Pa Òye Ìjẹ́kánjúkánjú Rẹ Mọ́
Ọ̀NÀ kan ṣoṣo wo ni ó dájú pé, Ọlọrun fọwọ́ sí láti máa bá ṣíṣiṣẹ́ sin Jehofa tọkàntọkàn nìṣó? Ó jẹ́ láti ní ojúlówó òye ìjẹ́kánjúkánjú tí ó jinlẹ̀ nínú ọkàn wa. Ṣíṣiṣẹ́ sin Ọlọrun tọkàntọkàn túmọ̀ sí ṣíṣiṣẹ́ sìn ín tọkàntara, ó sì béèrè ìgbọràn tí a fọkàn ṣe délẹ̀délẹ̀ sí gbogbo ohun tí ó bá ní kí a ṣe.
Wòlíì náà, Mose, tẹnu mọ́ àìní náà, nígbà tí ó fún orílẹ̀-èdè Israeli ní ìtọ́ni pé: “Kí ìwọ kí o fi gbogbo àyà rẹ àti gbogbo ọkàn rẹ̀, àti gbogbo agbára rẹ fẹ́ OLUWA Ọlọrun rẹ.” (Deuteronomi 6:5) Ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn náà, Kristi Jesu tún àṣẹ kan náà pa pé: “Iwọ gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jehofa Ọlọrun rẹ pẹlu gbogbo ọkàn-àyà rẹ ati pẹlu gbogbo ọkàn rẹ ati pẹlu gbogbo èrò-inú rẹ.” (Matteu 22:37) Aposteli Paulu mẹ́nu kan ohun àbéèrè fún kan náà yìí, nígbà tí ó sọ fún àwọn ará Efesu láti ṣe “ìfẹ́-inú Ọlọrun tọkàntọkàn,” àti nígbà tí ó rọ àwọn ará Kolosse pé: “Ohun yòówù tí ẹ bá ń ṣe, ẹ fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ lẹ́nu rẹ̀ bí ẹni pé fún Jehofa, kì í sì í ṣe fún ènìyàn.”—Efesu 6:6; Kolosse 3:23.
Bí ó ti wù kí ó rí, ó nira láti fi tọkàn-tara sínú iṣẹ́-ìsìn wa sí Ọlọrun, bí a kò bà ni ìmọ̀lára ìjẹ́kánjúkánjú jíjinlẹ̀ nínú ara wa tàbí bí òye ìjẹ́kánjúkánjú tí a ní nígbà kan rí bá tí lọ sílẹ̀ nísinsìnyí—bóyá tí ó ti sọnu pátápátá. Lónìí, a ń gbé ní àkókò kánjúkánjú kan, tí kò bá sáà èyíkèyìí mìíràn nínú ìtàn ẹ̀dá ènìyàn dọ́gba.
Àwọn Sáà Ìjẹ́kánjúkánjú Tí Ó Ṣe Pàtó
Ní àwọn àkókò tí ó ṣáájú sànmánì Kristian, àwọn sáà ìjẹ́kánjúkánjú mélòó kan wà. Dájúdájú ọjọ́ Noa àti sáà tí ó jálẹ̀ sí ìparun Sodomu àti Gomorra jẹ́ àwọn àkókò ìjẹ́kánjúkánjú ní ti gidi. (2 Peteru 2:5, 6; Juda 7) Láìsí iyè méjì, àwọn ọdún tí ó ṣáájú Ìkún Omi kún fún ìgbòkègbodò kánjúkánjú. Àní bí Noa àti ìdílé rẹ̀ kò tilẹ̀ mọ ìgbà tí Àkúnya náà yóò bẹ̀rẹ̀ ní pàtó, “ìbẹ̀rù Ọlọrun” tí wọ́n ní yóò ti mú un dá wọn lójú pé, wọn kò ní láti máa fòní dónìí fọ̀la dọ́la.—Heberu 11:7.
Lọ́nà jíjọra, ṣáájú ìparun Sodomu àti Gomorra, àwọn áńgẹ́lì “bẹ̀rẹ̀ sí kán Loti lójú,” wọ́n sì sọ fún un pé: “Sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ!” (Genesisi 19:15, 17, NW) Bẹ́ẹ̀ ni, ní àkókò yẹn kan náà, ìjẹ́kánjúkánjú gba àwọn olódodo là. Ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn náà, a gba àwọn Júù òǹdè ní Babiloni níyànjú pé: “Ẹ fà sẹ́yìn, ẹ fà sẹ́yìn, ẹ jáde kúrò láàárín rẹ̀, ẹ má fọwọ́ kan ohun àìmọ́ kan: ẹ kúrò láàárín rẹ̀.” (Isaiah 52:11) Ní 537 B.C.E., nǹkan bí 200,000 tí a kó ní ìgbèkùn ni ó jáde kúrò ní Babiloni ní wàràǹṣeṣà, ní ṣíṣe ìgbọràn sí àsọtẹ́lẹ̀ àṣẹ kánjúkánjú náà.
Òye ìjẹ́kánjúkánjú nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ipò wọ̀nyẹn yọrí sí iṣẹ́ ìsìn àfitọkàntọkànṣe láti ọ̀dọ̀ àwọn tí wọ́n mọ̀ pé àwọn ń gbé ní àkókò kánjúkánjú, tí wọ́n sì pa ìgbàgbọ́ náà mọ́ láàyè.
Ìjẹ́kánjúkánjú ní Àkókò Kristian
A tún lè gbúròó bí ìjẹ́kánjúkánjú ṣe ń dún léraléra jálẹ̀ Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki. “Ẹ máa wọ̀nà,” “ẹ máa wà lójúfò,” “ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà,” “ẹ wà ní ìmúratán”—gbogbo gbólóhùn wọ̀nyí ní Kristi Jesu lò láti gbin òye ìjẹ́kánjúkánjú tí ó tọ́ sínú àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. (Matteu 24:42-44; Marku 13:32-37) Ní àfikún sí i, gbogbo àwọn àkàwé rẹ̀ nípa àwọn wúńdíá mẹ́wàá, ẹrú burúkú, tálẹ́ńtì, àti yíya àwọn àgùntàn kúrò lára àwọn ewúrẹ́, ru ìfojúsọ́nà sókè, ó sì mú ìmọ̀lára ìjẹ́kánjúkánjú jáde.—Matteu 25:1, 14, 15, 32, 33.
Kì í ṣe pé Jesu sọ̀rọ̀ nípa ìjẹ́kánjúkánjú nìkan ni, ṣùgbọ́n ó tún ti ìjótìítọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́yìn nípa fífi ìjẹ́kánjúkánjú ṣiṣẹ́. Ní àkókò kan, ó sọ fún ogunlọ́gọ̀ náà nígbà tí wọ́n gbìyànjú láti dá a dúró pé: “Emi gbọ́dọ̀ polongo ìhìnrere ìjọba Ọlọrun fún awọn ìlú-ńlá mìíràn pẹlu, nitori pé tìtorí èyí ni a ṣe rán mi jáde.” (Luku 4:42, 43) Síwájú sí i, ó fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ níṣìírí láti bẹ Ọ̀gá ìkórè náà láti rán àwọn òṣìṣẹ́ púpọ̀ sí i jáde sínú ìkórè Rẹ̀ nítorí pé, “ìkórè pọ̀, ṣugbọn ìwọ̀nba díẹ̀ ni awọn òṣìṣẹ́.” (Matteu 9:37, 38) Irú ìbéèrè tàdúràtàdúrà bẹ́ẹ̀ sí Ọlọrun ń fi ẹ̀mí ìjẹ́kánjúkánjú hàn ní tòótọ́.
A Ha Ṣi Ìjẹ́kánjúkánjú Bẹ́ẹ̀ Lò Bí?
Àwọn kan lè gbé ìbéèrè tí ó bọ́gbọ́n mu náà jáde pé, Èé ṣe tí a fi nílò òye ìjẹ́kánjúkánjú nígbà náà lọ́hùn-ún, bí “ìpọ́njú ńlá” tí a sọ tẹ́lẹ̀ náà bá ṣì wà ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún níwájú?—Matteu 24:21.
A lè ní ìdánilójú pé Jesu kò lò ó bí arúmọjẹ lásán láti mú kí ọwọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ dí nínú iṣẹ́ wíwàásù àti kíkọ́ni. Rára o, ìfẹ́ tí Kristi ní fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, àti òye rẹ̀ pípé nípa ojú ìwòye Jehofa nípa àkókò, ni ìpìlẹ̀ fún ìmọ̀ràn rẹ̀ lórí ìjẹ́kánjúkánjú. Bẹ́ẹ̀ ni, Kristi Jesu mọ̀ pé a nílò ẹ̀mí ìjẹ́kánjúkánjú láti ṣàṣeparí ìfẹ́ inú Jehofa ní ìbámu pẹ̀lú ète Ọlọrun. Síwájú sí i, ó mọ̀ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun fúnra wọn yóò jàǹfààní nípa tẹ̀mí nípa pípa òye ìjẹ́kánjúkánjú wọn mọ́ títí òun yóò fi dé.
Jesu Kristi ti fi hàn kedere pé ìjẹ́rìí kárí ayé kan wà tí a ní láti ṣe parí láàárín àkókò kúkúrú. (Matteu 24:14; Marku 13:10) A ṣí àwọn ipele oníṣìsẹ̀ntẹ̀lé ti iṣẹ́ àyànfúnni yìí payá kìkì bí iṣẹ́ náà ṣe ń wá sí ojútáyé. Ṣùgbọ́n a nílò ìjẹ́kánjúkánjú láti lè gbé ìgbésẹ̀ kọ̀ọ̀kan. Jesu fi bí iṣẹ́ àyànfúnni yìí ṣe jẹ́ ṣísẹ̀ntẹ̀lé hàn, nígbà tí ó wí pé: “Ẹ óò sì jẹ́ ẹlẹ́rìí mi ní Jerusalemu ati ní gbogbo Judea ati Samaria ati títí dé apá ibi jíjìnnà jùlọ ní ilẹ̀-ayé.” (Ìṣe 1:8) Bí iṣẹ́ àyànfúnni náà sì ṣe wá sí ojútáyé nìyẹn títí di ọjọ́ òní. Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, ó ti túmọ̀ sí ìyàlẹ́nu kan fún àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun, tí ó sì ń béèrè fún àtúnṣebọ̀sípò nínú òye nígbà mìíràn.
Òye ìjẹ́kánjúkánjú ti Kristian ti ṣiṣẹ́ fún ète Jehofa. Ó ti ran àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ àyànfúnni wọn ní ṣísẹ̀ntẹ̀lé ní ìbámu pẹ̀lú ìṣètò Jehofa tí kò lábùkù. Bẹ́ẹ̀ sì ni lónìí, bí a bá bojú wẹ̀yìn wo ohun tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 2,000 ọdún, a túbọ̀ ń lóye ìṣètò àtọ̀runwá náà lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ sí i.
Ìjẹ́kánjúkánjú ti Kristian ran àwọn ọmọ ẹ̀yìn lọ́wọ́ láti jẹ́rìí kúnnákúnná ní Jerusalemu, Judea, Samaria, àti fún àwọn Júù tí a fọ́n ká ṣáájú 36 C.E., nígbà tí ojú rere àkànṣe tí a fi hàn sí Israeli wá sópin. (Danieli 9:27; Ìṣe 2:46, 47) Lọ́nà jíjọra, ìjẹ́kánjúkánjú Kristian ṣèrànwọ́ fún ìjọ ìjímìjí ní fífún gbogbo àwọn Júù ní ìkìlọ̀ kedere pé ètò ìgbékalẹ̀ wọn yóò dópin láìpẹ́. (Luku 19:43, 44; Kolosse 1:5, 6, 23) Lẹ́yìn tí ó sì parí láìròtẹ́lẹ̀ ní 70 C.E., ìjẹ́kánjúkánjú ran àwọn ẹlẹ́rìí Kristi ní ọ̀rúndún kìíní lọ́wọ́ láti polongo ìrètí ti ọ̀run fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ṣáájú kí ìpẹ̀yìndà tí a sọ tẹ́lẹ̀ náà tó tan òkùnkùn tẹ̀mí rẹ̀ tí ń ṣekú pani kálẹ̀. (2 Tessalonika 2:3; 2 Timoteu 4:2) Lẹ́yìn náà, jálẹ̀ àwọn ọ̀rúndún Sànmánì Ojú Dúdú, àwọn Kristian kéréje tí ó dà bí àlìkámà pa ìrètí Ìjọba náà mọ́ láàyè, gẹ́gẹ́ bí Kristi Jesu ti sọ tẹ́lẹ̀. (Matteu 13:28-30) Paríparí rẹ̀, nígbà tí àkókò tí Jehofa yàn kalẹ̀ tó, ó gbé ìjọ òde òní tí ó lókun dìde, tí ìhìn isẹ́ kánjúkánjú ti ìdájọ́ rẹ̀ fún àwọn wọnnì tí ń gbé ní ìran tí ó gbẹ̀yìn yìí gbún ní kẹ́ṣẹ́.—Matteu 24:34.
Gẹ́gẹ́ bíi Danieli ìgbàanì, àwọn Ẹlẹ́rìí Ọlọrun tí wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́ lóde òní kì yóò dágbá lé e láti béèrè lọ́wọ́ Jehofa pé: “Kí ni ìwọ ń ṣe nì?” (Danieli 4:35) Wọ́n ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé Jehofa mọ ohun tí ó yẹ wẹ́kú láti rí i pé iṣẹ́ òun di ṣíṣe ní àkókò. Nítorí náà, kàkà kí wọn gbé ìbéèrè dìde sí ọ̀nà tí Jehofa ń gbà ṣètò nǹkan, wọ́n láyọ̀ pé Ọlọrun ti fún wọn ní àǹfààní láti ṣiṣẹ́ papọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ ní àkókò pàtàkì yìí.—1 Korinti 3:9.
Ìṣírí Síwájú Sí i fún Ìjẹ́kánjúkánjú
Ìdí mìíràn fún ìjẹ́kánjúkánjú ni agbára tí a kò ní láti tọ́ka sí ọjọ́ àti wákàtí náà gan-an tí ìpọ́njú ńlá náà yóò bẹ́ sílẹ̀ lójijì. Ó dá Kristi Jesu lójú pé kò sí ẹnikẹ́ni lórí ilẹ̀ ayé tí ó mọ ọjọ́ àti wákàtí náà tí a ti pinnu tẹ́lẹ̀ pé ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ṣe kókó náà yóò bẹ̀rẹ̀. (Matteu 24:36) Ní àkókò mìíràn, ó sọ fún àwọn aposteli rẹ̀ tí ń hára gàgà pé: “Kì í ṣe tiyín lati mọ awọn àkókò tabi àsìkò tí Baba ti fi sí abẹ́ àṣẹ oun fúnra rẹ̀.” (Ìṣe 1:7) Bẹ́ẹ̀ ni, àbájáde náà ṣe kedere, ṣùgbọ́n kì í ṣáà ṣe tiwa láti mọ gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ náà.
Aposteli Paulu ní ìṣarasíhùwà tí ó tọ́ nípa ìjẹ́kánjúkánjú. Ó ṣeé ṣe kí ó ti ní àwọn ọ̀rọ̀ Jesu lọ́kàn, nígbà tí ó kọ̀wé sí àwọn ará Tessalonika nípa wíwà níhìn-ín Kristi pé: “Wàyí o níti awọn àkókò ati awọn àsìkò, ẹ̀yin ará, ẹ kò nílò kí a kọ̀wé nǹkankan sí yín.” (1 Tessalonika 5:1) Ó kọ lẹ́tà yìí ní nǹkan bí ọdún 17 lẹ́yìn tí Jesu ti wí pé: “Ẹ óò sì jẹ́ ẹlẹ́rìí mi . . . títí dé apá ibi jíjìnnà jùlọ ní ilẹ̀-ayé.” (Ìṣe 1:8) Ní àkókò yẹn, a kò lè kọ jù bẹ́ẹ̀ lọ nítorí pé a kò tí ì ṣí ohunkóhun payá sí i. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, wọ́n lè ní ìgbọ́kànlé pé dájúdájú, ọjọ́ Jehofa yóò dé “gẹ́gẹ́ bí olè ní òru,” nígbà tí àwọn Kristian yóò ṣì máa wàásù pẹ̀lú ìjẹ́kánjúkánjú.—1 Tessalonika 5:2.
Pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ní ọkàn, bóyá ni ó fi lè jẹ́ pé àwọn Kristian ọ̀rúndún kìíní rò pé ọjọ́ Jehofa ṣì jẹ́ ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sí i. Lóòótọ́, wọ́n mọ̀ nípa àwọn òwe àkàwé Jesu nípa ọba náà tí o lọ sí ilẹ̀ tí ó jìnnà rere àti nípa ọkùnrin náà tí o rìnrìn àjò lọ sí ilẹ̀ òkèèrè. Wọ́n tún mọ̀ pé àwọn òwe àkàwé náà fi hàn pé ọba náà yóò padà wá ní “àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀,” tí arìnrìn-àjò náà yóò sì padà wá “lẹ́yìn àkókò gígùn.” Ṣùgbọ́n láìṣiyèméjì wọ́n ṣe kàyéfì nípa irú ìbéèrè bíi, Nígbà wo ni “àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀”? Kí sì ni “lẹ́yìn àkókò gígùn” túmọ̀ sí? Ọdún mẹ́wàá ha ni bí? Ogún ọdún ha ni bí? Àádọ́ta ọdún ha ni bí? Àbí ó gùn jù bẹ́ẹ̀ lọ? (Luku 19:12, 15; Matteu 25:14, 19) Àwọn ọ̀rọ̀ Jesu yóò máa bá a nìṣó láti dún gbọnmọgbọnmọ létí wọn pé: “Ẹ̀yin pẹlu, ẹ wà ní ìmúratán, nitori pé ní wákàtí tí ẹ kò ronú pé ó lè jẹ́ ni Ọmọkùnrin ènìyàn ń bọ̀.”—Luku 12:40.
Ìyọrísí Dídára Ti Ìjẹ́kánjúkánjú
Bẹ́ẹ̀ ni, òye ìjẹ́kánjúkánjú tí Ọlọrun ń sún ṣiṣẹ́ ní ìyọrísí ìṣírí àgbàyanu lórí àwọn Kristian ọ̀rúndún kìíní, ní ríràn wọ́n lọ́wọ́ láti mú kí ọwọ́ wọn dí nínú iṣẹ́ tí ó ṣe pàtàkì jù lọ náà, ti wíwàásù àti kíkọ́ni. Ó ń bá a nìṣó láti máa fún wa níṣìírí lónìí ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà. Ó gbà wá lọ́wọ́ níní ìtẹ́lọ́rùn àìbìkítà tàbí ‘kí agara dá wa ní rere íṣe.’ (Galatia 6:9, King James Version) Ó dáàbò bò wá lọ́wọ́ ṣíṣe wọléwọ̀de pẹ̀lú ayé àti kíkó wọnú ẹ̀mí ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì rẹ̀ tí ń yọ́ kẹ́lẹ́ ṣeni lọ́ṣẹ́. Ó pa ọkàn wa pọ̀ sórí “ìyè tòótọ́ gidi.” (1 Timoteu 6:19) Oluwa náà Jesu wí pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun yóò dà bí “àgùtàn sáàárín ìkòokò,” ó sì mọ àìní náà fún wa láti pa ojú ìwòye onípinnu dídúró gbọn-in mọ́, láti baà lè gbéjà ko ayé. Bẹ́ẹ̀ ni, a ti pa wá mọ́, a ti dáàbò bò wá nípasẹ̀ òye ìjẹ́kánjúkánjú Kristian wa.—Matteu 10:16.
Nínú ọgbọ́n rẹ̀ tí kò lópin, Jehofa Ọlọrun ti máa ń fìgbà gbogbo fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní ìsọfúnni tí ó tó fún wọn láti pa òye ìjẹ́kánjúkánjú wọn mọ́ láàyè. Pẹ̀lú inúrere ni ó fi dá wa lójú pé a ń gbé ní “awọn ọjọ́ ìkẹyìn” ètò ìgbékalẹ̀ nǹkan ìsinsìnyí, tí ó ti díbàjẹ́ yìí. (2 Timoteu 3:1) A ń rán wa létí léraléra pé, a gbọ́dọ̀ máa tàn gẹ́gẹ́ bí olùtan ìmọ́lẹ̀ títí di ìgbà tí ìran tí a ń gbé nínú rẹ̀ bá kọjá lọ nínú ìpọ́njú ńlá, tí yóò dé òtéńté rẹ̀ ní Har–Magedoni.—Filippi 2:15; Ìṣípayá 7:14; 16:14, 16.
Bẹ́ẹ̀ ni, oyè ìjẹ́kánjúkánjú lọ́nà ti Ọlọrun jẹ́ apá kan iṣẹ́-ìsìn tọkàntọkàn wa sí Jehofa. Ó ń bi àwọn ìgbìdánwò Èṣù láti mú kí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun ‘ṣàárẹ̀, kí wọ́n sì rẹ̀wẹ̀sì ninu ọkàn wọn’ wó, ó sì ń ké àwọn ìgbìdánwò Èṣù nígbèrí. (Heberu 12:3) Títí ayérayé fáàbàdà, ìfọkànsìn tọkàntọkàn yóò mú kí àwọn ìránṣẹ́ Jehofa máa ṣègbọràn sí i, ṣùgbọ́n nísinsìnyí, ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí tí ó ṣáájú Armageddoni, ojúlówó òye ìjẹ́kánjúkánjú jíjinlẹ̀ jẹ́ apá ṣíṣe kókó nínú ìfọkànsìn tọkàntọkàn wa.
Ǹjẹ́ kí Jehofa Ọlọrun wa ran gbogbo wá lọ́wọ́ láti pa òye ìjẹ́kánjúkánjú wa mọ́ bí a ṣe ń bá a nìṣó láti máa sọ àwọn ọ̀rọ̀ aposteli Johannu náà ní àsọtúnsọ pé: “Àmín! Máa bọ̀, Jesu Oluwa.”—Ìṣípayá 22:20.