Ó Ha Yẹ Kí O Tọrọ Àforíjì Ní Tòótọ́ bí?
GEORGE Bernard Shaw kọ̀wé pé: ‘N kò tọrọ àforíjì rí.’ Àwọn mìíràn lè sọ pé: ‘Ohun tí mo bá ti ṣe, mo ti ṣe é nìyẹn.’
Bóyá àwa fúnra wa ń lọ́ tìkọ̀ láti gbà pé a jẹ̀bi nítorí kí ọ̀wọ̀ wa má baà dín kù. Bóyá a rò pé ẹnì kejì ni ó ní ìṣòro náà. Tàbí kí a lọ́kàn láti tọrọ àforíjì ṣùgbọ́n, kí a sún un síwájú títí di ìgbà tí a óò fi rò pé a ti gbójú fo ọ̀ràn náà.
Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀ nígbà náà, títọrọ àforíjì ha ṣe pàtàkì bí? Wọ́n ha lè ṣàṣeparí ohun kan ní tòótọ́ bí?
Ìfẹ́ Ń Mú Kí Ó Pọn Dandan fún Wa Láti Tọrọ Àforíjì
Ìfẹ́ ará jẹ́ àmì tí a fi ń dá àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi tòótọ́ mọ̀ yàtọ̀. Ó wí pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” (Jòhánù 13:35) Ìwé Mímọ́ rọ àwọn Kristẹni láti ‘nífẹ̀ẹ́ ara wọn lẹ́nì kíní kejì lọ́nà gbígbóná janjan láti inú ọkàn-àyà wá.’ (Pétérù Kìíní 1:22) Ìfẹ́ gbígbóná janjan ń mú kí ó pọn dandan fún wa láti tọrọ àforíjì. Èé ṣe? Nítorí pé àìpé ẹ̀dá ènìyàn máa ń fa ìbínú tí ń ká ìfẹ́ lọ́wọ́ kò lọ́nà tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀, bí a kò bá wá nǹkan ṣe sí i.
Fún àpẹẹrẹ, nítorí gbún-gbùn-gbún láàárín àwa àti ẹnì kan nínú ìjọ Kristẹni, a lè fẹ́ láti máa bá a yodì. Bí ó bá jẹ́ pé àwa ni a ti hùwà láìfí náà, báwo ni a ṣe lè mú ipò ìbátan onífẹ̀ẹ́ padà bọ̀ sípò? Nínú ọ̀ràn tí ó wọ́pọ̀ jù lọ, nípa títọrọ àforíjì àti sísapá láti fi ọ̀yàyà bá ẹni náà sọ̀rọ̀ ni. A jẹ àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa ní gbèsè ìfẹ́, nígbà tí a bá sì sọ pé, kí wọ́n má bínú fún ìwà láìfí kan tí a hù, a ti san díẹ̀ lára gbèsè yẹn.—Róòmù 13:8.
Láti ṣàkàwé: Mari Carmen àti Paqui jẹ́ obìnrin Kristẹni méjì tí wọ́n ti ń ṣọ̀rẹ́ bọ̀ láti ọjọ́ pípẹ́. Ṣùgbọ́n, nítorí pé Mari Carmen gba àwọn òfófó apanilára kan gbọ́, ọ̀rẹ́ òun àti Paqui kò da bíi ti àtẹ̀yìnwá mọ́. Láìṣàlàyé kankan, ó pa Paqui tì pátápátá. Nǹkan bí ọdún kan lẹ́yìn náà, Mari Carmen wá mọ̀ pé irọ́ ni òfófó náà. Kí ni ìhùwàpadà rẹ̀? Ìfẹ́ sún un láti tọ Paqui lọ, ó sì fi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ sọ ìkábàámọ̀ rẹ̀ jáde fún híhùwà lọ́nà búburú bẹ́ẹ̀. Àwọn méjèèjì bú sẹ́kún gidigidi, wọ́n sì ti wá di ọ̀rẹ́ kò-rí-kò-sùn láti ìgbà náà wá.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè má rò pé a ti ṣe ohun kan tí ó burú, títọrọ àforíjì lè yanjú èdè àìyedè. Manuel rántí pé: “Ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn èmi àti aya mi ń gbé ilé ọ̀kan nínú àwọn arábìnrin wa nípa tẹ̀mí nígbà tí ó wà ní ilé ìwòsàn. A ṣe gbogbo ohun tí a lè ṣe láti ran òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́ nígbà àìsàn rẹ̀. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà tí ó padà sílé, ó rojọ́ fún ọ̀rẹ́ kan pé a kò bá òun mójú tó ìnáwó ilé dáradára.
“A ṣèbẹ̀wò, a sì ṣàlàyé pé bóyá nítorí pé a jẹ́ ọ̀dọ́, tí a kò sì ní ìrírí, ni kò jẹ́ kí a lè bójú tó àwọn nǹkan bí ì bá ti ṣe. Kíá ni ó dáhùn padà nípa sísọ pé òun gan-an ni òun ní láti dúpẹ́ lọ́wọ́ wa, àti pé òun mọrírì gbogbo ohun tí a ti ṣe fún un gidigidi. Bí ìṣòro náà ṣe yanjú nìyẹn. Ìrírí yẹn kọ́ mi ní ìjẹ́pàtàkì fífi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ tọrọ ìdáríjì nígbà tí èdè àìyedè bá ṣẹlẹ̀.”
Jèhófà bù kún tọkọtaya yìí fún fífi ìfẹ́ hàn àti ‘lílépa àwọn ohun tí ń yọrí sí àlàáfíà.’ (Róòmù 14:19) Ìfẹ́ tún wé mọ́ kíkíyè sí ìmọ̀lára àwọn ẹlòmíràn. Pétérù rọ̀ wá láti máa fi “ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì hàn.” (Pétérù Kìíní 3:8) Bí a bá ń fi ìmọ̀lára hàn fún ọmọnìkejì, yóò lè ṣeé ṣe fún wa láti fòye mọ ìrora tí a ti fà nípa ọ̀rọ̀ tàbí ìṣe aláìnírònú, a óò sì sún wa láti tọrọ àforíjì.
“Ẹ Fi Ìrẹ̀lẹ̀ Èrò Inú Di Ara Yín Lámùrè”
Nígbà míràn, àwọn Kristẹni alàgbà olùṣòtítọ́ pàápàá lè fi ìbínú sọ̀rọ̀ sí ẹnì kíní kejì. (Fi wé Ìṣe 15:37-39.) Àwọn àkókò tí ìtọrọ àforíjì yóò ṣeni láǹfààní gan-an nìwọ̀nyí. Ṣùgbọ́n kí ni yóò ran alàgbà kan tàbí Kristẹni èyíkéyìí mìíràn tí ó ṣòro fún láti tọrọ àforíjì lọ́wọ́?
Ìrẹ̀lẹ̀ ni kọ́kọ́rọ́ náà. Àpọ́sítélì Pétérù gbani nímọ̀ràn pé: “Ẹ fi ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú di ara yín lámùrè sí ara yín lẹ́nì kíní kejì.” (Pétérù Kìíní 5:5) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òtítọ́ ni pé nínú ọ̀pọ̀ jù lọ awuyewuye, àwọn méjèèjì tí ọ̀ràn kàn ni wọ́n máa ń jẹ̀bi, Kristẹni onírẹ̀lẹ̀ yóò dàníyàn lórí àwọn ìkù-díẹ̀-káàtó tirẹ̀, yóò sì múra tán láti tẹ́wọ́ gbà wọ́n.—Òwe 6:1-5.
Ẹni tí a ń tọrọ àforíjì lọ́wọ́ rẹ̀ ní láti fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ gbà á. Fún àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ kí a sọ pé àwọn ọkùnrin méjì tí ó yẹ kí wọ́n jùmọ̀ sọ̀rọ̀ wà lórí òkè méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ tí yóò ré kọjá ọ̀gbun tí ó pín wọn níyà kò ṣeé ṣe. Ṣùgbọ́n, nígbà tí ọ̀kan nínú wọn bá sọ̀ kalẹ̀ sí àfonífojì tí ó wà nísàlẹ̀, tí ẹnì kejì sí tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀, wọ́n lè bá ara wọn sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìrọ̀rùn. Lọ́nà kan náà, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé àwọn Kristẹni méjì ní láti yanjú aáwọ̀ kan láàárín ara wọn, jẹ́ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn fi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ pàdé ẹnì kejì rẹ̀ nínú àfonífojì, kí a sọ ọ́ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, kí wọ́n sì tọrọ àforíjì tí ó yẹ.—Pétérù Kìíní 5:6.
Títọrọ Àforíjì Ṣe Pàtàkì Nínú Ìgbéyàwó
Ìgbéyàwó ẹni méjì tí wọ́n jẹ́ aláìpé ń pèsè àǹfààní láti tọrọ àforíjì lọ́nà tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀. Bí ọkọ àti aya bá sì ń fi ìfẹ́ hàn fún ìmọ̀lára ẹnì kíní kejì, yóò sún wọn láti tọrọ àforíjì bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé wọ́n sọ̀rọ̀ tàbí hùwà lọ́nà tí kò fi ìgbatẹnirò hàn. Òwe 12:18 tọ́ka sí i pé: “Àwọn kan ń bẹ tí ń yára sọ̀rọ̀ bí ìgúnni idà; ṣùgbọ́n ahọ́n ọlọgbọ́n, ìlera ni.” ‘Ọ̀rọ̀ bí ìgúnni idà’ kò lè ṣe kí ó má wáyé, ṣùgbọ́n a lè wò wọ́n sàn nípa àforíjì àtọkànwá. Àmọ́ ṣáá o, èyí ń béèrè fún wíwà lójú fò nígbà gbogbo àti ìsapá tí kò dáwọ́ dúró.
Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ nípa ìgbéyàwó rẹ̀, Susana sọ pé: “Èmi àti Jack* ti ṣègbéyàwó fún ọdún 24, ṣùgbọ́n a ṣì ń kọ́ ohun tuntun nípa ẹnì kíní kejì wa. Ó bani nínú jẹ́ pé, nígbà kan sẹ́yìn, a pínyà, a sì gbé ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ fún ọ̀sẹ̀ díẹ̀. Ṣùgbọ́n, a tẹ́tí sí ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ látẹnu àwọn alàgbà, a sì wà papọ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i. A wá mọ̀ nísinsìnyí pé, níwọ̀n bí a ti ní àkópọ̀ ìwà tí ó yàtọ̀ síra, ó ṣeé ṣe kí aáwọ̀ wáyé. Nígbà tí èyí bá sì ṣẹlẹ̀, a óò tọrọ àforíjì kíákíá, a óò sì gbìyànjú ní ti gidi láti lóye ojú ìwòye ẹnì kejì. Inú mi dùn láti sọ pé ìgbéyàwó wa ti sunwọ̀n sí i gidigidi.” Jack fi kún un pé: “A tún kọ́ láti mọ̀ àwọn àkókò ti inú máa ń tètè bí wa. Ní irú àwọn àkókò bẹ́ẹ̀, a máa ń bá ẹnì kíní kejì lò pẹ̀lú ìṣọ́ra gidigidi.”—Òwe 16:23.
Ó ha yẹ kí o tọrọ àforíjì bí o bá rò pé o kò jẹ̀bi bí? Nígbà tí ọ̀ràn bá kan ìmọ̀lára jíjinlẹ̀, ó ṣòro láti mọ ibi tí ẹ̀bi náà wà gan-an. Ṣùgbọ́n ohun tí ó ṣe pàtàkì jù lọ ni àlàáfíà nínú ìgbéyàwó. Gbé ọ̀ràn Ábígẹ́lì yẹ̀ wò, obìnrin Ísírẹ́lì kan tí ọkọ rẹ̀ hùwà ìkà sí Dáfídì. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò lè dá a lẹ́bi fún ìwà ẹ̀gọ̀ tí ọkọ rẹ̀ hù, ó tọrọ àforíjì. Ó bẹ̀bẹ̀ pé: “Èmi bẹ̀ ọ́, fi ìrékọjá ìránṣẹ́bìnrin rẹ jì í.” Dáfídì dáhùn padà nípa gbígba tirẹ̀ rò, ní fífi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ gbà pé bí kì í bá ṣe nítorí tirẹ̀, òun ì bá ti ta ẹ̀jẹ̀ aláìmọwọ́mẹsẹ̀ sílẹ̀.—Sámúẹ́lì Kìíní 25:24-28, 32-35.
Bákan náà, obìnrin Kristẹni kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ June, tí ó ti ṣègbéyàwó fún ọdún 45, ronú pé ìgbéyàwó aláṣeyọrí ń béèrè ìmúratán láti jẹ́ ẹni tí yóò kọ́kọ́ tọrọ àforíjì. Ó wí pé: “Mo bá ara mi sọ̀rọ̀ pé, ìgbéyàwó wa ṣe pàtàkì ju ìmọ̀lára mi gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan lọ. Nítorí náà, nígbà tí mo bá tọrọ àforíjì, mo ń nímọ̀lára pé mo ń mú ìgbéyàwó náà sunwọ̀n sí i.” Ọkùnrin àgbàlagbà kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jim sọ pé: “Mo máa ń tọrọ àforíjì lọ́wọ́ aya mi àní lórí àwọn ọ̀rọ̀ tí kò tó nǹkan pàápàá. Láti ìgbà tí a ti ṣiṣẹ́ abẹ lílágbára kan fún un, kì í pẹ́ ní ìrora ọkàn. Nítorí náà, mo máa ń fi ọwọ́ gbá a mọ́ra déédéé, tí mo sì máa ń sọ pé, ‘Jọ̀wọ́ má bínú, Olólùfẹ́ mi. N kò pète láti mú ọ bínú.’ Bí ohun ọ̀gbìn tí a bomi rin, lọ́gán ni ara rẹ̀ yóò yá gágá.”
Bí a bá ti mú ẹni tí a nífẹ̀ẹ́ jù lọ bínú, títọrọ àforíjì kíá mọ́sá máa ń gbéṣẹ́. Milagros fi tọkàntọkàn gbà, ní sísọ pé: “Mo ń jìyà lọ́wọ́ àìnígboyà, ọ̀rọ̀ líle látẹnu ọkọ mi sì máa ń bí mi nínú. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá tọrọ àforíjì, lọ́gán ni ìmọ̀lára mi máa ń yí padà.” Lọ́nà yíyẹ wẹ́kú, Ìwé Mímọ́ sọ fún wa pé: “Ọ̀rọ̀ dídùn dà bí afárá oyin, ó dùn mọ́ ọkàn, ó sì ṣe ìlera fún egungun.”—Òwe 16:24.
Sọ Títọrọ Àforíjì Dàṣà
Bí a bá sọ ọ́ dàṣà láti tọrọ àforíjì nígbà tí ó bá pọn dandan, ó ṣeé ṣe kí a rí i pé àwọn ènìyàn yóò dáhùn padà lọ́nà rere. Bóyá, wọn yóò sì fúnra wọn tọrọ àforíjì. Nígbà tí a bá fura pé a ti mú ẹnì kan bínú, èé ṣe tí a kò fi sọ ọ́ dàṣà láti tọrọ àforíjì dípò lílọ jìnnà dórí yíyẹ àṣìṣe sílẹ̀? Ayé lè rò pé títọrọ àforíjì jẹ́ àmì àìlera, ṣùgbọ́n ó fi ẹ̀rí ìdàgbàdénú Kristẹni ní ti gidi hàn. Àmọ́ ṣáá o, àwa kì yóò fẹ̀ láti dà bí àwọn tí wọ́n tẹ́wọ́ gba àwọn àṣìṣe kan, síbẹ̀ tí wọn fojú kéré ẹrù iṣẹ́ wọn. Fún àpẹẹrẹ, a ha ń sọ pé ẹ máà bínú ṣùgbọ́n tí kò dénú wa bí? Bí a bá pẹ́ kí a tó dé, tí a sì tọrọ àforíjì gan-an, a ha pinnu láti mú dídé lákòókò wa sunwọ̀n sí i bí?
Nígbà náà, bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ó ha yẹ kí a tọrọ àforíjì ní ti gidi bí? Bẹ́ẹ̀ ni, ó yẹ kí a ṣe bẹ́ẹ̀. A jẹ ara wa àti àwọn ẹlòmíràn ní gbèsè rẹ̀. Ìtọrọ àforíjì lè dín ìrora tí àìpé ń mú wá kù, ó sì lè mú àjọṣe tí kò lọ déédéé mọ́ sunwọ̀n sí i. Àforíjì kọ̀ọ̀kan tí a bá tọrọ jẹ́ kíkẹ́kọ̀ọ́ nínú ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, ó sì ń kọ́ wa láti túbọ̀ máa kíyè sí ìmọ̀lára àwọn ẹlòmíràn. Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí rẹ̀, àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa, alábàáṣègbéyàwó wa, àti àwọn ẹlòmíràn yóò wò wá gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó yẹ fún ìfẹ́ni wọn, tí ó sì ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé. A óò ní àlàáfíà èrò inú, Jèhófà Ọlọ́run yóò sì bù kún wa.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Kì í ṣe orúkọ wọn gan-an.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ìtọrọ àforíjì àtọkànwá ń gbé ìfẹ́ Kristẹni lárugẹ