ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 10/95 ojú ìwé 7
  • A Nílò Ìjọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • A Nílò Ìjọ
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1995
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Ìjọ Máa Yin Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Kí a Gbé Ìjọ Ró
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Gbogbo Wa La Wúlò Nínú Ìjọ!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020
  • Mọyì Ojúṣe Rẹ Nínú Ìjọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1995
km 10/95 ojú ìwé 7

A Nílò Ìjọ

1 Nígbà kan rí, àwọn ọmọ Kora fi ìmọrírì wọn hàn fún ìjọ Jehofa ní ọ̀nà yìí: “Ọjọ́ kan nínú àgbàlá rẹ sàn ju ẹgbẹ̀rún ọjọ́ lọ [níbòmíràn].” (Orin Da. 84:10) Fún wọn, ní ìfiwéra, ayé kò ní ohunkóhun láti fi fúnni. Bí o bá nímọ̀lára lọ́nà kan náà, ó yẹ kí ìgbésí ayé rẹ rọ̀ mọ́ ìjọ.

2 Láti ìgbà tí a ti dá a sílẹ̀, ìjọ Kristian ti fi hàn pé ìbùkún Jehofa wà lórí òun. (Ìṣe 16:4, 5) Ẹnikẹ́ni nínú wa kò gbọdọ̀ fojú tín-ínrín ìjọ tàbí ronú pé ó wulẹ̀ jẹ́ ọ̀nà kan láti pàdé pọ̀ nípa ti ara. Ìjọ jẹ́ ibi tí a ti ń fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa àdúgbò ní okun àti ìṣírí. Ó ń pèsè ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ oníṣọ̀kan, kí Jehofa baà lè kọ́ wa, kí a sì lè ṣètò wa fún ìgbòkègbodò Ìjọba.—Isa. 2:2.

3 Ìjọ Kristian jẹ́ ibi pàtàkì tí a ti ń kọ́ wa ní òtítọ́. (1 Tim. 3:15) Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jesu gbọ́dọ̀ “jẹ́ ọ̀kan”—ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Ọlọrun, pẹ̀lú Kristi, àti pẹ̀lú ara wọn lẹ́nì kíní-kejì. (Joh. 17:20, 21; fi wé Isaiah 54:13.) Ibi yòówù kí a lè lọ nínú ayé, àwọn ará wa gba àwọn ẹ̀kọ́ àti ìlànà Bibeli gbọ́, wọ́n sì ń gbé ní ìbámu pẹ̀lú wọn.

4 A ti kọ́ wa, a sì ti mú wa gbara dì láti mú iṣẹ́ àyànfúnni wa ti sísọ àwọn ènìyàn di ọmọ ẹ̀yìn ṣẹ. Lóṣooṣù, Ilé-Ìṣọ́nà, Jí!, àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ń fúnni ní ìsọfúnni tí ó ṣàǹfààní láti ràn wá lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò tí a gbé karí Ìwé Mímọ́. A ṣètò àwọn ìpàdé láti fi bí a ṣe lè wá ọkàn-ìfẹ́ rí, kí a sì mú un dàgbà hàn wá. Àwọn ìbísí tí a ń rí kárí ayé jẹ́rìí sí i pé Ọlọrun ń ti iṣẹ́ wa yìí lẹ́yìn.—Matt. 28:18-20.

5 Nípasẹ̀ ìjọ, a ń gba ìṣírí ‘tí ń ru wa lọ́kàn sókè sí ìfẹ́ ati sí awọn iṣẹ́ àtàtà,’ lójoojúmọ́. (Heb. 10:24, 25) A ń fún wa lókun láti fi ìṣòtítọ́ fara da àwọn àdánwò. Àwọn alábòójútó onífẹ̀ẹ́ ń ràn wá lọ́wọ́ láti kojú ìkìmọ́lẹ̀ àti àníyàn. (Oniwasu 4:9-12) A ń fún wa ní ìmọ̀ràn tí a nílò nígbà tí a bá wà nínú ewu ti ṣíṣáko lọ. Ètò àjọ mìíràn wo ni ń pèsè ìrú àbójútó onífẹ̀ẹ́ bí èyí?—1 Tessa. 5:14.

6 Ìfẹ́ inú Jehofa ni pé kí a dúró pẹ́kípẹ́kí ti ètò àjọ rẹ̀, kí a baà lè pa ìṣọ̀kan wa mọ́. (Joh. 10:16) Ọ̀nà kan tí ìjọ ń gbà ràn wá lọ́wọ́ láti pa àjọṣepọ̀ pẹ̀lú olùṣòtítọ́ ẹrú mọ́ ni nípa rírán àwọn alábòójútó arìnrìn àjò jáde láti fún wa níṣìírí. Dídáhùn padà wa sí ìtọ́sọ́nà onífẹ̀ẹ́ ń so wá pọ̀ nínú ìṣọ̀kan tí ń ṣèrànwọ́ láti mú wa lágbára nípa tẹ̀mí.

7 Ìjọ ṣe kókó fún ìgbàlà wa nípa tẹ̀mí. Láìsí i, a kò lè sin Jehofa pẹ̀lú ìtẹ́wọ́gbà. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a dúró pẹ́kípẹ́kí ti ohun tí Jehofa ti pèsè. Ǹjẹ́ kí a ṣiṣẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú góńgó rẹ̀, kí a sì fi tinútinú fi àwọn ìmọ̀ràn tí a ń gbà níbẹ̀ sílò. Ní ọ̀nà yìí níkan ṣoṣo ní a lè gbà fi bí ìjọ ti jẹ wá lógún tó hàn.—Orin Da. 27:4.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́