ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Lo Àwọn Ìwé Ìròyìn Wa Lọ́nà Tí Ó Dára Jù Lọ
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba—1996 | March
    • wọn, àní bi a kò bá tíì fi gbogbo wọn sode laaarin oṣu kan tabi meji si ìgbà ti a tẹ̀ wọn jade paapaa. Isọfunni ti wọn ní ninu kò dinku ni ijẹpataki nitori akoko ti o ti kọja . . . Jijẹ ki awọn iwe-irohin ti o ti pẹ́ sẹ́jọ láláìlò wọn rara fi aini imọriri hàn fun awọn ohun-eelo iyebiye wọnyi. . . . Dipo yíyọ awọn itẹjade ti o ti pẹ́ silẹ ki a sì gbagbe nipa wọn, kò ha ni dara ju lati lo isapa akanṣe lati fi wọn sode lọdọ awọn olufifẹhan bi?”

      16 Ọ̀pọ̀ àwọn aláìlábòsí ọkàn wà lónìí tí ń wá òtítọ́ kiri. Ìsọfúnni tí ó wà nínú ìwé ìròyìn kan ṣoṣo lè jẹ́ ohun gan-an tí wọ́n nílò láti ṣamọ̀nà wọn sínú òtítọ́! Jehofa ti fún wa ní ìhìn iṣẹ́ alárinrin láti pòkìkí, àwọn ìwé ìròyìn wa sì ń kó ipa pàtàkì nínú mímú ìhìn iṣẹ́ náà dé ọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn. Ìwọ yóò ha jẹ́ kí pípín ìwé ìròyìn kiri túbọ̀ jẹ ọ́ lọ́kàn ní ọjọ́ iwájú bí? Ìwọ yóò ha lo díẹ̀ lára àwọn àbá wọ̀nyí ní òpin ọ̀sẹ̀ tí a wà yìí bí? A óò bù kún ọ ní jingbinni bí o bá ṣe bẹ́ẹ̀.

      Àwọn Àbá Gbígbéṣẹ́:

      ◼ Ka àwọn ìwé ìròyìn náà ṣáájú àkókò, kí o sì dojúlùmọ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ inú wọn.

      ◼ Yan ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ohun kan tí àwọn ènìyàn àdúgbò rẹ máa ń nífẹ̀ẹ́ sí.

      ◼ Múra ìgbékalẹ̀ kan tí yóò bá onírúurú ènìyàn mu, bí ọkùnrin, obìnrin, tàbí àwọn èwe. Fi bí ìwé ìròyìn náà ṣe kan onílé náà hàn án, àti bí gbogbo ìdílé yóò ṣe gbádùn rẹ̀.

      ◼ Wéwèé láti nípìn-ín nínú ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìsìn pápá nígbà tí èyí tí ó pọ̀ jù lọ lára àwọn ènìyàn bá wà nílé. Àwọn ìjọ kan máa ń ṣètò fún ìjẹ́rìí ìrọ̀lẹ́ pẹ̀lú àwọn ìwé ìròyìn.

      ◼ Jẹ́ kí ìgbékalẹ̀ rẹ ṣe ṣókí, kí ó sì sọ ojú abẹ níkòó.

      ◼ Má ṣe sáré sọ̀rọ̀. Bí olùgbọ́ rẹ kò bá fìfẹ́ hàn, sísáré sọ̀rọ̀ kì í yóò ṣèrànwọ́. Gbìyànjú láti sinmẹ̀dọ̀, kí o sì fún onílé láǹfààní láti fèsì.

      ◼ Mú kí ìwé ìròyìn ní àwọn èdè míràn wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún àwọn ènìyàn tí yóò nílò wọn.

      Fífi Àwọn Ìwé Ìròyìn Lọni Láti Ilé dé Ilé:

      ◼ Rẹ́rìn-ín músẹ́ bí ọ̀rẹ́ kí o sì sọ̀rọ̀ jẹ́jẹ́.

      ◼ Jẹ́ onítara ọkàn nípa àwọn ìwé ìròyìn náà.

      ◼ Sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́ kí ó sì ṣe ketekete.

      ◼ Sọ̀rọ̀ lórí kókó ẹ̀kọ́ kan ṣoṣo; ru ọ̀kan-ìfẹ́ sókè nínú rẹ̀, kí o sì fi ìníyelórí rẹ̀ han onílé.

      ◼ Tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ kan ṣoṣo.

      ◼ Sọ̀rọ̀ lórí ìwé ìròyìn kan ṣoṣo, ní fífi èkejì kún un gẹ́gẹ́ bí amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀.

      ◼ Fi àwọn ìwé ìròyìn náà lé onílé lọ́wọ́.

      ◼ Jẹ́ kí onílé náà mọ̀ pé o wéwèé láti padà wá.

      ◼ Parí ọ̀rọ̀ rẹ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ bí ọ̀rẹ́ àti ìgbéniró, bí a kò bá gba àwọn ìwé ìròyìn náà.

      ◼ Kọ orúkọ gbogbo àwọn tí ó fi ìfẹ́ hàn àti àwọn ìwé tí o fi síta sílẹ̀ sínú àkọsílẹ̀ ilé-dé-ilé rẹ.

      Àwọn Àǹfààní Tí Ó Ń Ṣí Sílẹ̀ Láti Fi Àwọn Ìwé Ìròyìn Lọni:

      ◼ Ìjẹ́rìí ilé-dé-ilé

      ◼ Ìjẹ́rìí òpópónà

      ◼ Iṣẹ́ ìsọ̀-dé-ìsọ̀

      ◼ Ipa ọ̀nà ìwé ìròyìn

      ◼ Ìjẹ́rìí ìrọ̀lẹ́

      ◼ Nígbà tí a bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò

      ◼ Ṣíṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli àtijọ́

      ◼ Nígbà tí a bá ń rìnrìn àjò, tí a bá ń lọ rajà

      ◼ Nígbà tí a bá ń bá àwọn mọ̀lẹ́bí, àwọn òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ ẹni, àwọn aládùúgbò, àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ẹlẹgbẹ́ ẹni, àwọn olùkọ́ sọ̀rọ̀

      ◼ Nínú ọkọ̀ èrò, nínú àwọn iyàrá tí a ti ń dúró láti rí ẹnì kan

  • Ìpè Tí Ń runi Sókè Dún Jáde Ní Àpéjọpọ̀ Àgbègbè!—Ẹ Fi Ìdùnnú-Ayọ̀ Yin Jehofa Láti Ọjọ́ dé Ọjọ́!
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba—1996 | March
    • Ìpè Tí Ń runi Sókè Dún Jáde Ní Àpéjọpọ̀ Àgbègbè!—Ẹ Fi Ìdùnnú-Ayọ̀ Yin Jehofa Láti Ọjọ́ dé Ọjọ́!

      1 Aposteli Paulu béèrè pé: “Bí kàkàkí bá mú ìpè kan tí kò dún ketekete jáde, ta ni yoo gbaradì fún ìjà ogun?” (1 Kor. 14:8) Ìpè tí ó dún jáde ní Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Onídùnnú-Ayọ̀ Olùyìn” ha ròkè ketekete bí? Bẹ́ẹ̀ ni, ó ṣe bẹ́ẹ̀. ‘Ẹ yin Jehofa tìdùnnútìdùnnú lójoojúmọ́’ ni ìhìn iṣẹ́ tí ń runi sókè náà! Ìpè yìí ha ru ọkàn rẹ sókè sí iṣẹ́ bí? Ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọpọ̀ náà kún fún àwọn ìdí pàtàkì tí ó fi yẹ kí á máa yin Ọba ayérayé, Jehofa, déédéé.—Orin Da. 35:27, 28.

      2 Àwọn ọ̀run gígadabú ń polongo ògo Jehofa “láti ọjọ́ dé ọjọ́.” (Orin Da. 19:1-3) Bí àwọn ẹ̀dá aláìlèsọ̀rọ̀, aláìlẹ́mìí bá ń fi ìyìn fún Jehofa déédéé, kò ha yẹ kí á sún àwa ẹ̀dá ènìyàn olóye láti gbé ohùn wa sókè láti yìn ín nígbà gbogbo fún àwọn ànímọ́ àti àṣeyọrí rẹ̀ tí kò láfiwé bí? Ta ni ó tún yẹ fún ìyìn onídùnnú-ayọ̀ wa ju atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá wa lọ?—Orin Da. 145:3, 7.

      3 Láti Ọjọ́ dé Ọjọ́: Onípsalmu tí a mí sí kọ̀wé pé: “Ẹ máa fi ìgbàlà rẹ̀ hàn láti ọjọ́ dé ọjọ́. Nítorí tí Olúwa tóbi, ó sì ní ìyìn púpọ̀púpọ̀.” (Orin Da. 96:2, 4) Àwọn aṣáájú ọ̀nà nìkan ṣoṣo ha ni èyí kàn bí? Bẹ́ẹ̀ kọ́! Èyí ha túmọ̀ sí pé gbogbo wá ní láti sọ fún àwọn ẹlòmíràn nípa Jehofa nígbàkigbà àti níbikíbi tí a

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́