tó ń kọ máa wọ́. Bákan náà, tí ọmọlẹ́yìn Kristi bá lọ jẹ́ kí ohunkóhun pín ọkàn rẹ̀ níyà tàbí tí kò ṣe ojúṣe rẹ̀ mọ́, irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò ní yẹ fún Ìjọba Ọlọ́run.
Máa Fi Ọkàn-àyà Pípé Sin Jèhófà
11 Kí ẹ̀kọ́ tí Jésù fẹ́ fi àpèjúwe kúkúrú yẹn kọ́ wa lè ṣe kedere, ẹ jẹ́ ká fi àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ díẹ̀ kún àwòrán tó fẹ́ kó gbé wá sí wa lọ́kàn. Ọwọ́ alágbàṣe kan dí bó ṣe ń lo ohun èlò ìtúlẹ̀. Àmọ́, bó ṣe ń bá iṣẹ́ rẹ̀ nìṣó kò yéé ronú nípa àwọn tó fi sílé, aya àtàwọn ọmọ, àwọn ọ̀rẹ́, oúnjẹ, orin, bí wọ́n ṣe máa ń para wọn lẹ́rìn-ín àti bó ṣe máa ń wà lábẹ́ ibòji. Ọkàn rẹ̀ wá ń fà sí àwọn nǹkan yẹn. Lẹ́yìn tí alágbàṣe yẹn ti fi ohun èlò ìtúlẹ̀ kọ ilẹ̀ tó pọ̀ gan-an, ìfẹ́ tó ní sí àwọn nǹkan tó máa ń mú kí ìgbésí ayé gbádùn mọ́ni yìí gbà á lọ́kàn débi pé ó yí pa dà láti wo “àwọn ohun tí ń bẹ lẹ́yìn.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé alágbàṣe náà ṣì ní ọ̀pọ̀ iṣẹ́ láti ṣe kí wọ́n tó parí gbígbin irúgbìn sórí ilẹ̀ náà, ọkàn rẹ̀ ti pínyà, ìyẹn sì pa iṣẹ́ rẹ̀ lára. Láìsí àní-àní, alágbàṣe yẹn já ọ̀gá rẹ̀ kulẹ̀ torí pé kò ní ẹ̀mí ìfaradà.
12 Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wo bí ohun tó jọ èyí ṣe lè ṣẹlẹ̀ lóde òní. Alágbàṣe náà lè dúró fún Kristẹni èyíkéyìí tó dà bíi pé ó ń ṣe dáradára, àmọ́ tó wà nínú ewu nípa tẹ̀mí. Ní àfiwé, ẹ jẹ́ ká fi ọkàn yàwòrán arákùnrin kan tí ọwọ́ rẹ̀ máa ń dí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Àmọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó máa ń lọ sí àwọn ìpàdé àti òde ẹ̀rí, kò yéé ronú nípa àwọn nǹkan kan tó fẹ́ràn lára àwọn ohun tó jẹ́ ti ayé. Ọkàn rẹ̀ ń fà sí àwọn nǹkan yẹn gan-an. Lẹ́yìn tó ti lo ọdún mélòó kan lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, ìfẹ́ tó ní fún àwọn nǹkan ti ayé yìí wá gbà á lọ́kàn gan-an débi tó fi yí pa dà tó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wo “àwọn ohun tí ń bẹ lẹ́yìn.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé púpọ̀ ṣì wà láti ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, arákùnrin náà kò “di ọ̀rọ̀ ìyè mú ṣinṣin,” èyí sì ṣe ìpalára fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. (Fílí. 2:16) Kì í dùn mọ́ Jèhófà tó jẹ́ “Ọ̀gá ìkórè” nínú bí ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ kò bá lo ìfaradà mọ́.—Lúùkù 10:2.
13 Ẹ̀kọ́ tó ṣe kedere ni èyí kọ́ wa. Ó dára gan-an tá a bá ń kópa déédéé nínú àwọn ìgbòkègbodò tó gbámúṣé tó sì ń fúnni láyọ̀, bíi lílọ sí àwọn ìpàdé ìjọ àti òde ẹ̀rí. Àmọ́, fífi ọkàn-àyà pípé sin Jèhófà tún gba pé ká ṣe ohun tó ju ìyẹn lọ. (2 Kíró. 25:1, 2, 27) Bí Kristẹni kan bá ṣì ń nífẹ̀ẹ́ sí “àwọn ohun tí ń bẹ lẹ́yìn” nínú ọkàn-àyà rẹ̀, ìyẹn àwọn kan lára àwọn ohun tó jẹ́ ti ayé, ó lè pàdánù àjọṣe tó dára tó ní pẹ̀lú Ọlọ́run. (Lúùkù 17:32) Àyàfi tá a bá “fi tẹ̀gàntẹ̀gàn kórìíra ohun burúkú [tá a sì] rọ̀ mọ́ ohun rere” la tó lè “yẹ dáadáa fún ìjọba Ọlọ́run.” (Róòmù. 12:9; Lúùkù 9:62) Torí náà, gbogbo wa gbọ́dọ̀ rí i dájú pé bó ti wù kí ohunkóhun nínú ayé Sátánì yìí wúlò tàbí kó gbádùn mọ́ wa tó, a kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kó fà wá sẹ́yìn kúrò nínú fífi gbogbo ọkàn-àyà wa bójú tó gbogbo nǹkan tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run.—2 Kọ́r. 11:14; ka Fílípì 3:13, 14.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Lk 8:3
ń ṣèránṣẹ́ fún wọn: Tàbí “wọ́n ń tì wọ́n lẹ́yìn (pèsè fún) wọn.” Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà di·a·ko·neʹo lè tọ́ka sí pípèsè ohun tí ẹnì kan nílò nípa tara irú bíi ká báàyàn ra nǹkan, ká báàyàn se oúnjẹ, ká gbé oúnjẹ fúnni àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Wọ́n lo irú ọ̀rọ̀ yìí ní Lk 10:40 (“bójú tó àwọn nǹkan”), Lk 12:37 (“ìránṣẹ́”), Lk 17:8 (“ṣe ìránṣẹ́”) àti Iṣe 6:2 (“pín oúnjẹ”), àmọ́ ó tún lè tọ́ka sí àwọn iṣẹ́ míì tó jọ irú èyí tá a mẹ́nu kàn yìí. Nínú ẹsẹ yìí, ó ṣàpèjúwe bí àwọn obìnrin tí ẹsẹ 2 àti 3 sọ̀rọ̀ nípa wọn ṣe ṣètìlẹ́yìn fún Jésù àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, tí wọ́n ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé wọn lọ́wọ́. Àwọn obìnrin yẹn tipa bẹ́ẹ̀ fi ògo fún Ọlọ́run. Ọlọ́run mọ rírì iṣẹ́ rere wọn, ó sì jẹ́ kó wà lákọsílẹ̀ nínú Bíbélì fún ìran tó ń bọ̀ láti kà. (Owe 19:17; Heb 6:10) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì yìí kan náà ni wọ́n lò fún àwọn obìnrin nínú Mt 27:55; Mk 15:41.
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Lúùkù
9:49, 50— Kí nìdí tí Jésù kò fi ṣèdíwọ́ fún ọkùnrin kan tó ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọkùnrin náà kì í tẹ̀ lé Jésù? Ìdí tí Jésù kò fi ṣèdíwọ́ fún ọkùnrin náà ni pé wọn ò tíì dá ìjọ Kristẹni sílẹ̀ nígbà yẹn. Fún ìdí yìí, kì í ṣe dandan pé kí ọkùnrin yẹn máa tẹ̀ lé Jésù kó tó lè nígbàgbọ́ nínú orúkọ Jésù kó sì lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.—Máàkù 9:38-40.
Bíbélì Kíkà
JULY 16-22
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | LÚÙKÙ 10-11
“Àpèjúwe Ará Samáríà”
nwtsty àwòrán àti fídíò
Ọ̀nà Tó Lọ Láti Jerúsálẹ́mù sí Jẹ́ríkò
Ọ̀nà (1) tá a fi hàn nínú fídíò kékeré yìí fẹ́ jọ ọ̀nà àtijọ́ tó lọ láti Jerúsálẹ́mù sí Jẹ́ríkò. Ọ̀nà yẹn gùn tó ogún [20] kìlómítà, ó sì ní àwọn òkè gbágungbàgun. Téèyàn bá ń bọ̀ láti Jerúsálẹ́mù, ó máa rin nǹkan bí kìlómítà kan tó bá ń sọ̀ kálẹ̀ láti orí òkè tó wọ ìlú Jẹ́ríkò. Àwọn dánàdánà pọ̀ ní ọ̀nà yìí, ibẹ̀ sì máa ń dá, torí náà wọ́n fi àwọn ẹ̀ṣọ́ síbẹ̀ láti máa dáàbò bo àwọn arìnrìn-àjò. Jẹ́ríkò àwọn ará Róòmù (2) wà níbi tí ọ̀nà náà ti bẹ̀rẹ̀ ní aginjù Jùdíà. Ìlú Jẹ́ríkò tó ti pẹ́ (3) wà ní nǹkan bí kìlómítà méjì sí ìlú Róòmù.
“Kì í Bá Wọn Sọ̀rọ̀ Láìsí Àpèjúwe”
14 Ìkejì, rántí àpèjúwe ará Samáríà tó jẹ́ aládùúgbò rere. Bí Jésù ṣe bẹ̀rẹ̀ àpèjúwe ọ̀hún rèé: “Ọkùnrin kan ń sọ̀ kalẹ̀ láti Jerúsálẹ́mù lọ sí Jẹ́ríkò, ó sì bọ́ sí àárín àwọn ọlọ́ṣà, àwọn tí wọ́n bọ́ ọ láṣọ, tí wọ́n sì lù ú, wọ́n sì lọ, ní fífi í sílẹ̀ láìkú tán.” (Lúùkù 10:30) Ó yẹ fún àfiyèsí pé ọ̀nà tó lọ “láti Jerúsálẹ́mù sí Jẹ́ríkò” ni Jésù fi ṣàpèjúwe ọ̀rọ̀ rẹ̀. Jùdíà ló wà nígbà tó ń sọ àpèjúwe yìí, ibẹ̀ ò sì jìnnà sí Jerúsálẹ́mù; nítorí náà àwọn tó ń bá sọ̀rọ̀ ò ní ṣàìmọ ọ̀nà tó ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Gbogbo èèyàn ló mọ̀ pé ọ̀nà náà léwu gan-an, àgàgà fẹ́ni tó ń dá rìnrìn àjò. Ọ̀nà náà ṣe kọ́lọkọ̀lọ, ó sì máa ń dá páropáro, èyí ló jẹ́ káwọn ọlọ́ṣà máa ríbi fara pa mọ́ sí níbẹ̀.
15 Ohun kan tún yẹ fún àfiyèsí nínú lílò tí Jésù lo ọ̀nà tó lọ “láti Jerúsálẹ́mù sí Jẹ́ríkò” nínú àkàwé rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìtàn náà ṣe lọ, àlùfáà kan kọ́kọ́ kọjá lọ́nà yìí lẹ́yìn náà ni ọmọ Léfì kan tún kọjá—àmọ́ kò séyìí tó dúró lára wọn láti ṣaájò ọ̀gbẹ́ni náà. (Lúùkù 10:31, 32) Inú tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù làwọn àlùfáà ti ń sìn, àwọn ọmọ Léfì ló sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́. Níwọ̀n bí Jẹ́ríkò kò ti ju kìlómítà mẹ́tàlélógún sí Jerúsálẹ́mù, Jẹ́ríkò ni ọ̀pọ̀ àlùfáà àtàwọn ọmọ Léfì máa ń gbé nígbà tí wọn ò bá sí lẹ́nu iṣẹ́ nínú tẹ́ńpìlì. Ìdí rèé tó fi jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n máa ń gba ọ̀nà yìí kọjá. Tún kíyè sí i pé ọ̀nà tó wá “láti Jerúsálẹ́mù” ni àlùfáà àti ọmọ Léfì náà ti ń bọ̀, tó fi hàn pé tẹ́ńpìlì ni wọ́n ti ń bọ̀. Nítorí náà, kò sí àwíjàre kankan fún ìwà àìbìkítà táwọn ọkùnrin wọ̀nyí hù, pé, ‘Bó ṣe dà bí ẹni pé ọkùnrin tó bọ́ sọ́wọ́ àwọn ọlọ́ṣà náà ti kú ni ò jẹ́ kí àwọn ṣaájò rẹ̀, nítorí fífọwọ́ kan òkú kò ní jẹ́ kí wọ́n lè ṣiṣẹ́ nínú tẹ́ńpìlì fún ìwọ̀n àkókò kan.’ (Léfítíkù 21:1; Númérì 19:11, 16) Ǹjẹ́ kò ṣe kedere pé ohun táwọn olùgbọ́ Jésù mọ̀ dunjú ló gbé àpèjúwe rẹ̀ kà?
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Lk 10:33, 34
ará Samáríà kan: Àwọn Júù máa ń fojú yẹpẹrẹ wo àwọn ará Samáríà, wọn ò sì ń fẹ́ bá wọn da nǹkan pọ̀. (Jo 4:9) Àwọn Júù tiẹ̀ máa ń lo ọ̀rọ̀ náà “ará Samáríà” láti fi tẹ́ńbẹ́lú wọn àti láti pẹ̀gàn wọn. (Jo 8:48) Rábì kan tiẹ̀ sọ nínú ìwé Míṣínà pé: “Téèyàn bá jẹ búrẹ́dì àwọn ará Samáríà, ńṣe ló dà bí ìgbà téèyàn ń jẹ ẹran ẹlẹ́dẹ̀.” (Shebith 8:10) Ọ̀pọ̀ Júù ni kì í fara mọ́ ẹ̀rí tí ará Samáríà bá jẹ́, wọn ò sì ní gbà kó bá wọn ṣiṣẹ́. Torí pé Jésù mọ ojú tí kò dáa táwọn Júù fi ń wo àwọn ará Samáríà, ó fa kókó pàtàkì kan yọ nínú àpèjúwe tó ṣe, èyí tí wọ́n sábà máa ń pè ní àkàwé aláàánú ara Samáríà.
ó sì di àwọn ọgbẹ́ rẹ̀, ó da òróró àti wáìnì sórí wọn: Lúùkù tó jẹ́ oníṣègùn fara balẹ̀ ṣàkọsílẹ̀ àkàwé Jésù, ó sọ bí wọ́n ṣe máa ń tọ́jú ojú ọgbẹ́ láyé ìgbà yẹn. Wọ́n sábà máa ń lo òróró àti wáìnì láti fi tọ́jú ibi téèyàn ti fara pa. Wọ́n máa ń lo òróró láti mú kí ojú ọgbẹ́ náà dẹ̀ (fi wé Ais 1:6), wáìnì sì dà bí oògùn apakòkòrò. Lúùkù tún ṣàkàwé bí wọ́n ṣe di ojú ọgbẹ́ náà, kí ojú ọgbẹ́ náà máa bàa kẹ̀ sí i.
ilé èrò: Ìtúmọ̀ ọ̀rọ̀ Gíríìkì yìí ni “ibi tí wọ́n ti ń gba gbogbo nǹkan wọlé.” Àwọn arìnrìn-àjò àtàwọn ẹran wọn máa ń rí ibi tí wọ́n máa dé sí nírú àwọn ilé bẹ́ẹ̀. Olùtọ́jú ilé èrò máa ń pèsè ohun kòṣeémáàní fún àwọn arìnrìn-àjò, á sì gbowó lọ́wọ́ wọn, ó sì tún lè máa bá wọn ṣọ́ àwọn ohun ìní wọn tí wọ́n tọ́jú sọ́dọ̀ rẹ̀.
Ará Samáríà Kan Jẹ́ Aládùúgbò Rere
Àkàwé Jésù fi hàn pé ẹni tí ó dúró ṣánṣán ní tòótọ́ ni ẹni tí kì í ṣe pé ó ń pa òfin Ọlọ́run mọ́ nìkan ni, ṣùgbọ́n, tí ó tún ń fara wé àwọn ànímọ́ rẹ̀. (Éfésù 5:1) Fún àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ fún wa pé “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú.” (Ìṣe 10:34) A ha ń fara wé Ọlọ́run lọ́nà yìí bí? Àkàwé Jésù tí ó ru ìmọ̀lára sókè fi hàn pé a kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ọ̀ràn orílẹ̀-èdè, àṣà ìbílẹ̀, àti ìsìn dí ìfẹ́ fún àwọn aládùúgbò wa lọ́wọ́. Ní tòótọ́, a fún àwọn Kristẹni ní ìtọ́ni láti “ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn”—kì í ṣe sí kìkì àwọn ènìyàn tí a jọ wà ní ipò kan náà ní ti ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà, ẹ̀ya ìran, tàbí orílẹ̀-èdè, kì í sì í ṣe sí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa nìkan.—Gálátíà 6:10.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Lk 10:18
Mo bẹ̀rẹ̀ sí rí Sátánì tí ó ti já bọ́ ná bí mànàmáná láti ọ̀run: Àsọtẹ́lẹ̀ ni Jésù ń sọ níbí yìí, ó rí lílé tí wọ́n máa lé Sátánì kúrò ní ọ̀run bí ohun tó ti ṣẹlẹ̀. Iṣi 12:7-9 ṣàpèjúwe ìjà tó bẹ́ sílẹ̀ ní ọ̀run, ó sì so ìṣubú Sátánì mọ́ ìdásílẹ̀ Ìjọba Mèsáyà. Nínú ẹsẹ yìí, ńṣe ni Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa bó ṣe máa ṣẹ́gun Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ nínú ogun ọjọ́ iwájú yẹn, torí pé Ọlọ́run ṣẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn àádọ́rin ọmọlẹ́yìn rẹ̀, tí wọ́n jẹ́ èèyàn aláìpé ní agbára láti lé ẹ̀mí èṣù jáde.—Lk 10:17.
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Lúùkù
10:18—Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ fáwọn àádọ́rin ọmọ ẹ̀yìn náà pé: “Mo bẹ̀rẹ̀ sí rí Sátánì tí ó ti já bọ́ ná bí mànàmáná láti ọ̀run”? Kì í ṣohun tí Jésù ń sọ ni pé wọ́n ti lé Sátánì kúrò lọ́run nígbà yẹn o. Kété lẹ́yìn tí Ọlọ́run fi Kristi jẹ Ọba ní ọ̀run lọ́dún 1914 ni wọ́n tó ṣẹ̀ṣẹ̀ lé e kúrò lọ́run. (Ìṣí. 12:1-10) Lóòótọ́, tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, àwa ò lè fi gbogbo ẹnu sọ ọ́ bí ìgbà tó jẹ́ pé ó ti ṣẹlẹ̀, àmọ́ ó jọ pé ńṣe ni Jésù sọ̀rọ̀ lọ́nà yìí láti fi hàn pé ohun tó sọ yẹn kò ní ṣàìṣẹ.
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Lk 11:5-9
Ọ̀rẹ́, yá mi ní ìṣù búrẹ́dì mẹ́ta: Àwọn èèyàn tó wà ní Ìlà Oòrùn ayé fẹ́ràn kí wọ́n máa ṣàlejò gan-an, èyí sì hàn nínú àpèjúwe yìí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀gànjọ́ òru ni àlejò náà dé láìjẹ́ pé wọ́n ti ń retí rẹ̀, síbẹ̀ ó wu ẹni tí àlejò dé sọ́dọ̀ rẹ̀ láti fún àlejò náà ní ohun tó máa jẹ. Èyí jẹ́ ká rí i pé nígbà yẹn kò rọrùn láti dá ìgbà téèyàn máa dé ibi tó ń lọ. Abájọ tí ẹni tó gbàlejò náà fi lọ sọ́dọ̀ aládùúgbò rẹ̀ láti lọ tọrọ oúnjẹ ní àárín òru.
Yé dà mí láàmú: Kò yá aládùúgbò inú àkàwé yìí lára láti ran ọ̀rẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́, kì í ṣe torí pé ó jẹ́ èèyànkéèyàn, kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ torí pé ó ti lọ sùn. Nígbà yẹn, yàrá ńlá kan ló máa ń wà nínú ilé, pàápàá tó bá jẹ́ ilé àwọn tálákà. Tí baálé ilé náà bá máa ní láti dìde, ó ṣeé ṣe kó yọ gbogbo àwọn tó wà nílé lẹ́nu, títí kan àwọn ọmọ tó ti ń sùn.
ìtẹpẹlẹ rẹ̀ aláìṣojo: Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n lò níbí yìí lè túmọ̀ sí “àìmẹ̀tọ́mọ̀wà” tàbí “àìnítìjú.” Àmọ́ níbí yìí, ohun tó túmọ̀ sí ni kéèyàn máa béèrè nǹkan láìbẹ̀rù. Ọkùnrin inú àkàwé Jésù kò tijú, kò sì fà sẹ́yìn láti máa béèrè ohun tó fẹ́, ẹ̀kọ́ tí Jésù fi èyí kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ni pé kí wọ́n máa gbàdúrà fún ohun tí wọ́n nílò láìdáwọ́dúró.—Lk 11:9, 10.
Bíbélì Kíkà
JULY 23-29
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | LÚÙKÙ 12-13
“Ẹ Níye Lórí Ju Ọ̀pọ̀ Ológoṣẹ́”
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Lk 12:6
ológoṣẹ́: Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà strou·thiʹon ni wọ́n máa ń lò fún àwọn ẹyẹ tó kéré gan-an, àmọ́ ológoṣẹ́ ni wọ́n sábà máa ń lò ó fún jù, torí pé òun ni owó ẹ̀ kéré jù lọ lára àwọn ẹyẹ táwọn èèyàn ń rà pa jẹ.
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Lk 12:7
irun orí yín pàápàá ni a ti ka iye gbogbo wọn: Wọ́n sọ pé irun orí èèyàn máa ń pọ̀ tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún [100,000]. Bí Jèhófà ṣe mọ nǹkan tí ò fí bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì yìí fi hàn pé ọ̀rọ̀ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi jẹ ẹ́ lọ́kàn.
Kò Sóhun Tó Lè “Yà Wá Kúrò Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run”
4 Èkíní, Bíbélì fi yé wa yékéyéké pé Ọlọ́run ka gbogbo ìránṣẹ́ rẹ̀ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan sí. Fún àpẹẹrẹ, Jésù sọ pé: “Kì í ha ṣe ológoṣẹ́ méjì ni a ń tà ní ẹyọ owó kan tí ìníyelórí rẹ̀ kéré? Síbẹ̀, kò sí ọ̀kan nínú wọn tí yóò jábọ́ lulẹ̀ láìjẹ́ pé Baba yín mọ̀. Ṣùgbọ́n gbogbo irun orí yín gan-an ni a ti kà. Nítorí náà, ẹ má bẹ̀rù: ẹ níye lórí púpọ̀ ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́ lọ.” (Mátíù 10:29-31) Ẹ jẹ́ ká gbé ohun tí ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn túmọ̀ sí létí àwọn tí Jésù ń bá sọ̀rọ̀ ní ọ̀rúndún kìíní yẹ̀ wò.
5 A lè máa ṣe kàyéfì nípa ohun tó lè mú kéèyàn fẹ́ ra ológoṣẹ́. Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé, nígbà ayé Jésù, ológoṣẹ́ ni ẹyẹ olówó pọ́ọ́kú jù lọ táwọn èèyàn ń rà fún jíjẹ. Ṣàkíyèsí pé èèyàn lè fi ẹyọ owó kan ṣoṣo tí ìníyelórí rẹ̀ kéré ra ológoṣẹ́ méjì. Àmọ́ Jésù sọ lẹ́yìn ìgbà náà pé béèyàn bá ní ẹyọ owó méjì lọ́wọ́ tó fẹ́ fi ra ológoṣẹ́, kì í ṣe ológoṣẹ́ mẹ́rin ni wọ́n máa kó fún un, bí kò ṣe márùn-ún. Ńṣe ló dà bíi pé ọ̀kan tí wọ́n fi ṣe ènì yẹn kò níye lórí rárá. Àwọn ẹyẹ yẹn lé máà níye lórí lójú èèyàn, àmọ́ ojú wo ni Ẹlẹ́dàá fi ń wò wọ́n? Jésù sọ pé: “Kò sí ọ̀kan nínú wọn [àtèyí tí wọ́n fi ṣe ènì pàápàá] tí a gbàgbé níwájú Ọlọ́run.” (Lúùkù 12:6, 7) Òye ohun tí Jésù sọ lè wá bẹ̀rẹ̀ sí yé wa wàyí. Bí ẹyẹ ológoṣẹ́ kan ṣoṣo bá níye lórí tó bẹ́ẹ̀ lójú Jèhófà, mélòómélòó wá ni ẹ̀dá ènìyàn! Gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe ṣàlàyé, Jèhófà mọ̀ wá látòkèdélẹ̀. Kódà, ó mọ iye irun tó wà lórí wa pàápàá!
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Lk 13:24
Ẹ tiraka tokuntokun: Tàbí “Ẹ túbọ̀ máa sapá.” Ìmọ̀ràn Jésù yìí tẹnu mọ ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa fi tọkàntọkàn ṣe iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ká bàa lè láǹfààní láti gba ẹnu ọ̀nà tóóró wọlé. Àwọn ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú ẹ̀ túmọ̀ ẹsẹ Bíbélì yìí sí “Ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe; Sa gbogbo ipá rẹ.” Ọ̀rọ̀ ìṣe Gíríìkì náà a·go·niʹzo·mai tan mọ́ ọ̀rọ̀ orúkọ Gíríìkì náà a·gonʹ, èyí tí wọ́n sábà máa ń lò láti tọ́ka sí ìdíje eré sísá. Ní Heb 12:1, wọ́n lo ọ̀rọ̀ orúkọ yìí láti ṣàpẹẹrẹ “eré ìje” ìyè tí àwa Kristẹni ń sá. Wọ́n tún wá lò ó lọ́nà tó gbòòrò gẹ́gẹ́ bí “ìjàkadì” (Flp 1:30; Kol 2:1) tàbí “ìjà” (1Ti 6:12; 2Ti 4:7). Irú ọ̀rọ̀ ìṣe Gíríìkì tí wọ́n lò ní Lk 13:24, ni wọ́n túmọ̀ sí “kó ipa nínú ìdíje” (1Kọ 9:25), “tiraka” (Kol 1:29; 4:12; 1Ti 4:10), àti “ìjà” (1Ti 6:12). Torí pé ibi tí ọ̀rọ̀ yìí ti ṣẹ̀ wá ní ín ṣe pẹ̀lú ìdíje eré sísá, àwọn kan sọ pé a lè fi ìsapá tí Jésù fẹ́ ká ṣe wé bí eléré ìdárayá kan ṣe máa ń lo gbogbo iṣan rẹ̀, táá sì lo gbogbo okùn àti agbára rẹ̀ kó bàa lè gba ẹ̀bùn.
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Lk 13:33
kò ṣeé gbà wọlé: Tàbí “kò ṣe é ronú kàn.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì kankan tó dìídì sọ pé Jerúsálẹ́mù ni wọ́n ti máa pa Mèsáyà, síbẹ̀ a lè rí ohun tó jọ ọ́ nínú Da 9:24-26. Láfikún sí i, a lè retí pé tí àwọn Júù bá máa pa wòlíì kan, pàápàá Mèsáyà, ó ní láti jẹ́ ní Jerúsálẹ́mù. Ìlú Jerúsálẹ́mù ni ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn tó ní mẹ́ńbà mọ́kànléláàdọ́rin [71] tó sì jẹ́ ilé ẹjọ́ gíga ti máa ń pàdé, torí náà, ibẹ̀ ni wọ́n ti máa ń gbọ́ ẹjọ́ àwọn tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé wọ́n jẹ́ wòlíì èké. Jésù tún lè ní in lọ́kàn pé Jerúsálẹ́mù ni wọ́n ti máa ń rúbọ sí Ọlọ́run déédéé, ibẹ̀ náà sì ni wọ́n ti máa ń pa àgùntàn Ìrékọjá. Bí Jésù ṣe sọ gẹ́lẹ́ náà ló rí. Wọ́n mú un wá síwájú Sànhẹ́dírìn, wọ́n sì dájọ́ ikú fún un. Ìlú Jerúsálẹ́mù ló ti ṣẹlẹ̀, lẹ́yìn odi ìlú, ibẹ̀ ni Jésù ti kú gẹ́gẹ́ bí “Ìrékọjá wa.”—1Kọ 5:7.
Bíbélì Kíkà
JULY 30–AUGUST 5
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | LÚÙKÙ 14-16
“Àpèjúwe Ọmọ Tó Sọ Nù”
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Lk 15:11-16
Ọkùnrin kan ní ọmọkùnrin méjì: Àwọn apá kan nínú àpèjúwe ọmọ onínàákúnàá (tá a tún ń pè ní “ọmọ tó sọ nù”) ṣàrà ọ̀tọ̀. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àpèjúwe gígùn tí Jésù sọ. Apá tó ṣe pàtàkì ni àjọṣe àwọn tó wà nínú ìdílé náà. Nínú àwọn àpèjúwe míì, Jésù sábà máa ń lo àwọn ohun aláìlẹ́mìí, irú bíi oríṣiríṣi èso àti ilẹ̀ tàbí àjọṣe ọ̀gá sí ọmọọṣẹ́. (Mt 13:18-30; 25:14-30; Lk 19:12-27) Àmọ́ nínú àpèjúwe yìí, Jésù sọ̀rọ̀ nípa àjọṣe tímọ́tímọ́ tó wà láàárín bàbá àtàwọn ọmọ rẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn tó gbọ́ ìtàn yìí lè má tíì gbọ́ ìtàn bàbá tó lójú àánú báyìí rí. Àpèjúwe yìí ṣàpẹẹrẹ ìyọ́nú àti ìfẹ́ tó jinlẹ̀ tí Baba wa ọ̀run ní sí àwa ọmọ rẹ̀ tó wà lórí ilẹ̀ ayé, ìyẹn àwọn tí kò fi í sílẹ̀ àtàwọn tó pa dà sọ́dọ̀ rẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti ṣáko lọ.
Èyí àbúrò nínú wọn: Òfin Mósè sọ pé àkọ́bí ló máa gba ohun tó pọ̀ jù lára ogún bàbá wọn. (Diu 21:17) Torí náà, tó bá jẹ́ ẹ̀gbọ́n ni àkọ́bí inú àpèjúwe yìí, á jẹ́ pé ìdajì ohun tó gbà ni wọ́n máa fún àbúrò rẹ̀.
lo dúkìá rẹ̀ ní ìlò àpà: Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n lò níbí yìí túmọ̀ sí “láti tú nǹkan ká (káàkiri).” (Lk 1:51; Iṣe 5:37) Ní Mt 25:24, 26, wọ́n túmọ̀ rẹ̀ sí “fẹ́kà.” Níbí yìí, wọ́n lò ó bí ìgbà téèyàn ń fi nǹkan ṣòfò tàbí kéèyàn náwó da nù.
ìgbésí ayé oníwà wọ̀bìà: Tàbí “ìgbésí ayé tí kò nítumọ̀.” Wọ́n lo irú ọ̀rọ̀ Gíríìkì yìí kan náà ní Ef 5:18; Tit 1:6; 1Pe 4:4. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì yìí tún lè túmọ̀ sí ìná àpà tàbí ìnákúnàá, torí náà àwọn ìtúmọ̀ Bíbélì míì túmọ̀ ọ̀rọ̀ yìí sí “ìgbésí ayé onínàákúnàá.”
àwọn ẹlẹ́dẹ̀: Ohun àìmọ́ ni ẹlẹ́dẹ̀ jẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú Òfin, torí náà iṣẹ́ àbùkù, tí ò ṣe é gbọ́ sétí làwọn Júù ka títọ́jú ẹlẹ́dẹ̀ sí.—Le 11:7, 8.
pódi èso kárọ́ọ̀bù: Èso kárọ́ọ̀bù ní èèpo ẹ̀yìn tó ń dán, ó máa ń jọ awọ, ó sì máa ń ní àwọ̀ purplish-brown. Èso yìí máa ń rí kọrọdọ bí ìwo ẹran, èyí sì bá orúkọ tí wọ́n ń pè é ní èdè Gíríìkì mu (ke·raʹti·on, “ìwo kékeré”). Àwọ́n ẹṣin, màlúù àti ẹlẹ́dẹ̀ ni wọ́n máa ń jẹ èso kárọ́ọ̀bù nígbà yẹn kódà títí dòní. Ká lè mọ ibi tí nǹkan ti burú dé fún ọmọkùnrin náà, ó fẹ́ láti jẹ oúnjẹ àwọn ẹlẹ́dẹ̀.—Wo àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Lk 15:15.
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Lk 15:17-24
sí ọ: Tàbí “ní ojú rẹ.” Ọ̀rọ̀ aso ọ̀rọ̀ pọ̀ Gíríìkì yìí e·noʹpi·on, túmọ̀ sí “tẹ́lẹ̀; níwájú,” bákan náà sì ni wọ́n ṣe lò ó ní 1Sa 20:1 nínú Bíbélì Septuagint. Nínú ẹsẹ yẹn, Dáfídì béèrè lọ́wọ́ Jónátánì pé: “Kí sì ni ẹ̀ṣẹ̀ tí mo dá níwájú baba rẹ?”
ọkùnrin tí o háyà: Nígbà tí ọmọkùnrin náà pa dà sílé, ó ronú láti bẹ bàbá rẹ̀ pé kó gba òun gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn ọkùnrin tó háyà, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ọmọ. Irú òṣìṣẹ́ tí wọ́n háyà bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ sí àwọn ẹrú tí wọ́n rà, àwọn ẹrú máa ń gbé ilé ọ̀gá wọn, wọ́n á sì máa bá iṣẹ́ wọn lọ. Àmọ́ iṣẹ́ ojúmọ́ làwọn òṣìṣẹ́ tí wọ́n háyà máa ń ṣe.—Mt 20:1, 2, 8.
fi ẹnu kò ó lẹ́nu lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́: Tàbí “fẹnu kò ó lẹ́nu lọ́nà ìfẹ́.” Ọ̀rọ̀ ìṣe Gíríìkì náà phi·leʹo túmọ̀ sí láti “fẹnu ko ẹnu” (Mt 26:48; Mk 14:44; Lk 22:47) àmọ́ àwọn kan gbà pé ìtúmọ̀ rẹ̀ jinlẹ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ, pé ó túmọ̀ sí láti “fi ẹnu koni lẹ́nu lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́,” àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà ó máa ń túmọ̀ sí láti “ní ìfẹ́ni fún” (Jo 5:20; 11:3; 16:27). Bí Bàbá náà ṣe kí ọmọ rẹ̀ tọ̀yàyàtọ̀yàyà pẹ̀lú ìfẹ́ fi hàn pé ó wù ú láti gba ọmọ rẹ̀ tó ti ronú pìwà dà náà pa dà.
pè ní ọmọkùnrin rẹ: Àwọn ìwé àfọwọ́kọ kan fi kún un pé: “Fi mí ṣe bí ọ̀kan nínú àwọn ọkùnrin tí o háyà,” àmọ́ bá a ṣe yọ̀ ọ́ kúrò nínú Bíbélì tá a ṣe lọ́dún 2013 bá àwọn ìwé àfọwọ́kọ tọjọ́ wọn ti pẹ́ gan-an mu. Àwọn ọ̀mọ̀wé wá rí i pé ńṣe ni wọ́n kàn fi àwọn ọ̀rọ̀ yẹn kún un kó lè dọ́gba pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tó wà ní Lk 15:19.
aṣọ . . . òrùka . . . sálúbàtà: Aṣọ yìí kì í kàn ṣe aṣọ kan lásán àmọ́ ó jẹ́ èyí tí ó dára jù lọ, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ aṣọ olówó ńlá tí wọ́n kó iṣẹ́ aláràbarà sí lára, irú èyí tí wọ́n máa ń fún àlejò pàtàkì. Bí wọ́n ṣe fi òrùka sí ọwọ́ ọmọkùnrin náà fi hàn pé bàbá rẹ̀ ti yọ́nú sí i àti pé ó ti gba iyì, ògo àti ipò tó yẹ ẹ́ pa dà gẹ́gẹ́ bi ọmọ. Ọ̀pọ̀ ẹrú kì í lo òrùka, wọn ò sì ń wọ bàtà. Torí náà, ṣe ni bàbá náà ń fi hàn pé òun gba ọmọ òun pa dà tọwọ́tẹsẹ̀.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Lk 14:26
kórìíra: Nínú Bíbélì, onírúurú nǹkan ni ọ̀rọ̀ náà “kórìíra” lè túmọ̀ sí. Ó túmọ̀ sí kéèyàn máa bínú ẹnì kan ṣáá, kéèyàn sì fẹ́ kí ìyà máa jẹ onítọ̀hún, ó lè lágbára gan-an débi táá fi mú kí èèyàn fẹ́ ṣe ẹni náà ní jàǹbá. Ó sì lè túmọ̀ sí pé kéèyàn má nífẹ̀ẹ́ ohun kan tàbí ẹnì kan rárá, débi téèyàn á fi máa yẹra fún un nítorí pé kò fẹ́ máa rí i. Ó tún lè túmọ̀ sí pé kéèyàn má fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ ohun kan. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé Jákọ́bù “kórìíra” Léà, ó sì nífẹ̀ẹ́ Rákélì, ohun tí ọ̀rọ̀ yẹn túmọ̀ sí ni pé Jákọ́bù nífẹ̀ẹ́ Rákélì ju Léà lọ (Jẹ 29:31; Diu 21:15), wọ́n lo irú ọ̀rọ̀ yìí nínú àwọn ìwé àwọn Júù míì láyé ìgbàanì. Torí náà, ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ kò túmọ̀ sí pé káwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ máa bínú kíkankíkan sáwọn mọ̀lẹ́bí wọn àti sí ara wọn, torí pé èyí máa ta ko ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ lódindi. (Fi wé Mk 12:29-31; Ef 5:28, 29, 33.) Nínú ẹsẹ yìí, ọ̀rọ̀ náà “kórìíra” lè túmọ̀ sí “láti ní ìfẹ́ díẹ̀.”
Bá A Ṣe Lè Ní Ọrọ̀ Tòótọ́
7 Ka Lúùkù 16:10-13. Torí àǹfààní ara rẹ̀ ni ìríjú tó wà nínú àkàwé Jésù ṣe yan àwọn ọ̀rẹ́. Àmọ́ Jésù rọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n bá òun àti Ọlọ́run dọ́rẹ̀ẹ́ torí pé èyí á ṣe àwọn àtàwọn míì láǹfààní. Àwọn ẹsẹ Bíbélì tó tẹ̀ lé àkàwé tí Jésù ṣe jẹ́ ká rí i pé bá a bá ṣe lo “ọrọ̀ àìṣòdodo” tá a ní máa fi hàn bóyá a jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run àbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Ohun tí Jésù fẹ́ fàyọ ni pé a lè ‘fi ara wa hàn ní olùṣòtítọ́’ nínú bá a ṣe ń lo ọrọ̀ tá a ní. Báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?
8 Ọ̀nà pàtàkì wo la lè gbà fi hàn pé a jẹ́ olóòótọ́ nínú bá a ṣe ń lo ọrọ̀ wa? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń fowó ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ ìwàásù tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀. (Mát. 24:14) Bí àpẹẹrẹ, ọmọbìnrin kékeré kan lórílẹ̀-èdè Íńdíà ní kóló kékeré kan, ó sì máa ń fowó sínú rẹ̀ lóòrèkóòrè, kódà ó máa ń fi owó tó yẹ kó fi ra nǹkan ìṣeré sínú kóló náà. Nígbà tí kóló náà kún, ọmọbìnrin náà fi gbogbo owó inú rẹ̀ ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé. Arákùnrin míì lórílẹ̀-èdè Íńdíà ní oko àgbọn. Ìgbà kan wà tó kó àgbọn rẹpẹtẹ wá sí ọ́fíìsì àwọn tó ń túmọ̀ èdè Malayalam, ó mọ̀ pé wọ́n máa ń nílò àgbọn, tóun bá sì fún wọn lágbọn, ìyẹn á dín ìnáwó wọn kù. Ká sòótọ́, ọgbọ́n tó gbéṣẹ́ làwọn tá a sọ yìí lò. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ará nílẹ̀ Gíríìsì máa ń fi òróró ólífì, wàràkàṣì àtàwọn oúnjẹ míì ṣètìlẹ́yìn fún ìdílé Bẹ́tẹ́lì.
Bíbélì Kíkà