ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 10/95 ojú ìwé 1
  • Ẹ Máa Yin Jehofa Nígbà Gbogbo

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ Máa Yin Jehofa Nígbà Gbogbo
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1995
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹ̀yin Èwe, Ẹ Yin Jèhófà!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Máa Yin Jèhófà Lójoojúmọ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
  • Yin Jehofa Lójoojúmọ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1995
  • A Yà Wọ́n Sọ́tọ̀ Láti Jẹ́ Onídùnnú Olùyìn Jákèjádò Ayé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1995
km 10/95 ojú ìwé 1

Ẹ Máa Yin Jehofa Nígbà Gbogbo

1 Àwọn ìgbòkègbodò díẹ̀ kan wà tí wọ́n ṣe pàtàkì púpọ̀ débi pé wọ́n máa ń fìgbà gbogbo yẹ fún àfiyèsí wa. Jíjẹun, mímí, àti sísun wà lára wọn. Ìwọ̀nyí ṣe kókó bí a bá fẹ́ máa bá a lọ láti wà láàyè nípa ti ara. Aposteli Paulu fi wíwàásù ìhìn rere sí ipò kan náà, nígbà tí ó rọni pé: “Ẹ jẹ́ kí a máa rú ẹbọ ìyìn sí Ọlọrun nígbà gbogbo.” (Heb. 13:15) Nítorí náà, yíyin Jehofa yẹ fún àfiyèsí wa léraléra pẹ̀lú. Ó jẹ́ ohun tí ó yẹ kí a gbìyànjú láti ṣe lójoojúmọ́, ní yíyin Baba wa ọ̀run nígbà gbogbo.

2 Nígbà tí àwọn kan gbìyànjú láti yí àfiyèsí rẹ̀ sí ohun mìíràn, Jesu fèsì pé: “Emi gbọ́dọ̀ polongo ìhìnrere ìjọba Ọlọrun.” (Luku 4:43) Lákòókò iṣẹ́ òjíṣẹ́ ọlọ́dún mẹ́ta àti àbọ̀ rẹ̀, gbogbo ohun tí ó ṣe ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ní ìsopọ̀ tààràtà ní ọ̀nà kan pẹ̀lú yíyin Ọlọrun lógo. A mọ̀ pé Paulu ronú lọ́nà yìí, ní ojú ìwòye ohun tí ó sọ ní 1 Korinti 9:16 pé: “Ègbé ni fún mi bí emi kò bá polongo ìhìnrere!” A fún àwọn Kristian olùṣòtítọ́ yòókù níṣìírí láti múra tán nígbà gbogbo láti ṣe ìgbèjà ìrètí wọn fún àwọn ẹlòmíràn. (1 Pet. 3:15) Lónìí, ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn aṣáájú ọ̀nà onítara àti àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn akéde Ìjọba ń sakun láti fara wé irú àwọn àpẹẹrẹ rere bí ìwọ̀nyí.

3 Bí a ti ń ronú lórí ìtara àtọkànwá tí Jesu Kristi, Àwòkọ́ṣe wa, fi hàn, a ń sún wa láti tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí. (1 Pet. 2:21) Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, a lè kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wa, nígbà tí a bá dojú kọ àwọn ìṣòro ìgbésí ayé ojoojúmọ́. Báwo ni a ṣe lè lo gbogbo àǹfààní tí ó bá ṣí sílẹ̀ fún wa lójoojúmọ́ láti yin Jehofa, nígbà tí a ní iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tí ń gba gbogbo àkókò wa? A kò sì lè fọwọ́ rọ́ ojúṣe ìdílé tí ń béèrè ọ̀pọ̀ jù lọ lára àkókò wa sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan. Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ọ̀dọ́ ni àwọn ohun tí ó pọn dandan, tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀ràn ilé ẹ̀kọ́, ti mú ọwọ́ wọn dí fọ́fọ́. Àwọn kan lè ronú pé kò ṣeé ṣe láti yin Jehofa ní gbangba lójoojúmọ́. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn kan lè máà ṣàjọpín ìhìn rere ní ọ̀nà kankan fún odindi oṣù kan gbáko.

4 Jeremiah jẹ́ ẹnì kan tí kò lè ṣàìwàásù. Nígbà tí ó kùnà fún ìgbà díẹ̀ láti sọ̀rọ̀ lórúkọ Jehofa, ó nímọ̀lára pé iná tí kò ṣeé pa mọ́ra ń jó nínú òun. (Jer. 20:9) Lójú ohun tí ó jọ másùnmáwo lílágbára, Jeremiah máa ń wá ọ̀nà kan ṣáá láti jíhìn iṣẹ́ Jehofa fún àwọn ẹlòmíràn nígbà gbogbo. A ha lè fara wé àpẹẹrẹ ìgboyà rẹ̀, kí a sì tẹpẹlẹ mọ́ wíwá àwọn àǹfààní tí ó lè jẹ yọ láti yin Ẹlẹ́dàá wa lójoojúmọ́?

5 Sísọ̀rọ̀ nípa Jehofa kò ní láti mọ sí àwọn àkókò tí ó jẹ́ bí àṣà, tí a ṣètò fún wíwàásù pẹ̀lú àwọn akéde mìíràn nínú ìpínlẹ̀ ìjọ. Ẹni tí yóò fetí sílẹ̀ ni a ń wá. A ń bá àwọn ènìyàn pàdé léraléra lójoojúmọ́—wọ́n ń wá sí ilé wa, a ń ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú wọn lẹ́nu iṣẹ́, a ń tò sórí ìlà pẹ̀lú wọn ní ilé ìtajà, a ń rajà pẹ̀lú wọn ní ọjà, a sì ń wọkọ̀ pẹ̀lú wọn. Gbogbo ohun tí ó ń béèrè kò ju ìkíni bí ọ̀rẹ́ àti ìbéèrè tàbí ọ̀rọ̀ tí ń múni ronú, tí yóò ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀. Ọ̀pọ̀ ti rí i pé èyí ni ọ̀nà ìjẹ́rìí tí ń méso jáde jù lọ fún wọn. Nígbà tí a ní ọ̀pọ̀ àǹfààní láti bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa ìhìn rere, etí kò gbọdọ̀ gbọ́ pé a kò wàásù Ìjọba fún odindi oṣù kan gbáko.

6 Àǹfààní yíyin Jehofa kì yóò dópin láé. Gẹ́gẹ́ bí onipsalmu ti fi hàn, gbogbo ohun abẹ̀mí ní láti máa yin Jehofa, dájúdájú, a sì fẹ́ wà lára wọn. (Orin Da. 150:6) Bí ọkàn-àyà wa bá sún wa láti máa ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà gbogbo, a óò lo gbogbo àǹfààní tí ó bá ṣí sílẹ̀ fún wa lójoojúmọ́ láti sọ̀rọ̀ nípa Jehofa àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́